Ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, Àádọ́rin Agbègbè, àti Olóyè Gbogbogbò.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, bí a ti kede, nísisìyí èmi yíò gbé àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò, àwọn Àádọ́rin Agbègbè, àti àwọn Olóyè Gbogbogbò Ìjọ kalẹ̀ fún ìbò ìmúdúró yín.
Ẹ jọ́wọ́ e fi àtìlẹhìn yín hàn bí ẹ ti nṣe, níbikíbi tí ẹ lè wà. Àwọn wọ̀nni tí wọń bá takòó, a bèèrè pé kí ẹ kàn sí ààrẹ èèkàn yín.
A dalaba pé kí a ṣe ìmúdúró Russell Marion Nelson bí wòlíì, aríran, àti olùfihàn àti Ààrẹ Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn; Dallin Harris Oaks bí Olùdámọ̀ràn Kínní; àti Henry Bennion Eyring bí Olùdámọ̀ràn Kejì nínú Àjọ Ààrẹ Ìkinní.
Àwọn wọnnì tó bá faramọ lè fihàn.
Àwọn wọnnì tó bá tàkòó, tí ẹnikẹ́ni bá wà, lè fihàn.
A dalaba pé kí a ṣe imúdúró Dallin H. Oaks bí Ààrẹ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá àti M. Russell Ballard bí Aṣojú Ààrẹ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá.
Àwọn to bá faramọ, jọ̀wọ́ ṣàpẹrẹ.
Alátakò kankan tó bá wa lè fihàn.
A dalaba pé kí a ṣe imúdúró àwọn wọ̀nyí bí ọmọ Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá: M. Russell Ballard, Jeffrey R. Holland, Dieter F. Uchtdorf, David A. Bednar, Quentin L. Cook, D. Todd Christofferson, Neil L. Andersen, Ronald A. Rasband, Gary E. Stevenson, Dale G. Renlund, Gerrit W. Gong, àti Ulisses Soares.
Àwọn tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.
Alátakò kankan lè fihàn bẹ́ẹ̀.
A dalaba pé kí a ṣe ìmúdúró àwọn olùdámọ̀ràn nínú Àjọ Ààrẹ Ìkínní àti Iyejú àwọn Àpọ́stélì Méjìlá bí àwọn wòlíì, aríran, àti olùfihàn.
Gbogbo ẹni tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.
Ìlòdì, bí èyíkéyi bá wá, nípa irú àmì kannáà.
Bí a ti kéde tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, a ti nawọ́ ìpè kan sí Alexander Dushku láti sìn bí Aláṣẹ Gbogbogbò Áádọ́rin.
Àwọn tó bá faramọ, jọ̀wọ́ fihàn.
Àwọn alátakò, nípa irú àmì kannáà.
Bákannáà a kíyèsi ìdásílẹ̀ àwọn Áádọ́rin Agbègbè tí a lè rí orúkọ wọ́n ní ibiwẹ́ẹ̀bù Ìjọ pẹ̀lú ìmoore.
Àwọn wọnnì tí wọ́n fẹ́ láti darapọ̀ mọ́ wa ní fífi ìmoore hàn sí àwọn arákùnrin wọ̀nyí fún iṣẹ́ ìsin títayọ lè fihàn.
A dá àbá pé kí a ṣe ìmúdúró àwọn Aláṣẹ Gbogbogbò àti àwọn Àádọ́rin Agbègbè míràn, pẹ̀lú àwọn Àádọ́rin Agbègbè titun méjì tí a kéde ṣíwájú ní ọ̀sẹ̀ yí ní ibiwẹ́ẹ̀bù Ìjọ, àti àwọn Olóyè Gbogbogbò bí a ti gbé wọn kalẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.
Gbogbo ẹni tó bá faramọ lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa nínawọ́ sọ́kè.
Àwọn alátakò, to báwa.
A dúpẹ́ lọ́wọ́ yín, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, fún ìtẹ̀síwájú ìgbàgbọ́ àti àdúrà yín ní ìtìlẹhìn àwọn olórí Ìjọ.
Àwọn Ìyípadà sí Àwọn Àádọ́rin Agbègbè
Àwọn Àádọ́rin Agbègbè wọ̀nyí ni a ṣe ìmúdúró fún nínú abala àwọn olórí kan tí a ṣe bí ara ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò:
Rogério Boschi àti Kirt L. Hodges.
Àwọn Àádọ́rin Agbègbè wọ̀nyí ni a ṣe ìmúdúró fún nínú abala àwọn olórí kan tí a ṣe bí ara ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò:
Henry J. Eyring àti Youngjoon Kwon.