Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Orúkọ Ìjọ kò Gba Ìdúnádúrà.
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


13:36

Orúkọ Ìjọ kò Gba Ìdúnádúrà.

Nígbàtí a bá fi tìfẹ́tìfẹ́ tẹ̀lé àmọ̀ràn Olúwa, bí a ti fihàn nípasẹ̀ wòlíì alààyè Rẹ̀, nípàtàkì bí ó ti wa nì títako rírònú wa tẹ́lẹ̀, ní fífẹ́ ìrẹ̀lẹ̀ àti ẹbọ, Olúwa nbùkún wa pẹ̀lú àníkún agbára ti-ẹ̀mí.

Nínú ìsọníṣókí ìpàdé apapọ̀ ní Ọjọ́ Kẹrìndínlógúm Oṣù Kẹjọ, 2018, Ààrẹ Russel M. Nelson wípé: “Olúwa ti tẹ̀ pàtàkì orúkọ tí Òun ti fihàn fún Ìjọ Rẹ̀ mọ́ òun nínú, àní Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.1 A ní iṣẹ́ níwájú wa láti mú arawa wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Rẹ̀.”2

Ọjọ́ méjì lẹ́ẹ̀hìnnáà, ní Ọjọ́ kejidinlogun Oṣù Kẹjọ, mo wà pẹ̀lú Àárẹ́ Nelson ní Montreal, Canada. Títẹ̀lé ìpàdé àwọn ọmọ-ìjọ wa ní Palais de Congré ìwúnilórí, Ààrẹ Nelson dáhùn àwọn ìbèèrè láti ọ̀dọ̀ àwọn oníròhìn. Ó jẹ́wọ́ pé ó máa jẹ́ “ìpènijà láti [tún orúkọ Ìjọ gbékalẹ̀, àti] láti yí àṣà jíju ọgọrun ọdún [kan] padà.” Ṣùgbọ́n, o fikun pé, “orúkọ Ìjọ kò gba ìdúnádúrà.”2

Ọ̀sẹ̀ méje lẹ́hìnnáà, ó sọ̀rọ̀ ní ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò: “Olúwa tẹ pàtàkì orúkọ tí Òun ti paláṣẹ fún Ìjọ Rẹ̀ mọ́ mi nínú, àní Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn. … Olùgbàlà Fúnrarẹ̀ ẹnití ó wípé, ‘Nítorínáà báyi ni a ó pe ìjọ mi.’” Nígbànáà ó tunsọ pé, “Orúkọ Ìjọ kò gba ìdúnádúrà.”3

Ìbèèrè Rere Kan

Ìbèèrè rere kan yọjú: “Kínìdí báyìí?” nígbàtí a ti gba orúkọ ìnagijẹ “Mọ́mọ́nì” fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn díkédì? “Akọrin Àgọ́ Mọ́mọ́nì,” fídíò náà sàmì “Mo jẹ́ Mọ́mọ́nì kan,” orin Alakọbẹrẹ “Èmi ni Ọmọdékùnrin Mọ́mọ́nì kan”?

Ẹ̀kọ́ ti Krístì jẹ́ àìyípadà àti àìlópin. Síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ìṣísẹ̀ kókó àti pàtàkì ti iṣẹ́ Olùgbàlà ni a fihàn ní akoko yíyẹ wọn. Ní òwúrọ̀ yí, Ààrẹ Nelson wípé, “Ìmúpadàsípò jẹ́ ètò, kìí ṣe ìṣẹ̀lẹ̀.”5 Olúwa wípé, “Ohun gbogbo gbọ́dọ̀ wá sí ìmúṣẹ ní àkokò tiwọn.”5 Nísisìyí ni àkokò wa, a sì ntún ìfihàn orúkọ Ìjọ gbékalẹ̀.

Ìdánimọ̀ àti àyànmọ́ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn gba pé kí a pè é nípa orúkọ Rẹ̀. Láìpẹ́ mo wà ní Kirtland, Ohio, nibití Wòlíì Joseph Smith, pẹ̀lú àwọn ọmọ Ìjọ díẹ̀ nìkan, ti sọtẹ́lẹ̀ pe, “Ìjọ yí yíò kún Àríwá àti Gúsù Amẹ́ríkà—yíò sì kún gbogbo ayé.”6 Olúwa ṣàpèjúwe iṣẹ́ ìríjú yí bí “iṣẹ́ ìyàlẹ́nu àti àrà kan.”8 Ó sọ̀rọ̀ nípa “májẹ̀mú [tí yíò] di mímúṣẹ ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn,” fífi-ààyè gba “gbogbo … ilẹ̀-ayé [láti] di alábùnkúnfún.”9

Àwọn ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ yí ni à nyípadà sí àwọn èdè marunlelaadọta. Nígbẹ̀hìn, àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni a ó gbọ́ tí a ó sì kà ní àwọn èdè mẹ́jìdínlọ́gọ́ọ̀rún ní púpọ̀ ju orílẹ̀-èdè àti agbègbè igbalélógún.

Ìpadabọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì

Nígbatí Olùgbàlà bá padàdé nínú ọlánlá àti ògo, àwọn onígbàgbọ́ ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn yíò wà ní àárín gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo ènìyàn, gbogbo ẹ̀yà, gbogbo èdè, àti gbogbo àwọn ọ̀làjú ayé.

Agbára Dídàgbà Ìjọ

Agbára ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ Jésù Krístì kò ní wà lórí àwọn ẹnití wọ́n jẹ́ ọmọ Ìjọ nìkan. Nítorí àwọn ìfìhàn tọ̀run ní ọjọ́ wa, nítorí ìwé-mímọ́ ọ̀wọ̀ tí a múpadàbọ̀sípò sí ilẹ̀-ayé àti ẹ̀bùn alágbára ti Ẹ̀mí Mímọ́, a ó jẹ̀ ìmọ́lẹ̀ kan lórí òkè-kékèké bí òjìji ìrẹ̀lẹ̀ àìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì ní ayé tó ṣókùnkùn. Bíótilẹ̀jẹ́pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ lè fi ààyè gba kí ayé bo ìgbàgbọ́ wọn nínú Olùràpadà mọ́lẹ̀, a “kò ní mikàn kúrò ní ibi [tiwa].”9 Àwọn krìstẹ́nì tí wọn kò sí ní àárín jíjẹ́-ọmọ-ìjọ wa ní yíò gba ojúṣe wa àti ẹ̀rí wa dídájú ti Krístì mọ́ra. Àní àwọn krìstẹ́nì tí wọn nwò wá nísisìyí pẹ̀lú iyèméjì yíò gba wá mọ́ra bí ọ̀rẹ́ ní ọjọ́ kan. Ní àwọn ọjọ́ tó mbọ̀, a ó pè wá nípa orúkọ ti Jésù Krístì.

A dúpẹ́ lọ̀wọ́ yín fún ìtiraka akọni yín láti gbèrú orúkọ Ìjọ tòótọ́. Nínú ìpàdé àpapọ̀ ọdún mẹta sẹ́hìn, Ààrẹ Nelson ṣèlérí fún wa: “pé ìfọwọ́sí líle wa láti lo orúkọ títọ́ ti Ìjọ Olùgbàlà … [yíò mú] ìgbàgbọ́ púpọ̀si àti ààyè sí agbára ti-ẹ̀mí títóbi si wá fún wa.”10

Ìlérí yí ni a ti múṣẹ nípasẹ̀ àwọn olùfọkànsìn ọmọẹ̀hìn káàkiri ayé.11

Arákùnrin Lauri Ahola lati Ilà-oòrùn United States wípè bíótilẹ̀jẹ́pé ní ìgbàmíràn òun nri bi òdì láti ṣe àbápín orúkọ Ìjọ. Ṣùgbọ́n nítorí àmọ̀ràn wòlíì, òun tẹramọ. Ní ìgbà kan, òun nbẹ ọ̀rẹ́ kan wò ní Ìjọ ìgbàgbọ́ míràn. Nihin ni àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀:

“Olùbárìn kan bèèrè, “Ṣé Mọ́mọ́nì ni ọ́?”

“‘Ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ni mi, bẹ́ẹ̀ni,’ mo wí. Ó bẹ̀rẹ̀ sí mbi mí ní onírurú àwọn ìbèèrè, ọ̀kọ̀ọ̀kan bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú: ‘Ṣé Ìjọ Mọ́mọ́ni gbàgbọ́ … ?’ Ati ní ìgbà kọ̀ọkan, mo bẹrẹ ìdáhùn mi pẹ̀lú gbólóhùn-ọ̀rọ̀: ‘Ní ìmupadàbọ̀sípò Ìjọ Krístì, a gbàgbọ́ …’

“Nígbàtí ó ṣàkíyèsí pé èmi kò tẹ́wọ́gba àkọlé ‘Mọ́mọ́nì,’ ó bi mi léèrè ṣáká pé, ‘Ṣe Mọ́mọ́nì ni ọ?’

“Nítorínáà mo bíi léèrè bí ó bá mọ ẹnití Mọ́mọ́nì iṣe—ko dáhùn. Mo wí fun pé Mọ́mọ́ni jẹ́ wòlíì kan … [mo sì ní] ọlá láti wà ní ìbáṣe pẹ̀lú rẹ̀].

“‘Ṣùgbọ́n,’ mo tẹ̀síwájú pé, ‘Mọ́mọ́nì kò kú fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi. Mọ́mọ́ni kò … jìyà ní Gẹ́tsémánì tàbí kú ní orí àgbélèbú [fún mi]. … Jésù Krístì ni Ọlọ́run mi àti Olùgbàlà mi. … Nípa orúkọ Rẹ̀ sì ni mo sì fẹ́ kí a mọ̀ mí.’ …

“… Lẹ́hìn àwọn ìṣẹ́ju-akàn ìdákẹ́jẹ́ díẹ̀, [olùbárìn náà kígbe], ‘Nítorínáà, Krístẹ́nì ni ọ!’”12

Ààrẹ Nelson nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò

Rántí àwọn ọ̀rọ̀ Ààrẹ Nelson? “Mo ṣèlérí fún yín pé tí a ó bá sa ipá wa láti mú orúkọ Ìjọ Olúwa títọ́ padàbọ̀sípò, Òun ẹnití Ìjọ yí íṣe tirẹ̀ yíò da agbára àti ìbùkún Rẹ̀ sílẹ̀ lé orí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, irú èyí tí a kò rí rí láéláé.”13

Olúwa Nṣí Ọ̀nà Nígbàgbogbo

Olúwa npa àwọn ìlérí Rẹ̀ mọ́ nígbàgbogbo. Olúwa nṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wa bí a ti nṣe iṣẹ́ Rẹ̀.

Fún ọ̀pọ̀ ọdún a ti ní ìrètí láti ra àwọn bi ìdúrósí ayélujára ChurchofJesusChrist.org àti ChurchofJesusChrist.com. Kìí ṣé bẹ́ẹ̀ náà ni ríra. Nípa àkokò tí Ààrẹ Nelson kéde, méjèèjì ni ó wà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ó jẹ́ iṣẹ́-ìyanu kan.15

Olúwa ti gbé àwọn ìgbìyànjú wa ga ní títún orúkọ́ tí a ti lẹ̀ mọ́ Ìjọ tipẹ́tipẹ́ ṣe.

Ní rírìn síwájú nínú ìgbàgbọ́, orúkọ́ Akọrin Àgọ́ Mọ́mọ́nì ni a yípadà sí Akọrin Àgọ́ ní Igun-mẹ́rin Tẹ́mpìlì. Ibi-wẹ́ẹ̀bù LDS.org, èyí tí ó gbà ju míllíọ́nù mọ́kànlélógún àwọn ìbẹ̀wò lóṣooṣù, ni ó yílọ sí ChurchofJesusChrist.org.16 Kọ́llẹ́jì Káràkátà LDS ni a yípadà sí Kọ́llẹ́jì Ẹ́nsáìnì. Ibi-wẹ́ẹ̀bù Mormon.org ni a tún-darí sí ChurchofJesusChrist.org. Púpọ̀ ju àwọn ohun-èlò ẹgbẹ̀rún tí ó ní orúkọ “Mormon” tàbí “LDS” lílẹ̀ mọ́ wọn ni a ti yí lórúkọ-padà. Àwọn ònígbàgbọ́ àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn tún ibi-wẹ́ẹ̀bù, Pọ́dícástì, àti àkọsílẹ̀ Twítà wọn ṣe,

Àmi Titun Ìjọ

A gba àmì titun tí ó dálé Jésù Krístì.

“Ní oókan àmì náà ni ìjúwe ti ère àwo Thorvaldsen ti Krístọ́snáà. Ó fi olùjíìnde, alààyè Olúwa hàn tó nnawọ́ jáde láti gba gbogbo ẹnití yíò wá sọ́dọ Rẹ̀ mọ́ra.

“Pẹ̀lú àmì, Jésù Krístì ndúró lábẹ́ áṣìá kan tó [nrán wa létí] nípa olùjínde Olùgbàlà tí ó njáde látinú ibojì.”14

Orúkọ Ìjọ ní àwọn èdè
Orúkọ Ìjọ ní àwọn àfikún èdè

Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ti fi títẹ̀ kọ́ra ní púpọ̀ ju àádọ́ta èdè. Ibi titun àwọn orúkọ ìdúró ni a ti gbà káàkiri ayé.

Ìmoore fún Ríran àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́

A fi ìmoore hàn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èníyàn rere àti onínú-rere tí wọ́n ti bu-ọlá fún ìfẹ́-inú wa láti pè wá ní orúkọ títọ́. Mo ka àtẹ̀jáde kan láìpẹ́ tí ó ṣe àtúnṣọ Catholic Cardinal kan tí ó ntọ́ka sí “àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.”18 Bí mo ti ṣèbẹ̀wò pẹ̀lú olórí Krìstẹ́nì ìjọ kan ní oṣù kan sẹ́hìn ní ilà-òòrùn United States, ó tọ́ka sí Ìjọ nínú ìtọ́kasí àkọ́kọ́ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo orúkọ wa, àti títẹ̀lé e jú ìgbàkan lọ pẹ̀lú, “Ìjọ ti Jésù Krístì.”

A mọ̀ pé fífi àwọn ọ̀rọ̀ mẹfà kún orúkọ wa kò ní dára fún oníròhìn, ṣùgbọ́n bí Ààrẹ Nelson ti sọtẹ́lẹ̀, “oníròhìn tó dára yíò ní ìkáánú ní fífèsì sí ìbèèrè wa.”19 Ẹ ṣé fún nínawọ́ sí wá ní irú èrò kannáà tí a fún ti-ọ̀làjú, eléré, òṣèlú, tàbí àwọn ìṣètò ìletò nípa lílo orúkọ tí a fẹ́rànjù.

Àwọn ẹni díẹ̀ yíò wa, ni ìrètí láti dènà tàbí dín pàtàkì ìṣẹ́-ìránṣẹ́ wa kù, yíò tẹ̀síwájú láti pè wá ní “Mọ́mọ́nì” tàbí “Mọ́mọ́nì.” Pẹ̀lú ìwà-ọmọlúàbí, lẹ́ẹ̀kansi a ni kí àwọn oníròhìn onínú-dídára bu-ọlá fún ìfẹ́-inú wa láti pè wá nípa orúkọ wa ti bíi igba ọdún sẹ́hìn.

Ìgboyà àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn

Àwọn ẹgbẹẹgbẹ̀rún àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn wa tí wọ́n nfi ìgboya kéde orúkọ Ìjọ. Bí a ba ṣe ipá wa, àwọn míràn yíò tẹ̀le. Mo nifẹ ìtàn yí láti Tahiti.

Iriura Jean ọmọ ọdún mẹwa pinnu láti tẹ̀lé àmọ̀ràn Ààrẹ Nelson.

“Ní kíláàsì ilé-ìwé rẹ̀ wọ́n sọ̀rọ̀ òpin-ọ̀sẹ̀ … Iriura sì sọ̀rọ̀ nípa … ìjọ.

“Olùkọ́ rẹ̀, Vaite Pifao, wípé, ‘Áà, Mọ́mọ́nì ni ìwọn iṣe?’

“Iriura fi ìgboyà sọ pé,‘Rárá … mo jẹ́ ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn!’

“Olùkọ́ rẹ̀ fèsì, ‘Bẹ́ẹ̀ni,… Mọ́mọ́nì ni ìwọ iṣe.’

“Iriura tẹnumọ, ‘Rárá olùkọ́, mo jẹ́ ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn!’

“Ó ya Ms. Pifao lẹ́nu ní irú ìdánilójú Iriura ó sì jẹ́ ìyanu ní ìdí tí ó fi tẹnumọ́ lílò orúkọ gígùn ti ìjọ rẹ̀ [náà]. [Ó pinnu láti kọ́ síi nípa Ìjọ.]

“[Lẹ́hìnnáà, bí Arábìnrin] Vaite Pifao ti ṣe ìrìbọmi [ó fi ímoore rẹ̀ hàn] pé Iriura gbọ́ àmọ̀ràn Ààrẹ Nelson.”16

Arábìnrin tí ó kọ́ nípa Ìjọ nítorí akẹkọ rẹ̀

“Orúkọ Ìjọ kò gba ìdúnádúrà.” Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀síwájú nínú ìgbàgbọ́. Nígbàtí a bá fi tìfẹ́tìfẹ́ tẹ̀lé àmọ̀ràn Olúwa, bí a ti fihàn nípasẹ̀ wòlíì alààyè Rẹ̀ nípàtàkì bí ó ti wap nì títako ìrònú wa tẹ́lẹ̀, ní fífẹ́ ìrẹ̀lẹ̀ àti ẹbọ, Olúwa nbùkún wa pẹ̀lú àníkún agbára ti-ẹ̀mí tí ó rán àwọn ángẹ́lì Rẹ̀ láti tìwálẹ́hìn àti láti dúró pẹ̀lú wa.21 A gba ìmúdájú Olúwa àti àṣẹ Rẹ̀.

Mo jẹ́ ẹlẹri sí agbára ọ̀run tí ó bà lé olólùfẹ́ wòlíì wa, Ààrẹ Russell M. Nelson. Ìfẹ́-inú àtọkànwá rẹ̀ jùlọ ni láti mú inú Olúwa dùn àti láti bùkún àwọn ọmọ Baba wa Ọ̀run. Látinú ìrírí araẹni, mímọ́, mo jẹ́ ẹ̀rí nípa ìfẹ́ Olúwa fún un. Òun ni wòlíì Ọlọ́run.

Mo jẹri pé Jésù ni Krístì, Ọmọ Ọlọ́run. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Wo 3 Nífáì 27:7–9; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 115:4.

  2. Russell M. Nelson, in “The Name of the Church,” Newsroom, Aug. 16, 2018, newsroom.ChurchofJesusChrist.org.

  3. President Nelson Discusses the Name of the Church,” Newsroom, Aug. 21, 2018, newsroom.ChurchofJesusChrist.org.

  4. Russell M. Nelson, “TorúkọOrúkọ Títọ́ Ìjọ,” Liahona,, Nov. 2018, 87.

  5. Russell M. Nelson, “The Temple and Your Spiritual Foundation,” Liahona, Nov. 2021, 116.

  6. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 64:32.

  7. Teachings of Presidents of the Church: Joseph Smith (2007), 186.

  8. 2 Néfì 27:26.

  9. 1 Néfì 15:18.

  10. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 101:17.

  11. Russell M. Nelson, “Dída àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn Alápẹrẹ,” Liahona, Nov. 2018, 114.

  12. Wo Henry B. Eyring, “Báyìí Ni A Ó Pe Orúkọ Ìjọ Mi,” Liahona, Oct. 2021, 6–9.

  13. Lauri Ahola, “Using the Full Name of the Church Was Awkward but Worth It” (digital-only article), Liahona, Apr. 2020, ChurchofJesusChrist.org.

  14. Russell M. Nelson, “The Correct Name of the Church,” 89.

  15. Ibi-iṣẹ́ Ohun-ìní Intellectual tí nbojútó ibi orúkọ ti ChurchofJesusChrist.org láti 2006, kò sì tíì wà níbẹ̀. Ó jẹ́ alámì pé a fisílẹ̀ fún títà ní ìgbà kannáà bí Ààrẹ Nelson ti kéde, Ìjọ sì ra ibi orúkọ náà nípasẹ̀ ẹnì kẹ́ta ní iye ìbámu gan an.

    Nínú irú kannáà, Ìjọ ti bẹ̀rẹ̀ bíbojútó ipò àti wíwà ibi orúkọ ti ChurchofJesusChrist.com láti 2011. Pẹ̀lú ìyanilẹ́nu, òun bákannáà di gbígbékalẹ̀ ní Oṣù Kẹ́jọ August 2018 a sì ràá bákannáà fún iye ibámu.

  16. Nínú ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2018, Ààrẹ Nelson wípé:

    Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, àwọn ìjiyàn ayé púpọ̀ wa lórí mímú orúkọ tòótọ́ ti Ìjọ padàbọ̀sípò. Nítorí ayé ìgbàlódé nínú èyí tí à ngbé, àti pẹ̀lú ẹ̀rọ ìwákiri ohunrere tí ó nràn gbogbo wa lọ́wọ́ láti rí ìwífúnni tí a nílò lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀—pẹ̀lú ìwífúnni nípa Ìjọ Olúwa—àwọn ọlọfintoto sọ pé àtúnkọ ní àkokò yí kò mọ́gbọ́n wá. …

    “…Mo ṣèlérí fún yín pé tí a ó bá sa ipá wa láti mú orúkọ Ìjọ Olúwa títọ́ padàbọ̀sípò, Òun ẹnití Ìjọ yí íṣe tirẹ̀ yíò da agbára àti ìbùkún Rẹ̀ sílẹ̀ lé orí àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn” (”Orúkọ Títọ́ Ìjọ,” 88, 89).

    Látigbà ìyípadà ti LDS.org sí ChurchofJesusChrist.org, ibi àṣẹ (agbára àti okun ti ibi láti ṣe ìwákiri ẹ́ngìnì) lágbára ju bí ó ti wà tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ́. Fún àpẹrẹ, ChurchofJesusChrist.org ojú-ewé ilé nísisìyí, tí ó sì ti wà jù ọdún kan lọ, èsì gíga ìwákiri ní United States lórí Gúgù nígbàtí ẹnìkan nwákiri fún ọ̀ràn náà “ìjọ,” níbití a kò lè gba ìyàtọ̀ èyí tẹ̀lẹ̀tẹ̀lẹ̀.

  17. Russell M. Nelson, “Ṣíṣí Ọ̀run fún Ìrànlọ́wọ́,” Liahona, May 2020, 73.

  18. Wo Tad Walch, “‘If we can’t get along, it’s downright sinful’: The partnership between Catholics and Latter-day Saints,” Deseret News, July 1, 2021, https://www.deseret.com

  19. Russell M. Nelson, “The Correct Name of the Church,” 89.

  20. Orúkọ Títọ́ Ìjọ: Ìtàn Tahitian Kan,” Pacific Newsroom, Sept. 15, 2019, news-nz.ChurchofJesusChrist.org.

  21. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 84:88.