Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ṣíṣí àwọn Fèrèsé Ọ̀run
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́wàá 2023


14:12

Idamẹwa: Ṣíṣí àwọn Fèrèsé Ọ̀run

Àwọn fèrèsé ọ̀run nṣí ní àwọn ọ̀nà púpọ̀. Gbẹ́kẹ̀lé àkokò Olúwa; àwọn ìbùkún náà ó wá nígbàgbogbo.

Nígbàtí mo wà ní Gúsù Amẹ́ríkà láìpẹ́, Arákùnrin Roger Parra láti Venezuela pín ìrírí wọ̀nyí pẹ̀lú mi:

“Ní 2019 Venezuela mì tìtì nípa àwọn wàhálà tí àìsí iná fún ọjọ́ marun fa.

“Ìrúkèrúdò àti ìwà rúdurùdu jọba ní àwọn òpópónà, àti pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn oníkanra ènìyàn kò ní óunjẹ́ tótó.

“Àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí kógun ja àwọn ibi ìtàjà oúnjẹ, wọ́n nba gbogbo ohun tí ó wà ní ipa-ọ̀nà wọn jẹ́.

“Bí ẹni tó ni ilé búrẹ́dì kékeré kan, mo dàmú gidi nípa ilé-ìtàjà wa. Gẹ́gẹ́bí ẹbí, a pinnu láti fi gbogbo oúnjẹ inú ilé búrẹ́dì wa fún àwọn ènìyàn nínú àìní.

“Nínú òru dúdú kan gidi rògbòdìyàn wà níbigbogbo. Àníyàn kanṣoṣo tí mo ní ni ààbò olólúfẹ́ aya àti aàwọn ọmọ mi.

“Ní kùtùkùtù mo lọ sí ilé búrẹ́dì wa. Pẹ̀lú ìbànújẹ́, gbogbo olùtàjà oúnjẹ nítòsí ni a ti parun nípasẹ̀ àwọn olùkógun jalé, ṣùgbọ́n sí ìyàlẹ́nú nlá mi, ilé búrẹ́dì wa wà láìyingin. Kò sí ohun tí wọ́n bàjẹ́. Mo fi ìrẹ̀lẹ̀ dúpẹ́ láwọ́ Baba mi Ọ̀run.

“Dídé ilé, mo wí fún ẹbí mi nípa ìbùkún àti ààbò Ọlọ́run.

“Wọ́n fi ìmoore hàn gidi.

“Ọmọkùnrin mi àgbà, Rogelio, ọmọ ọdún méjìlá péré, wípé, ‘Papa! Mo mọ ìdí tí ibi-ìtàjà wa fi ní ààbò. Ìwọ àti Màmá nsan idamẹwa yín nígbàgbogbo.’”

Arákùnrin Parra parí pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ Málákì wá sí inú mi. ‘Èmi ó sì bá ajẹnirun wí nítorí yín, òun kì ó sì run èso ilẹ̀ yín’ [Malachi 3:11]. A kúnlẹ̀ a sì fi ìmoore dúpẹ́ lọ́wọ́ Baba Ọ̀run fún iṣẹ́-ìyanu Rẹ̀.”2

Ẹbí Parra.

Ẹ Dán Mi Wo Nísisìyí

Gbogbo ohun tí a ní àti gbogbo ohun tí a jẹ́ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́bí àwọn ọmọẹ̀hìn Krístì, a nifẹ láti ṣe àbápín pẹ̀lú àwọn tí ó wà ní àyíká wa,

Pẹ̀lú gbogbo ohun tí Olúwa fi fún wa, Òun ti ní kí a ṣe ìdápadà idamẹwa ti àsunkún wa sí Òun àti ìjọba Rẹ̀ ní ilẹ̀ ayé. Ó ti ṣe ìlérí pé tí a bá jẹ́ olotitọ ní idamẹwa wa, Òun yíò “ṣí … fèrèsé ọ̀run, kí nsì … tú ìbùkún jáde, tóbẹ́ẹ̀ tí kì yíò sí àyè tó láti gbà á.”3 Ó ti ṣe ìlérí pé Òun ó dá ààbò bò wá kúrò lọ́wọ́ ibi.4 Àwọn ìlérí wọ̀nyí dájú,5 Olúwa kéde, “ẹ fi èyí dán mi wò nísisìnyí,”6 gbólóhùn kan tí a kò rí níbi míràn nínú àwọn ìwé mímọ́.

Àwọn fèrèsé ọ̀run nṣí ní àwọn ọ̀nà púpọ̀. Àwọn kan jẹ́ ti ara, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ jẹ́ ti ẹ̀mí. Àwọn kan ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ àwọn kan sì rọrùn láti fojufò. Gbẹ́kẹ̀lé àkókò Olúwa; àwọn ìbùkún náà ó wá nígbàgbogbo.

A banújẹ́ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ntiraka láti ní àwọn ohun koṣemani ayé. Láìpẹ́ Ìjọ fi $54 milliọ́nù dọ́là U.S. fúnni láti pèsè ìrànlọ́wọ́ fún àwọn ọmọ àti ìyá àìlárá káàkiri ayé.7 Àti pé pẹ̀lú àwọn ẹbọ ọrẹ látinú àwẹ̀ oṣooṣù yín, àwọn bíṣọ́ọ̀pù rere wa nran ẹgbẹgbẹ̀rún lọ́wọ́ ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ tí wọ́n nílò oúnjẹ ránpẹ́ lórí tábìlì wọn, aṣọ lọ́rùn wọn, àti òrùlé lórí wọn. Ìlàdí pípẹ́ kanṣoṣo sí òṣì ayé yí ni ìhìnrere Jésù Krístì.8

Ọ̀ràn Ìgbàgbọ́ Kan

Àpóstélì Páùlù kìlọ̀ pé ọgbọ́n àwọn ènìyàn ní ìmọ̀ àwọn ohun ti ènìyàn ṣùgbọ́n wọ́n ní ìṣòrò ní níní ìmọ̀ àwọn ohun Ọlọ́run.9 Ayé nsọ̀rọ̀ idamẹwa ní àwọn àṣẹ nípa owó wa, ṣùgbọ́n òfin mímọ́ ti idamẹwa jẹ́ kókó ọ̀ràn nípa ìgbàgbọ́ wa. Jíjẹ́ olotitọ nínú idamẹwa wa ni ọ̀nà kan tí a fi nfi ìfẹ́ wa hàn láti fi Olúwa ṣíwájú nínú àwọn ìgbé-ayé wa, borí àwọn ìtọ́jú àti ìwuni ti ara wa. Mo ṣe ìlérí pé bí ẹ ti nní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa, àwọn ìbùkún tọ̀run yíò tẹ̀le.

Jésù wípé kí a fi “àwọn ohun èyí tíí ṣe ti Késárì fún Késárì; àti ohun tíí ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”10 Olùjínde Olùgbàlà ní kí àwọn ara Néfì kọ̀ àwọn ìlérí Rẹ̀ tí a rí ní Málákì sílẹ̀ sínú àkọsílẹ̀ wọn.11 Ní ọjọ́ wa, Olúwa tun òfin idamẹwa tọ̀run sọ, ní kíkéde pé: “Èyí yíò sì jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ idamẹwa àwọn ènìyàn mi. Wọ́n [yíò] sì san ida kan nínú mẹwa gbogbo àníkún wọn ní ọdọdún; èyí yíò sì jẹ́ òfin kan tí yíò dúró fún wọn títíláé.”12

Olúwa ṣe ìdarí kedere bí a ó ti máa pín idamẹwa, ó wípé, “Ẹ mú gbogbo idamẹwa wá sí ilé ìṣura,”13 tí ó túmọ̀ sí pé kí a mú àwọn ìdamẹwa wá sínú ìjọba ìmúpadàbọ̀sípò Rẹ̀, Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn.14 Ó darí pé lílò àwọn idamẹwa mímọ́ wọ̀nyí ni a ó fi pẹ̀lú àdúrà gbèrò nípasẹ̀ ìgbìmọ̀ Àjọ Ààrẹ Ìkínní, Iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá, Alákóso Bíṣọ́príkì, “àti nípa ohun ara mi sí wọn, ni Olúwa wí.”15

Owó Mímọ́ ti Olúwa

Àwọn owó mímọ́ wọ̀nyí kò wà fún àwọn olórí Ìjọ. Wọ́n wà fún Olúwa. Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú ìtiraka nní ìfura àdánidá mímọ́ ti ìríjú wọn.

Ààrẹ Gordon B. Hinckley tún ìrírí ìgbà-èwe yí sọ: “Nígbàtí mo wà ní ọ̀dọ́mọkùnrin mo bèèrè ìbèèrè kan pẹ̀lú baba mi … nípa níná àwọn owó ìjọ. Ó rán mi létí pé tèmi ni ojúṣe fífúnni-Ọlọ́run láti san àwọn idamẹwa mi àti ọrẹ. Nígbàtí mo ṣe bẹ́ẹ̀, [baba mi wípé,] èyí tí mo ti fúnni kìí ṣe tẹ̀mi mọ́. Ó wà fún Olúwa ẹnití a yàá sọ́tọ̀ fún.” Baba rẹ̀ fikun: “Ohun tí àwọn aláṣẹ Ìjọ fi ṣe kò kàn [ọ́, Gordon]. Wọ́n njíyìn sí Olúwa, ẹnití yíò bèèrè ìṣirò ní ọwọ́ wọn.”16

À nní ìwúwo jíjinlẹ̀ ti jíjẹ́ “ìyìn sí Olúwa.”

Oore Idamẹwa Ọrẹ-ẹbọ Yín

Látinú oore àwọn ìdamẹwa àti ọrẹ tí ẹ ti yàsọ́tọ̀ sí Olúwa, ọdún tó kọjá ju bíllíọ́nù kan dọ́là U.S. ni a lò láti bùkún àwọn tí ó wà nínú àìní.17

Ní àkokò ọlọ́lá ojúṣe wa láti mú ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere káàkiri ayé, a ní àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere 71,000 tí wọ́n nsìn ní 414 àwọn míṣọ̀n.18 Nítorí àwọn idamẹwa àti ọrẹ yín, àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere, láìka ipò ìṣúná owó ẹbí wọn sí, ni wọ́n lè sìn.

Àwọn Tẹ́mpìlì ni à nkọ́ káàkiri ayé ní àìlèrò oye. Lọ́wọ́lọ́wọ́, àwọn tẹ́mpìlì 177 ni wọ́n nṣiṣẹ́, 59 ni wọ́n wà lábẹ́ kíkọ́ tàbí àtúnṣe lọ́wọ́lọ́wọ́, àti 79 si ni a nṣètò tí a sì nya àwòrán.19 Àwọn idamẹwa yín nfi àyè gba àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì láti wà ní àwọn ibi tí Olúwa lè rí tẹ́lẹ̀ nìkan.

Púpọ̀ ju ọgbọ̀n ẹgbẹ̀rún àwọn ọmọ ìjọ tí wọ́n wà ní àwọn ilé ìjọsìn ẹgbẹgbẹ̀rún àti àwọn ohun èlò ní àwọn orílẹ̀ èdè àti agbègbè 195.20 Nítorí àwọn idamẹwa òtítọ́ yín, Ìjọ ni a ngbé kalẹ̀ ní àwọn ibi ọ̀nàjíjìn tí ẹ lè má tilẹ̀ bẹ̀wò láéláé ní àárín àwọn Ènìyàn Mímọ́ olódodo tí ẹ lè má mọ̀ láéláé.

Lọ́wọ́lọ́wọ́ Ìjọ nṣe onígbọ̀wọ́ àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga marun.20 Ìwọ̀nyí nsìn ju 145,000 àwọn akẹ́kọ̀ọ́. Ọgọrun kan àti ẹgbẹ̀rún mẹwa àwọn kílásì ni à nkọ́ ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ àti Ibi Ìkọ́ni wa.22

Àwọn ìbùkún wọ̀nyí àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ si nwá ní ìwọ̀n títóbi láti ọ̀dọ̀ dé ogbó ti gbogbo ipò ọrọ̀-ajé tí wọ́n san idamẹwa òtítọ́.

Agbára ti ẹ̀mí òfin idamẹwa tọ̀run ni a kìí wọ̀n nípa oye owó tí a dá, nítorí méjèèjì olùṣerere àti òtòṣì ni Olúwa pàṣẹ fún láti dá ìdá mẹ́wá èlé wọn.23 Agbára nwá látinú fífi ìgbẹ́kẹ̀lé wa sínú Olúwa.24

Àfikún ọ̀pọ̀ ti Olúwa tí a gbé nípa oore idamẹwa yín ti fi okun fún ìfipamọ́ Ìjọ, pípèsè àwọn ànfàní láti mú iṣẹ́ Olúwa dàgbà kọjá ohunkóhun tí a ti ní ìrírí. Gbogbo rẹ̀ ni Olúwa mọ̀, àti ní àkókò, a ó ri tí gbogbo èrèdí mímọ́ Rẹ̀ ó di mímúṣẹ.25

Àwọn ìbùkún nwá ní àwọn Ọ̀nà Ọ̀pọ̀lọpọ̀

Àwọn ìbùkún idamẹwa nwá ní àwọn ọ̀nà púpọ̀. Ní 1998, mo tẹ̀lé Alàgbà-nígbànáà Henry B. Eyring lọ sí ìpàdé Ìjọ nlá kan ní agbègbè Utah tí a mọ̀ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Silicon, ìletò kan ti àtinúdá nlá nínú ìgbàlódé. Ó jẹ́ àkókò dídàgbà ìṣerere, Alàgbà Eyring kìlọ̀ fún àwọn Ènìyàn Mímọ́ nípa ṣíṣe àfiwé ohun tí wọ́n ní pẹ̀lú àwọn míràn kí wọ́n sì máa fẹ́ púpọ̀ si. Èmi yíò rántí ìlérí Rẹ̀ nígbàgbogbo pé bí a ti nsan idamẹwa òtítọ́, ìfẹ́ wọn fún ohun ìní ayé si yíò dínkù. Ní àárín ọdún méjì, ohun ìgbàlódé ti tàn ká. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti sọ iṣẹ́ wọn nù, àti pé àwọn iléiṣẹ́ ntiraka ní àkokò àtúntò ìṣúná owó yí. Àwọn tí wọ́n tẹ̀lé àmọ̀ràn Ààrẹ Eyring di alábùkúnfún.

Ìlérí Rẹ̀ rán mi létí ìrírí míràn. Mo pàdé Charlotte Hlimi ọmọ ọdún méjìlá nítòsí Carcassonne, France, ní 1990 nígbàtí à nsìn bí ààrẹ míṣọ̀n. Àwọn Hlimi jẹ́ ẹbí olotitọ onírẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ngbé nínú ìyẹ̀wù kékeré pẹ̀lú àwọn ọmọ mẹ́jọ. Wọ́n ní àwòrán Olùgbàlà àti wòlíì ni ara ògiri. Nínú ìfọ̀rọ̀wanilẹnuwò fún ìbùkún bàbánlá rẹ̀, mo bèèrè bí Charlotte bá nsan idamẹwa òtítọ́. Ó fèsì pé, “Bẹ́ẹ̀ni, Ààrẹ Andersen. Ìyá mi ti kọ́ mi pé àwọn ìbùkún ti ara àti ti ẹ̀mí wa tí ó nwá látinú sísan idamẹwa wa. Ìyá mi kọ́ mi pé bí a bá san idamẹwa wa nígbàgbogbo, a kò ní ṣaláìní ohunkóhun. Àti pé Ààrẹ Andersen, a kò ṣaláìní ohunkóhun.”

Ẹbí Hlimi.

Ní fifún mi ní àyè láti pín ìtàn rẹ̀, Charlotte, nísisìyí jẹ́ ọdún marunlelogoji ó sì ṣe èdìdí ní tẹ́mpìlì, ó wípé: “Ẹ̀rí mi nípa idamẹwa jẹ́ ododo gan ní ìgbà náà, àti pé ó tilẹ̀ lágbárasi nísisìyí. Mo ní ìmoore jíjinlẹ̀ fún òfin yí. Bí mo ti ngbe e èmi ó tẹ̀síwájú láti jẹ́ alábùkúnfún lọ́pọ̀lọpọ̀.”26

Ní ọjọ́ kan ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yíò parí ìrìn-àjò ilẹ̀ ayé wa. Ọdún marundinlọgbọn sẹ́hìn, ní ọjọ́ díẹ̀ ṣíwájú kí ìyá ìyàwó mi, Martha Williams, tó kú ikú ààrùn jẹjẹrẹ, ó gba ìsọ̀wédowó kékeré kan nínú ìfìwéránṣẹ́. Ó bèèrè lọ́wọ́ Ìyàwó mi, Kathy, lọ́gán fún ìwé ìsọ̀wédowó rẹ̀ láti san idamẹwa rẹ̀. Bí ó ti rẹ ìyá rẹ̀ tí ó fẹ́rẹ̀ má lè kọ̀wé, Kathy bèèrè bí òun bá lè kọ ìsọ̀wédowó náà fun. Ìyá rẹ̀ fèsì, “Rárá Kathy. Mo fẹ́ ṣe é fúnra mi.” Lẹ́hìn náà ó fikun jẹ́jẹ́ pé, “Mo fẹ́ láti wà ní títọ́ níwájú Olúwa.” Ọ̀kan lára àwọn ohun ìkẹhìn tí Kathy ṣe fún ìyá rẹ̀ ni láti fi àpò ìwé idamẹwa rẹ̀ lé bíṣọ́ọ̀pù rẹ̀ lọ́wọ́.

Iṣẹ́ Pàtàkì Ọlọ́run

Arákùnrin àti arábìnrin mi, Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn ti jáde “láti ibi ìpamọ́,”26 ní mímú àwọn ìbùkún alámì wá káàkiri ilẹ̀ ayé. Àwọn tí wọ́n ndá wa lárayá síwájú yíò wà àti àwọn tí kò ṣé é. Mo ti ronú nípa àwọn ọ̀rọ̀ Gamaliel ọlọ́gbọ́n, ẹnití, ó kìlọ̀ fún àwọn ìgbìmọ ní Jérúsálẹ́mù, ní rírí àwọn iṣẹ́ ìyanu àwọn Àpóstélì Pétérù àti Jòhánù.

“Ẹ fi àwọn [okùnrin wọ̀nyí] sílẹ̀: nítorí bí … iṣẹ́ yí bá jẹ́ ti ènìyàn, yíò já sí asán:

“Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ ti Ọlọ́run, ẹ kò lè dojú rẹ̀ bolẹ̀; bíbẹ́ẹ̀kọ́ … àní a ó rí yín bí ẹnití ó njá ní àtakò sí Ọlọ́run.”28

Ẹ̀yin àti èmi jẹ́ ara iṣẹ́ pàtàkì ti Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé. Kò ní di asán ṣùgbọ́n yíò tẹ̀síwájú láti lọ káàkiri ayé, ní mímúra ọ̀nà sílẹ̀ fún pípadà Olùgbàlà. Ààrẹ Russell M. Nelson kédé: “Ní àwọn ọjọ́ tí ó nbọ̀, a ó rí àwọn ìfihan títóbijùlọ nípa agbára Olùgbàlà tí ayé kò rí. Ní àárín ìsisìyí àti àkokò tí Ó màa padàbọ̀ … Òun yíò fi àwọn ànfàní, ìbùkún, àti iṣẹ́ ìyanu àìlónkà lé orí awọn olódodo.”28

Èyí ni ẹ̀rí mi. Jésù ni Krístì. Èyí ni iṣẹ́ mímọ́ Rẹ̀. Òun yíò wá lẹ́ẹ̀kansi. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Ìfiṣọwọ́sí araẹni láti ọ̀dọ̀ Roger Parra, Aug. 4, 2023.

  2. Malachi 3:10.

  3. Wo Malachi 3:11. Alàgbà Jeffrey R. Holland wípé: “Nínú ayé mi, fún àpẹrẹ, mo ti rí ìlérí Ọlọ́run tí ó di mímúṣẹ pé Òun ‘ó bá ajẹnirun wí [nítori mi]’ [Malachi 3:11]. Ìbùkún ààbò náà ní ìlòdì sí ibi ni a ti tú jáde sí orí mi àti orí àwọn àyànfẹ́ mi kọjá agbára kankan tí mo ní láti jẹ́wọ́ dáadáa. Ṣùgbọ́n mo gbàgbọ́ pé ààbò ti wá, ó kéréjù ní apákanm nítorí ìpinnu wa, ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àti bí ẹbí, láti san idamẹwa” (“Like a Watered Garden,” Liahona, Jan. 2002, 38).

  4. Olúwa yíò ṣí àwọn fèrèsé ọ̀run gẹ́gẹ́bí ìnílò wa, kìí ṣe gẹ́gẹ́bí ọ̀kánjúwà wa. Bí a bá nsan idamẹwa láti di ọlọ́rọ̀, a nṣe é fún èrèdí àṣìṣe. … Ìbùkún fún olùfúnni … lè má tilẹ̀ jẹ́ ní ìrísí owó tàbí ohun-èlò èrè” (Àwọn Ìkọ́ni Gordon B. Hinckley [1997], 657).

  5. Malachi 3:10; 3 Nephi 24:10.

  6. Wo “Ìjọ Jésù Krístì Nṣèrànwọ́ láti Mú Àìjẹun Tó Dárató Kúrò Ní Àgbáyé,” Aug. 11, 2023, newsroom.ChurchofJesusChrist.org; bákanáà wo “Bí Ìjọ Jésù Krístì àti UNICEF Ṣe Npa Àwọn Ìyá àti Ọmọ Mọ́ Láìléwu,” Aug. 17, 2023, newsroom.ChurchofJesusChrist.org.

  7. “Olúwa sì pè àwọn ènìyàn rẹ̀ ní Síónì, nitorí wọ́n wà ní ọkàn kan àti inú kan, wọ́n sì gbé nínú òdodo; kò sì sí òtòṣì kankan ní àárín wọn” (Moses 7:18).

  8. Wo 1 Àwọn Kọ́ríntì 2:14. Ọgbọ́n-ìrònú ènìyàn kìí sí ní ìbámu pẹ̀lú ọgbọ́n Ọlọ́run nígbàgbogbo. Ní ọjọ́ Málákì, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti di jíjìnà kúrò ní ọ̀dọ̀ Olúwa. Olúwa rọ àwọn ènìyàn onímájẹ̀mú Rẹ̀, “Padá sọ́dọ̀ mi, èmi yíò sì padà sọ́dọ̀ rẹ.” Ohun tí ó tẹ̀lé ìpè jẹ́jẹ́ yí ni ìbèèrè ìjìnlẹ̀ pàtàkì kan fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa: “Ṣùgbọ́n ẹ wípé, níbo ni a ó ti padà?” (Malachi 3:7). Tàbí ní ọ̀rọ̀ míràn, “Kíni mo níláti yípadà? Báwo ni èmi ó ti súnmọ̀ Ọ́?” Olúwa ndàhùn nípa kíkọ́ pàtàkì idamẹwa, kìí kàn ṣe bí òfin ìnáwó ṣùgbọ́n ọ̀nà dídára láti yí àwọn ìfẹ́ ọkàn wa padà sí I.

    A ṣe àkíyèsí èyí nínú ẹbí ara wa. Ìyá Katty darapọ̀mọ́ Ìjọ ní ọjọ́ orí méjìlélógún. Martha àti Bernard Williams lọ sí Ìjọ fún ìgbà díẹ̀, ṣùgbọ́n lẹ́hìnnáà lílọ sí ìpínlẹ̀ míràn mú wọn di aláìwá-déédéé. Baernard gba ìmúṣiṣẹ́ ológun lọ ókè-òkun, Martha sì kó ilé wọn lọ sí Tampa, Florida, níbití ó ti tẹ́wọ́gba ìpè oore láti gbé pẹ̀lú auntí àti ọnkúlú rẹ̀ ẹnití ó tako Ìjọ. Nígbàtí ó ngbé nínú ipò ìrẹ̀lẹ̀ gan, tí ó nretí ọmọ àkọ́kọ́ tí kò sì lọ́ ilé-ìjọsìn, Martha Williams ṣe ìpinnu láti bẹ̀rẹ̀ sí nfi ìsọ̀wédowó idamẹwa rẹ̀ ránṣẹ́ sí bíṣọ́ọ̀pù. Lẹ́hìnáà nínú ayé rẹ̀, nígbàtí a bèèrè pé kínìdí, ó wípé òun rántí ohunkan tí àwọn òjíṣẹ́ ìhìnrere ti kọ́ òun nípa idamẹwa àti àwọn ìbùkún Ọlọ́run: “A nílò àwọn ìbùkún Ọlọ́run nínú ayé wa taratara, nítorínáà mo sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ìsọ̀wédowó wa sí bíṣọ́ọ̀pù.” Martha àti Bernard Williams padà sí Ìjọ. Ìbùkún wọn títóbijùlọ—àwọn ìran mẹ́fà ti di alábùkún nítorí ìpinnu rẹ̀ láti san idamẹwa nígbàtí kò ní ohunkankan ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti ìrèt´ nínú àwọn ìlérí Rẹ̀.

  9. Máttéù 22:21.

  10. Wo 3 Néfì 24.

  11. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 119:3-4. “Tithing is the donation of one-tenth of one’s income to God’s Church (wo Doctrine and Covenants 119:3–4; interest is understood to mean income). All members who have income should pay tithing” (General Handbook: Serving in The Church of Jesus Christ of Latter-day Saints, 34.3.1, Gospel Library).

  12. Malachi 3:10.

  13. “À nsan idamẹwa, bí Olùgbàlà ti kọ́ni, nípa mímú àwọn idamẹwa ‘wá sínú ilé ìṣura’ [Malachi 3:10; 3 Nephi 24:10]. A nṣe èyí nípa sísan idamẹwa wa fún bíṣọ́ọ̀pù tàbí ààrẹ ẹ̀ka. A kìí sàn idamẹwa nípa dídáwó sí àwọn ilé-àánú ààyò wa. Àwọn ìdáwó tí a níláti ṣe sí ilé-àánú nwá látinú àwọn ow´ ara wa, kìí ṣe látinú àwọn idamẹwa tí a paláṣẹ fún wa láti san sí ilé ìṣura Olúwa” (Dallin H. Oaks, “Tithing,” Ensign, May 1994, 35).

  14. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 120:1.

  15. Gordon B. Hinckley, “Dìde sí Ìran Títóbijù ti Iṣẹ́ náà,” Ensign, May 1990, 96.

  16. Wo “Ìròhìn 2022 lórí bí Ìjọ Jésù Krístì fi Ntọ́jú àwọn Wọnnì nínú Àìní,” Mar. 22, 2023, newsroom.ChurchofJesusChrist.org.

  17. Tí a gbà nípa ayélujára láti Ẹ̀ka Iṣẹ́-Ìránṣẹ́, Sept. 14, 2023.

  18. Wo “Tẹ́mpìlì Tí A Dárúkọ̀,” churchofjesuschrist.org/temples/list.

  19. Tí a gbà nípa ayélujára látinú àwọn Àkọsílẹ̀ Ọmọ-ìjọ àti Ìṣirò, July 28, 2023.

  20. Èyí pẹ̀lú Unifásitì Brigham Young, Unifásitì Brigham Young–Idaho, Unifásitì Brigham Young–Hawaii, Ensign College, àti BYU Pathway Àgbáyé.

  21. Tí a gbà nípa ayélujára láti Ilé-ẹ̀kọ̀ àti Idanilẹkọ, Osu keje 28, 2023.

  22. Wo Ìwé-ìléwọ́ Gbogbogbò, 34.3.1.

  23. Ààrẹ Dallin H. Oaks pín ìtàn yí nípa gbígbẹ́kẹ̀lé Olúwa: “Ìyá mi opó ṣe àtìlẹhìn àwọn ọ̀dọ́ ọmọ rẹ̀ mẹ́ta ní orí owó oṣù [kékeré]. … Mo bèèrè lọ́wọ́ ìyá mi ìdí tí ó fi nsan idamẹwa púpọ̀ lórí owó oṣù rẹ̀. Èmi kò gbàgbé àlàyé tí ó ṣe láéláé: ‘Dallin, àwọn ènìyàn kan lè wà tí wọ́n lè lọ láìsan idamẹwa, ṣùgbọ́n a kò lé ṣe bẹ́ẹ̀. Olúwa ti yàn láti mú baba yín lọ tí ó sì fi mí sílẹ̀ láti tọ́ ẹ̀yin ọmọ. Èmi kò lè ṣe èyí láìsí àwọn ìbùkún Olúwa, mo sì ngba àwọn ìbùkún wọnnì nípa sísan idamẹwa tóótọ́’” (“Tithing,” 33).

  24. “Pé nípa ìpèsè mi, láìka ìpọ́njú èyí tí ó sọ̀kalẹ̀ lé yín, kí íjọ lè dá dúró lórí gbogbo àwọn ìṣẹ̀dá míran ní abẹ́ ayé cẹ̀lẹ́stíà” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 78:14).

  25. Látinú ìfiṣọwọ́sí araẹni láti ọ̀dọ̀ Charlotte Martin, Aug. 30, 2023.

  26. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 1:30.

  27. Acts 5:38-39.

  28. Russell M. Nelson, “Ẹ Ṣẹ́gun Ayé kí ẹ sì Wá Ìsinmi,” Liahona, Nov. 2022, 95.