Ìsọ̀rọ̀ Nípa Ilera Ọpọlọ
Gbà mí láyè láti pín ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àkíyèsí tí mo ti ṣe bí ẹbí mi ti la àwọn ìdánwò kọjá.
Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹbí wa ti gbádùn àwọn ìbùkún ọrọ̀ nígbàtí à nfi tayọ̀tayọ̀ rìn ní ipá-ọ̀nà májẹ̀mú, a ndojúkọ àwọn òkè-nlá gíga bákannáà. Mo fẹ́ pín àwọn ìrírí ti araẹni díẹ̀ nípa àìsàn ọpọlọ. Ìwọ̀nyí pẹ̀lú ìrẹ̀wẹ̀sì ìṣègùn, ìtara líle, àrùn bipólà, ADHD—àti nígbàmíràn àpapọ̀ kan nípa gbogbo wọn. Mo pín àwọn ìrírí rírọ̀ wọ̀nyí pẹ̀lú àṣẹ àwọn tí ó ni.
Nígbà iṣẹ́-ìránṣẹ́ mi, mo ṣe alábapàdé ọgọọgọ́ọ̀rún àwọn olúkúlùkù ènìyàn àti ẹbí pẹ̀lú irú àwọn ìrírí kannáà. Nígbàmíràn mo wòye bí “àìsàn ìdahoro” ti ó bo ilẹ̀ tí a dárúkọ nínú àwọn ìwé-mímọ́ lè pẹ̀lú àrùn ọpọlọ.1 Ó jẹ́ ti àgbáyé, tí ó borí gbogbo ayé àti àṣà, tí ó nbá gbogbo—ọ̀dọ́, àgbàlagbà, ọlọ́rọ̀, àti òtòṣì jà. A kò yọ àwọn ọmọ Ìjọ kúrò.
Ní àkokò kannáà, ẹ̀kọ́ wa kọ́ wa láti tiraka láti dàbí Jésù Krístì àti láti di pípé nínú Rẹ̀. Àwọn ọmọ wa kọrin, “Èmi ngbìyànjú láti dàbí Jésù.”2 A fẹ́ láti di pípé àní bí Baba wa Ọ̀run àti Jésù Krístì ṣe jẹ́ pípé.3 Nítorí àrùn ọpọlọ lè nípalára pẹ̀lú ìgbìró wa nípa jíjẹ́-pípé, ó dúró bí èèwọ̀ gbogbo bákannáà nígbàkugbà. Bí àbájáde kan, àìmọ̀ púpọ̀ wà síi, ìjìyà pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ púpọ̀ síi, àti àìnírètí púpọ̀ síi. Ọ̀pọ̀lọpọ̀, ní ó nní ìmọ̀lara ìbonimọ́lẹ̀ nítorí wọn kò bá rírò òṣùwọ̀n pàdé, gbàgbọ́ pẹ̀lú àṣìṣe pé wọn kò ní àyè kankan nínú Ìjọ.
Láti bá ẹ̀tàn bẹ́ẹ̀ jà, ó ṣe pàtàkì láti rántí pé “Olùgbàlà ní ìfẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan àwọn ọmọ Baba Rẹ̀. Òun ní òye ìrora àti ìlàkàkà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nní ìrírí rẹ̀ ní kíkún bí wọ́n ti ngbé pẹ̀lú oríriríṣi ìgbòòrò ti àwọn ìpènijà ìlera ọpọlọ. Ó jìyà ‘àwọn ìrora àti ìpọ́njú ati àdánwò onírurú gbogbo; … [gbígbé] ìrora àti àìsàn àwọn ènìyàn rẹ̀ lé orí ararẹ̀’ (Álmà 7:11; àtẹnumọ́ a`fikún; bákannáà wo Hébérù 4:15–16; 2 Nefi 9:21). Nítorí Ó ní òye gbogbo ìpọ́njú, Ó mọ bí, Òun ó ‘ti wo oníròbìnújẹ́ ọkàn sàn’ (Lúkù 4:18; bákannáà wo Isaiah 49:13–16).”4 Àwọn ìpènijà nígbàkugbà nfi ìnílò fún àwọn àfikún ohun-èlò àti àtìlẹhìn tí kìí ṣe ìwà àbàwọ́n.
Gbà mí láyè láti pín ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àkíyèsí tí mo ti ṣe bí ẹbí mi ti la àwọn ìdánwò kọjá.
Àkọ́kọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn yíò ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú wa; wọn kò ní dá wa lẹ́jọ́. Nítorí ìkọlù ẹ̀rù líle, ìtara, àti ìrẹ̀wẹ̀sì, ọmọkùnrin wa padà sílé láti míṣọ̀n rẹ̀ lẹ́hìn ọ̀sẹ̀ mẹrin péré. Bí àwọn òbí rẹ̀, a rí i pé ó ṣòro láti bá ìjákulẹ̀ àti ìbànújẹ́ jà nítorí a ti gbàdúrà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún àṣeyege rẹ̀. Bíiti gbogbo àwọn òbí, a fẹ́ kí àwọn ọmọ wa ṣe orire kí wọ́n sì ní ìdùnnú. Ìṣẹ́-ìránṣẹ́ yẹ kí ó jẹ́ àmì pàtàkì kan fún ọmọkùnrin wa. Bákannáà à nronú ohun tí àwọn ènìyàn míràn lè rò.
Làìmọ̀ sí wa, ìpadàwá ọmọkùnrin wa jẹ́ bíbànilọ́kànjẹ́ àìlópin fún un. Ṣe àkíyèsí pé òun ní ìfẹ́ Olúwa ó sì fẹ́ láti sìn, àti pé síbẹ̀síbẹ̀ òun kò lè ṣé torí àwọn èrèdí tí òun kò lè làkàkà láti ní òye rẹ̀. Láìpẹ́ ó rí ararẹ̀ ní àmì àìnírètí pátápátá, ní jíjà pẹ̀lú ẹ̀bi jíjinlẹ̀. Òun kò ní ìmọ̀lára ìtẹ́wọ́gbà ṣùgbọ́n ìkúra. Ó di píparun nípasẹ̀ àwọn èrò ikú lemọ́lemọ́.
Nígbàtí a wà ní ipò àìlérò yí, ọmọkùnrin wa gbàgbọ́ pé ìṣe kan tí ó kù ni láti gba ẹ̀mí ara òun. Ó gba Ẹ̀mí Mímọ́ àti ọ̀wọ́ àwọn ángẹ́lì ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìkelè láti gbà á là.
Nígbàtí ó njà fún ayé rẹ̀ àti ní àkokò ìṣòro lílé gidi yí, ẹbí wa, àwọn olórí wọ́ọ̀dù, àwọn ọmọ ìjọ, àti àwọn ọ̀rẹ́ kọjá ipá wọn láti tìwálẹ́hìn àti láti ṣe iṣẹ́-ìránṣẹ́ sí wa.
Èmi kò ní ìmọ̀lára irú ìtújáde ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ rí. Èmi kò ní ọgbọ́n alágbára si àti ní irú ọ̀nà araẹni kan tí ó túmọ̀ sí ìtùnú àwọn tí ó wà nínú àìní ti ìtùnú. Ẹbí wa yíò fi ìmoore hàn títí fún ìtújáde náà.
Èmì kò lè ṣe àpèjúwe àìlónkà àwọn iṣẹ́-ìyanu tí ó bá àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí wá. Pẹ̀lú ìmoore, ọmọkùnrin wa yè, ṣùgbọ́n ó ti gba àkokò pípẹ́ àti ọ̀pọ̀ egbòogi, ìtora, àti ìtọ́jú ti ẹ̀mí fún un láti níwòsàn àti ìtẹ́wọ́gbà pé a ní ìfẹ́, mọ iyi, àti ìnílò rẹ̀.
Mo damọ̀ pé kìí ṣe gbogbo irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ó nparí bíi tiwa. Mo banújẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹnití wọ́n ti pàdánù àwọn olùfẹ́ni ní kùtùkùtù gan àti nísisìyí tí a físílẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀lára ọ̀fọ̀ bákannáà bí àwọn ìbèèrè àìdáhùn.
Àkíyèsí mi tó kan ni pé ó lè ṣòrò fún àwọn òbí láti mọ àwọn ìlàkàkà àwọn ọmọ wọn, ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ kọ́ arawa. Báwo ni a ṣe lè mọ ìyàtọ̀ ní àárín àwọn ìṣòrò tí ó wà pẹ̀lú ìgbèrú déédé àti àwọn àmì àìsàn. Bí àwọn òbí, a ní àṣẹ mímọ́ láti ran àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ láti la àárín ìpènijà ayé já; bákannáà, díẹ̀ lára wa jẹ́ olùtọ́jú-onímọ̀ ìlera ọpọlọ. Àwa bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀ nílò láti ṣètọ́jú fún àwọn ọmọ wa nípa ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti kọ́ láti níjánú pẹ̀lú akitiyan òdodo wọn bí wọ́n ti ntiraka láti bá ìgbèrò déédé pàdé. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wa mọ látinú àìṣedéédé araẹni wa pé ìdàgbà ti-ẹ̀mí ni ètò kan tí ó nlọ lọ́wọ́.
Nísisìyí a ní òye pé “kò sí ìtọ́jú-gbogbo jẹ́jẹ́ kan fún ẹ̀dùn-ọkàn àti lílera ọpọlọ. A ó ní ìrírí wàhálà àti ìrúkèrúdò nítorí à ngbé nínú ayé ìṣubú pẹ̀lú ara ìṣubú. Ní àfikún, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ndásí àwọn ohun tí ó lè darí sí àyẹ̀wò àrùn ọpọlọ. Ní àìkasí ọpọlọ wa àti ẹ̀dùn-ọkàn wíwà-dáadáa, tí ó ndojúkọ ìdàgbà ni ó nílera jù itẹ̀mọ́ nípa àwọn àìṣedéédé wa.”5
Fún ìyàwó mi àti èmi, ohun kan tí ó ti ràn wá lọ́wọ́ láti dúró ni sísúnmọ̀ Olúwa bí ó ti ṣeéṣe. Ní fífihàn, nísisìyí a ri bí Olúwa ti kọ́ wa pẹ̀lú sùúrù nínú àwọn àkokò àìnírètí nlá. Ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ tọ́ wa sọ́nà ní ẹsẹẹsẹ nínú àwọn wákàtì òkùnkùn. Olúwa ràn wá lọ́wọ́ láti ri pé oye ẹ̀mí ẹnìkọ̀ọ̀kan ṣe pàtàkì nínú ètò ayérayé ju iṣẹ́ ayé kankan tàbí àṣeyege.
Lẹ́ẹ̀kansi, kíkọ́ arawa nípa àrùn ọpọlọ múra wa sílẹ̀ láti ran arawa àti àwọn míràn lọ́wọ́ tí wọ́n lè máa làkàkà. Ìbárasọ̀rọ̀ kedere àti òdodo pẹ̀lú arawa yíò ran àkọlé pàtàkì yí lọ́wọ́ láti gba ìfetísílẹ̀ tí ó gbà. Lẹ́hìn gbogbo rẹ̀, àlàyé ṣíwájú ìmísí àti ìfihàn. Àwọn ìpènijà àìrí léraléra-ìgbà-gbogbo lè dàmú ẹnikẹ́ni, àti pé nígbàtí a bá kojú wọn, wọn hàn bí àìlèyanjú.
Ọ̀kan lára ohun àkọ́kọ́ tí a nílò láti kọ́ ni pé dájúdájú a kò dá wà. Mo pè yín láti ṣe àṣàrò àkọlé ìlera ọpọlọ ní abala Ìrànlọ́wọ́ Ìyè ti áàpù Ibi-ìkowepamọ́ Ìhìnrere. Kíkọ̀-ẹ̀kọ́ yíò darí sí níní-òye síi, ìtẹ́wọ́gbà síi, àánú síi, ìfẹ́ síi. Ó lè dín àjálù kù nígbàtí wọ́n bá nrànwálọ́wọ́ láti gbèrú àti láti ṣe àwọn ìgbèrò ìlera àti ìbaraṣe ìlera.
Àkíyèsí mi tó kẹ́hìn: a nílò láti ṣe ìṣọ́ lemọ́lemọ́ lórí arawa. A gbọ́dọ̀ ní ìfẹ́ arawa kí a sì dín dídájọ́ kù—pàtàkì nígbàtí a kò bá bá àwọn ìgbèrò wa pàdé. A gbọ́dọ̀ ran àwọn ọmọdé àti ọ̀dọ́ wa lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Jésù Krístì nínú ayé wọn, àní nígbàtí wọ́n bá nlàkàkà láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ ti-araẹni fún arawọn. Alàgbà Orson F. Whitney, ẹnití ó sìn bí ọmọ Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá, gba àwọn òbí wa lámọ̀ràn bí wọn ó ti ran àwọn irú-ọmọ wọn tí wọ́n nlàkàkà lọ́wọ́: “Ẹ gbàdúrà fún àwọn ọmọ yín … kí ẹ sì dì wọ́n mú pẹ̀ly´ ìgbàgbọ́ yín.”6
Mo ti máa nronú léraléra ohun tí ó túmọ̀ sí láti dì wọ́n mú pẹ̀lú ìgbàgbọ́. Mo gbàgbọ́ pé ó pẹ̀lú àwọn ìṣe ìfẹ́ tí ó rọrùn, ìwàtútù, ìwàrere, àti ọ̀wọ̀. Ó túmọ̀sí fífi àyè gbà wọ́n láti gbèrú ní ìṣísẹ̀ arawọn àti jíjẹ́ ẹ̀rí láti rànwọ́nlọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ ìfẹ́ Olùgbàlà. Ó gbà kí a ronú nípa wọn síi àti ní dídínkù nípa arawa tàbí àwọn míràn. Èyí túmọ̀ sí dídínkù ní sísọ̀rọ̀ àti fífetísílẹ̀ púpọ̀, púpọ̀ síi. A gbọ́dọ̀ ní ifẹ́ wọn, ró wọn lágbára, kí a sì yìn wọ́n léraléra nínú àwọn ìgbìyànjú wọn sí yíyege àti jíjẹ́ olotitọ́ sí Ọlọ́run. Àti ní òpin, a gbọ́dọ̀ ṣe ohun gbogbo ní agbára wa láti dúró ní sísúnmọ́ wọn—bí a ti dúró ní sísúnmọ́ Ọlọ́run.
Fún gbogbo ẹnití wọ́n ní ìdàmú ti-araẹni nípa àrùn ọpọlọ, ẹ di ìgbàgbọ́ yín mú, àní bí ẹ kò bá lè ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run ní àkokò yí. Ṣe ohunkóhun tí ó wà nínú agbára rẹ àti nígbànáà “ṣì dúró jẹ́ … láti rí ìgbàlà Ọlọ́run, àti láti ṣe ìfihàn apá rẹ̀.”7
Mo jẹ́ri pé Jésù Krístì ni Olùgbàlà wa. Ó mọ̀ wá. Ó ní ifẹ́ wa, Òun yíò sì dúró fún wa. Ní ìgbà ìdánwò ẹbí wa, mo ti mọ̀ bí Òun ṣe súnmọ́ tó. Àwọn ìlérí Rẹ jẹ́ òtítọ́:
Máṣe bẹ̀rù, èmí wà pẹ̀lú yín; áà ẹ máṣe fòyà,
Nítorí èmi ni Ọlọ́run yín èmi ó ṣì fún yín ní ìrànlọ́wọ́.
Èmi ó fún yín lókun, ràn yín lọ́wọ́, àti mú yín dúró, …
Dì yín mú nínú òdodo, ọwọ́ agbára rẹ̀.
Mímọ̀ bí ìpìlẹ̀ ṣe dúrú gbọingbọin ni, kí a lè fi tayọ̀tayọ̀ kéde:
Ọkàn náà lórí jésù tí ó tẹríba fún ìsinmi
Èmi kò ní, èmi kò lè, fi silẹ̀ fún àwọn ọ̀tá rẹ̀;
Ọkàn náà, bí gbogbo ọ̀run-àpáàdì tilẹ̀ wá rìrì, …
Emi kò ní paátì láéláé, rárá láéláé, rárá láéláé!8
Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.