Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ronú Sẹ̀lẹ́stíà!
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́wàá 2023


19:15

Ronú Sẹ̀lẹ́stíà!

Àwọn àṣàyàn yín lóni yío pinnu àwọn ohun mẹ́ta: irú ara èyí tí ẹ ó jínde pẹ̀lú, àti àwọn wọnnì tí ẹ ó jọ gbé títí láé.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, mo ní ìjìnlẹ̀ ìmoore láti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú yín loni. Ní ọjọ́ orí mi, ọjọ́ titun kọ̀ọ̀kan nmú àwọn ìyanu àti bákannáà àwọn ìpèníjà yíyanilẹ́nu wá. Ní ọ̀sẹ̀ mẹ́ta sẹ́hìn, mo fi àwọn iṣan ẹ̀hìn mi ṣèṣe. Nítorínáà, nígbàtí mo ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó lé ní ọgọ́rũn ní ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò ní dídìde dúró, lónìí mo rò pé èmi ó ṣe bẹ́ẹ̀ ní jíjókòó. Mo gbàdúrà pé Ẹ̀mí yío gbé àwọn ọ̀rọ̀ mi lọ sínú ọkàn yín lónìí.

Ní àìpẹ́ yi mo ṣe ayẹyẹ ọdún kọkàndín-lọ́gọ́rũn ọjọ́ ìbí mi àti ní báyí, mo bẹ̀rẹ̀ ọgọ́rũn ọdún ti wíwà láàyè. Wọ́n máa nsáábà bi mí léèrè àṣírí wíwà láàyè pẹ́ títí bẹ́ẹ̀. Ìbéèrè tó dára jù yío jẹ́ “Kínni mo ti kọ́ nínú wíwà láàyè mi tó súnmọ́ sẹ́ntúrì kan?”

Àkókò kò gbà fún mi loni láti dáhùn ìbéèrè náà ní kíkún, ṣùgbọ́n mo le ṣe àbápín ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣe kókó jùlọ tí mo ti kọ́.

Mo ti kọ́ ẹ̀kọ́ pé ètò Baba Ọ̀run gbayì, pé ohun tí a ṣe nínú ayé yí já mọ́ nkan gidigidi, àti pé Ètùtù Olùgbàlà ni ohun tí ó mú ètò Baba wa ṣeéṣe.1

Bí mo ti nja ìjàkadì pẹ̀lú ìrora líle tó wáyé nípasẹ̀ ìpalára mi àìpẹ́ yí, mo ti ní ìmọ̀lára àní ìjìnlẹ̀ ìmoore fún Jésù Krístì àti ẹ̀bùn Ètùtù Rẹ̀ tí a kò le ní òye rẹ̀. Ronú nípa rẹ̀! Olùgbàlà jìyà “àwọn ìrora àti àwọn ìpọ́njú àti àwọn ìdánwò ní onírũrú”2 kí Òun le tù wá nínú, wò wá sàn, tú wa sílẹ̀ ní àwọn àkókò àìní.3 Jésù Krístì ṣe àpèjúwe ìrírí Rẹ̀ ní Gẹ́tsémánè àti ní orí Kálfárì: “Ìjìyà èyítí ó mú èmi tikara mi, àní Ọlọ́run, tí ó tóbi ju ohun gbogbo lọ, láti gbọ̀n-rìrì nítorí ìrora, àti láti ṣẹ̀jẹ̀ nínú gbogbo ihò ara.”4 Ìpalára mi ti mú mi ronú lẹ́ẹ̀kansíi àti lẹ́ẹ̀kansíi lórí “títóbi Ẹni Mímọ́ Isráẹ́lì náà.”5 Ní àsìkò ìmúláradá mi, Olúwa ti fi agbára àtọ̀runwá Rẹ̀ hàn ní àwọn ọ̀nà àlàáfíà àti àìṣìṣe.

Nítorí Ètùtù àìlópin ti Jésù Krístì, ètò Baba wa Ọ̀run jẹ́ ètò pípé! Níní òye nípa ètò gbígbayì tí Ọlọ́run mú ohun ìjìnlẹ̀ jáde nínú ayé àti àìdánilójú jáde nínú ọjọ́ ọ̀la wa. Ó ngba ẹnìkọ̀ọ̀kan wa láàyè láti yàn a ó ti gbé ní ìhín lórí ilẹ̀ ayé àti ibi tí a ó gbé títí láé. Èrò orí tí kò ní ìpìlẹ̀ pé náà pé ká “máa jẹ, ká máa mu, kí a sì máa ṣe àjọyọ̀, nítorí ní ọ̀la àwa ó kú; yío sì dára fún wa”6 jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn irọ́ tí ó ṣe àjèjì jùlọ ní gbogbo àgbáyé.

Níhĩn ni ìròhìn nlá nípa ètò Ọlọ́run: àwọn ohun náà gan-an tí yío ṣe ayé ti ikú rẹ ní dáradára jùlọ bí ó ti le rí ni àwọn ohun kannáà gẹ́gẹ́ tí yío ṣe ayé rẹ jálẹ̀ gbogbo ayérayé ní dáradára jùlọ bí ó ti lè rí! Lóni, láti ràn yín lọ́wọ́ láti kún ojú òsùnwọ̀n fún àwọn ìbùkún aládùn tí Baba Ọ̀run ní fún yín, mo pè yín láti gba ìṣe “ríronú Sẹ̀lẹ́stíà”!7 Ríronú sẹ̀lẹ́stíà túmọ̀ sí wíwà nínú ẹ̀mí. A kọ́ láti inú wòlíì Jákọ́bù ti inú Ìwé Ti Mọ́mọ́nì pé “láti ní èrò inú ti ẹ̀mí jẹ́ ìyè ayérayé.”8

Ayé ti-ikú jẹ́ kíláàsì àgbà ní kíkọ́ ẹ̀kọ́ láti yàn àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jùlọ ní ayérayé. Àwọn ènìyàn púpọ̀jùlọ ngbé bí ẹnipé ayé yí ni gbogbo ohun tó wà. Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, àwọn àṣàyàn yín lóni yío pinnu àwọn ohun mẹ́ta: ibití ẹ ó gbé ní gbogbo ayérayé, pẹ̀lú irú ara wo ni a ó jíi yín dìde, àti àwọn wọnnì tí ẹ ó jọ gbé títíláé. Nítorínáà ẹ ronú Sẹ̀lẹ́stíà.

Nínú ọ̀rọ̀ mi àkọ́kọ́ bí Ààrẹ Ìjọ, mo gbà yín níyànjú láti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú òpin ni inú ọkàn. Èyí túmọ̀ sí fífi ìjọba Sẹ̀lẹ́stíà ṣe àfojúsùn ayérayé yín àti nígbànáà fífi pẹ̀lú ìṣọ́ra máa gbèrò ibití ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìpinnu yín nígbàtí ẹ wà níhĩn lórí ilẹ̀ ayé yío fi yín sí nínú ayé tó kàn.9

Olúwa ti kọ́ni ní kedere pé àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin tí wọ́n bá ti fi èdìdi dì nìkan bíi ọkọ àti aya nínú tẹ́mpìlì, àti tí wọ́n npa àwọn májẹ̀mú wọn mọ́, ni wọn yío wà papọ̀ jálẹ̀ àwọn ayérayé. Ó sọ pé,“Gbogbo àwọn májẹ̀mú, àwọn àdéhùn, àwọn ìdàpọ̀, àwọn ojúṣe, àwọn ìbúra, àwọn ẹ̀jẹ́, àwọn ìṣe, àwọn isopọ̀, àwọn ìbáṣepọ̀, tàbí àwọn ìgbèrò, tí a ṣe àti tí a kò wọnú rẹ̀ àti tí a kò fi èdìdi dì nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ ti ilérí … wọ́n ní òpin nígbàtí àwọn ènìyàn bá kú.”10

Nípa bẹ́ẹ̀, bí a bá fi àìgbọ́n yan láti gbé ìgbé ayé àwọn òfin tẹ̀lẹ́stíà nísisìnyí, a nyàn láti jẹ́ jíjí dìde pẹ̀lú ara tẹ̀lẹ́stíà. A nyàn láti máṣe gbé pẹ̀lú àwọn ẹbí wa títí láé.

Nítorínáà, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, báwo àti níbo àti pẹ̀lú tani ẹ̀yin fẹ́ láti gbé títí láé? Ẹ ní láti yàn.11

Nígbàtí ẹ bá nṣe àwọn àṣàyàn, mo pè yín láti mú ìwòye pípẹ́—ìwòye ti ayérayé kan. Ẹ fi Jésù Krístì ṣe àkọ́kọ́, nítorípé ìyè ayérayé yín gbáralé ìgbàgbọ́ yín nínú Rẹ̀ àti nínú Ètùtù Rẹ̀.12 Bákannáà ó gbáralé ìgbọràn yín sí àwọn òfin Rẹ̀. Ìgbọràn nla ọ̀nà fún ìgbé ayé aláyọ̀ fún yín lóni àti èrè ìparí, ti ayérayé lọ́la.

Nigbàtí ẹ bá ní ìdojúkọ pẹ̀lú wàhálà, ẹ ronú Sẹ̀lẹ́stíà! Nígbàtí a bá dán yín wò nípasẹ̀ ìdánwò, ẹ ronú Sẹ̀lẹ́stíà! Nígbàtí ayé tàbí olùfẹ́ kan bá já yín kulẹ̀, ẹ ronú Sẹ̀lẹ́stíà! Nígbàtí ẹnìkan bá kú láìpé ọjọ́, ẹ ronú Sẹ̀lẹ́stíà. Nígbàtí ẹnìkan bá dúró pẹ́ pẹ̀lú àìsàn ayọnilẹ́nu, ẹ ronú Sẹ̀lẹ́stíà. Nígbàtí àwọn ẹrù ayé bá kórajọ lé yín lórí, ẹ ronú Sẹ̀lẹ́stíà! Bí ẹ ti nbọ̀sípò láti inú ìjàmbá tàbí ìfarapa kan, bí èmi ti nṣe nísisìyí, ẹ ronú Sẹ̀lẹ́stíà!

Bí ẹ ti nfojúsùn sórí ríronú sẹ̀lẹ́stíà, ẹ retí láti dojúkọ àtakò.13 Ní àwọn dẹ́kéèdì sẹ́hìn, ọ̀jọ̀gbọ́n ẹlẹgbẹ́ mi kan ṣòfíntótó mi fún níní “àwọn tẹ́mpìlì púpọ̀jù” nínú mi, àti pé o ju ẹyọkan alámójútó lọ tí ó ti fìyà jẹmí nítorí ìgbàgbọ́ mi. Ó dá mi lójú, bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, pé ríronú Sẹ̀lẹ́stíà gbé iṣẹ́ mi lárugẹ.

Bí ẹ ti nronú sẹ̀lẹ́stíà, ọkàn yín yío máa yípadà díẹ̀díẹ̀. Ẹ ó fẹ́ láti máa gbàdúrà nígbà gbogbo síi àti nítòótọ́ síi. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ máṣe jẹ́ kí àwọn àdúrà yín dún bíi ohun títòsílẹ̀ ìfirajà kan. Ìwoye Olúwa rekọjá ọgbọ́n ti ara kíkú yín Ìdáhùn Rẹ̀ sí àwọn àdúrà yín le yà yín lẹ́nu yío sì ràn yín lọ́wọ́ láti ronú sẹ̀lẹ́stíà.

Ẹ rò ìdáhùn Olúwa sí Joseph Smith nígbàtí ó bẹ̀bẹ̀ fún ìtura nínú Ẹ̀wọ̀n Liberty. Olúwa kọ́ Wòlíì náà pé àwọn ìfiyà-jẹni rẹ̀ yìó fún un ní ìrírí yío sì jẹ́ fún rere rẹ̀.14 “Bí o bá fi ara dà á dáradára,” Olúwa ṣe ìlérí, “Ọlọ́run yíò gbé ọ ga lókè.”15 Olúwa nkọ́ Jósẹ́fù láti ronú sẹ̀lẹ́stíà àti láti fi ojú inú wo èrè ayérayé kan dípò fífi ojú sùn sórí àwọn ìṣòro onírora ti ọjọ́ náà. Àwọn àdúrà wa le jẹ́—wọ́n sì níláti jẹ́—ààyè ìbáni-sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Baba wa Ọ̀run.

Bí ẹ ti nronú sẹ̀lẹ́stíà, ẹ ó rí ara yín ní yíyẹra fún ohunkóhun tí ó bá jà yín lólè òmìnira yín láti yàn. Èyíkéyìí barakú—eré tẹ́tẹ́, tẹ́tẹ́ títa, gbèsè, àwọn òògùn olóró, ọtí líle, ìbínú, àwòrán ìwòkuwò, ìbálòpọ̀, tàbí onjẹ pàápàá—nmú Ọlọ́run bínú. Kínìdí? Nítorípé ìfẹ́kúfẹ yín di ọlọ́run yín. Ẹ nwò ó dípò sí Òun fún ìtùnú. Bí ẹ bá ntiraka pẹ̀lú bárakú kan, ẹ wá ìrànlọ́wọ́ ti ẹ̀mí àti ti ọ̀jọ̀gbọ́n tí ẹ nílò. Ẹ jọ̀wọ́ máṣe jẹ́ kí ìfẹ́kúfẹ kan jà yín lólè òmìnira yín láti tẹ̀lé ètò tó gbayì ti Ọlọ́run.

Ríronú sẹ̀lẹ́stíà yío ràn yín lọ́wọ́ bákannáà láti gbọ́ran sí òfin ìwà mímọ́. Àwọn ohun díẹ̀ ni yío mú ayé yín díjú kíákíá síi ju rírú òfin àtọ̀runwá yi lọ. Fún àwọn tí wọ́n ti dá àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run, àgbèrè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó yá jùlọ láti sọ ẹ̀rí yín nù.

Pùpọ̀ nínú àwọn ìdánwò ọ̀tá tí kò dáwọ́dúró jùlọ ní í ṣe sí àwọn ìrúfin ti ìwà mímọ́, Agbára láti ṣẹ̀dá ẹ̀mí jẹ́ ànfààní kan ti jíjẹ́ ọlọ́run tí Baba Ọ̀run fi ààyè gba àwọn ọmọ kíkú Rẹ̀ láti lò. Báyi, Ọlọ́run ṣe àgbékalẹ̀ àwọn ìtọ́ni kedere fún lílò agbára, ààyè àtọ̀runwá yi. Ìfarakanra wà fún ọkùnrin kan àti obìnrin kan nìkan tí wọ́n ti ṣègbeyàwó pẹ̀lú ara wọn.

Púpọ̀ nínú àwọn aráyé kò gbà èyí gbọ́, ṣùgbọ́n èrò orí ti ìta gbangba kìí ṣe alágbàwí ti òtítọ́. Olúwa ti kéde pé kò sí ẹni àìmọ́ kan tí yío dé ìjọba sẹ̀lẹ́stíà. Nítorínáà, nígbàtí ẹ bá nṣe àwọn ìpinnu tó ní í ṣe sí ìwà mímọ́, ẹ jọ̀wọ́ ẹ ronú sẹ̀lẹ́stíà. Bí o bá sì ti jẹ́ aláìmọ́, mo bẹ̀bẹ̀ sí ọ pé kí o ronúpìwàdà, Ẹ wá sí ọ̀dọ̀ Krístì kí ẹ sì gba ìlérí Rẹ̀ ti ìdáríjì pípé bí ẹ ti nronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín.16

Bí ẹ ti nronú sẹ̀lẹ́stíà, ẹ ó rí àwọn àdánwò àti àtakò nínú ìmọ́lẹ̀ titun kan. Nígbàtí ẹnìkan tí ẹ fẹ́ràn bá gbógun ti òtítọ́, ẹ ronú sẹ̀lẹ́stíà, kí ẹ má sì ṣiyèméjì ẹ̀rí yín. Páùlù Àpóstélì sọtẹ́lẹ̀ pé “ní ìgbà ìkẹhìn àwọn míràn yío kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọn ó sì fiyèsí àwọn ẹ̀mí tó ntannijẹ, àti ẹ̀kọ́ àwọn ọ̀mí èṣù.”17

Kò sí òpin sí àwọn ẹ̀tàn ti ọ̀tá. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ múrasílẹ̀. Ẹ máṣe gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn tí kò gbàgbọ́. Ẹ wá ìtọ́ni láti ọ̀dọ̀ àwọn ohùn tí ẹ le gbẹ́kẹ̀lé—láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì, àwọn aríran, àti àwọn olùfihàn àti láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́, ẹnití “yíò fi àwọn ohun gbogbo hàn sí yin èyí tí ó yẹ kí ẹ sẹ.”18 Ẹ jọ̀wọ́ ẹ ṣe iṣẹ́ ti ẹ̀mí láti fi kún agbára yín láti gba ìfihàn ti araẹni.19

Bí ẹ ti nronú sẹ̀lẹ́stíà, ìgbàgbọ́ yín yío lé kún. Nígbàtí mo wà ní ọ̀dọ́ akọ́ṣẹ́, owó tó nwọlé fún mi jẹ́ $15 ní oṣù kan. Ní òru kan, ìyàwó mi Dantzel béèrè bí mo bá nsan ìdámẹ́wàá lórí ìwọnba owó náà. Èmi kò nṣe é. Mo yára ronúpìwàdà mo sì bẹ̀rẹ̀ sí san àfikún $1.50 nínú ìdámẹ́wa oṣooṣù?

Njẹ́ Ìjọ yàtọ̀ rárá nítorípé àwa fi kún ìdámẹ́wa wa? Dájúdájú bẹ́ẹ̀kọ́. Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀, dídi olùsan ìdámẹ́wàá-kíkún yí èmi padà. Ó jẹ́ ìgba tí mo kọ́ ẹ̀kọ́ pé sísan ìdámẹ́wàá jẹ́ gbogbo ẹ̀ nípa ìgbàgbọ́, kìí ṣe owó. Bíi olùsan ìdámẹ́wàá-kíkún, àwọn fèrèsé ọ̀run bẹ̀rẹ̀sí ṣí fún mi. Mo ka ọ̀pọ̀ àwọn ànfààní ti iṣẹ́ mi lẹ́hìnwá sí nítorí sísan àwọn ìdámẹ́wàá wa lódodo.20

Sísan ìdámẹ́wàá nílò ìgbàgbọ́, àti bákannáà ó nmú ìgbàgbọ́ dàgbà nínú Ọlọ́run àti Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀.

Yíyàn láti gbé ìgbé ayé ìwà rere nínú ayé ti ìbálòpọ̀ àti ti olóṣèlú nmú ìgbàgbọ́ dàgbà.

Lílo àkokò síi nínú tẹ́mpìlì nmú ìgbàgbọ́ dàgbà. Iṣẹ́ ìsìn àti ìjọ́sìn yín nínú tẹ́mpìlì yío sì ràn yín lọ́wọ́ láti ronú sẹ̀lẹ́stíà. Tẹ̀mpìlì jẹ́ ibi ìfihàn. Níbẹ̀ a nfi hàn yín bí a ti le tẹ̀síwájú sí ìhà ayé sẹ̀lẹ́stíà kan. Níbẹ̀ ẹ ndi fífà súnmọ́ Olùgbàlà síi a sì nfún yín ní ààyè títóbijù sí agbára Rẹ̀. Níbẹ̀ ẹ ó gba ìtọ́ni ní yíyanjú àwọn wàhálà inú ayé yín, àní àwọn wàhálà tó jẹ́ ìdààmú jùlọ.

Àwọn ìlànà àti àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì jẹ́ pàtàkì sí ayérayé. A ntẹ̀síwájú láti máa kọ́ àwọn tẹ́mpìlì síi láti mú àwọn ó-ṣeéṣe mímọ́ wọ̀nyí di òtítọ́ nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan ìgbé ayé yín. A fi ìmoore hàn láti kéde àwọn ètò wa láti kọ́ tẹ́mpìlì kan ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìbí ogún wọ̀nyí.

  • Savai’i, Samoa

  • Cancún, Mexico

  • Piura, Peru

  • Huancayo, Peru

  • Viña del Mar, Chile

  • Goiânia, Brazil

  • João Pessoa, Brazil

  • Calabar, Nigeria

  • Cape Coast, Ghana

  • Luanda, Angola

  • Mbuji-Mayi, Democratic Republic ti Congo

  • Laoag, Philippines

  • Osaka, Japan

  • Kahului, Maui, Hawaii

  • Fairbanks, Alaska

  • Vancouver, Washington

  • Colorado Springs, Colorado

  • Tulsa, Oklahoma

  • Roanoke, Virginia

  • Ulaanbaatar, Mongolia

Olúwa ndarí wa láti kọ́ àwọn tẹ́mpìlì wọ̀nyí láti ràn wá lọ́wọ́ ronú sẹ̀lẹ́stíà. Ọlọ́run wà láàyè! Jésù ni Krístì. Ìjọ Rẹ̀ ni a ti múpadàbọ̀sípò láti bùkún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run. Mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Wo Jòhánnù 6:38.

  2. Álmà 7:11.

  3. Wo Álmà 7:12.

  4. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 19:18.

  5. 2 Néfì 9:40.

  6. 2 Néfì 28:7.

  7. It may prove to be easier to repent and progress spiritually here, while our spirit is united with our body, than in the next world between the time we die and are resurrected. Bí Ámúlẹ́kì ti kọ́ àwọn apẹ̀hìndà ará Sórámù, “ayé yí àkokò … láti múrasílẹ̀ láti pàdé Ọlọ́run” (wo Álmà 34:32–35).

  8. 2 Néfì 9:39.

  9. Wo Mosiah 4:30, where King Benjamin admonishes his people, “Bí ẹ kò bá kíyèsí ara yín, àti èrò ọkàn yín, àti iṣẹ́ yín, kí ẹ sì pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, kí ẹ sì tẹ̀síwájú nínú ìgbàgbọ́ … , ẹ̀yin ó parun.”

  10. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 76:43; àfikún àtẹnumọ́.

  11. Bẹ́ẹ̀ni, agbára òmìnira yín kò lè borí agbára òmìnira ẹlòmíràn àti àyọrísí tó bá dé. Mo ní ìtara láti ṣe èdidìsí àwọn òbí mi. Bákannáà, mo ní láti dúró títí tí wọn ó fi yàn láti gba agbára tẹ́mpìlì, nígbàtí wọ́n ti ju ọmọ ọgọrin ọdún lọ. Then they were sealed as husband and wife, and we children were sealed to them.

  12. The scriptures repeatedly testify that the gift of eternal life is only possible through the merits, mercy, and grace of the Savior Jesus Christ (Fún àpẹrẹ, wo, Moroni 7:41; bákannáà wo 2 Nephi 2:6–8, 27).

  13. Wo 2 Néfì 2:11.

  14. Wo Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 122:7.

  15. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 121:8.

  16. Wo Ìsàíàh1:16–18; Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 58:42–43.

  17. 1 Timothy 4:1. Ẹsẹ tó tẹ̀le tẹ̀síwájú, “Speaking lies in hypocrisy; having their conscience seared with a hot iron” (ẹsẹ 2). Paul bákannáà kéde pé gbogbo ẹnití ó “gbé ìgbé ìwà bí Ọlọ́run nínú Krístì Jésù yíò farada ìnunibíni” (2 Timothy 3:12).

  18. 2 Néfì 32:5; àfikún àtẹnumọ́. If we will ask, we may “receive revelation upon revelation, knowledge upon knowledge” (Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 42:61).

  19. Wo Russell M. Nelson, “Ìfihàn fún Ìjọ, Ìfihàn fún Ayé Wa,” Liahona, May 2018, 96.

  20. This is not to imply a cause-and-effect relationship. Some who never pay tithing attain professional opportunities, while some who pay tithing do not. Ìlérí náà pé a ó ṣí fèrèsé ọ̀run yíò ṣí fún olùsan idamẹwa. Àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì yíò jẹ́ onírurú.