Fẹ́ Ọmọnìkejì Rẹ
Ìyọ́nú jẹ́ ẹ̀yà ti Krístì. A bi i nípasẹ̀ ìfẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn kò sì mọ àwọn ààlà.
Ní òwúrọ̀ yí, mo pé yín láti darapọ̀ mọ́ mi nínú ìrìnàjò Áfríkà kan. Ẹ kì yíò rí eyikeyi àwọn kìnìún, abilà, tàbí erin, ṣùgbọ́n bóyá ní òpin ìrìn-àjò, ẹ o ríi bí ẹgbẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-Ìkẹhìn ṣe ndáhùn ní ọ̀nà aláìlẹ́gbẹ́ sí òfin nlá kejì ti Krístì “fẹ́ ọmọnìkejì rẹ” (Mákù12:31).
Fojúinú wò fún ìṣẹ́jú kan, ìgbèríko náà, erùpẹ̀ pupa Áfríkà. Ẹ rí láti ìyàngbẹ àti àgàn ilẹ̀ pé òjò kò rọ̀ ni eyikeyi ìwọ̀n tó ṣeé wọ̀n fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Àwọn ẹran-ọ̀sìn díẹ̀ tí wọ́n kọjá ní ipa ọ̀nà rẹ jẹ́ egungun díẹ̀ síi ju ẹran-ara lọ a sì ndarí wọn nípasẹ̀ darandaran Karamajong kan tí ó, pẹ̀lú ẹsẹ̀ nínú sálúbàtà, ó nrìn lọ ní ìrètí wíwá ewéko àti omi.
Bí ẹ ṣe nlọ kiri ní ọ̀nà tí ó nira tí ó sì ní òkúta, ẹ ó rí ọ̀pọlọ̀pọ̀ ẹgbẹ́ àwọn arẹwà ọmọdé ó sì jẹ́ ìyàlẹ́nu ìdí tí wọn kò fi sí ní ilé-ìwé. Àwọn ọmọdé náà rẹrin músẹ́ wọ́n sì ju ọwọ́, ẹ̀yin náà á sì ju ọwọ́ padà pẹ̀lú omijé àti ẹ̀rín músẹ́. Ìdá àádọ́rũn ólé méjì lára àwọn ọmọ tó kéré jùlọ tí ẹ rí nínú ìrìn àjò yìí ngbé nínú òṣì oúnjẹ, ọkàn yín sì kérora pẹ̀lú ìdààmú.
Ní iwájú, ẹ o rí ìyá kan tí ó gbé omi gálọ́nù márùn-ún (lítà mọ́kàndínlógún) tí ó farabàlẹ ṣe ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì ní orí rẹ̀ àti òmíràn ní ọwọ́ rẹ̀. Ó jẹ́ aṣojú ọ̀kan nínú àwọn ìdílé méjì-mẹ́jì ní agbègbè yí níbití àwọn obìnrin, ọ̀dọ́ àti àgbà, ti nrìn ju ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lọ, ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, lọ sí orísun omi fún ẹbí wọn. Ìgbì ìbànújẹ́ nṣàn lórí yín.
Wákàtí méjì kọjá ẹ sì dé ibi yíyàsọ́tọ̀, abẹ́ òjìjí kan sísanwó fún. Ibi ìpàdé náà kì í ṣe gbọ̀ngàn kan tàbí àgọ́ pàápàá, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, lábẹ́ àwọn igi nlánlá díẹ̀ tí ó npèsè ààbò lọ́wọ́ oòrùn mímú yanyan. Ní ibí yíì, ẹ ṣe àkíyèsí pé kò sí omi ṣíṣàn, kò sí iná mọ̀nàmọ́ná, kò sí àwọn ilé-ìgbọ̀nsẹ̀ ìgbàlódé. Ẹ wò yíká ẹ sì mọ̀ pé ẹ wà láarín àwọn ènìyàn kan tí wọ́n fẹ́ràn Ọlọ́run ẹ̀yin sì ní ìmọ̀lára ìfẹ́ Ọlọ́run fún wọn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Wọ́n ti péjọ láti gba ìrànlọ́wọ́ àti ìrètí, àti pé ẹ ti dé láti pín in.
Irú ìrìn àjò bẹ́ẹ̀ ni ti Arábìnrin Ardern àti èmi, nínú àjọrìn ti Arábìnrin Camille Johnson, Àarẹ Gbogbogbò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ àti ọkọ rẹ̀ Doug àti Arábìnrin Sharon Eubank, olùdarí Àwọn Ìṣẹ Ìrannilọ́wọ́ ti Ìjọ, bí a ti rin ìrìn-àjò ní Uganda, orílẹ̀-èdè tí ó ní mílíọ̀nù 47 ènìyàn ní Ààrin-Gbùngbùn Áfríkà ti ìjọ. Ní ọjọ́ náà, lábẹ́ òjìji àwọn igi, a ṣàbẹ̀wò sí iṣẹ́ àkànṣe ti ètò ìlera agbègbè kan ti ìpawọ́pọ̀ latí ọwọ́ Ilé-iṣẹ́ Àwọn Ìṣẹ Ìrannilọ́wọ́ ti Ìjọ ṣe agbátẹrù rẹ̀, UNICEF, àti Ilé-iṣẹ́ Ètò Ìlera tí Ìjọba Uganda. Ìwọ̀nyí jẹ́ àwọn ẹgbẹ́ tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀lé, tí a ti yàn pẹ̀lú ìṣọ́ra láti ríi dájú pé àwọn owó ìtọrẹ fún ètò ìrannilọ́wọ́ tí àwọn ọmọ ìjọ dá jẹ́ lílò pẹ̀lú ọgbọ́n.
Bí ó ti bani lọ́kàn jẹ́ tó láti rí àwọn ọmọdé tí wọn kò rí ànító oúnjẹ jẹ àti àwọn ipa ikọ́ ẹ̀gbẹ, ibà, àti ìgbẹ́ gbuuru lemọ́-lemọ́, àlékún ìrètí wá sí ọ̀dọ̀ ọ̀kọ̀ọ̀kan wa fún ọjọ́ ọ̀la dídára síi fún àwọn tí a pàdé.
Ìrètí náà wá, ní apá kan, nípasẹ̀ inú rere àwọn ọmọ Ìjọ láti gbogbo àgbáyé tí wọ́n nfi àkókò àti owó ṣètọrẹ fún ìgbìyàjú ọmọnìyàn ti Ìjọ. Bí mo ṣe rí àwọn aláìsàn àti àwọn tí ó ní ìpọ́njú ní rírànlọ́wọ́ àti gbígbé sókè, mo tẹ orí mi ba fún ìmoore. Ní àkókò náà, mo túbọ̀ lóye ohun tí Ọba àwọn ọba túmọ̀ sí, ẹni tí ó sọ pé:
“Ẹ wá, ẹ̀yin ẹni ìbùkún ti Baba mi, ẹ jogún ìjọba tí a pèsè sílẹ̀ fún yin… :
“Nítorí ebi pa mi, ẹ̀yin sì fún mi ní oúnjẹ, óungbẹ ngbẹ mí, ẹ̀yin fún mi ní ohun mímu: mo jẹ́ àlejò, ẹ̀yin sì gbà mí sí ilé” (Máttéù 25:34–35).
Ẹ̀bẹ̀ Olùgbàlà wa ni pé “Ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè rí iṣẹ́ rere yín, kí wọ́n sì lè yin Baba yín tí nbẹ ní ọ̀run lógo” (Máttéù 5:16; bakanáà wo àwọn ẹsẹ 14–15). Ní igun ilẹ̀ ayé tí ó jìnnà réré náà, àwọn iṣẹ́ rere yín mú kí ìgbésí ayé wọn mọ́lẹ̀, ó sì mú kí ẹrù àwọn ènìyàn tí wọ́n nílò rẹ̀ láìdaba fúyẹ́, a sì yin Ọlọ́run lógo.
Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó wùmí kí ẹ ti gbọ́ àdúrà ìdúpẹ́ àtọkànwá wọn sí Ọlọ́run. Wọn yìó fẹ́ kí nsọ fún yín ní èdè àbínibí Karamajong wọn, “Alakara.” Ẹ ṣeun.
Ìrìn àjò wa rán mi létí òwe ará Samáríà Rere náà, ẹni tí ìrìn àjò rẹ̀ gbé e lọ ní ojú ọ̀nà eléruku, kò yàtọ̀ sí èyí tí mo ṣàpèjúwe, ọ̀nà kan tó lọ láti Jerúsálẹ́mù sí Jẹ́ríkò. Ara Samáríà oníṣẹ́ìránṣẹ́ yìí kọ́ wa ní ohun tó túmọ̀ sí láti ní “ìfẹ́ ọmọnìkejì rẹ.”
Ó rí “ọkùnrin kan … [ẹni tí] ó bọ́ sí ọwọ́ àwọn ọlọ́ṣà, tí wọ́n gbà á ní aṣọ, wọ́n sì ṣá a lọ́gbẹ́, tí wọ́n sì fi sílẹ̀ lọ, ní àìpa tán” (Lúùkù 10:30). Ará Samaria náà “ní ìyọ́nú sí i” (Lúùkù 10:33).
Ìyọ́nú jẹ́ ẹ̀yà ti Krístì. A bi i nípasẹ̀ ìfẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn kò sì mọ àwọn ààlà. Jésù, Olùgbàlà aráyé, ni àkópọ̀ ìyọ́nú. Nígbàtí a kà pé “Jésù sọkún” (Jòhánnù 11:35), àwa jẹ́ ẹlẹri, bí Maria ati Marta ṣe jẹ́, èyí tí ìyọ́nú Rẹ̀, èyí tí Ó mú kí ó kérora ní ọkàn tí inú sì bàjẹ́ (wo Jòhánnù 11:33). Nínú àpẹrẹ Ìwé ti Mọ́mọ́nì kan ti ìyọ́nú Krístì, Jésù farahàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ó sì wí pé:
Njẹ́ ẹ ní ẹnikẹ́ni tí ó yarọ, tàbí fọ́jú, … yadi, tàbí tí wọ́n ní ìpọ́njú ní ọ̀nàkọnà? Ẹ mú wọn wá sí ìhín èmi yíò sì wò wọ́n sàn, nítorítí èmi ní ìyọ́nú sí yín. …
Ó sì mú gbogbo wọn láradá” (3 Néfì 17:7, 9).
Pẹ̀lú gbogbo ìgbìyànjú wa, ẹ̀yin àti Èmi kì yíò mú gbogbo ènìyàn láradá ṣùgbọ́n ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè jẹ́ ẹni tí ó lè ṣe ìyàtọ̀ fún rere ní ìgbésí ayé ẹnìkan. Ọmọdékùnrin kan ṣoṣo, ọmọkùnrin lásán, ló fi ìṣù búrẹ́dì márùn-ún àti ẹja méjì tí ó bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún náà sílẹ̀. A lè béèrè nípa ọrẹ ẹbọ wa, gẹ́gẹ́bí Ándérù ọmọ ẹ̀hìn ti ṣe nípa búrẹ́dì àti ẹja náà, “Kí ni wọ́n jẹ́ láàrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ bẹ́ẹ̀?” (Jòhánnù 6:9). Mo fi dá yin lójú pé; ó tó láti fúnni ní ohun tí ẹ lè fún ni tàbi tí ẹ lè ṣe àti lẹ́hìnnáà láti gba Krístì láàyè láti gbé ìtiraka wa ga.
Lórí ààyè yí, Alàgbà Jeffrey R. Holland pè wá, “ọlọ́rọ̀ tàbí tálákà, … láti ‘ṣe ohun tí a lè’ nígbàtí àwọn míràn wà nínú àìní.” Lẹ́yìn náà, ó jẹ́ ẹ̀rí, gẹ́gẹ́bí mo ti nṣe, pé Ọlọ́run “yíò ràn yín lọ́wọ́, yíò sì ṣamọ̀nà yín nínú àwọn ìṣe ìyọ́nú [yín] ti jíjẹ́ ọmọlẹ̀hìn” (““Ṣé Gbogbo Wa Kì Ha Ṣagbe?,” Liahona, Nov. 2014, 41).
Ní ilẹ̀ jíjìnnà náà, ní ọjọ́ mánigbàgbé náà, mo dúró nígbà náà, mo sì dúró nísisìyí gẹ́gẹ́bí ẹlẹ́rìí ìyọ́nú tí nru ọkàn sókè àti ìyípadà ìgbésí-ayé ti àwọn ọmọ Ìjọ, àti ọlọ́rọ̀ àti òtòṣì méjèèjì.
Òwe ará Samáríà Rere náà tẹ̀síwájú bí ó ṣe “di àwọn egbò [ọkùnrin náà] … tí ó sì tọ́jú rẹ̀” (Lúkù 10:34 Àwọn ìgbìyànjú Ìṣe Ọmọnìyàn ti Ìjọ wa njẹ́ kí a lè dáhùn kíákíá sí àwọn àjálù àdánidá àti dídi àwọn ọgbẹ́ àgbáyé tí ngbòòrò ti àrùn, ebi, ikú ìkókó, àìjẹunrekánú, lílé kúrò ní ibùgbé, àti àwọn ọgbẹ́ tí a kìí ṣáábà fojúrí ti ìrẹ̀wẹ̀sì, ìjákulẹ̀, àti àínìrètí.
Ara Samáríà náà “mú owó fadaka méjì jáde, ó sì fi wọ́n fún agbàlejò, ó sì wí fún un pé, “Tọ́jú rẹ̀” (Lúùkù 10:35). Bí Ìjọ kan a dúpẹ́ láti fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú “àwọn agbàlejò” míràn tàbí àwọn àjọ bíi Àwọn Ìṣẹ Ìrànlọ́wọ́ Catholic, UNICEF, ati Red Cross/Red Crescent, láti ṣe ìrànlọ́wọ́ nínú àwọn ìgbìyànjú ọmọnìyàn wa. A tún dúpẹ́ fun “pẹ́nsì méjì” tàbí yúrò méjì, pẹ́sòsì méjì, tàbí ṣílìn méjì, tí ó nsọ ẹrù tí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ kákiri àgbáyé ní láti rù di fífúyẹ́. Ó le má ṣeé ṣe pé kí ẹ mọ àwọn olùgbà àkókò, àwọn dọ́là, àti àwọn dimes yín, ṣùgbọ́n ìyọ́nú kò nílò wa láti mọ̀ wọ́n; ó nílò wa láti ní ìfẹ́ wọn nìkan.
O ṣeun, Ààrẹ Nelson, fún rírántí wa pé “nigbatí a bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn wa, Ó yí ọkàn wa padà sí àláfíà àwọn ẹlòmíràn” (“Òfin Nla Kejì,,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2019, 97). Mo jẹ́ ẹ̀rí pé olúkúlùkù wa yíò ní àlékún ayọ̀, àláfíà, ìrẹ̀lẹ̀, àti ìfẹ́ bí a ṣe ndáhùn sí ipè ti Àarẹ Nelson àti ẹ̀bẹ̀ Joseph Smith láti “bọ́ àwọn tí ebi npa, fi aṣọ wọ awọn tí wọ́n wà ní ìhòhò, pèsè fún opó, nu omijé aláìníbaba nù, [àti] tu àwọn olùpọ́njú nínú, bóyá nínú Ìjọ yi, tàbí eyikeyi míràn, tàbí láì kìí ṣe inú ìjọ kankan rara, níbikíbi [tí a bá ti rí] wọn ni” (“Ìfèsì Olótú sí Lẹ́tà láti ọ̀dọ̀ Richard Savary,” Àwọn Ìgbà àti Àkokò, Mar. 15, 1842, 732).
Ní gbogbo àwọn oṣù wọ̀nnì sẹ́yìn, a rí àwọn tí ebi npa àti àwọn tí a pọ́nlójú lórí pẹ̀tẹ́lẹ̀ gbígbẹ àti eléruku kan, a sì jẹ́ ẹlẹ́rìí sí àwọn ojú wọn tí nbẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́. Ní ọ̀nà tiwa, a kérora nínú ẹ̀mí inú wa sì bàjẹ́ (wo Jòhánnù 11:33, àti síbẹ̀síbẹ̀ àwọn ìmọ̀lára wọ̀nnì wálẹ̀ bí a ṣe rí ìyọ́nú àwọn ọmọ ìjọ tí wọ́n nṣiṣẹ́ bí a ti nbọ́ àwọn tí ebi npa, tí àwọn opó di pípèsè fún, àwọn olùpọ́njú di títù nínú, àwọn omijé wọn sì gbẹ.
Njẹ́ kí a máa wá ire àwọn ẹlòmíràn títí láé kí a sì fi hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe pé a “múra tán láti ru ẹrù ara wa” (Mòsíàh 18:8), láti “ṣe ìwòsàn ọkàn àwọn oníròbìnújẹ́” ((Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 138:42), àti láti pa òfin nlá kejì ti Krístì mọ́ lati “fẹ́ ọmọnìkejì rẹ” (Márkù 12:31). Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.