Ẹ Jẹ́ Àwọn Àtẹ̀lé Oníwàpẹ̀lẹ́ ti Krístì
Mo jẹ̀ ẹ̀rí pé “àwọn àtẹ̀lé oníwàpẹ̀lẹ́ Krístì” yìó rí àláfíà araẹni nínú ayé yí àti idàpọ̀ ológo tọ̀run.
À ngbé nígbàtí “àwọn àtẹ̀lé oníwàpẹ̀lẹ̀ ti Krístì”1 nní ìrírí àwọn ìpènijà àìláfiwé. Àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ nínú, ìjọ́sìn ìrẹ̀lẹ̀, tí wọ́n sì njẹri Krístì ti wọ́n nfi ìgbàgbogbo ní ìrírí àdánwò, ìdàmú, àti ìpọ́njú.1 Ìyàwó mi Mary, àti èmi kò yàtọ̀. Ní àwọn ọdún tó kọjá, a rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára àwọn ọ̀ré tímọ́tímọ́ wa ilé-ìwé gíga, àwọn alabarin òjíṣẹ́ ìhìnrere, àti akẹ́gbẹ́ tí wọ́n kọjá lọ, tàbí, bí Ààrẹ Russell M. Nelson ti sọ, ti wọ́n yege lọ sí òdìkejì ìkelè. A rí àwọn kan tí a tọ́ nínú ìgbàgbọ́ àti gbígbàgbọ́ tí wọ́n yẹsẹ̀ kúrò ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú.
Pẹ̀lú ìbànújẹ́, a pàdánù ọmọ-ọmọ ọjọ́-orí mẹ̀tàlélógún ẹnití ó kú nínú ẹ̀wu ìjàmbá ọkọ̀. Àwọn ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n kan, ọmọ ẹbí, àti ẹlẹgbẹ́ bákannáà ti farada àwọn ìpènijà ìlera nípàtàkì.
Nígbàkúgbà tí àwọn àdánwò bá ṣẹlẹ̀, à nṣọ̀fọ̀ a sì ntiraka láti gbé àjàgà ara wa.3 À npohùnréré àwọn ohun tí a kò ṣe yọrí àti àwọn orin tí a kò ní kọ.4 Àwọn ohun búburú nṣẹlẹ̀ sí àwọn ènìyàn rere ní ìrìn àjò ayé ikú yí. Iná olóró lórí Maui ní Hawaii, Gúsù Chile, àti Ìlà-òòrùn Canada ni àwọn àpẹrẹ ti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ búburújáì tí àwọn ènìyàn rere ndojúkọ nígbàmíràn.
A kàá nínú Píálì Iyebiye pé Olúwa fi ìwà-ẹ̀dá àwọn ẹ̀mí ayérayé hàn sí Abraham. Abraham kọ́ nípa ìṣíwájú ayé wa, àyànmọ́, pípinnu-tẹ́lẹ̀, ìṣẹ̀dá, yíyan Olùràpadà, àti igbé ayé kíkú yí, èyí tí ó jẹ́ ibùgbé kejì ènìyàn.5 Olúràpadà kéde pé:
“Àwa ó ṣe ayé kan níbi-èyí tí àwọn yí lè gbé;
“A ó sì dánwọn wò ní báyí,” láti ríi bóyá wọn yíó ṣe gbogbo ohunkóhun tí Olúwa Ọlọ́run wọn yíó paláṣẹ fún wọn.”6
Nísisìyí gbogbo wa wà nihin ní ibùgbé kejì ti ìrìnàjò wa síwájú ìlọsíwájú ní ìjọba ológo bí ara ètò ìgbàlà nlá Ọlọ́run àti ìgbéga. A di alábùkún pẹ̀lú agbára láti yàn tí ó sì dálé àwọn ìdánwò ayé ikú. Èyí ni àkókò tí a fún wa láti múrasílẹ̀ láti pàdé Ọlọ́run.7 A di alábùkúnfún láti mọ̀ nípa Jésù Krístì àti ojúṣe Rẹ̀ nínú ètò náà. A ní ànfàní láti di ọmọ ìjọ ìmúpadàbọ̀sípò Rẹ̀—Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn. Bí àwọn àtẹ̀lé oníwàpẹ̀lẹ̀ à ntiraka láti gbé àwọn òfin rẹ̀. Ko rọrùn fún àwọn àtẹ̀lé Rẹ̀ rárá. Tàbí kí ó rọrùn fún Olùgbàlà láti fi òtítọ́ mú iṣẹ́ ìránṣẹ́ ayé ikú ṣẹ.
Àwọn ìwé mímọ́ hàn kedere: ọ̀pọ̀lọpọ̀ yíò yọ̀ọ̀da sí ọ̀nà “ẹ jẹun, ẹ mu, kí ẹ sì máa yọ̀, nítorí ní ọ̀la” àwa ó kú.8 Àwọn aláìgbàgbọ́ nfarí wọlé sí rírojú nínú àhámọ́ ti irúkànnáà àwọn olùkópa tí wọ́n nṣe àgbàwí fún “ohun titun tó kàn”9 àti ìmọ̀ ènìyàn.10 Wọn kò mọ ibi tí wọ́n ó ti rí òtítọ́.11
Àwọn àtẹ̀lé oníwàpẹ̀lẹ́ ti Krístì kò tẹ̀lé ipá ọ̀na kankan nínú rẹ̀. Àwa ni oníyárí, oníṣẹ́ ọmọ ìjọ àwọn ìletò ibi tí à ngbé. A ní ìfẹ́, àbápín, a sì pe gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run láti tẹ̀lé àwọn ìkọ́ni Krístì.12 A tẹ̀lé àmọ̀ràn olólùfẹ́ wòlíì wa, Ààrẹ Nelson pé kí: a yan ojúṣe ti “ìwàpẹ̀lẹ́, nísisìyí àti ìgbàgbogbo.”13 Ọ̀nà ìmísí yí wà léraléra pẹ̀lú ìdarí ìwé mímọ́ àti ti wòlíì.
Ní 1829 a kò tíì ṣètò ìmúpadàbọ̀sípò Ìjọ, tàbí kí a ti tẹ Ìwé ti Mọ́mọ́nì jáde. Ẹgbẹ́ kékeré ti àwọn ènìyàn tí wọ́n ntiraka, tí Ẹ̀mí Ọlọ́run wọ̀ wọ́n lọ́kàn, tẹ̀lé Wòlíì Joseph Smith. Olúwa fi hàn sí àmọ̀ràn Joseph fún àwọn ìgbà ìṣòro pé, “Máṣe bẹ̀rù, ẹ̀yin agbo kékeré; ẹ ṣe rere; jẹ́ kí ayé àti ọ̀run jùmọ̀ takò yín, nítorí bí ẹ̀yin bá jẹ́ kíkọ́ lé orí àpáta mi, wọn kì yíò lè borí.”14 Bákannáà ó gbà wọ́n lámọ̀ràn:
“Wò mi nínú gbogbo èrò, máṣe ṣiyèméjì, máṣe bẹ̀rù.
“… Jẹ́ olotitọ, pa òfin mi mọ̀, ìwọ só sì jogún ìjọba ọ̀run.”16
Ní kedere, a kìí yí àyànmọ́ tọ̀run wa padà nígbàtí a bá njìyà ìpọ́njú. Nínú Hebrews, a gba àmọ̀ràn láti “wá sí ibi ìtẹ́ oore-ọ̀fẹ́ pẹ̀lú ìgboyà, kí a lè rí àánú gbà, kí a sì rí oore-ọ̀fẹ́ láti máa rannilọ́wọ́ ní àkókò tí ó wọ̀.”17 Jésù Krístì ni “olùpìlẹ̀ṣẹ̀ ìgbàlà ayérayé.”18
Mo fẹ́ràn àwọn ọ̀rọ̀ Mọ́mọ́nì, tí a ṣe àyọsọ nípasẹ̀ ọmọ rẹ̀ Mórónì, tí ó nyin “àwọn àtẹ̀lé oníwàpẹ̀lẹ́ ti Krístì … nítorí ìrìn ìwàpẹ̀lẹ́ yín pẹ̀lú àwọn ọmọ ènìyàn.”19
Fún àwọn wọnnì lára wa nínú Ìjọ tí wọ́n ntiraka láti jẹ́ “àwọn àtẹ̀lé oníwàpẹ̀lẹ́ ti Krístì, ọjọ́ dídán kan ndúró dè wá bí a ti nfojúsí ọ̀dọ̀ Olúwa wa àti Olùgbàlà, Jésù Krístì. Àwọn ìdánwò jẹ́ ara ayé ikú ó sì nṣẹlẹ̀ nínú ayé gbogbo ènìyàn káàkiri àgbáyé. Èyí pẹ̀lú àwọn kókó ìjà ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè àti olúkúlùkù.
A nbèèrè lọ́wọ́ àwọn olórí Ìjọ lemọ́lemọ́ pé, “Kínìdí tí Ọlọ́run òtítọ́ ṣe nfi àyè gba àwọn ohun búburú láti ṣẹlẹ̀, nípàtàkì sí àwọn ẹni rere?” àti pé “Kínìdí tí àwọn tí wọ́n jẹ́ olódodo tí wọ́n sì wà nínú iṣẹ́-ìsìn kò fi ní òmìnira kúrò nínú irú àwọn àjálù bẹ́ẹ̀?”
A kò mọ gbogbo ìdáhùn; ṣùgbọ́n, a mọ àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ pàtàkì tí ó nfi àyè gbà wá láti dojúkọ àwọn ìdánwò, jàmbá, àti ìpọ́njú pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ọjọ́ ọ̀là dídán tí ó ndúró de ẹnìkọ̀ọ̀kan wa. Kò sí àpẹrẹ dídárajù tí ó wà nínú ìwé mímọ́ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ sí kíkọjá nínú jàmbá ju ọ̀rọ̀ Olúwa sí Joseph Smith, Wòlíì, nìgbàtí ó wà ní àtìmọ́lé ní Ẹ̀wọ̀n Líberty.
Olúwa ní apákan kéde pé:
“Bí àgbọ̀n ọ̀run àpáàdì tilẹ̀ rọ̀ sílẹ̀ láti la ẹnu rẹ̀ gbòòrò nítorí rẹ, ìwọ mọ̀, ọmọ mi, pé gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí yío fún ọ ní ìrírí, yíò sì jẹ́ fún ire rẹ.
“Ọmọ Ènìyàn ti sọ̀kalẹ̀ kọjá gbogbo wọn. Ṣé ìwọ tóbi jùú lọ?
“… Máṣe bẹ̀rù ohun tí ènìyàn lè ṣe, nítorí Ọlọ́run yíò wà pẹ̀lú rẹ láé àti títíláé.”20
Ó hàn kedere pé, a ní Baba ní Ọ̀run ẹnití ó mọ̀ tí ó sì fẹ́ràn wa níti araẹni tí ó sì ní òye ìjìya wa ní pípé. Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, ni Olùgbàlà àti Olùràpadà wa.
Ààrẹ Russell M. Nelson àti Ààrẹ M. Russell Ballard méjèèjì pẹ̀lú agbára ti tẹnumọ pàtàkì àtẹ̀jáde kejì titun ti Wàásù Ìhìnrere mi.20 Èmi ó ṣe àbápín ìdùnnú wọn. Àtẹ̀jáde titun yí, ṣe ìgbéga iwé mímọ́, àwọn ìkéde alágbára.
“Nínú ìrúbọ ètùtù Rẹ̀, Jésù Krístì gbé àwọn ìrora, ìpọ́njú, àti àìlera wa lé orí Ararẹ̀. Nítorí èyí, Ó mọ̀ ‘gẹ́gẹ́bí ẹran ara láti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú gẹ́gẹ́bí àìlera wọn’ (Alma 7:12; bákannáà wo ẹsẹ Kọkanla). Ó npè, ‘Wá sí ọ̀dọ̀ mi,’ àti bí a ti nṣe é, Òun ó fún wa ní ìsinmi, ìrètí, okun, ojú-ìwòye, àti ìwòsàn (Matteu 11:28; bákannáà àwọn ẹsẹ 29–30).
“Bí a ti ngbẹ́kẹ̀lé Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀, Òun lè ràn wá lọ́wọ́ láti farada àwọn ìdánwò, àìsàn, àti ìrora wa. A lè kún fún ayọ̀, àláfíà àti àrọwà. Gbogbo ohun tí kò dára nípa ìgbé-ayé ni a lè mú yẹ nípasẹ̀ Ètùtù Jésù Krístì.”23
A lè fi tayọtayọ̀ jẹ́ àwọn àtẹ̀lé oníwàpẹ̀lẹ́ ti Krístì.
Ètò ìdùnnú Baba wa fún àwọn ọmọ Rẹ̀ kìí ṣe pẹ̀lú ìṣíwájú ayé ikú àti ayè ikú nìkan ṣùgbọ́n bákannáà ó jẹ́ okun fún ìyè ayérayé, pẹ̀lú ìdàpọ̀ nlá àti ológo pẹ̀lú àwọn wọnnì tí a ti sọnù. Gbogbo àṣìṣe yíò di títúnṣe, a ó sì rí i pẹ̀lú ojú-ìwòye àìníẹ̀bi àti lílóye kedere pípé.
Àwọn olórí Ìjọ ti ṣe àfiwé ojú-ìwòye yí pẹ̀lú ẹnìkan tí ó nrìn lọ sínú àárín eré ìran-mẹta.24 Àwọn tí kò ní ìmọ̀ ètò Baba kò ní òye ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nínú ìran àkọ́kọ́ (tàbí wíwà ìṣíwájú ayé ikú) àti èrèdí tí a gbé kalẹ̀ níbẹ̀; tàbí kí wọ́n ó ní òye híhàn àti àbájáde tí ó wá látinú ìran kẹ́ta, èyí tí ó jẹ́ ìmúṣẹ ológo nípa ètò Baba.
Ọ̀pọ̀lọpọ kò mọ rírì pé lábẹ́ ètò ìfẹ́ni àti àsọyé Rẹ̀, àwọn tí wọ́n dàbíi pé wọn kò dára tó, láìsì ẹ̀bi ara wọn, kò ní ní ìpalára nígbẹ̀hìn.25
Àwọn ìwé mímọ́ hàn kedere pé: àwọn àtẹ̀lé oníwàpẹ̀lẹ́ ti Krístì tí wọ́n jẹ́ olódodo, tí wọ́n tẹ̀lé Olùgbàlà, tí wọ́n sì pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́ yíò di alábùkún fún. Ọ̀kan lára àwọn ìwé mímọ́ tí ó ṣe pàtàkì jùlọ fún àwọn tí wọ́n jẹ́ olódodo, láìka ipò wọn nínú ayé sí, ni ara ọ̀rọ̀ Ọba Benjamin sí àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó ṣe ìlérí pé àwọn wọnnì tí wọ́n pa àwọn òfin mọ́ nítòótọ́ di alábùkún fún ní gbogbo nkan nínú ayé yí a ó sì “gbà wọ́n sí ọ̀run … [tí wọn ó sí] gbé pẹ̀lú Ọlọ́run ní ipò ìdùnnú àìlópín títíláé.”26
A damọ̀ pé ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ gbogbo wa ní ó ní ìrírí ìjì ti ara àti ti ẹ̀mí nínú ayé watí àwọn kan burú púpọ̀. Olùfẹ́ni Baba kan ní Ọ̀run àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, ẹnití ó jẹ́ olórí Ìjọ ìmúpadàbọ̀sípò Rẹ̀, ti pèsè àwọn ìwé mímọ́ àti wòlíì fún wa láti múra wa sílẹ̀, kìlọ̀ fún wa nípa àwọn ewu, wọ́n sì fún wa ní ìtọ́nisọ́nà láti múrasílẹ̀ àti láti dá ààbò bò wá. Àwọn ìdarí gba ìṣe kíákíá, àwọn kàn sì pèsè ààbò fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní ọjọ́ iwájú. Ọ̀rọ̀ ìṣíwájú Olúwa sí Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú, ìpín 1, kìlọ̀ fún wa láti “gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì.”27
Ìpín 1 bákannáà bá wa wí pe, “Ẹ Múra, ẹ múra fún èyí tí yíò wá.”28 Olúwa pèsè àyè sílẹ̀ fún àwọn ènìyàn Rẹ̀ láti múrasílẹ̀ fún àwọn ìpènijà tí wọn ó kojú.
Olúwa fi ìfihàn alágbára kan fún Ààrẹ Brigham Young Ní ọjọ́ kẹrinla Oṣù Kínní, 1847, ní Winter Quarters.29 Ìfihàn yí ni àpẹrẹ olótú ti Olúwa tí ó nmúra àwọn ènìyàn sílẹ̀ fún èyí tí ó nbọ̀. Àwọn Ènìyàn Mímọ́ ti bẹ̀rẹ̀ lílọ wọn sí òkè ìyàsímímọ́ ti Àfonífojì Salt Lake. Wọ́n ti fi àṣeyege kọ́ Tẹ́mpìlì Nauvoo wọ́n sì ti gba àwọn ìlànà ìgbàlà. A ti lé wọn kúrò ní Missouri, àti pé àwọn aninilára wọn ti lé wọn jáde kúrò ní Nauvoo ní àkokò òtútù líle. Ìfihàn náà sí Brigham fi àmọ̀ràn àfojúrí fúnni lórí bí wọn ó ti múrasílẹ̀ fún lílọ. Olúwa fi àtẹnumọ́ pàtàkì sí títọ́jú àwọn òtòṣì, opó, àìníbaba, àti ẹbí àwọn wọnnì tí wọ́n nsìn nínú Ọmọ-ogun Bàtàlíọ̀nù Mọ́mọ́nì bí ara kan ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ ṣe ntẹ̀síwájú lórí ìrìnàjò wọn.
Ní àfikún sí pípèsè àwọn ìmọ̀ràn míràn láti gbé pẹ̀lú òdodo, Olúwa tẹnumọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ méjì tí ó tẹ̀síwájú láti jẹ́ lílò ní òní.
Ní àkọ́kọ́, Ó gbà wọ́n níyànjú láti “yin Olúwa pẹ̀lú orin kíkọ, pẹ̀lú orin, pẹ̀lú jíjó, àti pẹ̀lú àdúrà ìyìn àti ṣíṣọpẹ́.”30
Ìkejì, Olùwa fún wọn ní àmọ̀ràn bí wọ́n bá “banújẹ́, kí wọ́n pe Olúwa Ọlọ́run wọn pẹ̀lú àdúrà, pé kí ọkàn wọn lè yọ̀.”31
Àwọn ìkìlọ méjì wọ̀nyí jẹ́ àmọ̀ràn nlá fún ọjọ́ ti ara wa. Ìgbé ayé tó kún fún ìyìn, orin, àti ṣíṣọpẹ́ ni ó di alábùkún àìláfiwé. Jíjẹ́ aláyọ àti gbígbẹ́kẹ̀lé ìrànlọ́wọ́ tọ̀run nípasẹ̀ àdúrà ni ọ̀nà alágbára láti jẹ́ àwọn àtẹ̀lé oníwàpẹ̀lẹ́ ti Krístì Títiraka nígbàgbogbo láti tújúká nṣèrànwọ́ láti yẹra fún níní ìrẹ̀wẹ̀sì nínú ẹ̀mí.
Òpin ìlà orin ojú-ìwòye tí ó ngbé ìdáhùn ìgbẹ̀hìn ti ẹ̀ṣọ́ rírẹwà jáde: “Ayé kò ní ìkorò tí ọ̀run kò lè wòsàn.”32
Gẹ́gẹ́bí Àpóstélì Olúwa Jésù Krístì kan, mo jẹ̀ ẹ̀rí pé “àwọn àtẹ̀lé Krístì” yìó rí àláfíà araẹni nínú ayé yí àti idàpọ̀ ológo tọ̀run. Mo jẹ́ ẹ̀rí dídájú mi nípa àtọ̀runwá Olùgbàlà àti òdodo Ètùtù Rẹ̀. Òun ni Olùgbàlà àti Olùràpadà wa. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.