Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ohun Ìní Títóbi Jùlọ
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


12:44

Ohun Ìní Títóbi Jùlọ

Ọ̀kọ̀ọ̀kan wa níláti wá sí ọ̀dọ̀ Krístì pẹ̀lú ìfarajì àìyẹ̀ sí ìhìnrere Rẹ̀.

Àwọn ìwé mímọ́ sọ nípa ọ̀dọ́ ọlọ́rọ̀ àti alákõso kan, ní sísáré tọ Jésù lọ, tí ó kúnlẹ̀ ní ẹsẹ̀ Rẹ̀ àti, pẹ̀lú ìṣòtítọ́ tí ó hàn, ó bèèrè lọ́wọ́ Olùkọ́ni, “Kíni kí èmi ó ṣe kí èmi ó le jogún ìyè ayérayé?” Lẹ́hìn ṣíṣe àyẹ̀wò àkópọ̀ gígùn kan nípa àwọn òfin tí ẹlẹgbẹ́ yí ti pamọ́ pẹ̀lú ìgbàgbọ́, Jésù wí fún ọkùnrin náà láti ta gbogbo àwọn ohun ìní rẹ̀, kí ó fi owó tí ó bá rí níbẹ̀ fún àwọn tálákà, kí ó gbé àgbélèbú rẹ̀, kí ó sì tẹ̀lé Òun. Ìgboyà ti ìdarí yìí mú kí ọ̀dọ́ alákõso náà—pẹ̀lú sálúbàtà rẹ̀ tí ó níye lórí—ó ní òtútù ní àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì lọ pẹ̀lú ìbànújẹ́ nítorípé, ìwé mímọ́ sọ pé, “Ó ní àwọn ohun ìní títóbi.”1

Ní híhàn gbangba, èyí jẹ́ ìtàn ìkìlọ̀ pàtàkì kan nípa àwọn ìlò ọrọ̀ àti àwọn àìní ti àwọn tálákà. Ṣùgbọ́n ní ìgbẹ̀hìn ó jẹ́ ìtàn nípa ìfọkànsìn tọkàntọkàn, láìfi ohunkóhun pamọ́, sí ojúṣe àtọ̀runwá. Pẹ̀lú tàbí láìsí àwọn ọrọ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wa níláti wá sí ọ̀dọ̀ Krístì pẹ̀lú irú ìfarajì ìgbàgbọ́ àìyẹ̀ sí ìhìnrere Rẹ̀ tí a retí láti ọ̀dọ̀ ọ̀dọ́mọkùnrin yìí. Ní èdè ìbínibí ti àwọn ọ̀dọ́ òde òní, a nílati kéde ara wa pe “gbogbo wa wà níbẹ̀.”2

Nínú ìtàn-àròsọ rẹ̀ tí ó máa njẹ́ mánigbàgbé, C. S. Lewis fi ojú inú wo Olúwa tí ó nsọ ohun kan fúnwa bí èyí: “Èmi kò fẹ́ … àkókò yín … [tàbí] owó yín … [tàbí] iṣẹ́ yín, [púpọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tó bí] èmi [kàn] ṣe fẹ́ẹ Yín. [Igi yìí tí ẹ̀yin ntọ́jú.] Èmi kò fẹ́ gé ẹ̀ka kan kúrò níhĩn àti ẹ̀ka kan lọ́hũn, mo fẹ́ … kí odidi [ohun] náà wálẹ̀. [Àti ehín náà,] Èmi kò fẹ́ gbẹ́ [ẹ], tàbí fi adé dé [e], tàbí [kún] un. [Mo fẹ́] yọ ọ́ sítà. [Ní pàtó, mo fẹ́ kí ẹ fa] odidi àdánidá ara-ẹni yín lemi lọ́wọ́. Èmi ó [sì] fún yín ní ara-ẹni titun dípò. Ní pàtó, èmi yío fún yín ní Ara-mi: ìfẹ́ mi …yío di [ìfẹ́ yín].”

Gbogbo ẹnití yío sọ̀rọ̀ nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò yi gbogbo wọn yio máa sọ, ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn, ohun tí Krístì sọ sí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà: Wá sí ọ̀dọ̀ Olùgbàlà rẹ. Wá pátápátá àti tọkàntọkàn. Gbé àgbélèbú rẹ, bí ó ti wù kí ó wúwo tó, kí o sì tẹ̀lé E.”4 Wọn ó sọ èyí ní mímọ̀ pé ní ìjọba Ọlọ́run, kò le sí àwọn òsùnwọ̀n ìlàjì-ọ̀nà, kò sí bíbẹ̀rẹ̀ kí á sì tún dúró, kò sí pípadà sẹ́hìn. Sí àwọn tí wọ́n bèèrè ìyọ̀nda láti sin òkú òbí kan tàbí sọ ó dìgbà sí àwọn ọmọlẹ́bí míràn, ìdáhùn Jésù jẹ́ líle díẹ̀ tí ó sì yéni kedere. “Ẹ fi èyíinì sílẹ̀ fún àwọn míràn,” ni Ó sọ. “Kò sí ẹnikan, tí ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé ohun ìtulẹ̀, tí ó sì bojúwẹ̀hìn, tí ó yẹ fún ìjọba Ọlọ́run.”5 Nígbàtí a bá béèrè àwọn ohun líle lọ́wọ́ wa, àní àwọn ohun tí ó tako àwọn ìpòngbẹ ọkàn wa, ẹ rántí pé jíjẹ́ olõtọ́ tí a ṣèlérí rẹ̀ sí iṣẹ́ Krístì níláti jẹ́ ìfọkànsìn gígajù ti ìgbé ayé wa. Àti pé, bíótilẹ̀jẹ́pé Isáiàh tún ìdánilójú ṣe fúnwa pé ó wà “láìsí owó àti láìdíyelé,”4—ó sì jẹ́ pé—a gbọdọ̀ múrasílẹ̀, ní lílo ìlà ti T. S. Ellot, láti ní i ó nọ́wa ní “ìdínkù ju ohungbogbo.”5

Dájúdájú, gbogbo wa ní àwọn ìwà tàbí àwọn àbùkù tàbí ìtàn ara-ẹni kan tí ó le mú wa kúrò nínú rírìbọmi pátápatá ti ẹ̀mí nínú iṣẹ́ yìí. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni Baba wa Ó sì dára tayọ ní dídáríjì àti ní gbígbàgbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti kọ̀sílẹ̀, bóyá nítorípé a fún Un ní àwọn àdáṣe pùpọ̀ ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Bíóṣewùkórí, ìrànlọ́wọ́ àtọ̀runwá wà fún olukúlùkù wa ní èyíkéyi wákàtí tí a bá ní ìmọ̀lára láti ṣe àtúnṣe nínú ìhùwàsí wa. Ọlọ́run fún Sáúlù ní “ọkàn míràn.”6 Ezekíẹlì ké pe gbogbo àwọn Isráẹ́lì ìgbàanì láti kọ ohun àtijọ́ wọn sílẹ̀ kí ó sì “ṣe … ọkàn titun kan àti ẹ̀mí titun kan.”7 Alma pè fún “ìyípadà nlá” kan8 tí yío mú ọkàn láti gbòòrò, àti pé Jésù Fúnra-Rẹ̀ kọ́ni pé “bíkòṣepé a tún ènìyàn bí, òun kò le rí ìjọba Ọlọ́run.”9 Ní kedere ṣíṣeéṣe ìyípadà lati gbígbé ní ìpele tí ó ga díẹ̀ síi ti nfi ìgbà-gbogbo jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run sí àwọn tí wọn wá a.

Ẹyin ọ̀rẹ́, nínú àkókò wa lọ́wọ́lọ́wọ́ yi a nrí gbogbo onírúurú àwọn pípín àti àwọn àtúnpín, àwọn ẹgbẹ́ àti àwọn ọ̀gbà-ẹgbẹ́, àwọn ìdánimọ̀ níhĩn àti lílépa fún ìdánimọ̀ lóhũn, pẹ̀lú ànító ìkanra tí ó pọ̀ju láti lọ yíká. Njẹ́ a lè bi ara wa léèrè bóyá ìgbé-ayé “gíga síi àti mímọ́ síi,”12 láti lo gbólóhùn Ààrẹ Nelson, le jẹ́ ohun kan tí a le lépa? Nígbàtí a nṣe bẹ́ẹ̀, yío dára bí a bá le rántí àkókò àrà ọ̀tọ̀ náà nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì nínú èyítí àwọn ènìyàn náà bèèrè tí wọ́n sì dáhùn ìbéèrè náà pẹ̀lú ìfẹsẹ̀múlẹ̀.

“O sì ṣe tí kò sí asọ̀ ní ààrin gbogbo àwọn ènìyàn náà, ní gbogbo ilẹ̀ náà; … nitori ifẹ Ọlọ́run èyítí o ngbé inu ọkàn àwọn ènìyàn náà.

“Ko sì sí ìlara, tabi ìjà, … tabi èyíkéyi irú ìwà ìfẹ́kúfẹ̃; dájúdájú kò sì sí irú àwọn ènìyàn tí ó ní ayọ̀ jù wọ́n lọ láàrín gbogbo àwọn ènìyàn tí a dá láti ọwọ́ Ọlọ́run.

“Ko sí ọlọ́ṣà, tabi apànìyàn, bẹ́ẹ̀ni kò sí àwọn ara Lámánì, tabi èyíkéyí irú èyàmẹyà; ṣùgbọ́n wọn wà ní íṣọ̀kan, àwọn ọmọ Krístì, àti ajogún sí ìjọba Ọlọ́run.

Bí wọ́n sì ti jẹ́ alábùkúnfún tó!11

Kíni ó jẹ́ kókó ọ̀nà abáyọ sínú ìgbé ayé ìtẹ́lọ́rùn àti ìdùnnú yìí? O wà nínú ọ̀rọ̀ kíkọ náà ní gbólóhùn kan; “Ìfẹ Ọlọ́run … gbé inu ọkàn àwọn ènìyàn náà.”12 Nígbàtí ìfẹ́ Ọlọ́run bá ṣètò ipa-ọ̀nà fún ìgbé-ayé tiwa, fún ìbáṣepọ̀ wa sí ara wa àti ní ìgbẹ̀hìn ìmọ̀lára wa fún gbogbo ẹ̀dá ènìyàn, nígbànáà ni àwọn ìyàtọ̀, àwọn àmì òdiwọ̀n, àti àwọn pípín àtọwọ́dá ti àtijọ́ yío kọjá lọ, àlàáfíà yío sì pọ̀ síi. Èyí ni pàtó ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nínú àpẹrẹ wa látinú Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Kò sí àwọn ará Lámánì, tàbí àwọn ènìyàn Jákọ́bù, tàbí àwọn ènìyàn Jósẹ́fù, tàbí àwọn ará Zórámù mọ́. Kò sí àwọn “ẹ̀yàmẹyà” rárá. Àwọn ènìyàn náà ti gba ìdánimọ̀ titun títayọ kan. Ó sọ pé, gbogbo wọn yío jẹ́ mímọ̀ bíi “àwọn ọmọ Krístì.”13

Dájúdájú, a nsọ̀rọ̀ níhĩn nípa òfin àkọ́kọ́ tí a fifún ẹbí ẹ̀dá ènìyàn—láti fẹ́ràn Ọlọ́run, láìsí àfipamọ́ tàbí yíyẹ̀ àdéhùn, tí ó jẹ́, pẹ̀lú gbogbo ọkàn, okun, àti agbára wa.14 Ìfẹ́ Ọlọ́run yi ni àkọ́kọ́ òfin nlá ní àgbáyé. Ṣùgbọ́n àkọ́kọ́ òtítọ́ nlá ní àgbáyé ni pé Ọlọ́run fẹ́ràn wa ní ọ̀nà náà gãn—tọkàntọkàn, láìsí àfipamọ́ tàbí ìdúnãdúrà, pẹ̀lú gbogbo ọkàn, agbára, inú, àti okun Rẹ̀. Àti nígbàtí àwọn ipá ọlánlá láti ọkàn Rẹ̀ àti tiwa wọnnì bá pàdé láìsí ìdíwọ́, ìbúgbàmù otítọ́ kan máa nwà ní ti ẹ̀mí àti ti agbára ìwà. Nígbànáà, bí Teilhard de Chardin ti kọ̀wé rẹ̀, ”fún ìgbà kejì nínú ìtàn àgbáyé, ìfẹ́ inú ènìyàn ti ṣe àwárí iná.”16

Ó jẹ́ nígbànáà, àti nígbànáà gan nìkan, ni a le pa òfin nlá kejì mọ́ dáradára ní àwọn ọ̀nà tí kò níi jẹ́ lásán tàbí bíntín. Bí a bá fẹ́ràn Ọlọ́run tó láti gbìyànjú láti jẹ́ olõtọ́ sí I, Òun yío fúnwa ní agbára, ìleṣe, ìfẹ́ inú, àti ọ̀nà láti fẹ́ràn àwọn aládũgbò wa àti ara wa. Bóyá nígbànáà àwa ó le sọ lẹ́ẹ̀kansíi pé, “Kò lè sí àwọn ènìyàn tí ó ní ayọ̀ jù wọn lọ láàrín gbogbo àwọn ènìyàn tí a dá láti ọwọ́ Ọlọ́run.”17

Ẹyin arákùnrin àti arábìnrin, mo gbàdúrà pé a ó yege níbití ọlọ́rọ̀ ọ̀dọ́mọkùnrin náà ti kùnà, pé a ó gbé àgbélèbú ti Krístì, bí ó ti wù kí ó le tó, láìka ohun tí ó le jẹ́ sí àti láìka iye tí ó le jẹ́ sí. Mo jẹ́rìí pé nígbàtí a ṣèlérí láti tẹ̀lé E, ipa ọ̀nà náà yío, ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn, gba ibi ọ̀nà adé ti àwọn ẹ̀gún àti kedere àgbélébú Rómánù kan. Bí ó ti wù kí ọ̀dọ́mọkùnrin alákoso wa jẹ́ ọlọ́rọ̀ tó, kò ní ànító ọrọ̀ láti ra ọ̀nà rẹ̀ jáde kúrò nínú ìsọdọ̀tun pẹ̀lú àwọn àmì wọnnì, bẹ́ẹ̀ni àwa kò le ṣe Fún ìbùkún ti gbígba gbogbo ohun-ìní títóbijùlọ—ẹ̀bùn ìyè ayérayé—ó kéré gab tí wọ́n fi ní kí a dúró ní ọ̀nà títẹ̀lé Àlùfáà Gíga ti ìmòye wa, Ìràwọ̀ Ọjọ́ wa, Alágbàwí, àti Ọba. Mo jẹ́ri pẹ̀lú Amálẹ́kì ìgbànì tí ó farasin pé olukúlùkù wa níláti “fi gbogbo ọkàn [wa] fún un bí ọrẹ kan.”18 Nípa irú ìpinnu, ìfọkànsìn ìdúróṣinṣin, a nkọrin:

Ẹ yin òkè náà; èmi wà títí lórí rẹ̀:

Òkè ti ìfẹ́ rẹ tó nranipadà. …

Níhĩn ni ọkàn mi, Áà gbà kí o sì fi èdidì dì í,

Fi èdidì dì í fún àwọn kóòtù rẹ lókè.19

Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín