Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ilé Elétò ti Ṣísẹ̀ntẹ̀lé Kan
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


Ilé Elétò ti Ṣísẹ̀ntẹ̀lé Kan

“Ètò ṣísẹ̀ntẹ̀lé” jẹ́ ọ̀nà kan tí ó rọrùn, àdánidá, àti tí ó múnádóko fún Olúwa láti kọ́ wa, bí àwọn ọmọ Rẹ̀, ní àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ pàtàkì.

Nínú ìmòye ayé mi àti nínú iṣẹ́-ìsìn ní Ìjọ, mo ti ṣe èyí ní ẹgbẹẹgbẹ̀rú àkokò—kì ṣe ṣíwájú àwọn arákùnrin mẹẹdogun tí wọ́n joko tààrà lẹ́hìn mi rí. Mo nímọ̀lára àwọn àdúrà yín àti tiwọn.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ọmọ ìlú abínibí ìjọba ti Tonga ní Guusu Pacific ni mí ṣùgbọ́n a tọ́ mi dàgbà ní Àríwá Amerika. Àjàkálẹ̀-àrùn náà ti dènà àwọn ọgọọgọrun, bóyá ẹgbẹẹgbẹrun àwọn ọ̀dọ́ ìránṣẹ́-ìhìnrere ọmọ Tonga tí wọ́n nsìn káàkiri àgbáyé láti padà sí ilẹ̀ ìbí wọn ọ̀wọ́n nítorí àwọn ààlà rẹ̀ tí ó wà ní títìpa. Díẹ̀ nínú àwọn alàgbà ọmọ Tonga ti wà lórí àwọn míṣọ̀n wọn fún ọdún mẹ́ta tí àwọn arábìnrin sì ti ju ọdún méjì lọ! Wọ́n nfi sùúrù dúró pẹ̀lú ìgbàgbọ́ èyítí a mọ̀ àwọn ènìyàn wa fún. Nibayi, ẹ máṣe jẹ́kí ó yà yín lẹ́nu púpọ̀ bí díẹ̀ nínú wọn tí wọ́n nsìn ní àwọn wọ́ọ̀dù àti àwọn èèkàn yín bá nrí i bí èmi lọ́pọ̀lọpọ̀ síi—ní gbígbó àti híhewú. A dúpẹ́ fún àwọn òjíṣẹ́-ììránṣẹ́ níbi gbogbo fún ìfọkànsìn wọn, pàápàá nígbàtí ó gùn tàbí kúrú síi ju bí wọ́n ti nírètí lọ nítorí àjàkálẹ̀-àrùn náà.

Ní ọjọ́ Ìsinmi kan nígbàtí mo jẹ́ díákónì, mo wà nínú gbọ̀ngàn pẹ̀lú tíréè omi kan tí mo npín oúnjẹ Olúwa nígbàtí obìnrin kan ṣẹ̀ṣẹ̀ rìn wọ inu ile nàá. Ni ìtẹríba, mo súnmọ́ ọ mo sì fún un ni tíréè naa. Ó mi orí, ó rẹrin músẹ́, ó sì mú ago omi kan. Ó ti pẹ́ dé jù láti gba búrẹ́dì. Láìpẹ́ lẹ́hìn ìrírí yi, olùkọ́ ilé mi, Ned Brimley, kọ́ mi pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ààyè àti àwọn ìbùkùn ìhìnrere ti Jésù Krístì ní a fún wa ní ètò ṣísẹ̀ntẹ̀lé.

Lẹ́hìnwá nínú ọ̀sẹ̀ náà, Ned Brimley àti ojúgbà rẹ̀ wá sí ilé wa pẹ̀lú ẹ̀kọ́ mánigbàgbé kan. Ned ránwa létí pé ètò wà nínú bí Ọlọ́run ṣe ṣẹ̀dá ayé. Olúwa ṣe ìṣọ́ra nlá ní ṣíṣe àlàyé fún Mósè ètò nínú èyítí Ó dá ayé. Ní àkọ́kọ́, Ó bẹ̀rẹ̀ nípa pípín ìmọ́lẹ̀ kúrò lára òkùnkùn, lẹ́hìnnáà omi láti ara ìyàngbẹ ilẹ̀. Ó ṣe àfikún ìyè ohun ọ̀gbìn àti àwọn ẹranko ṣaájú ṣíṣe àfihàn ẹ̀dá Rẹ̀ tí ó tóbi jùlọ sí ìpín ilẹ̀ ayé titun tí a ṣẹ̀dá: ọmọ ènìyàn, ní bíbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Ádámù àti Éfà.

“Nítorínáà Ọlọ́run dá ènìyàn ní àwòrán ara rẹ̀, ní àwòrán Ọlọ́run ní ó dá a; ọkùnrin àti obìnrin ni ó dá wọn. …

“Ọlọ́run sì rí ohun gbogbo tí ó dá, sì kíyèsii i, dáradára ní” (Gẹ́nẹ́sísì 1:27, 31).

Inú Olúwa dùn. Ó sì sinmi ní Ijọ́ keje.

Ètò ṣísẹ̀ntẹ̀lé náà nínú èyítí a ṣe ẹ̀dá ayé kò fún wa ní ìwòye ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ sí Ọlọ́run nìkan ṣùgbọ́n bákannáà èrèdí àti fún ẹni wo ni Ó dá ayé.

Ned Brimley àti ẹbí

Ned Brimley fi àmì sí ẹ̀kọ́ rẹ̀ tí ó ní ìmísí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rírọrùn kan: “Vai, ilé Ọlọ́run jẹ́ ọ̀kan tí ó lètò. Ó nretí kí o gbé ìgbé ayé rẹ pẹ̀lú ètò. Ní ṣísẹ̀ntẹ̀lé tó tọ́. Ó fẹ́ kí o sin míṣọ̀n kí o tó gbéyàwó.” Títí di àkokò yí, àwọn olùdarí ìjọ lọ́wọ́lọ́wọ́ nkọ́ni pé “Olúwa nretí ọ̀dọ́ kọ̀ọ̀kan tí ó lágbára láti múra láti sìn. … Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin … tí wọ́n nifẹ láti sìn kí wọ́n mura bákanáà” (Ìwé Ìléwọ́ Gbogbogbò: Sísìn nínú Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhì, 24.0, ChurchofJesusChrist.org). Arákùnrin Brimley tẹ̀síwájú: “Ọlọ́run fẹ́ kí ẹ ṣe ìgbéyàwó ṣaájú kí ẹ tó bí àwọn ọmọ. Àti pé Ó fẹ́ kí ẹ mú àwọn ẹ̀bùn yín dàgbàsókè nígbàgbogbo bí ẹ ti ngba ètò-ẹ̀kọ́. ” Bí ẹ bá yàn láti gbé ìgbé ayé yín kuro ni ṣísẹ̀ntẹ̀lé, ẹ̀yin yio rí ìgbé ayé tí ó nira síi tí ó sì rí rúdurùdu.

Arákùnrin Brimley tún kọ́ wa pé nípasẹ̀ ìrúbọ ètùtù Rẹ̀, Olùgbàlà nrànwálọ́wọ́ láti mú ètò padàbọ̀ sí àwọn ìgbé ayé wa tí ó rí rúdurùdu tàbí tí kò sí ní ṣísẹ̀ntẹ̀lé nípasẹ̀ àwọn yíyàn tí kò dára ti ara wa tàbí ti ẹlòmíràn.

Láti àkokò náà lọ, mo ti ní ìfàmọ́ra pẹ̀lú “èto ṣísẹ̀ntẹ̀lé.” Mo ti ṣe ìmúdàgbà ìhùwàsí ti wíwá ṣísẹ̀ntẹ̀lé nínú ìgbé ayé àti nínú ìhìnrere.

Alàgbà Bednar kọ́ni ní ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ yí: “Bí a ṣe nṣe àṣàrò, kọ́ ẹ̀kọ́, àti tí a ngbé ìgbé ayé ìhìnrere Jésù Krístì, ṣísẹ̀ntẹ̀lé nígbàgbogbo njẹ́ ìkẹ́kọ. Ẹ gbèrò, fún àpẹrẹ, àwọn ẹ̀kọ́ tí a kọ́ nípa bí àwọn ipò ohun ti ẹ̀mí ti ṣe pàtàkì sí láti orí ètò ti àwọn kókó ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó wáyé bí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere ti Olùgbàlà tí di mímú padàbọ̀sípò ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyí.”

Alàgbà Bednar ṣe ìtòsílẹ̀ Ìran Àkọ́kọ́ àti ìfarahàn ìṣíwájú ti Mórónì sí Joseph Smith bíi kíkọ́ ọmọkùnrin wòlíì náà ní àkọ́kọ́, àdánidá àti ìhùwàsí Ọlọ́run, ní títẹ̀lé pẹ̀lú ipa tí Ìwé ti Mọ́mọ́nì àti Èlíjàh yio kó nínú ìkójọpọ̀ Ísráẹ́lì ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìbòjú ní ìgbà iṣẹ́ ìríjú ìkẹhìn yí.

Alàgbà Bednar parí pé: “Ṣísẹ̀ntẹ̀lé onímisi yí kọ́ni ní ẹ̀kọ́ nípa àwọn ohun ti ẹ̀mí ti ó wà ní ipò gíga jùlọ sí Ọlọ́run” (“Ọkàn àwọn Ọmọ Yíò Yípada,” Liahona, Nov. 2011, 24).

Àkíyèsí kan tí mo ti ṣe ni pé “ètò ṣísẹ̀ntẹ̀lé” jẹ́ ọ̀nà kan tí ó rọrùn, tí ó jẹ́ ti àdánidá, àti tí ó múnádóko fún Olúwa láti kọ́ wa, bí àwọn ọmọ Rẹ̀, ní àwọn ìpìlẹ̀ pàtàkì.

A ti wá sí ayé láti kẹkọ àti láti ní ìrírí tí a kò le ní ní ọ̀nà míràn. Ìdàgbasókè wa jẹ́ àràọ̀tọ̀ fún olúkúlùkù wa lọ́kọ̀ọ̀kan àti apákan pàtàkì ti ètò Baba Ọ̀run. Ìdàgbasókè ti ara àti ti ẹ̀mí wa bẹ̀rẹ̀ ní àwọn ipele ó sì ndàgbà díẹ̀díẹ̀ bí a ti nní ìrírí lẹ́sẹẹsẹ.

Álmà fúnni ní ìwàásù tí ó lágbára kan lórí ìgbàgbọ́—ní yíya àwòrán lórí àpẹrẹ ti irúgbìn, èyítí, a bá tún ṣe àti tí a tọ́jú dáradára, yio dàgbà láti inú irúgbìn kékeré sínú igi ti ó dàgbà, igi tí ó gbó tí ó nmú èso dídùn jáde (wo Álmà 32:28-43). Ẹ̀kọ́ náà ní pé ìgbàgbọ́ yín yio pọ̀ síi bí ẹ bá ṣe nfi ààyè fún tí ẹ sì ntọ́jú irugbìn náà—tàbí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run náà—nínú ọkàn yín. Ìgbàgbọ́ yín yio pọ̀ síi bi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ “si wú nínú àyà yín”(ẹsẹ 28). Pé ó “nwú, ó sì hù, ó sì bẹ̀rẹ̀sí dàgbà” (ẹsẹ 30) jẹ́ méjèèjì wíwò àti kíkọ́ni ní ẹ̀kọ́. Ó jẹ́ ṣísẹ̀ntẹ̀lé bákannáà.

Olúwa nkọ́ wa lọ́kọ̀ọ̀kan ní ìbámu sí agbára wa láti kọ́ ẹ̀kọ́ àti bí a ṣe nkọ́ ẹ̀kọ́. Ìdàgbà wa dá lé orí ìfẹ́ wa, ìwádìí àdánidá, ipele ìgbàgbọ́, àti òye wa.

A kọ́ Néfì ní ohun tí Joseph Smith yio kọ́ ni Kirtland, Ohio, ju ọdún 2,300 lọ lẹ́hìnwá: “Nítorí kíyèsíi, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí pé: “Èmi ó fún àwọn ọmọ ènìyàn ní ẹsẹ léẹsẹ, ìlànà léìlànà, díẹ̀ nihin àti díẹ̀ lọ́hun; alábùkúnfún sì ni àwọn wọnnì tí wọ́n bá fetísílẹ̀ sí ìlànà mi, tí wọ́n sì fi ètí wọn yá sí ìmọ̀ràn mi, nítorí wọn yíò kọ́ ọgbọ́n” (2 Néfì 28:30).

Pé a kọ́ “ẹsẹ lórí ẹsẹ, ìlànà lé ìlànà, díẹ̀ nihin àti díẹ̀ lọhun,” lẹ́ẹ̀kansi jẹ́ ṣísẹ̀ntẹ̀lé.

Ẹ wo àwọn àlàyé wọ̀nyí tí a ti gbọ́ púpọ̀ jùlọ nínú àwọn ìgbésí ayé wa: “Àwọn nkan àkọ́kọ́ ní àkọ́kọ́” tàbí “Fún wọn ní wàrà ṣaájú ẹran.” Báwo ni nípa “A ní láti rìn kí á tó sáré”? Ìkọ̀kan àwọn òwe wọ̀nnì nṣe àpèjúwe nkan tí ó jẹ́ ṣísẹ̀ntẹ̀lé.

Àwọn iṣẹ́-ìyanu nṣiṣẹ́ ní ìbámu sí ètò ṣísẹ̀ntẹ̀lé. Àwọn iṣẹ́-ìyanu nwáyé nígbàtí a kọ́kọ́ lo ìgbàgbọ́. Ìgbàgbọ́ ṣaájú iṣẹ́-ìyanu náà.

Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin bákannáà ní a yàn sí ọ́físì Oyèàlúfáà Árónì ní ṣísẹ̀ntẹ̀lé, ní ìbámu sí ọjọ́-orí ti ẹni tí a nyàn: díákónì, olùkọ́, àti lẹ́hìnnáà àlùfáà.

Àwọn ìlànà ti ìgbàlà àti ìgbéga jẹ́ ṣísẹ̀ntẹ̀lé ní àdánidá. A ṣe ìrìbọmi ṣíwájú gbígba ẹ̀bún Ẹ̀mí Mímọ́. Àwọn ìlànà tẹ́mpìlì bákannáà jẹ́ ṣísẹ̀ntẹ̀lé. Nitòótọ́, bí ọ̀rẹ́ mi Ned Brimley ti fi ọgbọ́n kọ́ mi, oúnjẹ Olúwa jẹ ṣísẹ̀ntẹ̀lé—ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú búrẹ́dì, omi tẹ̀le.

“Bí wọ́n sì ti njẹun, Jésù mú àkàrà, ó sì súre, ó bù ú, ó sì fifún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn, ó sì wípé, Gbà, jẹ; èyí ni ara mi.

“Ó sì mú ago, ó dúpẹ́, ó sì fifún wọn, wípé, Ẹ mu gbogbo yín nínú rẹ̀;

“Nítorí èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi ti májẹ̀mú titun, tí a ta sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ènìyàn fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀” (Máttéù 26:26–28).

Ní Jerusalemu àti ní Amẹrika, Olùgbàlà ṣe ìdásílẹ̀ oúnjẹ Olúwa ní ètò kannaà gangan.

“Kíyèsi i, ilé ètò ni ilé mi, ni Olúwa Ọlọ́run wi, kìí ṣe ilé rúdurùdu” (Èkọ́ àti àwọn májẹ̀mú 132:8).

Ìrònúpìwàdà jẹ́ ṣísẹ̀ntẹ̀lé Ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, àní bí ó ṣe èérún kan. Ìgbàgbọ́ nílò ìrẹ̀lẹ̀, èyítí ó jẹ́ èròjà pàtàkì tí níní “ìrora ọkàn àti ẹ̀mí ìròbìnújẹ́” (2 Nephi 2:7).

Ní tootọ, àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ mẹ́rin àkọ́kọ́ ti ìhìnrere jẹ́ ṣísẹ̀ntẹ̀lé A gbàgbọ́ pé àwọn ìpìlẹ̀ àti àwọn ìlànà Ìhìnrere ni: èkíní, Ìgbàgbọ́ nínú Olúwa Jésù Krístì; èkejì, Ìrònúpìwàdà; ẹ̀kẹta, Baptísímù nípá ìrìbọmi fún ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀; ẹ̀kẹrin, ìgbọ́wọ́ lé lórí fún ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́.(Àwọn Nkan Ìgbàgbọ́ 1:4).

Ọba Benjamin kọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ ní òtítọ́ pàtàkì yi: “Kí ẹ̀yin sì ríi pé ẹ ṣe àwọn nkan wọ̀nyí nínú ọgbọ́n àti ètò; nítorípé kò tọ́ kí ènìyàn sáré ju bí ó ṣe lágbára. Àti pẹ̀lú, ó jẹ́ ohun ẹ̀tọ́ pé kí ó lãpọn, kí ó bã lè gba èrè nã; nítorínã, a níláti ṣe ohun gbogbo létò-letò” (Mòsíàh 4:27).

Njẹ́ kí á gbé ìgbé ayé wa pẹ̀lú ṣísẹ̀ntẹ̀lé tí Olúwa ti lànà sílẹ̀ fún wa. A ó bùkún wa bí a tí nwò fún tí a sì ntẹ̀lé àwọn àpẹrẹ àti ṣísẹ̀ntẹ̀lé náà nínú èyítí Olúwa nkọ́ni ní ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ sí I. Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.