Àwọn Àmì Ìyàsọ́tọ̀ ti Ìdùnnú
Kíkọ́ lé orí ìpìlẹ̀ ti Jésù Krístì ṣe kókó sí ìdùnnú wa.
Nígbàtí mo wà lórí ọkọ-òfúrufú fún iṣẹ́ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn, mo rí ara mi ní jíjoko ní ẹ̀gbẹ́ ọkùnrin kan láti Netherlands. Mo ní ìtara láti bẹ̀ ẹ́ wò níwọ̀nbí mo ti sìn ní Belgium àti ní Netherlands bí ọ̀dọ́ òjíṣẹ́ ìhìnrere.
Bí a ti nmọra, ó fúnmi ní káàdì iṣẹ́ pẹ̀lú àkọlé iṣẹ́ àìláfiwé ti “ọ̀jọ̀gbọ́n ìdùnnú.” Mo sọ̀rọ̀ ṣokí lórí iṣẹ́ yíyanilẹ́nu rẹ̀ mo sì béèrè ohun tí ọ̀jọ̀gbọ́n ìdùnnú nṣe. Ó ní òun nkọ́ àwọn ènìyàn bí wọn ó ti ní ìgbé ayé ìdùnnú nípa ṣíṣe àgbékalẹ̀ àwọn ìbáṣepọ̀ àti àwọn àfojúsùn tó nítumọ̀. Mo fèsì pé, “Èyí yanilẹ́nu, ṣùgbọ́n yí ó ti rí bí o bá le kọ́ni bákannáà bí àwọn ìbáṣepọ̀ wọnnì bá le tẹ̀síwájú tayọ ibojì tí o sì dáhùn àwọn ìbéèrè míràn ti ọkàn, bí irú kínni èrèdí ìgbé ayé, báwo ni a ṣe le borí àwọn àìlera wa, àti níbo ni a nlọ lẹ́hìn tí a bá kú? Ó gbà pé yío jẹ́ ohun yíyanilẹ́nu bí a bá ní àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nnì, ó sì dùn mọ́mi láti ṣe àbápín pẹ̀lú rẹ̀ pé a ni.
Lóni, yío wù mí láti ṣe àgbéyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tó ṣe kókó fún ìdùnnú tòótọ́ tí ó dàbí pé ó ti fo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ru nínú ayé rúdurùdu yi, níbirí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn nkan ti nwuni ṣùgbọ́n tí díẹ̀ ṣe pàtàkì nítòótọ́.
Alma kọ́ àwọn ènìyàn ìgbà rẹ̀ pé, “Nítorí ẹ kíyèsĩ, èmi wí fún un yín, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ni ó nbọ̀wá; kí ẹ kíyèsĩ, ohun kan wà, èyítí ó ṣe pàtàkì ju gbogbo wọn lọ—nítorí ẹ kíyèsĩ, àkokò nã kò jìnà tí Olùràpadà yío máa gbé tí yíò sì wá sí ààrín àwọn ènìyàn rẹ̀.”1
Ìkéde yi ṣe pàtàkì sí wa bákannáà ní òní bí a ti nretí tí a sì nmúrasílẹ̀ fún Bíbọ̀ Èkejì ti Krístì!
Nítorínáà, àkíyèsí mi àkọ́kọ́ ni pé kíkọ́ lé orí ìpìlẹ̀ ti Jésù Krístì ṣe kókó sí ìdùnnú wa. Èyí ni ìpìlẹ̀ kan tí ó dájú, “ìpìlẹ̀ kan níbití bí àwọn ènìyàn bá kọ́ lé, wọn kò le ṣubú.”2 Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ nmúra wa sílẹ̀ fún àwọn ìpèníjà ti ìgbé ayé, bí ó ti wù kí ó rí.
Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́hìn, mo lọ sí ibi ìpàgọ́ àwọn Síkáòtù ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn pẹ̀lú ọmọkùnrin wa Justin. Bí àwọn ètò náà ti nlọ lọ́wọ́, ó fi pẹ̀lú ìwúrí kéde pé òun àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ fẹ́ gba àmì-ẹ̀yẹ eré tafàtafà ṣíṣe. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ nílò kí àwọn ọmọkùnrin náà ó yege nínú ìdánwò kíkọ kúkúrú kan kí wọn ó sì gún ohun àfojúsùn kan pẹ̀lú ọfà wọn.
Ọkàn mí rì. Ní àkókò yí, Justin jẹ́ aláìlágbára gan-an nítórí okùn-iṣan wíwú, àrùn kan tó ti nbá jà láti ìgbà ìbí. Mo ròó bí ó bá le fa ọrun náà sẹ́hìn tó láti ju ọfà sí ohun àfojúsùn.
Bí òun àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ti kúrò lọ sí ibi kíláàsì àwọn tafàtafà, mo gbàdúrà jẹ́jẹ́ pé kò ní di ẹni yẹ̀yẹ́ nípasẹ̀ ìrírí náà. Lẹ́hìn àwọn wákàtí àníyàn díẹ̀, mo rí i tí ó nbọ̀wá sí ìhà ọdọ̀ mi pẹ̀lú ẹ̀rín-músẹ́ títóbi kan. “Baba!” ó kígbe. “Mo gba ìtọ́sí àmì-ẹ̀yẹ náà! Mo gún ojú akọ mãlù kan; ó wà lára ìfojúsùn ti ẹ̀gbẹ́ tèmi, ṣùgbọ́n mo gún ojú akọ mãlù kan!” Ó ti fa ọrun náà lọ sẹ́hìn tó pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ̀ ó sì jẹ́ kí ọfà fò, láìle darí ipa lílọ rẹ̀. Mo ti ní ìmoore tó fún ìfaradà olùkọ́ àwọn tafàtafà náà, tí kò sọ pé, “Ó mà ṣe o, àṣìṣe àfojúsí!” Dípò bẹ́ẹ̀, ní rírí àwọn àlébù àti ìgbìyànjú pẹ̀lú ìtara Justin, ó fi àánú dáhùn pé, “Iṣẹ́ rere!”
Báyí ni yío ti rí fúnwa bí a bá ṣe dáradára jùlọ tí a le ṣe láti tẹ̀lé Krístì àti àwọn wòlíì Rẹ̀ láìka àwọn àlébù wa sí. Bí a bá wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nípa pípa àwọn májẹ̀mú wa mọ́ àti ríronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, a ó fi pẹ̀lú ayọ̀ gbọ́ oríyìn Olùgbàlà wa pé: “O ṣeun, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere àti olõtọ́.”3
Mo jẹ́ ẹ̀rí mi sí yín nípa jíjẹ́ ti ọ̀run Olùgbàlà aráyé àti nípa ìfẹ́ àti agbára ìranipadà Rẹ̀ láti wòsàn, fún lókun, àti láti gbé wa sókè nígbàtí a bá nfi ìtara làkàkà láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ní ìdàkejì, kò sí bí a ṣe le lọ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ èrò àti bákannáà sí ìhà Jésù. Olùgbàlà ti ṣẹgun ikú, àrùn, àti ẹ̀ṣẹ̀ ó sì ti pèsè ọ̀nà kan fún pípé wa ní ìgbẹ̀hìn bí a bá tẹ̀lé E pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa.4
Àkíyèsí mi kejì ni pé ó ṣe pàtàkì sí ìdùnnú wa pé kí a máa rántí pé àwa jẹ́ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ti olùfẹ́ni Baba Ọ̀run kan. Mímọ̀ àti gbígbẹ́kẹ̀lé òtítọ́ yí nyí ohun gbogbo padà.
Ní ọdún púpọ̀ sẹ́hìn, nínú ọkọ̀ òfurufú wá sílé láti ibi iṣẹ́ yíyàn ti Ìjọ kan, Arábìnrin Sabin àti èmi bá ara wa ní ìjókòó tààrà lẹ́hìn ọkùnrin títóbi gidi kan tí ó ní ilà ìwò ojú nlá àti ìbínú ní yíyà sí ẹ̀hìn orí pípá rẹ̀ àti bákannáà nọ́mbà 439.
Nígbàtí a gúnlẹ̀, mo wí pé, “Mo tọrọ gáfárà, sà. Njẹ́ mo le bèèrè nípa pàtàkì nọ́mbà tí wọ́n ya ilà rẹ̀ sí ẹ̀hìn orí rẹ?” Èmì kò bèèrè nípa ìwò ojú tó nbínú.
Ó wípé, “Èmi ni. Èyí ni ẹni tí mo jẹ́. Èmi ló ni ààlà náà: 219!”
Ọgọrun mẹ́rin àti mọ́kàndínlógójì ni nọ́mbà náà gan-an tí ó wà ní orí rẹ̀, nítorínáà ó yà mí lẹ́nu pé ó ṣì í pè níwọ̀n ìgbàtí ó ti jẹ́ pàtàkì sí i tóbẹ́ẹ̀.
Mo ronú nípa bí ó ti bani-nínújẹ́ tó pé ìdánimọ̀ àti iyì-ara ẹni ọkùnrin yí dá lórí nọ́mbà kan tí ó ní í ṣe pẹ̀lú agbégbé ẹgbẹ́ ipá kan. Mo ronú sí ara mi pé: ọkùnrin tí ìwò ojú rẹ̀ le burúkú yi ti fi ìgbà kan rí jẹ́ ọmọdékùnrin ti ẹnìkan tí ó ṣì nílò láti ní ìmọ̀lára iyì àti jíjẹ́ ti ẹni. Bí ó bá mọ ẹnítí òun jẹ́ gan-an àti ti ẹni tí òun í ṣe, nítorí gbogbo wa ni a ti “rà pẹ̀lú iye kan.”5
Ìlà ọgbọ́n kan wà nínú orin kan láti inú fíìmú Ọmọ Ọba Egiptì tí ó sọ pé, “Wo ayé rẹ láti inú àwọn ojú ti ọ̀run.”6 Bí ìmọ̀ nípa ìran àtọ̀rúnwá àti agbára ayérayé wa ti nwọlé jinlẹ̀ sí inú ọkàn wa, àwa yío le wo ìgbé ayé wa pẹ̀lú èrèdí, ní fífi ìdáwọ́lé hàn láti kọ́ ẹ̀kọ́ àti láti gbèrú láti inú rẹ̀, àní bí “a ti nrí láti inú jígí, ní síṣókùnkùn”7 fún ìgbà kúkúrú kan.
Ìkẹta àmì ìyàsọ́tọ̀ fún ìdùnnú ni láti máa fi ìgbà gbogbo rántí ìkàyẹ ti ọkàn kan. A nṣe èyí dára jùlọ nípa títẹ̀lé ìkìlọ̀ Olùgbàlà pé: “ Ẹ fẹ́ràn ara yín; bí èmi ti fẹ́ràn yín.”8
Ó kọ́ni bákannáà pé, “Níwọ̀n bí ẹyin bá ti ṣé sí ọ̀kan tó kéréjù lára àwọn arákùnrin mi wọ̀nyí, ẹyin ti ṣe é sí mi.”9
Ìwé Òwe fi ọgbọ́n dáni nímọ̀ràn pé, “Máṣe fawọ́ ire sẹ́hìn kúrò lọ́dọ̀ ẹnití í ṣe tirẹ̀, bí ó bá wà ní agbára ọwọ́ rẹ láti ṣe é.”10
A kì yío ké àbámọ̀ láé pé a nṣe àánú púpọ̀. Ní ojú Ọlọ́run, ìnú rere jẹ́ ọ̀kannáà pẹ̀lú dídi nlá. Apákan jíjẹ́ alãnú ni jíjẹ́ olùdáríjini àti aláìdánilẹ́jọ́.
Ní àwọn ọdún púpọ̀ sẹ́hìn ọ̀dọ́ ẹbí wa fẹ́ wo eré ìtàgé kan fún ìpàdé ẹbí nílé nírọ̀lẹ́. Gbogbo wa ti wà nínú ọkọ̀ bíkòṣe fún ọmọkùnrin wa kan àti ìyàwó mi, Valerie. Ilẹ̀ ti ṣú tẹ́lẹ̀, bí ọmọkùnrin wa ti ṣí ìlẹ̀kùn tí ó sì sáré sí ìhà ibi ọkọ̀, ó ṣèèṣì gbá ohun kan tí ó rò pé ó dàbí ológbò ní ibi ẹnu ọ̀nà. Pẹ̀lú ìkãnú fún ọmọkùnrin wa àti ìyàwó mi, tí ó wà ní ẹ̀hìn rẹ̀ tààrà, kìí ṣe ológbò wa ṣùgbọ́n dípò rẹ̀ síkọ́nkì kan tí inú rẹ̀ kò dùn rárá, tí ó sì jẹ́ kí wọn ó mọ̀ ọ́! Gbogbo wa padà sí inú ilé, nibití àwọn méjèèjì ti wẹ̀ tí wọ́n sì fọ irun wọn pẹ̀lú omi tòmátò, tí ó yẹ dájú fún àtúnṣe láti pa òórùn síkọ́nkì rẹ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n ó fi tún ara wọn ṣe tí wọ́n sì pààrọ̀ aṣọ wọn, gbogbo wa ti di aláìní imú sí òórùn kankan, nítorínáà a pinnu pé a ti dára láti lọ sí ibi eré ìtàgé náà.
Lẹ́ẹ̀kannáà tí a jókòó ní ẹ̀hìn gbọ̀ngàn náà, ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ní àyíká wa pinnu lójijì láti jáde lọ ra gúgúrú. Ṣùgbọ́n, nígbàtí wọ́n padà dé, ìkankan kò padà sí orí ìjókòó wọn ti tẹ́lẹ̀.
A ti rẹ́rĩn bí a ti rántí ìrírí náà, ṣùgbọ́n yío ti rí bí gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa bá ní òórùn? Yío ti rí bí a bá le gbọ́ òórùn àìṣòtítọ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, ìlara, tàbí ìgbéraga? Pẹ̀lú àwọn àìlera tiwa ní fífihàn, ìrètí wà pé a ó máa ṣọ́ra a ó sì máa gba ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíràn yẹ̀wò díẹ̀ síi àti, bẹ́ẹ̀, àwọn náà pẹ̀lú wa bí a ti nṣe àwọn ìyípadà tí a nílò ní ìgbé ayé wa. Mo fẹ́ràn òórùn tábà nínú ilé ìjọsìn, nítorípé ó fihàn pé ẹnìkan ngbìyànjú láti yípadà. Wọ́n nílò àwọn ọwọ́ ìkíni-káàbọ̀ wa yíka ara wọn.
Ààrẹ Russell M. Nelson ti sọ pẹ̀lú ọgbọ́n pé, “Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó rọrùn jùlọ láti mọ àtẹ̀lé tòótọ́ ti Jésù Krístì ni bí ẹni náà ti nṣe pẹ̀lú àánú sí àwọn ẹ̀nìyàn míràn sí.”11
Páùlù kọ̀wé sí àwọn ará Éfésù pé, “Ẹ máa ṣoore fún ọmọnìkejì yín, ẹ ní ìyọ́nú, ẹ máa dáríjì ara yín, àní bí Ọlọ́run nínú Krístì ti darí yín.”12
Bí àwọn ọmọẹ̀hìn Jésù Krístì, a pè wá láti gbẹ́kẹ̀lé Baba Ọ̀run àti Olùgbàlà wa kí a má sì ṣe gbìyànjú láti pààrọ̀ Wọn. Jésù Krístì mọ̀ àwọn àìpé gbogbo ènìyàn ní pípé yío sì ṣe ìdájọ́ wọn ní pípé.
Àmì ìyàsọ́tọ̀ ìdùnnú ìkẹrin tèmi ni láti dúró nínú ìwòye ayérayé kan. Ètò ti Baba wa ràn dé inú àwọn ayérayé; ó rọrùn láti fi ojú sun ìhínyí àti ìsisìyí kí a sì gbàgbé ti ẹ̀hìn-ìhínyìí.
A kọ́mi ní ẹ̀kọ́ yí pẹ̀lú agbára ní iye àwọn ọdún kan sẹ́hìn láti ọwọ́ ọmọbìnrin wa, Jennifer, ẹni ọdún mẹ́rìndínlógún nígbànáà. Ó ti fẹ́ ní iṣẹ́ abẹ pípàrọ̀ ẹ̀dọ̀fóró méjì, nibití àwọn lóòbù márũn tí wọ́n nṣàìsàn nínú àwọn ẹ̀dọ̀fóró rẹ̀ yío ti jẹ́ yíyọ kúrò pátápátá tí wọn ó sì fi àwọn lóóbù kékeré tí wọ́n lálàáfíà méjì paàrọ̀ wọn, tí a fi sílẹ̀ nípasẹ̀ àwọn ọ̀rẹ́ yíyanilẹ́nu bíi ti Krístì. Ó jẹ́ ìlànà tí ó ga ní ewu, síbẹ̀ ní alẹ́ tọ́ ṣaájú iṣẹ́ abẹ rẹ̀, Jennifer fẹ́rẹ̀ wàásù sí mi pẹ̀lú gbogbo títóbi 90 pound (mọ́kànlélógójì kílò), rẹ̀, wípé, “Má ṣèyọnu, Baba! Ní ọ̀la èmi ó jí pẹ̀lú àwọn ẹ̀dọ̀fóró titun tàbí èmi ó jí ní ibi tí ó dárajù. Ọnà yíówù kó jẹ́ yío dára.” Èyí ni ìgbàgbọ́; èyí ni ìwòye ayérayé! Rírí ìgbé ayé láti ibi ọ̀gangan ànfààní ayérayé npèsè ṣíṣe kedere, ìtùnú, ìgboyà, àti ìrètí.
Nígbàtí ọjọ́ tí a ti ndúró fún tipẹ́ náà dé láti yọ okùn oníhò èémí kí wọn ó sì pa ẹrọ atẹ́gùn tí ó ti nran Jennifer lọ́wọ́ lati mí, a dúró pẹ̀lú àníyàn láti ríi bóyá àwọn lóòbò kékèké méjì rẹ̀ yío ṣiṣẹ́. Nígbàtí ó mí èémí rẹ̀ àkọ́kọ́, lójúẹsẹ̀ ó bẹ̀rẹ̀ sí sunkún. Ní rírí àníyàn wa, ó yára sọ̀rọ̀ sókè pé, “Ó kan dára tóbẹ́ẹ̀ láti mí.”
Láé láti ọjọ́ náà, mo ti dúpẹ́ lọ́wọ́ Baba Ọ̀run ní òwúrọ̀ àti alẹ́ pé ó ṣeéṣe fúnmi láti mí. A jẹ́ yíyíká pẹ̀lú àwọn ìbùkún àìlónkà tí a le fi ìrọ̀rùn mú ní yẹpẹrẹ bí a kò bá ṣọ́ra. Ní ìdàkejì, nígbàtí a kò bá retí ohunkóhun tí a sì mọyì ohun gbogbo, ìgbé ayé ó ndàbí idán.
Ààrẹ Nelson ti sọ pe: “Òwúrọ̀ tuntun kọ̀ọ̀kan jẹ́ ẹ̀bùn kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Àní afẹ́fẹ́ tí a nmí jí olùf.ẹni ẹ̀yáwó láti ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ó npawá mọ́ láti ọjọ́ dé ọjọ́ ó sì ntìwá lẹ́hìn láti àkókò kan sí òmíràn. Nítorínáà, ìṣe ọlọ́la wa àkọ́kọ́ ti òwúrọ̀ níláti jẹ́ àdúrà ìrẹ̀lẹ̀ ti ìmoore.”13
Èyí mú mi wá sí àkíyèsí mi ìkarũn àti ìparí, èyítí í ṣe pé ẹ kò le ní ìdùnnú síi láé ju bí ẹ ti fi ìmoore hàn lọ.
Olúwa kéde pé, “Ẹnití ó bá sì gba ohun gbogbo pẹ̀lú ọpẹ́ ni a ó ṣe lógo.”14 Bóyá èyí jẹ́ nítorípé ìmoore nfi ìbí fún ọ̀gọ̀rọ̀ àwọn ìwà rere míràn.
Òye wa yío ti yípadà tó bí a bá jí ní gbogbo owúrọ̀ pẹ̀lú àwọn ìbùkún tí a fi ìmoore hàn fún ní alẹ́ ìṣaájú nìkan. Ìkùnà láti mọ iyì àwọn ìbùkún wa le yọrí sí àìnítẹ́lọ́rùn, èyítí ó le jà wá lólè ayọ̀ àti ìdùnnú tí ìmoore nmúwá. Àwọn wọnnì tí wọ́n wà nínú ilé nlá tó sì ní ààyè ntàn wá láti wò kọjá àmì, nípa bẹ́ẹ̀ kí a sì pàdánù àmì náà pátápátá.
Ní tòótọ́, ìdùnnú àti ìbùkún tó tobijùlọ ti ayé kíkú ni a ó ri nínú ẹnití a ti dà nípasẹ̀ oore ọ̀fẹ́ Ọlọ́run bí a ti ndá tí a sì npa àwọn májẹ̀mú mímọ́ pẹ̀lú Rẹ̀ mọ́ Olùgbàlà wa yío gbọ̀nwá nù yío sì túnwaṣe nípasẹ̀ àwọn ìtọ́sí ti ọrẹ ẹbọ ètùtù Rẹ̀ Ó sì ti sọ nípa àwọn tí wọ́n fi tínútinú tẹ̀lé E pé, “Wọn yío jẹ́ tèmi ní ọjọ́ náà nígbàtí èmi ó wá láti wá tún àwọn ọ̀ṣọ́ mi ṣe.”15
Mo ṣe ìlérí fún yín pé bí a bá kọ́ ìgbé ayé wa sí orí ìpìlẹ̀ ti Jésù Krístì; tí a mọ iyì ìdánimọ̀ òtítọ́ wa bíi ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Ọlọ́run; tí a rántí yíyẹ ọkàn kan; tí a dúró nínú ìwòye ayérayé; tí a sì fi pẹ̀lú ìmoore mọyì àwọn ọ̀pọ̀ ìbùkun wa, ní pàtàkì ìpè ti Krístì láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀, a le rí ìdùnnú tòótọ́ tí a nlépa nínú ìdáwọ́lé ayé kíkú yi. Ìgbé ayé yío ní àwọn ìdojúkọ rẹ̀ síbẹ̀, ṣùgbọ́n a ó ní agbára láti kojú ọ̀kọ̀ọ̀kan dára síi pẹ̀lú èrò inú àti àlàáfíà nítorí àwọn òtítọ́ ayérayé tí a ní òye rẹ̀ tí a sì fi ngbé.
Mo jẹ́ ẹ̀rí mi fún yín nípa jíjẹ́ òtítọ́ ti Ọlọ́run, olùfẹ́ni Baba wa, àti ti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ, Jésù Krístì. Bákannáà mo jẹ́rìí nípa àwọn wòlíì alààyè, àwọn aríran, àti àwọn olùfihàn. Ó ti jẹ́ ìbùkún tó láti gba ìmọ̀ràn ọ̀run nípasẹ̀ wọn. Bí Olùgbàlà ti sọ kedere pé, “Bóyá nípa ohun ara mi tàbí nípa ohun àwọn ìránṣẹ́ mi, ó jẹ́ ọ̀kannáà.”16 Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.