Rírí Ẹbí ti Ọlọ́run láti inú Jígí Àkópọ̀
Mo gbàgbọ́ pe a lè, nípasẹ̀ ojú ìgbàgbọ́, súùmù síta kí a sì wo ara wa àti ẹbí wa pẹ̀lú ìrètí àti ayọ.
Nígbàtí ọmọbìnrin wa tó kéréjùlọ, Berkeley, kéré, mo bẹ̀rẹ̀ sí lílo jígí ìkàwé―irú èyí tó máa njẹ́kí nkan súùmù súnmọ́ni tó sì nmú ohun gbogbo tóbi síi. Ní ọjọ́ kan, bí a ti joko papọ̀ tí à nka ìwé kan, mo wo ó pẹ̀lú ìfẹ́ ṣùgbọ́n bákannáà pẹ̀lú ìbànújẹ́ nítorí, lọ́gán, ó dàbí pé ó ti dàgbà si. Mo rò ó pé, “Níbo ni àkokò lọ? Ó ti tóbi gidi!”
Bí mo ti mú jígí ìkàwé mi sókè láti nu omijé kan kúrò, mo damọ̀ pé, “Ah dúró—kò tóbijù; ó kan jẹ́ àwọn jígí wọ̀nyí ni! Má ṣèyọnu.”
Nígbàmíràn gbogbo ohun tí a lè rí ni ìwò sísúnmọ́ náà, tí a ti mú tóbi ti àwọn wọnnì tí a fẹ́ràn. Ní alẹ́ yí, mo pè yín láti súùmù jáde kí ẹ sì wò láti inú oríṣiríṣi àwọn jígí—jígí ti ayérayé kan tí ó nfojúsùn sí orí àwòrán títóbi, ìtàn yín títóbi ju.
Ní àwọn ìgbà ìṣaájú tí a ti ẹ̀dá ènìyàn sí inú àlàfo, àwọn rọ́kẹ́tì náà tí kò ní olùdarí kò ní àwọn fèrèsé. Ṣùgbọ́n nípasẹ̀ míṣọ̀n Apollo mẹ́jọ sí òṣùpá, àwọn àmòye ìràwọ̀ ní ọ̀kan. Nígbàtí ó nléfòó nínú àlàfo, a lù wọ́n pẹ̀lú agbára ti rírí ilẹ̀ ayé wa àti mímú àwòrán títayọ yí, ní kíkó àkíyèsí gbogbo aráyé tán! Àwọn amòye ìràwọ̀ wọnnì ní ìrírí ìwúrí tí ó lágbára gidi tí a fi fun ní orúkọ ara rẹ̀: Ìwòkọjá Ìyọrísí.
Wíwò láti ibi èrò orí ìrọ̀rùn titun kan nyí ohun gbogbo padà. Arìnrìnàjò sí àlàfo kan wí látinú ojú-ìwòyé yí pé “ó ndín àwọn nkan kù sí ìwọ̀n tí ẹ rò pé ó ṣeé múlò. … A lè ṣe èyí. Àláfíà ní orí ilẹ̀ ayé—kò sí wàhálà. Ó nfún àwọn ènìyàn ní irú okun náà … irú agbára náà.”1
Gẹ́gẹ́bí ẹlẹ́ran ara, a ní àmì ti wíwò ìdúró ayé, ṣùgbọ́n Ọlọ́run rí ọlá àkópọ̀ ti gbogbo ayé. Ó rí gbogbo ẹ̀dá, gbogbo wa, ó sì kún pẹ̀lú ìrètí.
Njẹ́ ó ṣeéṣe láti bẹ̀rẹ̀ láti rí bí Ọlọ́run ti nrí àní nígbàtí à ngbé lórí ìpín ilẹ̀ ayé yí—láti mọ ìmọ̀lára àkópọ̀ yí lára? Mo gbàgbọ́ pe a lè, nípasẹ̀ ojú ìgbàgbọ́, súùmù síta kí a sì wo ara wa àti ẹbí wa pẹ̀lú ìrètí àti ayọ.
Àwọn ìwé mímọ́ faramọ. Mórónì sọ̀rọ̀ nípa àwọn wọnnì tí ìgbàgbọ́ wọn “lágbára gidigidi” pé wọ́n “rí nítòótọ́ … pẹ̀lú ojú ìgbàgbọ́, inú wọn sì dùn.”2
Pẹ̀lú ojú fífisún lórí Jésù Krístì, wọ́n ní ìmọ̀lára ayọ̀ wọ́n sì mọ òtítọ́ yí pé: nítorí Krístì, gbogbo rẹ̀ já síre. Gbogbo ohun tí ẹ̀yin àti ẹ̀yin àti ẹ̀yin ndààmú nípa rẹ̀—gbogbo rẹ̀ yíò Dára! Àti pé àwọn wọnnì tí wọ́n nwò pẹ̀lú ojú ìgbàgbọ́ lè ní ìmọ̀lára pé yíò Dára nísisìyí.
Mo la àkókò pálapàla kan kọjá ní ọdún àgbà ní ilé-ìwé gíga mi nígbàtí èmi kìí ṣe àwọn àṣàyàn tó dára. Mo rántí rírí ìyá mi tí ó nsọkún, tí ó sì nyà mi lẹ́nu pé bóya mo ti já a kulẹ̀. Ní àkokò náà, mo dààmú pé omijé rẹ̀ túmọ̀sí pé ó ti sọ ìrètí nù fún mi, àti pé bí kò bá ní ìrètí fún mi, bóyá kò sí ọ̀nà láti padà.
Ṣùgbọ́n baba mi mọ̀ nípa sísúùmù síta àti wíwò fún ìgbà pípẹ́. Ó ti kẹkọ láti inú ìrírí pé ìdàmú máa ndàbí ìfẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀, ṣùgbọ́n kìí ṣe ìkannáà.3 Ó lo ojú ìgbàgbọ́ láti ri pé gbogbo èyí ó yọrí síre, àti pé níní ìrètí rẹ̀ yí mi padà.
Nígbàtí mo gboyè jáde ní ilé-ìwé gíga tí mo sì wá sí BYU, baba mi fi àwọn lẹ́tà ránṣẹ́ sí mi, ní rírán mi létí ẹni tí mo jẹ́. Ó di adánilárayá mi, àti pé gbogbo ènìyàn nílò adánilárayá—ẹnìkan tí kìí wí fún yín pé, “Ẹ̀yin kò yára sáré tó”; wọ́n nfi tìfẹ́tìfẹ́ rán yín létí pé ẹ lè ṣe é.
Baba ṣe àpẹrẹ àlá Léhì. Bíiti Lehi, ó mọ̀ pé ẹ kò sáré lé àwọn olólùfẹ́ tí wọ́n ti sọnù. “Ẹ dúró níbi tí ẹ wà kí ẹ sì pè wọ́n. Ẹ lọ sí ibi igi, ẹ dúró níbi igi, ẹ̀ tẹramọ́ jíjẹ èso náà àti pé, pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ kan ní ojú yín, ẹ tẹ̀síwájú láti ṣẹ́wọ́ sí àwọn tí ẹ fẹ́ràn ẹ sì nfihàn nípa àpẹrẹ pé jíjẹ́ èso náà jẹ́ ohun ìdùnnú!”4
Àwòrán tí a rí yí ti ràn mí lọ́wọ́ ní àwọn àkokò ìrẹ̀wẹ̀sì nígbà tí mo rí ara mi níbi igi, tí mo njẹ èso náà tí mo sì nsọkún nítorí ìdàmú mi, àti lódodo, bí èyí ti jẹ́ ìrànlọ́wọ́ tó? Dípò bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí a yan ìrètí—ìrètí nínú Ẹlẹ́dã wa àti nínú ẹnìkan wa sí ẹlòmíràn, ní rírú okun wa láti jẹ́ dídára ju bí a ti wà nísisìyí.
Ní kété lẹ́hìntí Alàgbà Neal A. Maxwell kọjá lọ, oníròhìn kan bèèrè lọ́wọ́ ọmọkùnrin rẹ̀ ohun tí yíó pàdánù jùlọ. Ó wípé oúnjẹ alẹ́ ní ilé àwọn òbí rẹ̀ nítorípé òun máa nfi ibẹ̀ sílẹ̀ nígbàgbogbo pẹ̀lú ìmọ̀lára bí ẹnipé baba rẹ̀ gbàgbọ́ nínú rẹ̀.
Èyí ní àyíká àkókò tí àwọn ọmọ wa àgbà nbẹ̀rẹ̀ láti máa wá sílé fún àwọn oújẹ alẹ́ Ọjọ́-ìsinmi pẹ̀lú àwọn lọ́kọlaya wọn. Nínú ọ̀sẹ̀ náà mo rí ara mi ní ṣíṣe títòsílẹ̀ ní inú mi nípa àwọn ohun tí mo lè rán wọn létí ní Ọjọ́-ìsinmi, bíiti “Bóyá ìgbìyànjú àti ṣèrànwọ́ síi pẹ̀lú àwọn ọmọ nígbàtí ẹ bá wà nílé” tàbí “Ẹ má gbàgbé láti jẹ́ olùfetísílẹ̀ rere.”
Nígbàtí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ arákùnrin Maxwell, mo sọ ìtòsílẹ̀ náà nu mo sí pa ohùn àríwísí náà lẹnu mọ́, nítorínáà nígbàtí mo bá rí àwọn ọmọ mi tí wọ́n ti dàgbà fún àkókò kúkúrú bẹ́ẹ̀ ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀, mo nfojúsùn sórí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun dídára tí wọn ti nṣe. Nígbàtí ọmọkùnrin wa àgbà-jùlọ, Ryan, kọjá lọ ní àwọn ọdún díẹ̀ lẹ́hìnnáà, mo rántí níní ìmoore pé àkokò wa papọ̀ jẹ́ ti ìdùnnú àti dídára síi.
Ṣíwájú kí a tó baraṣe pẹ̀lú olùfẹ́ kan, ṣe a lè bèèrè ìbèèrè náà lọ́wọ́ ara wa pé “Njẹ́ ohun tí mo fẹ́ ṣe tàbí sọ yíó ṣèrànwọ́ tàbí panilára?” Àwọn Ọ̀rọ̀ wa jẹ́ ọ̀kan lára àwọn agbára tìtayọ wa, àti pé àwọn ọmọ ẹbí dàbí pátákó dúdú ènìyàn, tó dúró níwájú wa tó nwípé, “Kọ ohun tí o bá rò nípa mi!” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, bóyá mímọ̀ọ̀mọ̀ tàbí àìmọ̀ọ̀mọ́, níláti jẹ́ onírètí àti gbígbani-níyànjú.5
Ìṣẹ́ wa kìí ṣe láti kọ́ ẹnìkan tí ó nla ọ̀nà pála-pàla kọjá pé wọn kò dára tàbí wọ́n jẹ́ ajánikulẹ̀. Nínú àwọn ọ̀ràn àìwọ́pọ̀ a lè nímọ̀lára ìfura láti bániwí, ṣùgbọ́n nígbà púpọ̀ jùlọ ẹ jẹ́ kí a sọ fún àwọn olùfẹ́ wa, nínú àwọn ọ̀na ọ̀rọ̀-sísọ àti àìsọ, àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fẹ́ gbọ́: “Ẹbí wa nní imọ̀lárá jíjẹ́ odidi àti pípé nítorípé ẹ wà nínú rẹ̀.” “Ẹ ó di fífẹ́ràn fún ìyókù ayé yín—bí ó ti wù kí ó rí.”
Nígbàmíràn ohun tí a nílò ni ikaanu ju àmọ̀ràn; fífetísílẹ̀ ju kíkọ́ni; ẹnìkan tí ó gbọ́ tí ó si nyanu, “Báwo ni èmi ó ti ní ìmọ̀lára láti sọ ohun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ?”
Ẹ rántí pé, àwọn ẹbí ni ilé-àyẹ̀wò tí Ọlọ́run-fúnni níbití a tí nwá ojútũ sí àwọn nkan, nítorínáà àwọn àṣìgbé ẹsẹ̀ àti àṣìṣe ìṣirò kò kan ṣeéṣe ṣùgbọ́n ó lè wáyé. Àti pé njẹ́ kò ní wuni, ní òpin ayé wa, bí a bá lè rí pé àwọn ìbáṣepọ̀ wọnnì, àní àwọn àkokò pípeniníjà wọnnì, ni àwọn ohun gan tí ó rànwá lọ́wọ́ láti dàbí Olùgbàlà wa? Ìbáṣe ṣíṣòro kọ̀ọ̀kan jẹ́ ànfàní láti kọ́ bí a ó ti ní ìfẹ́ dé ìpèle jíjinlẹ̀—ìpèle ìwàbí Ọlọ́run.6
Ẹ jẹ́ kí a súùmù síta láti wo àwọn ìbáṣepọ̀ ẹbí bí ọkọ̀ alágbára kan láti kọ́ wa ní àwọn ẹ̀kọ́ tí a wá sí ìhín láti kọ́ bí a ti nyípadà sí Olùgbàlà.
Ẹ jẹ́ kí a gbà, nínú ayé ṣíṣubú pé kò sí ọ̀nà kankan láti jẹ́ lọ́kọláyà, òbí, ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin, ọmọ-ọmọ, olùtọ́ni, tàbí ọ̀rẹ́ pípé—ṣùgbọ́n àwọn ọ̀nà míllíọ́nù láti jẹ́ ẹnirere.7 Ẹ jẹ́ kí a dúró níbi igi, kópa nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, kí a sì ṣe àbápín rẹ̀. Nípa gbígbé àwọn ènìyàn ga ní àyíka wa, a ó gòkè papọ̀.
Ní àìsíoríre, ìrántí jíjẹ èso kò tó; a nílò láti kópa lẹ́ẹ̀kan àti lẹ̀ẹ̀kansi ní àwọn ọ̀nà tí ó ntun àwọn jígí wa fi sípò tí ó sì nso wá pọ̀ mọ́ àkópọ̀ ti tọ̀run nípa ṣíṣí àwọn ìwé mímọ́, èyí tí ó kún pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀, láti lé òkùnkùn lọ, dídúró lórí eékún wa títí àdúra díẹ̀ wa ó fi di títóbi. Èyí ni ìgbàtí àwọn ọkàn bá rọ̀, tí a sì bẹ̀rẹ̀ sí rí bí Ọlọ́run ti nrí.
Ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn wọ̀nyí, bóyá iṣẹ́ wa títóbi jùlọ yíò jẹ́ pẹ̀lú àwọn olólùfẹ́ wa—àwọn ènìyàn rere tí wọ́n ngbé nínú ayé búburú. Ìrètí wa nyí ọ̀nà tí wọ́n fi nwo ara wọn àti ẹnití wọ́n jẹ́ lódodo padà. Àti pé nípasẹ̀ jígí ìfẹ́ yí wọn ó rí ẹnití wọn yíó dà.
Ṣùgbọ́n ọ̀tà kò fẹ́ kí àwa tàbí àwọn olùfẹ́ wa ó padà sílé papọ̀. Àti nítorípé a ngbé lórí ìpín ilẹ̀ ayé tí ó ní ààlà nípa àkókò àti opin àti iye àwọn ọdún,8 ó ngbìyànjú láti mú ìdẹ́rùbà tòótọ́ gan an múlẹ̀ nínú wa. Ó le láti rí, nígbàtí a bá súùmù wọlé, tí ìdarí wa já mọ́ nkan síi ju ìyára wa.
Ẹ rántí pé, “Bí ẹ bá fẹ́ yára lọ, ẹ dá lọ. Bí ẹ bá fẹ́ lọ jìnna, ẹ lọ papọ̀.”9 Pẹ̀lú ọpẹ́, Ọlọ́run tí à njọ́sìn kò ní ààlà nípa àkokò. Ó rí ẹni tí àwọn olólùfẹ́ wa jẹ́ dájúdájú àti ẹni tí a jẹ́ dájúdájú.10 Nítorínáà Ó ní sùúrù pẹ̀lú wa, ní ìretí pé a ó ní sùúrù pẹ̀lú ara wa.
Èmi ó gbà pé àwọn ìgbà kan wà nígbàtí ilẹ̀ ayé, ilé wa fún ìgbà díẹ̀, máa ndàbí erékùṣù ìkoro—àwọn àkokò nígbàtí mo ní ojú kan ti ìgbàgbọ́ tí ojú kejì sì nsọkún.11 Njẹ́ ẹ mọ ìmọ̀lára yí?
Mó ní i ní Ọjọ́ Ìṣẹ́gun.
Njẹ́ a lè yan ìdúró òtítọ́ ti wòlíì wa dípò bẹ́ẹ̀ nígbàtí ó ṣe àwọn ìlérí àwọn iṣẹ́ ìyanu nínú àwọn ẹbí wa? Bí abá ṣeé, ayọ̀ wa yíò pọ̀si àní bí rúdurùdu tilẹ̀ pọ̀ si. Ó nṣe ìlérí pé a lè ní ìrírí àkópọ̀ àbájáde ka nrẹ̀ nísisìyí, láìka àwọn ipò wa sí.12
Níní ojú ìgbàgbọ́ yí nísisìyí ni àtúnmú, tàbí àtúnsọ kan, ti ìgbàgbọ́ tí a ní ṣíwájú kí a tó wá sí ìpín ilẹ̀ ayé yí. Ó rí tayọ àìní-ìdánilójú ti àkokò kan, ní fífi àyè gbà wá láti “fi ìyàrí ṣe gbogbo ohun tí ó wà ní agbára wa; àti nígbànáà … kí a dúró jẹ́.”13
Njẹ́ ohun kan wa tí ó ṣòro nínú ayé yín lọ́wọ́lọ́wọ́, ohun kan tí ẹ̀ ndàmú pé kò lè yanjú? Láìsí ojú ìgbàgbọ́, èyí lè dàbí pé Ọlọ́run ti sọ ojú-ìwò àwọn ohun kan nù, àti pé njẹ́ èyí jẹ́ òtítọ́ bí?
Tàbí bóyá ẹ̀rù yín púpọ̀jù ni pé ẹ ó la inú àkókò ìṣòrò yi kọjá ní ẹ̀yin nìkan, ṣùgbọ́n èyí yíó túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ti pa yín tì, àti pé njẹ́ èyí jẹ́ òtítọ́ bí?
Ó jẹ́ ẹ̀rí mi pé Olùgbàlà ní okun, nítorí Ètùtù Rẹ̀, láti yí àlákálá búburú tí ẹ lè máa là kọjá padà sí ìbùkún. Ófún wa ní ìlérí kan “pẹ̀lú májẹ̀mú àìyẹ̀” pé bí a ti ntiraka láti fẹ́ràn àti láti tẹ̀lé E, “ohun gbogbo pẹ̀lú èyí tí a ti pọ́n [wa] lójú yíò ṣiṣẹ́ fún rere [wa].”14 Gbogbo ohun.
Àti nítorípé àwa jẹ́ ọmọ májẹ̀mú, a lè bèèrè fún ìmọ̀lára ìrètí yí nísisìyí!
Nígbàtí àwọn ẹbí wa kò pé, a lè mú ìfẹ́ wa fún àwọn míràn jẹ́ pípé títí yíó fi di ìfẹ́ ìgbà gbogbo, àìyípadà, bí-ó-tiwù-kí ó rí—irú ìfẹ́ tí ó nti ìyípadà lẹ́hìn tí ó sì nfi àyè gba ìdàgbàsókè àti ìpadà.
Ó jẹ́ iṣẹ́ Olùgbàlà láti mú àwọn olólùfẹ́ padà. Ó jẹ́ iṣẹ́ Rẹ̀ àti ní àkokò Rẹ̀. Ó jẹ́ iṣẹ́ wa láti pèsè ìrètí àti ọkàn tí wọ́n lè wá bá nílé. “A kò ní bóyá àṣẹ [Ọlọ́run] láti dálẹ́bi tàbí agbára Rẹ̀ láti ràpadà, ṣùgbọ́n a ti fún wa ní àṣẹ láti lo ìfẹ́ Rẹ̀.”15 Ààrẹ Nelson bákannáà ti kọ́ni pé àwọn míràn nílò ìfẹ́ wa ju ìdájọ́ wa lọ. “Wọ́n nílò láti ní ìrírí ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ ti Jésù Krístì tí ó hàn nínú àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe [wa].”16
Ìfẹ́ ni ohun tí ó nyí ọkàn padà. Ó jẹ́ èrò inú mímọ́jùlọ nínú ohun gbogbo, àwọn míràn sì lè mọ̀ ọ́ lára. Ẹ jẹ́ kí a rọ̀mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ti wòlíì wọ̀nyí tí a fúnni ní àádọ́ta ọdún sẹ́hìn: “Kò sí ilé kan tí ó jẹ́ ìkùnà àyàfi tí ó bá jáwọ ní gbígbìyànjú.”17 Dájúdájú, àwọn tí wọ́n nifẹ jùlọ àti èrè gígùn jùlọ.
Nínú àwọn ẹbí ti ayé, à kàn nṣe ohun tí Ọlọ́run ti ṣe pẹ̀lú wa ni—nínawọ́ sí ọ̀nà àti ríretí pé àwọn olólùfẹ́ wa yíò lọ ní ìdarí náà, ní mímọ̀ pé ipa ọ̀nà tí wọ́n rìn jẹ́ tiwọn láti yàn.
Àti pé nígbàtí wọ́n bá kọjá sí ẹ̀gbẹ́ kejì ìkelè tí wọ́n sì fà súnmọ́ sí “fífà wálẹ̀” ìfẹ́ni ti ibùgbé tọ̀run wọn,18 mo gbàgbọ́ pé yíò dàbí jíjọra nítorí bí a ti fẹ́ràn wọn nihin.
Ẹ jẹ́ kí a lo àkópọ̀ jígí náà kí a sì rí àwọn ènìyàn tí a fẹ́ràn tí a sì gbé pẹ̀lú bí àwọn ojúgbà bí a ti pín lórí ilẹ̀ ayé rirẹwà wa.
Ẹ̀yin àti èmi? A lè ṣe èyí! A lè máa dìmú títí lọ kí a sì máa rètí títí lọ! A lè dúró níbi igi kí a kópa nínú èso náà pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ ní ojú wa, kí a sì jẹ́ kí Ìmọ́lẹ̀ Krístì ní ojú wa di ohun kan tí àwọ́n ẹlòmíràn lè gbáralé nínú àwọn wákàtí wọn tó ṣókúnkùn jùlọ. Bí wọ́n ṣe nrí tí ìmọ́lẹ̀ nfarahàn nínú ìrísí wa, wọn yíò di fífà sí i. A lè ṣerànwọ́ nígbànáà láti ṣe àtúnṣe ìfojúsùn àfiyèsí wọn sí ojúlówó orísun ti ìfẹ́ àti ìmọ́lẹ̀, “ìràwọ̀ òwúrọ̀ àti dídán,” Jésù Krístì.19
Mo jẹ́ ẹ̀rí mi pé èyí—gbogbo èyí—yíò yípadà wá di dáradára síi tóbẹ́ẹ̀ ju bí a ti lè rò láéláé! Pẹ̀lú ojú ìgbàgbọ́ lórí Jésù Krístì, njẹ́ kí a lè ri pé ohun gbogbo yíò dára ní òpin kí a sì ní ìmọ̀lára pé yíò dara nísisìyi. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.