Alábàárìn Wa Ní Gbogbo Ìgbà
Ẹ̀yin àti èmi ní ànfàní láti ní Ẹ̀mí Mímọ́ bí alabarin ìgbàgbogbo wa.
Ẹ̀yin àyànfẹ́ arákùnrin àti arábìnrin mi, nínú ìpàdé àpapọ̀ yí a ti di alábùkún fún pẹ̀lú ìtújáde ìfìhan kan. Àwọn ìránṣẹ́ Olúwa Jésù Krístì ti sọ̀rọ̀ wọn ó sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ òtítọ́, ìgbani-níyànjú, àti ìdarí.
Mo ti gba ìfọwọ́tọ́ nípa àwọn ẹ̀rí tí a jẹ́ nínú ìpàdé àpapọ̀ yí pé Olúwa nsọ̀rọ̀ sí wa níti araẹni nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́. Bí a ti ngbàdúrà àti nígbànáà tí à ngbọ́ àwọn ìṣílétí Ẹ̀mí, a ó jèrè ìwòye àti ìbùkún títóbijùlọ láti tọ́ wá sọ́nà nínú àwọn ọjọ́ líle iwájú tí ó npọ̀ si.
A ti gbọ́ lẹ́ẹ̀kansi tí Ààrẹ Nelson kìlọ̀ fún wa pé “ní àwọn ọjọ́ tí nbọ̀, kò ní ṣeé ṣe láti wà láàyè nípa ti ẹ̀mí, láìsí ìtọ́nisọ́nà, dídarí, títùninínú àti ipa Ẹ̀mí Mímọ́ nígbàgbogbo.”16
Ìkìlọ̀ ti wòlíì ti darí mi láti jíròrò ohun tí mo lè kọ́ àwọn ọmọ mi, ọmọ-ọmọ, àti ọmọ-ọmọ-ọmọ nípa bí wọn ó ti ní ìtọ́sọ́nà pàtàkì ní àwọn ọjọ́ líle iwájú fúnra wọn.
Nítorínáà èyí ni ọ̀rọ̀ lẹ́tà ránpẹ́ sí àwọn àtẹ̀lé mi tí ó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbàtí èmi kò bá sí pẹ̀lú wọn ní àwọn ọjọ́ dídùnmọ́ni iwájú. Mo fẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí mo ti mọ̀ pé yíò ràn wọ́n lọ́wọ́.
Mo ti ní òye ohun tí yíò gbà fún wọn láti ní ipa ti Ẹ̀mí Mímọ́ nígbàgbogbo dáradára nínú àwọn ọjọ́ èyí tí à ngbé. Mo sì ti ní ìmọ̀lára wíwọnilọ́kan láti sọ̀rọ̀ ní òní nípa ìrírí araẹni mi nípa pípe Ẹ̀mí Mímọ́, ní sísúnmọ́ bí mo ti lè ṣe, láti jẹ́ alabarin mi nígbàgbogbo. Àdúrà mi ni pé kí nle gbà yín níyànjú láti ṣe bákannáà.
Èmi ó bẹ̀rẹ̀ láti ronú nípa àti láti gbàdúrà nípa àwọn ọmọ Hẹ́lámánì, Néfì àti Léhì, àti àwọn ìránṣẹ́ míràn ti Olúwa tí wọ́n nṣiṣẹ́ pẹ̀lú wọn. Wọ́n dojúkọ àtakò líle. Wọ́n nsìn ní ibi búburú wọ́n sì níláti kojú àwọn ẹ̀tàn tó burújáì. Mo ní ìgboyà, ẹ̀yin náà lè ní, látinú ẹsẹ kan yí látinú àkọsílẹ̀ Helaman:
“Àti nínú ọdún kọkàndínlọ́gọ́rin ni asọ̀ púpọ̀ bẹ̀rẹ̀sí wà. Ṣùgbọ́n ó sì ṣe tí Néfì àti Léhì, àti púpọ̀ nínú àwọn arákùnrin nwọn tí ó mọ̀ nípa àwọn ẹsẹ ìlànà ẹ̀kọ́ ìgbàgbọ́ nwọn, nítorípé nwọ́n ngba ìfihàn púpọ̀púpọ̀ lójojúmọ́, nítorínã nwọ́n sì nwãsù sí àwọn ènìyàn nã, tóbẹ̃ tí nwọ́n fi òpin sí àwọn asọ̀ nwọn nínú ọdún kannã.”2
Àkọsílẹ̀ yí gbà mí níyànjú, ó sì lè gà yín níyànjú. Àwọn ọmọkùnrin Helaman ni a kọ́ tí a sì tọ́sọ́nà nípasẹ̀ onírurú àwọn ìrirí pẹ̀lu Ẹ̀mí Mímọ́. Èyí fi dá mi lójú pé wọ́n lè kọ́wa nípasẹ̀ kí a sì kọ́ ẹkọ láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí ẹsẹ lórí ẹsẹ, ní gbígba ohun tí a nílò, àti pé nígbàtí a bá ṣetán, a ó gbà síi
A ti gbamí níyànjú ní ọ̀nà kannáà nípasẹ̀ àkọsílẹ̀ Néfì tí a ní kí ó padà lọ sí Jerusalem fún àwọn àwo Laban. Ẹ rántí àṣàyàn tí ó ṣe. Ó ṣe àṣàyàn kan, “Èmi yíò lọ láti ṣe àwọn ohun tí Olúwa ti pa láṣẹ.”3
Ìrírí Néfì pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́ lorí iṣẹ́ rírán náà ti fún mi ní ìgboyà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà nígbàtí mo ti bẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ tí mo mọ̀ pé ó jẹ́ iṣẹ́ yíyàn láti ọ̀dọ̀ Olúwa ṣùgbọ́n èyítí ó dàbí ẹnipé ó jìnnà tayọ ìrírí mi àtẹ̀hìnwá àti tayọ ohun tí mo rí bí okun mi.
Ẹ rántí ohun tí Néfì sọ nípa ìrírí rẹ̀: “Ó sì jẹ́ ní òru; mo sì mú kí [àwọn arákùnrin mi] ó fi ara wọn pamọ́ sí ẹ̀hìn odi. Lẹ́hìn tí wọ́n sì ti fi ara wọn pamọ́, èmi, Néfì, yọ́ kẹ́lẹ́ sí inú ìlú nlá náà mo sì lọ ní ìhà ilé Lábánì.”
Ó tẹ̀síwájú láti wípé, “A sì darí mi, nípasẹ̀ Ẹ̀mí, ní áìmọ tẹ́lẹ̀ àwọn ohun tí èmi ìbá ṣe.”5
A ti gbamí níyànjú nípa mímọ̀ pé Néfì jẹ́ títọ́sọ́nà nípasẹ̀ Ẹ̀mí ní ìṣẹ́jú sí ìṣẹ́jú jálẹ̀ òru náà lóri iṣẹ́ rírán ti Olúwa.
A nílò, ẹ ó sì nílò, ìbárin ti Ẹ́mí Mímọ́ nígbàgbogbo. Nísisìyí, a fẹ́ ẹ, ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀ a mọ̀ nípa ìrírí pé kò rọrùn láti ṣe àṣeyege rẹ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wa nrò a sì nsọ a sì nṣe àwọn ohun nínú ayé wa ojojúmọ́ tí ó lè mú Ẹ̀mí bínú.
Nígbàtí èyí bá ṣẹlẹ̀, bí yíò ti ṣe, a lè ní ìmọ̀lára àìfọwọ́sí láti ọ̀dọ̀ Olúwa. A sì lè gba àdánwò láti ní ìmọ̀lára pé a dá wà. Ó ṣe pàtàkì láti rántí ìlérí dídájú tí a ngbà ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ bí a ti nronúpìwàdà tí a sì nṣe àbápín oúnjẹ Olúwa: “Kí wọn ó lè ní Ẹ̀mí rẹ̀ láti wà pẹ̀lú wọn nígbàgbogbo.”5
Bí ẹ bá ti ní ìmọ̀lára agbara Ẹ̀mí Mímọ́ lóni, ẹ lè gbà á bí ẹ̀rí pé Ètùtù náà nṣiṣẹ́ nínú ayé yín.
Bí Alàgbà Jeffrey R. Holland ti wí: “Nígbàkugbà tí àwọn àkokò lílejù wọ̀nyí bá wá, a kò gbọ́dọ̀ juwọ́lẹ̀ sí ẹ̀rù pé Ọlọ́run ti pa wá tì tàbí Òun kò gbọ́ àwọn àdúrà wa. Ó máa ngbọ́ wa. Ó máa nrí wa. Ó máa nní ìfẹ́ wa.”6
Ìdánilójú náà ti ràn mi lọ́wọ́. Nígbàtí mo bá ní ìmọ̀lára jíjìnnà sí ọ̀dọ̀ Olúwa, nígbàtí àwọn ìdáhùn sí àdúrà mi bá dàbí pé ó pẹ́, mo ti kọ́ láti tẹ̀lé ìmọ̀ràn Ààrẹ Nelson láti yẹ ayé mi wò fún àwọn ànfàní láti ronúpìwàdà. Ó rán wa létí pé, “Ìronúpìwàdà ojoojúmọ́ ni ipá ọ̀nà sí ìwẹ̀mọ́, àti pé ìwẹ̀mọ́ nmú agbára wá.”7
Bí ẹ bá ri ara yín pé ẹ nní ìṣòro níní ìmọ̀lára Ẹ̀mí Mímọ́, ẹ lè jíròrò bóyá ohunkan wà fún èyítí ẹ nílò láti ronúpìwàdà kí ẹ sì gba ìdáríjì.8 Ẹ lè gbàdúrà pẹ̀lú ìgbàgbọ́ láti mọ ohun ṣíṣe láti di wíwẹ̀mọ́ àti nípa bayi kí a súnmọ́ dídi yíyege fún fífi ìgbàgbogbo jẹ́ alábàárìn ti Ẹ̀mí Mímọ́.
Bí ẹ bá fẹ́ láti gba jíjẹ́ alábàárìn Ẹ̀mí Mímọ́, ẹ gbọ́dọ̀ fẹ́ ẹ fún àwọn èrèdí tó tọ́. Àwọn èrèdí yín gbọ́dọ̀ jẹ́ àwọn èrèdí ti Olúwa. Bí àwọn èrò-inú yín bá jẹ́ ìmọtaraẹni-nìkan jù, yíò ṣòro fún yín láti gba àwọn ìṣílétí Ẹ̀mí.
Kókó náà fún mi àti fún yín ni láti fẹ́ ohun tí Olùgbàlà gbá. Èrò-inú wa níláti jẹ́ dídarí nípasẹ̀ ìfẹ́ aláìlábàwọ́n ti Krístì. Wọ́n nílò láti jẹ́ “Gbogbo ohun tí mo fẹ́ ni ẹ fẹ́. Ìfẹ́ Tìrẹ ni ká ṣe.”
Mo ngbìyànjú láti rántí ìrúbọ Olùgbàlà àti ìfẹ́ Rẹ̀ fún mi. Lẹ́hìnnáà, nígbàtí mo bá gbàdúrà sí Baba Ọ̀run láti ṣọpẹ́, mo nní ìmọ̀lára ìfẹ́ àti ìdánilójú pé àwọn àdúrà mi ti gbà àti pé èmi ó gba ohunkóhun tí ó dárajùlọ fún mi àti àwọn wọnnì tí mo fẹ́ràn. Ó nfún ẹ̀rí mi lókun
Nínú gbogbo àwọn ohun èyítí Ẹ̀mí Mímọ́ ti jẹri, èyítí ó ṣe iyebíye jùlọ fún wa lè jẹ́ pé Jésù ni Krístì, alààyè Ọmọ Ọlọ́run. Olùgbàlà ṣe ìlérí pé, “Nígbàtí Olùtùnú bá wá, ẹnití èmi ó rán sí yín láti ọ̀dọ̀ Baba, àní Ẹ̀mí òtítọ́, èyí tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Baba, òun ó jẹri nípa mi.”9
Ní àwọn ọdún sẹ́hìn, mo gba ìpè fóònù kan láti ọ̀dọ̀ iyà kan tó níyọnu. Ó wí fún mi pé ọmọbìnrin rẹ̀ ti kó lọ jìnnà kúrò nílé. Ó ròó látinú ìbásọ̀rọ̀ kékeré tí ó ní pẹ̀lú ọmọbìnrin rẹ̀ pé ohun kan kò tọ́nà gidi. Ó bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú mi láti ṣèrànwọ́.
Mo ṣe àwárí ẹni tí ó jẹ́ olùkọ́ni-ilé ọmọbìnrin rẹ̀. Ẹ lè sọ nípa orúkọ náà pé ó jẹ́ ìgbà pípẹ́ sẹ́hìn. Mo pè é. Ó jẹ́ ọ̀dọ́. Síbẹ̀síbẹ̀ ó wí fún mi pé àwọn méjèèjì, òun àti alabarin rẹ̀ ti ní ìtanijí ní òru náà, kìí ṣe pẹ̀lúàníyàn fún ọmọbìnrin náà nìkan, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìmísí pé ó fẹ́ ṣe àwọn àṣàyàn tí yíò mú ìbànújẹ́ àti ìkorò wá. Pẹ̀lú ìmísí ti Ẹ̀mí náà nìkan, wọ́n lọ láti rí i.
Ní àkọ́kọ́ òun kò fẹ́ sọ fún wọn nípa ipò rẹ̀. Lábẹ́ ìmísí, wọ́n bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ láti ronúpìwàdà kí ó sì yan ipa ọ̀nà tí Olúwa ní fún un. Ó mọ̀ nígbànáà, mo gbàgbọ́ pé nípasẹ̀ Ẹ̀mí, pé ọ̀nà kanṣoṣo tí wọ́n fi lè mọ ohun tí wọ́n mọ̀ nípa ayé rẹ̀ jẹ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ìyá kan yí àwọn àníyàn ìfẹ́ni rẹ̀ padà sí Baba Ọ̀run àti Olùgbàlà. A ti rán Ẹ̀mí Mímọ́ sí ilé àwọn olùkọ́ni-ilé wọnnì nítorí wọ́n nfẹ́ láti sin Olúwa. Wọ́n ti tẹ̀lé ìmọ̀ràn àti ìlérí tí a rí nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú pé:
“Kí inú rẹ pẹ̀lú kún fún ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ sí gbogbo ènìyàn, àti sí ará ilé ìgbàgbọ́, kí ìwa ọ̀run ó sì ṣe èrò ọkàn rẹ lọ́ṣọ̀ọ́ láì dáwọ́ dúró; nígbànáà ni ìfi ọkàn tán rẹ yíò ní agbára síi ní ọdọ̀ Ọlọ́run; àti ẹ̀kọ́ ti oyè àlùfáà yíò sàn térétéré sí orí ọkàn rẹ bí àwọn ìrì láti ọ̀run.
“Ẹ̀mí Mímọ́ yíò jẹ́ alabarin rẹ ní gbogbo ìgbà, àti pé ọ̀pá àṣẹ rẹ, ọ̀pá àṣẹ tí kíì yípadà ti ìṣòdodo àti òtìtọ́; àti ìjọba rẹ ìjọba àìlópin, àti láìsí ọ̀nà tipátipá yíò ṣàn sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láé àti títí láéláé.”10
Mo jẹri pé Olúwa ti pa ìlérí Rẹ̀ mọ́. Ẹ̀mí Mímọ́ ni a nrán sí àwọn olotitọ onimàjẹ̀mú ọmọ Ìjọ Jésù Krístì. Nínisìyí, àwọn ìrírí yín yíò jẹ́ àrà ọ̀tọ̀, Ẹ̀mí yíò sì ṣe ìtọ́sọ́nà ní ọ̀nà tí ó dára jùlọ tí a mú yẹ sí ìgbàgbọ́ àti agbára yín láti gba ìfihàn fún yín àti fún àwọn wọnnì tí ẹ fẹ́ràn tí ẹ̀ sì nsìn. Mo gbàdúrà pẹ̀lú ọkàn mi pé ìgbẹ́kẹ̀lé yín yíò dàgbà.
Mo jẹ́ ẹ̀rí mi pé Ọlọ́run Baba wà láàyè. Ó fẹ́ràn yín. Ó ngbọ́ gbogbo àdúrà yín. Jésù Krístì gbàdúrà sí Baba láti rán Ẹ̀mí Mímọ́ láti ṣe ìtọ́sọ́nà, ìtùnú, kí ó sì jẹri nípa òtítọ́ náà fún wa. Baba àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀ farahàn sí Joseph Smith nínú igbó ṣúúrú àwọn igi. Wòlíì Joseph Smith ṣe ìyírọ̀pada Ìwé ti Mọ́mọ́nì nípa ẹ̀bùn àti agbára Ọlọ́run.
Àwọn ìránṣẹ́ tọ̀run mú àwọn kọ́kọ́rọ́ oyè-àlùfáà padàbọ̀sípò. Ààrẹ Russell M. Nelson ni wòlíì Ọlọ́run fún gbogbo ilẹ̀ ayé.
Bí ẹlẹri Jésù Krístì kan, mo mọ̀ pé Ó wà láàyè ó sì ndarí Ìjọ Rẹ̀. Ẹ̀yin àti èmi ní ànfàní láti ní Ẹ̀mí Mímọ́ bí alabarin wa ní gbogbo ìgbà kí a sì ní àwọn òtítọ́ wọnnì ní fífi ẹsẹ̀ múlẹ̀ bí a ti nrántí tí a sì nní ìfẹ́ Olùgbàlà, ronúpìwàdà, tí a sì nbèèrè fún ìfẹ́ Rẹ̀ láti wà nínú ọkàn wa. Mo gbàdúrà pé kí a lè ní ìbùlún àti ìbárìn Ẹ̀mí Mímọ́ ní ọjọ́ yí àti ní gbogbo ọjọ́ ayé wa. Mo fẹ́ràn yín. Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.