Oninakuna àti Ọ̀nà Tí Ó Darí Sílé
Bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn àṣàyàn lè ti mú wa jìnnà kúrò lọ́dọ̀ Olùgbàlà àti Ìjọ Rẹ̀, Olùkọ́ni Olùwòsàn dúró ní ọ̀nà tí ó darí sí ilé, ó nkí yín káàbọ̀.
Ọkùnrin Kan Ní Ọmọkùnrin Méjì
Àwọn kan ti pè é ní ìtàn kúkurújùlọ tí a sọ rí.1 Látìgbà tí a ti ṣe ìyípada sí àwọn ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn èdè káàkiri àgbáyé, ó ṣeéṣe gan pé ní ìgbà mìlẹ́níà méjì tó kọjá, òòrùn kò wọ̀ láìsí ìtàn tí à ntọ́ka sí níbikan ní àgbáyé.
A sọ́ nípasẹ̀ Jésù Krístì, Olùgbàlà àti Olùràpadà wa, ẹni tí ó wá sí ilẹ̀ ayé “láti gba èyí tí ó sọnù là.”2 Ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ jẹ́jẹ́ wọ̀nyí: “Ọkùnrin kan ní ọmọ méjì.”3
Lọ́gán ni a kọ́ nípa ìjà ìrora-ọ̀kan. Ọmọ kan4 wí fún baba rẹ̀ pé òun ti parí pẹ̀lú ìgbé ayé nílé. Ó nfẹ́ òmìnira rẹ̀. Ó nfẹ́ láti fi ọ̀làjú àtí àwọn ìkọ́ni òbí rẹ̀ sílẹ̀. Ó bèèrè fún ìpín ogún tirẹ̀—nísisìyí.5
Ṣe ẹ lè ro ohun tí baba náà ní ìmọ̀lára rẹ nígbàtí ó gbọ́ èyí? Nígbàtí ó damọ̀ pé ohun tí ọmọ rẹ̀ fẹ́ ju ohunkóhun lọ ni láti fi ẹbí náà sílẹ̀ àti pé bóyá kí ó máṣe padà mọ́?
Ètò Ìdáwọ́lé Nlá
Ọmọ náà ti gbúdọ̀ ní ìmọ̀lára híhàn ti ìdáwọ́lé àti ìdùnnú. Ní ìparí, ó wà ní àyè ara rẹ̀. Yíyọ kúrò nínú àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ àti àwọn òfin ọ̀làjú ọ̀dọ́ rẹ̀, ó lè ṣe àwọn àṣàyàn ti ara rẹ̀ nígbẹ̀hìn láìsí okun láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí rẹ̀. Kò sí ẹ̀bì. Òun lè yà sínú ìtẹ́wọ́gbà ti ìletò onínú-kannáà kí ó sì gbé igbé-ayé ni àayè ara rẹ̀.
Dídé orílẹ̀-èdè ní ọ̀nàjíjìn réré, ó tètè dọrẹ titun ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ngbé ìgbé ayé tí ó ti fìgbàgbogbo lá àlá rẹ̀ rí. Ó gbúdọ̀ ti jẹ́ olùfẹ́ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀, nítorí ó nlo owó rẹ̀ lọfẹ. Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ titun—àwọn alanfani ìnákúná rẹ̀—kò dá a lẹ́jọ́. Wọ́n ṣe ayẹyẹ, wọ́n yìn ín, wọ́n sì jẹ́ àṣíwájú àwọn àṣàyàn rẹ̀.6
Njẹ́ ìbákẹ́gbẹ́ ìròhìn ti wà ní ìgbà náà, dájúdájú òun ìbá ti kún àwọn ojú ewé pẹ̀lú àwọn fọ́tò ẹranko àwọn ọ̀rẹ́ tó nrẹrin: #Livingmybestlife! #Neverhappier! #Shouldhavedonethislongago!
Ìyàn
Ṣùgbọ́n àjọyọ̀ náà kò pẹ́—ó ṣọ̀wọ́n kí ó tó ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn ohun méjì ṣẹlẹ̀: àkọ́kọ́, owó rẹ̀ tán, àti ìkejì, ìyàn gba gbogbo ilẹ̀ náà.7
Bí àwọn ìdàmú ti nburú si, ó nbẹ̀rù. Ẹnìkan tí a kò lè dádúró, olùjayé gíga nísisìyí kò lè jẹ oúnjẹ ẹ̀ẹ̀kan, kí a tó sọ ti ibi tí ó lè dúró si. Báwo ni yíò ti yè?
Ó ti lawọ́ sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀—ṣé wọn yíò ràn án lọ́wọ́ nísisìyí? Mo lè rí i tí ó nbèèrè fún àtìlẹhìn kékeré—fún ìsisìyí nìkan—títí ó fi dìde lórí ẹsẹ̀ rẹ̀.
Àwọn ìwé mímọ́ wí fún wa pé, “Ẹnìkẹ́ni kò sì fifun.”8
Ní ìtara láti wà láàyè, ó rí àgbẹ̀ ìbílẹ̀ kan tí ó gbà á láti tọ́jú àwọn ẹlẹ́dẹ̀.9
Ebi npaá gidi nísisìyí, ó dánìkan wà a sì pàátì, ó gbúdọ̀ ti ya ọ̀dọ́mọkùnrin náà lẹ́nu bí àwọn ohunkan ṣe lè burú jáì, burú gan.
Kìí ṣe ẹbi inú nìkan ni ó ndàmú rẹ̀. Ebi ẹ̀mí òfo ni ó jẹ́. Ó ti da lójú gan pé jíjuwọ́lẹ̀ sí àwọn ìfẹ́ ayé rẹ̀ yíò mú inú rẹ̀ dùn, pé àwọn òfin ìwà ni àtakò sí ìdùnnú náà. Nísisìyí ó mọ̀ dáadáa. Àti pé ah, irú oyè tí ó ní láti san fún ìmọ̀ náà!10
Bí ebi ti ara àti ti ẹ̀mi ṣe npọ̀ si, èrò rẹ̀ padà sí baba rẹ̀. Ṣé yíò ràn án lọ́wọ́ lẹ́hìn gbogbo ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀? Àní onírẹ̀lẹ̀ jùlọ lára àwọn ìránṣẹ́ baba rẹ̀ ní oúnjẹ láti jẹ àti òrùlé látinú ìjì.
Ṣùgbọ́n ó padà sọ́dọ̀ baba rẹ̀?
Láéláé.
Jẹ́wọ́ sí ìletò rẹ̀ pé òun ti jẹ́ ogún òun run?
Kòṣeéṣe.
Dojúkọ àwọn aladugbo tí wọ́n ti kìlọ̀ fun dájúdájú pé òun ndójú ti ẹbí rẹ̀ àti pé ó nmú ìbànújẹ́ bá ọkàn àwọn òbí rẹ̀? Padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ àtijọ́ rẹ̀ lẹ́hìn gbígbéraga nípa bí ó ṣe gba ara rẹ̀ sílẹ̀?
Àìlègbàmọ́ra.
Ṣùgbọ́n, ebi, àdánìkanwà, àti pé àbámọ̀ kò kàn ní lọ kúrò—títí “òun ó fi di ararẹ̀ mú.”11
Ó mọ ohun tí ó nílò láti ṣe.
Ìpadàbọ̀
Nísisìnyí ẹ jẹ́ kí a lọ padà sí baba, olùkọ́ oníròbìnújẹ́ ọkàn ti ilé. Àwọn ọgọgọrun melo, bóyá ẹgbẹgbẹ̀rún, ti àwọn wákàtí tí ó ti lò ní dídàmú nípa ọmọ rẹ̀?
Ìgbà melo ni ó ti wo ọ̀nà gan tí ọmọ rẹ gba tí ó sì ntún àdánù wíwọnú ara tí ó ti ní ìmọ̀lára rẹ̀ yẹ̀wò bí ọmọ rẹ ti rìn lọ? Àdúra melo ni ó ti gbà ní òru jíjìn, tí ó nbẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run pé kí ọmọ rẹ̀ lè wà láláfíà, pé òun yíò rí òtítọ́, pé òun yíò padà wá?
Àti pé nígbànáà ní ọjọ́ kan, wo ọ̀nà ìta adánìkanwà—ọ̀nà tí ó darí sí ilé—ó sì rí àwòrán jíjìn kan tí ó nrìn sí iwájú rẹ.
Njẹ́ ìyẹn ṣeéṣe?
Bíótilẹ̀jẹ́ pé ẹni náà wà ní òkèrè, baba náà mọ ní kíákíá pé ọmọ òun ni.
Ó sáré pàdé rẹ̀, ó rọ̀mọ ní ọrùn, ó sì fi ẹnu kòó ní ẹnu.12
“Baba,” ọmọ náà kígbe jáde, nínú ọ̀rọ̀ tí ó ti kọ́ ní ẹgbẹ̀rún ìgbà, “èmi ti dẹ́ṣẹ̀ sí ọ̀run àti sí iwájú rẹ. Èmi kò sì yẹ ní ẹni tí à bá máa pè ní ọmọ rẹ̀ mọ́ . Gbogbo ohun tí mo bèèrè ni pé kí o fi mi ṣe bí ọ̀kan lára àwọn alágbàṣe rẹ̀.”13
Ṣùgbọ́n baba fẹ́rẹ̀ má jẹ́ kí ó parí. Pẹ̀lú omijé ní ojú rẹ̀, ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹ mú ààyò aṣọ wá kánkán, kí ẹ sì fi wọ̀ ọ́. Ẹ sì fi òrùka bọ̀ ọ́ ní ọwọ́ àti batà ní ẹsẹ̀ rẹ̀. Ẹ ṣe àpèjẹ láti ṣe ayẹyẹ. Ọmọ mi ti padà!”14
Ayẹyẹ
Nínú ibi iṣẹ́ mi ni a fi àwòrán kan kọ́ sí láti ọwọ́ ayàwòrán Richard Burde. Harriet èmí sì fẹ́ràn àwòrán yí. Ó fi ìran jẹ́jẹ́ kan hàn látinú òwe Olùgbàlà nínú ìrísí ìjinlẹ̀.
Nígbàtí gbogbo ènìyàn nyayọ gidi ní pípadà ọmọ náà, ẹnìkan kò rí bẹ́ẹ̀—arákùnrin rẹ̀ àgbà.15
Ó nru àwọn ẹrù ẹ̀dùn-ọkàn.
Ó wà níbẹ̀ nígbàtí arákùnrin rẹ̀ bèèrè fún ogun tirẹ̀. Ó ti jẹ́ ẹ̀rí lakọkọ nípa ìwọ̀n títóbi ti ọ̀fọ̀ lórí baba rẹ̀.
Láé láti ìgbà tí arákùnrin rẹ̀ ti lọ, ó ti gbìyànjú láti gbé àjàgà baba rẹ̀. Ní ojojúmọ́, ó ti ṣiṣẹ́ láti mú ìrora ọkàn baba rẹ̀ padàbọ̀sípò.
Àti pé nísisìyí ọmọ onírìnkurìn ti dé, àwọn ènìyàn kò sì lè dúró láti fun arákùnrin rẹ̀ olóríkunkun ní gbogbo àkíyèsí wọn.
“Ní gbogbo ọdún wọ̀nyí,” ó wí fún baba rẹ̀, “èmi kò sì kọ̀ rí láti ṣe ohun kankan tí ìwọ bèèrè. Síbẹ̀ ní gbogbo ìgbà náà, ìwọ kò ṣe ayẹyẹ fún mi.”16
Olùfẹ́ni baba náà fèsì, “Ọmọ ọ̀wọ́n, gbogbo ohun tí mo ní tìrẹ ni! Èyí kìí ṣe nípa ṣíṣe àfiwé èrè tàbí ayẹyẹ. Èyí jẹ́ nípa ìwòsàn. Èyí ni àkókò tí a ti nretí ní gbogbo ọdún wọ̀nyí. Arákùnrin rẹ ti kú ó sì tún yè lẹ́ẹ̀kansi! Ó nù ṣùgbọ́n nísisìyí a ti ri!”17
Òwe kan fún Ìgbà Wa
Ẹ̀yin olólùfẹ́ arákùnrin àti arábìnrin mi, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n, bíi ti gbogbo àwọn òwe Olùgbàlà, èyí yí kìí ṣe nípa àwọn ènìyàn tí wọ́n gbé tipẹ́tipẹ́ sẹ́hìn. Ó jẹ́ nípa ẹ̀yin àti èmi, ní òní.
Tani nínú wa tí kò ti kúrò ní ipa-ọ̀nà mímọ́, fífi àìlọ́gbọ́n ronú pé a lè rí ìdùnnú si ní lílọ ní ọ̀nà ìmọ̀tara ti ara wa?
Tani nínú wa tí kò tíì ní ìmọ̀lára ìrẹ̀lẹ̀, ìrora ọkàn, àti ìtara fún ìdáríjì àti àánú?
Àní bóyá ó ti yà wá lẹ́nu pé, “àní ṣé ó tilẹ̀ ṣeéṣe láti padà sẹ́hìn? Ṣé èmi ó gba àlébù títíláé, ìpatì, kí àwọn ọ̀rẹ́ mi tẹ́lẹ̀ sì yẹra fún mi? Njẹ́ ó dára jù láti dúró sípò ìsọnù? Báwo ni Ọlọ́run ó ti dáhùn bí mo bá gbìyànjú láti padà?”
Òwe yí fún wa ní èsì.
Baba wa Ọ̀run yíò sáré pàdé wa, ọkàn Rẹ̀ sì nṣànsílẹ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ àti àánú. Òun ó rọ̀mọ́ wa; fi aṣọ si lọ́rùn, òrùka ní ọwọ́ rẹ̀, bàtà ní ẹsẹ̀ rẹ̀; kí ẹ sì kéde, “A nṣe ayẹyẹ ní òní! Nítorí ọmọ mi, tí ó ti kú tẹ́lẹ̀, ti wá sí ayé!”
Ọ̀run ó yọ̀ ní ìpadàbọ̀ wa.
Ayọ̀ Àìlèsọ tí ó sì Kún fún Ògo
Njẹ́ kí nmú àkokò díẹ̀ nísisìyí kí nsì sọ̀rọ̀ sí yín lọ́kọ̀ọ̀kan?
Ohun èyí ó wù kí ó ṣẹlẹ̀ ní ilé ayé yín, mo tunsọ mo sì kéde àwọn ọ̀rọ̀ olólùfẹ́ ọ̀rẹ́ mi àti ọmọlàkejì Àpóstélì Alàgbà Jeffrey R. Holland: “Kò ṣeéṣe fún yín láti rẹlẹ̀ ju ìmọ́lẹ̀ àìlópin ti [ìrúbọ ètùtù] Krístì tí ó ndán.”18
Bíótilẹ̀jẹ́pé àwọn àṣàyàn wa lè ti mú wa jìnnà kúrò lọ́dọ̀ Olùgbàlà àti Ìjọ Rẹ̀, Olùkọ́ni Olùwòsàn dúró ní ọ̀nà tí ó darí sí ilé, ó nkí yín káàbọ̀. Àwa bí àwọn ọmọ Ìjọ Jésù Krístì nwá láti tẹ̀lé àpẹrẹ Rẹ̀ àti láti rọ̀mọ́ yín bí arákùnrin àti arábìnrin wa, bí àwọn ọ̀rẹ́ wa. À yayọ̀ a sì nṣe ayẹyẹ pẹ̀lú yín.
Ìpadà yín kò ní dín ìbùkún àwọn ẹlòmíràn kù. Nítorí ẹ̀bùn oore Baba jẹ́ àìlópin, àti pé ohun tí a fún ẹnìkan ní kíkéréjù kìí dín ẹ̀tọ́ ìbí àwọn ẹlòmíràn kù.19
Èmi kò díbọ́n pé pípadà bọ̀ jẹ́ ohun ìrọ̀rùn láti ṣe. Mo lè jẹ́ ẹ̀rí nípa ìyẹn. Nítòótọ́, ó lè, jẹ́ àṣàyàn líle jùlọ tí ẹ ó ṣe láéláé.
Ṣùgbọ́n mo jẹ́ ẹ̀rí pé ní àkokò tí ẹ bá pinnu láti padà tí ẹ sì rìn ní ọ̀nà Olùgbàlà àti Olùràpadà, agbára Rẹ̀ yíò wọnú ayé yín ẹ ó sì di yíyípadà.20
Àwọn ángẹ́lì ní ọ̀run yíò yayọ̀.
Bẹ́ẹ̀ sì ni àwa, ẹbí yin nínú Krístì. Lẹ́hìn gbogbo rẹ̀, a mọ ohun tí ó dàbí láti jẹ́ oninakuna. Gbogbo wa gbẹ́kẹ̀lé irú agbára ètùtù ti Krístì kannáà lójojúmọ́. A mọ ipa ọ̀nà yí, a ó sì rìn ín pẹ̀lú yín.
Rárá, ipa ọ̀nà wa kò ní ṣófo kúrò nínú ọ̀fọ̀, ìkorò, tàbí ìbànújẹ́. Ṣùgbọ́n a ti dé ibí yí “nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Krístì pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tí kò mì nínú rẹ̀, tí ẹ ngbẹ́kẹ̀lé gbogbo àṣepé rẹ̀ pátápátá, ẹni tí ó jẹ́ alágbára láti gbàlà.” Àti lápapọ̀ a ó “tẹ̀ síwájú pẹ̀lú ìdúróṣinṣin nínú Krístì, níní ìrètí pípé dídán, àti ìfẹ́ Ọlọ́run àti gbogbo [ènìyàn].”21 Lápapọ̀ a ó “yayọ̀ pẹ̀lú ayọ̀ Àìlèsọ tí ó sì Kún fún Ògo,”22 nítorí Jésù Krístì ni okùn wa!23
Ó jẹ́ àdúrà mi pé ọ̀kọ̀ọ̀kan lára wa lè gbọ́, nínú òwe ìjìnlẹ̀ yí, ohùn Baba tí ó npè wá láti wọ ọ̀nà tí ó darí sí ilé—kí a lè ní ìgboyà láti ronúpìwàdà, gba ìdáríjì, àti kí a tẹ̀lé ipa ọ̀nà tí ó darí padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run alaanu àti olùyọ́nú wa. Nípa èyí ni mo jẹ́ ẹ̀rí tí mo sì fi ìbùkún mi sílẹ̀ fún yín ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.