Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Rírí Ojúrere Olúwa ní Gbogbo Àwọn Ọjọ́ Mi
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


8:59

Rírí Ojúrere Olúwa ní Gbogbo Àwọn Ọjọ́ Mi

Báwo ni a ṣe nṣe sí àwọn ìpọ́njú wa? Ṣé à nní ìmọ̀lára ìdúpẹ́ nítorí a nní ìdojúkọ síi lórí àwọn ìbùkún wa ju lórí àwọn wàhálà wa.

Àjàkálẹ̀ àrùn COVID-19 jẹ́ ọ̀kan nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àdánwò àti àwọn ìpèníjà ti àwọn ọmọ Ọlọ́run ti dojúkọ jákèjádò ìtàn àgbáyé. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yi, èmi àti ẹbí mi ọ̀wọ́n la ìgbé-ayé awọn ọjọ́ dúdú díẹ̀ kọjá. Àjàkálẹ̀ àrùn náà àti àwọn ìdí míràn mú ikú àti ìrora wá sínú ẹbí wa nípasẹ̀ kíkọjálọ ti àwọn olùfẹ́ ọ̀wọ́n díẹ̀. Pẹ̀lú ìtọ́jú egbòogi, ààwẹ̀, àti àdúrà, ní ààrìn ọ̀sẹ̀ márun arákùnrin mi Charly, arábìnrin mi Susy, àti arákùnrin-àna mi Jimmy kọjá sí òdìkejì ìkelè.

Ní àwọn ìgbà míràn mo ti ronú ìdí tí Olùgbàlà fi sunkún nígbàtí ó rí ìjìyà Màríà nípa ikú arákùnrin rẹ̀, Lásárù, àní bíótilẹ̀jẹ́pé Òun mọ̀ pé Òun ní agbára láti jí Lásárù dìde àti pé láìpẹ́ Òun yío lo agbára yi láti kó ọ̀rẹ́ Rẹ̀ yọ lọ́wọ́ ikú.1 Mo ní ìyàlẹ́nu nípasẹ̀ àánú àti ìyọ́nú Olùgbàlà fún Màríà; Ó ní òye ìrora tí kò ṣeé júwe tí Maríà ní ìmọ̀lára rẹ̀ ní ìgbà ikú arákùnrin rẹ̀, Lásárù.

A nní irú ìmọ̀lára ìrora líle kannáà nígbàtí a bá ní ìrírí ìyapa ránpẹ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn olùfẹ́ wa. Olùgbàlà ní àánú pípé fún wa! Kìí dá wa lẹ́bi fún ìwò-kúkúrú wa tàbí fún níní òpin nínú ìwoye ìrìnàjò ayérayé wa. Dípò bẹ́ẹ̀, Ó ní àánú fún àwọn ìbànújẹ́ àti ìjìyà wa.

Baba Ọrun àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, fẹ́ kí a ní ayọ̀.2 Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni pé: “Ayọ̀ tí à nní ìmọ̀lára rẹ̀ ní díẹ̀ í ṣe pẹ̀lú àwọn ipò ti ìgbé-ayé wa àti pé ohun-gbogbo ní í ṣe pẹ̀lú ìfojúsùn àwọn ìgbé-ayé wa. “Nígbàtí ìfojúsùn ìgbé-ayé wa bá jẹ́ lórí ètò ìgbàlà ti Ọlọ́run, … a lè ní ìmọ̀lára ayọ̀ láìka ohun tí ó nṣẹlẹ̀—tàbí tí kò ṣẹlẹ̀ sí—nínú ìgbé-ayé wa.”3

Nígbàtí mo jẹ́ ọ̀dọ́ ojíṣẹ́-ìránṣẹ́, mo rántí ìgbà tí oníṣẹ́-ìránṣẹ́ dáradára kan tí mo bọ̀wọ̀ fún gba àwọn ìròhìn ìbànújẹ́. Ìyá rẹ̀ àti àbúrò rẹ̀ ọkùnrin ti kọjá lọ nínú ìjàmbá burúkú kan. Ààrẹ míṣọ̀n náà fún alàgbà yi ní ànfàní láti padà sí ilé fún ìsìnkú. Ṣùgbọ́n, lẹ́hìn sísọ̀rọ̀ pẹ̀lú bàbá rẹ̀ lórí fóònù, oníṣẹ́ ìránṣẹ́ yi pinnu láti dúró kí ó sì parí mísọ̀n rẹ̀

Bíbẹ òjíṣẹ́-ìránṣẹ́ wò ní ilé-ìwòsàn

Ní àìpẹ́ lẹ́hìnnáà, nígbàtí a nsìn ní agbègbè kannáà, ojúgbà mi àti emi gba ipè pàjáwìrì kan; àwọn olè ti jí kẹ̀kẹ́ tí ó jẹ́ ti oníṣẹ́-ìránṣẹ́ yi kannáà gbé wọ́n sì ti ṣe é léṣe pẹ̀lú ọ̀bẹ. Òun àti ojúgbà rẹ̀ níláti rìn lọ sí ilé ìwòsàn tí ó súnmọ́ jùlọ, níbití ojúgbà mi àti èmi ti pàdé pẹ̀lú wọn. Ní ojú ọ̀nà sí ilé ìwòsàn náà, mo nní ìkáànú fún oníṣẹ́-ìránṣẹ́ yi. Mo nwoye pé ọkàn rẹ̀ yío ní ìrẹ̀wẹ̀sì àti pé dájúdájú, lẹ́hìn ìrírí búburú yi, òun yío fẹ́ padà lọ sílé nísisìyí.

Ṣùgbọ́n, nígbàtí a dé ilé ìwòsàn, mo rí oníṣẹ́-ìránṣẹ́ yi ní ìdùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀, ó ndúró fún gbígbélọ fún iṣẹ́ abẹ—ó sì nrẹ́rín músẹ́. Mo ròó, “Báwo ni yío ṣe máa rẹ́rin ní irú àkókò bíi èyí?” Nígbàtí ara rẹ̀ nyá bọ̀ nílé ìwòsàn, pẹ̀lú ìtara ó npín àwọn iwé ìléwọ́ àti àwọn ẹ̀dà Ìwé ti Mọ́mọ́nì fún àwọn dókítà, àwọn nọ́ọ̀sì, àti àwọn aláìsàn míràn. Àní pẹ̀lú àwọn àdánwò wọ̀nyí, kò fẹ́ padà lọ sílé. Dípò bẹ́ẹ̀, ó sìn títí di ọjọ́ tó kẹ́hìn nínú iṣẹ́-ìsìn rẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́, agbára, okun, àti ìtara.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ Ìwé ti Mọ́mọ́nì, Néfì sọ pé, “Nítorítí mo ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú ní ìgbà àwọn ọjọ́ mi, bíótilẹ̀ríbẹ̃, nítorítí mo ti rí ojúrere Olúwa lọ́pọ̀ ní gbogbo àwọn ọjọ́ mi.”4

Mo ronú nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àdánwò tí Néfì ní ìrírí wọn, púpọ̀ èyítí ó wà nínú ìwé kíkọ rẹ̀. Àwọn àdánwò rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti ní òye pé gbogbo wa ní àwọn ọjọ́ dúdú wa. Ọkan nínú àwọn àdánwò wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ nígbàtí a pàṣẹ fún Néfì láti padà sí Jérúsálẹ́mù láti gba àwọn àwo idẹ tí Lábánì ní ní ìkáwọ́ rẹ̀. Díẹ̀ nínú àwọn arákùnrin Néfì jẹ́ àwọn ènìyàn tí ìgbàgbọ́ wọn kéré, àní wọ́n sì lu Néfì pẹ̀lú ọ̀pá kan. Néfì ní ìrírí àdánwò míràn nígbàtí ó kán ọrun rẹ̀ tí kò sì le wá oúnjẹ fún ẹbí rẹ̀. Lẹ́hìnwá, nígbàtí a pàṣẹ fún Néfì láti kan ọkọ̀ kan, àwọn arákùnrin rẹ̀ fi ṣe yẹ̀yẹ́ wọ́n sì kọ̀ láti ràn án lọ́wọ́. Láìka àwọn àdánwò wọ̀nyí àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ míràn sí ní ìgbà ìgbé ayé rẹ̀, Néfì máa nfi ìgbàgbogbo mọ rírì ìwàrere Ọlọ́run.

Néfì ni a sorọ̀ nínú ọkọ̀-ojú-omi

Bí àwọn ẹbí rẹ̀ ti nkọjá lórí òkun ní ojú ọ̀nà wọn lọ sí ilẹ̀ ìlérí, díẹ̀ nínú àwọn ẹbí Néfì “bẹ́rẹ̀ sí nṣe àjọyọ̀ fúnrawọn,” sọ̀rọ̀ líle, wọ́n sì gbàgbé pé agbára Olúwa ni ó ti dá wọn sí. Nígbàtí Néfì bá wọn wí, wọ́n bínú wọ́n sì dì í pẹ̀lú àwọn okùn tí ó fi jẹ́ pé kò le mira. Ìwé ti Mọ́mọ́nì sọ pé àwọn arákùnrin rẹ̀ “mún [un] pẹ̀lú ọwọ́ líle púpọ̀”; àwọn ọrùn ọwọ́ àti ọrùn ẹ̀sẹ̀ rẹ̀ “wú púpọ̀, títóbi sì ni egbò náà.”5 Néfì ní káànú pẹ̀lú líle ọkàn àwọn arákùnrin rẹ̀ àti pé nígbàmíràn, ó nní ìmọ̀lára bíborí pẹ̀lú ìbànújẹ́.6 “Bíótilẹ̀ríbẹ̃,” ó kédé pé, “èmi yí ojú sí Ọlọ́run mi, mo sì yìn ín ní gbogbo ọjọ́ nã; èmi kò sì kùn sí Olúwa nítorí ti àwọn ìpọ́njú mi.”7

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, báwo ni àwa ti ndásí àwọn ìpọ́njú wa? Njẹ́ awa nkùn níwájú Olúwa nítorí wọn? Tàbí, bíi ti Néfì àti ọ̀rẹ́ mi oníṣẹ́-ìrànṣẹ́ tẹ́lẹ̀rí, njẹ́ a nní ìmọ̀lára ìdúpẹ́ nínú ọ̀rọ̀, èrò, àti ìṣe nítorípé a fojúsùn sí àwọn ìbùkún wa síi ju àwọn ìṣoro wa lọ?

Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, fún wa ní àpẹrẹ ní ìgbà iṣẹ́-ìránṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé. Ní àwọn àkókò ìṣoro àti ìdánwò, àwọn ohun díẹ̀ ló wà tí ó nmú àlàáfíà àti ìtẹ́lọ́rùn nlá wá fúnwa ju sísin àwọn ènìyàn bíi tiwa lọ. Ìwé ti Matteu ṣe àlàyé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nígbàtí Olùgbàlà gbọ́ pé ìbátan Rẹ̀, Jòhánnù Onítẹ̀bọmi ni a ti bẹ́ lórí láti ọwọ́ Ọba Hẹ́ródù láti mú inú ọmọbìnrin Hẹrodáíàsì dùn.

“Àwọn ọmọ-ẹhìn rẹ̀ sì wá, wọ́n gbé òkú rẹ̀ sin, wọ́n sì lọ, wọ́n sì wí fún Jésù.

“Nígbàtí Jésù sì gbọ́, ó dìde kúrò níbẹ̀ nípasẹ̀ ọkọ̀-ojuomi lọ sí ibi ijù ní òun kan: nígbàtí àwọn ènìyàn sì gbọ́, wọ́n sì ti ìlú wọn rìn tọ̀ ọ́ ní ẹsẹ̀.

“Jésù sì jáde lọ, ó rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, inú rẹ̀ sì yọ́ sí wọn, ó sì ṣe ìwòsàn àwọn àrùn ara wọn

“Nígbàtí ó di àṣálẹ́ àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wípé, Ibi ijù ni èyí, ọjọ́ sì ti kọjá tán: rán ijọ ènìyàn lọ, kí wọn ó le lọ sí ìletò lọ ra oúnjẹ fún ara wọn.

“Ṣùgbọ́n Jésù wí fún wọn pé, wọn kò ní lọ; ẹ fún wọn ní oúnjẹ.”8

Jésù Krístì fi hàn wá pé ní àwọn àkókò ìdánwò àti ìpọ́njú a le dá àwọn ìṣòro ti àwọn ẹlòmíràn mọ̀. Ní ìmọ̀ pẹ̀lú ìyọ́nú, a le nawọ́ jáde kí a sì gbé wọn sókè. Bí a sì ti nṣe bẹ́ẹ̀, a ó di gbigbé sókè bákannáà nípa iṣẹ́-ìsìn wa bíi-ti-Krístì. Ààrẹ Gordon B. Hinckley sọ pé: “Ìwòsàn dídára jùlọ tí mo mọ̀ fún àníyàn ni iṣẹ́-síṣe. Òògùn dídára jùlọ fún àìnírètí ni iṣẹ́-ìsìn. Ìwòsàn dídára jùlọ fún ìkáàrẹ̀ ni ìpèníjà ti ríran ẹnikan lọ́wọ́ àní ẹnití ó ti rẹ̀ púpọ̀.”9

Nínú Ijọ Jésù Krístì yìí, mo ti ní àwọn ànfààní lọ́pọ̀lọpọ̀ láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ àti láti sin àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ mi. Àwọn àkókò wọ̀nyí ni mo nní ìmọ̀lára pé Baba Ọrun nmú àwọn ẹrù mi fúyẹ́. Ààrẹ Russell M. Nelson ni wòlíì Ọlọ́run lórí ilẹ̀-ayé; ó jẹ́ àpẹrẹ nlá ti bí a ṣe níláti ṣe ìṣẹ́-ìránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn ní ìgbà àwọn àdánwò tí ó ṣòro. Mo da ẹ̀rí mi pọ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ Àwọn Ènìyàn Mímọ́ míràn pé Ọlọ́run jẹ́ olùfẹ́ni Baba wa Ọrun. Mo ti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ àìlópin Rẹ̀ nínú àwọn ọjọ́ dúdú mi. Olùgbàlà wa, Jésù Krístì, ní òye àwọn ìrora wa àti àwọn ìpọ́njú wa. Ó nfẹ́ láti mú àwọn ẹrù wa fúyẹ́ kí ó sì tù wá nínú. A gbọ́dọ̀ tẹ̀lé àpẹrẹ Rẹ̀ nípa sísìn àti ṣíṣe iṣẹ́-ìránṣẹ́ sí àwọn wọnnì tí wọ́n ní àwọn ẹrù àní títóbi ju tiwa lọ. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.