Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìfẹ́ Ọlọ́run: Ayọ̀ Púpọ̀ Jùlọ sí Ọkàn
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


10:24

Ìfẹ́ Ọlọ́run: Ayọ̀ Púpọ̀ Jùlọ sí Ọkàn

A kò le rí ìfẹ́ Ọlọ́run nínú àwọn ipò ti ìgbé ayé wa ṣùgbọ́n nínú wíwà Rẹ̀ nínú ìgbé ayé wa.

Ẹyin arakunrin ati arabinrin, njẹ́ ẹ mọ bi Ọlọrun, Baba wa Ọrun, ṣe fẹràn yín patapata? Njẹ ẹ ti ni ìmọ̀lara ifẹ Rẹ jinlẹ ninu ẹmi yín bi?

Nigbati ẹ ba m ọ̀tí ẹ sì ní òye bi o ṣe fẹràn yín tán bi ọmọ Ọlọ́run, o nyí ohun gbogbo pada. Ó nṣe àyípadà ìmọ̀lára tí ẹ nní nípa ara yín nígbàtí ẹ bá ṣe àwọn àṣìṣe. O nṣe àyipada ìmọ̀lara yín nigbati awọn nkan ti o nira ba ṣẹlẹ. O nṣe àyipada ìwòye yín nípa awọn ofin Ọlọrun. O nṣe àyipada ìwòye yín nípa awọn ẹlòmiiran, ati ti agbara yín lati mú iyatọ wá.

Alàgbà Jeffrey R. Holland kọ́ pé: “Ofin nlá àkọ́kọ́ ti gbogbo ayérayé ni láti fẹ́ràn Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn okun, inú, àti agbára wa—èyí ni òfin nlá àkọ́kọ́. Ṣùgbọ́n òtítọ́ nla´ àkọ́kọ́ ti gbogbo ayérayé ni pé Ọlọ́run fẹ́ràn wa pẹ̀lú gbogbo ọkàn okun, inú, àti agbára Rẹ̀.”1

Bawo ni olukuluku wa ṣe le mọ otitọ nla ti ayeraye naa jinlẹ ninu ọkan wa?

Wòlíì Néfì ni a fi ẹ̀rí tí ó lágbára jùlọ nípa ìfẹ́ Ọlọ́run hàn nínú ìran . Lẹ́hìn wíwo igi ìyè náà, Néfì bèèrè láti mọ ìtumọ̀ rẹ̀. Ni idahun, angẹli kan fi ilu kan, iya kan, ati ọmọ-ọwọ kan han Néfì. Bí Néfì ti wo ìlú Násárẹ́tì àti Màríà ìyá olódodo, tí ó gbé Jésù jòjòló dání ní ápá rẹ̀, áńgẹ́lì náà kéde pé, “Wo Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ni, àní Ọmọ Baba Ayérayé!”2

Ni akoko mimọ náà, Néfì ní òye pe ninú ibi Olugbala, Ọlọrun nfi ifẹ Rẹ mimọ ati pipe han. INéfì jẹri pé, ìfẹ́ Ọlọ́run “tan ara rẹ̀ ká lóde nínú ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn.”3

Igi ìyè

A lè ṣe àwòrán ìfẹ́ Ọlọ́run bí ìmọ́lẹ̀ tí ntàn jáde láti ara igi ìyè, tí ó tan ara rẹ̀ ká lóde lórí gbogbo ilẹ̀-ayé sínú ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn. Ìmọ́lẹ̀ àti ìfẹ́ Olọ́run wọ gbogbo àwọn eda Re lára.4

Nigba miiran a nfi aṣiṣe ro pe a le ní ìmọ̀lára ifẹ Ọlọrun lẹ́hìn ti a ti tẹle ọpa irin ti a si jẹ nínú eso naa. Sibẹsibẹ, ìfẹ́ Ọlọrún, kii ṣe gbígbà fún awọn ti wọ́n wa síbi sibi igi nikan ṣugbọn o jẹ agbara gan ti o ru wa lati igi náà.

“Nitorinaa, o jẹ ohun tí ó wuni ju ohun gbogbo lọ,” Nefì kọni pé, angẹli naa sì kigbe pé, “Bẹẹni, ati tí ó ṣe inú dídùn julọ fún ọkàn.”5

Ogún ọdún sẹ́hìn, olùfẹ́ ọ̀wọ́n ọmọlẹbí kan kúrò nínú Ìjọ. O ni ọpọlọpọ awọn ibeere ti a ko dahun. Iyawo rẹ, oluyipada, duro ṣinṣin si igbagbọ rẹ. Wọn ṣiṣẹ takuntakun lati ṣetọju igbeyawo wọn ninú awọn iyatọ ti o dide.

Ni ọdun to kọja o kọ awọn ibeere mẹta silẹ nipa Ijọ ti o nira fun un lati bá laja o si fi wọn ranṣẹ si awọn tọkọtaya meji ti wọn ti jẹ ọrẹ fun ọpọlọpọ ọdun. O pe wọn lati ronu lori awọn ibeere wọnyíkí wọn ó sì wa si oúnjẹ ale lati pin awọn ero wọn.

Lẹhin ibẹwo yii pẹlu awọn ọrẹ, o lọ si yara rẹ o bẹrẹsí ṣiṣẹ lori iṣẹ akanṣe kan. Ibaraẹnisọrọ irọlẹ ati ifẹ ti a fihan sí i nipasẹ awọn ọrẹ rẹ wa si oókan àyà rẹ. Òun kọ lẹ́hìnnáà kọ pé a fi dàndàn mu láti dá iṣẹ́ rẹ dúró. Ó wípé: “Ìmọ́lẹ̀ dídán kún inú ọkàn mi. … Mo ní ìfaramọ pẹlu imọlara ìjinlẹ ti ìmọlẹ yi, ṣugbọn ninu ọran yii o tẹsiwaju lati dagba ni okun sii ju ti iṣaaju lọ o si duro fun awọn iṣẹju pupọ. Mo joko ni idakẹjẹ pẹlu ìmọ̀lara náà, eyiti mo wa ní òye rẹ̀ bíi ìfarahan ti ifẹ Ọlọrun fun mi. … Mo ni imọlara ti ẹmi ti o sọ fun mi pe mo le pada si ile ijọsin ki nsì ṣe afihan ifẹ Ọlọrun yii ninu ohun ti mo bá ṣe nibẹ. ”

Lẹhinnaa o ronú nipa awọn ibeere rẹ. Ìmọ̀lára ti o gba ni pe Ọlọrun bu-ọla fun awọn ibeere rẹ ati pe àìni awọn idahun ti o han kedere ko yẹ ki o da a duro ní lílọ siwaju.6 O níláti pin ifẹ Ọlọrun pẹlu ẹni gbogbo bí o ti tẹsiwaju lati máa ronu. Bí ó ṣe ṣiṣẹ́ lórí ìmòye náà, ó ní ìmọ̀lára ìbátan kan pẹ̀lú Joseph Smith, ẹni tí ó sọ lẹ́yìn Ìran Àkọ́kọ́ rẹ̀ pé, “Ọkàn mi kún fún ìfẹ́, àti fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ èmi lè yọ̀ pẹ̀lú ayọ̀ ńlá.”7

Ní iyalẹnu, ní awọn oṣu diẹ diẹ lẹhinna, o gba ipe kanna ti o ti ṣe ni ogún ọdun ṣaaju. Ni igba akọkọ ti o ṣe ipe naa, o ṣe awọn ojuse rẹ bi ọmọ ìjọ tí ó le ṣiṣẹ́. Nísisìyi ibeere fun u ko di “Bawo ni mo ṣe le mu ipe yii ṣẹ?” ṣugbọn “Bawo ni mo ṣe le ṣe afihan ifẹ Ọlọrun nipasẹ iṣẹ ìsìn mi?” Pẹlu ọna tuntun yii, o ni ayọ, itumọ, ati èrò nla ninú gbogbo awọn abala ti ipe rẹ.

Ẹ̀yin arábìnrin àti arákùnrin, báwo ni a ṣe le gba ágbára tí ó nyínipadà ti ìfẹ́ Ọlọ́run. Wòlíì Mọ́mọ́nì pè wá láti “gbàdúrà sí Bàbá pẹ̀lú gbogbo agbára tí ó wà nínú yín, pé kí ìfẹ́ yì í ó kún inú yín, èyítí ó ti fi jínkí gbogbo àwọn tí wọn jẹ́ olùtẹ̀lé Ọmọ rẹ̀, Jésù Kríst.”8 Kii ṣe pé Mọ́mọ́nì pe wa lati gbadura ki a le ni ìmọ̀lara ifẹ Ọlọrun fun àwọn ẹlòmíràn nikan ṣugbọn lati gbadura ki a le mọ nipa ifẹ mimọ ti Ọlọrun fun ara wa9

Bí a ṣe ngba ìfẹ́ Rẹ̀, a nrí ayọ̀ títóbijù nínú títiraka láti fẹ́ràn àti láti sin bí Òun ti ṣe, ní dída “àwọn ọmọlẹ́hìn tòótọ́ ti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì.”10

A kò le rí ìfẹ́ Ọlọ́run nínú àwọn ipò ti ìgbé ayé wa, ṣùgbọ́n nínú wíwà Rẹ̀ nínú ìgbé ayé wa. A nmọ̀ nípa ìfẹ́ Rẹ̀ nígbàtí a bá gba okun tí ó tayọ tiwa àti nígbàtí Ẹmí Rẹ̀ bá mú àlàáfíà, ìtùnú, àti ìdarí wá. Nígbàmíràn ó le ṣòro láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Rẹ̀. A lè gbàdúrà láti mú kí ojú wa là láti rí ọwọ́ Rẹ̀ nínú ìgbé ayé wa àti láti rí ìfẹ́ Rẹ̀ nínú àwọn ẹwà àwọn ẹ̀dá Rẹ̀.

Bí a ṣe ńronú nípa ìrúbọ àìlópin àti ayérayé ti Olùgbàlà, a lè bẹ̀rẹ̀ sí ní òye ìfẹ́ Rẹ̀ fún wa. A nfi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ kọ àwọn ọ̀rọ̀ orin ti Eliza R. Snow: “Ẹjẹ̀ Rẹ̀ iyebíye ni ó dà sílẹ̀ lọ́fẹ́; Ayé Rẹ̀ ní ó fi ọ̀fẹ́ fi fúnni.”11 Irẹlẹ Rẹ ninu ijiya nla nsunsóri awọn ẹmi wa, ní ṣiṣi ọkan wa sílẹ̀ lati wa idariji ni ọwọ Rẹ ati kikun inú wa pẹlu ifẹ lati gbe bi Oun ti ṣe.10

Ààrẹ Nelson kọ̀wé, “Bí a bá ṣe di olùfarajì tó ní síṣe àwòkọ́ṣe ìgbé ayé wa bíi ti Rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ wa yóò dà mímọ́ àti tọ̀run síi.”12

“Nígbàtí mo jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlá, àwọn ọ̀rẹ́ mi àti èmi pinnu láti fo apákan àkọ́kọ́ ti kílàsì Alákọ́bẹ̀rẹ̀ wa. Nígbà a dé níkẹhìn, sí ìyàlẹ́nu wa, olùkọ́ náà kí wa tọ̀yàyàtọ̀yàyà. Lẹhinna o gba adura àtọkànwánínú eyiti o fi ìmoore tòótọ́ hàn si Oluwa pe a ti pinnu lati wa si kilaasi ni ọjọ náà ní ti ifẹ ọkan wa. Èmi kò lè rántí ohun tí ẹ̀kọ́ náà jẹ́ nípa tàbí orúkọ olùkọ́ wa paapaa ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ní ìwọ̀n ọgbọ́n ọdún lẹ́hìnnáà, mo ṣì ni ìfọwọ́bà nípasẹ̀ ìfẹ́ àìlábàwọ́n tí ó fihàn mí ní ọjọ́ náà.”

Ní ọdún márun sẹ́yìn mo ṣe àkíyèsí àpẹẹrẹ ti ìfẹ́ àtọ̀runwá nígbà lílọ sí Àkọ́bẹ̀rẹ̀ ní wọ́ọ̀dù kan ni Russia. Mo rii arabinrin olõtọ kan ti o kunlẹ niwaju awọn ọmọkunrin meji ti wọ́n njẹri fun wọn pe àní bíó ba jẹ awọn nikan ni wọ́n ngbe lori ilẹ-aye, Jesu ìbá jiya ki o sì ku fun àwọn nikan.

Mo jẹ́ri pé Olúwa àti Olùgbàlà wa kú nítòótọ́ fún olúkúlùkù wa. Ó jẹ́ àfihàn ìfẹ́ àílopin Rẹ̀ fún wa àti fún Baba Rẹ̀.

“Mo mọ̀ pé Olùdándè mi wà láàyè.” Irú ìtùnú wo ni gbólóhùn dídùn yi fúnni! Ó wà láàyè láti bùkún [wa] pẹ̀lú ìfẹ́ Rẹ̀.”14

Njẹ́ kí a lè ṣí ọkàn wa láti gba ìfẹ́ àìlábàwọ́n tí Ọlọ́run ní fún wa àti nígbànáà kí a le pín ìfẹ́ náà jáde nínú ohun gbogbo tí a bá nṣe àti tí a bá jẹ́. Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Jeffrey R. Holland, “Ọ̀la Olúwa Yóò Ṣe Àwọn Ìyanu Láarín Wa,,” Liahona, May 2016, 127.

  2. 1 Néfì 11:21.

  3. 1 Néfì 17:40; ìtẹnumọ́ àfikún.

  4. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 88:13

  5. 1 Néfì 11:22, 23.

  6. Wo 1 Néfì 11:17.

  7. Joseph Smith, in Karen Lynn Davidson and others, eds., The Joseph Smith Papers, Histories, Volume 1: Joseph Smith Histories, 1832–1844 (2012), 13; punctuation and capitalization modernized.

  8. Mórónì 7:48.

  9. Wo Neill F. Marriott, “Abiding in God and Repairing the Breach,” Liahona, Nov. 2017, 11: “Perhaps our life in a loving premortal world set up our yearning for true, lasting love here on earth. A ṣe apẹrẹ fun wa lati fun ifẹ ati lati nifẹ, ati ifẹ ti o jinlẹ julọ wa nigbati a ba jẹ ọkan pẹlu Ọlọrun. ”

  10. Mórónì 7:48

  11. “Ọgbọ́n ati Ìfẹ́ náà ti Tóbi Tó,” Hymns,no. 195.

  12. See Linda S. Reeves, “Worthy of Our Promised Blessings,” Liahona, Nov. 2015, 11: “Mo gbàgbọ́ pé bí a bá le máa fi ojojúmọ́ rántí àti ṣe ìdámọ̀ jíjìn ìfẹ́ tí Baba wa Ọrun àti Olùgbàlà wa ní fún wa, a ó fẹ́ láti ṣe ohunkóhun láti padà sí ọ̀dọ̀ Wọn llẹ́ẹ̀kansíi, láti jẹ́ yíyíká pẹ̀lú ìfẹ́ Wọn títí ayérayé.”

  13. Russell M. Nelson, “Ìfẹ́ Àtọrunwá,” Ensign, Feb. 2003, 17.

  14. “I Know That My Redeemer Lives,” Àwọn orinno. 136.