Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Láti Jẹ́ Ọmọlẹ̀hìn Jésù Krístì
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


9:49

Láti Jẹ́ Ọmọlẹ̀hìn Jésù Krístì

Láti jẹ́ ọmọlẹ̀hìn Krístì ni làti tiraka láti mú àwọn ìṣe wa, ìhùwà, àti ìgbésí ayé wa wà ní ìbámu pẹ̀lú ti Olùgbàlà.

Nínú àṣàrò àwọn ìwé-mímọ́ ti ara mi, mo ti ní ìwúrí nípa ìyípadà Sáùlù ti Társù, ẹnití ó di mímọ̀ sí Páùlù lẹ́hìnwá, bí á ti ṣe àpèjúwe rẹ̀ nínú Bíbélì.

Páùlù jẹ́ ènìyàn tí nṣiṣẹ́ nínú inúnibíni ti Ìjọ àti àwọn Krìstìání. Ṣùgbọ́n nítorí agbára ọ̀run àti Ètùtù ti Jésù Krístì, a yí i padà pátápátá, ó sì di ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́ nlá Ọlọ́run. Àpẹ̀ẹrẹ ìgbésí ayé rẹ̀ ni OlùgbàIà Jésù Krístì.

Nínú ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀kọ́ Páùlù sí àwọn ará Kọ́ríntì, ó pè wọ́n láti jẹ́ ọmọlẹ́hìn rẹ̀ gẹ́gẹ́bí òun tìkararẹ̀ jẹ́ ọmọlẹ́hìn Krístì (wo 1 Kọ́ríntì 11: 1). Èyi jẹ́ ìpè tòótọ́ àti tí ó wúlò láti àkokò Páùlù títí di òní: láti jẹ́ ọmọlẹ́hìn Jésù Krístì.

Mo bẹ̀rẹ̀ láti ronú lórí ohun tí ó túmọ̀ sí láti di ọmọlẹ́hìn Krístì. Àti pàtàkì jùlọ, mo bẹ̀rẹ̀ síí bèèrè, “Ní ọ̀nà wo ni kí nṣe àfarawé Rẹ̀?”

Láti jẹ́ ọmọlẹ̀hìn Krístì ni làti tiraka láti mú àwọn ìṣe wa, ìhùwà, àti ìgbésí ayé wa wà ní ìbámu pẹ̀lú ti Olùgbàlà. Ó jẹ́ láti gba àwọn ìwà-rere. Ó jẹ́ láti jẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn tòótọ́ ti Jésù Krístì.

Mo ti ṣe àṣàrò díẹ̀ nínú àwọn apá kan ìgbésí ayé Olùgbàlà, àti pé mo ti mú, gẹ́gẹ́bí apákan ọ̀rọ̀ mi loni, mẹ́rin lára àwọn ìwà Rẹ̀ tí mo gbìyànjú láti farawé tí mo sì npín pẹ̀lú yín.

Ìwà àkọ́kọ́ Olùgbàlà ni ìrẹ̀lẹ̀. Jésù Krístì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ púpọ̀ láti ṣaájú-ayé-ikú. Ní Ìgbìmọ̀ ní Ọ̀run, Ó mọ̀ àti gba ìfẹ́ Ọlọ́run láàyè láti borí nínú ètò ìgbàlà fún ènìyàn. Ó sọ pé, “Baba, ìfẹ́ tìrẹ ni kí á ṣe, kí ògo sì jẹ́ tirẹ títí láéláé”(Mósè 4:2).

A mọ̀ pé Jésù Krístì kọ́ni ní ìrẹ̀lẹ̀ ó sì rẹ ara Rẹ̀ sílẹ̀ láti yin Baba Rẹ̀ lógo.

Ẹ jẹ́ kí á gbé ní ìrẹ̀lẹ̀ nítorí ó mú àlááfìá wa (wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 19:23). Ìrẹ̀lẹ̀ ṣaájú ògo, ó sì nmú ojúrere Ọlọ́run wá sórí wa: “Bẹ́ẹ̀ni, kí gbogbo yín tẹríba fún ara yín, kí ẹ sì fi ìrẹ̀lẹ̀ wọ ara yín lí aṣọ: nítorí Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn agbéraga, ó sì fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀”(1 Pétérù 5:5). Ìrẹ̀lẹ̀ mú àwọn ìdáhùn jẹ́jẹ́ wa. Ó jẹ́ orísun ìwà òdodo kan.

Alàgbà Dale G. Renlund kọ́ni:

“Àwọn ẹnìkộkan ẹnití nrìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run rántí ohun tí Baba Ọ̀run àti Jésù Krístì ti ṣe fún wọn.”

“A nṣe ìṣe ọlọ́lá pẹ̀lú Ọlọ́run nípa rírìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Rẹ” (“Ṣe Òdodo, Fẹ́ Àánú, kí o sì Rìn Ní Ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run,” Làìhónà, Oṣù Kọkànlá. 2020, 111, 109).

Ìwà èkejì Olùgbàlà ni ìgboyà. Nígbàtí mo ronú nípa Jésù Krístì ní ẹni ọdún méjìlá, tí ó joko ní tẹ́mpìlì Ọlọ́run láàrín àwọn dókítà ti òfin tí Ó sì nkọ́ wọn ní àwọn nkan ti ọ̀run, mo ṣe àkíyèsí pé Ó ti ní tẹ́lẹ̀, ní ìbẹ̀rẹ̀ ayé Rẹ̀, òye dídára kan ti ìgboyà, ìgboyà kan pàtó. Nígbàtí púpọ̀ jùlọ yio nírètí láti rí ọdọ́mọkùnrin náà ní kíkọ́ láti ọwọ́ àwọn dókítà ti òfin, Òun nkọ́ wọn bí “àwọ́n ṣe ngbọ́ tirẹ̀, àti ní bíbéèrè àwọn ìbéèrè” (Ìyírọ̀padà èdè Joseph Smith, Lúkù 2:46 [ní Lúkù 2:46, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé c]).

A sin ìgbàkíkún míṣọ̀n kan ní Democratic Republic ti Congo Mbuji-Mayi Míṣọ̀n láti 2016 si 2019. Ọnà láti rin ìrìn-ajo ní míṣọ̀n láti agbègbè kan sí òmíràn jẹ́ nípasẹ̀ ojú ọ̀nà. Ìyàlẹ́nu kan ti dìde ní agbègbè náà, pẹ̀lú àwọn oníjàgídí-jàgan tí wọ́n di ìhámọ́ra pẹ̀lú àwọn ohun ìjà tí wọ́n ti fi abẹfẹ́lẹ́ sí, ní bíbọ́ sí ojú ọ̀nà làti dàmú ìrìn àwọn arìnrìn-àjò.

Àwọn ìránṣẹ́-ìhìnrere marun tí wọ́n nrin ìrìn-àjò láti agbègbè kan sí òmíràn bíi apákan gbígbé-kiri fi ara gbà nínú àwọn ìdàmú wọ̀nyí. Nítorítí àwa náà ti fi ara gbà ìyàlẹ́nu yí fúnra wa ní àwọn ìgbàkan ṣaájú, a bẹ̀rẹ̀ síí bẹ̀rù fún ìgbésí ayé àti ààbò gbogbo wa, tí a nlọ́ra pàápàá láti rin ìrìn-àjò ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyí láti ṣe àbẹ̀wò sí àwọn òjíṣẹ́-ìránṣẹ́ àti láti ṣe àwọn ìpàdé agbègbè. A kò mọ bí yio ṣe pẹ́ tó. Mo ṣe agbejade ìfisùn kan, èyítí mo fi ránṣẹ́ sí Ààrẹ Agbègbè, mo sì ṣàlàyé àwọn ìmọ̀lára ìbẹ̀rù wa nípa títẹ̀síwájú láti rin ìrìn-àjò nígbàtí ó jẹ́ pé ọ̀nà náà nìkan ni ọ̀nà láti dé ọ̀dọ̀ àwọn òjíṣẹ́-ìránṣẹ́ wa.

Nínú ìdáhùn rẹ̀, Alàgbà Kevin Hamilton, tí ó jẹ́ ààrẹ wa ní Agbègbè Guusu ìlà oòrùn Afirika, kọ̀wé sí mi: “Ìmọ̀ràn mi ni láti ṣe ohun tí ó dára jùlọ tí o lè ṣe. Jẹ́ ọlọgbọ́n kí o sì kún fún àdúrà. Ẹ máṣe mọ̀ọ́mọ̀ fi ara yín tàbí àwọn ìránṣẹ́-ìhinrere yín sí ọ̀nà ìpalára, ṣùgbọ́n ní àkokò kannáà ẹ lọ síwájú nínú ìgbàgbọ́. “Nítorí Ọlọ́run kò fún wa ní ẹ̀mí ìbẹ̀rù, ṣùgbọ́n ti agbára, àti ìfẹ́, àti ọkàn pípé.”(2 Tímótéù1:7).”

Ìgbaniníyànjú yìí fún wa lókun púpọ̀ ó sì fún wa láyè láti máa rìnrìn àjò kí a sì sìn pẹ̀lú ìgboyà títí di òpin iṣẹ́ wa nítorí a gbọ́ ìtọ́ni láti ọ̀dọ̀ Baba wa Ọ̀run nípasẹ̀ ìwé-mímọ́ náà.

Nínú ìwé mímọ́ ti òde-òní, a ka àwọn ọ̀rọ̀ onímìísí ti Wòlíì Joseph Smith tí ó ṣe àfihàn ìyànjú ti Olúwa fún wa: “Ẹyin ará, àwa kì yío ha tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ tí ó tóbi tóbẹ́ẹ̀? Ẹ lọ síwájú àti kìí ṣe sẹ̀hìn. Ìgboyà, ẹ̀yin ará; àti síwájú, síwájú sí ìṣẹ́gun náà!” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 128:22).

Ẹ jẹ́ kí á ní ìgboyà láti ṣe ohun tí ó tọ́, pàápàá nígbà tí kò jẹ́ olókìkí—ìgboyà láti jà fún ìgbàgbọ́ wa àti láti ṣe ìṣe nípa ìgbàgbọ́. Ẹ jẹ́ kí á ní ìgboyà láti ronúpìwàdà lójoójúmọ́, ìgboyà láti gba ìfẹ́ Ọlọ́run àti láti pa àwọn òfin Rẹ mọ́. Ẹ jẹ́ kí á ní ìgboyà láti gbé pẹ̀lú òdodo àti láti ṣe ohun tí a nírètí lọ́wọ́ wa ní àwọn oríṣiríṣi ojúse àti ipò wa.

Ìwà ẹ̀kẹ́ta Olùgbàlà ni ìdáríjì. Lákokò iṣẹ́-ìránṣẹ́ ayé ikú Rẹ̀, Olùgbàlà ṣe ìdíwọ́ fún àwọn tí wọ́n fẹ́ sọ òkúta pa obìnrin kan tí a mú nínú àgbèrè. Ó pàṣẹ fún obìnrin náà láti “lọ, kí ó má sì ṣe dẹ́ṣẹ̀ mọ́” (Jòhánnù 8:11). Èyí sún un sí ìronúpìwàdà àti ní ìgbẹ̀hìn ìdáríjì, nítorí gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ àwọn ìwé mímọ́, “obìnrin náà yin Ọlọ́run lógo láti wákàtí náà ó sì gba orúkọ rẹ̀ gbọ́” (Ìyírọ̀padà èdè Joseph Smith, Jòhánnù 8:11 [ní Jòhánnù 8:11, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé c]).

Lákokò ìfọkànsìn Kérésìmesì ní Oṣù kejìlá ọdún 2018, Ààrẹ wa ọ̀wọ́n Russell M. Nelson sọ̀rọ̀ nípa àwọn ẹ̀bùn mẹ́rin tí a ti gbà láti ọ̀dọ̀ Olùgbàlà. Ó sọ pé ẹ̀bùn kan tí Olùgbàlà fúnni ni agbára láti dáríjì.

Nípasẹ̀ Ètùtù àìlópin Rẹ̀, ẹ lè dáríji àwọn tí wọ́n ti ṣe ìpalára tí wọ́n sì lè ma gba ojúse fún ìwà ìkà wọn sí yín.

“Nígbàgbogbo ó rọrùn láti dariji ẹni tí ó fi tọkàntọkàn àti ìrẹ̀lẹ̀ wá ìdáríjì yín. Ṣùgbọ́n Olùgbàlà yio fún yín ní agbára láti dáríjì ẹnikẹ́ni tí ó ṣe yín níbi ní eyikeyi ọ̀nà” (“Ẹ̀bùn mẹ́rin Tí Jésù Krístì Fún Yín” [First Presidency Christmas devotional, Dec. 2, 2018], broadcasts.ChurchofJesusChrist.org).

Ẹ jẹ́ ki a fi tọkàntọkàn dáríji ara wa láti gba ìdáríjì Baba. Ìdáríjì nsọ wá di òmìnira ó sì njẹ́ kí á yẹ láti ṣe alabapin nínú oúnjẹ-Olúwa ní gbogbo ọjọ́-ìsinmi. A nílò Ìdáríjì làti jẹ́ ọmọ-ẹ̀hìn Jésù Krístì tòótọ́.

Ìwà ẹ̀kẹ́rin Olùgbàlà ni ìrúbọ. Èyí jẹ́ apákan ìhìnrere ti Jésù Krístì. Olùgbàlà fúnni ní ìrúbọ gíga jùlọ ti ẹ̀mí Rẹ̀ fún wa kí a lè rà wá padà. Níní ìmọ̀lára ìrora ti ìrúbọ, Ó bèèrè lọ́wọ́ Baba Rẹ̀ láti mú ago náà kúrò, ṣùgbọ́n Ó lọ sí òpin ẹbọ àìnípẹ̀kun. Èyí ni Ètùtù Jésù Krístì.

Ààrẹ M. Russell Ballard kọ́ni ní èyí: “Ẹbọ ni ìfihàn [náà] ti ìfẹ́ àìlábàwọ́n. Ìwọ̀n ìfẹ́ wa fún Olúwa, fún ìhìnrere, àti fún ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa ni a lè wọ̀n nípasẹ̀ ohun tí a fẹ́ láti rúbọ fún wọn” (“Àwọn Ìbùkún Ẹbọ,” Ẹ́nsáìn, Oṣù karun (Èbìbí) 1992, 76).

A lè fi àkokò wa rúbọ láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, láti sin àwọn ẹlòmíràn, láti ṣe rere, láti ṣe iṣẹ́ ìtàn ẹbí, àti láti gbé ìpè Ìjọ wa ga.

A lè fúnni nínú àwọn ọ̀nà owó wa nípa sísan idamẹwa, àwọn ọrẹ àwẹ̀, àti àwọn ẹ̀bùn míràn láti kọ́ ìjọba Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé. A nílò ìrúbọ láti pa àwọn májẹ̀mú tí a ti dá pẹ̀lú Olùgbàlà mọ́.

Àdúrà mi ni pé nípa títẹ̀lé Jésù Krístì àti lílo àwọn ìbùkún Ètùtù Rẹ̀, a ó máa di onírẹ̀lẹ̀ púpọ̀ síi, a ó ní ìgboyà síi, a ó máa dáríjì síi, a ó sì máa rúbọ síi fún ìjọba Rẹ̀.

Mo jẹri pé Baba wa Ọ̀run wà láàyè àti pé Ó mọ olúkúlùkù wa ní ọ̀kọ̀ọ̀kan, pé Jésù ni Krístì, pé Ààrẹ Russell M. Nelson ni wòlíì Ọlọ́run ní òní. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ni ìjọba Ọlọ́run ní orí ilẹ̀ ayé àti pé Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ òtítọ́. Ní orúkọ Jésù Krístì, Olùràpadà wa, àmín.