Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Njẹ́ Ẹ Fẹ́ Ní Ìdùnnú?
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́wàá 2023


47:28

Njẹ́ Ẹ Fẹ́ Ní Ìdùnnú?

Ẹ dúró ní ipá-ọ̀nà májẹ̀mú. Ìgbésí ayé yín yìó rọrùn, yío nídùnnú síi, yìó sì kún fún ayọ̀.

Njẹ́ ẹ fẹ́ ní ìdùnnú? Kíni ó nmú inú yin dùn? Ààrẹ Nelson wípé: “Bí ẹ bá fẹ́ ní ìbànújẹ́, ẹ rú àwọn òfin—kí ẹ má sì ṣe ronúpìwàdà. Bí ẹ̀yin bá fẹ́ ayọ̀, ẹ̀ dúró ní ipa-ọ̀nà májẹ̀mú.”1 Njẹ́ kò ha rọrùn láti ní ìdùnnú? Ẹ dá àwọn májẹ̀mú kí ẹ sì pa wọ́n mọ́ ní ayé yín. Ẹ jẹ́ kí a gbé àwọn ohun kan tí ó lè rànwálọ́wọ́ láti dúró ní ipa-ọ̀nà májẹ̀mú yẹ̀wò.

Kíni ipa-ọ̀nà májẹ̀mú?

Bí Alàgbà Dale G. Renlund ti wí, “Ọ̀rọ̀ náà ipa-ọ̀nà májẹ̀mú tọ́ka sí oríṣiríṣi májẹ̀mú nípa èyítí a fi nwá sọ́dọ̀ Krístì tí a sì nso mọ́ Ọ. Nípasẹ̀ ísopọ̀ májẹ̀mú yí, a ní ààyè sí agbára ayérayé Rẹ̀. Ipa-ọ̀nà bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì àti ìrònúpìwàdà, ìrìbọmi ni ó tẹ̀le àti gbígba Ẹ̀mí Mímọ́.”3 A nṣe ìsọdọ̀tun àwọn májẹ̀mú wọ̀nyí ní gbogbo àkókò tí a bá kópa nínú oúnjẹ Oluwa.

Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú májẹ̀mú ìrìbọmi, a ṣe àwọn májẹ̀mú púpọ̀ síi jálẹ̀ ìgbésí ayé wa. Lẹ́ẹ̀kan sí i, Alàgbà Renlund wí pé: “Ipa-ọ̀nà májẹ̀mú náà ndarí sí àwọn ìlànà ti tẹ́mpìlì, bíi irú ẹ̀bùn tẹ́mpìlì. Ẹ̀bùn tẹ́mpìlì náà jẹ́ ẹ̀bùn Ọlọ́run ti àwọn májẹ̀mú mímọ́ tí ó so wa pọ̀ ní kíkún síi sí Òun.”4

2. Njẹ́ Ẹ wà ní Ipá-Ọ̀nà Májẹ̀mú?

Nígbà míràn nígbàtí a bá dá àwọn májẹ̀mú, a máa nkùnà láti pa wọ́n mọ́. Nígbàtí èyí bá ṣẹlẹ̀, báwo ni ẹ ṣe lè padà sí ipa-ọ̀nà májẹ̀mú? Jẹ́ kí nṣe àbápín àwọn àpẹrẹ ti pípadà sí ipa-ọ̀nà májẹ̀mú náà.

Ní nkan bí oṣù kan sẹ́hìn, mo gba ọ̀rọ̀ kàn látọ̀dọ̀ ìránṣẹ́ ìhìnrere kan tó ti padà sílé, ẹnití ó sìn pẹ̀lú wa. Ó wípé: “Àwọn àkókò tí ó kẹ́hìn ti jẹ́ líle. Jíja ìjàkadì pẹ̀lú àìbalẹ̀ ọkàn àti ìbànújẹ́ ojojúmọ́ ti nrẹ̀mí sílẹ̀, ó sì nira púpọ̀. Mo nímọ̀lára àdánikanwà àti pé mo kàn nbanújẹ́. Mo ti ngbàdúrà fún ìtọ́sọ́nà ti Baba wa Ọ̀run fún àláfíà àti ìtùnú nínú ohun tí mo lè ṣe láti kojú ìnira náà. … Nígbà tí mo ngbàdúrà, mo nímọ̀lára ìṣílétí tí ẹ̀mí nsọ fún mi pé mo ní láti san ìdámẹ́wàá mi ní kíkún. … Mo nímọ̀lára ẹ̀mí tó lágbára, àti pé lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ mo nímọ̀lára ìyára láti ṣe bẹ́ẹ̀. Pẹ̀lú ìfẹ́ inú láti ṣe bẹ́ẹ̀, mo nímọ̀lára ìṣílétí pé ‘bí o bá san ìdámẹ́wàá rẹ ohun gbogbo yíò Dára.‘ Mo ṣì ntiraka síbẹ̀ láti rí àláfíà, ṣùgbọ́n mo ní ẹ̀rí kan nínú Olùgbàlà wa àti pé nípasẹ̀ ìgbọ́ràn mi, mo lè nímọ̀lára kí èmi ó sì rí àláfíà tí mo nwá nínú ọkàn àti inú mi. Mo ti pinnu láìpẹ̀ yi láti padà wá sí ìjọ àti láti wá ẹ̀mí nínú gbogbo ohun tí mò nṣe.”

Nísisìyí ó nṣe dáradára gidi. Ẹyin bákannáà lè béèrè lọ́wọ́ Baba Ọ̀run fún àláfíà, ṣùgbọ́n ìdáhùn lè yàtọ̀ sí ohun tí ẹ nírètí pé yíò jẹ́. Níwọ̀n ìgbà tí ẹ bá nwá láti mọ Olùgbàlà tí ẹ sì gbàdúrà sí Baba Ọ̀run, Òun yíò fún yín ní ìdáhùn àdáni fún yín.

Ààrẹ Thomas S. Monson kọ́ni:

“Ẹ̀kọ́ títóbi jùlọ tí a lè kọ́ nínú ayé ikú ni pé nígbàtí Ọlọ́run bá sọ̀rọ̀ tí a sì gbọràn, a ó máa fi ìgbà gbogbo ṣe èyítí ó tọ́.”4

“Nígbàtí a bá pa àwọn òfin mọ́, ìgbésí ayé wa yíò nídùnnú síi, yío di mímúṣẹ síi, yío sì dínkù ní lílọ́lù. Àwọn ìpèníjà wa àti àwọn wáhálá yíò rọrùn síi láti gbàmọ́ra, a ó sì gba àwọn ìbùkún tí [Ọlọ́run] ti ṣe ìlérí.”5

Nígbàtí wọ́n pè mí láti jẹ́ bíṣọ́ọ̀pù, ó jẹ́ àkókò tó le jù nínú ìgbésí ayé mi. Mo jẹ́ ọ̀dọ́ baba ní ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ̀n ọdún mi, ṣùgbọ́n mo wà nínú ìṣòro owó nítorí àwọn ìpèníjà ẹbí. Èmi kò lè rí ojútùú eyikeyi, mo sì rò pé àwọn ìpèníjà náà kò ní dópin láé. Mo ti rẹ̀wẹ̀sì nípa ti owo àti ti ìmí-ẹ̀dùn. Mo bẹ̀rẹ̀ síí ṣiyèméjì nípa okun mi pẹ̀lú. Ní àkókò ìṣòro náà ni ààrẹ èèkàn nawọ́ ìpè náà sí mi. Mo gba ìpè náà lọ́nàkọnà, bíótilẹ̀jẹ́pé ó le.

Ìyàwó mi bákannáà ní ìfọ̀rọ̀-wáni-lẹ́nuwò pẹ̀lú ààrẹ èèkàn, ṣùgbọ́n kò lè sọ pé bẹ́ẹ̀ni, kò sì sọ pé rárá bẹ́ẹ̀náà ṣùgbán o tẹramọ́ wíwa omijé lójú. Ó sọkún fún gbogbo ọ̀sẹ̀ náà, ó béèrè lọ́wọ́ Baba Ọ̀run, “Ó ṣe jẹ́ ìsinsìnyí?” àti pé “Njẹ́ ẹ mọ ẹni kọ̀ọ̀kan nítòótọ́?”?” Kò rí ìdáhùn gbà, ṣùgbọ́n a mú mi dúró bí bíṣọ́ọ̀pù ní ọjọ́ ìsinmi tí ó tẹ̀ lé e. Kò bi Baba Ọ̀run léèrè àwọn ìbéèrè wọ̀nnì mọ́ ṣùgbọ́n ó tì mí lẹ́hìn nínú ìpè mi fún ọdún mẹ́fà.

Ní ọjọ́ Ọjọ́ Ìsinmi tí wọ́n dámi sílẹ̀, ìyàwó mi gbọ́ ohùn kan nígbà tó ngba oúnjẹ Olúwa. Ohùn náà sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sí i pé, “Nítorí pé ó ṣòro fún ọ láti rìn, mo pè òun bí bíṣọ́pù láti dì ọ́ mú kí ó sì máa rìn fún ọ.” Nígbàtí ó ronúpadà sí ọdún mẹ́fà sẹ́hìn, ó rí i pé gbogbo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpèníjà tí ó dà bí èyí tí kò lópin ni a ti yanjú nísisìnyí ní ojú ọ̀nà.

A kẹ́kọ̀ọ́ pé nígbàtí a bá rò pé kò dára fún wa láti gba ìpè, ó lè jẹ́ àkókò tí a nílò ìpè náà jùlọ. Nígbàkugbà tí Olúwa bá pè wá láti sìn nínú eyikeyi ìpè, bóyá ó jẹ́ ìpè fífúyẹ́ tàbí tí ó wúwo, Ó rí àwọn àìní wa. Ó npèsè okun tí a nílò ó sì ní àwọn ìbùkún ní ṣíṣe tán láti dà jáde sórí wa bí a ṣe nsìn pẹ̀lú ìṣòtítọ́.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkan míràn tún wà tó npín ọkàn wa níya kúrò ní dídúró lórí ipa-ọ̀nà májẹ̀mú. Ohun yòówù kó jẹ́, kò pẹ́ jù rí láé láti yí ọkàn wa padà sí Baba Ọ̀run fún ìrànlọ́wọ́. Alàgbà Paul V. Johnson kọ́ wa pé: “Nígbàtí a bá tẹ̀lé Sàtánì, a nfi agbára fun. Nígbàtí a bá tẹ̀lé Ọlọ́run, Ó nfún wa ní agbára.”6

Ọba Benjamin nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ ẹ̀rí pé: “Èmi yío fẹ́ pé kí ẹyin ronú lórí ipò alábùkún-fún àti ìdùnnú ti àwọn wọnnì tí wọ́n pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. Nítorí ẹ kíyèsi, wọ́n di alábùkúnfún nínú ohun gbogbo, méjèèjì níti-ara àti níti-ẹ̀mí; àti pé bí wọ́n bá dìí mú lódodo dé òpin a ó gbà wọ́n sí ọ̀run, pé nípa èyí wọn ó gbé pẹ̀lú Ọlọ́run nínú ipò inúdídùn tí kò nípẹ̀kun.”7

Báwo Ni Pípa Àwọn Májẹ̀mú Mọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run Ṣe Lè Mú Inú Yín Dùn?

Ìyàwó mi sọ pé ìgbéyàwó wa máa nso wá pọ̀, àti nítorí náà òun lè ṣe àwọn ohun tí òun kò lè ṣe tẹ́lẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, látì ìgbà tó ti wà ní ọ̀dọ́, ó máa nṣòro fún un láti jáde nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n kò ṣòro mọ́ nítorí pé mo máa nlọ pẹ̀lú rẹ̀. Ó jẹ́ ẹni kúkúrú kò sì lè dé àwọn sẹ́lífù gíga àyàfi bí ó bá lo àga tàbí àkàbà, ṣùgbọ́n mo lè mú àwọn nkan láti àwọn ṣẹ́lífù gíga fún un nítorí mo ga jù ú lọ. Gbígbà àjàgà Olùgbàlà wa sí orí wa rí bẹ́ẹ̀. Bí a ṣe so ara wa pọ̀ mọ́ Ọ, a lè ṣe àwọn ohun tí a kò lè ṣe fúnra wa nítorípé Òun lè ṣe àwọn ohun tí àwa kò lè ṣe fúnra wa.

Alàgbà David A. Bednar wí pé: “Dídá àti pípa àwọn májẹ̀mú mímọ́ mọ́ nso wá sí àti pẹ̀lú Olúwa Jésù Krístì. Ní pàtàkì, Olùgbàlà npè wá láti gbẹ́kẹ̀lé kí a sì fà papọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀, àní bíótilẹ̀jẹpè ìgbìyànjú wà tí ó dára jùlọ kò dọ́gba a kò sì lè ṣe àfiwé pẹ̀lú Tirẹ̀. Bí a ṣe nní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú tí a sì nfa ẹrù wa pẹ̀lú Rẹ̀ nínú ìrìnàjò ayé ikú, nítòótọ́ àjàgà Rẹ̀ rọrùn ẹrù Rẹ̀ sì fúyẹ́.”8

Ààrẹ Nelson ti kọ́ni bákannáà:

“Síso ara yín pẹ̀lú Olùgbàlà túmọ̀ sí pé ẹ ní ààyè sí okun àti agbára ìràpadà Rẹ̀.”9

“Èrè fún pípa àwọn májẹ̀mú mọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ni agbára àtọ̀runwá—agbára tí ó nfún wa lokun láti kojú àwọn ìpèníjà, ìdánwò, àti ìrora-ọkàn dáadáa. Agbára yí nmú ọ̀nà wa rọrùn. Àwọn tí wọ́n ngbé ìgbé ayé àwọn òfin ti Jésù Krístì gígajù ní ààyè sí agbára Rẹ̀ gígajú.”10

“Pípa májẹ̀mú mọ́ nmú ayé rọrùn nítòótọ́! Ẹnìkọ̀ọ̀kan tí ó ndá àwọn májẹ̀mú nínú àwọn àwo ìrìbọmi àti nínú àwọn tẹ́mpìlì—tí wọ́n sì npa wọn mọ́—ní ààyè púpọ̀ sí agbára ti Jésù Krístì.”11

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, njẹ́ ẹ fẹ́ ní ìdùnnú? Ẹ Dúró ní Ipá-ọ̀nà Májẹ̀mú Ìgbésí ayé yín yìó rọrùn, yío nídùnnú síi, yìó sì kún fún ayọ̀. Olùgbàlà wa npè, “Ẹ wa sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ó ńṣiṣẹ́, tí a sì di ẹrù wúwo lé lórí, èmi yíò sì fi ìsinmi fún yín.”12 Òun ni Krístì alààyè. Ó nru ẹrù wa ó sì nmú kí ìgbésí ayé wa rọrùn si. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.