Nírẹ̀lẹ̀ láti Gbà àti Láti Tẹ̀le
Ìbéèrè náà fi hàn pé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ jẹ́ ohun tí a nílò fún wa láti múra tán láti padà wá sí iwájú Ọlọ́run.
Ní orí karùn ún ti Álmà, ìbéèrè àròsínú kan wà: “Njẹ́ ẹ̀yin lè sọ, nínú ọkàn yín, tí a bá yàn an fún yín láti kú ní báyìí, pé ẹ̀yin ti rẹ ara yín sílẹ̀ tó bẹ́ẹ̀?”1 Ìbéèrè náà fi hàn pé ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ jẹ́ ohun tí a nílò fún wa láti múra tán láti padà wá sí iwájú Ọlọ́run.
Gbogbo wa fẹ́ràn láti ronú pé a jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ dáadáa, ṣùgbọ́n àwọn ìrírí kan nínú ìgbésí ayé jẹ́ kí a mọ̀ pé ọkùnrin tàbí obínrin agbéraga sábà máa nwà láàyè gan-an nínú wa.
Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn, nígbàtí àwọn ọmọbìnrin wa méjèèjì ṣì ngbé nílé, mo pinnu láti fi ẹ̀ka iṣẹ́ ajé tí mo nbójútó ní ilé iṣẹ́ tí mò nṣiṣẹ́ hàn àwọn àti ìyàwó mi.
Ìdí mi gan-an ni láti fi ibi kan hàn wọ́n níbi tí, kò dà bí ilé wa, gbogbo ènìyàn ló máa nṣe ohun tí mo ní kí wọ́n ṣe láì bèèrè ìbèère. Bí a ti dé ẹnu-ọ̀nà iwájú, èyítí ó máa nṣí láìfọwọ́yí nígbàtí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mi bá súnmọ́, ó yà mí lẹ́nu pé kò ṣí ní àkókò yí. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹ̀ṣọ́ kan tí mi ò tíì rí rí wá síbi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà ó sì béèrè káàdì ìdánimọ̀ ilé iṣẹ́ mi lọ́wọ́ mi.
Mo sọ fún un pé èmi kò nílò káàdì ìdánimọ̀ kan láti wakọ̀ sínú ilé pẹ̀lú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mi àti lẹ́hìnnáà mo bèèrè ìbéèrè ìgbéraga ti aṣa lọ́wọ́ rẹ̀: “Njẹ́ o mọ ẹni ti ò nbáwí?”
Èyí tí ó dáhùn pé, “Ó dára, níwọ̀n bí o kò ti ní káàdì ìdánimọ̀ ilé-iṣẹ́ rẹ, èmi kò lè mọ̀ ẹni tí o jẹ́, àti pé nígbàtí mo wà ní ẹnu-ọ̀nà yí ìwọ kì yíò rí ààyè láti wọ inú agbègbè náà láìsí ìdánimọ̀ pípé.”
Imo ronú nípa wíwo jígí ìfiwò láti wo ìṣesí ọmọbìnrin mi sí gbogbo èyí, ṣùgbọ̀n mo mọ̀ pé wọ́n ngbádù gbogbo ìṣẹ́ju-akàn àkokò náà! Ìyàwó mi ní ẹ̀gbẹ́ mi nmi orí rẹ̀ ní àìfọwọ́sí ìwà mi. Ohun àṣekẹ́hìn mi ni láti tọrọ gáfárà fún ẹ̀ṣọ́ náà kí nsọ pé ma bínú púpọ̀ fún ṣíṣe búburú mi sí i. “A ti dáríjí ẹ́,” ṣùgbọ́n láìsí káàdì ìdánimọ̀ ilé-iṣẹ́ ìwọ kì yíò wọlé lónìí!”
Lẹ́hìnáà mo wakọ̀ jẹ́jẹ́ díẹ̀díẹ̀ padà sílé láti mú káàdì ìdánimọ̀ mi, lẹ́hìn tí mo ti kẹ́kọ̀ọ́ iyebíye yìí: Pé nígbà tí a bá yàn láti má ṣe jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, á máa di ẹni àbùkù nígbẹ̀hìn.
Nínú Òwe a rí i pé: “Ìgbéraga ènìyàn ni yíò rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀: ṣùgbọ́n ọlá yíò gbé onírẹ̀lẹ̀ ọkàn ró.”2 Láti lè ní ìrẹ̀lẹ̀, a gbọ́dọ̀ lóye ohun tí ó túmọ̀ sí gidi nínú àyíká ọ̀rọ̀ ìhìnrere.
Àwọn ènìyàn kan ṣe ìdàmù jíjẹ́ onírẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú àwọn ohun míràn gẹ́gẹ́bí, jíjẹ́ tálákà. Ṣùgbọ́n ní tòótọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló wà tí wọ́n jẹ́ tálákà àti agbéraga àti ọ̀pọ̀ bákannáà tí wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ tí wọ́n sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Àwọn míràn tí wọ́n ntijú gan-an tàbí tí wọ́n ní ọ̀wọ̀ ara rírẹlẹ̀ lè ní ìrísí ìrẹ̀lẹ̀ òde ṣùgbọ́n inú wọn kún fún ìgbéraga.
Nígbànáà kíni ìrẹ̀lẹ̀? Ní ìbámu sí Wàásù Ìhìnrere Mi, ó jẹ́ “ìfẹ́ láti tẹríba fún ìfẹ́ Olúwa. … Ó jẹ́ agbára láti kẹ́kọ̀ọ́. … [Ó jẹ́] ìpìlẹ̀ pàtàkì fún ìdàgbàsókè tẹ̀mí.”3
Ó dájú pé ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà fún gbogbo wa láti mú ìwà bíi ti Kristi yìí gbèrú sí i. Mo fẹ́ láti kọ́kọ́ ṣàwárí bí a ti jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ sí, tàbí tí ó yẹ, ní títẹ̀lé ìmọ̀ràn wòlíì wa. Ìdánwò àgbéjáde fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa lè jẹ́:
-
Njẹ́ a máa ndárúkọ Ìjọ ní kíkún ní gbogbo àwọn ìbáraẹnisọ̀rọ̀ wa? Ààrẹ Russell M. Nelson wípé, “Láti mú orúkọ Olúwa kúrò nínú Ìjọ Olúwa jẹ́ ìṣẹ́gun pàtàkì fún Sátánì.”4
-
Njẹ́ à njẹ́ kí Ọlọ́run borí nínú ìgbésí ayé wa nípa gbígba ipè ti wòlíì wa kan ní pàtó bí? “Lónìí mo pe àwọn ọmọ ìjọ wa níbi gbogbo láti darí kúrò ní àwọn ìwà ìkọ̀sílẹ̀ àti àwọn ìṣe ìkórira.”5
-
Njẹ́ à nṣẹ́gun ayé, ní gbígbẹ́kẹ̀lé ẹ̀kọ́ Krístì ju ọgbọ́n ènìyàn lọ, gẹ́gẹ́bí wòlíì wa ti kọ́ni?6
-
Ṣé a ti di onílàjà tó nsọ ohun rere sí àti nípa àwọn ènìyàn bí? Ààrẹ Nelson kọ́ wa ní ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò tí ó kọjá yí: “Bí ohunkóhun bá jẹ́ ìwà rere, yẹ ní fífẹ́, tàbí ti ihìnrere tàbí yẹ fún yíyìn èyí ni a lè sọ nípa ènìyàn míràn—bóyá sí ojú rẹ̀ tàbí ní ẹ̀hìn rẹ̀—èyí níláti jẹ́ òṣùwọ̀n ìbáraẹnisọ̀rọ̀ wa.”7
Ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn ìlànà tí ó rọrùn ṣùgbọ́n tí ó lágbára. Ẹ rántí, gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn Mósè ní láti ṣe láti gba ìwòsàn ni láti wo ejò idẹ tí ó ti gbé sókè.7 Ṣùgbọ́n nítorí ti ìrọ̀rùn ọ̀nà nã, tàbí àìnira rẹ̀, ọ̀pọ̀ ni ó wà tí ó ṣègbé.”8
Ní àkókò ìpàdé yí a ti gbọ́ a sì máa tún gbọ́ ìmọ̀ràn tí kò lè kùnà ti àwọn wòlíì àti àwọn àpóstélì wa. Ó jẹ́ àkókò pípé láti mú ìrẹ̀lẹ̀ dàgbà, kí a sì jẹ́ kí àwọn èrò alágbára wa gbé ìdánilójú tí ó tilẹ̀ lágbára jùlọ mì pé Olúwa nsọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àwọn àyànfẹ́ olùdarí wọ̀nyí.
Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ní mímú ìrẹ̀lẹ̀ dàgbàsókè, a tún gbọ́dọ̀ lóye kí a sì gbà pé a kò ní ànfàní láti borí àwọn ìpèníjà wa tàbí láti ṣàṣeyọrí agbára wa ní kíkún nípasẹ̀ àwọn akitiyan tiwa nìkan. Àwọn agbọ̀rọ̀sọ ìwúrí, àwọn olùkọ̀wé, àwọn olùkọ́ni àti àwọn olùdásíṣẹ́ kákiri àgbáyé, nípàtàkì lorí àwọn irú ẹ̀rọ dígítà yíò sọ pé ohun gbogbo dá lórí wa àti àwọn ìṣe wa nìkan. Aráyé gbàgbọ́ nínú apá ẹran ara.
Ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìhìnrere tí a múpadàbọ̀sípò a ti kẹ́kọ̀ọ́ pé a gbẹ́kẹ̀lé inúrere Baba Ọ̀run àti Ètùtù ti Olùgbàlà wa Jésù Krístì, “nítorí a mọ̀ pé nípa oore-ọ̀fẹ́ ni a fi gbà wá là, lẹ́hìn gbogbo ohun tí a lè ṣe.”9 Ìdí nìyí tí ó fi ṣe pàtàkì tóbẹ́ẹ̀ láti dá májẹ̀mú kí a sì pa á mọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, níwọ̀n bí ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yíò ti fún wa ní àyè kíkún sí ìmúláradá, mímúná, àti agbára pípé ti Jésù Krístì nípasẹ̀ Ètùtù Rẹ̀.
Wíwà ní ìpàdé oúnjẹ Olúwa lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ àti sísìn nínú tẹ́mpìlì nígbàgbogbo láti ṣe alábapín nínú àwọn ìlànà àti láti gba àti láti tún àwọn májẹ̀mú ṣe jẹ́ àmì pé a mọ ìgbẹ́kẹ̀lé wa sí Baba Ọrun àti Olùgbàlà wa, Jésù Krístì. Èyí yíò pe agbára Wọn sínú ayé wa láti rànwá lọ́wọ́ nínú gbogbo àwọn ìṣòro wa àti níkẹhìn kí ìwọ̀n ẹ̀dá wa di mímú ṣẹ.
Láìpẹ́ sẹ́hìn ipele ìrẹ̀lẹ̀ àti òye ti ìgbẹ́kẹ̀lé mi lórí Olúwa ní a dánwò lẹ́ẹ̀kánsii. Mo wà nínú takisí tó nlọ sí pápákọ̀ òfúrufú láti bá ọkọ̀ òfúrufú kan rìn fún àkókò kúkurú lọ sí ibi kan níbití ipò nínira púpọ̀ kan wà láti yanjú. Awakọ̀ takisí náà, tí kìí ṣe ọmọ ìjọ, wò mí nípasẹ̀ dígí ó sì sọ pé, “Mo ríi pé ara rẹ kò dára lónìí!”
“Ṣé o lè sọ?” Mo bèèrè.
“Dájúdájú,” o sọ. Nígbànáà ó sọ ohunkan bíi, “Lódodo óní ẹ̀mí àìdára gan ní àyíká rẹ!”
Mo ṣàlàyé fún un pé mo ní ipò ìnira kan láti kojú nígbà tó béèrè lọ́wọ́ mi pé, “Njẹ́ o ti ṣe gbogbo ohun tí agbára rẹ lè ṣe láti yanjú èyí?”
Mo fèsì pé mo ti ṣe ohun gbogbo tí mo tì le ṣe.
Nígbànáà ó sì sọ ohunkan tí èmi kò lè gbàgbé láé pé: “Nítorínáà, fi èyí lé Ọlọ́run lọ́wọ́, ohun gbogbo yíò sì jásí rere.”
Mo jẹ́wọ́ pé a dán mi wò láti bi í léèrè pé, “Ṣé o mọ ẹni tí ò nbá sọ̀rọ̀?” Ṣùgbọ́n èmi ò ṣeé! Ohun tí mo ṣe ni láti rẹ ara mi sílẹ̀ nínú àdúrà níwájú Olúwa ní gbogbo ìrìn-àjò òfúrufú wákàtí kan náà, ní bíbèèrè fún ìrànlọ́wọ́ àtọrunwá. Bí mo ṣe kúrò nínú ọkọ̀ òfuurufú náà, mo gbọ́ pé ipò ìṣòro láti yanjú ti ní étò àti pé wíwàníbẹ̀ mi kò ní pọndandan mọ́.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, àṣẹ náà, ìpè, àti ìlérí láti ọ̀dọ̀ Olúwa hàn kedere àti pé ó jẹ́ títuni-nínú: “Jẹ́ onírẹ̀lẹ̀; Olúwa Ọlọ́run rẹ yíò sì darí rẹ, yíò sì fún ọ ní ìdáhùn sí àdúrà rẹ.”10
Njẹ́ kí a jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ láti tẹ̀lé ìmọ̀ràn àwọn wòlíì wa kí a sì gba pé Ọlọ́run àti Jésù Krístì nìkan ló lè yí wa padà—nípasẹ̀ àwọn ìlànà àti àwọn májẹ̀mú tí a gbà nínú Ìjọ Rẹ̀—sí ẹ̀dà tiwa tí ó dára jùlọ ti ara wa ní ayé yìí àti, lọ́jọ́ kan, sọ wá di pípé nínú Kristi. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.