Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Agbára Jésù Krístì nínú Ayé Wa Lójoojúmọ́
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́wàá 2023


10:17

Agbára Jésù Krístì nínú Ayé Wa Lójoojúmọ́

Mo ti ríi pé orísun okun náà ni ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì bí a ti nlépa láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan àti ojoojúmọ́.

Ẹyin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, èyí ni Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn. Ó ti jẹ́ ayọ̀ tó láti péjọ nínú Ìjọ Rẹ̀. Mo kún fún ọpẹ́ pé Ààrẹ Russell M. Nelson ti rán wa létí láti máa lo orúkọ pípé ti Ìjọ Olúwa nígbàkúùgbà kí a le máa rántí Ìjọ ẹnití èyí í ṣe àti àwọn ìkọ́ni ẹnití a ntẹ̀lé.

Ààrẹ Nelson ti sọ pé: “Ní àwọn ọjọ́ tí ó nbọ̀, a ó rí àwọn ìfarahàn títóbijùlọ tí agbára Olùgbàlà tí ayé kò rí rí láé. … Òun ó fi àwọn ànfààní, àwọn ìbùkún, àti àwọn iṣẹ́ ìyanu àìlekà fún àwọn olódodo.”1

Ọ̀kan lára àwọn ànfààní àti àwọn ààyè títóbijùlọ fún èmi àti ìyàwó mi, Renee, ni láti pàdé pẹ̀lú àwọn Ènìyàn Mímọ́ níbití a ti nsìn. A gbọ́ àwọn ìtàn wọn, a ṣe ẹlẹ́rìí àwọn àdánù wọn, a ṣe àbápín ẹ̀dùn ọkàn wọn, a sì yọ̀ pẹ̀lú àṣeyọrí wọn. A ti ṣe ẹlẹ́rìí púpọ̀ nínú àwọn ìbùkún àti iṣẹ́ ìyanu tí Olùgbàlà ti fi fún àwọn olõtọ́. A ti pàdé àwọn ènìyàn tí wọ́n ti la kòṣeéṣe kọjá, tí wọ́n ti jìyà ohun tí kò ṣeé rò.

Ààrẹ José Batalla ati ìyàwó rẹ̀, Arábìnrin Valeria Batalla.
Flavia Cruzado ati baba rẹ̀.

A ti rí ìfarahàn agbára Olùgbàlà nínú opó kan tí ó pàdánù ọkọ rẹ̀ nígbàtí wọ́n wà ní ẹnú iṣẹ́ Olúwa ní Bolivia.2 A ti rí i nínú ọ̀dọ́mọbìnrin kan ní Argemtina ẹnití a tì sí abẹ́ tírénì tí ó sì pàdánù ẹsẹ̀ rẹ̀, nítorípé ẹnìkan kàn fẹ́ jí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ alágbẽká rẹ̀.3 Àti nínú ànìkanwà baba rẹ̀, ẹnití nísisìyí ó níláti ṣa àwọn èrúnrún kí ó sì fún ọmọbìnrin rẹ̀ lókun lẹ́hìn irú ìwà ìkà tí kò ṣeé ṣàlàyé bẹ́ẹ̀. A ti rí i nínú àwọn ẹbí tí wọ́n pàdánù àwọn ìbùgbé àti gbogbo ohun ìní wọn ní àkókò àwọn iná ní Chile ní ọjọ́ méjì péré ṣaájú Kérésìmesì ní 2022.4 A ti rí i nínú àwọn wọnnì tí wọ́n jìyà lẹ́hìn ìkọ̀sílẹ̀ tó nira àti nínú àwọn tí wọ́n bọ́ sọ́wọ́ ìlòkulò láìṣẹ̀.

Àwọn iná ní Chile.

Kínni ó fún wọn ní agbára láti la àwọn ohun líle kọjá? Kínni ó ṣe àfikún ìpele ti okun láti tẹ̀síwájú nígbàtí ohun gbogbo dàbí pé ó ti sọnù?

Mo ti ríi pé orísun okun náà ni ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì bí a ti nlépa láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan àti ojoojúmọ́.

Wòlíì Jákọ́bù kọ́ni pé, “Òun sì nbọ̀wá sínú ayé kí ó lè gba gbogbo ènìyàn là bí wọ́n bá fetísílẹ̀ sí ohùn rẹ̀; nítorí ẹ kíyèsíi, òun jìyà àwọn ìrora gbogbo ènìyàn, bẹ̃ni, àwọn ìrora ẹ̀dá alãyè gbogbo, àti àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin, àti àwọn ọmọdé, tí wọ́n jẹ́ ti ìdílé Ádámù.”5

Nígbà míràn, níní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì le dàbí ohun kan tí kò ṣeéṣe, tí a fẹ́rẹ̀ má le ṣe yọrí. A le rò pé wíwá sí ọ̀dọ̀ Krístì nílò okun, agbára, àti jíjẹ́ pípé kan tí a kò ní, àti pé a kò kàn le rí agbára láti le ṣe gbogbo rẹ̀ tán. Ṣùgbọ́n ohun tí mo ti kọ́ láti ara gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí ni pé ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì ni ohun tí nfún wa ní agbára láti bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò náà. Ní àwọn ìgbà míràn a le rò pé, “Mo nílò láti ṣe àtúnṣe ayé mi kí èmi tó wá sí ọ̀dọ̀ Jésù.” ṣùgbọ́n òtítọ́ ibẹ̀ ni pé a nwá sí ọ̀dọ̀ Jésù láti ṣe àtúnṣe ayé wa nípasẹ̀ Rẹ̀.

A kò wá sí ọ̀dọ̀ Jésù nítorípé a jẹ́ pípé. A wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nítorípé a ní àbùkù àti nínú Rẹ̀ a le “sọ wá di pípé.”6

Báwo ni a ṣe le bẹ̀rẹ̀ sí lo ìgbàgbọ́ díẹ kékeré ní ojoojúmọ́? Fún èmi ó bẹ̀rẹ̀ ní òwúrọ̀: nígbàtí mo bá jí, dípò kí nwo ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ mi, èmi ó gbàdúrà. Àní àdúrà tó rọrùn kan. Lẹ́hìnnáà èmi ó ka ìwé mímọ́ kan. Èyí nràn mí lọ́wọ́ pẹ̀lú májẹ̀mú mi ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ tí mo ndá bí mo ti nkópa nínú àmì májẹ̀mú láti máa ˇrántí rẹ̀ nígbà gbogbo.”7 Nígbàtí mo bá bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ mi pẹ̀lú àdúrà àti ìwé mímọ́, mo le “rántí Rẹ̀” nígbáti mo bá wo ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ mi. Mo le “rántí Rẹ̀” nígbàtí mo bá nbá ìyàwó àti àwọn ọmọ mi sọ̀rọ̀, nígbàtí mo bá dojúkọ àwọn ìṣòro àti àwọn ìjà, èmi ó sì gbìyànjú láti kojú wọn bí Jésù yío ti ṣe.

Nígbàtí mo bá “rántí Rẹ̀,” mo nní ìmọ̀lára ìfẹ́ inú láti yípadà, láti ronúpìwàdà. Mo nrí orísun agbára láti pa àwọn májẹ̀mú mi mọ́, mo sì ní ìmọ̀lára ipá Ẹ̀mí Mímọ́ nínú ayé mi “mo sì npa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ èyítí ó ti fi fún [mi]; kí [èmi] ó le máa fi ìgbà gbogbo ní Ẹ̀mí rẹ̀.”8 Ó nràn mí lọ́wọ́ láti fi ara dà títí dé òpin.9 Tàbí ó kéré jù dé òpin ọjọ́! Àti pé ní àwọn ọjọ́ wọnnì tí mo bá kùnà láti rántí Rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́, Òun sì wà níbẹ̀, tí ó nfẹ́ràn mi tí ó sì nsọ fúnmi pé ó Dára, o le gbìyànjú lẹ́ẹ̀kansíi lọ́la.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa jẹ́ àìpé ní rírántí Rẹ̀, olùfẹ́ni Baba wa Ọrun kò kùnà rí láé láti rántí wa.

Ọkan nínú àwọn àṣìṣe tí a sáábà máa nṣe ni láti rò pé pípa àwọn májẹ̀mú, tàbí àwọn ìlérí tí a ṣe sí Ọlọ́run mọ́, jẹ́ àdéhùn ti a ṣe pẹ̀lú Rẹ̀: Mo gbọ́ràn, Òun sì dáàbò bò mí kúrò nínú ohun búburú kankan ní ṣíṣẹlẹ̀ sí mi. Mo nsan ìdámẹ́wa mi, èmi kò sì ní pàdánù iṣẹ́ mi tàbí iná kò ní jó ilé mi. Ṣùgbọ́n lẹ́hìnnáà nígbàtí àwọn nkan kò bá lọ bí a ṣe nírètí, a nkigbé sí Olúwa pé, “Ìwọ kò ha bìkítà bí mo ṣègbé?”10

Àwọn májẹ̀mú wa kìí ṣe bíi ìṣàdéhùn lásán; wọ́n jẹ́ ìṣàtúnṣe.11 Nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú mi mo ngba agbára ìyani-sí-mímọ́, ìfúnni-lókun ti Jésù Krístì, èyítí ó nfún mi ní ààyè láti di ènìyàn ọ̀tun, láti dáríjì fún ohun tó dàbí àìṣeé-dáríjì, láti borí kòṣeéṣe. Rírántí Jésù Krístì nígbà gbogboní agbára; ó nfún mi ní àfikún okun láti “pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ èyítí òun ti fi fún [mi].”12Ó nrànmí lọ́wọ́ láti dára síi, láti rẹ́rĩn músẹ́ láìnídìí, láti jẹ́ onílàjà,13láti yẹra fún ìjà, láti jẹ́kí Ọlọ́run borí nínú ayé mi.14

Nígbàtí ìrora wa tàbí ìrora ẹnìkan tí a fẹ́ràn bá pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí a kò le rí ara gbé e, rírántí Jésù Krístì àti wíwá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ le mú ẹrù náà fúyẹ́, mú ọkàn náà rọ̀, kí ó sì mú ìrora náà rọrùn. Èyí ni agbára tí ó mú ṣeéṣe fún baba kan tayọ agbára àdánidá rẹ̀ láti mú ọmọbìnrin rẹ̀ dúró la ìrora àfojúrí àti ti ẹ̀dùn ọkàn ti pípàdánù ẹsẹ̀ rẹ̀ já.

Flavia Cruzado pẹ̀lú Alàgbà Ulisses Soares.

Nígbàtí Alàgbà Soares bẹ Argentina wò nínú Oṣù Kẹfà tí ó kẹ́hìn tí ó sì bèèrè lọ́wọ́ Flavia nípa ìjàmbá bíbani-nínújẹ́ rẹ̀, ó fi pẹ̀lú ìgbàgbọ́ fèsì pé, “Mo ní ìrírí ìdààmú, ìkorò, ìbínú, àti ìkórĩra nígbàtí [èyí ṣẹlẹ̀]. Ohun kan tí ó rànmí lọ́wọ́ ni láti máṣe bèèrè pé, ‘ó ṣe jẹ́ èmi?’ ṣùgbọ́n ‘fún kínni?’ Èyí ni ohun kan tí ó mú mi súnmọ́ àwọn ẹlòmíràn àti sí Olúwa. … Dípò kí nfi ara mi jìnnà sí I, mo níláti so mọ́ Ọ.”15

Ààrẹ Nelson kọ́ni pé: Èrè fún pípa àwọn májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run mọ́ ni agbára ti ọ̀run—agbára tí ó nfún wa lokun láti kojú àwọn ìpèníjà, àwọn ìdánwò, àti àwọn ìrora-ọkàn dárajù. … Bayi, àwọn olùpamọ́ májẹ̀mú ní ẹ̀tọ́ sí irú ìsinmi pàtàkì kan.”16 Èyí ni irú àláfíà àti ìsinmi tí mo rí ní ojú opó náà, láìka ìrora ọkàn ti ṣíṣe àárò ọkọ rẹ̀ lójoojúmọ́ sí.

Ìjì ní orí Òkun Gálílì.

Májẹ̀mú Titun sọ fún wa nípa àkókò kan nígbàtí Jésù àti àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ wà nínú ọkọ̀ ojú omi:

“ìjì líle ti afẹ́fẹ́ kan dìde, àwọn ìgbì omi sì rọ̀ sínú ọkọ̀ ojú-omi. …

“Òun sì wà … ó nsún lórí ìrọ̀rí: wọ́n sì jí i, wọ́n sì wí fún un pé, Olùkọ́ni, ìwọ kò bìkítà bí àwa ṣègbé?

“Ó sì jí, ó sì bá afẹ́fẹ́ ná wí, ó sì wí fún òkun pé, Dákẹ́, jẹ́. …

Ó bèèrè pé, “Kílódé tí ẹ̀yin fi bẹ̀rù tó bẹ́ẹ̀? kínní ṣe tí ẹyin kò ní ìgbàgbọ́?”17

Mo ti máa nfi ìgbà gbogbo ní ìjọlójú nípasẹ̀ ìtàn yí. Njẹ́ Olúwa retí wọn láti lo ìgbàgbọ́ wọn láti mú ìjì náà dákẹ́ bí? Láti bá àwọn afẹ́fẹ́ ná wí? Ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì ni ìmọ̀lára àláfíà láti kojú ìjì náà, ní mímọ̀ pé a kò ní ṣègbé nítorípé Òun wà nínú ọkọ̀ pẹ̀lú wa.

Èyí ni irú ìgbàgbọ́ tí a rí nígbàtí a bẹ àwọn ẹbí wò lẹ́hìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ iná ní Chile. Àwọn ilé wọn ti jóná kanlẹ̀, wọ́n ti pàdánù ohun gbogbo. Síbẹ̀ bí a ti nrìn nínú ohun tí ó ti jẹ́ àwọn ibùgbé wọn tẹ́lẹ̀ rí, tí wọ́n sì nsọ fúnwa nípa àwọn ìrírí wọn, a ní ìmọ̀lára pé a ndúró lórí ilẹ̀ mímọ́. Arábìnrin kan sọ fún ìyàwó mi pé, “Nígbàtí mo ríi pé àwọn ilé itòsí njóná, mo ní ìtẹ̀mọ́ra pé ilé wa yío jóná, pé a ó pàdánù ohun gbogbo. Dípò ìdààmú, mo ní ìrírí ìmọ̀lára àláfíà tí kò ṣeé júwe. Ní ọ̀nà kan, mo ní ìmọ̀lára pé ohun gbogbo yío dára.” Gbígbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run àti pípa àwọn májẹ̀mú wa pẹ̀lú Rẹ̀ mọ́ nmú agbára wá sí àìlera wa àti ìtùnú sí ìbànújẹ́ wa.

Mo fi ìmoore hàn fún ànfààní tí Renee àti èmi ní láti pàdé díẹ̀ lára àwọn Ènìyàn Mímọ́ tí kò wọ́pọ̀ wọ̀nyí, fún ọ̀pọ̀ àwọn àpẹrẹ ìgbàgbọ́, okun, àti ìfaradà wọn. Fún àwọn ìtàn ọkàn bíbàjẹ́ àti ìjákulẹ̀ tí kò níi jáde láé ní ojú ewé àkọ́kọ́ ìwé ìròhìn kan tàbí kí ó lọ kárí ayé. Fún àwọn àwòrán tí a kò yà nípa àwọn omijé tí a ta sílẹ̀ àti àwọn àdúrà tí a gbà lẹ́hìn àdánù kan tàbí ìkọ̀sílẹ̀ kan tó nira, fún àwọn àtẹ̀jíṣẹ́ tí a kò ṣe rí nípa ẹ̀rù, ìbànújẹ́, àti ìrora tí ó di fífúyẹ́, ọpẹ́ fún ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀. Àwọn ènìyàn wọ̀nyí fún ìgbàgbọ́ tèmi lókun , àti fún èyí mo ní ìjìnlẹ̀ ìmoore.

Mo mọ̀ pé èyí ni Ìjọ ti Jésù Krístì. Mo mọ̀ pé Ó dúró ní síṣetán lati fúnwa ní ẹ̀bùn pẹ̀lú agbára Rẹ̀, bí a ti nwá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ní ọjọ́ kọ̀ọ̀kan àti ní ojoojúmọ́. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.