Ọlọ́run mọ̀ Ó sì fẹ́ràn yín.
Ètò ìdùnnú Ọlọ́run wa nípa yín. Ojúlówó Ọmọ Rẹ̀ tí ó níye nlá ni yín.
Ní ọdún mẹ́fà sẹ́hìn ẹbí wa nrìnrìn àjò lọ lálẹ́ ni ìta ìlú nlá Oxford. Gẹ́gẹ́bí ó ti sábà máa nrí pẹ̀lú àwọn ọmọdé, a ní láti dúró nítorí náà a rí ibùdó ìpèsè kan tí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé ìtajà àti ilé oúnjẹ. Pẹ̀lú ìpéye, a tò jáde kúrò nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, a ṣabẹ̀wò àwọn ìpèsè náà, a sì tò padà wọlé, a tún bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wa.
Ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lẹ́hìn náà ọmọkùnrin wa àgbà béèrè ìbéèrè pàtàkì kan pé: “Níbo ni Jasper wà?” Jasper máa fìgbàgbogbo jókòó láyè ara rẹ ní ẹ̀hìn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà. A lérò pé ó ti sùn tàbí ó nfi ara rẹ̀ pa mọ́ tàbí ó nṣe ẹ̀tàn lé wa lórí ni.
Bí arákùnrin rẹ̀ ṣe yẹ ẹ̀hìn ọkọ̀ náà wò dáadáa, a rí i pé ọmọkùnrin wa ọmọ ọdún marun kò sí níbẹ̀. Ọkàn wa kún fún ìbẹ̀rù. Bí a ṣe yí ọkọ̀ padà láti padà sí ibùdó iṣẹ́ ìsìn, a bẹ Baba Ọ̀run pé kí Jasper wà ní ààbò. A pe ọlọ́pàá a sì sọ ipò náà fún wọn.
Nígbà tí a débẹ̀ pẹ̀lú ìdàníyàn, ní ohun tí ó lé ní ogójì ìṣẹ́jú lẹ́hìnnáà, a rí ọkọ̀ ọlọ́pàá méjì nínú ọgbà ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, àwọn ìmọ́lẹ̀ ntàn. Jasper wà nínú ọ̀kan nínú wọn, tí ó nfi bọ́tìnì ṣeré. Mi ò lè gbàgbé ìmọ̀lára ìdùnnú tí a ní nígbà tí a tún darapọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ olówe ti Olùgbàlà dojúkọ àkójọpọ̀, mímúpadàbọ̀sípò, tàbí lílàkàkà láti wá èyí tí ó ti túká tàbí tí ó sọnù. Lára ìwọ̀nyí ni òwe ti àgùtàn tí ó sọnù, owo tí ó sọnù, àti ọmọ tí ó sọnù.1
Gẹ́gẹ́bí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí pẹ̀lú Jasper ti rí nínú ọkàn mi láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, mo ti ronú lórí ìdánimọ̀ àtọ̀runwá àti ìjẹ́pàtàkì àwọn ọmọ Ọlọ́run, agbára ìràpadà Jésù Krístì, àti ìfẹ́ pípé ti Baba ní Ọ̀run, tí ó mọ̀ ẹ̀yin àti èmi. Mo nírètí láti jẹ́ ẹ̀rí àwọn òtítọ́ wọ̀nyí lónìí.
I. Ẹ̀yin Ọmọ Ọlọ́run
Ayé jẹ́ ìpèníjà. Ọ̀pọ̀ ènìyàn nímọ̀lára pé wọ́n ní rẹ̀wẹ̀sì, wọ́n dánìkanwà, dádúró, tàbí pé ó rẹ̀ wọ́n. Nígbà tí nkan bá le koko, a lè máa rò pé a ti rìn kiri tàbí a ti ṣubú sẹ́hìn. Mímọ̀ pé gbogbo wa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run àti ọmọ ẹbí Rẹ̀ ayérayé yíò mú ipò jíjẹ́ àti èrèdí padàbọ̀sípò.2
Ààrẹ Ballard ṣe àbápín pé: “Ìdámọ̀ pàtàkì kan wà tí gbogbo wa ṣe àbápín nísisìyí àti títí láé. … Ìyẹn ni pé ẹ jẹ́ àti pé ẹ ti jẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin Ọlọ́run nígbàgbogbo. … Lílóye òtítọ́ yìí—lílóye rẹ̀ dájúdájú àti fífara mọ́ ọn—jẹ́ ìyípadà ìgbésí ayé.”3
Ẹ máṣe àìlóye tàbí dín bí ẹ ṣe jẹ́ pàtàkì sí Baba yín ní Ọ̀run kù. Ẹ̀yin kìí ṣe ìyọrísí àìròtẹ́lẹ̀ àbínibí, ọmọ òrukàn àgbà ayé, tàbí ábájáde ti ọ̀rọ̀ pẹ̀lú àkókò pẹ̀lú ààyè. Níbití ìṣètò wa, ni oníṣe wa.
Ayé yín ní ìtumọ̀ àti èrèdí. Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere ti Jésù Krístì tó nlọ lọ́wọ́ nmú ìmọ́lẹ̀ àti òye wá nípa ìdánimọ̀ àtọ̀runwá yín. Ẹ jẹ́ olólùfẹ́, olùfẹ́ni ọmọ Baba Ọ̀run. Ẹ̀yin ni kókó-ọ̀rọ̀ ti gbogbo àwọn òwe àti àwọn ikẹkọ wọnnì. Ọlọ́run fẹ́ yín tó bẹ́ẹ̀ tí Ó fi rán Ọmọ Rẹ̀, láti wòsàn, gbàsílẹ̀, àti láti ṣe ètùtù fún yín.4
Jésù Krístì mọ iyì àbínibí tọ̀run àti iye ayérayé ti ẹnìkọ̀ọ̀kan.5 Ó ṣàlàyé bí àwọn òfin nlá méjèèjì láti fẹ́ràn Ọlọ́run àti láti fẹ́ràn aládùúgbò wa ṣe jẹ́ ìpìlẹ̀ gbogbo àwọn òfin Ọlọ́run.6 Ọ̀kan nínú iṣẹ́ àtọ̀runwá ni láti tọ́jú àwon tí ó jẹ́ aláìní.7 Èyí ni ìdí tí àwa gẹ́gẹ́bí ọmọ ẹ̀hìn Jésù Krístì “a máa ru ẹrù ara wa, …ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú àwọn tí nṣọ̀fọ̀ … , àti láti tu àwọn tí wọ́n nílò ìtùnú nínú.”8
Ẹ̀sìn kìí ṣe nípa ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run nìkan; ó tún jẹ́ nípa ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú ara wa. Alàgbà Holland ṣàlàyé pé ọ̀rọ̀ Gẹ̀ẹ́sì náà ẹ̀sìn wá láti inú ọ̀rọ̀ Látìn náà religare, tó túmọ̀ sí “láti dè” tàbí, níti ọ̀rọ̀ gan, “láti tún dè.” Nípa bẹ́ẹ̀, “ẹ̀sìn tòótọ́ [ni] ìdè tí ó so wa mọ́ Ọlọ́run àti pẹ̀lú ara wa.”9
Bí a ṣe nhùwà sí ara wa ṣe kókó lotitọ. Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni, “Ọ̀rọ̀ Olùgbàlà ṣe kedere: Àwọn ọmọ ẹ̀hìn Rẹ̀ tòótọ́, gbésókè, gbàníyànjú, yílọ́kàn padà, àti mímísí.”10 Èyí pàápàá ṣe pàtàkì jùlọ nígbàtí àwọn arìrìn àjò ẹlẹgbẹ́ wa ba nímọ̀lára sísọnù, dídánìkanwà, dìgbàgbé, tàbí yọkúrò.
A ò ní láti wò jìnnà láti wá àwọn ènìyàn tó ntiraka. A lè bẹ̀rẹ̀ nípa ríran ẹnì kan lọ́wọ́ nínú ẹbí wa, ìpéjọ, tàbí ládùúgbò wa. A tún lè wá ọ̀nà láti mú ìjìyà 700 mílíọ̀nù ènìyàn tí wọ́n ngbé nínú ipò òṣì púpọ̀ kúrò11 tàbí 100 mílíọ̀nù ènìyàn tí wọ́n fipá mú wọn kúrò ní ipò wọn nítorí inúnibíni, ìja, àti ìwà ipá.12 Jésù Krístì ni àpẹẹrẹ pípé ti bíbójútó àwọn aláìní—àwọn tí ebi npa, àwọn àjèjì, àwọn aláìsàn, àwọn òtòṣì, àwọn tí wọ́n wà lẹ́wọ̀n. Iṣẹ́ Rẹ̀ ni iṣẹ́ wa.
Alàgbà Gong kọ́ni pé “Ìrìn àjò wa sí Ọlọ́run ni a sábà máa nrí papọ̀.”13 Bí bẹ́ẹ̀, àwọn wọ́ọ̀dù wá yẹ kí ó jẹ́ ìbí ààbò fún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run. Njé a máa nlọ sí ilé-ìjọsìn láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ tàbí à ndá àwọn ìletò tí èrèdí wọn jẹ́ láti jọ́sìn sílẹ̀, rántí Krístì, kí a sì máa ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún ara wa bí?14 A lè tẹ̀lé ìmọ̀ràn Ààrẹ Nelson láti dájọ́ díẹ̀ síi, ní ìfẹ́ púpọ̀ síi, kí a sì nawọ́ ìfẹ́ mímọ́ ti Jésù Krístì nípasẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa.15
II Agbára Ìwòsàn ti Jésù Krístì
Ètùtù Jésù Krístì ni ìfihàn ìfẹ́ tí ó gajùlọ Baba wa Ọ̀run sí àwọn ọmọ Rẹ̀.16 Ọ̀rọ̀ náà ètùtù ṣàpèjúwe ìtòlẹ́sẹẹsẹ “ní ọ̀kan” ti àwọn tí a ti yà sọ́tọ̀ tàbí tí a yà nípa.
Ìṣe pàtàkì ti Olùgbàlà wa ni láti pèsè ọ̀nà méjèèjì láti padà sí ọ̀dọ̀ Baba Ọ̀run àti láti ṣe ìrànlọ́wọ́ ní ìrìn-àjò náà. Olùgbàlà mọ̀ nípa ìrírí Rẹ̀ bí ó ti lè ṣe àtìlẹ́hìn fún wa nípa àwọn ìpèníjà ayé.17 Ẹ máṣe ṣe àṣìṣe: Krístì ni olùgbàlà wa àti olùwòsàn ti ọkàn wa.
Bí a ṣe nlo ìgbàgbọ́, Ó nrànwá lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nínú ìnira. Ó tẹ̀síwájú láti nawọ́ ìpè ìfẹ́ni àti pẹ̀lú àánú Rẹ̀:
“Ẹ wa sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ó ńṣiṣẹ́ tí a sì di ẹrù wúwo lé lórí, èmi yíò sì fi ìsinmi fún yín.
“Ẹ gba àjàgà mi sí ọrùn yín, kí ẹ sì máa kọ́ ẹ̀kọ́ lọ́dọ̀ mi; … ẹ̀yin ó sí rí ìsinmi fún ọkàn yín.”18
Àkàwé àjàgà náà lágbára. Gẹ́gẹ́bí Ààrẹ Howard W. Hunter ṣe ṣàlàyé: “Àjàga jẹ́ ohun èlò kan … tí ó jẹ́ kí agbára ẹranko kejì ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìsapá ẹranko kan, pínpín àti dídín iṣẹ́ wíwúwo [iṣẹ́ tí ó wà lọ́wọ́] kù. Ẹrù kan tí ó le koko tàbí tí kò ṣeé ṣe fún ẹnì kan láti ru lè jẹ́ àìtọ́dọ́gba àti ìtùnú tí ẹni méjì bá so pọ̀ pẹ̀lú àjàgà tí ó wọ́pọ̀.”19
Ààrẹ Nelson kọ́ni: “Ẹ wá sọ́dọ̀ Krístì láti gba àjàgà pẹ̀lú Rẹ̀ àti pẹ̀lú agbára Rẹ̀, kí ẹ̀yin má baà dá nìkan fa ẹrù ayé. Ẹ̀yin nfa ẹrù ayé lọ́pọ̀lọpọ̀ pẹ̀lú Olùgbàlà àti Olùràpadà ayé.”20
Báwo ni a ṣe ngba àjàgà tàbí sopọ̀ mọ Olùgbàlà? Alàgbà David A. Bednar ṣàlàye:
“Dídá àti pípa àwọn májẹ̀mú mímọ́ mọ́ nso wá sí àti pẹ̀lú Olúwa Jésù Krístì. Ní àkójá, Olùgbàlà npè wá láti gbẹ́kẹ̀lé àti láti fà papọ̀ pẹ̀lú Rẹ. …
“A kò wà àti pé a kò sì nílò láti dánìkanwà.”21
Sí ẹnikẹ́ni tí á di ẹrù rù, tó sọnù, dàmú: Ẹ kò gbọdọ̀ dánìkan ṣe èyí.22 Nípasẹ̀ Ètùtù ti Krístì àti àwọn ìlànà Rẹ̀ ẹ lè gba àjàgà tàbí so pọ̀ mọ́ Ọ. Òun yìó fi ìfẹ́ pèsè okun àti ìwòsàn tí ẹ nílò láti kojú ìrìn-àjò tí ó wà níwájú. Òun ni ààbò lọ́wọ́ ìjì síbẹ̀.23
III. Ìfẹ́ ti Baba Ọ̀run
Fún àkọsílẹ̀ náà, Jasper jẹ́ ọlọgbọ́n, olùfẹ́ni, olóye, tí ó sì ṣòro. Ṣùgbọ́n kókó sí ìtàn yí ní pé ó jẹ́ tèmi. Ọmọ mì ni, àti pé mo ní ìfẹ́ rẹ̀ díẹ̀ si ju bí ó ṣe mọ̀ lọ. Bí aláìpé kan, baba ayé bá ní irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ nípa ọmọ rẹ̀, njẹ́ ẹ lè fojú inú wo bí Baba Ọ̀run tó jẹ́ ẹni pípé, ológo, olùfẹ́ni ṣe nímọ̀lára yín tó?
Sí àwon ọ̀rẹ́ mi ti ìran ti ó ndìde Gen Z ati Gen Alpha: ẹ jọ̀wọ́ ẹ mọ̀ pé ìgbàgbọ́ nílò iṣẹ́.24 A ngbé ní àkókò kan tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn gbà pé “ìrírí nìkan ni gbígbàgbọ́.” Ìgbàgbọ́ lẹ̀ jẹ́ ìpèníjà ó sì nílò àwọn àṣàyàn. Ṣùgbọ́n àdúrà ngbà.25 A sì lè ní ìmọ̀lára ìdáhùn.26 Díẹ̀ nínú àwọn ohun dídájú jùlọ ní ayé ni a kò rí; a nímọ̀lára, mọ̀, a sì ní ìrírí wọn. Àwọn náà dájú bákannáà.
Jésù Krístì nfẹ́ kí ẹ mọ̀ kí ẹ́ sì ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Baba yín ní Ọ̀run.27 Ó kọ́ni, “Ọkùnrin wo nínú yín, tí ó ní ọmọkùnrin kan, tí yíò sì dúró níta, tí yíò sì wí pé, Baba, ṣí ilé rẹ, kí èmi lè wọlé, kí nsì bá ọ jẹun, tí kì yíò wí pé, Wọlé, ọmọ mi; nítorí tèmi ni tìrẹ, tìrẹ si ni tèmi?”28 Njẹ́ ẹ lè ronú nípa ti araẹni díẹ̀ si, àwòrán olùfẹ́ni Ọlọ́run Baba Ayérayé bí?
Ọmọ Rẹ̀ ni yín. Bí ẹ bá ní ìmọ̀lára sísọnù, bí ẹ bá ní àwọn ìbéèrè tábì ṣàìní ọgbọ́n, bí ẹ bá ntiraka pẹ̀lú àwọn ipò yín tàbí jìjàkadì pẹ̀lú àìbìkítà ti ẹ̀mí, ẹ yípadà sí I. Ẹ gbàdúrà Si fún ìtùnú, ìfẹ́, àwọn ìdáhùn, àti ìdarí. Eyikeyi àìní àti ibikíbi tí ẹ bá wà, ẹ tú ọkàn yín jáde sí Bàbá yín Ọ̀run. Fún àwọn kan, ẹ lè fẹ́ tẹ̀lé ìpè Ààrẹ Nelson kí ẹ sì bèèrè “bóyá Ó wà níbẹ̀ lóòtọ́—tí Ó bá mọ̀ yín. Ẹ bèèrè lọ́wọ́ Rẹ̀ bí Òun bá ní ìmọ̀lára nípa yín. Àti pé nígbànáà ẹ fetísílẹ̀.”29
Ẹyin Arákùnrin àti Arábìnrin Ọ̀wọ́n:
-
Ẹ mọ Baba yín Ọ̀run. Ó jẹ́ pípé àti olùfẹ́ni.
-
Ẹ mọ ẹni tí Jésù Krístì jẹ́.30 Òun ni Olùgbàlà àti Olùràpadà wa. Ẹ so ara yín àti àwọn ti ẹ fẹ́ pọ̀ mọ́ Ọ.
-
Àti pé kí ẹ mọ ẹni tí ẹ jẹ́. Ẹ mọ ìdánimọ̀ àtọ̀runwá tòótọ́ yín. Ètò ìdùnnú Ọlọ́run wa nípa yín. Ojúlówó Ọmọ Rẹ̀ tí ó níye nlá ni yín. Ó mọ̀ Ó sì fẹ́ràn yín.
Nípa àwọn ohun wọ̀nyí ni mo jẹ́rìí ni orúkọ Jésù Krístì, àmín.