Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ẹ̀yin Arákùnrin àti Arábìnrin nínú Krístì
Ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò Oṣù Kẹ́wàá 2023


16:12

Ẹ̀yin Arákùnrin àti Arábìnrin nínú Krístì

Njẹ́ kí a gbádùn jíjẹ́ ìbátan ti ẹ̀mí tí ó wà ní àárín wa si kí a sì mọ iyì ìhùwàsí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti àwọn onírurú ẹ̀bùn tí a ní.

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, a ti ní àwọn abala ìyanu ìpàdé àpapọ̀ ní òní. Gbogbo wa ti ní ìmọ̀lára Ẹ̀mí Olúwa àti ìfẹ́ Rẹ̀ nípa àwọn ọ̀rọ̀ pípín nípasẹ̀ àwọn olórí wa. Mo ní ànfàní láti bá yín sọ̀rọ̀ ní ìrọ̀lẹ́ yí bí olùsọ̀rọ̀ ìparí ti abala yí. Mo gbàdúrà pé kí Ẹ̀mí Olúwa tẹ̀síwájú pẹ̀lú wa bí a ti nyayọ̀ papọ̀ bí arákùnrin àti arábìnrin òtítọ́ nínú Krístì.

Àyànfẹ́ wòlíì wa, Russell M. Nelson, kéde: “Ní òní mo pe àwọn ọmọ ìjọ̀ níbigbogbo láti jẹ́ àpẹrẹ nípa pípa àwọn ìwà àti ìṣe ẹ̀tànú ti. Mo bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú yín láti gbé ọ̀wọ̀ ga fún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run.”1 Bí ìjọ àgbáyé tí ó sì ndàgbà si, títẹ̀lé ìpè yí láti ẹnu wòlíì wa ni ohun àmúyẹ pàtàkì fún gbígbé ìjọba Olùgbàlà ga ní gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.

Ìhìnrere Jésù Krístì kọ́ni pé gbogbo wa jẹ́ ọmọbíbí ẹ̀mí ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin àwọn òbí ọ̀run tí wọ́n fẹ́ràn wa nítòótọ́2 àti pé a gbé bí ẹbí ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ṣíwájú kí a tó bí wa sí ilẹ̀ ayé yí. Ìhìbrere bákannáà kọ́ wa pé a dá gbogbo wa ní àwòrán àti ìwò Ọlọ́run.3 Nítorínáà, a dọ́gbà níwájú Rẹ̀,4 nítorí Òun “fi ẹ̀jẹ̀ kannáà dá gbogbo orílẹ̀-èdè lókùnrin [àti lóbìnrin].”5 Nítorínáà, gbogbo wa ní ìwà ẹ̀dá àtọ̀runwá, ogún, àti agbára, nítorí “Ọlọ́run kan àti Baba gbogbo, ẹni tí ó wà lórí gbogbo àti nípa gbogbo, àti nínú [wa] gbogbo.”6

Bí ọmọẹ̀hìn Jésù Krìstì, a pè wá láti mú ìgbàgbọ́ wa pọ̀ si nínú, àti ìfẹ́ fún, arákùnrin ti ẹ̀mí wa àti jíjẹ́ arábìnrin nípa síso ọkàn wa papọ̀ lódodo nínú ìrẹ́pọ̀ àti ìfẹ́, láìka àwọn ìyàtọ̀ wa sí, nípa èyí kí a mú okùn wa pọ̀ si láti gbé ọ̀wọ̀ ga fún ọlá ti gbogbo àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Ọlọ́run.7

Ṣé kìí ṣe èyí gangan ni ipò tí àwọn ènìyàn Néfì ní ìrírí rẹ̀ fún bíi sẹ́ntúrì méjì lẹ́hìn tí Krístì ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí wọn?

Àti pé dájúdájú kò sì sí irú àwọn ènìyàn tí ó láyọ̀ jù wọn lãrín gbogbo àwọn ènìyàn tí a ti ọwọ́ Ọlọ́run dá. …

“Bẹ̃ni kò sí ara Lámánì, tabi irúkìrú ẹlẹ́yàmẹ̀yà; ṣùgbọ́n wọn wà ní íṣọ̀kan, àwọn ọmọ Krístì, àti ajogún ìjọba Ọlọ́run.

“Bí wọ́n sì ti jẹ́ alábùkúnfún tó!”11

Ààrẹ Nelson tẹnumọ pàtàkì títan ọlá àti ọ̀wọ̀ ká fún àwọn ọmọlàkeji wa síwájú si nígbàtí ó wípé: “Aṣẹ̀dá gbogbo wa pe ẹnìkọ̀ọ̀kan wa láti pa àwọn ìwà ẹ̀tanú ti ní àtakò sí ẹgbẹ́kẹ́gbẹ́ àwọn ọmọ Ọlọ́run. Ẹnìkẹ́ni lára wa tí ó bá ní ẹ̀tanú sí ẹ̀yà míràn nílò ìrònúpìwàdà! … Ó yẹ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ṣe ohunkóhun tí a bá lè ṣe ní àyíká agbára wa láti tọ́jú ọlá àti ọ̀wọ̀ tí ó tọ́sí gbogbo ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Ọlọ́run.”9 Ní òdodo, ọlá ènìyàn ṣíwájú bíbọ̀wọ̀ fún àwọn ìyàtọ̀ wa.10

Ríronú ìsopọ̀ mímọ́ tí ó dà wá pọ̀ mọ́ Ọlọ́run bí àwọn ọmọ Rẹ̀, ìdarí ti wòlíì yí tí a fúnni nípasẹ̀ Ààrẹ Nelson làìṣiyèméjì ni ìpìlẹ̀ ìgbésẹ̀ síwájú kíkọ́ àwọn afárá níní òye sànju dídá àwọn ògiri ẹ̀tanú àti ìyapa sílẹ̀ ní àárín wa.11 Bákannáà, bí Paul ti kìlọ̀ fún áwọn ará Éfésù, a gbọ́dọ̀ damọ̀ pé ní èrò láti ṣe àṣeyege èrèdí yí, a ó nílò láti mú kí ìlàkàkà olúkúlùkù àti lápapọ̀ ṣe ìṣe pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀, ọkàn tútù, àti ìpamọ́ra ní ọ̀kan sí òmíràn.12

Ìtàn kan wà nípa ará Júù kan Rabbi ẹnití ò ngbádùn lílà-oòrùn pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ méjì. Ó bi wọ́n pé, “Báwo ni ẹ ó fi mọ ìgbàtí ilẹ̀ bá ṣú tán, tí ọjọ́ titun sì ti bẹ̀rẹ̀?”

Ọ̀kan lára wọn dáhùn pé, “Ìgbàtí o bá lè wo ilàoòrùn kí ó sì lè mọ ìyàtọ̀ ní àárín àgùtàn kan sí ewúrẹ́ kan.”

Òmírán fèsì lẹ́hìnnáà pé, “Ìgbàtí ó bá lè wo pípàdé náà kí o sì mọ ìyàtọ̀ ní àárín igi olífì kan sí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan.”

Nígbànnáà wọ́n yípadà sí rabbi ọlọ́gbọ́n wọ́n sì bèèrè ìbèèrè kannáà lọ́wọ́ rẹ̀. Lẹ́hín ìronú pípẹ́, ó dáhùn pé, “Ìgbàtí ẹ bá lè wo ìlàoòrùn kí ẹ sì rí ojú obìnrin kan tàbí ojú ọkùnrin kan kí ẹ sì wípé, ‘arábìnrin mi ni; arákùnrin mi ni.’”13

Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, mo lè fi dáa yín lójú pé ìmọ́lẹ̀ ọjọ́ titun kan ntàn dídán nínú ìgbé ayé wa nígbàtí a bá rí tí a sì tọ́jú àwọn ọmọlàkejì wa pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ọlá àti bí àwọn arákùnrin òtítọ́ nínú Krístì.

Nígbà iṣẹ́-ìránṣẹ́ ayé Rẹ̀, Jésù fi àpẹrẹ ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ jíjọnilójú yí hàn nítorí Ó “lọ káàkiri ní ṣíṣe rere ”14 sí gbogbo ènìyàn, ó npè wọ́n láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ kí wọ́n sì ṣe àbápín oore Rẹ̀, láìka ilẹ̀-ìbí wọn, ipò àwùjọ, tàbí àwọn ìwa ọlàjú sí. Ó ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́, ó wòsàn, ó sì nfetísí àìní gbogbo ènìyàn nígbàgbogbo, nípàtàkì àwọn wọnnì tí a kà sí ẹni ọ̀tọ̀, fojúparẹ́, tàbí pati. Kò sẹ́ ẹnikẹ́ni ṣùgbọ́n ó tọ́jú wọn pẹ̀lú ìṣedéédéé àti ìfẹ́, nítorí ó rí wọn bí arákùnrin àti arábìnrin Rẹ̀, ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ti Baba kannáà.15

Ọ̀kan lára ọ̀ràn wíwọnilọ́kàn jùlọ nígbàtí ó ṣẹlẹ̀ ni ìgbàtí Olùgbàlà rin ìrìnàjò lọ sí Galilee, ní èrèdí láti gba ọ̀nà èyítí ó lọ sí Samaria.16 Jésù nígbànáà pinnu láti joko ní ẹ̀bá kànga ti Jacob láti simi. Nígbàtí ó wà níbẹ̀, obìnrin ará Samaria kanwá láti pọn omi sínú ago rẹ̀. Nínú ọgbọ́n títóbijùlọ Rẹ̀, Jésù bá a sọ̀rọ̀, wípé, “Fún mi láti mu.”17

Ó ya obìnrin yí lẹ́nu pé Júù kan nbèèrè lọ́wọ́ obìnrin ará Samaria fún ìrànlọ́wọ́ ó sì fi ìyanu rẹ̀ hàn, ó wípé, “Ee tirí, tí ìwọ tíi ṣe Júù, fi nbèèrè ohun mímu lọ́wọ́ mi, emi ẹnití iṣe obìnrin ará Samaria? Nítorítí àwọn Júù kìí bá àwọn ará Samaria da nkan pọ̀.”18

Ṣùgbọ́n ó hàn pé Jésù, gbé ìrẹ̀wẹ̀sì Rẹ̀ sẹgbẹ kò sì ka àwọn àṣà dídìmú-ọjọ́ pípẹ́ ti ìríra ní àárín àwọn ará Samaria àti Júù, pẹ̀lú ìfẹ́ ó ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí obìnrin yí, ó ràn an lọ́wọ́ láti ní òye ẹnití Ó jẹ́ lotitọ, pé òun ni Messiah, ẹnití yíò sọ ohun gbogbo àti ẹnití ó ndúrò de bíbọ̀ rẹ̀.19 Ipa ti ìrọ̀rùn iṣẹ́ ìránṣẹ́ fà kí obìnrin náà sa lọ sínú ìlú láti kéde sí àwọn ènìyàn ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó wípé, “Èyí ha lè jẹ́ Krístì na?”20

Mo ní ìyọ́nú fún àwọn wọnnì tí a ti palára, fojúparẹ́, tàbí ṣe inúnibíni sí nípasẹ̀ àwọn ènìyàn ẹlẹ́tanu, nítorí, ní ìgbà ayé mi, mo ti rí ìrora tí àwọn ènìyàn rere njìyà lákọ́kọ́ látinú gbígba ìdájọ́ tàbí lé kúrò nítorí wọ́n níláti sọ̀rọ̀, wòó, tàbí gbé ìgbé ayé ọ̀tọ̀. Mo ní ìmọ̀lára ìbànújẹ́ nínú ọkàn mi fún àwọn wọnnì tí inú wọn dúró nínú òkùnkùn, tí àwọn ìran wọn wà ní ìdínkù, tí ọkàn wọn sì dúró ní líle nípa ìgbàgbọ́ nínú dídárajùlọ ara wọn àti àìdára ti àwọn wọnnì tí wọ́n yàtọ̀ sí wọn. Ìdínkù ìwò wọn nípa àwọn ẹlòmíràn ndínà agbára wọn lotitọ láti rí ẹni tí wọ́n jẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run.

Bí a ti sọtẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ àwọn wòlíì, à ngbé ní àwọn ọjọ́ ewu tí ó ndarí lọ sí Bíbọ̀ Ẹ̀ẹ̀kejì Olùgbàlà.21 Ayé lápapọ̀ ti di àríyànjiyàn nípa àwọn ìyapa líle, tí ẹléyàmẹ̀yà, òṣèlú, àti àwọn ìlà ọrọ̀-aje àwùjọ dá sílẹ̀. Irú àwọn ìyapa bẹ́ẹ̀ nígbàmíràn ní òpin nfún àwọn ènìyàn ní ipa ọ̀nà ríronú àti ṣíṣe ìṣé ní ìbámu sí wíwà ọmọlàkejì wọn. Fún èrèdí yí, kò jẹ́ àìwọ́pọ̀ láti rí àwọn ènìyàn tí wọ́n njúwe ọ̀nà ríronú, ṣíṣe ìṣe àti sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀làjú míràn, ẹ̀yà, àti àwọn ìran bí àìdára, ní mímú lò ìgbèrò, àṣìṣe, àti àwọn èrò ìpẹ̀gàn ìgbàkugbà, tí ó nmú àwọn ìwà ìrẹnisílẹ̀ jáde, àìnáání, àìlọ́wọ́, àní àti ẹ̀gàn ní àtakò sí wọn. Irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ ní ìtàkùn wọn nínú ìgbéraga, ìlara, àti owú jíjẹ́, ihùwàsí àdánidá ti ara,22 tí ó sì lòdì pátápátá sí àwọn ìwà Bíiti Krístì. Ìṣe yí kò tọ́ fún àwọn wọnnì tí wọ́n ntiraka láti di ọmọẹ̀hìn òtítọ́ Rẹ̀.23 Nítòótọ́, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, kò sí ibi kankan fún àwọn èrò ẹ̀gàn tàbí ìṣe nínú ìletò àwọn Ènìyàn Mímọ́.

Bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin májẹ̀mú, a lè ṣèrànwọ́ láti mú irú ìwà yí kúrò nípa wíwo àwọn ìyàtọ̀ híhàn tí ó wà ní àárín wa pẹ̀lú àwọn ojú Olùgbàlà24 àti dídá lórí ohun tí a ní papọ̀—ìdánimọ̀ tọ̀run àti jíjẹ́ ìbátan wa. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, a lè tiraka láti rí arawa ní ríronú lórí àwọn àlá, ìrètí, ìbànújẹ́, àti ìrora aladugbo wa. Gbogbo wa jẹ́ ẹlẹgbẹ arìnrìn àjò bí àwọn ọmọ Ọlọ́run, dídọ́gba nínú ipò àìpé àti nínú agbára wa láti dàgbà. A pè wá láti rìn papọ̀, pẹ̀lú àláfià, pẹ̀lú àwọn ọkàn tí ó kún fún ìfẹ́ síwájú Ọlọ́run àti sí gbogbo ènìyàn—tàbí, bí Abraham Lincoln ti ṣàkíyèsí, “Láìsí ìkùnsínú sí ẹnikẹ́ni àti ìfẹ́ àìlẹ́gbẹ́ fún ẹni gbogbo.”25

Njẹ ẹ ha ti jíròrò rí lórí bí a ti ṣe àpèjúwe ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ti ọ̀wọ̀ fún ọlá ènìyàn àti ìbádọ́gbà nípa ọ̀nà ìrọ̀rùn tí a fi ntún ilé Olúwa ṣe? Gbogbo wa nwá sí tẹ́mpìlì ní ìrẹ́pọ̀ nínú èrèdí kanṣoṣo àti ní kíkún fún ìfẹ́ láti jẹ́ mímọ́ àti àìlábàwọ́n ní iwájú mímọ́ Rẹ̀. Nínú ẹ̀wù funfun, gbogbo wa ni a gba láti ọwọ́ Olúwa Funrarẹ̀ bí àwọn àyànfẹ́ ọmọ, lọ́kùnrin àti lóbìnrin ti Ọlọ̀run, ìrandíran ti Krístì.26 A ní ànfàní láti ṣe irú àwọn ìlànà kannáà, dá àwọn májẹ̀mú kannáà, fi arawa sílẹ̀ sí gbígbé ìgbé ayé gígajùlọ àti mímọ́jùlọ, kí a sì gba irú àwọn ìlérí ayérayé kannáà. Ní ìrẹ́pọ̀ nínú èrèdí, a nrí ara wa pẹ̀lú àwọn ojú titun, àti nínú ìṣọ̀kan wa, a nṣe àjọyọ àwọn ìyàtọ̀ wa bí àwọn ọmọ àtọ̀runwá Ọlọ́run.

Láìpẹ́ mo ṣèrànwọ́ láti tọ́ àwọn ọlọ́lá àti òṣìṣẹ́ ìjọba sọ́nà nínú ilé ṣíṣí fún Tẹ́mpìlì Brasilia Brazil. Mo dúró díẹ̀ ní agbègbè ìyírapadà pẹ̀lú ààrẹ Brazil, a sì sọ̀rọ̀ ẹ̀wù funfun tí gbogbo ènìyàn nwọ nínú tẹ́mpìlì. Mo ṣe àlàyé fun un pé ìlò gbogbogbò ẹ̀wù funfun yí fihàn pé a jẹ́ ọ̀kannáà sí Ọlọ́run àti pé, nínú tẹ́mpìlì, àwọn ìdánimọ̀ wa kìí ṣe ìgbákejì ààrẹ orílẹ̀-èdè tàbí olórí ìjọ ṣùgbọ́n ó jẹ́ ìdánimọ̀ ayérayé wa bí àwọn ọmọ olùfẹ́ni Baba Ọ̀run.

Ìṣubú Iguaçú.

Omi Iguazu nṣàn ní apá gúsù Brazil ó sì ndà sínú plateau tí ó di ìṣètò ìṣubúomi tí a mọ̀ áàkiri aye bí àwọn ìṣubú Iguazu—ọ̀kan lára àwọn tó rẹwà jùlọ tí ó sì jẹ́ ìṣẹ̀dá ti Ọlọ́run tí ó wuni lórí ilẹ̀ ayé. Ìwọn Kọ́lọ́sà omi nṣàn sínú odò kan nígbànáà ó sì nya sọ́tọ́, ó ndì ọgọọgọrun àwọn ìṣubú omi tí kò lẹ́gbẹ́. Ní sísọ́rọ́ ìjúwe, ètò ìyanilẹ́nu ti àwọn ìṣubúomi yí ni ìfihàn ẹbí ti Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé, nítorí a pín irú ohun èlò àti ilẹ̀-ìbí ti ẹ̀mí kannáà, tí a gbà látinú ogun tọ̀run àti jíjẹ́ ìbátan wa, Bákannáà, ọ̀kọ̀ọ̀kan wa nṣàn nínú àwọn ọ̀làjú, ìran, àti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, pẹ̀lú ìmọ̀-ènìyàn, ìrirì, àti ìmọ̀lára ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Pẹ̀lú èyí, a tẹ̀ síwájú, bí àwọn ọmọ Ọlọ́run àti bí àwọn arákùnrin àti arábìnrin nínú Krístì, láì sọ ìsopọ̀ ti ọ̀run wa nù, èyí tí ó mú wa jẹ́ àìláfiwé ènìyàn àti olólùfẹ́ ìletò.27

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́, njẹ́ kí ọkàn àti inú wa wà ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ àti ẹ̀rí pé gbogbo wa baradọ́gba níwájú Ọlọ́run, pé gbogbo wa gba irú agbára ayérayé àti ogún kannáà ní kíkún. Njẹ́ kí a gbádùn jíjẹ́ ìbátan ti ẹ̀mí tí ó wà ní àárín wa si kí a sì mọ iyì ìhùwàsí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti àwọn onírurú ẹ̀bùn tí a ní. Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, mo ṣe ìlérí fún yín pé a ó ṣàn ní ọ̀nà ara wa, bí omi Ìṣubú Iguazu, láìsí sísọ ìsopọ̀ tọ̀run tí ó nfi wá hàn bí àwọn ènìyàn títayọ nù, “àwọn ọmọ Krístì, àti ajogún sí ìjọba Ọlọ́run.”28

Mo jẹ́ ẹ̀rí sí yín pé bí a ti ntẹ̀síwájú láti ṣàn ní ọ̀nà yí nínú ìgbé-ayé ikú wa, ọjọ́ titun yíò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ titun tí yíò tàn sí ìgbé-ayé wa tí yíò si tànná ànfàní ìyanu láti fi iyì si, àti láti di alábùkún kíkún si nípa, oríṣiríṣi tí a dá sílẹ̀ nípasẹ̀ Ọlọ́run ní àárín àwọn ọmọ Rẹ̀.29 Dájúdájú a ó di àwọn ohun èlò ní ọwọ́ Rẹ̀ láti gbé ọ̀wọ̀ àti ọlá ga ní àárín gbogbo àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Rẹ̀. Ọlọ́run wà láàyè! Jésù ni Olùgbàlà aráyé. Ààrẹ Nelson ni wòlíì Ọlọ́run ní ọjọ́ wa. Mo jẹ́ri àwọn òtítọ́ wọ̀nyí ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.