Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Wò ìsàlẹ̀ Òpópónà náà
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


Wò ìsàlẹ̀ òpópónà náà

Fífojúsùn lórí àwọn nkan tí ó ṣe pàtàkì jùlọ—pàápàá àwọn ohun wọ̀nnì “ní ìsàlẹ̀ òpópónà,” àwọn ohun ayérayé wọ̀nnì—jẹ́ kọ́kọ́rọ́ láti ṣe ìdarí ní ìgbé-ayé yi.

Nígbàtí mo di ọmọ ọdún marundinlogun, mó gba ìwé ìyọ̀da ìkẹ́kọ, èyítí ó fún mi láàyè láti wa ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí ọ̀kan nínú òbí mi bá wà pẹ̀lú mi. Nígbàtí baba mi bèèrè bóyá èmi yio fẹ láti lọ fún ìwakọ̀, inú mi dùn.

Ó wakọ̀ ní máìlì mélòó kan sí ẹ̀hìn ìlú sí ọ̀nà gígùn, tààrà, olópó-méjì kan tí àwọn ènìyàn díẹ̀ nlò—kí nṣàkíyèsí, bóyá ibi kan ṣoṣo tí òun ní ìmọ̀lára àìléwu ni. Ó dúró lórí èjìká ọ̀nà, a sì pa àwọn ijoko wa dà. Ó fún mi ni ìdánilẹ́kọ díẹ̀ lẹ́hìnnáà ó sọ fún mi pé, “Rọra lọ sí òpópónà kí o kàn wakọ̀ títí èmi yio fi sọ fún ọ láti dúró.”

Mo tẹ̀lé àwọn àṣẹ rẹ̀ déédé. Ṣùgbọ́n lẹ́hìn bíi ọgọta ìṣẹ́jú àáyá, ó wípé, “Ọmọ, dá ọkọ̀ náà dúró. Ò nmú mi ṣàárẹ̀. Ò nyíwọ́ kiri gbogbo òpópónà. Ó bèèrè, “Kíni ò nwò?”

Pẹ̀lú ìbínú díẹ̀, mo sọ wípé, “mo nwo òpópónà.”

Lẹ́hìnnáà ó sọ èyí: “mo nwo ojú rẹ, àti pé ò nwo ohun tí ó wá ní iwájú ìbòrí ọkọ́ nikan. Bí ó bá wo ohun tí ó wà ní ọ̀gangan iwájú rẹ̀, ìwọ kí yio wakọ̀ tààrà láéláé.” Lẹ́hìnáà ó tẹnumọ, “Wò ìsàlẹ̀ òpópónà náà. Èyíinì yio ràn ọ́ lọ́wọ́ láti wakọ̀ tààrà. ”

Bíi ọmọ ọdún marundinlogun, mo rò pé èyí jẹ́ ẹ̀kọ́ ìwakọ̀ kan tí ó dára. Mo sì ti mọ̀ láti ìgbànáà pé ó jẹ́ ẹ̀kọ́ nlá fún ìgbé-ayé pẹ̀lú. Fífojúsùn lórí àwọn nkan tí ó ṣe pàtàkì jùlọ—pàápàá àwọn ohun wọ̀nnì “ní ìsàlẹ̀ òpópónà,” àwọn ohun ayérayé wọ̀nnì—jẹ́ kọ́kọ́rọ́ láti ṣe ìdarí ní ìgbé-ayé yi.

Ní àkokò kan nínú ìgbé-ayé Olùgbàlà, Ó fẹ́ láti dá wà, nítorínàà “Ó gun orí-òkè kan lọ lọ́tọ̀ láti gbàdúrà.”1 Ó rán àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ lọ pẹ̀lú àwọn ìtọ́sọ́nà láti kọjá òkun. Ní òkùnkùn alẹ́, ọkọ̀ ojú-omi tí ó gbé àwọn ọmọ-ẹ̀hìn wá kojú ìjì líle. Jésù lọ yọwọ́n ṣùgbọ́n ní ọ̀nà aláìlẹ́gbẹ́. Àkọọ́lẹ̀ ìwé-mímọ́ ka pé, “Ní ìṣọ́ kẹrin òru Jésù lọ sọ́dọ̀ wọn, ní rírìn lórí òkun.”2 Nígbàtí wọ́n rí I, wọ́n bẹ̀rẹ̀síí bẹ̀rù, nítorí wọ́n rò pé àwòrán tí ó súnmọ́ wọn jẹ́ òkú tàbí iwin kan. Jésù, ní ìmọ̀lára ìbẹ̀rù wọn Ó sì fẹ́ láti fi ọkàn àti àyà wọn balẹ̀, Ó ké sí wọn, “Ẹ tújuka; èmi ni; ẹ má fòyà.”3

Kì í ṣe pé Pétérù rí ìtura nìkan ṣùgbọ́n ó tún ní ìgboyà. Ní ìgboyà àti ìyára nígbàgbogbo, Pétérù kígbe sí Jésù, “Olúwa, tí ó bá jẹ́ ìwọ, pàṣẹ fún mi láti wá sí ọ̀dọ̀ rẹ lórí omi.”4 Jésù fèsì pẹ̀lú ìkésíni Rẹ̀ tí ó dámọ̀ tí kò sì ní àsìkò: “Wá.”5

Pétérù, ní inú-dídùn dájú nípa ìfojúsọ́nà náà, jáde nínú ọkọ̀ ojú-omi náà kìí ṣe sínú omi ṣùgbọ́n sórí omi. Lakoko tí ó dojúkọ Olùgbàlà, o lè ṣe ohun tí kò ṣeéṣe, pàápàá rìn lórí omi. Ní ìbẹ̀rẹ̀, ìjì náà ko fa àìbalẹ̀ ara fún Pétérù. Ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ “aláriwo”6 níkẹhìn ṣe ìdíwọ́ fún un, ó sì pàdánù ìdojúkọ rẹ. ìbẹ̀rù náà padà. Nítorí náà, ìgbàgbọ́ rẹ̀ dínkù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rì. “Ó kígbe, wípé, Olúwa, gbà mí.”7 Olùgbàlà, tí ó ní ìtara nígbàgbogbo láti gbàlà, nawọ́ ó sì gbé e sókè sí àìléwu.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ ló wà láti kọ́ láti inú àkọọ́lẹ̀ ìyanu yi, ṣùgbọ́n èmi yio mẹ́nuba mẹ́ta.

Dojúkọ Krístì

Ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́: fojúsí Jésù Krístì. Nígbàtí Pétérù tẹjú rẹ̀ mọ́ Jésù, ó lè rìn lórí omi. Ìji, ìgbì omi, àti afẹ́fẹ́ kò lè ṣe ìdíwọ́ fún un níwọ̀n ìgbàtí ó fi ojú rẹ̀ sí Olùgbàlà.

Lílóye èrèdí ìkẹhìn wa nràn wá lọ́wọ́ láti pinnu ohun tí ìfojúsí wá yẹ kí ó jẹ́. A kò lè ṣe ere kan yọrí láìmọ̀ ibi-afẹ́dé, tàbí kí a gbé ìgbé-ayé tí ó ní ìtumọ̀ láìsí mímọ ìdí rẹ̀. Ọ̀kan nínú àwọn ìbùkún nla tí ìhìnrere Jésù Krístì tí a múpadà bọ̀sípò ni pé ó dáhùn, laarin àwọn ohun míràn, ìbéèrè náà “Kíni ìdí ìgbé-ayé?” “Ìdí wa ní ìgbé-ayé yi ni láti ní ayọ̀ kí á sì múra láti padà sí iwájú Ọlọ́run.”8 Rírántí pé a wà níbí lórí ilẹ̀-ayé láti múra láti padà láti gbé pẹ̀lú Ọlọ́run ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa láti fojúsí àwọn ohun tí ó ndarí wa lọ sí ọ̀dọ̀ Krístì.

Fífojúsí Krístì nílò ìbáwí, ní pàtàkì nípa àwọn ìwà ti ẹ̀mí kékeré àti rírọ̀rùn tí ó nṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa láti di ọmọ-ẹ̀hìn tó dára jùlọ. Kò sí ọmọ-ẹ̀hìn láìsí ìbáwí.

Ìfojúsí wa sí Krístì yio hàn díẹ̀ síi nígbàtí a bá wo ìsàlẹ̀ òpópónà ní ibití a fẹ́ wà, àti tani a fẹ́ láti dà àti lẹ́hìnnáà wá àkokò lójoójúmọ́ láti ṣe àwọn ohun wọ̀nnì tí yio ràn wá lọ́wọ́ láti dé ibẹ̀. Fífojúsí Krístì lè jẹ́ kí àwọn ìpinnu wa rọrùn kí ó sì pèsè ìtọ́sọ́nà fún bí a ṣe lè lo àkokò àti àwọn orísun wa ní dídára jùlọ.

Nígbà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun wà tí ó yẹ fún ìfojúsí wa, a kọ́ ẹ̀kọ́ láti inú àpẹrẹ Pétérù nípa pàtàkì fífi Krístì sí ààrin gbùngbun ìfojúsí wa nígbàgbogbo. Nípasẹ̀ Jésù Krístì nìkan ni a lè padà láti gbé pẹ̀lú Ọlọ́run. A gbáralé oore-ọ̀fẹ́ Krístì bí a ṣe ntiraka láti dàbí Rẹ àti láti wá ìdáríji àti agbára ìfúnnilókun Rẹ̀ nígbàtí a bá kùnà.

Ṣọ́ra fún Àwọn Ìdíwọ̀

Ẹ̀kọ́ kejì: ṣọ́ra fun àwọn ídíwọ́. Nígbàtí Pétérù yí ojú rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ Jésù àti sí afẹ́fẹ́ àti àwọn ìgbì tí ó nà án ni ẹsẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ si rì.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun lo wà “ní ìwájú ìbòrí” tí ó lè ṣe ìdíwọ́ fún wa láti fojúsíKrístì àti àwọn ohun ayérayé tí o “wà ní ìsàlẹ̀ òpópónà.” Èṣù ni olùdíwọ́ nla. A kọ́ ẹ̀kọ́ láti inú àlá Léhì pé àwọn ohùn láti inú ilé nlá àti gbígbòrò nwá láti tàn wá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ohun tí yio mú wa kúrò ní ipa-ọ̀nà ìmúrasílẹ̀ láti padà lọ́ láti gbé pẹ̀lú Ọlọ́run.9

Ṣùgbọ́n àwọn ìdíwọ́ míràn wà tí kò hàn gbanga tí ó lè jẹ́ ewu bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́. Bí ọ̀rọ̀ naa ti lọ, “Ohun kàn ṣoṣo tí ó wúlò fún ibi láti ìṣẹ́gun ni fún àwọn ènìyàn rere láti má ṣe ohunkóhun.” Alátakò dàbí ẹni pé ó pinnu láti mú àwọn ènìyàn rere má ṣe ohunkohun, tàbí ó kéré jù láti fi àkokò wọn ṣòfò lórí àwọn ohun tí yio ṣe ìdíwọ́ fún wọn kúrò nínú àwọn ìdí gíga wọn àti ibi-afẹ́dé wọn. Fún àpẹrẹ, díẹ̀ nínú àwọn ohun tí ó jẹ́ ìyípadà dídára nínú ìwọ̀ntúnwọ̀nsì lè di àwọn ìdíwọ́ àìdára láìsí ìkóníjanu. Ọ̀tá ní òyue pé àwọn ìdàmú kò ní láti jẹ́ búburú tàbi aláìmọ́ láti nípá.

A Lè Yọ Wá

Ẹ̀kọ́ kẹ́ta: a lè yọ wá. Nígbàtí Pétérù bẹ̀rẹ̀ síí rì, ó kígbe pé, “Olúwa, gbà mí. Lójúkanáà Jésù sì na ọwọ́ rẹ, ó si dìí mú.”10 Nígbàtí a bá ri pé à nrì, nígbàtí a bá dojúkọ ìpọ́njú, tàbí nígbàtí a bá rẹ̀wẹ̀sì, Ó lè yọ àwa náà.

Ní ojú ìpọ́njú tàbí ìdánwò, ẹ lè dàbí èmi láti nírètì pé yíyọ yio jẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ rántí pé Olùgbàlà wá sí ìrànlọ́wọ́ àwọn Àpọ́stélì ní ìṣọ́ kẹrin òru—lẹ́hìn tí wọ́n ti lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ òru ní síṣe làálàá nínú ìjì.11 A lè gbàdúrà pé bí ìrànlọ́wọ́ náà ò bá le dé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó kéré jù yio wá ní ìṣọ́ kejì tàbí pàápàá ìṣọ́ kẹ́ta ti òru inú òwe náà. Nígbàtí a gbọ́dọ̀ dúró, ní ìdánilójú pé Olùgbàlà nṣàkíyèsí nígbàgbogbo, nfún wa ní ìdanilójú pé a kò ní láti farada ju bí a ṣe lè faradà lọ.12 Sí àwọn tí wọn ndúró ní ìṣọ́ kẹ́rin òru, bóyá tí ẹ ṣì wà larin ìjìyà, ẹ má ṣe sọ ìrètí nù. Àkóyọ máa nwá nígbàgbogbo sí àwọn olõtọ́, bóyá lákokò ayé ikú tàbí nínú àwọn ayérayé.

Nígbà míràn rírì wa nwá nítorí àwọn àṣìṣe àti àwọn ìrékọjá wa. Bí ẹ ba rí ara yín ní rírì fún àwọn ìdí wọ̀nnì, ẹ ṣe yíyàn aláyọ̀ láti ronúpìwàdà.13 Mo gbàgbọ́ pé àwọn ohun díẹ̀ ni ó fún Olùgbàlà ní ayọ̀ díẹ̀ si ju gbígba àwọn tí ó yípadà, tàbí padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.14 Àwọn ìwé-mímọ́ kún fún àwọn ìtàn àwọn ènìyàn tí wọ́n ti ṣubú nígbà kan tí wọ́n sì ní àlébù ṣùgbọ́n tí wọ́n ronúpìwàdà tí wọ́n sì fẹsẹ̀múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ Krístì. Mo rò pé àwọn ìtàn wọ̀nyí wà nínú àwọn ìwé-mímọ́ láti rán wa létí pé ìfẹ́ Olùgbàlà fún wa àti agbára Rẹ̀ láti ràwá padà jẹ́ àìlópin. Kìí ṣe pé Olùgbàlà ni ayọ̀ nìkan nígbàtí a bá ronúpìwàdà, ṣùgbọ́n a gba ayọ̀ nla pẹ̀lú.

Íparí

Mo pè yín láti jẹ́ àtọkànwá nípa “wíwò ìsàlẹ̀ òpópónà náà” kí ẹ sì mú ìfojúsí yín pọ̀ si nínú àwọn ohun wọ̀nnì tí ó ṣe pàtàkì. Njẹ́ kí á lè fi Krístì sí ààrin gbùngbun ìfojúsí wa. Laarin gbogbo àwọn ìdíwọ́, àwọn ohun tó wà “ní iwájú ìbòrí,” àti àwọn ìjì líle tí ó yí wa ká, mo jẹ ẹ̀rí pé Jésù ni Olùgbàlà wa àti Olùràpadà wa àti Alákóyọ wa. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Tẹ̀