Ìmúpadàbọ̀sípò Ojojúmọ́
A nílò ìtújáde títẹ̀síwájú, ojoojúmọ́ ti ìmọ́lẹ̀ ọ̀run. A nílò “àwọn àkókò ìsọdọ̀tun.” Àwọn àkókò ìmúpadàbọ̀sípò araẹni.
A péjọ ní àárọ̀ Ọjọ́-Ìsinmi rírẹwà yí láti sọ̀rọ̀ nípa Krístì, yọ̀ nínú ìhìnrere Rẹ̀, kí a sì ṣe àtìlẹ́hìn àti ìmúdúró ara wa bí a ti nrìn ní “ojú ọ̀nà” ti Olùgbàlà wa.1
Àwa gẹ́gẹ́bí ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn, a péjọpọ̀ fún érédí yí ní gbogbo Ọjọ́-ìsinmi laní gbogbo ọdún. Bí ẹ̀yin kìí bá ṣe ọmọ Ìjọ, a kí yín káàbọ̀ pẹ̀lú ọ̀yàyà jùlọ a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún dídarapọ̀ pẹ̀lú wa láti jọ́sìn Olùgbàlà kí a sì kọ́ ẹ̀kọ́ nípa Rẹ̀. Bíi tiyín, àwa náà ntiraka—bíótilẹ̀jẹ́ ní àìpé—láti di ọ̀rẹ́, aládugbò, àti ẹ̀dá ènìyàn dídára síi,2 a sì nlépa láti ṣe èyí nípa títẹ̀lé Àpẹrẹ wa, Jésù Krístì.
A ní ìrètí pé ẹ ó lè ní ìmọ̀lára òtítọ́ ti ẹ̀rí wa. Jésù Krístì Wà Láàyè! Òun ni Ọmọ Ọlọ́run alààyè, Ó sì ndarí àwọn wòlíì lórí ilẹ̀ ayé ní ìgbà tiwa. A npe gbogbo ènìyàn láti wá, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí ẹ sì ní ìpín nínú ire Rẹ̀! Mo jẹ́ ẹ̀rí ara-ẹni tèmi pé Ọlọ́run wà láàrin wa ati pé dájúdájú Òun yío súnmọ́ gbogbo ẹnítí ó bá súnmọ́ Ọ.3
A kà á sí iyì kan láti rìn pẹ̀lú yín nínú ipa ọ̀nà híhá àti tóóró ti jíjẹ́ ọmọlẹ́hìn Olùgbàlà.
Ọgbọ́n Rírìn ní Ìlà Tààrà kan
Èrò orí kan wà tí a máa nṣábà túnsọ pé àwọn tí wọ́n bá sọnù má nrìn ní pípòyìkà. Ní àìpẹ́ púpọ̀ sẹ́hìn, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Max Planck fún Biological Cybernetics ìdánwò ìmọ̀ orí náà. Wọ́n kó àwọn olùkópa lọ sí inú igbó dídí kan wọ́n sì fún wọn ní àwọn aṣẹ rírọrùn kan: “Ẹ rìn ní ìlà tààrà kan.” Kò sí àwọn àmì ìdámọ̀ tí ó ṣeé rí. Àwọn ẹni dídánwò náà ní láti gbáralé ọgbọ́n ìdarí tiwọn nìkan.
Báwo ni ẹ ṣe rò pé wọ́n ṣe?
Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ náà parí pé, “Àwọn ènìyàn [máa] nrìn ní yíyípo nítòótọ́ nígbàtí wọn kò bá ní àwọn àpẹrẹ sí ìdarí rírìn wọn.”4 Nígbàtí a bi wọ́n léèrè lẹ́hìnwá, díẹ̀ nínú àwọn olùkópa náà sọ pẹ̀lú idáraẹni-lójú pé àwọn kò yẹ̀ kúrò bí ó ti wù kí ó kéré mọ. Láìka idánilójú giga wọn sí, dátà GPS fihàn pé wọ́n rìn nínú àwọn àkámọ́ tí ó súnmọ́ra tóbẹ́ẹ̀ bíi ogún mítà ní dàyámítà.
Kíníṣe tí a nní irú àkókò líle bẹ́ẹ̀ ní rírìn nínú ilà tààrà kan? Àwọn olùwádìí ìjìnlẹ̀ kan fi òye orí gbée pé àwọn yíyàkúrò kékeré, tí ó dàbí ẹnipé kò jẹ́ nkan nínú àyíká nṣe ìyàtọ̀ náà. Àwọn míràn ti tọ́kasí òtítọ́ pé gbogbo wa la ní ẹsẹ̀ kan tí ó fi díẹ̀ lágbára ju èkejì lọ. Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, “ó ṣeéṣe jù,” pé a ntiraka láti rìn tààrà síwájú “[nítorí] ti àìdánilójú tí ó npọ̀ síi nípa ibití tààrà síwájú wà.”5
Ohunkóhun tí ó fàá, ó jẹ́ àdánidá ènìyàn: láìsí àwọn àmì ìdámọ̀ àfojúrí tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀lé, a nsún kúrò ní ojú ọ̀nà.
Yíyàkúrò ní Ipá Ọ̀nà náà
Njẹ́ kò wuni bí àwọn ohun kékeré, tí ó dàbí ẹnipé kò jẹ́ nkan ṣe le ṣe ìyàtọ̀ pàtàkì nínú ìgbé ayé wa?
Mo mọ èyí láti inú ìrírí ti ara ẹni bíi awakọ̀ òfurufú. Gbogbo ìgbà tí mo bá ti bẹ̀rẹ̀ lílọ sí pápákọ̀ ofurufú kan, mo mọ̀ pé púpọ̀ iṣẹ́ mi yío jẹ́ ṣíṣe àwọn àtúnṣe ojú ọ̀nà kékèké léraléra láti darí ọkọ̀ náà láìléwu sí ọ̀nà-ìsáré ibi ìsọ̀kalẹ̀ ti a fẹ́.
Ẹ lè ní irú ìrírí kannáà nígbàtí a bá nwa ọ̀kọ̀ kan. Atẹ́gùn, àwọn àìdára ojú ọ̀nà, àìpé ipò ìwakọ̀, àìfọkànsí tó—láì mẹ́nuba àwọn ìṣe ti àwọn awakọ̀ míràn—gbogbo rẹ̀ le ti yín kúrò ní ipa ọ̀nà tí ẹ nínú yín. Ẹ kùnà láti ṣe àfiyèsí àwọn ohun wọ̀nyí ẹ̀yin sì le parí sí níní ọjọ́ burúkú kan.6
Èyí ní í ṣe síwa ní ti ara.
Bákannáà ó ní í ṣe síwa ní ti ẹ̀mí.
Púpọ̀ jùlọ àwọn ìyípadà nínú ìgbé ayé wa ní ti ẹ̀mí—méjèèjì ní rere àti ìdàkejì—nṣẹlẹ̀ díẹ̀díẹ̀, ìgbésẹ̀ kan ní àkókò kan. Bíi ti àwọn olùkópa nńú ìkẹ́kọ̀ọ́ ti Max Planck, a lè má ríi nígbàtí a bá yà kúrò ní ojú ọ̀nà. A tilẹ̀ le ní ìdánilójú gíga pe a nrìn ní ìlà tààrà kan. Ṣùgbọ́n òtítọ́ ibẹ̀ ni pé láìsí ìrànlọ́wọ́ àwọn àmì ìdámọ̀ láti tọ́ wa, kò le yẹ̀ pé àwa ó yà kúrò ní ọ̀nà a ó sì parí sí àwọn ibi tí a kò lérò láé pé a ó wà.
Èyí jẹ́ òtítọ́ fún ẹnìkọ̀ọ̀kan. Ó jẹ́ òtítọ́ bákannáà fún àwọn àwùjọ àti àwọn orílẹ̀ èdè. Àwọn ìwé mímọ́ kún pẹ̀lú àwọn àpẹrẹ.
Ìwé àwọn Onídajọ́ ṣe àkọsílẹ̀ pé lẹ́hìntí Jóṣhúà kú, “àwọn ìran míràn dìde … èyítí kò mọ Olúwa, tàbí síbẹ̀ àwọn iṣẹ́ èyítí ó ti ṣe fún Isráẹ́lì.”7
Láìka àwọn ìlàjà yíyanilẹ́nu ti ọ̀run sí, àwọn àbẹ̀wò, àwọn ìtúsílẹ̀, àti iṣẹ́ ìyanu àwọn ìṣẹ́gun tí àwọn ọmọ Isráẹ́lì rí ní ìgbà ayé ti Moses àti Jóṣúà, láàrin ìran kan àwọn ènìyàn náà ti pa Ọnà náà tì wọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí rìn ní ìbámu sí àwọn ìfẹ́ inú tiwọn. Àti pé, nítòótọ́, kò gba àkókò pípẹ́ kí wọn ó tó san iye kan fún ìhùwàsí náà.
Nígbàmíràn ìṣubú kúrò yi máa njẹ́ ìrandíran. Nígbàmíràn ó nṣẹlẹ̀ láàrin àwọn ọdún tàbí àwọn oṣù pàápàá.8 Ṣùgbọ́n gbogbo wa ni ó le jẹ́. Kò jẹ́ nkan bí àwọn ìrírí wa ní ti ẹ̀mí ti lágbára tó nígbàkan rí, bíi ẹ̀dá ènìyàn ó ṣeéṣe fún wa láti rìnkiri. Èyí ti jẹ́ àwòrán kan láti ìgbà àwọn ọjọ́ Ádámù títí di ìsisìyí.
Níhĩn ni Ìròhìn Rere náà
Ṣùgbọ́n gbogbo rẹ̀ kò sọnu. Ní ìyàtọ̀ sí àrìnkiri àwọn tí a fi ṣe ìdánwò, àwa ní àwọn àmì ìdámọ̀ tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀lé, àfojúrí, tí a le lò láti ṣe àgbéyẹ̀wò ọnà wa.
Àti pé kínni àwọn àmì ìdámọ̀ wọ̀nyí?
Dájúdájú nínú wọn ni àdúrà ojoojúmọ́ àti síṣe àròjinlẹ̀ àwọn ìwé mímọ́ àti lílo àwọn irinṣẹ́ ìmísí bíi Wá, Tẹ̀lé Mi. Ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, a le lọ síbi ìtẹ́ Ọlọ́run nínú ìrẹ̀lẹ̀ àti ìṣòtítọ́. A le ṣe àròjinlẹ̀ àwọn ìṣe wa kí a sì ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn àkókò ti ọjọ́ wa—ní gbígbèrò fífẹ́ àti àwọn ìfẹ́-inú wa nínú ìmọ́lẹ̀ Tirẹ̀. Bí a bá ti yẹ̀ kúrò, kí a bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run láti múwa padàbọ̀sípò, kí a sì fi arajì láti ṣe dáradára síi.
Àkókò ríròsínú yi jẹ́ ànfàní kan fún síṣe àtúnṣe. Ó jẹ́ ọgbà ìrònú níbití a ti le rìn pẹ̀lú Olúwa kí a sì jẹ́ kíkọ́, gbígbé sókè, àti sísọ di mímọ́ nípa ọ̀rọ̀ Baba wa Ọrun tí a kọ àti ọ̀rọ̀ Baba Ọ̀run èyítí ẹ̀mí fihàn. Ó jẹ́ àkókò mímọ́ nígbàtí a nrántí àwọn májẹ̀mú ọ̀wọ̀ wa láti tẹ̀lé Jésù onírẹ̀lẹ̀ náà, nígbàtí a nṣe àgbéyẹ̀wò ìlọsíwájú wa tí a sì nmú ara wa ṣe déédé pẹ̀lú àwọn àmì ìdámọ̀ ti ẹ̀mí tí Ọlọ́run ti pèsè fún àwọn ọmọ Rẹ̀.
Ẹ ronú nípa rẹ̀ bíi ìmúpadàbọ̀sípò ojojúmọ́ara-ẹni tiyín. Nínú ìrìn àjò wa bíi àwọn arìnrìnàjò ní ipa ọ̀nà ògo, a mọ̀ bí ó ti rọrùn tó láti ṣubú kúrò. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́bí àwọn yíyàkúrò kékeré ṣe le fà wa jáde ní Ọnà Olùgbàlà, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ìṣe kékeré àti rírọrùn ti síṣe àtúnṣe ṣe lè darí wa padà dájúdájú. Nígbàtí òkùnkùn bá rákòrò wọ inú ìgbé ayé wa, bí ó ti máa nfi ìgbàgbogbo ṣe, ìmúpadàbọ̀sípò ojojúmọ́ wa nṣí ọkàn wa sí ìmọ́lẹ̀ ọ̀run, èyítí ntan ìmọ́lẹ̀ sí ọkàn wa, tí yío lé àwọn òjìji, àwọn ìbẹ̀rù, àti àwọn iyèméjì kúrò.
Àwọn Ìtukọ̀ Kékèké, Àwọn Ọkọ̀ Nlá
Bí a bá lépa rẹ̀, dájúdájú “Ọlọ́run yío fi ìmọ̀ fún [wa] nípa Ẹmí Mímọ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ni, nípa ẹ̀bùn àìlesọ ti Ẹmí Mímọ́.”10 Ní gbogbo ìgbà tí a bá bèèrè, Oun yío kọ́wa ní Ọnà náà yío sì ràn wá lọ́wọ́ láti tẹ̀lé e.
Èyí, ní tòótọ́, gba aápọn àìdúró ní apá ọ̀dọ̀ wa. A kò le ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn ìrírí ti-ẹ̀mí ti àtẹ̀hìnwá. A nílò ìṣàn kan tí ó ṣe déédé.
A kò le gbáralé àwọn ẹ̀rí ti àwọn ẹlòmíràn. A gbọ́dọ̀ mú tiwa dàgbà.
A nílò ìtújáde títẹ̀síwájú, ojoojúmọ́ ti ìmọ́lẹ̀ ọ̀run.
A nílò “àwọn àkókò ìsọdọ̀tun.”11 Àwọn àkókò ìmúpadàbọ̀sípò.
“Àwọn omi tó nyí” kò le “dúró ní àìmọ́” pẹ́.”12 Láti pa àwọn èrò àti àwọn ìṣe wa mọ́ ní àìlábàwọ́n, a níláti máa yí!
Lẹ́hìn ohun gbogbo, Ìmúpadàbọ̀sípò ti ìhìnrere ati Ìjọ náà kìí ṣe ohun kan tó ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kannáà tí ó sì parí. Ó jẹ́ ìlànà àìdúrókan—ọjọ́ kan ní àkókò kan, ọkàn kan ní àkókò kan.
Bí àwọn ọjọ́ wa ti nlọ, bẹ́ẹ̀ ni lílọ ìgbé ayé wa. Ònkọwé kan sọ ọ́ ní ọ̀nà yí: “Ọjọ́ kan dàbí gbogbo ìgbé ayé. O nbẹ̀rẹ̀ ní síṣe ohun kan, ṣùgbọ́n párí ní síṣe ohun míràn, o pèrò láti jẹ́ iṣẹ́ rírán kan, ṣùgbọ́n o kò debẹ̀ láé. … Àti ní opin ìgbé ayé yín, gbogbo wíwà yín ní iyì àìròtẹ́lẹ̀ kannáà, bẹ́ẹ̀ náà. Gbogbo ìgbé ayé rẹ ní àwòrán kannáà bíi ti ọjọ́ kan.”13
Njẹ́ ẹ fẹ́ láti yí àwòrán ayé yín padà?
Ẹ yí àwòrán ọjọ́ yín padà.
Njẹ́ ẹ fẹ́ láti yí ọjọ́ yín padà?
Ẹ yí wákàtí yìí padà?
Ẹ yí ohun tí ẹ nrò, ní ìmọ̀lára, àti tí ẹ nṣe padà ní àkókò yí gan.
Ohun ìtukọ̀ kékeré kan le darí ọkọ̀ nlá kan.14
Àwọn bíríkì kékèké le di mawọn ilé títóbi tó bẹ́ẹ̀.
Àwọn wóró kékèké le di àwọn sẹ̀kúóyà giga bíi ilé ìṣọ́.
Àwọn ìṣẹ́jú àti àwọn wákàtí tí a lò dáradára ni àwọn búlọ́ọ́kù ìkọ́lé ti ayé tí a gbé dáradára. Wọ́n le ṣe ìmísí inúrere, gbé wa sókè láti inú ìgbèkùn ti àwọn àìlera, kí ó sì darí wa padà sí ipa ọ̀nà ríràpadà tí ìdáríjì àti ìyàsímímọ́.
Ọlọ́run ti Àwọn Ìbẹ̀rẹ̀ Ọtun
Pẹ̀lú yín, mo gbé ọkàn mi sókè ní ìmoore fún ẹ̀bùn nlá ti ànfàní ọ̀tun, ayé ọ̀tun, ìrètí ọ̀tun.
A gbé àwọn ohùn wa sókè nínú ìyìn Ọlọ́run ọ̀pọ̀ àti olùdáríjì wa. Nítorí dájúdájú Ó jẹ́ Ọlọ́run àwọn ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun. Òpin rírẹwà ti gbogbo iṣẹ́ Rẹ̀ ni láti rànwá lọ́wọ́, àwa ọmọ Rẹ̀, láti yege nínú ìlépa wa fún àìkú àti ìyè ayérayé.15
A le di ẹ̀dá titun nínú Krístì, nítorí Ọlọ́run ti ṣe ìlérí pé, “Ní gbogbo ìgbà tí àwọn ènìyàn mi bá ronúpìwàdà ni èmi ó dárí àwọn ìrékọjá wọn sí mi jì wọ́n”16 kì yío sì “rántí wọn mọ́.”17
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi àyànfẹ́, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n, gbogbo wa nsún láti ìgbà dé ìgbà.
Ṣùgbọ́n a le padà sí ojú ọ̀nà. A le darí ọ̀nà wa la òkùnkùn àti àwọn àdánwò ti ayé yí já kí a sì rí ọ̀nà wa padà sí ọ̀dọ̀ olùfẹ́ni Baba wa Ọrun bí a bá wá àwọn àmì ìdámọ̀ ti ẹ̀mí tí Ó ti pèsè, tí a gba ìfihàn ara-ẹni mọ́ra, tí a sì tiraka fún ìmúpadàbọ̀sípò ojojúmọ́ Báyí ni a ndi ọmọẹ̀hìn tòótọ́ ti Olùgbàlà wa ọ̀wọ́n, Jésù Krístì.
Bí a ti nṣe bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run yíò rẹ́rin sí wa. “Olúwa yío … Bùkún fún ọ lórí ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ. Olúwa yío fi ìdí yín múlẹ̀ bí àwọn ènìyàn mímọ́ sí ara rẹ̀.”18
Pé a ó lépa ìmúpadàbọ̀sípò ojojúmọ́ kí a sì tiraka láìdúró láti rìn nínú Ọnà ti Jésù Krístì ni àdúrà mi. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.