Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
“Ìwọ Ha Fẹ́ Mi Ju Àwọn Wọ̀nyí Lọ Bí?”
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


13:6

Ìwọ Ha Fẹ́ Mi Ju Àwọn Wọ̀nyí Lọ Bí?

Kíni àwọn ohun tí ẹ le ṣe láàrin ìgbé ayé tiyín láti fihàn pé ẹ fẹ́ Olúwa ní àkọ́kọ́?

Ní Oṣù Kọkànlá 2019, ọ̀rẹ́ mi àti èmi ṣe àbẹ̀wò sí Ilẹ̀ Mímọ́. Nígbàtí a wà níbẹ̀, a ṣe àgbéyẹ̀wò a sì ṣe àṣàrò àwọn ìwé mímọ́ nípa ìgbé-ayé Jésù Krístì. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kan a dúró ní bèbè ìwọ̀-oòrùn-àríwá ti Òkun Gálílì ní ibi kan tí ó le jẹ́ ibití Jesù ti pàdé àwọn ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀ lẹ́hìn Àjínde Rẹ̀.

Lẹ́hìn Àjínde Jésù Krístì bí a ti kà nínú Jòhánnù orí 21, Pétérù àti àwọn ọmọ ẹ̀hìn míràn npẹja ní gbogbo òru náà láìsí àṣeyọrí.1 Ní òwúrọ̀, wọ́n rí ọkùnrin kan tí ó ndúró níbi bèbè náà ẹnítí ó sọ fúnwọn láti ju àwọ̀n wọn sí ẹ̀gbẹ́ kejì ọkọ̀. Sí ìyàlẹ́nu wọn, àwọ̀n náà di kíkún pẹ̀lú iṣẹ́ ìyanu.2

Lójúkannáà wọ́n mọ̀ pé ọkùnrin náà ni Olúwa, wọ́n sì yára sáré lọ kí I.

Bí wọ́n ti nwọ́ àwọ̀n náà lọ sí bèbè, tí ó kún fún ẹja, Jésù wí pé, “Ẹ wá jẹun.”3 Jòhánnù ròhìn pé “nígbàtí wọ́n jẹun tán, Jésù wí fún Símónì Pétérù pé, Símónì, ọmọ Jónà, ìwọ fẹ́ mi ju àwọn wọ̀nyí lọ bí?”4

Bí mo ti ndúró lórí bèbè yí kannáà, mo ríi pé ìbéèrè Olùgbàlà yi jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ìbéèrè pàtàkì jùlọ ti Ó le bi mí lọ́jọ́kan Mo fẹ́rẹ̀ le gbọ́ ohùn Rẹ̀ ní bíbèrè pé, “Russell, ìwọ fẹ́ mi ju àwọn wọ̀nyí lọ bí?”

Njẹ́ ẹ ronú ohun tí Jésù ntọ́ka sí nígbàtí Ó bèèrè lọ́wọ́ Pétérù pé, “Ìwọ fẹ́ mi ju àwọn wọ̀nyí lọ bí?”

Ní mímú ìbéèrè yí bá ara wa mu ní ọjọ́ wa, Olúwa le máa biwá léèrè nípa bí ọwọ́ wa ṣe dí tó àti nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ipá rere àti àìdára tí wọ́n ndíje fún àfiyèsí wa àti àkókò wa. Ó le máa bi ọ̀kọ̀ọ̀kan wa bí a bá fẹ́ràn Rẹ̀ ju àwọn ohun ti ayé yi lọ. Èyí le jẹ́ ìbéèrè nípa ohun tí a gbé níyì gan nínú ayé, ẹnití a ntẹ̀lé, àti bí a ti nwo àwọn ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́bí àti àwọn aládugbò. Tàbí bóyá Ó nbèèrè ohun tí ó nmú ayọ̀ àti ìdùnnú wá fún wa.

Njẹ́ àwọn ohun ti ayé yi nmú ayọ̀, ìdùnnú, àti àlàáfíà náà wá fún wa tí Olùgbàlà fi fún àwọn ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀ àti tí Ó nfi fún wa? Òun nìkan ni ó le mú ayọ̀, ìdùnnú, àti àlàáfíà òtítọ́ wá nípasẹ̀ fífẹ́ràn Rẹ̀ àti títẹ̀lé àwọn ìkọ́ni Rẹ̀.

Báwo ni èmi ó ṣe dáhùn ìbéèrè náà “Ìwọ ha fẹ́ mi ju àwọn wọ̀nyí lọ bí?

Nígbàtí a bá ṣe àwárí ìtumọ̀ kíkún sí ìbéèrè yìí, a lè di dídára síi bíi ọmọlẹ́bí, aládugbò, ọmọ ilú, ọmọ Ìjọ, àti ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Ọlọ́run.

Ní ọjọ́ orí mi, mo ti wà níbi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ètò ìsìnkú. Ó dámi lójú pé púpọ̀ yín yío ti ṣe àkíyèsí ohun tí èmi ti kíyèsí. Nígbàtí a bá nṣe àjọyọ̀ ìgbé-ayé ọmọlẹ́bí tàbí ọ̀rẹ́ kan tí ó ti kú, ó ṣọ̀wọ́n fún olùsọ̀rọ̀ kan láti sọ nípa ìwọ̀n ilé ẹni náà, iye àwọn ọkọ̀, tàbí owó tó kù ní ilé ìfowópamọ́. Wọn kìí sáábà sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìfiránṣẹ́ lórí ìbákẹ́gbẹ́ àwùjọ. Ní púpọ̀ jùlọ ibi àwọn ètò ìsìnkú tí mo ti lọ, wọ́n máa nfojúsùn sórí àwọn ìbáṣepọ̀ olùfẹ́ wọn, iṣẹ́-ìsìn sí àwọn ẹlòmíràn, àwọn ẹ̀kọ́ àti àwọn ìrírí ayé, àti ìfẹ́ wọn fún Jésù Krístì.

Ẹ má ṣìmí gbọ́ o. Èmi kò sọ pé níní ilé tó dára tàbí ọkọ̀-ayọ́kẹ́lẹ́ tó dára jẹ́ àṣìṣe tàbí pé lílo ìbákẹ́gbẹ́ àwùjọ jẹ́ ohun tó burú. Ohun tí èmi nsọ ni pé ní ìparí, àwọn ohun wọ̀nnì jámọ́ nkan níwọ̀nbá kékeré gan ní àfiwé sí fífẹ́ràn Olùgbàlà.

Nígbàtí a bá fẹ́ràn Rẹ̀ tí a sì ntẹ̀lé E, a nní ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀. A nronúpìwàdà. A ntẹ̀lé àpẹrẹ Rẹ̀ a sì nṣe ìrìbọmi àti pé a ngba Ẹmí Mímọ́. A nforítì dé òpin a sì ndúró ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú. A ndáríji àwọn ọmọlẹ́bí àti àwọn aládugbò nípa jíju àwọn ẹ̀hónú tí a le ní sílẹ̀. A ntiraka pẹ̀lú ìtara láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. A ntiraka láti jẹ́ olùgbọ́ràn. A ndá a sì npa àwọn májẹ̀mú mọ́. A nbọ̀wọ̀ fún àwọn baba àti ìyá wa. A npa àwọn ipá tí kò dára ti ayé tì sí ẹ̀gbẹ́kan. A npèsè ara wa sílẹ̀ fún Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Rẹ̀.

Nínú “Krístì Alààyè Náà: Ẹrí ti àwọn Àpóstélì,” a kà pé: “[Jésù] yío padà wá sí orí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ kan. Òun yío ṣe àkóso bíi Ọba àwọn Ọba yío sì ṣe ìjọba bíi Olúwa àwọn Olúwa, gbogbo eékún ni yío sì wólẹ̀ àti gbogbo ahọ́n yío sọ̀rọ̀ ní jíjọ́sìn níwájú Rẹ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wa yío sì dúró láti jẹ́ dídálẹ́jọ́ nípasẹ̀ Rẹ̀ ní ìbámu sí àwọn iṣẹ́ wa àti àwọn ìfẹ́ inú ọkàn wa.”7

Bíi ọ̀kan lára àwọn Àpóstélì tí ó fọwọ́sí ìwé pélébé “Krístì Alààyè Náà,” mo le sọ pé mímọ pé Jésù “ni ìmọ́lẹ̀, ìyè, àti ìrètí ti aráyé”8 nfún mi ní ìfẹ́ inú gígajù láti fẹ́ràn Rẹ̀ síi ní ojoojúmọ́.

Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run Bàbá àti Jésù Krístì wà láàyè. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Wọ́n fẹ́ràn wa. Àwọn ìwé mímọ́ kọ́ni pé “Ọlọ́run fẹ́ aráiyé tóbẹ́ẹ́ gẹ́, tí ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kanṣoṣo fúnni, pé ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàá gbọ́ má bàá ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”9 Àwọn ìwé mímọ́ kọ́ni bákannáà pé Jésù “fẹ́ràn aráyé tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ tí ó fi ayé tirẹ̀ sílẹ̀, pé kí iye àwọn tí wọ́n bá gbàgbọ́ le di ọmọ Ọlọ́run.”10

Baba Ọrun fẹ́ràn wa tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ tí Ó pèsè èrò ìgbàlà Rẹ̀ pẹ̀lú Olùgbàlà kan bíi àwòrán ààrin gbùngbùn. Jésù Krístì sì fẹ́ràn wa tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ tí nínú Ìgbìmọ̀ gíga ní Ọrun, nígbàtí Baba Ọrun bèèrè, “Tani èmi ó rán?” Jésù, ẹnití ó jẹ́ àkọ́bí nínú gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀mí ti Baba, dáhùn pé, “Èmi nìyí, rán mi.”11 Ó wí fún Baba pé, “Bàbá, ìfẹ́ tìrẹ ni kí á ṣe, kí ògo sì jẹ́ tìrẹ títí láé.”12 Jésù fi ara rẹ̀ sílẹ̀ láti jẹ́ Olùgbàlà àti Olùràpadà wa kí àwa le dàbí Wọn kí a sì padà sí ọ̀dọ̀ Wọn.

Àwọn ìwé mímọ́ méjèèjì wọ̀nyí kọ́ni bákannáà pé láti padà sí ọ̀dọ̀ Wọn a nílò láti gbàgbọ́. A nílò láti gbàgbọ́ nínú Jésù àti nínú ètò ìdùnnú ti Ọlọ́run. Láti gbàgbọ́ ni láti fẹ́ àti láti tẹ̀lé Olùgbàlà wa kí a sì pa àwọn òfin mọ́, àní nínú àwọn àdánwò àti ìjà.

Ayé òde òní kò fararọ. Àwọn ìjákulẹ̀, àwọn èdè àìyédè, àwọn ìjìyà, àti àwọn ìyọlẹ́nu ni ó wà.

Ààrẹ Dallin H. Oaks, ní sísọ̀rọ̀ ní 2017, ṣe àkíyèsí àwọn nkan wọ̀nyí: ”Àwọn àkókò ìpèníjà ni ìwọ̀nyí, tí ó kún pẹ̀lú àwọn ìdàmú nlá, àwọn ogun àti ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ogun, ṣíṣeéṣe àwọn àjàkálẹ̀ àrùn ti àwọn àìsàn tí nràn mọ́ni, àwọn ọ̀gbẹlẹ̀, àwọn ìkún omi, àti ooru mímú ní gbogbo àgbáyé.”13

A kò le sọ ìfẹ́ wa fún àti ìrètí nínú Jésù nù, àní bí a tilẹ̀ dojúkọ àwọn ìpèníjà tó dàbí ẹnipé ó fẹ́ borí wa. Bàbá Ọ̀run àti Jésù kì yíò gbàgbé wa láé. Wọ́n fẹ́ràn wa.

Ní Oṣù Kẹwa tó kọjá, Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ wa ní pàtàkì fífi Baba Ọrun àti Jésù Krístì ṣe àkọ́kọ́ nínú ìgbé ayé wa. Ààrẹ Nelson kọ́ wa pé ọ̀kan nínú àwọn ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Isráẹ́lì ni “jẹ́kí Ọlọ́run borí.”14

Ó bi olukúlùkù wa léèrè pé: “Ṣe ẹ̀ nfẹ́ láti jẹ́kí Ọlọ́run borí nínú ayé yín? Ṣe ẹ̀ nfẹ́ láti jẹ́kí Ọlọ́run jẹ́ agbára pàtàkì jùlọ nínú ayé yín? Ṣe ẹ ó fàyè gba àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀, òfin Rẹ̀, àti májẹ̀mú Rẹ̀ láti ní ipá lórí ohun tí ẹ ó ṣe lójojúmọ́? Ṣe ẹ ó fàyè gba ohùn Rẹ̀ láti wà ní ipò ìṣíwájú leyíkéyi míràn? Ṣe ẹ̀ nfẹ́ láti jẹ́ kí ohunkóhun tí Ó nílò kí ẹ ṣe jẹ́ ìṣíwájú lórí gbogbo àwọn ìlépa míràn? Ṣé ẹ̀ nfẹ́ láti jẹ́ kí ìfẹ́ Rẹ̀ ó gbé tiyín mì?”9

A gbọ́dọ̀ máa rántí nígbà gbogbo pé ìdùnnú tòótọ́ wa dá lórí ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run, pẹ̀lú Jésù Krístì, àti pẹ̀lú ara wa.

Ọnà kan láti fi ìfẹ́ wa hàn ni nípa dídarapọ̀ mọ́ ẹbí, àwọn ọ̀rẹ́, àti àwọn aládugbò ní síṣe àwọn nkan kékèké láti sin ara wa dáradára síi. Ẹ ṣe àwọn ohun tí yío mú kí ayé yí jẹ́ ibi tí ó dára síi.

Kíni àwọn ohun tí ẹ le ṣe láàrin ìgbé ayé tiyín láti fihàn pé ẹ fẹ́ Olúwa ní àkọ́kọ́?

Bí a ṣe nfojúsùn sórí fífẹ́ràn àwọn aládugbò wa bí Òun ti fẹ́ wọn, a nbẹ̀rẹ̀ láti fẹ́ràn àwọn tí wọ́n wà ní àyíká wa nítòótọ́.16

Mo bèèrè lẹ́ẹ̀kansíi, báwo ni ẹ̀yin ó ṣe dáhùn sí ìbéèrè Olùgbàlà náà “Ìwọ ha fẹ́ mi ju àwọn wọ̀nyí lọ bí?

Bí ẹ ti nronú sí ìbéèrè yí bí èmi ti ṣe, mo gbàdúrà pé kí ẹ̀yin ó le dáhùn bí Pétérù ti ṣe ní ìgbà pípẹ́ sẹ́hìn, “Bẹ́ẹ̀ni, Olúwa, ìwọ mọ̀ pé mo fẹ́ràn rẹ.”18 nígbànáà ó sì fihàn nípa fífẹ́ àti sísin Ọlọ́run àti gbogbo àwọn yí ó wà ní àyíká rẹ̀.

Mo jẹ́rìí pé a jẹ́ alábùkún fún láti ní ìhìnrere Jésù Krístì láti tọ́ wa ní ọ̀nà tí a fi ngbé àti tọ́jú ara wa. Nínú Rẹ̀, a ṣe àwárí pé olukúlùkù ọmọbìnrin àti ọmọkùnrin Ọlọ́run ṣe iyebíye sí I.

Mo jẹ́ri pé Jésù Krístì ni Olùgbàlà wa. Òun ni Ọmọ Ọlọ́run. Mo sì jẹ́ ẹ̀rí mi pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.