Ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, Àádọ́rin Agbègbè, àti Olóyè Gbogbogbò
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, bí a ti kede, nísisìyí èmi yíò gbé àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, àwọn Àádọ́rin Agbègbè, àti àwọn Olóyè Gbogbogbò Ìjọ kalẹ̀ fún ìbò ìmúdúró yín.
Ẹ jọ́wọ́ e fi ìbò yín hàn bí ẹ ti nṣe níbikíbi tí ẹ lè wà. Bí a bá rí àwọn wọ̀nni tí wọń tako eyikeyi nínú àwọn àbá, a bèèrè pé kí ẹ kàn sí ààrẹ èèkan yín.
A dalaba pé kí a ṣe ìmúdúró Russell Marion Nelson bí wòlíì, aríran, àti olùfihàn àti Ààrẹ Ìjọ Jésù Kristì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn; Dallin Harris Oaks bí Olùdámọ̀ràn Kínní; àti Henry Bennion Eyring bí Olùdámọ̀ràn Kejì nínú Àjọ Ààrẹ Ìkinní.
Àwọn wọnnì tó bá faramọ lè fihàn.
Àwọn wọnnì tó bá tàkòó, tí ẹnikẹ́ni bá wà, lè fihàn.
A dalaba pé kí a ṣe imúdúró Dallin H. Oaks bí Ààrẹ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá àti M. Russell Ballard bí Aṣojú Ààrẹ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá.
Àwọn to bá faramọ, jọ̀wọ́ ṣàpẹrẹ.
Alátakò kankan tó bá wa lè fihàn.
A dalaba pé kí a ṣe imúdúró àwọn wọ̀nyí bí ọmọ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá: M. Russell Ballard, Jeffrey R. Holland, Dieter F. Uchtdorf, David A. Bednar, Quentin L. Cook, D. Todd Christofferson, Neil L. Andersen, Ronald A. Rasband, Gary E. Stevenson, Dale G. Renlund, Gerrit W. Gong, àti Ulisses Soares.
Àwọn tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.
Alátakò kankan lè ṣe àmì bẹ́ẹ̀.
A dalaba pé kí a ṣe ìmúdúró àwọn olùdámọ̀ràn nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá bí àwọn wòlíì, aríran, àti olùfihàn.
Gbogbo ẹni tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.
Ìlòdì, tí ẹnìkankan bá wá, nípa irú àmì kannáà.
A ti dá àwọn Alàgbà J. Devn Cornish, Timothy J. Dyches, David F. Evans, Robert C. Gay, James B. Martino, àti Terence M. Vinson bí Aláṣẹ Gbogbogbò Áádọ́rin a sì fún wọn ní ipò ìfẹ̀hìntì.
Àwọn wọnnì tí wọ́n fẹ́ láti darapọ̀ mọ́ wa ní fífi ìmoore hàn sí àwọn arákùnrin wọ̀nyí àti ẹbí wọn fún iṣẹ́-ìsìn ìfọkànsìn wọn lè ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìnawọ́ sókè.
A kíyèsi pé Alàgbà Dean M. Davies, ẹnití ó kọjá lọ ní Ọjọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n Oṣù Kẹjọ, 2021, yíò ti ní ìdásílẹ̀ bí Aláṣẹ Gbogbogbò Àádọ́rin ní ìpàdé àpapọ̀ yí. A nawọ́ ìbákẹ́dùn àtọkànwá wa sí Arábìnrin Davies àti ẹbí a sì fi ìmoore hàn fún iṣẹ́-ìsìn àìsimi Alàgbà Davies.
Bákannáà a kíyèsi pẹ̀lú ìdúpẹ́ àwọn Àádọ́rin Agbègbè tí wọ́n ti parí iṣẹ́-ìsìn wọn ní ọdún tí ó kọjá yí.
Àwọn wọnnì tí wọ́n fẹ́ láti darapọ̀ mọ́ wa ní fífi ìmoore hàn sí àwọn arákùnrin wọ̀nyí fún iṣẹ́ ìsin títayọ lè fihàn.
A dá àbá pé kí a ṣe ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò míràn, àwọn Àádọ́rin Agbègbè—pẹ̀lú àwọn Àádọ́rin Agbègbè titun méjì tí a kéde ṣíwájú ní ọ̀sẹ̀ yí ní newsroom.ChurchofJesusChrist.org—àti àwọn Olóyè Gbogbogbò bí a ti gbé wọn kalẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.
Gbogbo ẹni tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.
Àwọn alátakò, bí ọ̀kankan bá wà.
A dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ìtẹ̀síwájú ìgbàgbọ́ yín àti àdúrà ní ìtìlẹhìn àwọn olórí Ìjọ.
Àwọn Ìyípadà sí Àwọn Àádọ́rin Agbègbè
Àwọn Àádọ́rin Agbègbè wọ̀nyí ni a ṣe ìmúdúró fún nínú ìpàdé àwọn olórí kan tí a ṣe bí ara ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò.
Pedro E. Hernández àti Charden Ndinga.
Àwọn Àádọ́rin Agbègbè wọ̀nyí ni a ṣe ìmúdúró fún nínú ìpàdé àwọn olórí kan tí a ṣe bí ara ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò.
Guillermo I. Guardia àti Gaëtan Kelounou.
Àwọn Àádọ́rin Agbègbè wọ̀nyí ni a dásílẹ̀ ní Ọjọ́ Kínní Oṣù Kẹ́jọ, 2021;
P. David Agazzani, Quilmer A. Agüero, Frederick O. Akinbo, Nelson Ardila, Richard C. Baquiran, Dong Chol Beh, Matthieu Bennasar, Lawrence P. Blunck, Luis J. Camey, Douglas B. Carter, Aroldo B. Cavalcante, Luis C. Chaverri, Ulises Chávez, Brent J. Christensen, Douglas L. Dance, M. T. Ben Davis, Marc C. Davis, J. Scott Dorius, M. Dirk Driscoll, Antonio F. Faúndez, José A. Fernández, Matías D. Fernández, Candido Fortuna, Bruce E. Ghent, Michael A. Gillenwater, Michael D. Groll, Daniel G. Hamilton, Tom-Atle Herland, Raymond S. Heyman, Jerat K. C. Igwe, Christophe Kawaya, John A. Koranteng, Ming-Shun Kuan, Todd S. Larkin, Juan J. Levrino, Carlo M. Lezano, Felix A. Martinez, J Vaun McArthur, Kevin K. Miskin, Helamán Montejo, Michael R. Murray, Ryan V. Pagaduan, A. Moroni Pérez, Carlos E. Perrotti, Mark P. Peteru, Thomas T. Priday, Brian L. Rawson, Rene Romay, Blake M. Roney, Luis G. Ruiz, Maximo A. Saavedra Jr., Pedro A. Sanhueza, Eric J. Schmutz, Paul H. Sinclair, Benjamin T. Sinjoux, David L. Stapleton, Daniel Texeira, Seiji Tokuzawa, Maxsimo C. Torres, Jesús Vélez, Carlos Villarreal, Paul H. Watkins, Robert K. William, C. Dale Willis, Kevin J Worthen, àti Luis G. Zapata.