Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Kò ha sí ìkunra ní Gíléádì?
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


10:24

Kò ha sí ìkunra ní Gíléádì ?

Agbára ìwòsàn ti Olùgbàlà kìí ṣe agbára Rẹ̀ nìkan láti ṣe ìwòsàn àwọn ara wa ṣùgbọ́n, àní bóyá ní pàtàkì jùlọ, agbára Rẹ̀ láti wo àwọn ọkàn wa.

Láìpẹ́ lẹ́hìn míṣọ̀n mi, lákokò mi bí ọmọ ilé-ìwé ní BYU, mo gba ìpè fóònù kan láti ọ̀dọ̀ baba mi. Ó sọ fún mi pé a ti yẹ̀ òun wó pẹ̀lú jẹjẹrẹ alákan àti pé, bótilẹ̀jẹ́pé àwọn ààyè rẹ̀ láti wà láyé kò dára, ó pinnu láti gba ìwòsàn kí ó sì padà sí àwọn ìṣẹ ìgbé áyé déédé rẹ̀. Ìpè fóònù yẹn jẹ́ àkokò ìrònú fún mi. Baba mì ti jẹ́ bíṣọ́ọ́pù mi, ọ̀rẹ́ mi, àti olùdàmọ́ràn mi. Gẹ́gẹ́bí ìyá mi, àti àwọn arákùnrin mi, àti èmi ti rnonú ọjọ́ iwájú, ó dàbí ẹnipé ó ṣófo. Àbúrò mi ọkùnrin, Dave, nsin míṣọ̀n kan ní New York ó sì kópa ní ọ̀nà jíjìn nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ẹbí tí ó nira wọ̀nyí.

Àwọn olùpèsè ìṣègùn ti ọjọ́ náà daba iṣẹ́-abẹ láti gbìyànjú àti dènà ìtànkálẹ̀ jẹjẹrẹ náà. Ẹbí wa gbàwẹ̀ tọkàntọkàn, a sì gbàdúrà fún ìyanu kan. Mo ní ìmọ̀lára pé a nígbàgbọ́ kíkún pé a lè wo baba mi sàn. Ní kété ṣaájú iṣẹ́ abẹ, arákùnrin ẹ̀gbọ́n mi, Norm, fún baba mi ní ìbùkún kan. Pẹ̀lú gbogbo ìgbàgbọ́ tí a lè ní, a gbàdúrà pé kí á mu láradá.

A ṣètò iṣẹ́-abẹ náà fún àwọn wákàtí púpọ̀, ṣùgbọ́n lẹ́hìn ìgbà díẹ̀, dókítà wá sí yàrá ìdádúró láti pàdé pẹ̀lú ẹbí wa. Ó sọ fún wa pé bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-abẹ náà, wọ́n lè ríi pé jẹjẹrẹ náà ti tàn káàkiri ara baba mi. Ní dídá lórí ohun tí wọ́n ṣe àkíyèsí, baba mi ní oṣù díẹ̀ láti gbé. Inú wa bàjẹ́ gan-an.

Bí baba mi ṣe jí látinú iṣẹ́-abẹ, ó ní àníyàn láti mọ̀ bóyá ìlànà náà ní àṣeyọrí. A pín àwọn ìròhìn burúkú náà pẹ̀lú rẹ̀.

A tẹ̀síwájú láti gbàwẹ̀ àti láti gbàdúrà fún iṣẹ́ ìyanu kan. Bí ìlera baba mi ti lọ lẹ̀ kíákíá, a bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà pé kí ó kúrò nínú ìrora. Ní ìparí, bí ipò rẹ ti burú si, a bèèrè lọ́wọ́ Olúwa láti gbà á láàyè láti yára kọja. Ní oṣù díẹ̀ lẹ́hìn iṣẹ́-abẹ, gẹ́gẹ́bí àsọtẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ oníṣẹ́-abẹ, baba mi kú.

Ìfẹ́ àti ìtọ́jú púpọ̀ ni a dà sórí ẹbí wa nípasẹ̀ àwọn ọmọ-ẹgbẹ́ wọ́ọ̀dù àti àwọn ọ̀rẹ́ ẹbí. A ṣe ìsìnkú rírẹwà kan tí ó bu ọlá fún ìgbé ayé baba mi. Bí àkokò ti nkọjá, síbẹ̀síbẹ̀, tí a sì bẹ̀rẹ̀ síí ní ìrírí ìrora ti àìsì baba mi, mo bẹ̀rẹ̀ síí ní ìyàlẹ́nu ìdí tí baba mi kò fi jẹ́ wíwòsàn. Ó yàmílẹ́nu bóyá ìgbàgbọ́ mi kò lágbára to. Kínìdí tí àwọn ẹbí kan gba iṣẹ́-ìyanu, ṣùgbọ́n ẹbí wa kò gbà? Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ ní míṣọ̀n mi láti yíjú sí àwọn ìwé-mímọ́ fún àwọn ìdáhùn, nítorí náà mo bẹ̀rẹ̀ sí wá àwọn ìwé-mímọ́.

Májẹ̀mú Láéláé kọ́ni nípa tùràrí aládùn tàbi ìkunra, tí a nlò fún ìwòsàn àwọn ọgbẹ́, tí a ṣe láti inú igbó tí a gbìn ní Gíléádì . Ní àwọn àkokò Májẹ̀mú Láéláé ìkunra wá láti mọ̀ọ́ bíi “ìkunra ti Gílíádì.”1 Wòlíì Jeremíàh dárò lórí àwọn àjálù tí ó kíyèsí ní àárín àwọn ènìyàn rẹ̀ ó sì ní ìrètí fún ìwòsàn. Jeremíàh béèrè pé, “Ṣé kò sí ìkunra ní Gíléádì; Ṣe ko si oníṣègùn níbẹ̀? ”2 Nípasẹ̀ lítíréṣọ̀, orin, àti iṣẹ́-ọnà, Olùgbàlà Jésù Krístì nígbàgbogbo ni a ntọ́ka sí bi ìkunra ti Gíléádì nítorí agbára ìwòsàn Rẹ̀ tí ó lápẹrẹ. Bíi Jeremíàh, ó nyàmílẹ́nu, “Ṣé kò ha si ìkunra ní Gíléádì fún ẹbí Nielson?”

Márkù orí kejì ti Májẹ̀mú Titun, a rí Olùgbàlà ní Kapernaumu. Ọ̀rọ̀ agbára ìwòsàn ti Olùgbàlà ti tàn káàkiri ilẹ̀ náà, àti pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn rin ìrìn àjò lọ sí Kapernaumu láti gba ìwòsàn láti ọwọ́ Olùgbàlà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ péjọ ní àyíká ilé níbití Olùgbàlà wà tí kò sì àyè fún Òun láti gba gbogbo wọn wọlé. Àwọn ọkùnrin mẹ́rin gbé ọkùnrin kan tí ó ní àrùn ẹ̀gbà wá fún Olùgbàlà láti wosàn. Wọn kò lágbára láti kọjá láàrín àwọn èrò náà, àti nítorínáà wọ́n ṣí òrùlé ilé náà wọ́n sì sọ ọkùnrin náà kalẹ̀ .láti pàdé Olùgbàlà.

Bí mo ṣe ka àkọsílẹ̀ yii, ẹnú yà mí sí ohun tí Olùgbàlà sọ bí Ó ti pàdé ọkùnrin yi: “Ọmọ, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”3 Mo rò pé bí mo bá jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin mẹ́rin tí ó gbé ọkùnrin yi, èmi ìbá ti sọ fún Olùgbàlà pé, “Ní òtítọ́ a gbe wa sihin láti gba ìwòsàn.” Mo lérò pé Olùgbàlà lè ti dáhùn, “Mo wò ó sàn.” Ṣé ó ṣeéṣe pé èmi kò lóye ní kíkún—pé agbára ìwòsàn ti Olùgbàlà kìí ṣe agbára Rẹ̀ nìkan láti ṣe ìwòsàn àwọn ara wa, ṣùgbọ́n bóyá pàápàá pàtàkì díẹ̀ síi, agbára Rẹ̀ láti wo àwọn ọkàn wa àti àwọn ọkàn tí ó bàjẹ́ ní ẹbí mi sàn?

Olùgbàlà kọ́ni ní ẹ̀kọ́ pàtàkì nípasẹ̀ ìrírí yi bí Ó ṣe mú ọkùnrin yi láradá nípa ti ara níkẹhìn. Ó hàn-kedere fún mi pé ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ni pé kí Òun lè fi ọwọ kan àwọn ojú àwọn fọ́jú wọ̀n sì lè ríran. Ó lè fi ọwọ kan àwọn etí àwọn adití, wọ́n sì lè gbọ́. Ó lè fọwọ́ kan ẹsẹ̀ àwọn tí kò le rìn, wọ́n sì le rìn. Ó lè wo ojú wa àti etí wa àti ẹsẹ̀ wa sàn, ṣùgbọ́n èyí tí ó ṣe pàtàkì jù gbogbo rẹ̀ lọ, Ó lè wo ọkàn wa sàn bí Ó ṣe ńfọ̀ wá mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ kí ó sì gbé wa sókè nínú àwọn àdánwò líle.

Nígbàtí Olùgbàlà farahàn fún àwọn ènìyàn nínú Ìwé Mọ́mọ́nì lẹ́hìn Àjínde Rẹ̀, Ó tún sọ̀rọ̀ nípa agbára ìwòsàn Rẹ̀. Àwọn ará Néfì gbọ́ ohùn Rẹ̀ láti ọ̀run wí pé, “Ṣé ẹ kò ní padà sí ọ̀dọ̀ mi nísisìyí, kí ẹ sì ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì yípadà, Kí èmi lè wò yin sàn?”4 Lẹ́hìnwá, Olùgbàlà kọ́ni pé, “Nítorí ẹ kò mọ bíkòṣe ohun tí wọn yio padà ronúpìwàdà, kí wọn sì wá sọ́dọ̀ mi pẹ̀lú ìpinnu ọkàn ni kikun, Èmi yìo sì wò wọ́n sàn5 Olùgbàlà kò tọ́ka sí ìwòsàn ti ara ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀ ìwòsàn ọkàn wọn nípa ti ẹ̀mí.

Mórónì mú àfikún òye wa bí ó ṣe pín àwọn ọ̀rọ̀ ti baba rẹ̀, Mọ́mọ́nì. Lẹ́hìn sísọ nípa àwọn iṣẹ́ ìyanu, Mọ́mọ́nì ṣàlàyé, “Krístì sì ti wípé: Bí ẹ̀yin ó bá ní ìgbàgbọ́ nínú mi ẹ̀yin yíò ní agbára láti ṣe ohunkóhun tí ó tọ́ nínú mi.”6 Mo kọ́ pé ohun ìgbàgbọ́ mi gbọdọ̀ jẹ́ Jésù Krístì, àti pé Mo nílò láti gba ohun tí ó wúlò nínú Rẹ̀ bí mo ṣe lo ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀. Mo lóye nísisìyí pé pípapòdà baba mi ṣe ìwúlò sí èrò Ọlọ́run. Nísisìyi, bí mo ṣe ngbé ọwọ́ mi lé orí ẹlòmíràn láti bùkún ọkùnrin tàbí obìnrin, ìgbàgbọ́ mi wà nínú Jésù Krístì, mo sì ní òye pé ènìyàn lè àti pé yio gba ìwòsàn nípa ti ara tí ó bá wúlò nínú Krístì.

Ètùtù Olùgbàlà, èyí tí ó pèsè méèjèjì ìràpadà àti agbára ìmúṣiṣẹ́ Rẹ̀, ni ìbùkún tí ó ga jùlọ tí Jésù Krístì fún gbogbo ènìyàn. Bí a ṣe ronúpìwàdà pẹ̀lú ìpinnu ọkàn ní kíkún, Olùgbàlà wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀. Bí a ṣe fi inúdídùn fi ìfẹ́ wa sílẹ̀ fún Baba, pàápàá ní àwọn ipò tí ó nira jùlọ, Olùgbàlà yio gbé àwọn ẹrù wa sókè yio sì jẹ́ kí wọ́n fúyẹ́.7

Ṣùgbọ́n ìhín ni ẹ̀kọ́ nlá tí mo kọ́. Mo ti fi àṣìṣe gbàgbọ́ pé agbára ìwòsàn ti Olùgbàlà kò ṣiṣẹ́ fún ẹbí mi. Bí mo ṣe bojúwo ẹ̀hìn nísisìyí pẹ̀lú àwọn ojú dídàgbà àti ìrírí síi, mo ríi pé agbára ìwòsàn ti Olùgbàlà ti hàn nínú àwọn ìgbésí ayé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ-ẹgbẹ́ ẹbí mi. Mo kọjúsí ìwòsàn ara tí mo kùnà láti rí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ti ṣẹlẹ̀. Olúwa fún mi ní okun ó sì gbé ìyá mi ga ju agbára rẹ̀ lọ nípasẹ̀ ìdánwò líle yi, àti pé ó gbé ìgbé ayé gígùn àti dídára. Ó ní ipa rere tí ó lápẹrẹ lórí àwọn ọmọ àti àwọn ọmọ-ọmọ rẹ̀. Olúwa bùkún fún èmi àti àwọn arákùnrin mi pẹ̀lú ìfẹ́, ìṣọ̀kan, ìgbàgbọ́, àti ìfaradà èyítí ó dí apákan pàtàkì ti àwọn ìgbésí ayé wa tí ó tẹ̀síwájú loni.

Ṣùgbọ́n báwo nípa baba mi? Bí pẹ̀lú gbogbo àwọn ti yio ronúpìwàdà, a mú u láradá nípa tẹ̀mí bí ó ti wá tí ò sì gba àwọn ìbùkún tí ó wà nítorí Ètùtù Olùgbàlà. Ó gba ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti ní bayi ó ndúró de ìyanu ti Ajinde. Àpọ́stélì Páùlu kọ́ni pé: “Nítorí bí gbogbo ènìyàn ṣe kú nínú Ádámù, àní bẹ́ẹ̀ni a ó sọ gbogbo ènìyàn di alààyè nínú Krístì.”8 Ṣé o ríi, mo nsọ fún Olùgbàlà pé, “A mú baba mi wá sí ọ̀dọ̀ rẹ láti gba ìwòsàn,” àti pé Olùgbàlà ti jẹ́ kí ó hàn sími gbangba pé Ó wòósàn. Ìkunra Gílíádì ṣiṣẹ́ fún ẹbí Nielson—kìí ṣe ní ọ̀nà tí a rò, ṣùgbọ́n ní ọ̀nà pàtàkì pàápàá tí ó bùkún tí ó sì tẹ̀síwájú láti bùkún àwọn ìgbésí ayé wa.

Nínú Jòhánnù orí kẹfà ti Májẹ̀mú Titun, Olùgbàlà ṣe iṣẹ́ ìyanu tí ó dùmọ́ni jùlọ. Pẹ̀lú ẹja díẹ̀ àti àwọn àkàrà díẹ̀, Olùgbàlà bọ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n. Mo ti ka àkọọ́lẹ̀ yí ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, ṣùgbọ́n apákan kan wa tí ìrírí tí Mo pàdánù ti ó ti wá ní ìtumọ̀ nla si mi. Lẹ́hìn ti Olùgbàlà bọ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, Ó bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀hìn Rẹ̀ láti kó àwọn àjẹkù tí ó kù jọ, àwọn tí ó ṣẹ́kù, kún agbọ̀n méjìlá. Ó yàmílẹ́nu ìdí tí Olùgbàlà fi gba àkokò láti ṣe èyí. Ó ti di mímọ̀ fún mi pé ẹ̀kọ́ kan tí a lè kọ́ láti ọ̀nà náà ni èyí: Ó lè bọ́ ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n àti pé ó ṣẹ́ kù. “Ore-ọfẹ mi tó fún gbogbo ènìyàn.”9 Agbára ìràpadà àti ìwòsàn ti Olùgbàlà lè bo eyikeyi ẹ̀ṣẹ̀, ọgbẹ́, tàbí ìdánwò, bíótiwù kí ó tóbi tàbí kí ó le tó—àti pé àwọn àjẹkù wa. Ore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀ tó.

Pẹ̀lú ìmọ̀ náà, a lè lọ síwájú pẹ̀lú ìgbàgbọ́, ní mímọ̀ pé nígbàtí àwọn àkokò tí ó nira bá dé, àti pé dájúdájú wọn yio, tàbí nígbàtí ẹ̀ṣẹ̀ yíká ayé wa, Olùgbàlà dúró “pẹ̀lú ìwòsàn ní ìyẹ́-apá rẹ̀,”10 npè wá láti wa si ọ̀dọ̀ Rẹ̀.

Mo jẹri mi fún ọ nípa Ìkunra ti Gíléádì, Olùgbàlà Jésù Krístì, Olùràpadà wa, àti ti agbára ìwòsàn ìyanu Rẹ̀. Mo jẹri ìfẹ́ Rẹ̀ láti wò ọ́ sàn. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.