Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Tẹ́mpìlì àti Ìpilẹ̀ṣẹ̀ Ti-ẹ̀mí Yín
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹwa (Ọ̀wàwà) 2021


Tẹ́mpìlì àti Ìpilẹ̀ṣẹ̀ Ti-ẹ̀mí Yín

Ìgbàkugbà tí irú àjálù kankan bá ṣẹlẹ̀ ní ìgbé-ayé yín, ibi ààbò jùlọ láti wà níti-ẹ̀mí ni gbígbé nínú àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì yín!

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, mo dúpẹ́ láti wà pẹ̀lú yín ní òwúrọ̀ yí láti pín àwọn ìmọ̀lára ọkàn mi.

Bí ẹ ti mọ̀, à nṣe àwọn kókó àtúnṣe ní Tẹ́mpìlì onítàn Salt Lake. Iṣẹ́ àyíká yí pẹ̀lú kókó títẹramọ́ ìpìlẹ̀ṣẹ̀ àtètèkọ́ṣe, èyí tí ó sin dáadáa ju bíi sẹ́ntúrì kan lọ. Ṣùgbọ́n tẹ́mpìlì èyí gbọ́dọ̀ dúró pẹ́ jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ní iparí Oṣù Karun, mo yẹ ìlọsíwájú lórí iṣẹ́ títóbi yí wò. Mo lérò pé ẹ ó mọyì wíwo ohun tí ìyàwó mi, Wendy, àti èmi rí. Mo ro pé ẹ ó wo ìdí tí orin “Bí Ìpìlẹ̀ṣẹ̀ ṣe Dúróṣinṣin tó”1 ti ní ìtumọ̀ titun fún mi.

2:4

Fídíò látinú àyíká àtúnṣe Tẹ́mpìlì Salt Lake: “A nwo àtètèkọ́ṣe ìpìlẹ̀ Tẹ́mpìlì Salt Lake. Mo ndúró ní agbègbè lábẹ́ ohun tí ó jẹ́ Yàrá Ọ̀gbà. Bí mo ti nyẹ gbígbẹ́ gbogbo ilé yí wò, ó yà mí lẹ́nu ohun tí àwọn olùlànà ṣe yọrí. Mo wà ní ìyanu tán-pátápátá nígbàtí mo wò pé wọ́n kọ́ tẹ́mpìlì títóbijùlọ yí pẹ̀lú àwọn ohun-èlò àti ọgbọ́n tí ó wà fún wọn nìkan ní jíju bí sẹ́ntúrì kan lọ sẹ́hìn.

“Àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ díkédì wọ̀nyí lẹ́hìnnáà, bákannáà, bí a bá yẹ ìpìlẹ̀ṣẹ̀ wò tímọ́tímọ́, a ó rí ààye ìpalára àgbàrá, nínú iṣẹ́ òkúta àtètèkọ́ṣe, àti ipele onírurú ti ìmúdúró nínú ríri-okútàmọ́lẹ̀.

“Nísisìyí, bí mo ṣe njẹri ohun tí àwọn ayàwòrán-ilé, àti amoye ìkọ́lé òde-òní lè ṣe láti tẹramọ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ àtètèkọ́ṣe, ó yà mí lẹnú gidigidi. Iṣẹ́ wọn jẹ́ ìyanilẹnu!

“Ìpilẹ̀ṣẹ̀ ilé kankan, nípàtàkì ọ̀kan títóbí bíiti èyí, gbọ́dọ̀ jẹ́ líle àti alágbára tó láti kojú isẹ́lẹ̀, ìpàta, ìjì líle, àti gbígbésílẹ̀ àìròtẹ́lẹ̀ tí ó lè pa àwọn ilé lára. Iṣẹ́ líle ti fífúnlókun tí ó wà lọ́nà nísisìyí yíò rọ̀mọ́ tẹ́mpìlì mímọ́ yí pẹ̀lú ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí ó lè tí yíò sì dúró títí.”

A kò pa ìgbìyànjú kankan ti láti fún tẹ́mpìlì ọ̀wọ̀ yí, èyí tí ó di pípalárapúpọ̀si, ìpilẹ̀ṣẹ̀ kan tí yíò tako àwọn agbára àdánidá sínú Mìllẹ́níọ̀mù. Ní ọ̀ná kannáà, àkokò ti tó nísisìyí kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa lo àwọn òṣùwọ̀n àìlẹ́gbẹ́—bóyá àwọn òṣùwọ̀n tí a kò ṣe tẹ́lẹ̀rí—láti fún ìpilẹ̀ṣẹ̀ ti ẹ̀mí araẹni wa lókun. Àwọn àkokò àìrò pè fún àwọn òṣùwọ̀n àìrò.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi, ìwọ̀nyí ni àwọn ọjọ́ ìkẹhìn. Bí ẹ̀yin àti èmi yíò bá tako àwọn ewu àti ìtẹ̀mọ́lẹ̀ tí ó nbọ̀, ó ṣe pàtàkì kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ ti-ẹ̀mí gbọingbọin tí a kọ́ lé orí àpàta Olùràpadà wa, Jésù Krístì.2

Nítorínáà mo bèèrè lọ́wọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan yín, “Báwo ni ìpilẹ̀ yín ṣe dúróṣinṣin tó? Àti pé kíni ẹ nílò fún rírọ̀mọ́ ẹ̀rí yín àti níní ìmọ̀ ìhìnrere?”

Tẹ́mpìlì wà ní oókan ìfúnlókun ìgbàgbọ́ wa àti ìtìlẹ́hìn ti-ẹ̀mí nítorí Olùgbàlà àti ẹ̀kọ́ Rẹ̀ jẹ́ oókan-àyà tẹ́mpìlì. Ohungbogbo tí a kọ́ni ní tẹ́mpìlì, nípasẹ̀ àṣẹ àti nípasẹ̀ Ẹ̀mí, nmú ìmọ̀ wa nípa Jésù Krístì pọsi. Àwọn ìlànà pàtàkì Rẹ̀ so wá mọ́ Ọ nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú mímọ́ oyeàlùfáà. Nígbànáà, bí a ti npa májẹ̀mú wa mọ́, Ó nfún wa ní ẹ̀bùn pẹ̀lú agbára ìfunnilókun wíwòsàn, Rẹ̀.3 Àti pé áà, bí a ó ṣe nílò agbára Rẹ̀ ní àwọn ọjọ́ iwájú.

A ti ṣe ìlérí fún wa pé “Bí [a] bá múrasílẹ̀ [a] kò ní bẹ̀rù.”4 Ìdánilójú yí ní àwọn àbájáde jíjinlẹ̀ ní òní. Olúwa ti kéde pé pẹ̀lú àwọn ìpènijà àìrò ti òní, àwọn tí wọ́n bá kọ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ wọn lé Jésù Krístì, tí wọ́n sì ti kọ́ bí wọn ó ti fa agbára Rẹ̀, kò nílò láti juwọ́lẹ̀ sí àwọn àníyàn àìláfiwé àkokò yí.

Àwọn ìlànà tẹ́mpìlì àti májẹ̀mú jẹ́ ti àtijọ́. Olúwa pàṣẹ fún Ádámù àti Éfà láti gbàdúrà, dá májẹ̀mú, àti láti rú ẹbọ.5 Nítòótọ́, “ìgbàkugbà tí Olúwa bá ti ní àwọn ènìyàn lórí ilẹ̀-ayé tí yíò gbọ́ran sí ọ̀rọ̀ Rẹ̀, a ti pàṣẹ fún wọ́n láti kọ́ àwọn tẹ́mpìlì.”6 Ìwọn iṣẹ́ wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìtọ́ka sí ìkọ́ni tẹ́mpìlì, wíwọṣọ, èdè, àti pùpọ̀si.7 Ohungbogbo tí a gbàgbọ́ àti gbogbo ìlérí tí Ọlọ́run ti ṣe sí àwọn ọmọ májẹ̀mú Rẹ̀ wá papọ̀ nínú tẹ́mpìlì. Ní gbogbo ọjọ́, tẹ́mpìlì mú òtítọ́ onìyebíye mọ́lẹ̀ pé awọn tí ó dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run tí wọ́n sì npa wọ́n mọ́ ni àwọn ọmọ májẹ̀mú.

Báyìí, nínú ilé Olúwa, a lè dá àwọn májẹ̀mú kannáà pẹ̀lú Ọlọ́run tí Ábráhámù, Ísáákì, àti Jákọ́bù dá. A sì lè gba irú àwọn ìbùkún kannáà!

Àwọn Tẹ́mpìlì Kirtland àti Nauvoo.

Àwọn tẹ́mpìlì ti jẹ́ ara iṣẹ́ ìríjú láti àwọn ọjọ́ ìṣíwájú.8 Èlíjàh fi àwọn kọ́kọ́rọ́ àṣẹ èdidì fún Joseph Smith ní Tẹ́mpìlì Kirtland. Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ oyèàlùfáà ni a múpadàbọ̀sípò ni Tẹ́mpìlì Nauvoo.9

Títí dìgbà pípa, Joseph Smith tẹ̀síwájú láti gba àwọn ìfihàn tí ó mú ìmúpadàbọ̀sípò nípa ẹ̀bùn tẹ́mpìlì àti àwọn ìlànà èdidì tẹ̀síwájú.10 Ó damọ̀, bákannáà, pé àtúnṣe síwájúsi ni a nílò. Lẹ́hìn fífi ẹ̀bùn fún Brigham Young ní Oṣù Karun 1842, Joseph wí fún Brigham pé, “Èyí ni a kò tòsílẹ̀ àbí, ṣùgbọ́n a ti ṣe dídárajùlọ tí a lè ṣe lábẹ́ àwọn ipò èyí tí a fi wá sí tí a sì fẹ́ láti mú ọ̀ràn yí lọ́wọ́ kí a sì ṣètò kí a sì fi-ètò ṣe gbogbo àwọn ayẹyẹ wọ̀nyí.”11

Títẹ̀lé ikú Wòlíì, Ààrẹ Young fojúsí ìparí Tẹ́mpìlì Nauvoo12 àti lẹ́hìnnáà wọ́n kọ́ àwọn tẹ́mpìlì ní Agbègbè Utah. Ní ìyàsímímọ́ Tẹ́mpìlì St. George, Brigham Young fi taratara kéde kánjúkánjú iṣẹ́ tẹ́mpìlì nígbàtí ó wípé, “Nígbàtí mo ronú lórí ẹ̀kọ́ yí, mo fẹ́ kí ahọ́n àwọn àrá méje jí àwọn ènìyàn dìde.”13

Láti ìgbànáà síwájú, àwọn ìlànà tẹ́mpìlì ni à ntúnṣe díẹ̀díẹ̀. Ààrẹ Harold B. Lee ṣe àlàyé ìdí tí àwọn ìṣísẹ̀, ètò, àní àti ìṣàkóso ìlànà tẹ́mpìlì tẹ̀síwájú láti yípadà nínú ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ Olùgbàlà. Ó wípé: “Àwọn ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ ìhìnrere Jésù Krístì jẹ́ tọ̀run. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó nyí àwọn ẹ̀kọ́-ìpìlẹ̀ àti [ẹ̀kọ́] Ìjọ padà àyàfí tí Olúwa bá ṣeé nípasẹ̀ ìfihàn. Ṣùgbọ́n àwọn ọ̀nà nyípadà bí ìdarí ìmísí ṣe nwá sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n nṣe àkóso.”14

Yẹ bí fífúnni ní oúnjẹ-Olúwa ti yípadà ní àwọn ọdún wò. Ní àwọn ọjọ́ ìṣíwájú, omi oúnjẹ-Olúwa ni a fifún gbogbo-ìjọ nínú ohun-èlò títóbi kan. Gbogbo-ènìyàn nmu láti inú rẹ̀. Nísisìyí a nlo ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ife jíjùsọnù. Àwọn ìlànà yípadà, ṣùgbọ́n àwọn májẹ̀mú dúrotítí bákannáà.

Ẹ jíròrò àwọn òtítọ́ mẹ́ta wọ̀nyí:

  1. Ìmúpadàbọ̀sípò jẹ́ ètò kan, kìí ṣe ìṣẹ̀lẹ̀, àti pé yíò tẹ̀síwájú títí Olúwa yíò fi wá lẹ́ẹ̀kansi.

  2. Àbájáde ìgbẹ̀hìn ti ìkójọ Ísráẹ́lì15 ni láti mú àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì wá fún àwọn onígbàgbọ́ ọmọ Ọlọ́run.

  3. Bí a ti nlépa bí a ó ti ṣe àṣeyọrí àbájáde náà dáradárasi, Olúwa nfi òye hàn si. Ìmúpadàbọ̀sípò tó nlọ-lọ́wọ́ nílò ìfìhàn tó nlọ lọ́wọ́.

Àjọ Ààrẹ Kínní àti Iyejú àwọn Apóstélì Méjìlá ti bèèrè lọ́wọ́ Olúwa lemọ́lemọ́ bí àwọn ọ̀nà dídárasi bá wà láti mú àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì lọ fún àwọn onígbàgbọ́ ọmọ Rẹ̀. À nwá ìtọ́sọ́nà léralérá lórí bí a ṣe lè mu àṣẹ ìyára àti àìtàsé, májẹ̀mú, àti àwọn ìlànà pẹ̀lú àwọn ìyàtọ̀ nínú èdè àti ọ̀làjú gbogbogbò tẹ́mpìlì dájú.

Lábẹ́ ìdarí Olúwa àti ní ìdáhùn sí àwọn àdúrà wa, àwọn àtúnṣe ìlànà ni a ti ṣe làìpẹ́. Òun ni Ẹnìkan tí ó nfẹ́ kí ẹ ní ìmọ̀ pẹ̀lú híhàn yékéyéké ohun tí ẹ̀ ndá májẹ̀mú láti ṣe. Òun ni Ẹnìkan tí ó nfẹ́ kí ẹ ní ìrírí kíkún nípa àwọn ìlànà mímọ́ Rẹ̀. Òun nfẹ́ kí ẹ ní òye àwọn ànfàní, ìlérí, àti ojúṣe yín. Òun nfẹ́ kí ẹ ní òye ti-ẹ̀mí àti ìtàgìrì tí ẹ kò ní rí. Èyí ni Òun nfẹ́ fún gbogbo àwọn alábójútó tẹ́mpìlì, ibikíbi yíówù kí wọ́n gbé.

Àwọn àtúnṣe lọ́wọ́lọ́wọ́ nínú àwọn ìṣíṣẹ̀ tẹ́mpìlì, àti àwọn míràn tí yíò tẹ̀le, ni ẹ̀rí títẹ̀síwájú pé Olúwa ndarí Ìjọ Rẹ̀ pẹ̀lú aápọn. Ó npèsè àwọn ànfàní fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wa láti gbé àwọn ìpinlẹ̀ṣẹ̀ ti-ẹ̀mí wa ga dáradárasi nípa fífi ìgbé-ayé wa sí orí gbùngbun Rẹ̀ àti lórí àwọn ìlànà àti májẹ̀mú tẹ́mpìlì Rẹ̀. Nígbàtí ẹ bá mú ìkaniyẹ tẹ́mpìlì yín wá, pẹ̀lú ọkàn ìròbìnújẹ́, àti wíwá oye-inú sí ikẹkọ ní ilé Olúwa, Òun yíò kọ́ wa.

Ṣé ọ̀nà-jíjìn, àwọn ìpènijà ìlera, tàbí àwọn ìdènà míràn yí dá lílọsí tẹ́mpìlì wa fún àkokò kan dúró, mo pè yín láti gbé àkokò déédé kan kalẹ̀ láti tún àwọn májẹ̀mú yín tí ẹ ti dá kà.

Bí ẹ kò bá nifẹ láti lọsí tẹ́mpìlì síbẹ̀, ẹ lọ léraléra si—kìí ṣe dídínkù. Ẹ jẹ́ kí Olúwa, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Rẹ̀, kọ́ni kí ó sì mí sí yín níbẹ̀. Mo ṣe ìlérí fún yín pé ní àkokò pípẹ́, tẹ́mpìlì yíò di ibi ààbò, ìtùnú, àti ìfihàn kan.

Bí ó bá ṣeéṣe fún mi láti sọ̀rọ̀ ní ọ̀kan-sí-ọ̀kan pẹ̀lú gbogbo ọ̀dọ́-àgbà, èmi ó bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú yín láti wá ojúgbà pẹ̀lú ẹnití ẹ lè ṣe èdidì nínú tẹ́mpìlì. Ó lè yà yín lẹ́nu irú ìyàtọ̀ tí èyí yíò ṣe ní ìgbé-ayé yín. Mo ṣe ìlérí pé yíò ṣe gbogbo ìyàtọ̀! Bí ẹ bá ṣe ìgbeyàwó nínú tẹ́mpìlì tí ẹ sì padà léraléra, ẹ ó ní okun àti ìtọ́sọ́nà nínú àwọn ìpinnu yín.

Bí èmi bá lè sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọkọ kọ̀ọ̀kan àti ìyàwó tí wọ́n kò tíì ṣe èdidì nínú tẹ́mpìlì, èmi yíò bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú yín láti gbé àwọn ìgbésẹ̀ tó ṣeéṣe láti gba ìlànà, dídádé yíyípadà ìgbé-aye.16 Njẹ́ yíò ṣe ìyàtọ́ kan? Bí ẹ bá nfẹ́ láti ní-ìlọsíwájú títíláé àti láti wà papọ̀ títíláé. Fífẹ́ láti wà papọ̀ títíláé kò ní mu jẹ́ bẹ́ẹ̀. Kò sí ayẹyẹ míràn tàbí ìgbaṣẹ́ tí yíò mú jẹ́ bẹ́ẹ̀.17

Bí èmi bá lè sọ̀rọ̀ sí ọ̀kọ̀ọ̀kan ọkùnrin tàbí obìnrin tí wọ́n nwọ̀nà fún ìgbeyàwó ṣùgbọ́n tí wọn kò tíì rí ojúgbà ayérayé wọn, èmi yíò rọ̀ yín kí ẹ máṣe dúró títí dé ìgbeyàwó láti gba ẹ̀bùn tẹ́mpìlì ní ilé Olúwa. Ẹ bẹ̀rẹ̀ nísisìyí láti kọ́ àti láti ní ìrírí ohun tí ó túmọ̀ sí láti róni ní agbára oyè-àlùfáà.

Àti sí ọ̀kọ̀ọ̀kan lára yín tí wọ́n ti dá májẹ̀mú tẹ́mpìlì, mo bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú yín láti wá—láti ní ìmọ̀ àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì àti àwọn ìlànà—pẹ̀lú àdúrà àti àìtàsé.18 Àwọn ìlẹ̀kùn ti-ẹ̀mí yíò ṣí. Ẹ ó kọ́ bí ẹ ó ti pín ìkelè ọ̀run àti ilẹ̀-ayé níyà, bí ẹ ó ti bèèrè fún àwọn ángẹ́lì Ọlọ́run láti tọ̀jú yín, àti bí ẹ ó ti gba ìdarí lati ọ̀run dáradárasi. Àwọn ìgbìyànjú ìtara yín láti ṣe bẹ́ẹ̀ yíò tún yín ṣe yíò sì fún ìpilẹ̀ṣẹ̀ ti-ẹ̀mí yín lókun.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, nígbàtí àwọn ìtúnṣe lórí Tẹ́mpìlì Salt Lake bá ṣetán, kì yíò si ibi ààbò jùlọ ní ìgbà ìsẹ́lẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Salt Lake ju inú tẹ́mpìlì náà lọ.

Bákannáà, ìgbàkugbà tí irú àjálù kankan bá ṣẹlẹ̀ ní ìgbé-ayé yín, ibi ààbò jùlọ láti wà níti-ẹ̀mí ni gbígbé nínú àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì yín!

Ẹ jọ̀wọ́ ẹ gbà mí gbọ́ nígbàtí mo bá wípé nígbàtí ẹ bá kọ́ ìpilẹ̀ṣẹ̀ ti-ẹ̀mí yín digbídigbí lé Jésù Krístì, ẹ kò nílò láti bẹ̀rù. Bí ẹ bá jẹ́ olotitọ sí àwọn májẹ̀mú yín tí ẹ dá nínú tẹ́mpìlì, ẹ ó ní okun nípa agbára Rẹ̀. Lẹ́hìnnáà, nígbàtí àwọn ìsẹ́lẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ẹ ó lè dúró gbọingbọin nítorí ìpilẹ̀ṣẹ ti-ẹ̀mí yín wà gbọingbọin àti àìyẹsẹ̀.

Mo nifẹ yín, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n. Àwọn òtítọ́ wọ̀nyí ni mo mọ̀: Ọlọ́run, Baba wa Ọ̀run, nfẹ́ kí ẹ yàn láti wá sílé sọ́dọ̀ Rẹ̀. Ètò ìlọsíwájú ayérayé Rẹ̀ kò díjú, ó sì nbu-ọlá fún agbára òmìnira yín. Ẹ ní òmìnira láti yan ẹnití ẹ fẹ́ jẹ́—àti pẹ̀lú ẹnití ẹ ó jẹ́—nínú ayé tó nbọ̀!

Ọlọ́run wà láàyè! Jésù ni Krístì! Èyí ni Ìjọ Rẹ̀, tí a mú padàbọ̀sípò láti ràn yín lọ́wọ́ láti mú àyànmọ́ tọ̀run yín ṣẹ. Ní mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Wo “Bí Ìpìlẹ̀ kan Ṣe Fẹsẹ̀-múlẹ̀ Gọingọin,” Àwọn orin,, no. 85.

  2. Nítorínáà “nígbàtí èṣù … bá sì [fẹ́] [ẹ̀fúfù] rẹ̀ wá, … kò lè ní agbára lórí [wa] … nítorí àpáta eyítí [a] kọ́ yín lé, èyítí íṣe ìpìlẹ̀ dídájú, ìpìlẹ̀ èyítí ènìyàn kò lè ṣubú lórí rẹ̀ bí wọ́n bá kọ́lé le lórí” (Hẹ́lámánì 5:12; àtẹnumọ́ àfikún).

  3. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 109:15, 22.

  4. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 38:30; bákannáà wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 10:55.

  5. Wo Mósè 5:5-6.

  6. Ìtumọ̀ Bíbélì, “Tẹ́mpìlì.”

  7. Fún àpẹrẹ, wo Ẹ́ksódù 28; 29; Léfítíkù 8. The tabernacle of Moses was known as a “tent of the testimony” (Númérì 9:15) and a “tabernacle of testimony” (Ẹ́ksódù 38:21). Tẹ́mpìlì Solomon ni a parun ní 578 B.C., ọdún díẹ̀ lẹ́hìn tí ẹbí Léhí kúrò ní Jerusalem. Ìmúpadàbọ̀sípò tẹ́mpìlì yí nípasẹ̀ Zerubbabel ṣẹlẹ̀ ní àwọn àádọ́rin ọdún lẹ́hìnnáà. Nígbànáà ó bàjẹ́ nípa iná ní 37, BC. Herod fẹ tẹ́mpìlì náà ní 18, BC. Nígbànáà tẹ́mpìlì yí, tí Jésù mọ̀, ni a parun ní A.D. 70. Nefi ní àwọn ìrírí bíiti-tẹ́mpìlì nípa lílọ “sínú òkè déédé” láti gbàdúrà (1 Néfì 18:3) áti lẹ́hìnnáà wọ́n kọ́ tẹ́mpìlì kan “bíiti tẹ́mpìlì Solomon,” bíótilẹ̀jẹ́pé ó dínkù ní agbára (wo 2 Néfì 5:16).

  8. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 88:119; 124:31.

  9. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 110:13-16; 124:28. The cornerstone for the Nauvoo Temple was laid on April 6, 1841, just a few months after Joseph Smith received the revelation to build it. The Nauvoo Temple had augmented functions. For example, the Lord explained that a baptismal font was needed for the Saints to be baptized for those who were dead (wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 124:29–30).

  10. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 131and 132; Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 128 contains an epistle Joseph Smith wrote to the Saints concerning baptism for the dead. There he declared that the salvation of the dead “is necessary and essential to our salvation, … [for] they without us cannot be made perfect—neither can we without our dead be made perfect” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú128:15).

  11. Joseph Smith, in Àwọn Ènìyàn Mímọ́: Ìtàn Ìjọ Jésù Krístì ní àwọn Ọjọ́ Ìkẹhìn, vol. 1, Òṣùwọ̀n Òtítọ́, 1815–1846 (2018), 454.

  12. Church Historian George A. Smith concluded that 5,634 brothers and sisters received their endowment in the partially completed Nauvoo Temple in December 1845 and January 1846. Èdidì gb`wọn tọkọ-taya tẹ̀síwájú di Feb. 7, [1846,] nígbà èyí tí tọkọ-taya 2,000 ti darapọ̀ látọwọ́ oyè-àlùfáà fún àkokò àti ayérayé” (Bruce A. Van Orden, “Temple Finished before Exodus,” Deseret News, Dec. 9, 1995, deseret.com; see also Richard O. Cowan, “Endowments Bless the Living and Dead,” Church News, Aug. 27, 1988, thechurchnews.com).

  13. “What do you suppose the fathers would say if they could speak from the dead? Would they not say, We have lain here thousands of years, here in this prison house, waiting for this dispensation to come? Why, if they had the power the very thunders of heaven would be in our ears, if we could but realize the importance of the work we are engaged in. All the angels in heaven are looking at this little handful of people, and stimulating them to the salvation of the human family. … When I think upon this subject, I want the tongues of seven thunders to wake up the people” (Discourses of Brigham Young, sel. John A. Widtsoe [1954], 403–4).

  14. Harold B. Lee, “Ìjọba Ọlọ́run—Ìjọba Ètò kan,” Ensign, Jan. 1971, 10. Bákanna\a` wo ẹ̀là-ọ`rọ tì a sọ nípasẹ̀ Ààrẹ Wildord Woodruff; ó kéde: “Mo fẹ́ wípé, bí a`àrẹ I`jọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ìgbà Ìkẹhìn, pé a níláti lọ́ kí a sì ní ìlọsíwájú. A kò tíì [lọ] tán nínú ìfihàn. … Ààrẹ [Brigham] Young, who followed President Joseph Smith, led us here. He organized these temples and carried out the purposes of his calling and office. … Òun kò gba gbogbo àwọn ìfihàn tí ó wà fún iṣẹ́ yí; bẹ́ẹ̀náà ni Ààrẹ Taylor, tàbí ni Wilford Woodruff. Kò ní sí òpin sí iṣẹ́ yí títí a ó fi ṣàṣepé” (Ìwàásù tiWilford Woodruff, sel. G. Homer Durham [1946], 153–54).

  15. Wo 3 Néfì 29:8–9.

  16. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 131:2, 4.

  17. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 132:7.

  18. Alàgbà John A. Widtsoe wrote: “Sí ọkùnrin tàbí obìnrin tí wọ́n lọ nínú tẹ́mpìlì, pẹ̀lú ojú lílàṣílẹ̀, gbígbọ́ àwọn àmì àti májẹ̀mú, àti mímú dúró-déédé, ìgbìyànjú títẹ́síwájú láti ní ìmọ̀ ní kíkún, Ọlọ́run nsọ ọ̀rọ̀ rẹ̀, àti pé àwọn ìfihàn nwá. Ẹ̀bùn tẹ́mpìlì ti jẹ́ àmì ọlọ́rọ̀ tí òpònú nìkan yíò gbìyànjú láti júwé rẹ̀; ó kún fún àwọn ìfihàn sí àwọn tí wọ́n n;o agbára wọn lati wá àti láti rí, tí àwọn ọ̀rọ̀ ènìyàn lè ṣàlàyé tàbí mú híhàn-kedere ṣíṣeèṣe tíó wà nínú iṣẹ́-ìsìn tẹ́mpìlì hàn. Ẹ̀bùn èyítí a fúnni nípasẹ̀ ìfihàn ni a lè ní ìmọ̀ rẹ̀ nípasẹ̀ ìfihàn” (in Archibald F. Bennett, Olùgbàlà lórí Òkè Síónì [Sunday School manual, 1950], 168).