Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìwádìí Tòótọ́ Kan Gba Èrè
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


9:4

Ìwádìí Tòótọ́ Kan Gba Èrè

Mo pe gbogbo wa láti máa mú ìgbàgbọ́ wa nínú Krístì pọ̀ si nígbàgbogbo, ẹnití ó tẹ̀síwájú ní yíyí àwọn ìgbésí ayé gbogbo àwọn tí wọ́n nwa A padà.

Bẹ̀rẹ̀ ní 1846, ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn ọkùnrin olùlànà, àwọn obìnrin, àti àwọn ọmọdé kọrí sí ìhà ìwọ̀-oòrùn sí Síónì. Ìgbàgbọ́ nla wọn ru ìgboyà àìlópin wọn sókè. Fún àwọn kan, ìrìn-àjò náà kò parí láé nítorí tí wọ́n kú ní ojú ọ̀nà. Àwọn míràn, ní dídojúkọ ìpọ́njú nlá, tẹ̀ síwájú nínú ìgbàgbọ́.

Nítorí wọn, àwọn ìran lẹ́hìnwá, ẹbí mi gbádùn àwọn ìbùkún ìhìnrere òtítọ́ ti Jésù Krístì.

Gẹ́gẹ́ bí ọdọ́mọkùnrin míràn, tí èmi yíò darúkọ lẹ́hìnwá, mo jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá nígbàtí mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìbéèrè ẹ̀sìn àti ìgbàgbọ́ mi. Mo lọ sí ilé ìjọsìn ti ìjọ míràn tí ó súnmọ́ ilé mi, ṣùgbọ́n mo ní ìmọ̀lára ìfẹ́-inú láti ṣe àbẹ̀wò sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ oríṣiríṣi àwọn ìjọ.

Ní ọ̀sán ọjọ́ kan, mo wòye àwọn ọdọ́mọkùnrin méjì tí wọ́n wọ kótù dúdú àti àwọn ṣẹ́ẹ̀tì funfun tí wọ́n nwọ ilé aladugbo mi. Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọ̀nyí ní ìwò—pàtàkì

Ní ọjọ́ kejì mo pàdé aladugbo mi, Leonor Lopez, mo bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípa àwọn ọkùnrin méjèèjì náà. Leonor ṣàlàyé pé wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́-ìhìnrere fún Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Ó fi ayọ̀ sọ fún mi pé ẹbí òun ti ṣe ìrìbọmi nínú ìjọ náà ní ọdún kan sẹ́hìn. Nígbàtí ó rí ìfẹ́-inú mi, Leonor pè mí láti pàdé àwọn ìránṣẹ́-ìhìnrere àti láti kẹkọọ nípa Ìjọ náà.

Ọjọ́ méjì lẹ́hìnnáà, mo darapọ̀ mọ́ ẹbí Lopez láti pàdé àwọn ìránṣẹ́-ìhìnrere. Wọ́n ṣe àfihàn ara wọn bií Alàgbà John Messerly láti Ogden, Utah, àti Alàgbà Christopher Osorio láti Walnut Creek, California. Èmi kò le gbàgbé wọn láéláé.

Àwọn òjíṣẹ́-ìránṣẹ́ nkọ́ni nibi oúnjẹ-alẹ́

Níwọ̀n bí mo ti jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá péré, Alàgbà Messerly tẹnumọ pé kí á lọ sítòsí ilẹ̀kùn sí ilé mi kí ìyá mi lè mọ ohun tí wọ́n nkọ́ mi. Níbẹ̀, ó fi inúrere ṣàlàyé pé wọ́n wá láti pín ọ̀rọ̀ kan nípa Jésù Krístì ó sì bèèrè fún ìgbanílààyè láti kọ́ mi. Ìyá gbà ó sì darapọ̀ mọ́ wa pàápàá lakoko tí wọ́n nkọ́ mi.

Àwọn ìránṣẹ́-ìhìnrere kọ́kọ́ wípé kí Leonor gbàdúrà. Èyí fọwọ́ tọ́mi jìnlẹ̀ gan nítorì pé àdúrà rẹ̀ kìí ṣe àtúnwí ti àwọn ọ̀rọ̀ àkọ́sórí kan ṣùgbọ́n ìsọ̀rọ̀ láti inú ọkàn rẹ. Mo ní ìmọ̀lára pé ó nbá Baba rẹ̀ Ọ̀run sọ̀rọ̀ lõtọ́.

Lẹ́hìnáà àwọn ìránṣẹ́-ìhìnrere kọ́ wa nípa Jésù Krístì. Wọ́n fi àwòrán Rẹ̀ tí ó wúmi lórí hàn nítorí pé ó jẹ́ àwòrán Krístì tí ó jínde, tí ó wà láàyè.

Olùgbàlà Jésù Krístì

Wọ́n tẹ̀síwájú, ní kíkọ́ wa bi Jésù ṣe fi ìdí Ìjọ Rẹ̀ múlẹ̀ ní àwọn ìgbà àtijọ́, pẹ̀lú Òun ní orí tí àwọn Àpóstélì méjìlá darapọ̀ mọ́ Ọ. Wọ́n kọ́ wa nípa Ìyapa-Kúrò-Nínú-Ìgbàgbọ́—bí a ṣe mú òtítọ́ àti àṣẹ Kri´stì kúrò láyé lẹ́hìn tí àwọn Àpóstélì Rẹ̀ ti kú.

Wọ́n sọ fún wa nípa ọdọ́mọkùnrin ẹni ọdún mẹ́rìnlá kan ti a npè ni Joseph Smith ti, lakoko ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1800, ṣe àbẹ̀wò sí àwọn ìjọ lóríṣiríṣi tí ó nwá òtítọ́. Bí àkokò ti nlọ, Joseph túnbọ̀ dààmú síi. Lẹ́hìn tí ó kà nínú Bíbélì pé a lè “bèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run”1 fún ọgbọ́n, Joseph, ní síṣe ìṣe nínú ìgbàgbọ́, lọ sí igbó ṣúúrú ti àwọn igi kan láti gbàdúrà kí ó sì bèèrè ìjọ èyítí ó yẹ kí ó darapọ̀ mọ́.

Ọ̀kan nínú àwọn ìránṣẹ́-ìhìnrere ka akọ̀sílẹ̀ Joseph nípa ohun tí o ṣẹlẹ̀ bí ó ti ngbàdúrà:

“Mo rí òpó ìmọ́lẹ̀ kan ní ọ̀gangan òkè orí mi, tí ó ju dídán ìtànṣán oòrùn lọ, èyí tí ó nsọ̀kalẹ̀ díẹ̀díẹ̀ títí tí ó fi dúró lé mi lórí.

“… Nígbàtí ìmọ́lẹ̀ náà sinmi lé mi lórí mo rí àwọn Ẹni Nlá méjì, àwọn ẹnití ìmọ́lẹ̀ àti ògo wọn ju gbogbo àpèjúwe, wọ́n ndúró ní òkè orí mi nínú afẹ́fẹ́. Ọ̀kàn lára wọn sọ̀rọ̀ sí mi, ó pè mí ní orúkọ ó nawọ́ sí ẹnìkejì, ó wípé—Èyí ni Àyànfẹ́ Ọmọ Mi. Gbọ́ Tirẹ̀!2

Lakoko ẹ̀kọ́ náà, Ẹ̀mí jẹrisi àwọn òtítọ́ púpọ̀ sí mi.

Àkọ́kọ́, Ọlọ́run fetísílẹ̀ sí gbogbo àwọn àdúrà òdodo àwọn ọmọ Rẹ̀, ọ̀run ṣí sílẹ̀ fún gbogbo ènìyàn—kìí ṣe àwọn díẹ̀ kan.

Ìkejì, Ọlọ́run Baba, Jésù Krístì, àti Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́ ẹ̀dá mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, tí wọ́n jẹ́ ọ̀kan nínú èrò Wọn “láti mú àìkú àti ìyè ayérayé ènìyàn wá sí ìmúṣẹ.”3

Ìkẹ́ta, a dá wa ní àwòrán Ọlọ́run. Baba wa Ọ̀run àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, ní àwọn àgọ́ ara ti ẹran àti egungun bíi tiwa, ṣùgbọ́n a ṣe Wọ́n lógo àti ní pípé, Ẹ̀mí Mímọ́ sì jẹ́ ẹni nlá ti ẹ̀mí.4

Ẹ̀kẹrin, nípasẹ̀ Joseph Smith, Jésù Krístì mú ìhìnrere Rẹ̀ àti Ìjọ òtítọ́ padàbọ̀ sí ayé. Àṣẹ oyeààlúfà tí a fún àwọn Àpóstélì Krístì ní ẹgbẹ̀run méjì ọdún sẹ́hìn jẹ́ oyèàlúfà kannáà tí a fún Joseph Smith àti Oliver Cowdery nípasẹ̀ Pétérù, Jákọ́bù, àti Jòhánnù.5

Ní ìparí, a kọ́ ẹkọ nípa ẹ̀rí míràn ti Jésù Krístì: Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Tí a kọ láti ọwọ́ àwọn wòlíì àtijọ́, ó sọ nípa àwọn ènìyàn tí ngbé ní Amẹrika ṣaájú, ní àkókò, àti lẹ́hìn ìbí Jésù. Láti inú rẹ̀ a kọ́ ẹkọ bí wọ́n ti mọ̀, tí wọ́n nifẹ, tí wọ́n sì jọ́sìn fún Krístì, ẹnití ó farahàn wọ́n gẹ́gẹ́bí Olùgbàlà tí ó jínde .

Ẹ̀mi gbé mi gidigidi bí mo ti kẹkọọ nípa ìkéde Olùgbàlà fún wọn: “Ẹ kíyèsíi, èmi ni Jésù Krístì, tí àwọn wòlíì jẹ́ri pé yíò wá sínú ayé.”6

Àwọn ìránṣẹ́-ìhìnrere fún wa ní ẹ̀dà Ìwé ti Mọ́mọ́nì. A kàá a sì gba ìpè náà tí a rí ní òpin Ìwé ti Mọ́mọ́nì, èyí tí ó kà pé:

“Àti nígbatí ẹ̀yin yíò sì gbà àwọn ohun wọ̀nyí, èmi gbà yín níyànjú pé kí ẹ bẽrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, Baba Ayérayé, ní orukọ Krístí, bí àwọn ohun wọ̀nyí kì bá í ṣe òtítọ́; bí ẹ̀yin bá sì bẽrè tọkàn-tọkàn, pẹ̀lú gbogbo ìfẹ́ inú yín, níní ìgbàgbọ́ nínú Krístì, òun yíò fi òtítọ́ inú rẹ̀ hàn sí yín, nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ̀.

“Àti nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́ ẹ̀yin lé mọ̀ òtítọ́ ohun gbogbo.”7

Ó ti fẹ́rẹ̀ tó ọdún marundinlaadọta láti ìgbà tí ìyá mi àti èmi kọ́kọ́ kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ayọ̀ àti agbára tí níní ìgbàgbọ́ nínú Krístì. Ó jẹ́ nítorí ìgbàgbọ́ wọn nínú Krístì ni ẹbí Lopez ṣe pín ìgbàgbọ́ titun wọn pẹ̀lú mi. Ó jẹ́ nítorí ìgbàgbọ́ wọn nínú Krístì ni àwọn ìránṣẹ́-ìhìnrere méjì wọ̀nyí ṣe fi ilé wọn sílẹ̀ ní Amẹrika láti wá ìyá mi àti èmi. Ìgbàgbọ́ gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n wọ̀nyí ni o gbin hóró mústádì ti ìgbàgbọ́ sínú wa tí ó ti dàgbà láti ìgbà náà di igi alágbára kan ti àwọn ìbùkún ayérayé.

Lakoko àwọn ọdún oníbùkún wọ̀nyí, a ti mọ̀, bí Ààrẹ Russell M. Nelson ti kéde, pé: “Ohun gbogbo tí ó dára ní ìgbésí ayé—gbogbo ìbùkún tí ó ní agbára pàtàkì ayérayé—bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Fífi àyè gba Ọlọ́run láti borí nínú ayé wa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé Ó nfẹ́ láti tọ́ wa sọ́nà. Ìrònúpìwàdà òtítọ́ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ pé Jésù Krístì ní agbára lati wẹ̀nùmọ́, wosàn, àti láti fún wa lókun.”8

Mo pe gbogbo wa láti máa mú ìgbàgbọ́ wa nínú Krístì pọ̀ si nígbàgbogbo, ẹnití ó ti yí àwọn ìgbésí ayé ìyá mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n àti èmi padà tí ó sì tẹ̀síwájú láti yí àwọn ìgbésí ayé gbogbo àwọn tí wọ́n nwa A padà. Mo mọ̀ pé Joseph Smith ni Wòlíì Ìmúpadàbọ̀sípò, pé Ààrẹ Nelson ni wòlíì wa lónìí, pé Jésù ni Krístì alààyè àti Olùràpadà wa, àti pé Bàbá Ọ̀run wà láàyè ó sì ndáhùn àwọn àdúrà gbogbo àwọn ọmọ Rẹ̀. Mo jẹ́ri àwọn òtítọ́ wọ̀nyí ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.