Ìyìn fún Ọkùnrin Náà
Bí a ti jẹ́ alábùnkún fun púpọ̀-púpọ̀ tó láti mọ gbogbo ohun tí a mọ̀ nítorípé a ní Joseph Smith, wòlíì àkókò iṣẹ ìríjú ti ìkẹhìn yí.
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, mo ní ìrẹ̀lẹ̀ láti wà pẹ̀lú yín ní àárọ̀ yí. Mo gbàdúrà pé Olúwa yío bùkún mi.
Àwọn ojú mi kò rí bí wọ́n ti máa nrí tẹ́lẹ̀ mọ́. Mo lọ rí dókítà ojú, mo sì wí pé, “Èmi kò le rí ẹ̀rọ-aṣínilétí.”
Ó sì wí pé, “Ó dára, àwọn ojú rẹ ti dàgbà. Wọn kò le yípadà.”
Nítorínáà èmi ó ṣe dáradára jùlọ tí mo le ṣe.
Yío wùmí láti ṣe àbápín àwọn ohun díẹ̀ tí ó ti wà nínú mi pẹ̀lú yín. Ó ti dàbí ẹnipé mo ní Wòlíì Jósẹ́fù ní inú mi ní àwọn oṣù díẹ̀ tó gbẹ́hìn. Mo ti jókòó mo sì ro ojúṣe ológo rẹ̀ ní dída wòlíì ti ìsisìyí, ìgbà iṣẹ́ ìríjú ti ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn àkókò.
Mo ronú bí a ti ní ìmoore tó bí ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti awọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn pé Joseph Smith, ọmọdékùnrin kan tí ó ní ìfẹ́ inú láti mọ ohun tí ó nílò láti ṣe láti rí ìdáríjì fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, rí ìgboyà láti lọ sí inú igbó ṣúúrú ti àwọn igi nítòsí ilé rẹ̀ ní Palmyra, New York, àti pé níbẹ̀ ó kúnlẹ̀ nínú àdúrà, àti—nípa ọ̀rọ̀ ti ara rẹ̀—ó gbàdúrà sókè fún ìgbà àkọ́kọ́ (wo Ìtàn—Josefu Smith 1:14
Ní ìgbà náà, bí Jósẹ́fù ṣe dé orí eékún rẹ̀ ní ibi tí a pè ní Igbó Ṣúúrú Mímọ́, àwọn ọ̀run ṣí. Àwọn ẹ̀dá ènìyàn méjì, tí wọ́n tàn ju òòrùn ọ̀sán gangan lọ, fi ara hàn níwájú rẹ̀. Ọkan bá a sọ̀rọ̀ ó sì wípé, “[Joseph,] èyí ni Àyànfẹ́ Ọmọ Mi. Gbọ́ Tirẹ̀!” (Ìtàn—Josefu Smith 1:17). Báyi ni Ìmúpadàbọ̀sípò ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere àìlópin ti Jésù Krístì bẹ̀rẹ̀.
Nítorípé Jésù, Olùgbàlà wa àti Olùràpadà wa, bá ọmọdékùnrin Jósẹ́fù sọ̀rọ̀ tí ó sì ṣí àkókò iṣẹ ìríjú yí tí a ngbé inú rẹ̀ nísisìyí, a nkọrin, “Ìyìn fún ọkùnrin náà ẹnití ó sọ̀rọ̀ pẹ̀lú Jèhófàh!” (“Ìyìn sí Ọkùnrin náà,” Àwọn Orin Ìsìn, no. 27). A dúpẹ́ lọ́wọ́ Olúwa fún Joseph Smith àti fún ìgboyà rẹ̀ láti lọ sínú igbó ṣúúrú ti àwọn igi náà ní 1820, nitòsí ilé rẹ̀ ní Palmyra, New York.
Mo ti nronú nípa gbogbo àwọn ohun ìyanu tí a mọ̀ àti gbogbo àwọn ohun tí a ní. Ẹyin àyànfẹ́ arákùnrin àti arábìnrin mi, ẹ̀rí mi si yín ní òwúrọ̀ yí ni bí a ti jẹ́ alábùnkún fun púpọ̀-púpọ̀ tó láti mọ gbogbo ohun tí a mọ̀ nítorípé a ní Joseph Smith, wòlíì àkókò iṣẹ ìríjú ti ìkẹhìn yí.
A ní òye èrèdí ìgbé ayé, ti ẹni tí a jẹ́.
A mọ ẹni tí Ọlọ́run jẹ́; a mọ ẹni tí Olùgbàlà jẹ́, nítorípé a ní Jósẹ́fù, ẹnití ó lọ sínú igbó súúrú àwọn igi bíi ọmọdékùnrin kan, ní wíwá ìdáríjì fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
Mo rò pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn nkan ológo àti yíyanilẹ́nu jùlọ ti ẹnikẹ́ni nínú ayé yi le mọ̀—pé Baba wa Ọrun àti Olúwa Jésù Krístì ti fi Ara Wọn hàn ní ọjọ́ ìkẹhìn yí àti pé a ti gbé Jósẹ́fù dìde láti mú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere àìlópin ti Jésù Krístì padàbọ̀sípò.
A ní Ìwé ti Mọ́mọ́nì. Ìwé ti Mọ́mọ́nì ti jẹ́ ẹ̀bùn ìyanu àti yíyanilẹ́nu tó fún gbogbo àwọn ọmọ Ìjọ. Ó jẹ́ ẹ̀ri míràn, májẹ̀mú míràn pé Jésù ni Krístì náà. A ní i nítorípé Jósẹ́fù yẹ láti lọ gbé àwọn àwo náà, ó ní ìmísí láti ọ̀run láti ṣe ìyírọ̀padà wọn nípa ẹ̀bùn àti agbára Ọlọ́run àti láti fi ìwé náà fún aráyé.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ mi rọrùn, ó jinlẹ̀, ó sì kún fún ìfẹ́ fún Wòlíì Joseph Smith àti fún gbogbo àwọn wọnnì, àwọn arákùnrin àti arábìnrin mi, tí wọ́n ti ṣe ìmúdúró rẹ̀ tí wọ́n sì ṣetán láti tì í lẹ́hìn ní ìgbà ọ̀dọ́ rẹ̀.
Yío wùmí láti gbé oríyìn ní òwúrọ̀ yí fún ìyá rẹ̀. Mo ti máa nfi ìgbà gbogbo ròó bí ó ti jẹ́ ìyanu tó pé nígbàtí Jósẹ́fù dé ilé láti ibi ìrírí náà nínú Igbó Ṣúúrú Mímọ́ tí ó sì sọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ fún ìyá rẹ̀, Lucy Mack Smith gbà á gbọ́.
Mo ní ìmoore fún baba rẹ̀ àti fún àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn arábìnrin rẹ̀ àti fún ẹbí rẹ̀, tí wọ́n dúró tì í nínú ojúṣe nlá náà tí Olúwa ti gbé lé e lórí láti di wòlíì láti mú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere àìlópin ti Jésù Krístì padàbọ̀sípò lẹ́ẹ̀kansíi sórí ilẹ̀ ayé.
Nítorínáà ẹ̀rí mi ní òwúrọ̀ yí ni pé mo mọ̀ pé Jésù Krístì ni Olùgbàlà àti Olùràpadà aráyé. Mo mọ̀ bákannáà pé Baba wa Ọ̀run àti Olúwa Jésù Krístì fi ara hàn wọ́n sì bá Jósẹ́fù sọ̀rọ̀ wọ́n sì múra rẹ̀ sílẹ̀ láti jẹ́ wòlíì náà.
Mo ní ìyanu, ó sì dámi lójú pé ó rí bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ yín náà, nípa bí a ti jẹ́ alábùnkún fun tó láti mọ̀ ohun tí a mọ̀ nípa èrèdí wa nínú ayé, ìdí tí a fi wà níhĩn, ohun tí a nílati máa gbìyànjú láti ṣe àti láti yọrí ní ìgbé ayé wa ojojúmọ́. A wà nínú ìlànà gbígbìyànjú láti múra wa sílẹ̀, ọjọ́ kan ní àkókò kan, láti jẹ́ dídára díẹ̀ síi, alãnú díẹ̀ síi, mímúra díẹ̀ síi fún ọjọ́ náà, èyí tí yío wá dájúdájú, nígbàtí a ó kọjá padà sí ọ̀dọ̀ Baba wa Ọ̀run àti Olúwa Jésù Krístì.
Èyíinì nsúnmọ́ díẹ̀ síi fún mi. Láìpẹ́ èmi ó di ẹni ọdún marundinlaadọwa. Àwọn ọmọ mi máa nsọ pé àwọn rò pé mo ti dàgbà púpọ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ, ṣùgbọ́n èyí kò ṣe nkan. Mo nṣe dídára jùlọ tí mo le ṣe.
Ṣùgbọ́n fún ó fẹ́rẹ̀ tó àádọ́ta ọdún, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, mo ti ní ànfààní láti lọ káàkiri àgbáyé nínú iṣẹ́ yíyàn mi bíi Aláṣẹ Gbogbogbò ti Ìjọ. Ó ti jẹ́ ìbùkún yíyanilẹ́nu. Mo rò pé mo ti fẹ́rẹ̀ súnmọ́ gbogbo àwọn abala àgbáyé jùlọ. Mo ti pàdé àwọn ọmọ Ìjọ ní gbogbo àgbáyé.
Áà, mo ti fẹ́ràn yín tó. Ó ti jẹ́ ìrírí ológo tó—láti wo àwọn ojú yín, wà ní ọ̀dọ̀ yín, àti láti ní ìmọ̀lára ìfẹ́ yín tí ẹ ní fún Olúwa àti fún Ìmúpadàbọ̀sípò ìhìnrere ti Jésù Krístì.
Kí Baba wa Ọ̀run ṣe ìṣọ́ lórí wa nísisìyí kí Ó sì bùkún gbogbo àwọn ìtẹ̀síwájú ìpàdé apapọ̀ náà. Kí a sì le ní Ẹmí Olúwa dáradára nínú ọkàn wa, àti kí ìfẹ́ wa fún ìhìnrere ti Jésù Krístì—àyànfẹ́ Olùgbàlà wa, Olúwa Jésù Krístì—máa pọ̀ síi bí a ti ntiraka láti sìn Ín àti láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́ àti láti dàbí Rẹ̀ síi nípa pé a wá síbi ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò. Níbikíbi tí ẹ bá wà nínú ayé yí, kí Ọlọ́run bùkún fún yín. Kí Ẹ̀mí Olúwa wà pẹ̀lú wa. Njẹ́ kí a le ní ìmọ̀lára agbára ọ̀run bí a ti njọ́sìn papọ̀ nínú abala ti ìpàdé apapọ̀ yí.
Mo fi ẹ̀rí àti ìjẹ́rí mi sílẹ̀ fún yín pé mo mọ̀ pé Jésù ni Krístì. Òun ni Olùgbàlà wa, Olùràpadà wa. Òun ni ọ̀rẹ́ wa dídára jùlọ. Ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.