Ẹ Ṣẹ́gun Ayé kí ẹ sì Wá Ìsinmi
Ẹ wá ìsinmi látinú àìní-ìdánilójú, líle, àti ìrora ayé yí nípa ṣíṣẹ́gun ayé nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú yín pẹ̀lú Ọlọ́run.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, mo moore láti kíi yín ní Ọjọ́ Ìsinmi ológo yí. Ẹ̀ nwà ní ọkàn mi nígbàgbogbo. O yàmílẹ́nu ní ọ̀nà tí ẹ fi ndìde nínú ìṣe nígbàkugbà tí ẹ bá rí àwọn míràn nínú àìní. Mo dúró nínú ìyanu ní ìgbàgbọ́ àti ẹ̀rí tí ẹ̀ njúwe lẹ́ẹ̀kàn àti lẹ́ẹ̀kansi. Mo sọkun lórí àwọn ìrora ọkàn, ìjákulẹ̀, àti ìdàámú yín. Mo nifẹ yín. Mo mu dáa yín lójú pé Baba Ọ̀run àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì nifẹ yín. Wọ́n ní ìfura àwọn ipò yín, inúrere yín, àìní yín, àti àdúrà yín fún ìrànlọ́wọ́ tinútinú. Lẹ́ẹ̀kan àti lẹ́ẹ̀kansi, mo gbàdúrà fún yín láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Wọn fún yín.
Níní ìrírí Wọn ṣe kókó, bí ó ti dàbí ẹnipé à ndáwálọ́nà lójojúmọ́ nípa àwọn ìsunkúnsínú ìròhìn ìkọlù. Ẹ lè ti ní àwọn ọjọ́ nígbàtí ẹ nfẹ́ kí ẹ lè wọ aṣọ ìwọ̀sùn yín, kí ẹ bora nínú bọ́ọ̀lù kan, kí a sì ní kí ẹnìkan jíi yín nígbàtí gbogbo ìrúkèrúdò bá ti tán.
Ṣùgbọ́n, ẹ̀yin arákùnrin àti aràbìnrin mi ọ̀wọ́n, àwọn ohun ìyanu púpọ̀ gan an wà níwájú. Ní àwọn ọjọ́ tí ó nbọ̀, a ó rí àwọn ìfihanni títóbijùlọ nípa agbára Olùgbàlà tí ayé kò rí rí. Ní àárín ìsisìyí àti àkokò tí ó màa padàbọ̀ “pẹ̀lú agbára àti ògo nlá,”1 Òun yíò fi àwọn ànfàní, ìbùkún, àti iṣẹ́ ìyanu àìlónkà lé orí awọn olódodo.
Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, lọ́wọ́lọ́wọ́ à ngbé nínú ohun tí ó jẹ́ àkokò tí ó le jùlọ dájúdájú nínú àkọọ́lẹ̀-ìtàn ayé. Àwọn ìṣòro àti ìpènijà nfi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn sílẹ̀ ní níní ìmọ̀lára ìbonimọ́lẹ̀ àti àárẹ̀. Bákannáà, ẹ ro ìrírí àìpẹ́ tí ó lè ti fi ìmọ́lẹ̀ hàn lórí bí ẹ̀yin àti ẹ̀mi fi lè rí ìsìnmi.
Ní ìgbà ṣíṣí ilé àìpẹ́ ti Tẹ́mpìlì Washington D.C., ọmọ ẹgbẹ́ ilé ṣiṣí jẹri ìwòye ìyípadà bí ó ti tẹ̀lé onírurú àwọn gbajúmọ̀ aròhìn kiri nínú tẹ́mpìlì. Bẹ́ẹ̀náà ẹbí ọ̀dọ́ kan di títamọ́ nínú àrìnká ìròhìn yí. Olùròhìn kan tẹramọ́ bíbèèrè nípa “ìrìnàjò” ti aláàbò tẹ́mpìlì bí ọkùnrin tàbí obìnrin ṣe nrìn nínú tẹ́mpìlì. Ó nfẹ́ láti mọ̀ bí ìrìnàjò tẹ́mpìlì ṣe jẹ́ alápẹrẹ àwọn ìpènijà nínú ìrìnàjò ẹnìkan nínú ayé.
Ọ̀dọ́mọdékùnrin kan nínú ẹbí bẹ̀rẹ̀ lórí ìbáraẹnisọ̀rọ̀ náà. Ní ìgbàtí ẹgbẹ́ àrìnrìnká wọnú yàrá ẹ̀bùn tẹ́mpìlì, tí ó sì wípé, “Ah, ìyẹn dára. Nihin ni ibìkan fún àwọn ènìyàn láti sinmi lórí ìnìnàjò tẹ́mpìlì.”
Mo ṣiyèméjì pé ọ̀dọ́mọdékùnrin náà mọ bí àkíyèsí rẹ̀ ti jinlẹ̀ tó. Kò jọ pé ó ní èrò nípa ìsopọ̀ tààrà ní àárìn dídá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run nínú tẹ́mpìlì àti ìlérí yíyanilẹ́nu Olùgbàlà.
“Ẹ wa sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ó ńṣiṣẹ́, tí a sì di ẹrù wúwo lé lórí, èmi yíò sì fi ìsinmi fún yín.
“Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì máa kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi; … ẹ̀yin ó sì rí ìsinmi fún ọkàn yín
“Nítorí àjàgà mi rọrùn, ẹrù mi sì fúyẹ́.”2
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, mo kẹ́dùn fún àwọn wọnnì tí wọ́n fi Ìjọ sílẹ̀ nítorí wọ́n nímọ̀lára pé jíjẹ́ ọmọ ìjọ nbèèrè fún púpọ̀ jù lọ́wọ́ wọn. Wọn kò í tíì ṣe àwárí pé dídá májẹ̀mú àti pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ dájúdájú nmú ayé rọrùn. Ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó ndá àwọn májẹ̀mú nínú àwo ìrìbọmi àti nínú tẹ́mpìlì—tí wọ́n sì npa wọn mọ́—ní ààyè púpọ̀ sí agbára Jésù Krístì. Ẹ jọ̀wọ̀ ẹ jíròrò òtítọ́ yíyanilẹ́nu náà!
Èrè fún pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ni agbára àtọ̀runwá—agbára tí ó nfún wa lokun láti kojú àwọn àdánwò, ìdánwò, àti ìrora-ọkàn dáadáa. Agbára yí nmú ọ̀nà wa rọrùn. Àwọn tí wọ́n ngbé àwọn òfin gígajù ti Jésù Krístì ní ààye sí agbára gígajú. Bayi, àwọn olùpamọ́ májẹ̀mú ní ẹ̀tọ́ sí irú ìsinmi pàtàkì tí ó nwá nípasẹ̀ ìbáṣepọ̀ ti májẹ̀mú wọn pẹ̀lú Ọlọ́run.
Ṣíwájú kí Olùgbàlà tó jọ̀wọ́ Ararẹ̀ sí ìrora Gethsemane àti Calvary, Ó kéde sí àwọn Àpóstélì Rẹ̀, “Nínú ayé ẹ̀yin yíò ní ìpọ́njú: ṣùgbọ́n ẹ tújúká; mo ti ṣẹ́gun ayé.”3 Ní ṣísẹ̀ntẹ̀lé, Jésù bẹ ẹ̀nìkọ̀ọ̀kan wa láti ṣe bákannáà nígbàtí Ó wípé, “èmi yíò fẹ́ kí ẹ lè ṣẹ́gun ayé.”4
Ẹyin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, ọ̀rọ̀ mi sí yín ní òní ni pé nítorí Jésù Krístì ṣẹ́gun ìṣubú ayé yí, àti pé nítorí Òun ṣe Ètùtù fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa, ẹ̀yin náà lè ṣẹ́gun ayé yí tí ó kún fún ẹ̀ṣẹ̀, ìmọtaraẹni-nìkan, àti ikaarẹ nígbàkugbà.
Nítorí Olùgbàlà, nípasẹ̀ Ètùtù àìlópin Rẹ̀, ra ẹnìkọ̀ọ̀kan wa padà kúrò nínú àìlera, àṣìṣe, àti ẹ̀ṣẹ̀, àti nítorí Ó ní ìrírí gbogbo ìrora, ìdàmú, àti ẹrù yín tí ẹ ti ní rí,5 lẹ́hìnnáà, bí ẹ ṣe nronúpìwàdà tí ẹ sì nwá ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀, ẹ lè dìde kọjá ewu ayé lọ́wọ́lọ́wọ́ yí.
Ẹ lè ṣẹ́gun ikaarẹ ayé ti ẹ̀mí àti ààrun rírẹni ẹ̀dùn ọkàn ti ayé, pẹ̀lú ìréra, ìgbéraga, ìbínú, ìwà èérí, ìkóríra, ojúkòkùrò, owú, àti ẹ̀rù. Bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn ìdàmú àti ìyípo nyí wa ká, ẹ lè rí ìsinmi òtítọ́—tí ó túmọ̀ sí ìrànlọ́wọ́ àti àláfíà—àní ní àárín àwọn wàhàlà yíyọnilẹ́nu jùlọ yín.
Òtítọ́ pàtàkì nṣí àwọn ìbèèrè ìpìlẹ̀ mẹ́ta.
Àkọ́kọ́, kíni ó túmọ̀ sí pé kí a ṣẹ́gun ayé?
Ìkejì, báwo ni a ó ti ṣe?
Àti Ìkẹ́ta, báwo ni ṣíṣẹ́gun ayé ṣe nbùkún ayé wa?
Kíni ó túmọ̀ sí pé kí a ṣẹ́gun ayé? Ó túmọ̀ sí ṣíṣẹ́gun àdánwò láti tọ́jú àwọn ohun ayé yí ju àwọn ohun Ọlọ́run. Ó túmọ̀ sí gbígbẹ́kẹ̀lé ẹ̀kọ́ Krístì ju ẹ̀kọ́ àwọn ènìyàn lọ. Ó túmọ̀ sí dídùnnú nínú òtítọ́, kíkọ ẹ̀tàn, àti dída “àtẹ̀lé onírẹ̀lẹ̀ ti Krístì .”6 Ó túmọ̀ sí yíyàn láti dá ohunkóhun tí ó lè darí Ẹ̀mí kúrò dúró. Ó túmọ̀ sí fífẹ́ láti “fi àwọn ẹ̀ṣẹ̀” dídùnmọ́ni sílẹ̀.7
Nísisìyí, ṣíṣẹ́gun ayé dájúdájú kò túmọ̀ sí dída pípé nínú ayé yí, tàbí kò túmọ̀ sí pé àwọn wàhàlà yín yíò kúrò pẹ̀lú ìyanu—nítorí wọn kò nílọ. Àti pé kò túmọ̀ sí pé ẹ kò ṣì ní ṣe àṣìṣe. Ṣùgbọ́n ṣíṣẹ́gun ayé túmọ̀ sí pé kíkọ ẹ̀ṣẹ̀ yín yíò pọ̀ si. Ọkàn yín yíò rọ̀ bí ìgbàgbọ́ yín nínú Jésù Krístì ti npọ̀ si.8 Ṣíṣẹ́gun ayé túmọ̀sí dídàgbà láti ní ìfẹ́ Ọlọ́run àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀ ju bí ẹ ti nifẹ ẹnikẹni tàbí ohunkóhun míràn lọ.
Nígbànnáà, báwo, ni a ṣe lè ṣẹ́gun ayé? Ọba Bẹ́njámínì kọ́ wa ní báwò. Ó kọ́ni pé “ènìyàn ẹlẹ́ran ara jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run” yíò sì wà bẹ́ẹ̀ títíláé“bíkòṣepé ó jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ònfà Ẹ̀mí Mímọ́, tí ó sì gbé ìwà ti ara sílẹ̀ tí ó sì di ènìyàn mímọ́ nípasẹ̀ ètùtù Krístì Olúwa.”9 Gbogbo ìgbà tí ẹ bá wá láti tẹ̀lé àwọn ìṣílétí Ẹ̀mí, gbogbo ìgbà tí ẹ bá ṣe ohunkóhun rere—àwọn ohun tí “ènìyàn ẹlẹ́ran ara” kò lè ṣe, ẹ̀ nṣẹ́gun ayé.
Ṣíṣẹ́gun ayé kìí ṣe ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí ó nṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ kan tàbí méjì. Ó nṣẹlẹ̀ ní gbogbo ìgbé ayé bí a ti nrọ̀mọ́ ẹ̀kọ́ Krístì léraléra. À nkọ́ ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì nípa ríronúpìwàdà ojojúmọ́ àti pípá àwọn májẹ̀mú tí ó nfún wa ní ẹ̀bùn agbára mọ́. À ndúró lórí ipá ọ̀nà májẹ̀mú a sì ndi alábùkún pẹ̀lú okun ti ẹ̀mí, ìfihàn araẹni, àníkún ìgbàgbọ́, àti ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ángẹ́lì. Gbígbé ẹ̀kọ́ Krístì lè mú ìyípo ìwàrere, alágbára jùlọ tí ó ndá ìyàra ti ẹ̀mí sílẹ̀ nínú ayé wa jáde.10
Bí a ti ntiraka láti gbé ìgbé ayé àwọn òfin gígajù ti Jésù Krístì, ọkàn wa àti ìwà-ẹ̀dá wa gan an yíò bẹ̀rẹ̀ sí nyípadà. Olùgbàlà gbé wa sókè jú títì ayé ṣíṣubú yí nípa bíbùkún wa pẹ̀lú ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́, inúrere, ìwarere, ìkóraẹni-níjánu, àláfíà, àti ìsinmi.
Nísisìyí, ẹ lè máa ronú pé èyí ndún bíi ti iṣẹ́ líle ti ẹ̀mí ju ìsinmi lọ. Ṣùgbọ́n nihin ni òtítọ́ Ọlọ́lá: Nígbàtí ayé bá tẹnumọ pé agbára, ìní, òkìkí, àti ìgbádùn ti ara nmú ìdùnnú wá, wọn kò ní! Wọn kò lè ni! Ohun tí wọ́n nmú jáde kìí ṣe ohunkankan ṣùgbọ́n ìrọ́pò kòròfo fún “ipò ìbùkún àti ìdùnnú àwọn [tí wọ́n] npa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́.”11
Òtítọ́ ni pé ó jẹ́ ikaarẹ̀ púpọ̀ síi láti wá ìdùnnú níbití ẹ ti ẹ kò ti lè rí i! Bákannáà, nígbàtí ẹ bá ru ẹrù ara yín fún Jésù Krístì àti tí ẹ sì ṣe iṣẹ́ ti ẹ̀mí tí a nílò láti ṣẹ́gun ayé, Òun, àti Òhun nìkan, ni ó ní agbára láti gbé yín sókè ju ayé yí lọ.
Nísisìyí, báwo ni ṣíṣẹ́gun ayé ṣe nbùkún ayé wa? Ìdáhùn náà hàn kedere: Wíwọ inú májẹ̀mú ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run nso wa pọ̀ mọ́ Ọ ní ọ̀nà tí ó nmú ohungbogbo nípa ayé rọrùn. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ máṣe ṣì mi gbọ́: èmi kò wípé dídá àwọn májẹ̀mú nmú ìgbé ayé rọrùn. Nítòótọ́, ẹ retí àtàkò, nítorí ọ̀tá kò fẹ́ kí ẹ ṣe àwárí agbára Jésù Krístì. Ṣùgbọ́n ríru ẹrù ara yín pẹ̀lú Olùgbàlà túmọ̀ sí pé ẹ ní ààyè sí agbára okun àti ìràpadà Rẹ̀ .
Mo tún ìkọ́ni ìjìnlẹ̀ ti Ààrẹ Ezra Taft Benson sọ pé: “Àwọn arákùnrin àti aràbìnrin tí wọ́n ngbé ìgbé ayé wọn fún Ọlọ́run yíò ṣe àwárí pé Òun lè ṣe púpọ̀ síi látinú ìgbé ayé wọn ju bí wọ́n ti lè ṣe. Òun yíò mú ayọ̀ jìnlẹ̀, mú ìran wọn gbòòrò, mú iye inú wọn tají, …gbé ẹ̀mí wọn ga, mú ìbùkún wọb pọ̀ si, fún wọn ní àníkún àwọn ànfàní, tu ẹ̀mí wọn nínú, gbé ọ̀rẹ́ dìde, àti pé kí ó da àláfíà jáde.”12
Àwọn ànfàní àìláfiwé wọ̀nyí ntẹ̀lé àwọn tí wán nwá àtìlẹhìn ọ̀run láti rànwọ́n lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun ayé yí. Dé òpin yí, mo nawọ́ sí àwọn ọmọ gbogbo Ìjọ àṣẹ kannáà tí mo fún àwọn ọ̀dọ́ àgbà wa ní Oṣù Karun tó kọjá. Nígbànáà mo rọ̀ wọ́n—mo sì bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú yín nísisìyí—láti gba àkóso ẹ̀rí ti ara yín nípa Jésù Krístì àti ìhìnrere Rẹ̀. Ṣiṣẹ́ fún un. Ẹ ṣìkẹ́ rẹ̀ ki ó le dàgbà. Ẹ bọ́ ọ ní òtítọ́. Ẹ máṣe dà á rú pẹ̀lú àwọn ẹ̀kọ́ irọ́ ti àìgbàgbọ́ àwọn ọkùnrin àti obìnrin. Bí ẹ ti nfi ìfúnlókun lemọ́lemọ́ ti ẹ̀rí yín nípa Jésù Krístì jẹ́ ìṣíwájú gíga jùlọ yín, ẹ wo iṣẹ́ ìyanu tí yíò ṣẹlẹ̀ nínú ayé yín.
Ẹ̀bẹ̀ mi síi yín ní òwúrọ̀ yí ni kí ẹ wá ìsinmi látinú àìníìdánilójú, líle, àti ìrora ayé yí nípa ṣíṣẹ́gun ayé nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú yín pẹ̀lú Ọlọ́run. Ẹ jẹ́ kí Ó mọ̀ nípasẹ̀ àdúrà yín àti ìṣe pé ẹ ní ìpinnu nípa ṣíṣẹ́gun ayé, Ẹ ní kí Ó mù iyè inú yín gbòòrò kí Ó sì rán ìrànlọ́wọ́ tí ẹ nílò. Ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, ẹ ṣe àkọsílẹ̀ àwọn èrò yín tí ó wá sínú yín bí ẹ ti ngbàdúrà; lẹ́hìnnáà ẹ tẹ̀lé e taratara. Lo àkokò síi nínú tẹ́mpìlì àti wíwá láti ní ìmọ̀ bí tẹ́mpìlì ṣe nkọ́ yín láti dìde kọjá ayé ìṣubú yí.14
Ààrẹ Nelson ti ṣe àsọtúnsọ àtẹnumọ́ náà pé ìkójọpọ̀ ti Ísráẹ́lì ni ohun pàtàkì jùlọ jùlọ tí ó nṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀-ayé loni. Ohun èlò pàtàkì kan nípa kíkójọ yí ni mímúra àwọn ènìyàn kan tí wọ́n léṣe, tí wọ́n ṣetán, tí wọ́n sì yẹ láti gba Olúwa nígbàtí Ó bá wá lẹ́ẹ̀kansi; àwọn ènìyàn kan tí wọ́n ti yan Jésù Krístì lórí ayé ìṣubú yí; àwọn ènìyàn kan tí wọ́n láyọ̀ nínú agbára òmìnira wọn láti gbé ìgbé ayé gíga jù, mímọ́ jù àwọn òfin Jésù Krístì.
Mo pè yín, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, láti di ènìyàn olódodo yí. Ẹ ṣìkẹ́ kí ẹ sì bu ọlá fún májẹ̀mú yín ju gbogbo àwọn ìfarasìn míràn lọ. Bí ẹ ti njẹ́ kí Ọlọ́run borí nínú ayé yín, mo ṣe ìlérí àláfíà títóbi jùlọ, ìgbẹ́kẹ̀lé, ayọ̀, àti bẹ́ẹ̀ni, ìsinmi fún yín.
Pẹ̀lú agbára jíjẹ́ àpóstélì mímọ́ tí a fi fún mi, mo bùkún yín nínú ìgbésẹ̀ láti ṣẹ́gun ayé. Mo bùkún yín láti mú ìgbàgbọ́ yín nínú Jésù Krístì pọ̀ si kí ẹ sì kọ́ bí ẹ ó ti fa sí orí agbára Rẹ̀ dáradára si. Mo bùkún yín láti lè ní òye òtítọ́ kúrò nínú ìṣìnà. Mo bùkún yín láti tọ́jú àwọn ohun Ọlọ́run síi ju àwọn ohun ayé. Mo bùkún yín láti rí àìní àwọn wọnnì ní àyíká yín kí ẹ sì fún àwọn wọnnì tí ẹ fẹ́ràn lókun Nítorí Jésù Krístì ṣẹ́gun ayé yí, ẹ̀yin náà lè ṣé bákannáà. Ní mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.