Òtítọ́ Ayérayé
Ìnílò wa láti dá òtítọ́ mọ̀ kò tíì ṣe pàtàkì jù báyi lọ rí!
Ẹ̀yin Arákùnrin àti arábìrin, ẹ ṣeun fún ìfọkànsìn yín sí Ọlọ́run Baba àti sí Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, ẹ sì ṣeun fún ìfẹ́ àti iṣẹ̀ ìsìn yín sí ara yín. Ẹ jẹ́ àrà ọ̀tọ̀ nítòótọ́!
Ọ̀rọ̀-ìṣíwájú
Lẹ́hìn tí ìyàwó mi, Anne, àti èmi gba ìpè kan láti sìn bí olùdarí mísọ̀n ìgbà kíkún, ẹbí wa pinnu láti kọ́ orúkọ ìránṣẹ́ ìhìnrere kọ̀ọ̀kan kí a tó dé sí inú pápá. A gba àwọn fọ́tò, a ṣe àwọn káàdì pélébé, a sì bẹ̀rẹ̀sí ṣe àṣàrò àwọn ìwò ojú àti ṣíṣe àkọ́sórí àwọn orúkọ.
Nígbà tí a dé, a ṣe àwọn ìpàdé àpapọ̀ ọ̀rọ̀-ìṣíwájú pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́-ìhìnrere. Bí a ti ndarapọ̀, mo rọra gbọ́ ọmọkùnrin wa ẹni ọdún mẹ́sãn:
“Ó dára láti pàdé rẹ, Sámù!”
“Rákẹ́lì, níbo lo ti wá?”
Wáò, Dáfídì, o ga o!”
Pẹ̀lú àníyàn, mo lọ bá ọmọkùnrin wa mo sì sọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ pé, “Héè, jẹ́ ká rántí láti tọ́ka sí àwọn ìránṣẹ́-ìhìnrere bí Alàgbà tàbí Arábìnrin.”
Ó wò mí pẹ̀lú ìwò ojú dídàrú ó sì wí pé, “Baba, mo rò pé ó yẹ kí a ṣe àkọ́sórí àwọn orúkọwọn ni.” Ọmọkùnrin wa ṣe ohun tí ó rò pé ó tọ́ ní dídá lórí òye rẹ̀.
Nítorínáà, kínni òye wa nípa òtítọ́ nínú ayé òde òní? A nní àtakò léraléra pẹ̀lú àwọn èrò inú líle, ríròhìn pẹ̀lú ẹtanú, àti àkọsílẹ̀ tí kò pé. Ní àkókò kannáà, ìwọ̀n àti àwọn orísun àwọn ìwífúnni yi ngbilẹ̀ si. Ìnílò wa láti dá òtítọ́ mọ̀ kò tíì ṣe pàtàkì jù báyi lọ rí!
Òtítọ́ ṣe kókó fúnwa láti ṣe àgbékalẹ̀ kí a sì fún ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run lókun, rí àlàáfíà àti ayọ̀, kí a sì dé ibi agbára àtọ̀runwá wa. Loni, ẹ jẹ́kí á gbé àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yẹ̀ wò:
-
Kínni òtítọ́, àti kínni ìdí tí ó fi ṣe pàtàkì?
-
Báwo ni a ó ti rí òtítọ́?
-
Nígbàtí a bá rí òtítọ́, báwo ni a ti le ṣe àbápín rẹ̀?
Òtítọ́ Jẹ́ ti Ayérayé
Olúwa ti kọ́wa nínú ìwé-mímọ́ pé, “òtítọ́ ni ìmọ àwọn nkan bí wọ́n ṣe wà, àti bí wọ́n ṣe ti wà rí, àti bí wọn yíó ṣe wá” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 93:24). “A kò dá a tàbí ṣe é” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 93:29) àti pé “kò ní òpin” (Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 88:66).1 Òtítọ́ jẹ́ pípé, àìlèyẹ̀, àìleyípadà. Ní àwọn ọ̀rọ̀ míràn, òtítọ́ jẹ́ ti ayérayé.2
Òtítọ́ nràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ẹ̀tàn,3 dá rere mọ̀ yàtọ̀ sí ibi,4 gba ààbò,5 àti láti rí ìtùnú àti ìwòsàn.6 Bákannáà òtítọ́ le ṣe atọ́nà àwọn ìṣe wa,7 sọ wá di òmìnira,8 yà wá sí ḿimọ́,9 kí ó sì darí wa sí ìyè ayérayé.10
Ọlọ́run Nfi Òtítọ́ Ayérayé Hàn
Ọlọ́run nfi òtítọ́ ayérayé hàn sí wa nípasẹ̀ àjọṣe àwọ̀n ìbáṣepọ̀ onífihàn kan tí ó ní Òun Fúnra Rẹ̀, Jésù Krístì, Ẹmí Mímọ́, àwọn wòlíì, àti àwa nínú. Ẹ jẹ́kí á sọ ìyàtọ́ síbẹ̀ ìfarakọ́ra àwọn ipa tí olùkópa kọ̀ọ̀kan nkó nínú ìlànà yí.
Àkọ́kọ́, Ọlọ́run ni orísun gbogbo òtítọ́ ayérayé náà.11 Òun àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì,12 ní òye pípé ti òtítọ́ wọ́n sì nfi ìgbà gbogbo ṣe ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ àti àwọn òfin tòótọ́.13 Agbára yí nfún Wọn láàyè láti ṣe ẹ̀dá kí wọ́n sì ṣe àkóso àwọn ayé14 ati bákannáà láti fẹ́ràn, ṣe ìtọ́ni, ati láti ṣìkẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ní pípé,15 Wọ́n fẹ́ kí á ní òye kí a sì ṣe àmúlò òtítọ́ kí á le gbádùn àwọn ìbùkún náà bí Àwọn ti ṣe.16 Wọ́n le pín òtítọ́ bíi ènìyàn tàbí, ní wíwọ́pọ̀ síi, nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ bí irú Ẹmí Mímọ́, àwọn ángẹ́lì, tàbí àwọn wòlíì alààyè.
Ìkejì, Ẹ̀mí Mímọ́ njẹri gbogbo òtítọ́.17 Òun nfi àwọn òtítọ́ hàn sí wa tààrà Ó sì njẹrí àwọn òtítọ́ tí a kọ́ni láti ọwọ́ àwọn míràn. Àwọn ìṣílétí láti ọ̀dọ̀ Ẹmí máa nsábà wá bíi àwọn èrò sí inú wa àti àwọn ìmọ̀lára sí ọkàn wa.18
Ìkẹta, àwọn wòlíì ngba òtítọ́ àti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ́n sì npín òtítọ́ náà pẹ̀lú wa.10 A nkọ́ òtítọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì àtẹ̀hìnwá nínú àwọn ìwé mímọ́20 àti láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì alààyè ní ibi ìpàdé apapọ̀ gbogbogbò àti nípasẹ̀ àwọn ọ̀nà ìbáraẹni-sọ̀rọ̀ míràn tí a fọwọ́sí.
Ní iparí, ẹ̀yin àti èmi kó ipa pàtàkì nínú ìlànà yi. Ọlọ́run nretí wa láti lépa, dámọ̀, kí a sì mú òtítọ́ lò. Agbára wa láti gbà àti láti ṣe àmúlò òtítọ́ dá lórí okun ti ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Baba àti Ọmọ, ìdáhùnsí wa sí ipá ti Ẹmí Mímọ́, àti ìbárẹ́ wa pẹ̀lú àwọn wòlíì ti ọjọ́-ìkẹhìn.
A nílò láti rántí pé Sátánì nṣiṣẹ́ láti mú wa kúrò ninu òtítọ́. Ó mọ̀ pé láìsí òtítọ́, a kò le gba èrè ìyè ayérayé. Ó nhun àwọn fọ́nrán òtítọ́ pẹ̀lú àwọn ìmọ̀ orí ti ayé láti da iyè wa rú kí ó sì yọ wá lẹ́nu kúrò nínú ohun tí a bá wa sọ láti ọwọ́ Ọlọ́run.21
Lílépa, Dídámọ̀, àti Mímú Òtítọ́ Ayérayé Lò
Bí a ti nlépa òtítọ́ ayérayé,22 àwọn ìbéèrè méjì tó tẹ̀lé yí le rànwá lọ́wọ́ láti mọ̀ bóyá èrò inú kan wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tàbí orísun míràn:
-
Njẹ́ èrò orí náà njẹ́ kíkọ́ni déédé nínú àwọn ìwé mímọ́ tàbí àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì alààyè bí?
-
Njẹ́ èrò orí náà ndi fífẹsẹ̀ múlẹ̀ nípa ẹ̀rí ti Ẹmí Mímọ́ bí?
Ọlọ́run nfi àwọn òtítọ́ ti ẹ̀kọ́ hàn nípasẹ̀ àwọn wòlíì, Ẹmí Mímọ́ sì nfi ẹsẹ̀ àwọn òtítọ́ náà múlẹ̀ Ó sì nràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àmúlò wọn.23 A gbọ́dọ̀ lépa kí a sì múrasílẹ̀ láti gba àwọn ìṣílétí ti ẹ̀mí wọ̀nyí nígbàtí wọ́n bá wá.24 A jẹ́ olùgbà jùlọ sí ìjẹ́rí ti Ẹmí nígbàtí a bá jẹ́ onírẹ̀lẹ̀,25 tí a ngbàdúrà pẹ̀lú òtítọ́ ọkàn tí a sì nṣe àṣàrò àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,26 àti tí a npa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́.27
Lẹ́hìn tí Ẹmí Mímọ́ bá ti fi ẹsẹ̀ òtítọ́ kan pàtó múlẹ̀ sí wa, òye wa njinlẹ̀ si bí a bá ti nfi ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ náà sínú ìṣe. Nígbàtí ó bá yá, bí a ti ngbé ìgbé ayé ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ náà, a njèrè ìmọ̀ kan tó dájú nípa òtítọ́ náà.28
Fún àpẹrẹ, mo ti ṣe àwọn àṣìṣe mo sì ní ìmọ̀lára ìrẹ̀wẹ̀sì fún àwọn yíyàn tí kò dára. Ṣùgbọ́n nípasẹ̀ àdúrà, àṣàrò, àti ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, mo gba ẹ̀rí nípa ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ ti ìrònúpìwàdà.29 Bí mo ti tẹ̀síwájú láti máa ronúpìwàdà, òye mi nípa ìrònúpìwàdà di lílágbára si. Mo ní ìmọ̀lára sísúnmọ́ Ọlọ́run àti Ọmọ Rẹ̀ si. Mo mọ̀ nísisìyí pé a lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì nípasẹ̀ Jésù Krístì, nítorípé mo ní ìrírí àwọn ìbùkún ti ìrònúpìwàdà ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.30
Gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run Nígbàtí Òtítọ́ Kò Tíì di Fífihàn Síbẹ̀
Nítorínáà, kínni a níláti ṣe nígbàtí a bá nfi tọkàntọkàn lépa fún òtítọ́ tí kò tíi` di fífihàn síbẹ̀? Mo ní ìyọ́nú fún àwọn wọnnì nínú wa tí wọ́n npòngbẹ fún àwọn ìdáhùn tí ó dàbí ẹnipé kò wá.
Sí Joseph Smith, Olúwa gbà á nímọ̀ràn pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́ títí tí èmi yíò fi ri pé ó tọ́ láti sọ ohun gbogbo di mímọ̀ … nípa ohun náà.” (Ẹkọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 10:37).
Àti sí Emma Smith, Ó ṣe àlàyé pé, “Máṣe kùn nítorí àwọn ohun tí ìwọ kò tíì rí, nítorí a fi wọ́n pamọ́ fún ọ àti fún àwọn aráyé, èyítí ó jẹ́ ọgbọ́n nínú mi fún àkókò tí ó nbọ̀” (Ẹkọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 25:4)
Èmi pẹ̀lú ti wá àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè àtọkànwá. Ọpọ̀lọpọ̀ àwọn ìdáhùn ti wá; àwọn kan kò tíì wá.31 Bí a ti ndúró—ní gbígbẹ́kẹ̀lé ọgbọ́n àti ìfẹ́ Ọlọ́run, ní pípa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, àti fífi ara ti ohun tí a mọ̀—Òun nràn wá lọ́wọ́ láti rí àlàáfíà títí tí Òun ó fi fi òtítọ́ ohun gbogbo hàn.32
Níní Òye Ẹkọ́ àti Àwọn Ètò-ìmúlò
Nígbàtí a bá nwá òtítọ́, ó nrànwá lọ́wọ́ láti ní òye ìyàtọ̀ láàrin ẹ̀kọ́ àti ètò-ìmúlò. Ẹkọ́ ntọ́ka sí àwọn òtítọ́ ayérayé, bí irú àdánidá Ọlọ́run-olórí-ọ̀run, ètò ìgbàlà, ẹbọ ìṣètùtù ti Jésù Krístì, Ìlànà ni lílo ẹ̀kọ́ tó dá lórí àwọn ipò lọ́wọ́lọ́wọ́. Àwọn ìlànà nranwá lọ́wọ́ lati ṣe ìpínfúnni Ìjọ ní ọ̀nà tí ó létò.
Nígbàtí ẹ̀kọ́ kìí yípadà láé, ìlànà ndi títúnṣe láti àkókò dé àkókò. Olúwa nṣiṣẹ́ nípasẹ̀ àwọn wòlíì Rẹ̀ láti di ẹ̀kọ́ Rẹ̀ mú àti láti ṣe àtúnṣe sí àwọn ètò-ìmúlò Ìjọ ní ìbámu sí àwọn ìnílò àwọn ọmọ Rẹ̀.
Pẹ̀lú ẹ̀dùn, nígbàmíràn a máa nda ètò-ìmúlò pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀kọ́. Bí a kò bá ní òye ìyàtọ̀ náà, a nfi ewu níní ìjákulẹ̀ ṣeré nígbàtí àwọn ètò-ìmúlò bá yípadà, àní a sì le bẹ̀rẹ̀ sí máa tọpinpin ọgbọ́n Ọlọ́run tàbí ipa onífihàn ti àwọn wòlíì,33
Kíkọ́ni ní Òtítọ́ Ayérayé
Nígbàtí a bá gba òtítọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, Ó ngbàwá níyànjú láti ṣe àbápín ìmọ̀ náà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.34 A nṣe èyí nígbàtí a bá nkọ́ kíláàsì kan, ntọ́ ọmọ kan sọ́nà, tàbí ṣe àjọsọ àwọn òtítọ́ ìhìnrere pẹ̀lú ọ̀rẹ́ kan.
Ìfojúsùn wa ni láti kọ́ni ní òtítọ́ ní ọ̀nà tí yío pe agbára ìyílọ́kànpadà ti Ẹ̀mí Mímọ́.35 Ẹ jẹ́kí nṣe àbápín àwọn ìfipè kan tó rọrùn láti ọ̀dọ̀ Olúwa àti àwọn wòlíì Rẹ̀ tí ó le rànwá lọ́wọ́.36
-
Dídá lé Bàbá Ọ̀run, Jésù Krístì, àti ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ Wọn.37
-
Dúró dáradára nínú àwọn ìwé mímọ́ àti nínú àwọn ìkọ́ni àwọn wòlíì ọjọ́-ìkẹhìn.38
-
Sinmi lé ẹ̀kọ́ tí a gbékalẹ̀ nípasẹ̀ ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́ri tì wọ́n ní àṣẹ.39
-
Ẹ yẹra fún àdárò, àwọn èrò inú ti ara ẹni, tàbí àwọn èrò orí ti ayé.40
-
Kọ́ni ní kókó ẹ̀kọ́ kan láàrin àkójọpọ̀ àwọn òtítọ́ ìhìnrere tó bárajọ.41
-
Ẹ lo àwọn ètò ìkọ́ni tí ó npe ipá ti Ẹmí.42
-
Ẹ ṣe ìbáraẹnisọ̀rọ̀ ní kedere láti yẹra fún èdè àìyédè.43
Sísọ Òtítọ́ nínú Ìfẹ́
Bí a ti nkọ́ni ní òtitọ́ ṣe pàtàkì gan-an Páùlù gbà wà níyànjú láti sọ “òtítọ́ nínú ìfẹ́” (wo Efésù 4:14–15). Èyí túmọ̀ sí pé òtítọ́ ní ààyè dídárajùlọ ti bíbùkún ẹlòmíràn nígbàtí a bá gbé e pẹ̀lú ìfẹ́ bíi-ti-Krístì.44
Òtítọ́ tí a bá kọ́ni láìsí ìfẹ́ le fa àwọn ìmọ̀lára ìdánilẹ́jọ́, ìrẹ̀wẹ̀sì, àti dídánìkanwà. Ó ṣaábà máa ndarí sí ìbínú àti ìpínyà—àní ìjà. Ní ọ̀nà míràn, ìfẹ́ láìsí òtítọ́ jẹ́ ṣíṣófo kò sì ní ìlérí ti dídàgbà.
Méjéèjì òtítọ́ àti ìfẹ́ ṣe kókó fún ìdàgbàsókè wa ti ẹ̀mí.45 Òtítọ́ npèsè ẹ̀kọ́, àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́, àti àwọn òfin tó ṣe dandan láti jèrè ìyè ayérayé, nígbàtí ìfẹ́ nṣe àmúwá ìwúrí tí a nílò láti ṣe ìgbàmọ́ra kí a sì ṣiṣẹ́ lórí ohun tí ó jẹ́ òtítọ́.
Mo fi ìmoore hàn títí láé fún àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n fi sùúrù kọ́mi ní òtítọ́ ayérayé pẹ̀lú ìfẹ́.
Íparí
Ní ìparí, ẹ jẹ́kí nṣe àbápín àwọn òtítọ́ ayérayé tí wọ́n ti di ìdákọ̀ró sí ọkàn mi. Mo ti gba ìmọ̀ àwọn òtítọ́ wọ̀nyí nípa títẹ̀lé àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́ tí a sọ̀rọ̀ lé lórí lóni.
Mo mọ̀ pé Ọlọ́run jẹ́ Baba wa Ọ̀run.46 Ó mọ ohun gbogbo,47 Ó ní gbogbo agbára,48 àti olùfẹ́ni ní pípé.49 Ó ṣe ẹ̀dá ètò kan tí ó mu ṣeéṣe fúnwa láti jèrè ìyè ayérayé kí a sì dàbí Rẹ̀.50
Bí apákan ètò náà, Ó rán Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, láti ràn wá lọ́wọ́.51 Jésù kọ́ wa láti ṣe ìfẹ́ Baba52 àti láti fẹ́ràn ara wa.53 Ó ṣe ètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa54 Ó sì fi ẹ̀mí Rẹ̀ lélẹ̀ ní orí àgbélèbú.55 Ó jí dìde kúrò nínú òkú lẹ́hìn ọjọ́ mẹ́ta,56 Nípasẹ̀ Krístì àti ore ọ̀fẹ́ Rẹ̀, a ó jínde,57 a le jẹ́ dídáríjì,58 a sì le rí okun nínú ìpọ́njú.59
Ní ìgbà iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ ní ilẹ̀ ayé, Jésù gbé Ìjọ Rẹ̀ kalẹ̀.60 Lẹ́hìn àkókò díẹ̀, Ìjọ náà di yíyípadà, àwọn òtítọ́ sì sọnù.61 Jésù Krístì mú Ìjọ Rẹ̀ àti àwọn òtítọ́ ìhìnrere padàbọ̀sípò nípasẹ̀ Wòlíì Joseph Smith.62 Àti lóní, Krístì tẹ̀síwájú láti darí Ìjọ Rẹ̀ nípasẹ̀ àwọn wòlíì àti àwọn àpóstélì alààyè.63
Mo mọ̀ pé bí a ti nwá sí ọ̀dọ̀ Krístì, a le “sọ wá di pípé nínú rẹ̀” nígbẹ̀hìn (Mórónì 10:32), a le gba “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀ kan” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 93:33), kí a sì gba “gbogbo ohun tí Baba [náà] ní” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 84:38). Sí àwọn òtíiọ́ ayérayé wọ̀nyí ni mo jẹ́ ẹ̀rí ni orúkọ mímọ́ Jésù Krístì, àmín.