Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ní Ipa Ọnà ti Ojúṣe Wọn
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́wàá 2023


14:29

Ní Ipa Ọnà ti Ojúṣe Wọn

Ẹyin tí ẹ ntẹ̀síwájú ní òní ní ipa ọ̀nà ti ojúṣe yín ni agbára Ìjọ Olùgbàlà tí a múpadà bọ̀sípò.

Mo fi ìtara gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ ti Ẹmí Mímọ́ bí mo ti nfi ìfẹ́, ìtẹríba, àti ìmoore mi hàn fún àwọn ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti awọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn káàkiri gbogbo àgbáyé.

Àwọn ti Kẹ̀kẹ́ Ẹrù Tó Kẹ́hìn

Ọdún 1947 ṣe àmì ayẹyẹ àjọ̀dún ọgọ́rũn ọdún tí dídé àkọ́kọ́ àwọn aṣaájú ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ikẹhìn sí inú Àfonífojì Salt Lake. Àwọn ayẹyẹ ìrántí pùpọ̀ ló wáyé nínú ọdún náà, àti pé àìlónkà àwọn àfihàn ìmoore jẹ́ sísọ fún àwọn olùfọkànsìn ọmọ-ẹ̀hìn Jésù Krístì tí wọ́n fi ìtànná sí àwọn ipa ọ̀nà ẹsẹ̀, kọ́ àwọn ilé, gbin àwọn irúgbìn nínú àgàn aṣálẹ̀, tí wọ́n sì tẹ àwọn ibùgbé dó.

Ààrẹ J. Reuben Clark, olùdámọ̀ràn kinní nínú Àjọ Ààrẹ Èkíní, fi ọ̀kan lára àwọn oríyìn mọ́nigbàgbé àti wíwọnilára jùlọ fún àwọn onígbàgbọ́ aṣaájú wọ̀nyí nínú ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́wàá 1947.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Ààrẹ Clark rọra mọ rírì àwọn olùdarí tí wọ́n jẹ́ ẹni mímọ̀ dáradára ní kúkúrú, àwọn ẹnití wọ́n ṣe atọ́nà kíkólọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn, àwọn bíi Brigham Young, Heber C. Kimball, Wilford Woodruff, Parley P. Pratt, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn míràn. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, kókó èrèdí rẹ̀ kìíṣe láti ṣe àtúnwí àwọn àṣeyọrí àwọn ẹni ẹ̀yẹ wọnyí. Dípò bẹ́ẹ̀, ó fi àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ sùn sí orí àwọn ọkàn dídúró ṣinṣin àwọn ẹnití orúkọ wọn kò jẹ́ mímọ̀ tàbí kí wọn ó jẹ́ kíkọsílẹ̀ pẹ̀lú àṣẹ nínú ìtàn Ìjọ Àkọ́lé ìkọ́ni ti ọ̀rọ̀ rẹ̀ náà ni, “Àwọn ti Kẹ̀kẹ́ Ẹrù Tó Kẹ́hìn.”1

Ààrẹ Clark ṣe àpèjúwe ní àsọyé púpọ̀ nípa àwọn ìhùwàsí àti àwọn ìpèníjà tí àwọn olùkólọ tí wọ́n rìn ìrìn àjò nínú kẹ̀kẹ́ bíbò tó kẹ́hìn náà dojúkọ nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tírénì oníkẹ̀kẹ́ gígùn tó sọdá àwọn pápá náà. Ó gbé oríyìn fún àwọn akíkanjú wọ̀nyí tí a kò mọ orrúkọ àti tí a kò ṣe ayẹyẹ fún àwọn tí, ọjọ́ lẹ́hìn ọjọ́, ọ̀sẹ̀ lẹ́hìn ọ̀sẹ̀, àti oṣù lẹ́hìn oṣù, há ní ọrùn nítorí eruku rírú sókè nípasẹ̀ gbogbo àwọn kẹ̀kẹ́ tó nyí lọ níwájú wọn—àwọn tí wọ́n borí àwọn ìdènà tí kò dáwọ́dúró tí wọ́n kojú ní ojú ọ̀nà.

Ààrẹ Clark sọ pé, “Àwọn ti inú kẹ̀kẹ́ tó kẹ́hìn tẹ̀ síwájú, nínú aṣọ gbígbó tí ó sì ti rẹ̀ wọ́n, egbò ẹsẹ̀, wọ́n fẹ́rẹ̀ rẹ̀wẹ̀sì nígbà míràn, fi ara dà nípa ìgbàgbọ́ wọn pé Ọlọ́run fẹ́ràn wọn, pé ìhìnrere tí a múpadà bọ̀sípò jẹ́ òtítọ́, àti pé Olúwa ṣaájú Ó sì darí Àwọn Arákùnrin jáde níwájú.”2

“Sí àwọn ọkàn onírẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, títóbi nínú ìgbàgbọ́, títóbi nínú iṣẹ́, títóbi nínú ìgbé ayé òdodo, títóbi nínú ṣíṣe ẹ̀dá ogún ìní wa àìdíyelé, mo fi pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ fún wọn ní ìfẹ́ mi, ìtẹríba mi, ìbuọláfún mi pẹ̀lú ọ̀wọ̀.”3

Kò Ṣe Aláì-Ṣiṣẹ́

Ní 1990, Ààrẹ Howard W. Hunter, Ààrẹ ti Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá nígbànáà, sọ ọ̀rọ̀ kan nípa ìdásí kòṣeémáni ti àìlónkà àwọn ọmọ ìjọ tí wọ́n nsìn tọkàn-tọkàn àti lódodo tí wọ́n sì ngba ìmọrírì tàbí ìyìn kékeré tàbí àìsí rárá ní gbangba.

Ààrẹ Hunter ṣàlàyé pé:

“A sọ ọ́ [nípa ọ̀dọ́ àti akíkanjú Ọgágun Mórónì] pé:

“’Bí gbogbo ènìyàn bá ti wà rí, tí wọ́n sì wà, àti ti wọn yíò wa láé, bíi ti Mórónì, kíyèsĩ, àwọn agbára ọ̀run àpãdì gan-an ìbá di aláìlágbára títí láéláé; bẹ́ẹ̀ni, èṣù kì bá ti lágbára lórí ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn láé.’ (Alma 48:17).

“Ó ti jẹ́ ọ̀rọ̀ ìwúrí tó sí gbajúmọ̀ àti alágbara ọkùnrin ka. … Àwọn ẹsẹ méjì lẹ́hìnwá jẹ́ ọ̀rọ̀ kan nípa Hẹ́lámánì àti àwọn arákùnrin rẹ̀, tí wọ́n kó ipa tí ó dínkù ní híhànde ju Mórónì, èyí kà pé:

“Nísisìyí ẹ kíyèsĩ, Hẹ́lámánì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ kò ṣe aláì-ṣiṣẹ́ fún àwọn ènìyàn nã bí ti Mórónì.’”4

Ààrẹ Húnter tẹ̀síwájú pé, “Ní àwọn ọ̀rọ̀ míràn, àní bíótilẹ̀jẹ́ pé Hẹ́lámánì kò jẹ́ fífúrasí tàbí híhànde bíi Mórónì, ó ṣiṣẹ́ bákannáà; èyí túmọ̀sí pé ó jẹ́ ẹni tó ṣèrànwọ́ tàbí wúlò bíi ti Mórónì.”5

Ààrẹ Hunter lẹ́hìnnáà gba gbogbo wa nímọ̀ràn láti jẹ́ kò ṣe aláì-ṣiṣẹ́. Ó wí pé: “Bí o bá ní ìmọ̀lára pé púpọ̀ nínú àwọn ohun tí o ṣe ní ọdún yi tàbí nínú àwọn ọdún to nbọ̀ kò mú ọ di gbajúmọ̀ gidi, mú ọkàn. Púpọ̀jù nínú àwọn ènìyàn tó dára jùlọ tí wọ́n ti gbé rí kò gbajúmọ̀ gidi bẹ́ẹ̀ náà. Sìn kí o sì gbèrú, lódodo àti ní jẹ́ẹ́jẹ́.”6

Ní Ipa Ọnà ti Ojúṣe Wọn

Mo ní ìmoore fún mílílọnù àwọn ọmọ Ìjọ tí wọ́n nwá sí ọ̀dọ̀ Olùgbàlà lónìí7tí wọ́n sì ntẹ̀ síwájú ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú nínú àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù tó kẹ́hìn ti àwọn tírénì kẹ̀kẹ́ ẹrù ìgbàlódé wa—àti nítòótọ́ tí wọn jẹ́ kò ṣe aláì-ṣiṣẹ́. Ìgbàgbọ́ líle yín nínú Bàbá Ọ̀run àti Olúwa Jésù Krístì, àti ìgbé ayé yín tí ó jẹ́ ìwọ̀ntúnwọ̀nsì àti yíyàsọ́tọ̀ fún mi ní ìmísí láti jẹ́ ènìyàn àti ọmọ-ẹ̀hìn dáradára síi.

Mo fẹ́ràn yín. Mo ní ìtẹríba fún yín. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín. Mo sì gbé oríyìn fún yín

Ọ̀rọ̀ kan nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì láti ẹnu Sámúẹ́lì ará Lámánì ṣe ìkékúrú dárajùlọ nípa àwọn ìmọ̀lára mi fún yín.

“Ẹ rí i pé èyítí ó pọ̀ jù nínú wọn ni ó wà ní ipa ọ̀nà ojúṣe wọn, wọ́n sì nrìn ní ọ̀nà òtítọ́ níwájú Ọlọ́run, wọ́n sì fiyèsí láti pa àwọn òfin rẹ̀ àti àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́. …

“Bẹ́ẹ̀ni, mo wí fún yín, pé èyítí ó pọ̀ jù nínú wọn nṣe èyí, wọ́n sì ntiraka pẹ̀lú aápọn láìkáarẹ̀ pé kí wọn ó le mú ìyókù àwọn arákùnrin wọn wá sínú ìmọ̀ òtítọ́ náà.”8

Mo gbàgbọ́ pé gbólóhùn ọ̀rọ̀ “ní Ipa ọ̀nà ti ojúṣe wọn” nṣe àpèjúwe àwọn onífura arákùnrin àti arábìnrin tí wọn nwò fún tí wọ́n sì jókòó ti àwọn ènìyàn tí wọ́n nìkan wà nínú àwọn ìpàdé ìjọ àti ní onírũrú àwọn àgbékalẹ̀ míràn. Wọ́n ntiraka déédé láti tu àwọn tí wọ́n nílò ìtùnú nínú,8 láìsí àwọn ìrètí ìmọrírì tàbí ìyìn.

Gbólóhùn náà “ní Ipa ọ̀nà ti ojúṣe wọn” nṣe àpèjúwe àwọn lọ́kọ-láya àti àwọn ọmọ tí wọ́n ṣe àtìlẹ́hìn fún ojúgbà, òbí, tàbí ọmọ tí ó nsìn ní ipò olùdarí nínú Ìjọ Olúwa tí a múpadàbọ̀sípò. Ipa ìmúnidúró wọn déédé, jẹ́jẹ́, àti tí ó wọ́pọ̀ ní àìdámọ̀ nmú ìbùkún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹnikọ̀ọ̀kan àti àwọn ẹbí ṣeéṣe ní àwọn ọ̀nà tí yío di mímọ̀ ní kíkún ní ayérayé nìkan.

Gbólóhùn náà “ní Ipa ọ̀nà ti ojúṣe wọn” nṣe àpèjúwe àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tí, lẹ́hìn tí wọ́n ti yà kúrò ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, wọ́n tún-nyà pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ lẹ́ẹ̀kansíi,9 ní ríronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn, àti lílépa agbára ìwẹ̀númọ́ àti ìwòsàn ti Ètùtù Olùgbàlà. Wíwá sí ọ̀dọ̀ Krístì11nípa pípadà sí ipa ọ̀nà májẹ̀mú láti àwọn ìyànà búburú sí “àwọn ipa ọ̀nà kíkà léèwọ̀”12ṣe pàtàkì ní ti ẹ̀mí ó sì ṣòro ní ti òdodo. Bí wọ́n ti ntẹ̀ síwájú pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tí wọn kò sì kãrẹ̀ nínú ṣíṣe rere, wọ́n nfi ìpìlẹ̀ iṣẹ́ nlá kan lélẹ̀ nínú ìgbé ayé ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn,12 “dé gbogbo ìrandíran àti fún ayérayé.”13

Gbólóhùn náà “ní Ipa ọ̀nà ti ojúṣe wọn” nṣe àpèjúwe àwọn olódodo ẹnìkọ̀ọ̀kan tí wọ́n npòngbẹ láti dàpọ̀ mọ́ Olùgbàlà nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú àti àwọn ìlànà ìhìnrere Rẹ̀ tí a fọwọ́ sí—ṣùgbọ́n tí a le má gbà wọ́n láàyè láti ṣe bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ àwọn ìdí tí ó tayọ agbára wọn. Mo ṣe ìlérí pé ìrora ti ara ẹni yín yío di fífúyẹ́ àti pé ìgbọràn àti ìṣòdodo yín láti fi pẹ̀lú sùúrù ju ìfẹ́ yín sílẹ̀ fún Ọlọ́run yío gba èrè ní “àkókò yíyẹ ti Olúwa.”15 “Ẹkún le pẹ́ di alẹ́ kan, ṣùgbọ́n ayọ̀ nbọ̀ ní òwúrọ̀.”16

Gbólóhùn náà “ní Ipa ọ̀nà ti ojúṣe wọn” nṣe àpèjúwe àwọn onímĩsí ayírọ̀padà àti àwọn olùtúmọ̀ ní àyíká àgbáyé tí wọ́n nsin Olúwa nípa ríran àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn ọmọ ijọ lọ́wọ́ láti “gbọ́ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere náà ní ahọ́n ti[wọn], àti ní èdè ti[wọn].”17 Àwọn ohùn wọn, ìfọwọ́sí, àti àwọn ìwé tí wọ́n ti fi yírọ̀padà ngbé àwọn òtítọ́ ayérayé, síbẹ̀ díẹ̀ nínú wa ló mọ orúkọ wọn tàbí fi ìmoore hàn láé. Nípasẹ̀ ẹ̀bùn àwọn ahọ́n pẹ̀lú èyí tí a ti bùkún wọn, àwọn ayírọ̀padà àti àwọn olùtúmọ̀ nsìn tọkàntọkàn, láìṣe-taraẹni, àti, ní ìgbà pùpọ̀ jùlọ, láìfarahàn láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ gba àwọn ìbùkún ẹ̀mí ti ìgbàgbọ́ nípasẹ̀ kíkà àti gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.18

Gbólóhùn náà “ní Ipa ọ̀nà ti ojúṣe wọn” nṣe àpèjúwe àwọn ọkùnrin àti obìnrin inú-ìgbéyàwó tí wọ́n nbu ọlá fún ojúṣe májẹ̀mú wọn láti máa bí síi kí wọn ó sì kún ilẹ̀ ayé, àti àwọn ẹnití a bùkún pẹ̀lú okun àti ìforítì láti ja ìjàkadì pẹ̀lú àwọn ọmọdé wọn nínú àwọn ìpàdé oúnjẹ Olúwa. Nínú ayé kan tí ó ndi rúdurùdu síi tí ó sì njìyà àwọn àjálù àti àṣìtò àwọn ohun pàtàkì, àwọn ọkàn onígboyà wọ̀nyí kò fetísí àwọn ohùn ti ayé tí ó nyin ìmọtaraẹni-nìkan; wọ́n bọ̀wọ̀ fún jíjẹ́-mímọ́ àti síṣe pàtàkì ìgbé ayé nínú ètò ìdùnnú ti Baba Ọ̀run fún àwọn ọmọ Rẹ̀.

Pùpọ̀ àwọn lọ́kọ-láya inú-ìgbéyàwó bákannáà ngbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run nígbàtí òdodo àwọn ìfẹ́ inú ọkàn wọn kò bá wáyé bí àti nígbàtí wọ́n ti nírètí àti tí wọ́n ti lá àlá. Wọ́n “ndúró de Olúwa”19wọn kìí sì bèèrè pé kí Ó bá àwọn àfojúsùn wọn ti ilẹ̀ ayé pàdé. “Nítorí láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé ni àwọn ènìyàn kò ti gbọ́ tàbí wòye nípasẹ̀ etí, bẹ́ẹ̀ni ojú kankan kò tíì rí, Áà Ọlọ́run, bíkòṣe ìwọ, bí àwọn ohun náà ti tóbi tó tí ìwọ ti pèsè fún [àwọn] ẹni náà tí ó dúró dè ọ́.”20

Gbólóhùn náà “ní Ipa ọ̀nà ti ojúṣe wọn” nṣe àpèjúwe àwọn ẹgbẹgbẹ̀rún àti ẹgbẹgbẹ̀rún olùdarí àwọn èwe àti àwọn olùkọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ tí wọ́n fẹ́ràn tí wọ́n sì nkọ́ àwọn ọmọ inú Ìjọ ní Ọjọ́ Ìsinmi kọ̀ọ̀kan.

Ẹ ronú lórí ipa ayérayé ti iṣẹ́-ìsìn ṣíṣe láti ọwọ́ olùfọkànsìn ọmọ-ẹ̀hìn wọ̀nyí—àti àwọn ìbùkún ìyanu tí a ṣe ìlérí fún àwọn ẹnití wọ́n nṣe ìpínfúnni sí àwọn ọmọdé.

“[Jésù] sì gbé ọmọ kan, ó sì gbé e sí àárín wọn: nígbàtí ó sì ti gbé e sí ọwọ́ rẹ̀, ó wí fún wọn pé,

“Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọ̀kan lára àwọn ọmọ wọ̀nyí ní orúkọ mi, gbà mí: ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbà mí, kò gba èmi, ṣùgbọ́n ẹni tí ó rán mi.”21

Gbólóhùn náà “ní Ipa ọ̀nà ti ojúṣe wọn” nṣe àpèjúwe àwọn olùfọkànsìn ọmọ tí wọ́n nfi pẹ̀lú ìṣọ́ra ṣe ìtọ́jú fún àwọn arúgbó òbí, ìyá kan tí a dù-ní-oorun tí ó ntu ọmọ kan tí ẹ̀rù nbà nínú nígbàtí ó dúró bíi “abo kìnìun ní ẹnu ọ̀nà” ilé rẹ̀,21 àwọn ọmọ Ìjọ tí wọ́n ntètè dé tí wọ́n sì ndúró pẹ́ láti tò àti láti palẹ̀ àwọn àga mọ́, àti onímĩsí ẹnìkọ̀ọ̀kan tí wọ́n pe ẹbí, àwọn ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ láti wá wò, wá ṣe ìrànlọ́wọ́, àti láti wá dúró.22

Mo ti ṣe àpèjúwe àwọn àṣàyàn àpẹ̀rẹ díẹ̀ péré ti àwọn olùpa májẹ̀mú mọ́ àti olùfọkànsìn ọmọ-ẹ̀hìn Jésù Krístì bí ìwọ tí o ntẹ̀síwájú “ní ipa ọ̀nà ojúṣe [rẹ].” Àwọn mílíọ́nù àfikún àwọn àpẹrẹ ti àwọn ènìyàn mímọ́ ọjọ́-ikẹhìn tí wọ́n nfi “gbogbo ọkàn” wọn sílẹ̀24 ún Ọlọ́run ni a nrí nínú àwọn ilé tí a fi Krístì sí ààrin gbùngbùn rẹ̀ àti nínú àwọn ẹ̀ka Ìjọ yíká ayé.

Ẹ fẹ́ràn ẹ sì nsìn, ẹ nfetísílẹ̀ ẹ sì nkọ́ ẹ̀kọ́, ẹ nṣètọ́jú ẹ sì ntù nínú, ẹ nkọ́ni ẹ sì njẹ́rí nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́. Ẹ ngba ãwẹ̀ ẹ sì ngbàdúrà nígbà-kũgbà, ẹ ndi alágbára àti alágbára síi nínú ìrẹ̀lẹ̀, ẹ sì ndúró àti dúró ṣinṣin síi nínú ìgbàgbọ́ ti Krístì, “títí ọkàn [yín] fi kún fún ayọ̀ àti ìtùnú, bẹ́ẹ̀ni, àní títí dé sísọ-di-mímọ́ àti ìyà-sí-mímọ́ ọkàn [yín], ìyà-sí-mímọ́ èyítí nwá nítorí ti … jíjọ̀wọ́ ọkàn [yín] fún Ọlọ́run.24

Ìlérí àti Ẹrí

Àwọn ti kẹ̀kẹ́ ẹrù tó kẹ́hìn, gbogbo àwọn tí kò ṣe aláì-ṣiṣẹ́, àti ẹ̀yin lóni tí ẹ ntẹ̀síwájú ní ipa ọ̀nà ti ojúṣe yín ni agbára Ìjọ Olùgbàlà tí a múpadà bọ̀sípò. Àti pé bí Olúwa ti ṣe ìlérí, “gbogbo ìtẹ́ àti ilẹ̀-ọba, àwọn ilẹ̀ ọmọ-ọba àti agbára, yíò di fífihàn àti gbígbékalẹ̀ lórí gbogbo àwọn tí wọ́n ti farada pẹ̀lú ìgboyà fún ìhìnrere Jésù Krístì.”26

Mo fi tayọ̀tayọ̀ jẹ́ri pé Baba Ọ̀run àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀ wà láàyè, àti pé àwọn ìlérí Wọn dájú, ní orúkọ mímọ́ Olúwa Jésù Krístì, àmín.