Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ẹ Di Ìmọ́lẹ̀ Yín Mú Sókè
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


10:28

Ẹ Di Ìmọ́lẹ̀ Yín Mú Sókè

Ìpè mi ní òní jẹ́ ìrọ̀rùn: ẹ pín ìhìnrere. Ẹ jẹ́ arayín kí ẹ sì di ìmọ́lẹ̀ yín mú sókè.

Nígbàtí mo wà lórí ọkọ-òfúrufú lọsí Peru ní ọdún díẹ̀ sẹ́hìn, mo joko nítòrí aláìgbàgbọ́ olùkéde-araẹni kan. Ó bèèrè ìdí tí mo fì gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Nínú ìbárasọ̀rọ̀ alárinrin tí ó ṣẹlẹ̀, mo wí fún pé mo gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run nítorí Josèph Smith rí I—nígbànáà mo sì fikún pé ìmọ̀ mi nípa Ọlọ́run wá látinú ìrírí araẹni, ti-ẹ̀mí òdodo. Mo pín ìgbàgbọ́ mi pé “ohun gbogbo fihàn pé Ọlọ́run wà”1 mo sì bèèrè bí òun bá gbàgbọ́ nínú ilẹ̀-ayé—ibi ilẹ̀ aginjù ayé yí nínú ààyè—ti wá sí wíwa-láyé. Ó fèsì, nínú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, “ìjàmbá” lè ṣẹlẹ̀ ní àìmoye ìgbà. Nígbàtí mo ṣàlàyé bí àìṣeéṣe rẹ̀ tító yíò jẹ́ fún “ìjàmbá” kan láti mú irú èrò bẹ́ẹ̀ jáde, ó dákẹ́ fún ìgbà díẹ̀ lẹ́hìnnáà ó sì wí ní àdánidá-rere pé, “Ó rí mi mú.” Mo bèèrè bí òun bá lè ka Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ó wípé òun lè kà á, nítorínáà mo fi ẹ̀dà kan ránṣẹ́ si.

Ní àwọn ọdún lẹ́hìnnáà mo dá ọ̀rẹ́ titun kan nígbàtí mo wà ní Lagos, Nigeria. A di olùbárìn bí òun ṣe wo ìwé-ìrìnnà mi Mo bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípa ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn rẹ̀, ó sì fi ìgbàgbọ́ gidi nínú Ọlọ́run hàn. Mo pín ayọ̀ àti ìyára ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Jésù Krístì mo sì bèèrè bí òun bá fẹ́ láti kọ́ síi láti ẹnu àwọn ójíṣẹ́-ìránṣẹ́. Ó wípé bẹ́ẹ̀ni, a kọ, a sip ṣe ìrìbọmi rẹ̀. Ọdún kan tàbí méjì lẹ́hìn náà, bí mo ṣe nrìn nínú ibùdókọ̀-òfúrufú ní Leberia, mo gbọ́ ohùn kan tí ó pe orúkọ mi. Mo yípadà, ó sì jẹ́ ọ̀dọ́mọkùnrin kannáà tí ó mbọ̀ pẹ̀lú ẹ̀rín títóbi ní ẹ̀nu. A fi tayọ̀-tayọ̀ dìmọ́ra, ó sì jẹ́ kí nmọ̀ pé òun nwá sí Ìjọ déédé òun sì nṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn òjíṣẹ́-ìránṣẹ́ láti kọ́ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀.

Èmi kò mọ̀ bóyá ọ̀rẹ́ mi aláìgbàgbọ́ ka Ìwé ti Mọmọ́nì rí tàbí darapọ̀ mọ́ Ìjọ. Ọ̀rẹ́ mi kejì ṣe é. Fún méjèèjì, ojúṣe mi2—ànfàní mi—jẹ́ irú kannáà: di ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere mú sókè—láti nifẹ, pín, àti láti pe ní ọ̀nà àdànidá, déédé.2

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, mo ní ìrírí àwọn ìbùkún ti pípín ìhìnrere, wọ́n sì jẹ́ alámì. Nihin ni àwọn èrò díẹ̀:

Pípín Ìhìnrere Nmú Ayọ̀ àti Ìrètí Wá

Ẹ wòó, ẹ̀yin àti èmi mọ̀ pé a gbé bí àwọn ọmọ òbí wa ọ̀run ṣíwájú wíwá sí ilẹ̀-ayé yí3 àti pé ilẹ̀-ayé ni a dá fún èrèdí fífún ẹnìkọ̀ọ̀kan ní ànfàní láti gba ara, jèrè ìrírí, kẹkọ, àti dàgbà ní èrò láti gba ìyè ayérayé—èyí tí íṣe ìgbé-ayé Ọlọ́run.4 Baba Ọ̀run mọ̀ pé a ó jìyà a ó sìn dẹ́ṣẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé, nítorínáà Ó rán Ọmọ Rẹ̀, ẹnití “ìgbé-ayé àìláfiwé”6 àti ẹbọ ètùtù àìláfiwé7 mu ṣeéṣe fún wa láti gba ìdáríjì, ìwòsàn, kí a sì ní ìwòsàn.8

Láti mọ àwọn òtítọ́ wọ̀nyí jẹ́ ìyípadà ìgbé-ayé! Nígbàtí ẹnìkan bá kọ́ èrèdí ológo ti ayé, ní ìmọ̀ pé Krístì ndáríjì ó sì ntu àwọn tí wọ́n ntẹ̀le E nínú, tí wọ́n sì yàn nígbànáà láti tẹ̀lé Krístì wọnú omi ìrìbọmi, ìgbé-ayé nyípadà fún dídára si—àní nígbàtí àwọn ipò ayé kò bá ṣe é.

Arábìnrin dídán dídunnú kan tí mo bá pàdé ní Onitsha, Nieria, wí fún mi pé láti ìgbà tí òun ti kọ́ ìhìnrere tí ó sì ṣe ìrìbọmi (nísisìyí mo lo àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀), “Ohungbogbo dára fún mi. Inú mi dùn. Mo wà ní ọ̀run.”7 Pípín ìhìnrere nmú ayọ̀ àti ìrètí wá sọ́kàn olùgbà àti olùfúnni méjèèjì. Nítòọ́tọ́, “bí ayọ̀ yín yíò ti pọ̀ tó”8 bí ẹ ṣe npín ìhìnrere! Pípín ìhìnrere jẹ́ ayọ lórí ayọ̀, ìrètí lórí ìrètí.9

Pípín Ìhìnrere Nmú Agbára Ọlọ́run Wá sínú Ìgbé-ayé Wa

Nígbàtí a ṣe ìrìbọmi, ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wa wọ inú májẹ̀mú12 títíláé pẹ̀lú Ọlọ́run “láti sìn Ín àti láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́,”13 èyítí ó pẹ̀lú “láti dúró bí ẹlẹri kan nípa [Rẹ̀] ní ìgbà gbogbo àti ní ibi gbogbo.”14 Bí a ti “ngbé nínú” Rẹ̀ nípa pípa májẹ̀mú yí mọ́, agbára yíyàsímímọ́, ààyè, ìmúdúró, ti ìwàbí-Ọlọ́run nṣàn sínú ìgbé-ayé wa látọ̀dọ̀ Krístì, gẹ́gẹ́bí ẹ̀ká ti ngba ìkẹ́ látinú ọgbà.12

Pípín Ìhìnrere Ndá Ààbò Bò Wá kúrò nínú Àdánwò

Olúwa paṣẹ pé:

“Ẹ gbé ìmọ́lẹ̀ yín sókè kí ó lè tàn sí aráyé. Kíyèsi èmi ni ìmọ́lẹ̀ èyí tí ẹ ndìmú sókè—èyí tí ẹ ti rí tí mo ṣe. …

“… Èmi ti pàṣẹ pé … kí ẹ wá sọ́dọ̀ mi, pé ẹ lè nímọ̀lára àti ri; àní bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin yíò ṣe sí ayé; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣẹ̀ sí òfin yí mú ararẹ̀ jìyà ní dídarí sínú àdánwò.”13

Yíyàn láti máṣe di ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere mú sókè nmú wa rìn sí àwọn òjìji, níbití a ti ngbà àdánwò síra wa. Nípàtàkì, ìsọ̀rọ̀ náà jẹ́ òtítọ́, yíyan láti di ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere mú sókè nmú wa súnmọ́ ìmọ́lẹ̀ àti ààbò tí ó npèsè ní ìlòdì sí àdánwò. Irú ìbùkún títóbijùlọ kan ní òde òní!

Pípín Ìhìnrere Nmú Ìwòsàn Wá

Arábìnrin Tiffany Myloan tẹ́wọ́gba ìpè láti ti àwọn òjíṣẹ-ìránṣẹ́ lẹ́hìn pẹ̀lú ìlàkàkà wúwo araẹni, àti àwọn ìbèèrè nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀. Ó wí fún mi láìpẹ́ pé títi àwọn òjíṣẹ́-ìránṣẹ́ lẹ́hìn ti tún ìgbàgbọ́ òun ṣe àti ọgbọ́n wíwà-dáadáa. Nínú àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀, “Ṣíṣe iṣẹ́-ìránṣẹ́ jẹ́ wíwòsàn gidi.”14

Ayọ̀ Ìrètí Agbára ìmúdúró látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ààbò kúrò nínú àdánwò Ìwòsàn Gbogbo èyí—àti púpọ̀ (pẹ̀lú ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀)15—nrọ̀ lórí ẹ̀mí wa bí ìbùkún láti ọ̀run bí a ti npín ìhìnrere.

Nísisìyí, Yíyípadà sí Ànfàní Títóbi Wa

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, “ọ̀pọ̀lọpọ̀ wà … ní àárín yín gbogbo … àwọn ẹgbẹ́, [ọ̀gbà,] àti àwọn ẹ̀sìn … tí wọ́n npamọ́ kúrò nínú òtítọ́ nìkan nítorí wọn kò mọ ìbi tí òun ó ti rí i.”16 Ìnílò láti di ìmọ́lẹ̀ ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere Krístì mú sókè kò tóbijùlọ rí láéláé nínú àkọsílẹ̀-ìtàn ènìyàn. Òtítọ́ kò sì tíì wà ní àrọ́wọ́tó bẹ́ẹ̀ si rí.

Jimmy Ton, ẹnití ó dàgbà bí Buddhist, ní ìtẹ̀mọ́ra nípa ẹbí kan tí wọ́n pín ìgbé-ayé wọn lóri YúTubù. Nígbàtí a kọ́ pé wọ́n jẹ́ ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, ó ṣe àṣàrò ìhìnrere lórí ayélujára fúnrarẹ̀, ka Ìwé ti Mọ́mọ́nì ní lílo áàpù, ó sì ṣe ìrìbọmi lẹ́hìn ìpàdé pẹ̀lú àwọn òjíṣẹ-ìránṣẹ́ ní kọ́llẹ́jì.17 Alàgbà Ton nísisìyí jẹ́ òjíṣẹ́-ìránṣẹ́ ìgbà-kíkún fúnrarẹ̀.

Òun àti ẹlẹgbẹ́ rẹ àwọn òjíṣẹ́-ìránṣẹ́ káàkiri ayé ni ọmọ-ogun Olúwa—láti tún ọ̀rọ̀ wòlíì wa sọ.21 Àwọn ìránṣẹ́-ìhìnrere wọ̀nyí pa ìṣe ayé ti: nígbàtí àwọn iwadi ròhìn pé Gen Z nyí padà kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run,19 àwọn ajagun wa20 àwọn alàgbà àti arábìnrin nyí àwọn ènìyàn padà Ọlọ́run. Ní iye nọ́mbà àwọn ọmọ Ìjọ ndarapọ̀ pẹ̀lú àwọn òjíṣẹ́-ìránṣẹ́ ní pípín ìhìnrere, ríran púpọ̀si àti púpọ̀si àwọn ọ̀rẹ́ lọ́wọ́ láti sọ́dọ̀ Krístì àti Ìjọ Rẹ̀.

Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ọ̀wọ́n ní Liberia ran àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta-ó-lé-méje láti wọnú omi ìrìbọmi nínú oṣù mẹwa kò sí ìránṣẹ́-ìhìnrere ìgbà-kíkún tí ó nsìn ní orílẹ̀-èdè wọn rárá. Nígbàtí ọ̀kan lára àwọn ààrẹ èèkàn wa oníyanu ní Liberia gbọ́ pé àwọn ìránṣẹ́-ìhìnrere ìgbà-kíkún lè máa pada bọ̀, ó sọ̀rọ̀: “Áà ó dára, nísisìyí wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́ pẹ̀lú iṣẹ́ wa.”

Òtítọ́ ni ó sọ: ìkórajọ Ísráẹ́lì—ìdí títóbijùlọ lórí ilẹ̀-ayé24ni ojúṣe májẹ̀mú wa. Èyí sì ni àkokò wa! Ìpè mi ní òní jẹ́ ìrọ̀rùn: pín ìhìnrere. Ẹ jẹ́ arayín kí ẹ sì di ìmọ́lẹ̀ yín mú sókè. Ẹ gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ tọ̀run kí ẹ sì tẹ̀lé àwọn ìṣílétí ti-ẹ̀mí. Ẹ pín ayé yín déédé àti ní àdánidá, ẹ pe ẹlòmíràn láti wá kí ó sì rí, láti wá kí wọ́n sì ṣèrànwọ́, àti láti wá kí wọ́n sì wà pẹ̀lú.22 Kí ẹ sì yayọ̀ bí ẹ̀yin àti àwọn tí ẹ nifẹ ti ngba àwọn ìlérí ìbùkún.

Mo mọ̀ pé nínú Krístì ni a nwàásù ìròhìn ayọ̀ wọ̀nyí sí ọlọ́kàntútù, nínú Krístì ni a ti ntún ìròbìnújẹ́ ọkàn ṣe; nínú Krístì ni à nkéde ómínira sí àwọn onígbèkùn; àti nínú Krístì, nínú Krístì nìkan ni, a ti nfún àwọn ẹnití ó nṣọ̀fọ̀ ní ẹwà fún eérú.23 Nítorínáà, ni ìnílò nlá láti mú kí àwọn ohun wọ̀nyí di mímọ̀!24

Mo jẹri pé Jésù Krístì ni olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́ wa.25 Òun yíò parí, Òun yíò ṣe àṣetan, lílo ìgbàgbọ́ wa—bíótilẹ̀jẹ́pé aláìpé —ní dídi ìmọ́lẹ̀ ìhìnrere wá mú sókè. Òun yíò ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu nínú ìgbé-ayé wa àti ní ìgbé-ayé gbogbo àwọn tí Ó kópapọ̀, nítorí Òun ni Ọlọ́run àwọn ìṣẹ́-ìyanu.26 Ní orúkọ ìyànu ti Jésù Krístì, àmín.