Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ẹ̀kọ́ ti Jíjẹ́ Ara Kannáà
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa 2022


Ẹ̀kọ́ ti Jíjẹ́ Ara Kannáà

Ẹ̀kọ́ wíwàpẹ̀lú nwá sílẹ̀ sí èyí fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa: Èmi jẹ́ ọ̀kan pẹ̀lú Krístì nínú májẹ̀mú ìhìnrere.

Èmi yíò fẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa ohun tí mo pè ní ẹ̀kọ́ ti jíjẹ́ ara kannáà nínú Ìjọ Jésù Krístì ti awọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Ẹ̀kọ́ yí ní apá mẹ́ta: (1) ojúṣe ti wíwàpẹ̀lú nínú kíkórajọ ti àwọn ènìyàn májẹ̀mú Olúwa, (2) pàtàkì ti iṣẹ́ ìsìn àti ìrúbọ ní wíwàpẹ̀lú, àti (3) gbùngbun ti Jésù Krístì láti wàpẹ̀lú.

Ìjọ Jésù Krístì ti awọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ní ìbẹ̀rẹ̀ kùtùkùtù ni ó wọ́pọ̀ ní Àríwá àwọn aláwọ̀ funfun America àti àwọn Ènìyàn mímọ́ Àríwá European pẹ̀lú àwọn ìbátan díẹ̀ ti àwọn Àbínibí America, àwọn Áfríkà America, àti àwọn Pacific Islander. Nísisìyí, ọdún mẹ́jọ sẹ́hìn kúrò ní igba ọdún ìdásílẹ̀ rẹ̀, Ìjọ ti pọ̀ si lọ́pọ̀lọpọ̀ ní iye àti ní ẹ̀yà nínú Àríwá Amẹrika àní àti púpọ̀ ní ìyókù àgbáyé.

Bí àsọtẹ́lẹ̀ tipẹ́tipẹ́ ti ìkójọpọ̀ awọn ènìyàn májẹ̀mú Olúwa ní ọjọ́-ìkẹhìn ṣe njèrè ìyára sí, Ìjọ yíò ní àwọn ọmọ ìjọ láti gbogbo orílè-èdè, ìbátan, èdè, àti ènìyàn nínú nítòótọ́.1 Èyí kìí ṣe ìtànká tí a ti rò tẹ́lẹ̀ tàbí tí a fi ipá mú ṣùgbọ́n ohun àdánidá kan tí ó nṣẹlẹ̀ tí a yíò retí, ní dídamọ̀ pé àwọ̀n ìhìnrere nkójọ láti gbogbo orílẹ̀-èdè àti gbogbo ènìyàn.

A ti jẹ́ alábùkún fún tó láti rí ọjọ́ náà tí a ngbé Síónì kalẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ní gbogbo ibi àti ní àwọn àdúgbò ti arawa. Bí Ààrẹ Joseph Smith ti wí, àwọn ènìyàn Ọlọ́run ní gbogbo ọjọ́ orí ti nwo iwájú pẹ̀lú ìrètí ayọ̀ di ọjọ́ yí, a sì “jẹ́ ẹni àánú tí Ọlọ́run ti yàn láti mú ògo Ọjọ́-ìkẹhìn jáde.”2

A fún wa ní ànfàní yí, a kò lè fi ààyè gba ìran kankan, ẹ̀lẹ́yàmẹ̀yà, tàbí àwọn ìpìnyà míràn láti wà nínú Ìjọ Krístì ọjọ́-ìkẹhìn. Jésù pàṣẹ fún wa, “Ẹ jẹ́ ọ̀kan; tí ẹ kò bá jẹ́ ọ̀kan ẹ kìí ṣe tèmi.”3 A gbọ́dọ̀ ní ìtara ní fífà ẹ̀tanú àti ojúsájú tu kúrò ní Ìjọ, kúrò nínú àwọn ilé wa, àti ju gbogbo rẹ̀ lọ kúrò nínú ọkàn wa. Bí oríṣiríṣi ìkani Ìjọ wa ṣe ndàgbà si títíláé, ìkíni káàbọ̀ wa gbọ́dọ̀ dàgbà púpọ̀ si lọ́gán àti ní ìyárí títíláé. A nílò ara wa.4

Nínú ìwàásù àkọ́kọ́ rẹ̀ sí àwọn Ará Kọ́ríntì: Páùlù kéde pé gbogbo ẹni tí ó bá ṣe ìrìbọmi sínú Ìjọ jẹ́ ọ̀kan nínú ara Krístì.

“Nítorí gẹ́gẹ́ bí ara ti jẹ́ ọ̀kan, tí ó sì ní ẹ̀yà púpọ̀, ṣùgbọ́n tí gbogbo ẹ̀yà tí íṣe púpọ̀ jẹ́ ara kan: bẹ́ẹ̀ sì ni Krístì pẹ̀lú.

“Nítòrípé nípa Ẹ̀mí kan ni a ti baptisi gbogbo wa sínú ara kan, ìbá ṣe júù, tàbí Kèfèrí, ìbá ṣe ẹ̀rú tàbí òmìnira; a sì ti mú gbogbo wa mu sínú Ẹ̀mí kan. …

“… Kí ìyapa kí ó máṣe sí nínú ara; ṣùgbọ́n kí àwọn ẹ̀yà ara kí ó má ṣe ìtọ́jú kannáà fún ara wọn.

“Bí ẹ̀yà kan bá sì njìyà, gbogbo ẹ̀yà a sì jùmọ̀ báa jìyà; tàbí bí a bá nbọlá fún ẹ̀yà kan, gbogbo ẹ̀yà á jùmọ̀ báa yọ̀.”5

Ọgbọ́n ti jíjẹ́ ara kannáà ṣe pàtàkì sí àláfíà ti ara, ti ọpọlọ, àti ti ẹ̀mí wà. Síbẹ̀síbẹ̀, ó ṣeéṣe pé ní ìgbà míràn ẹnìkọ̀ọ̀kan wa lè rò pé a kò wà ní ìbámu. Ní àwọn àkokò ìrẹ̀wẹ̀sì, a lè rò wípé a kò ní kájú òṣùwọ̀n láé sí ipò gíga Olúwa tàbí ìrètí àwọn ẹlòmíràn.6 A lè fi àìmọ̀kan gbé ìrètí lé orí àwọn ẹlòmíràn, àní tàbí arawa, tí kìí ṣe ìrètí Olúwa. A lè sọ̀rọ̀ ní ọ̀nà jẹ́jẹ́ pé bí ẹ̀mí kan ṣe níyelórí sí dá lórí àwọn àṣeyọri tàbí ìpè kan, ṣùgbọ́n ìwọ̀nyí kìí ṣe òṣùwọ̀n ti dídúró wa ní ojú Olúwa. “Olúwa nwo ọkàn.”7 Ó ní ìbojútó nípa ìfẹ́ wa àti ìpòngbẹ àti ohun tí à ndà.8

Arábìnrin Jodi King kọ̀wé nípa ìrírí ti ara rẹ̀ nì àwọn ọdún sẹ́hìn:

“Èmi kò nímọ̀lára bí ẹnipé èmi kò jẹ́ ara kannáà ní ìjọ títí tí ọkọ mi, Cameron, àti èmi fi bẹ̀rẹ̀ ìlàkàkà pẹ̀lú àìrọ́mọbí. Àwọn ọmọ àti ẹbí tí wọ́n ti mú ayọ̀ wá fún mi gan láti rí ní ìjọ nísisìyí bẹ̀rẹ̀ sí fa ìbànújẹ́ àti ìrora fún mi.

“Mo nímọ̀lára jíjẹ́ àgàn láìsí ọmọ kan ní apá mi tàbí àpò itẹdi ní ọwọ́. …

“… Ọjọ́ Ìsinmi líle júlọ ni àkọ́kọ́ ní wọ́ọ̀dù wa titun. Nítorí a kò ní àwọn ọmọ, wọ́n bèèrè lọ́wọ́ wá bóyá a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìgbeyàwó àti ìgbà tí gbèrò bíbẹ̀rẹ̀ ẹbí kan. Mo ti di dídára si nì dídáhùn àwọn ìbèèrè wọ̀nyí láìjẹ́ kí wọ́n pa mí lára—mo mọ̀ pé wọn kò ní láti mú mi bínú.

“Ṣùgbọ́n, ní ọjọ́ Ìsinmi yí, dídáhùn àwọn ìbèèrè wọnnì jẹ́ líle nípàtàkì. A ṣẹ̀ṣẹ̀ ri pé, lẹ́hìn níní ìrètí, pé—síbẹ̀ lẹ́ẹ̀kansi a—kò lóyún.

“Mo rìn lọ sínú ìpàdé oúnjẹ Olúwa nínú ìmọ̀làra ìrẹ̀wẹ̀sì, àti pé dídáhùn àwọn ìbèèrè ‘jẹ́kí nmọ̀ ọ́’ wọnnì jẹ́ líle fún mi.

“Ṣùgbọ́n Ilé Ẹ̀kọ́ Ọjọ́ Ìsinmi ni ó mú ìbànújẹ́ bá ọkàn mi nítoọ́tọ́. Ẹ̀kọ́ náà—ní èrò láti jẹ́ nípa ojúṣe àtọ̀runwá àwọn ìyá—kíákíà ó ṣí kúrò ó sì di abala [ìbínú]. Ọkàn mi wọlẹ̀ omijé sì bẹ̀rẹ̀sí nṣàn jẹ́jẹ́ sí ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi bí mo ti gbọ́ tí àwọn obìnrin nráùn nípa ìbùkún tí èmi yíò fúnni ní ohunkóhun fún.

“Mo kọ fìrí kúrò nínú ìjọ. Ní àkọ́kọ́, èmi kò fẹ́ padà lọ. Èmi kò fẹ́ ní ìrírí irú ìmọ̀lára ìpatì lẹ́ẹ̀kansi. Ṣùgbọ́n ní alẹ́ náà, lẹ́hìn sísọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọkọ mi, a mọ̀ pé a yíò tẹramọ́ lílọ sí ìjọ kìí ṣe nítorípé Olúwa ti ní kí a lọ nìkan ṣùgbọ́n bákannáà nítorípé àwa méjèèjì mọ̀ pé ayọ̀ tí ó nwá látinú títún májẹ̀mú ṣe àti níní ìmọ̀lára Ẹ̀mí nínú ìjọ kọjá ìbànújẹ́ tí mo mọ̀ lára ní ọjọ́ náà.

“Nínú ìjọ, àwọn opó, olùkọ̀sílẹ̀, àti àwọn ọmọ ìjọ dídánìkanwà wà; àwọn tí wọ́n wà pẹ̀lú ọmọ ẹbí tí wọ́n ti ṣubú kúrò nínú ihìnrere; àwọn ènìyàn pẹ̀lú àwọn àìsàn líle tàbí ìlàkàkà ìṣúná; àwọn ọmọ ìjọ tí wọ́n ní ìrírí ònfà irú-ẹ̀yà kannáà; àwọn ọmọ ìjọ tí wọ́n nṣiṣẹ́ láti borí ìwà bárakú tàbí iyèméjì, àwọn olùyípadà àìpẹ́; àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kó wá; àwọn tí kò níbùgbé, àti pé itòsílẹ̀ náà lọ síwájú àti síwájú si.

“Olùgbàlà pè wá láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀—bí ó ti wù kí àwọn ipò wa jẹ́. A wá sí ìjọ láti tún àwọn májẹ̀mú wa ṣe, láti mú ìgbàgbọ́ wa pọ̀ si, láti rí àlàáfíà, àti láti ṣe bí Òun ti ṣe ní pípé nínú ayé Rẹ̀—ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n nímọ̀lára pé àwọn kò jẹ́ ara kannáà”8

Páùlù ṣe àlàyé pé Ìjọ àti àwọn olóyè rẹ̀ ni a fifúnni láti ọwọ́ Ọlọ́run “fún àṣepé àwọn ènìyàn mímọ́, fún iṣẹ́ ìránṣẹ́, fún ìmúdàgbà ara Krístì:

“Títí gbogbo wa yíò wá nínú ìṣọ̀kan ìgbàgbọ́, àti ti ìmọ̀ Ọmọ Ọlọ́run, sí ènìyàn pípé, sí ìwọ̀n ìnàsókè ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Krístì.”9

Nígbànáà, ó jẹ́ àpárá ìbànújẹ́ kan, nígbàtí ẹnìkan, bá ní ìmọ̀lára pé òun lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin kò bá àpẹrẹ dídára pàdé ní gbogbo àwọn abala ìgbé ayé, tí ó parí rẹ̀ pé wọn kò jẹ́ ara kannáà nínú ìṣètò gan tí a ṣe láti ọwọ́ Ọlọ́run láti rànwálọ́wọ́ tẹ̀síwájú sí ìhà àpẹrẹ dídára náà.

Ẹ jẹ́ kí a fi ìdájọ́ sí ọwọ́ Olúwa àti àwọn wọnnì tí Ó ti yàn kí a sì ní ìtẹ́lọ́run láti fẹ́ràn àti láti tọ́jú ara wa ní ọ̀nà tí a lè ṣe. Ẹ jẹ́ kí a bèèrè lọ́wọ́ Rẹ̀ láti fi ọ̀nà hàn wá, ní ojojúmọ́, láti “mú … àwọn tálákà, àti àwọn alábùkù ara, àti àwọn amúkũn, àti àwọn afọ́jú”11—èyí ni, gbogbo ènìyàn—tó wá sí àpèjẹ nlá Olúwa.

Ojú Kejì ẹ̀kọ́ ti jíjẹ́ ara kannáà ní íṣe pẹ̀lú àwọn ìdásí ti ara wa. Bi ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣọ̀wọ́n kí a tó ronú nípa rẹ̀, púpọ̀ ju ti jíjẹ́ ara kannáà wa nwá láti inú iṣẹ́-ìsìn àti ìrúbọ tí à nṣe fún àwọn ẹlòmíràn àti fún Olúwa. Ìfojúsùn púpọ̀jù lórí àwọn àìní araẹni wa tàbí ìtura wa lè já ọgbọ́n jíjẹ́ ara kannáà wa kulẹ̀.

A ntiraka láti tẹ̀lé ẹ̀kọ́ ti Olùgbàlà:

“Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ di nlá ní àárín yín, òun ni yíò ṣe ìránṣẹ́ yín. …

“Nítorí Ọmọ-ènìyàn tìkararẹ̀ kò ti wà kí a ba máa ṣe ìránṣẹ́ fún, bíkòṣe láti máa ṣe ìránṣẹ́ fúnni, àti láti fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.”12

Jíjẹ́ ara kannáà kìí wá bí a ti ndúró fún un ṣùgbọ́n bí a ti nnawọ́ jáde láti ran ara wa lọ́wọ́.

Ní òní, láìríre, yíya araẹni sọ́tọ̀ sí iṣẹ́ kan tàbí rírúbọ ohunkóhun fún ẹnikẹ́ni míràn ti nda àtakò-àṣà. Nínú ọ̀rọ̀ kan fún Ìròhìn Deseretní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yí, onkọ̀wé Rod Dreher ṣe àtúnṣọ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ kan pẹ̀lú ọ̀dọ́ ìyá kan ní Budapest:

“Mo wà lórí trámù Budapest pẹ̀lú … ọ̀rẹ́ kan ní tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ lé ní ọgbọ̀n ọdún—ẹ jẹ́ kí a pè é ní Kristina—nígbàtí a wà ní ọ̀nà láti ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún àgbàlàgbà obìnrin [Krìstẹ́nì] kan ẹnití, pẹ̀lú olóògbé ọkọ rẹ̀, ó farada inúnibíni láti ọwọ́ ípínlẹ̀ ẹgbẹ́ ìlú kan. Bí a ti nní ìkọlù lẹgbẹ òpópónà ìlú-nlá, Kristina sọ̀rọ̀ nípa bí ó ti le tó láti jẹ́ olotitọ pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ ọjọ́ orí rẹ̀ nípa ìtiraka tí òun dojúkọ bí ìyàwó àti ìyá àwọn ọ̀dọ́mọdé.

“Ìṣòro Kristina jẹ́ wíwọ́pọ̀ pátápátá fún ọ̀dọ́mọbìnrin kan ó nkọ́ bí yíò ti jẹ́ ìyá àti ìyàwó kan—síbẹ̀ ìwà tí ó gbòdekan ní àárín ìran rẹ̀ ni pé àwọn ìṣòro ìgbé ayé jẹ́ ìdẹ́rùbà sí àláfíà ẹni tí a sì níláti kọ̀. Njẹ òun àti ọkọ rẹ̀ njiyàn nígbàmíràn? Nígbànáà ó níláti fi í sílẹ̀, ni wọ́n wí. Njẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ nbíi nínú? Nígbànáà ó níláti rán wọn lọ sí ilé ìtọ́jú ojúmọ́.

“Kristina dàmú pé àwọn ọ̀rẹ́ òun kò gba pé àwọn àdánwó náà, àní àti ìjìyà, jẹ́ apákan dídára ti ìgbé ayé —àti àní bóyá apákan ìgbé ayé rere, bí jíjìyà náà bá kọ́ wa bí a ó ti ní sùúrù, inúrere àti ìfẹ́ni. …

“… Unifásiti ti Notre Dame olùkẹ́gbẹ́ ti ẹ̀sìn Christian Smith ríi nínú ẹ̀kọ́ àwọn àgbàlagbà [àwọn ọjọ́ orí] méjìdínlógún sí mẹ́tàlélógún pé púpọ̀jùlọ lára wọn gbàgbọ́ pé àwùjọ kìí ṣe ohun kankan ju gbígbá ‘kíkójọ àdáṣe olúkúlùkù jáde láti gbádùn ayé.’12

Nípa ìmọ̀ ẹ̀kọ́ yí, ohunkóhun tí a bá rí pé ó ṣòro ‘jẹ́ ìrísí ìrẹ́jẹ.’”13

Ní ìlòdì, àwọn aṣíwájú olùlànà wa gba ọgbọ́n jíjìn ti jíjẹ́ ara kannáà, ìrẹ́pọ̀, àti ìrètí nínú Krístì nípa àwọn ìrúbọ tí wọ́n ṣe láti sin ní míṣọ̀n, kọ́ àwọn tẹ́mpìlì, pa àwọn ilé títura wọn ti lábẹ́ ìnira wọ́n ó sì bẹ̀rẹ̀ lẹ́ẹ̀kansi, àti ní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọ̀nà míràn wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ àti ọ̀nà wọn sí èrò Síónì. Àní wọ́n nfẹ́ láti fi ayé wọn rúbọ tí ó bá ṣeéṣe. Gbogbo wa ni a jẹ alánfààní ti ìforítì wọn. Ọ̀kannáà jẹ́ otítọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní òní tí wọ́n lè sọ ìbáṣepọ̀ ẹbí àti àwọn ọ̀rẹ́ nù, pádánù àwọn ànfàní iṣẹ́, tàbí bákannáà jìyà ẹlẹ́yàmẹ̀yà tàbí ìlòkulò bí àbájáde ti ṣíṣe ìrìbọmi. Èrè wọn, bákannáà, ni ọgbọ́n alágbára ti jíjẹ́ ara kannáà ní àárín àwọn ènìyàn májẹ̀mú. Èyíkéyí ìrúbọ tí a bá ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa nràn wá lọ́wọ́ làti fi ẹsẹ̀ ipò wa múlẹ̀ pẹ̀lú Rẹ̀ ẹnití Ó fi ẹ̀mí Rẹ̀ ṣe ìràpadà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀.

Ohun-èlò pàtàkì jùlọ àti òpin ẹ̀kọ́ ti jíjẹ́ ara kannáà jẹ́ gbùngbun ojúṣe Jésù Krístì. A kò darapọ̀ mọ́ Ìjọ fún jíjọ́sìn nìkan, bí èyí ti jẹ́ pàtàkì tó. A darapọ̀ fún ìràpadà nípasẹ̀ ìfẹ́ àti oore-ọ̀fẹ́ Jésù Krístì. A darapọ̀ láti mú àwọn ìlànà ìgbàlà àti ìgbéga dúró fún arawa àti àwọn tí a fẹ́ràn ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ìkelè. A darapọ̀ láti kópa nínú iṣẹ́ nlá ti gbígbé Síónì kalẹ̀ ní mímúrasílẹ̀ fún ìpadàbọ̀ Olúwa.

Ìjọ ni olùpamọ́ àwọn májẹ̀mú ìgbàlà àti ìgbéga tí Ọlọ́run fúnni nípasẹ̀ àwọn ìlànà oyè-àlùfáà mímọ́.14 Nípa pípa àwọn májẹ̀mú wọ̀nyí mọ́ ni a ngbà ọgbọ́n gígajùlọ àti jíjìnlẹ̀ jùlọ ti jíjẹ́ ara kannáà. Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni:

Níwọ̀n bí ẹ̀yin àti èmi ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run, ìbáṣepọ̀ wa pẹ́lú Rẹ̀ di sísúnmọ́ síi ju ìṣaájú májẹ̀mú wa lọ. Nísisìyí a jẹ́ síso papọ̀. Nítorí májẹ̀mú wa pẹ̀lú Ọlọ́run, òun kò ní ṣàárẹ̀ láé nínú àwọn ìtiraka Rẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́, a kò sì ní tán sùúrù tó kún fún àánú Rẹ̀ pẹ̀lú wa láé. Ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ní ibi pàtàkì kan nínú ọkàn Ọlọ́run. …

“… Jesus Christ is the guarantor of those covenants (see Hebrews 7:22; 8:6).”16

Bí a bá rántí èyí, ìrètí gíga Olúwa fún wa yíò mísí wa, kò ní mú wa, rẹ̀wẹ̀sì.

A lè nímọ̀lára ayọ̀ bí a bá lépa, níkọ̀ọ̀kan àti lápapọ̀, “òṣùwọ̀n ìnàsókè ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ Krístì.”16 Láìka àwọn ìjákulẹ̀ àti ìfàsẹ́hìn ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà, ó jẹ́ ìwákiri ọlọ́lá. À ngbéga a sì ngba ara wa níyànjú ní lílépa ipa ọ̀nà iwájú, ní mímọ̀ pé bí ó tiwù kí ìpọ́njú àti bí ó ti wù kí ìfàsẹ́hìn tó nínú àwọn ìbùkún tí a ti ṣèlérí, a lè “tújúká; [nítorí Krístì ti] borí ayé,”17 àwa sì wà pẹ̀lú Rẹ̀. Jíjẹ́ ọ̀kan pẹ̀lú Baba, Ọmọ, àti Ẹ̀mí Mímọ́ ni àìsí iyèméjì ìgbẹ̀hìn ti wíwàpẹ̀lú.19

Bayi, ẹ̀kọ́ ti jíjẹ́ ara kannáà padà di èyí, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa lè fi múlẹ̀ pé: Jésù Krístì kú fún mi; Ó rò mí sí yíyẹ fún ẹ̀jẹ̀ Rẹ̀. Ó nifẹ mi ó sì lè mú gbogbo ìyàtọ̀ wá nínú ìgbé ayé mi; oore ọ̀fẹ́ Rẹ̀ yíò yí mi padà. Bí mo ti nronúpìwàdà, oore ọ̀fẹ́ Rẹ̀ yíò yí mi padà. Mo jẹ́ ọ̀kan pẹ̀lú Rẹ̀ nínú májẹ̀mú ìhìnrere; mo jẹ́ ara kannáà nínú Ìjọ àti ìjọba Rẹ̀; mo sì jẹ́ ara kannáà nínú èrò Rẹ̀ láti mú ìràpadà wá fún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run.

Mo jẹ́rí pé ẹ wàpẹ̀lú, ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Wo Ìfihàn 5:9; bákannáà wo 1 Nefi 19:17; Mosiah 15:28; Doctrine and Covenants 10:51; 77:8, 11.

  2. Teachings of Presidents of the Church: Joseph Smith (2007), 186.

  3. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 38:27.

  4. Olùfiyèsí ọlọ́gbọ́n ìmọ̀ ti kíyèsi pé:

    “Ẹ̀sìn tí ó kàn jẹ́ ọ̀ràn ìkọ̀kọ̀ ti jẹ́, títí di àkókò tiwa, tí a kò mọ̀ ní aráyé—àti fún èrèdí rere. Irú ẹ̀sìn bẹ́ẹ̀ nkúrò kíákíá sínú ìgbádùn inú ilé, irú ààyò ọ̀kan tàbí púpọ̀si olúkúlùkù, bíi kíka ìwé kan tàbi wíwo amọ́hùnmáwòrán. Nítorínáà, kìí ṣe ìyanilẹ́nu pé ìwákiri fún ti ẹ̀mí ti di ológe bẹ́ẹ̀. Ó jẹ́ ohun tí olúkúlùkù, yà kúrò nínú ẹ̀sìn, ní ìtara wíwá ìrọ́pò.

    “Níní ẹ̀mí nitoọtọ jẹ́ pàtàkì ara gbogbo ẹ̀sìn—ṣùgbọ́n díẹ̀ ara, kò sì lè jẹ́ ìrọ́pò fún gbogbo rẹ̀. Ẹ̀sìn kìí ṣe irú ẹ̀yà ìdárayá tí ó nfi ìgbàmíràn fúnni ní ìrírí tó tayọ. Ó lè tún igbé ayé ẹnìkan ṣe—gbogbo ayé enìkan—tàbí kó sọnù, kí ó fi ìtara, àwọn ẹ̀mí òfìfo sílẹ̀, tí kò sì atora tí ó lè débẹ̀. Fún ẹ̀sìn láti tún ìgbé ayé ẹnìkan ṣe, ó nílò láti jẹ́ ìwọpọ̀ àti gbangba; ó níláti sopọ̀ sí òkú àti àìbí” (Irving Kristol, “The Welfare State’s Spiritual Crisis,” The Wall Street JournalFeb. 3, 1997).

  5. 1 Corinthians 12:12–13, 25–26.

  6. Wo Russell M. Nelson, “Perfection Pending,” Ensign, Nov. 1995, 86–88; Jeffrey R. Holland, “Be Ye Therefore Perfect—Eventually,” Liahona, Nov. 2017, 40–42.

  7. 1 Sámúẹ́lì 16:7.

  8. As expressed by Elder Jeffrey R. Holland, “‘Come as you are,’ a loving Father says to each of us, but He adds, ‘Don’t plan to stay as you are.’ We smile and remember that God is determined to make of us more than we thought we could be” (“Songs Sung and Unsung,” Liahona, May 2017, 51).

  9. Jodi King, “Wíwàpẹ̀lú nínú Ìjọ nípasẹ̀ Jígí Àìrọ́mọbí,” Liahona, Mar. 2020, 46, 48–49.

  10. Efesu 4:12-13.

  11. Lúkù 14:21.

  12. Markù 10:43, 45; àfikùn àtẹnumọ́.

  13. Rod Dreher, “A Christian Survival Guide for a Secular Age,” Deseret Magazine, Apr. 2011, 68.

  14. Dreher, “A Christian Survival Guide for a Secular Age,” 68.

  15. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 84:19–22.

  16. Russell M. Nelson, “Májẹ̀mú Àìlópin,” Liahona, Oct. 2022, 6, 10.

  17. Éfésù 4:13

  18. Jòhánnù 16:33

  19. Wo Jòhánù 17:20–23. “Áti nísisìyí, èmi yíò gbà yín níyànjú láti wá Jésù yĩ kiri nípa ẹniti àwọn wòlĩ àti àwọn àpóstélì ti kọ, pé kí õre ọ̀fẹ́ Ọlọ́run Baba, àti pẹ̀lú Jésù Krístì Olúwa, àti Ẹ̀mí Mímọ́, ẹniti ó njẹ́rĩ sí wọn, ó wà, kí ó sì máa gbé nínú yín títí láé” (Ether 12:41).

Tẹ̀