Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Bí Ayọ̀ Yín Ó Ti Pọ̀ Tó
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́wàá 2023


13:48

Bí Ayọ̀ Yín Ó Ti Pọ̀ Tó

Mo pè yín bayi láti mu “bí ẹ ti-mọ̀ yín,” àti pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí ìgbà-ọlá, kí ẹ sì lọ ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, èrò mi ní òní wà lórí kíkójọ Ísráẹ́lì, ohun tí Ààrẹ Russell M. Nelson pè ní “ohun tó ṣe pàtàkì jùlọ tí ó nṣẹlẹ̀ ní ilẹ̀ ayé ní òní. Kò sí ohun míràn tí a lè fi wé títóbi rẹ̀, kò sí ohun míràn tí a lè fi wé pàtàkì rẹ̀, kò sí ohun míràn tí a lè fi wé ọlánlá rẹ̀.”1

Ìkójọ náà ni ìdámọ̀ ìgbẹ̀hìn pé “àwọn ọkàn ṣe iyebíye níwájú Ọlọ́run.”2 Ó jẹ́ rírọrùn bí èyí. À nkó àwọn ọmọ Ọlọ́run jọ ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyí “ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbùkún ni ó rọ̀ lé wọn lórí”3 àti ìlérí ti “ọrọ̀ àìlópin.”4 Ó ntẹ̀lé pé láti kó Ísráẹ́lì jọ a nílò àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere—púpọ̀ si ju àwọn tí wọ́n nsìn.5 Ní òní mo nsọ̀rọ̀ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn àgbà olóye nínú Ìjọ tí wọ́n lè sìn bí àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere. Ọlọ́run nílò yín. A nílò yín ní New York àti Chicago, Australia àti Afríkà, Thailand àti Mexico, àti níbigbogbo ní àárín.

Ẹ jẹ́ kí nmú yín padà sí ọdún 2015. Mo jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá titun tí a ṣẹ̀ pè. Ọ̀kan lára àwọn ojúṣẹ ìyanu tí à ngbé bí Àpóstélì ni láti yan àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere sí pápá iṣẹ́ wọn. Mo ti kópa bí Àádọ́rin nínú ètò náà,6 ṣùgbọ́n nisisìyí, bí àpóstélì kan, mo ní ìmọ̀lára ìwọ̀n kíkún ti yíyànni síṣẹ́ náà. Mo bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àdúrà ní fífi oye púpọ̀ àwọn ọ̀dọ́ alàgbà àti àwọn obìnrin, ní ọ̀kan sí ọ̀kan, ní àwọn míṣọ̀n ní àyíká ayé. Nígbànáà, mo yípadà sí àwọn tọkọtayà àgbà. Àwọn mẹ́wá ni ó wà lórí ìtòsílẹ̀. Kìí ṣe púpọ̀ gan. Ní ìyàlẹ́nu, mo bèèrè lọ́wọ́ àwọn ẹlẹgbẹ́ mi láti Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìhìnrere, “Àwọn melo tí a nílò ní ọ̀sẹ̀ yí láti kún àwọn ìnílò wa?”

Ó fèsì, “Ọgọrun mẹ́ta.”

Àkokò ìfarabalẹ̀ ti dúró pẹ̀lú mi: tọkọtayà mẹwa láti kún àyè ọgọrun-mẹta.

Ààrẹ Russell M. Nelson ti gba àwọn tọkọtayà níyànjú láti “lọ sórí eékún wọn kí wọ́n sì bèèrè lọ́wọ́ Baba Ọ̀run bí àkókò bá tọ́ fún wọn láti sìn papọ̀.”7 Ó wípé, nínú gbogbo ìgboyè, “ìfẹ́ láti sìn lè jẹ́ pàtàkì jùlọ.”8

Bí ìwé-mímọ́ tí ó wípé, “Tí ẹ bá ní ìfẹ́ láti sin Ọlọ́run a pè yín sí iṣẹ́ náà.”7 Iṣẹ́ náà wà nípa òfin ìkórè. A ka nínú Jòhánù pé, “Kí ẹnití ó fúrúgbìn àti ẹnití ó nkórè lè jọ máa yọ pọ̀.”10

Mo ti rí tí òfin ìkórè wá sí ìmúṣẹ nínú ẹbí ara mi.

Àwọn ọdún díẹ̀ sẹ́hìn mò nbẹ ẹbí wò, nígbàtí bíṣọ́ọ̀pù ni kí nparí iṣẹ́ ìsìn oúnjẹ Olúwa.11 Bí mo ti nsọ̀kalẹ̀ láti orí pẹpẹ, obìnrin kan dé ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ méje ó sì fi ara rẹ̀ hàn bí Arábìnrin Rebecca Guzman.

Ó bèèrè, “Alàgbà Rasband, njẹ́ o mọ Rulon àti Verda Rasband?”

Inú mi dùn mo sì fèsì, “Àwọn ni òbí mi.”

Ẹ le rí ibití èyí nlọ. Pẹ̀lú ìfọwọ́sí Rebecca, ẹni tí ó wà pẹ̀lú ẹbí nihin ní gbàgede Ìpàdé Àpapọ̀, mo pín ìtàn ẹbí rẹ̀ ti ọdún marundinlọgbọ́n sẹ́hìn.12

Arábìntin Verda àti Alàgbà Rulon Rasband.

Àwọn òbí mi, Alàgbà Rulon àti Arábìnrin Verda Rasband, ni wọ́n sìn bí tọkọtayà àgbà ní míṣọ̀n Fort Lauderdale Florida.13 Wọn njìhìn ìhìnrere àti pé nípa ìtọ́nisọ́nà tọ̀run wọ́n kan ilẹ̀kùn ilé Rebecca. Ó jẹ́ ọ̀dọ́ ó sì fẹ́ràn láti fetísílẹ̀ sí orin Osmonds, ní pàtàkì ọ̀rẹ́ mi Donny—ẹni tí ó wà níbi ní òní.14 Ó ti fetísílẹ̀ sí ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ìròhìn wọn ó sì kọ́ pé wọ́n jẹ́ ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Ó ní ìmọ̀lára pé ohun kan wà tí ó yàtọ̀ nípa wọn, ó sì nròó pé ó lè jẹ́ ẹ̀sìn wọn, Rbecca lo ọdún méjì ní ṣíṣe ìwákiri ohun tí Ìjọ gbàgbọ́ ní ilé-ìwé yàrá ìkàwé. Nítorínáà, nígbàtí tọkọtayà tó dùnwò kan ilẹ̀kùn ẹbí rẹ̀ tí wọ́n sì fi ara wọn hàn bí àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn, ó yàá lẹ́nu.

“Ìyá mi wí fún mi pé kí nlé wọn jáde,” Rebecca kọ̀wé lẹ́hìnnáà pé, “ṣùgbọ́n ọkàn mi wípé, ‘Rárá.’ Mo wo inú ojú wọn, mo sì ní ìmọ̀lára ìyárí púpọ̀ àti ìfẹ́. Ìrántí náà ṣì nmú omijé wá sí ojú mi àti ẹ̀dùn-ọkàn ìjìnlẹ̀ sí ọkàn mi.”15

Rebecca pè wọ́n wọlé, àwọn òbí mi òjíṣẹ́ ìhìnrere sì pín ọ̀rọ̀ kan pẹ̀lú rẹ̀, àwọn arábìnrin rẹ̀ kékeré, àti, pẹ̀lú àtakò rẹ, ìyá rẹ̀.

Rebecca júwe fún mi pé: “Àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì jẹ́ ìyàlẹ́nu ní ṣíṣe àlàyé ìbèèrè kankan tí a ní. Mo ṣì lè rí ojú wọn bí ẹnipé ìmọ́lẹ̀ yí wọn ká. A máa ndìmọ́ ìyá rẹ ní gbogbo ìgbà tí ó bá nlọ ó sì máa nṣe àmì ríran ìyá mi lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára ìtùnú àti ọ̀wọ̀. Baba rẹ ní ìtànṣán kan ní ojú rẹ bí ó ti nkọ́ wa nípa Jésù Krístì. Ó gbìyànjú láti mú baba mi pẹ̀lú nínú ìbárasọ̀rọ̀ ó sì yege lórí rẹ̀ nígbẹ̀hìn. Baba mi ni olóúnjẹ ní kílọ́bù ìbílẹ̀ ìlú kan ó sì nse oúnjẹ alẹ́ fún àwọn òbí rẹ, pẹ̀lú ṣíṣe páì ọlọ́sànwẹ́wẹ́ tí baba rẹ fẹ́ràn gan.”16

Nígbàtí Alàgbà àti Arábìnrin Rasband ní kí Rebecca àti ẹbí rẹ ka Ìwé ti Mọ́mọ́nì, Rebecca ṣe bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ marun. Ó fẹ́ ṣe ìrìbọmi kíákíá, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹbí míràn kò tíì ṣetán. Lẹ́hìn oṣù mẹ́rin, Rebecca tẹnumọ pé kí òun ṣe ìrìbọmi kí òun sì darapọ̀ mọ́ Ìjọ òtítọ́. Ó rántí, “Gbogbo okun ẹ̀mí mi mọ̀ pé òtítọ́ ni.”17 Ní oṣù karun ọjọ́ karun, 1979, àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere ṣe ìrìbọmi fún Rebecca ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún, ìyá rẹ̀, àti arábìnrin méjì. Baba mi ni ajẹri níbi ìrìbọmi.

Nígbàtí mo pàdé Rebecca àti ẹbí rẹ̀ ní ilé-ìjọsìn, a ya fọ́tò ẹbí rẹ pẹ̀lú mi. Mo mu lọ sílé fún ìyá mi àgbàlagbà, ó sì dìí mú sí ọkàn rẹ̀. Lẹ́hìnnáà ó wí fún mi pé, “Ronnie, èyí ni ọ̀kan lára àwọn ọjọ́ ìdùnnú jùlọ nilé ayé mi.”

Àwọn Guzman, àwọn Rasband, àti àwọn Osmonds.

Èsì ìyá mi bẹ̀bẹ̀ fún ìbèèrè fún àwọn àgbà wa: “Kíní ẹ̀ nṣe ní àkókò ti igbé ayé yín yí?” Àwọn ọ̀nà púpọ̀ wà tí àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere àgbà fi lè ṣe ohun tí ẹlòmíràn kò lè ṣe. Ẹ jẹ́ ipa alámì fún rere, olóye nínú Ìjọ, wọ́n sì dúró láti gbaníyànjú kí wọ́n sì gba àwọn ọmọ Ọlọ́run là.

Àwọn kan lára yín lè máa ronú pé: “Ṣùgbọ́n báwo ni ti fífi àwọn ọmọ-ọmọ sílẹ̀? A ó tàsé àwọn ohun ìsàmì, ọjọ́ ìbí, ọ̀rẹ́, àní àti àwọn ohun ọ̀sìn wa.” Bí mo bá ti bèèrè lọ́wọ́ ìyá mi ìdí tí òun àti Baba fi lọ ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, mo mọ̀ pé òun ìbá ti wí bayi pé: “Mo ní àwọn ọmọ-ọmọ. Mo fẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé baba yín àti èmi sìn ní pápá iṣẹ́ ìránṣẹ́, a fẹ́ láti gbé àpẹrẹ kalẹ̀ fún ìrandíran wa, a sì di alábùkúnfún, alábùkúnfún gan.”

Bí mo ti bẹ àwọn ibi iṣẹ́ ìránṣẹ́ wò yíká àgbáyé, mo ti rí iṣẹ́ ìsìn alámì ti ẹgbẹ́ pàtàkì ti àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere àgbà wa. Ó hàn kedere pé inú wọn dùn láti ṣe “ìfẹ́ Olúwa” kí wọ́n sì wà nípa ṣíṣe “ìṣòwò Olúwa.”19

Fún àwọn kan, a sì ní ìrètí sí ẹgbẹgbẹ̀rún lára yín, pé iṣẹ́ ìsìn ìgbà-kíkún òjíṣẹ́ ìhìnrere ní igun míràn àgbáyé yíò jẹ́ ibi tí ó tọ́.20 Fún àwọn míràn, sísin iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìsìn-Ìjọ ní ilé lè jẹ́ ààyò. Nítori àwọn ọ̀ràn ìlera àti àwọn ipò míràn, àwọn tí wọn kò lè sìn wà. A ní òye àwọn ipò, yíò sì jẹ́ ìrètí mi tí ẹ bá lè wá àwọn ọ̀nà láti ti àwọn tí wọ́n nsìn lẹ́hìn. Ẹ tẹ̀lé àmọ̀ràn wòlíì kí ẹ sì gbàdúrà láti mọ ohun tí Olúwa yíò fẹ́ kí ẹ ṣe.

Àwọn pápá ibi iṣẹ́ ìránṣẹ́ yíká àgbáyé nbẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ yín. Ààrẹ Russell M. Nelson ti wí nípa àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere àgbà wa, “Wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ nínú ẹ̀mí, wọ́n lọ́gbọ́n, wọ́n sì nfẹ́ láti ṣiṣẹ́.”21

Ní ìtà pápá, ẹ ó ní àwọn ànfàní oríṣiríṣi: ẹ lè sìn níbi iṣẹ́ iṣẹ́-ìránṣẹ́ tàbí tẹ́mpìlì, fún àwọn ọ̀dọ́ òjíṣẹ́ ìhìnrere lókun, mú àwọn ẹ̀ká kékeré gbèrú, ṣiṣẹ́ ní àwọn gbàgede àkọọ́lẹ̀-ìtàn ẹbí tàbí àwọn ibi onítàn, kọ́ni ní ibi idanilẹkọ, pèsè iṣẹ́ ìsìn rírannilọ́wọ́, ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ àgbà, ṣèrànwọ́ ní àwọn gbàgede ìgbanisíṣẹ́ tàbí lórí àwọn oko Ìjọ. Àwọn ọ̀nà pàtó láti sìn, ohun tí ó báa yín mu jùlọ, ibití a ti nílò yín, àti bí ẹ ti lè ṣetán láti lọ sọ̀rọ̀ ní ibiwẹ́ẹ̀bù “Òjíṣẹ́ Ìhìnrere Àgbà.”22 Bákannáà ẹ lè sọ̀rọ̀ pẹ̀lú bíṣọ́ọ̀pù yín tàbí ààrẹ ẹ̀ká.

Mo ti pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tọkọtayà láti sìn kí wọ́n sì máa wò bí Ìmọ́lẹ̀ Krístì ti kún ìwò wọn.23 Ní ìpadàbọ̀ wọn, wọ́n ti júwe dídàgbà súnmọ́ Olúwa si àti súnmọ́ ara wọn, níní Ẹ̀mí Olúwa ní títú sílẹ̀ lórí wọn, àti mímọ́ pé wọ́n nṣe ìyàtọ̀.24 Tani kò ní fẹ́ ìyẹn?

Iṣẹ́ ìránṣẹ́ lè jẹ́ ipele títóbijùlọ nínú ayé lọ́kọláyà. Àkọlé rere kan lè jẹ́ “Olúwa Mi Yíò Ní Ìlò Mi.”25 Ẹ lè wà ní ilẹ̀ àìmọ̀ dáadáa; bákannáà, agbára Ẹ̀mí yíò mú yín ní ìmọ̀lára wíwà nílé.

Àwọn òbí mi, àti ẹgbẹgbẹ̀rú mẹwa àwọn tọkọtayà òjíṣẹ́ ìhìnrere pípadàbọ̀ ti jẹ́ ẹ̀rí nípa ayọ̀ tí wọ́n rí nínú iṣẹ́́ ìránṣẹ́ ìhìnrere. Olúwa ti wí nínú ìwé-mímọ́ ọjọ́-ìkẹhìn pé, “Bí ó bá sì rí bẹ́ẹ̀ pé ẹ̀yin ṣe làálàá ní gbogbo ọjọ́ ayé yín ní kíkígbe ironúpìwàdà sí àwọn ènìyan yìí, tí ẹ̀yin sì mú, bí ó ṣe ọkàn kan péré wá sí ọ̀dọ̀ mi, báwo ni ayọ̀ yín yíò ṣe pọ̀ tó pẹ̀lú rẹ̀ ní ìjọba Baba mi!”26

Isaiah fún wa ní ìjúwe ewì kan nípa ohun tí ó túmọ̀ sí láti sìn ní “pápá” iṣẹ́ ìránṣẹ́. Ìwé mímọ́ wí fún wa pé “pápá jẹ́ àgbáyé.”27 Wòlíì àtijọ́ nlá yí kọ pé, “Nítorí ayọ̀ ni ẹ ó fi jáde, àláfíà ni a ó fi tọ́ yín: àwọn òkè nlá àti òkè kékèké yíò bú sí orin níwájú yín, gbogbo igi ìgbẹ́ yíò sì pàtẹ́wọ́ wọn.”28 Àwọn òkè kékeré, àwọn òkè nlá, pápá, àti àwọn igi ní a lè fiwé àwọn ààrẹ ibi iṣẹ́ ìránṣẹ́, bíṣọ́ọ̀pù, olórí ẹ̀kùn, àwọn ọmọ ìjọ, àti àwọn wọnnì tí wọ́n nwá òtítọ́ ṣùgbọ́n “wọn kò mọ ibi tí wọn ó ti ri.”28 Wọn ó jẹri pé àwọn àgbà òjíṣẹ́-ìhìnrere ó yí àlà-ilẹ̀ padà pẹ̀lú ẹ̀rí wọn nípa Olùgbàlà àti Olùràpadà wa, Jésù Krístì.

Gẹ́gẹ́bí Àpóstélì Olúwa Jésù Krístì kan, mo ni kí ẹ sìn bí òjíṣẹ́ ìhìnrere nínú ìkójọ Ísráẹ́lì àti bóyá kí ẹ sìn lẹ́ẹ̀kan si. A nílò yín—a nílò yín. Inú wa dùn sí ẹ̀yin àgbà, fún ìgbé ayé tí ẹ ti darí àti àwọn àpẹrẹ tí ẹ ti jẹ́ nínú ilé yín, wọ́ọ̀dù, àti èèkàn. Mo pè yín bayi láti mu bí ẹ ti-mọ̀ yín, àti pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí ìgbà-ọlá, kí ẹ sì lọ ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́. Mo gbàdúrà pé ìgbà míràn tí mo bá joko láti yan àwọn tọkọtayà síṣẹ́ ọgọgọrun lára yín yíò ti dúró taratara fún ìpè yín.

Bákannáà mo ṣe ìlérí pé bí ẹ ti nsìn, ẹ ó ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Olúwa nínú ayé yín, ẹ ó mọ̀ Ọ́, Òun ó sì mọ̀ yín, àti pé “bí ayọ̀ yín yíò ti pọ̀ tó.”30 Ìyàsímímọ́ iṣẹ́-ìsìn yín sí Jésù Krístì yíò mísí yíò sì bùkún ẹbí yín, ọmọ-ọmọ yín, àti ọmọ-ọmọ-ọmọ yín. “Aláfíà, àti ìfẹ́ [yíò] lékún”31 si nínú ayé wọn fún àwọn ọdún tó nbọ̀. Mo ṣe ìlérí. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Russell M. Nelson, “Ìrètí ti Ísráẹ́lì” (worldwide youth devotional, June 3, 2018), Gospel Library.

  2. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 18:10.

  3. 3 Néfì 10:18.

  4. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 78:18.

  5. The Church has 62,544 missionaries in 411 missions across the world from North and South America to Europe and Africa, Asia, and Australia/Oceania. There are 27,000 senior Church-service missionaries. (Dátà Ẹ̀ká Iṣẹ́ Ìránṣẹ́ Ìhìnrere, Sept. 2023.)

  6. Wo Ronald A. Rasband, “The Divine Call of a Missionary,” Liahona, May 2010, 52–53.

  7. Russell M. Nelson, “Senior Missionary Moments,” Liahona, Apr. 2016, 27.

  8. Russell M. Nelson, “Senior Missionaries and the GospelLiahona, Nov. 2004, 79.

  9. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 4:3.

  10. John 4:36.

  11. Mo wà ní New York, USA, attending the baptism of granddaughter Brooklyn and the blessing of granddaughter Ella, April 2006.

  12. Lẹ́tà látọ̀dọ̀ Rebecca Guzman to Elder Ronald A. Rasband, Sept. 8, 2009.

  13. Àwọn òbí mi sìn ní Fort Lauderdale Florida Mission in 1979.

  14. The Osmond family was a popular American music group known for their pop songs. The group reached the height of fame in the mid 1970s, performing on television variety shows. Donny and Marie continued with television with stage careers while the brothers performed for decades as country artists in Branson, Missouri.

  15. Lẹ́tà látọ̀dọ̀ Rebecca Guzman, Sept. 8, 2009.

  16. Lẹ́tà látọ̀dọ̀ Rebecca Guzman, Sept. 8, 2009.

  17. Lẹ́tà látọ̀dọ̀ Rebecca Guzman, Sept. 8, 2009.

  18. Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 64:29.

  19. Senior missionary opportunities take many forms, and couples or senior sisters may list preferences as well as a full-time or Church-service assignment. Ultimately, the prophet of the Church issues the call for full-time service. Stake presidents issue Church-service assignments. Service can range from 6 months to 23 months, and senior missionaries have more flexibility, less strenuous activity than young missionaries. Wo seniormissionary.ChurchofJesusChrist.org.

  20. Russell M. Nelson, “Senior Missionaries and the Gospel,” Liahona, Nov. 2004, 79.

  21. Wo seniormissionary.ChurchofJesusChrist.org.

  22. Wo Álmà 5:14. “Ìrísí” ni a lè júwe bí ríronú lórí ìwà ti ẹ̀mí olúkúlùkù àti ipó inú.

  23. Wo Jude 1:22; Mosiah 4:20.

  24. Wo “Èmi Ó Lọ Sí Ibití Ìwọ Fẹ́ Kí Nlọ,” Hymns, no. 270.

  25. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 18:15.

  26. Olúwa ṣe àlàyé pé “Pápá náà ni ayé; … ìkórè sì ni òpin ayé” (Matthew 13:38–39

  27. Isaiah 55:12.

  28. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 123:12.

  29. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 18:15.

  30. Jude 1:2.