Rírìn nínú Ìbáṣepọ̀ Májẹ̀mú pẹ̀lú Krístì
Ẹni náà tí a palára tí a sì kán fún wa yío gba ayé kíkú láàyè láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ nínú wa, ṣùgbọ́n kò sọ fúnwa láti kojú àwọn ìpèníjà wọnnì fúnra wa.
A fi mí hàn sí ipa ọ̀nà ẹ̀sẹ̀ kan ní Isráẹ́lì nipasẹ̀ ọ̀rẹ́ mi dáradára Ilan. “A pè é ní Ipa Ọnà Ẹsẹ̀ Jésù,” ó wí, “nítorípé ó jẹ́ ipá-ọ̀nà láti Násárẹ́tì sí Kapernáúmù tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbàgbọ́ pé Jésù ti rìn.” Mo pinnu lójúkannáà àti níbẹ̀ pé mo fẹ́ láti rìn ín, nítorínáà mo bẹ̀rẹ̀ sí nṣètò ìrìn-àjò kan lọ sí Isráẹ́lì.
Ní ọ̀sẹ̀ mẹ́fà ṣaájú ìrìn-àjò náà, mo fi ọrùn ẹsẹ̀ mi kán. Ọkọ mi dàámú nípa ìpalára náà; àníyàn mi títóbi jùlọ ni bí èmi ó ṣe rìn Ipa Ọnà Ẹsẹ̀ Jésù ní oṣù kan lẹ́hìnwá. Mo jẹ́ alágídí nípa àdánidá, nítorínáà èmi kò fagilé àwọn tíkẹ́ẹ̀tì ọkọ̀ òfurufú.
Mo rántí pípàdé atọ́nà wa ará Isráẹ́lì ní òwúrọ̀ Ọṣù Kẹfà rírẹwà náà. Mo fò jáde lórí ẹsẹ̀ kan àti lẹ́hìnnáà mo fa àwọn ọpá ìfirìn àti súkútà orunkún kan jáde. Mya, atọ́nà wa, wo ibi lílẹ̀ mi ó sì wí pé, “Uh, èmi kò rò pé o le rìn ipa ọ̀nà ẹsẹ̀ yí ní ipò náà.”
“Bóyá kò rí bẹ́ẹ̀,” mo fèsì. “Ṣùgbọ́n kò sí ohun kan tó dí mi lọ́wọ́ láti gbìyànjú.” Ó mi orí rẹ̀ díẹ̀, a sì bẹ̀rẹ̀. Mo fẹ́ràn rẹ̀ fún èyíinì, fún gbígbàgbọ́ pé mo le rin ipa ọ̀nà ẹsẹ̀ náà ní kíkán.
Mo lọ kiri ibi ipa ọ̀nà gíga náà àti ipa ọ̀nà ẹsẹ̀ náà fún ìgbà kan fúnra mi. Nígbànáà, ní ìwúrí nípasẹ̀ òtítọ́ ìfarasìn mi, Mya fa okùn tínrín kan jáde, ó so ó mọ́ àwọn ìfọwọ́mú súkútà mi, ó sì bẹ̀rẹ̀sí fàá. Ó fà mí gun àwọn òkè, kọjá níbi ọgbà lẹ́mọ́nù, àti níbi àwọn yanrìn bèbè Òkun ti Gálílì. Ní ìparí ìrìn àjò náà, mo fi ìjìnlẹ̀ ìmoore hàn fún atọ́nà mi dáadáa, ẹnití ó ti rànmí lọ́wọ́ láti yọrí ohun kan tí èmi ìbá má le ṣe àṣeyọrí fúnra ara mi.
Nígbàtí Olúwa pe Énọ́kù láti rìn la ilẹ̀ náà já kí ó sì jẹ́rĩ nípa Rẹ̀, Énọ́kù lọ́ra.1 Ó jẹ́ ọmọdé, ó lọ́ra ní ọ̀rọ̀ sísọ. Báwo ni òun ó ṣe rin ipa ọ̀nà náà nínú ipò rẹ̀? Ó ní ìfọ́jú nípa ohun tí ó kán nínú rẹ̀. Ìdáhùn Olúwa sí ohun tó dí i lọ́wọ́ rọrùn ó sì jẹ́ ní ojúẹsẹ̀: “Rìn pẹ̀lú mi.”2 Bíi Énọ́kù, a gbọ́dọ̀ rántí pé Ẹni náà tí a palára tí a sì kán fún wa3 yío gba ayé kíkú láàyè láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀ nínú wa, ṣùgbọ́n kò sọ fúnwa láti kojú àwọn ìpèníjà wọnnì ní àwa nìkan.4 Bí ó ti wù kí ìwúwó ìtàn wa tó tàbí ìlọsíwájú lọ́wọ́lọ́wọ́ ti ipa ọ̀nà wa, Òun ó pè wá láti rìn pẹ̀lú Rẹ̀.5
Ẹ ronú nípa ọ̀dọ́mọkùnrin ní ìṣòro ti wàhálà kan ẹnití ó pàdé Olúwa ní ibi aginjù kan. Jákọ́bù ti rìn jìnnà kúrò nílé. Nínú òkùnkùn òru, ó lá àlá kan tí kìí ṣe pé ó ní àkàbà nínú nìkan ṣùgbọ́n bákannáà ó di àwọn ìlérí májẹ̀mú pàtàkì mú, nínú èyí tí ohun tí mo fẹ́ràn láti pè ní ìlérí ìka-márũn wà.6 Ní òru náà, Olúwa dúró ní ẹ̀gbẹ́ Jákọ́bù, Ó fi Ara Rẹ̀ hàn bíi Ọlọ́run ti baba Jákọ́bù, àti lẹ́hìnnáà Ó ṣèlérí pé:
-
Mo wà pẹ̀lú rẹ.
-
Èmi ó pa ọ́ mọ́ ní ààbò.
-
Èmi ó mú ọ wálé lẹ́ẹ̀kansíi.
-
Èmi kì yíò fi ọ sílẹ̀.
-
Èmi yíò pa ìlérí mi sí ọ mọ́.7
Jákọ́bù ní àṣàyàn kan láti ṣe. Ó le yàn láti gbé ìgbé ayé rẹ̀ ní ìrọ̀rùn bíi ojúlùmọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run baba rẹ̀, tàbí ó le yàn láti gbé ìgbé ayé nínú ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú dídúróṣinṣin pẹ̀lú Rẹ̀ Ní àwọn ọdún lẹ́hìnwá, Jákọ́bù jẹ́ri nípa ayé kan tí a gbé ní ààrin àwọn ìlérí májẹ̀mú: “Ọlọ́run … dá mi ní ohùn ní ọjọ́ ìpọ́njú mi, ó sì wà pẹ̀lú mi ní àjò tí mo rè.”8 Gẹ́gẹ́ bí Ó ti ṣe fún Jákọ́bù, Olúwa yío dáhùn olukúlùkù wa ní ọjọ́ ìpọ́njú wa bí a bá yàn láti so ayé wa pẹ̀lú Tirẹ̀. Ó ti ṣe ìlérí láti rìn pẹ̀lú wa ní ọ̀nà náà.
A pe èyí ní ipá ọ̀nà májẹ̀mú—ipa ọ̀nà tí ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú májẹ̀mú ti ìrìbọmi tí ó sì darí sí àwọn májẹ̀mú tó jinlẹ̀ síi tí a nṣe nínú tẹ́mpìlì. Bóyá ẹ ngbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọnnì ẹ sì nronú nípa àwọn ihò ìsàmìsí. Bóyá gbogbo ohun tí ẹ nrí ni ipa ọ̀nà àwọn ohun ìnílò kan. Wíwò súnmọ́ dáadáa nṣe àfihàn ohun kan tí ó wọni lọ́kàn síi. Májẹ̀mú kìí ṣe nípa àdéhùn nìkan, bíótilẹ̀jẹ́pé èyíinì ṣe pàtàkì. Ó jẹ́ nípa ìbáṣepọ̀ kan. Ààrẹ Russell M. Nelson kọ́ni pé, “Ipa ọ̀nà májẹ̀mú jẹ́ nípa ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run.”9
Ẹ yẹ májẹ̀mú ìgbéyàwó wò. Ọjọ́ ìgbéyàwó ṣe pàtàkì, ṣùgbọ́n pàtàkì bákannáà ni ìbáṣepọ̀ tí a lò nínú ìgbé ayé tí a ngbé papọ̀ lẹ́hìnwá. Èyí kannáà jẹ́ òtítọ́ pẹ̀lú ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run. Àwọn ipò ti di gbígbékalẹ̀, àwọn ìrètí yío sì wà ní ojú ọ̀nà. Àti síbẹ̀ Ó npè ẹ̀nìkọ̀ọ̀kan wa láti wá bí a ti wà, pẹ̀lú èrò ọkàn kíkún, àti láti “tẹ̀ síwájú”10 pẹ̀lú Òun ní ẹ̀gbẹ́ wa, ní gbígbẹ́kẹ̀lé pé àwọn ìbùkún Rẹ̀ tí a ti ṣèlérí yío wá. Ìwé mímọ́ ránwa létí pé ní ọ̀pọ̀ ìgbà àwọn ìbùkún wọnnì máa nwá ní àkókò Tirẹ̀ àti ni ọ̀nà Tirẹ̀: ọdún 38,11 ọdún 12,12 lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.13 Bí àwọn ipa ọ̀nà wa yío ti bèèrè, bẹ́ẹ̀ ni ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀ yío jẹ́.14
Tirẹ̀ jẹ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìrẹ̀lẹ̀ kan. Jésù Krístì yío pàdé wa níbi tí a wà bí a ti wà. Èyí ni ìdí ti ọgbà náà, àgbélèbú náà, àti isà okú náà. A rán Olùgbàlà wá láti rànwá lọ́wọ́ láti borí.15 Ṣùgbọ́n dídúró níbi tí a wà kò ní mú ìtúsílẹ̀ tí a nlépa wá. Gẹ́gẹ́bí Òun kò ti fi Jákọ́bù síbẹ̀ nínú ìdọ̀tí, Olúwa kò níi lọ́kàn láti fi ẹnìkankan wa sí ibi tí a wà.
Tirẹ̀ bákannáà ni iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìgòkè. Òun ó ṣiṣẹ́ nínú wa16 láti gbé wa sókè sí ibi tí Òun wà àti, ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, yío fúnwa lágbára láti dà bí Òun ti rí. Jésù Krístì wá láti gbé wa sókè.17 Ó fẹ́ rànwá lọ́wọ́ láti dàbí. Èyí ni èrèdí ti tẹ́mpìlì.
A gbọ́dọ̀ rántí pé: kìí ṣe ọ̀nà náà nìkan ni yío gbé wa ga; alábàárìn náà ni––Olùgbàlà wa. Àti pé èyí ni ìdí ti ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú.
Nígbàtí mo wà ní Isráẹ́lì, mo ṣe àbẹ̀wò sí Western Wall. Fún àwọn Júù, èyí ni ibi mímọ́ jùlọ ní Isráẹ́lì. Ó jẹ́ gbogbo ohun tó ṣẹ́kù nínú tẹ́mpìlì wọn. Púpọ̀ jùlọ máa nwọ ohun tiwọn tó dára jùlọ nígbàtí wọ́n bá nṣàbẹ̀wò sí ibi mímọ́ yí; yíyàn aṣọ wọn jẹ́ àmì ti ìfọkànsìn wọn sí ìbáṣepọ̀ wọn pẹ̀lú Ọlọ́run. Wọ́n a máa lọ sí ibi ògiri náà láti ka ìwé mímọ́, láti jọ́sìn, àti láti tú àwọn àdúrà wọn jáde. Ẹ̀bẹ̀ fún tẹ́mpìlì kan ní ààrin wọn máa ngba gbogbo ọjọ́ wọn, gbogbo àdúrà wọn, ìpòngbẹ yí fún ilé ti májẹ̀mú kan. Mo ní ìtẹríba fún ìfọkànsìn wọn.
Nígbàtí mo padà sílé láti Isráẹ́lì, mo fetísílẹ̀ ní sísúnmọ́ sí àwọn ìbárasọ̀rọ̀ ní àyíká mi nípa àwọn májẹ̀mú. Mo ṣe àkíyèsí pé àwọn ènìyàn nbèèrè pé, Kínni ìdí tí mo fi níláti rìn ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú? Njẹ́ mo nílò láti wọ inú ilé kan fún dídá àwọn májẹ̀mú? Kínni ìdí ti mo fi nwọ gámẹ́ntì mímọ́? Ṣé kí èmi ó kópa nínú ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú kan pẹ̀lú Olúwa? Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè rere àti pàtàkì wọ̀nyí jẹ́ rírọrùn: ó dá lórí ìpele ìbáṣepọ̀ tí o bá fẹ́ ní ìrírí rẹ̀ pẹ̀lú Jésù Krístì.18 Olukúlùkù wa yío nílò láti ṣe àwárí ìdáhùn tiwa sí àwọn ìbéèrè ti ara ẹni jíjinlẹ̀ wọnnì.
Nihin ni témi: Mo rìn ní ipa ọ̀nà yí bíi “àyànfẹ́ ọmọbìnrin ti àwọn òbí ọ̀run,”19 tí a mọ̀ ní ti ọ̀run20 tí a sì gbẹ́kẹ̀lé jinlẹ̀jinlẹ̀.21 Bí ọmọ ti májẹ̀mú náà, mo ní ẹ̀tọ́ láti gba àwọn ìbùkún tí a ṣe22 ìlérí. Mo ti yàn23 láti rìn pẹ̀lú Olúwa. A ti pè mí24 láti dúró bíi ẹlẹ́rìí ti Krístì. Nígbàtí ipa ọ̀nà náà bá dàbí pé ó ṣòro, mo ndi fífún lókun25 pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́. Ní àkókò kọ̀ọ̀kan tí mo bá kọjá ní ẹnu ọ̀nà ilé Rẹ̀, mo nní ìrírí ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú jíjinlẹ̀ síi pẹ̀lú Rẹ̀. Mo jẹ́ yíyàsímímọ́26 pẹ̀lú Ẹmí Rẹ̀, bíbùkún27 pẹ̀lú àwọn ẹ̀bùn Rẹ̀, àti yíyà sọ́tọ̀28 láti gbé ìjọba Rẹ̀ ga. Nípasẹ̀ ìlànà kan ti ìrònúpìwàdà ojoojúmọ́ àti kíkópa nínú onjẹ Olúwa ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, mó nkọ́ ẹ̀kọ́ láti di dídúró ṣinṣin29 àti lílọ káàkiri ní ṣíṣe rere30 Mo rin ipa ọ̀nà yí pẹ̀lú Jésù Krístì, ní fífojú sọ́nà sí ọjọ́ náà tí a ti ṣèlérí nígbàtí Òun ó wá lẹ́ẹ̀kansíi. Nígbànáà èmi ó jẹ́ fífi èdìdi dì ní Tirẹ̀31 àti gbígbé sókè bíi ọmọbìnrin mímọ́32 kan ti Ọlọ́run.
Èyí ni ìdí tí mo fi nrìn ní ipá ọ̀nà májẹ̀mú.
Èyí ni ìdí tí mo fi rọ̀ mọ́ àwọn ìlérí májẹ̀mú.
Èyí ni ìdí tí mo fi wọ inú ilé májẹ̀mú Rẹ̀.
Èyí ni ìdí ti mo fi nwọ gámẹ́ntì mímọ́ bíi olùránni-létí kan ní gbogbo ìgbà.
Nítorípé mo fẹ́ gbé ìgbé ayé nínú ìbáṣepọ̀ ìfarasìn májẹ̀mú pẹ̀lú Rẹ̀.
Bóyá ẹ̀yin náà fẹ́ bákannáà. Ẹ bẹ̀rẹ̀ níbi tí ẹ wà.33 Ẹ máṣe jẹ́kí ipò rẹ kó dí ọ lọ́wọ́. Ẹ rántí, ìgbésẹ̀ tàbí ipò ní ipa ọ̀nà náà kò ṣe pàtàkì bíi ìlọsíwájú.34 Sọ fún ẹnìkan tí o le gbẹ́kẹ̀lé ẹnití ó wà ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú, kí ó fi ọ́ hàn sí Olùgbàlà tí àwọn ti mọ̀. Ẹ kọ́ ẹ̀kọ́ síi nípa Rẹ̀. Kópa nínú ìbáṣepọ̀ náà nípa wíwọ inú májẹ̀mú pẹ̀lú Rẹ̀. Ọjọ́ orí tàbí ipò yín kò já mọ́ ohun kan. Ẹ lè rìn pẹ̀lú Rẹ̀.
Lẹ́hìn tí a parí rírìn Ipa Ọ̀nà Ẹsẹ̀ ti Jésù náà, Mya kò gba okùn rẹ̀. Ó fi í sílẹ̀ ní síso mọ́ súkútà mi. Fún àwọn ọjọ́ díẹ̀ tó tẹ̀lé, àwọn ọ̀dọ́ nẹ́fíù mi àti ọ̀rẹ́ wọn npin láàrin ara wọn láti fà mí nínú àwọn òpópónà Jérúsálẹ́mù.35 Wọ́n ríi dájú pé èmi kò pàdánù kankan lórí àwọn ìtàn Jésù. A ránmi létí nípa okun ìran tí ó ndìde. A lè kọ́ ẹ̀kọ́ láti ọ̀dọ̀ yín. Ẹ ní ìfẹ̀ inú gidi kan láti mọ atọ́nà náà, Jésù Krístì. Ẹ gbẹ́kẹ̀lé agbára ti okùn náà tí ó nso wá pọ̀ mọ́ Òun. Ẹ ní ẹ̀bùn nínú dídarí àwọn ẹlòmíràn sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀.36
Pẹ̀lú ọpẹ́, à nrin ipa ọ̀nà yí papọ̀, ní pípe ìgbàni-níyànjú jáde ní ẹ̀bá ọ̀nà.37 Bí a ṣe nṣe àbápín ìrírí ti ara ẹni wa pẹ̀lú Kristi, a ó fún ìfọkànsìn ti ara ẹni wa lókun. Nípa èyí ni mo jẹ́ ẹ̀rí ni orúkọ Jésù Krístì, àmín.