Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ìtàn Ọdún Àjínde Títóbijùlọ Tí A Ti Sọ Rí
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2023


Ìtàn Ọdún Àjínde Títóbijùlọ Tí A Ti Sọ Rí

Ẹ wo Ìwé ti Mọ́mọ́nì nínú ìmọ́lẹ̀ titun kí ẹ sì gbèrò ẹ̀rí ìjìnlẹ̀ tí ó njẹ nípa òdodo Krístì tó jínde.

Lẹ́tà Àjọ Ààrẹ Ìkínní ní Ọdún Àjínde

Bóyá ẹ lè rántí gbígbọ́ lẹ́tà kan látọ̀dọ̀ Àjọ Ààrẹ Ìkínní tí a kà nínú wọ́ọ̀dù tàbí ẹ̀ká ní àpọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀sẹ̀ sẹ́hìn. Lẹ́tà náà kéde pé ní Ọjọ́ ìsìnmi tí ó nbọ̀—Ọjọ́ Ìsinmi Ọdún Àjínde—gbogbo àwọn wọ́ọ̀dù àti ẹ̀ká níláti pàdé fún ìpàdé oúnjẹ Olúwa nìkan, fífi àfikún àkokò sílẹ̀ fún ìjọ́sìn ní ilé bí àwọn ẹbí láti ṣe ayẹyẹ ìsinmi pàtàkì jùlọ yí.1

Lẹ́tà Àjọ Ààrẹ Ìkínní gba ìfojúsí mi, àti pé ó fa ríronú mi lórí ọ̀nà tí ẹbí wa fi nṣe ayẹyẹ Ọdún Àjínde láti àwọn ọdún sẹ́hìn. Bí mo ti nronú nípa àwọn ayẹyẹ wa si, ni mò nrí ara mi si rírò ó bí a bá nfi àìfiyèsí dín ìtumọ̀ òtítọ́ kù nípa ìsinmi yí, ní gbùngbun sí gbogbo àwọn onígbàgbọ́ nínú Jésù Krístì.

Àwọn Àṣà Kérésìmesì àti Ọdun Àjínde

Àwọn èrò wọnnì darí mi láti jíròrò ìyàtọ̀ ní àárín ọ̀nà tí a fi nṣe ayẹyẹ Kérésìmesì bí a ti fi wé Ọdún Àjínde. Ní Oṣù Kejìlá, báknanáà a gbìyànjú láti fi ìṣeré “Lílu Aago,” ìbọ̀sẹ̀ Kérésìmesì, àti àwọn ẹ̀bùn lẹgbẹ òmíràn, àwọn àṣà aláròjinlẹ̀—bí irú ìtọ́jú fún àwọn wọnnì nínú àìní, kíkọ àwọn orin ìyìn àti dídùn Kérésìmesì, àti pé bẹ́ẹ̀ni ṣíṣí àwọn ìwé mímọ́ àti kíka ìtàn ní Kérésìmesì ní Luku 2. Ọdọọdún bí a ti nka ìtàn látinú Bíbélì títóbi àtijọ́, bóyá ẹbí wa nṣe ohun tí ẹbí yín nṣe—wọṣọ pẹ̀lú táwẹ̀lì ní orí wa àti èjìká àti fífúnni ní àwọn aṣọ-ìwẹ́ láti rọ́pò Joseph, Mary, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹnití wọ́n wá láti jọ́sin Jésù ọmọ-ọwọ́, a tún fi ìṣúra ìtàn Kérésìmesì lélẹ̀ nípa ìbí Olùgbàlà.

Àwọn ayẹyẹ ẹbí wa ní Ọdún Àjínde, bákannáà, ti ní ìyàtọ̀ díẹ̀. Mo rò pé ẹbí wa ti gbáralé “lílọ sí ilé ìjọsìn” láti pèsè ara gbùngbun-Krístì Ọdún Àjínde, onítumọ̀; àti nígbànáà bí ẹbí, a níláti kórajọ láti pín nínú àwọn àṣà tó ní í ṣe sí Ọdún Àjínde. Mo ti fẹ́ràn wíwo àwọn ọmọ wa àti pé nísisìyí àwọn ọmọ-ọmọ wa nṣọdẹ fún àwọn ẹyin Ọdún Àjínde kí a sì wo inú àwọn apẹ̀rẹ̀ Ọdún Àjínde.

Ṣùgbọ́n lẹ́ta Àjọ Ààrẹ Ìkínní jẹ́ ìpè ìtanijí kan. Kìí ṣe pé wọ́n pè gbogbo wá láti mu dájú pé ayẹyẹ wa jẹ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì jùlọ ti ó ṣẹlẹ̀ rí lórí ilẹ̀ ayé—Ètùtù àti Àjínde Jésù Krístì—pẹ̀lú ọ̀wọ̀ àti ọlá tí ó tọ́ sí Olúwa, ṣùgbọ́n bákannáà wọ́n fún wa ní àkokò síi pẹ̀lú àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ ní Ọjọ́ Ìsinmi Ọdún Àjínde láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Àwòrán
Olùjínde Olùgbàlà

Àwọn ọ̀rọ̀ Wòlíì Joseph Smith wọ̀nyí fi ọ̀rọ̀ àgikún sí pàtàkì ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí ó yí Ọdún Àjínde ka: “Àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ ẹ̀sìn wa jẹ́ ẹ̀rí àwọn Àpóstélì àti Wòlíì, nípa Jésù Krístì, pé Ó kú, a sì sín, ó jí dìde ní ọjọ́ kẹ́ta, ó sì gòkè re ọ̀run; àti pé ohun gbogbo míràn èyí tí ó dálé ẹ̀sìn wa jẹ́ ìsomọ́ sí i lásán ni.”2

Lesa àti èmi ti sọ àwọn ọ̀nà tí ẹbí wa fi lè ṣe dáradara si ní àkokò ìgbà Ọdún Àjínde. Bóyá ìbèerè tí a ti bi ara wa ni ọ̀kan tí a lè gbèrò: pé báwo ni a ṣe lè ṣe àwóṣe ìkọ́ni àti ayẹyẹ Àjínde Jésù Krístì, ìtàn Ọdún Àjínde, pẹ̀lú irú ìbámu, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ kannáà, àti àṣà ẹ̀sìn ọlọ́rọ̀ ti ìbí Jésù Krístì, ìtàn Kérésìmesì?

Ó dàbí pé gbogbo wa ngbìyànjú. Mo ṣe àkíyèsí ìdàgbà ìtiraka ní àárín àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn síwájú Ọdún Àjínde tí ó wà ní gbùngbun-Krístì si. Èyí pẹ̀lú ìdámọ̀ nlá àti àròjinlẹ̀ Ọjọ́ Ìsinmi Ọ̀pẹ àti Jímọ̀ Rere bí a ti nṣe nípa àwọn ará Krìsténi wa. Bákannáà a lè gba àwọn àṣà Ọdún Àjínde títọ́ gbùngbun-Krístì tí a rí nínú àwọn ìṣe àti ọ̀làjú ti àwọn orílẹ̀-èdè káàkiri ayé.

Ọ̀kàwé Májẹ̀mú Titun N. T. Wright dábá pé: “A níláti gbé àwọn ìgbésẹ̀ láti ṣe ayẹyẹ Ọdún Àjínde ní àwọn ọ̀nà àtinúdá titun: ní iṣẹ́-ọ̀nà, ìwé, àwọn ìṣere ọmọdé, ewì, orin, ijó, àwọn àjọ̀dún, aago, àjọyọ̀ orin. … Èyí ni àjọyọ̀ títóbí jùlọ wa. Ẹ mú Kérésìmesì kúrò, àti nínú àwọn ọ̀ràn ti bíbélì ẹ ó sọ àwọn orí méjì nù ní iwájú Matteu àti Luku, kò sí ohunkóhun míràn. Ẹ mú Ọdún Àjínde kúrò, ẹ kò sì ní ní Májẹ̀mú Titun; ẹ kò ní krìstẹ́nì kankan.”3

Ọdún Àjínde, Bíbélì, àti Ìwé ti Mọ́mọ́nì

A ṣìkẹ́ Bíbélì fún gbogbo ohun tí ó kọ́ wa nípa ìbí, iṣẹ́ ìránṣẹ́, ìkànmọ́-àgbélèbú, àti Àjínde Jésù Krístì. Kò sí àwọn ọ̀rọ̀ mẹ́ta tó kó àyọrísí ìrètí àti ayérayé pọ̀ fún gbogbo ènìyàn ju àwọn wọnnì tí a sọ nípasẹ̀ àngẹ́lì tọ̀run ní òwúrọ̀ Ọdún Àjínde ní Ọgbà Isà-òkú: “Ó Jí Dìde.”4 A fi ìmoore jíjinlẹ̀ hàn fún ìwé mímọ́ Májẹ̀mú Titun tí ó pa ìtàn Ọdún Àjínde mọ́ àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ Ọdún Àjínde Olùgbàlà ní Judea àti Galilee.

Bí Lesa àti èmi ti tẹ̀síwájú láti jíròrò àti láti wá àwọn ọ̀nà láti mú ayẹyẹ Ọdún Àjínde ẹbí wa gbòòrò láti wà ní gbùngbun-Krístì, a sọ̀rọ̀ ohun tí àṣà kíka ìwé mímọ́ tí a lè fi hàn sí ẹbí wa—tí ó ṣe Luku 2 déédé fún Ọdún Àjínde tí ẹ bá fẹ́.

Àti nígbànáà a ní fìfihàn tọ̀run yí: Ní àfikún sí àwọn ẹsẹ pàtàkì nípa Ọdún Àjínde nínú Májẹ̀mú Titun, àwa bí Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ni a fún ní ẹ̀bùn pẹ̀lú Ọdún Àjínde olókìkí jùlọ. Ẹ̀bùn kan nípa ẹ̀rí àìláfiwé, ẹ̀rí míràn nípa iṣẹ́ ìyànu Ọdún Àjínde bóyá, tí ó ní, àwọn ìwé mímọ́ Ọdún Àjínde ọlọ́lá nínú ní gbogbo Krìtẹ́nì. Bẹ́ẹ̀ni èmì ntọ́ka sí Ìwé ti Mọ́mọ́nì, àti nípàtàkì si, sí àkọsílẹ̀ Jésù Krístì tí ó nfi ara hàn sí àwọn olùgbé nínú Ayé Titun nínú àjínde ológo Rẹ̀.

Wòlí Joseph Smith júwe Ìwé ti Mọ́mọ́nì bí “ìwé tí ó tọ́ jùlọ nínú eyikeyi,”5 àti bíbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú 3 Nefi 11, ó sọ ìtàn títóbi ti ìbẹ̀wò Krístì tó jínde sí àwọn ará Nefi, iṣẹ́ ìránṣẹ́ Ọdún Àjínde ti Olùgbàlà. Àwọn iwé mímọ́ Ọdún Àjínde wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀rí àkọsílẹ̀ Àjínde Olúwa Jésù Krístì.

Nínú àwọn orí wọ̀nyí, Krístì pe àwọn Àpóstélì Méjìlá, ó kọ́ni bí Ó ti ṣe nínú Ìwàásù Rẹ̀ ní orí Òkè, ó kéde pé Òun ti mú òfin Mósè ṣẹ, àti àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa kíkójọ Ísráẹ́lì ní ọjọ́-ìkẹhìn. Ó wo aláìsàn sàn ó sì gbàdúrà fún àwọn ènìyàn ní irú ọ̀nà ológo tí “kò sì sí ahọ́n tí ó lè sọọ́, tàbí kí ẹnìkẹ́ni ó lè kọọ́, tàbí kí ọkàn ẹnìkẹ́ni ó lè ròo nípa àwọn ohun nlá àti ohun ìyanu bí àwa ti ríi àti tí a gbọ́ tí Jésù sọ; kò sì sí ẹnìkẹ́nì tí ó lè mọ̀ irú ayọ̀ tí ó kún ọkàn wa ní àkokò tí àwa gbọ́ọ tí ó gbàdúrà sí Bàbá fún wa.”6

Àwòrán
Jésù Krístì Farahàn sí àwọn Ará Néfì

Ní Ọdún Àjínde yí, ẹbí wa máa dojúkọ àwọn ẹsẹ mẹ́tàdínlógún àkọ́kọ́ àwọn ẹsẹ mẹ́tàdínlógún àkọ́kọ́ ti 3 Nefi 11, pẹ̀lú èyí tí ẹ faramọ́. Ẹ rántí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn nlá tí wọ́n yí tẹ́mpìlì ká ní ilẹ̀ Ọ̀pọ̀ tí wọ́n gbọ́ ohun Ọlọ́run Baba tí wọ́n sì rí Jésù Krístì tí ó nsọ̀kalẹ̀ jáde ní ọ̀run láti nà ìpè Ọdún Àjínde dídára jùlọ.

“Ẹ dìde kí ẹ sì wá sí ọ́dọ̀ mi, … kí ẹ̀yin ó lè fi ọwọ́ yín sí ìhà mi, àti kí ẹ̀yin ó lè fi ọwọ́ yín sí ojú àpá ìṣó ni ọwọ́ àti ẹsẹ̀ mi, kí ẹ̀yin ó lè mọ̀ wípé èmi ni … Ọlọ́run ti gbogbo ilẹ̀ ayé, ti a sì pa fún ẹ̀ṣẹ̀ aráyé.

“Àti pé … àwọn ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn lọ síwájú, … ní ọ̀kọ̀ọ̀kan … tí a sì rí pẹ̀lú ojú wa tí wọ́n sì ní ìmọ̀lára rẹ̀ pẹ̀lú ọwọ́ wọn, … a sì jẹri àkọsílẹ̀, pé oun ni, …

“Wọ́n … sì kígbe jáde pẹ̀lú ohùn kan, wọ́n wípé:

“Hòsánnà! Ìbùkún ni fún orúkọ Ọlọ́run Ẹnití-Ó-Gá-Jùlọ! Wọ́n sì wólẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ Jésù, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un.”7

Ro, àwọn ará Néfì ní Tẹ́mpìlì fọwọ́kan ọwọ́ Olúwa tó jínde lódodo! A ní ìrètí láti mú kí àwọn orí wọ̀nyí nínú 3 Nefi bí apákan àṣà Ọdún Àjínde wa bí ó ti Luku 2 jẹ́ ti àṣà Kérésìmesì wa. Ní òdodo, Ìwé ti Mọ́mọ́nì pín ìtàn Ọdún Àjínde títóbí jùlọ tí a ti sọ rí. Ẹ máṣe jẹ́ kí ó jẹ́ Ọdún Àjínde títóbi jùlọ tí a sọ rí.

Ṣùgbọ́n mo pè yín láti wo Ìwé ti Mọ́mọ́nì nínú ìmọ́lẹ̀ titun kí a sì ro ẹ̀rí ìjìnlẹ̀ tí ó jẹ́ nípa òdodo Krístì tó jínde bákannáà bí ìjìnlẹ̀ ọrọ̀ ẹ̀kọ́ Krístì.

Ìwé ti Mọ́mọ́nì jẹ́ ẹ̀rí mĩràn nípa Jésù Krístì.

A lè bèèrè, Báwo ni kíka àwọn ìwé mímọ́ Ìwé ti Mọ́mọ́nì ní Ọdún Àjínde fi lè bùkún ayé wa àti àwọn wọnnì lára olùfẹ́ni wa ní ọ̀nà onítumọ̀? Jiju ẹyọkan lè damọ̀. Ìgbàkugbà tí a bá ka tí a sì ṣe àṣàrò látinú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, a lè retí àbájáde tó lápẹrẹ.

Láìpẹ́, Lesa àti èmi lọ wo ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n kan, obìnrin onígbàgbọ́ ẹnití ìgbé ayé rẹ ké kúrú nípa àìsàn. A kórajọ pẹ̀lú ẹbí rẹ̀ àti ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, ní ìpàṣípààrọ̀ àwọn ìrántí dídún nípa ẹ̀mí dídára yí tí wọ́n ti bùkún ayé wa.

Nígbàtí a ṣi ndúró lọ́nà jíjìnnà kúrò nibi pósí, ní bíbá àwọn míràn sọ̀rọ̀, mo ṣe àkíyèsí àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ọjọ́ orí Alakọbẹrẹ méjì tí wọ́n dé bi pósí wọ́n sì na ìkórí ọmọ ẹsẹ̀ sókè—ojú wọn sì ndé etí rẹ̀—láti san ìbọ̀wọ̀fún ìgbẹ̀hìn wọn sí àyànfẹ́ àùntí wọn. Làìsí ẹlòmíràn nítòsí, Lesa ṣubú ó sì dáwó sí ẹ̀gbẹ́ wọn láti fún wọn ní ìtùnú àti ìkọ́ni. Ó bèèrè bí wọ́n ti nṣe sí àti bóyá wọ́n mọ ibi tí auntí wọn wà bayi. Wọ́n ṣe alábápín ìbànújẹ́ wọn, ṣùgbọ́n nígbànáà àwọn ọmọbìnrin iyebíye Ọlọ́run wọ̀nyí, pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé tí ó ntàn nínú ojú wọn, wọ́n wípé wọ́n mọ̀ pé inú auntí wọn dùn bayi àti pé ó le wà pẹ̀lú Jésù.

Ní ọjọ́ orí kékeré yín, wọ́n rí àláfíà nínú ètò ìdùnnú nlá àti pé, nínú ọ̀nà èwe ti ara wọn, wọ́n jẹri òdodo ìjìnlẹ̀ àti ẹwà ìrọ̀rùn Àjínde Olùgbàlà. Wọ́n mọ èyí nínú ọkàn wọn nítorí àwọn ìkọ́ni àròjinlẹ̀ àwọn òbí olùfẹ́ni, ẹbí, àti àwọn olórí Alakọbẹrẹ tí wọ́n gbin èso ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì àti ìyè ayérayé. Wọ́n gbọ́n kọjá ọjọ́ orí wọn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òtítọ́ wọ̀nyí tí àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ní òyè wá sí wọn nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ Ọdún Àjínde àti iṣẹ́ ìránṣẹ́ olùjínde Olùgbàlà àti ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì bí a ti sọ́ nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì.

Mo ti ṣe àkíyèsí pé nígbàtí Ààrẹ Russell M. Nelson fúnni ní ẹ̀bùn Ìwé ti Mọ́mọ́nì sí ẹnìkan tí kìí ṣe ìgbàgbọ́ wa, pẹ̀lú àwọn olórí ayé, nígb`akugbà tí ó bá yí sí 3 Néfì àti kíkà nípa ìfarahàn ti Krístì tó jínde sí àwọn ará Néfì. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wòlíì alààyè ní àkótán njẹ́ ẹ̀rí nípa Krístì alààyè.

A kò lè dúró bí ẹlẹri Jésù Krístì títí a lè fi jẹ́ ẹ̀rí nípa Rẹ̀. Ìwé ti Mọ́mọ́nì ni ẹ̀rí míràn ti Jésù Krístì nítorí nínú gbogbo àwọn ojú ewé mímọ́, wòlíì kan lẹ́hìn òmíràn jẹ́ ẹ̀rí kìí ṣe pé Krístì yíò wá nìkan, ṣùgbọ́n pé Òun ti wá.

Nítorí Tirẹ̀

Èmi di ẹ̀dà àtẹ̀jáde àkọ́kọ́ Ìwé ti Mọ́mọ́nì kan mú ní ọwọ́ mi. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ nígbàgbogbo ntì mi. Nítorí ọ̀pọ̀ ìgbé ayé àgbà mi, ti fanimọ́ra, dídìmú, àti rírọ̀mọ́ ohun tí ọ̀dọ́mọkunrin Joseph Smith ṣe láti gba ìwé ọ̀wọ̀ ti ìwé mímọ́ tí a yírọ̀ rẹ padà tí a sì tẹ̀ jáde. Àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó níláti ṣẹlẹ̀ jẹ́ tàgétàgé láti rò.

Ṣùgbọ́n ìyẹ̀n kìí ṣe ìdí tí ìwé yí fi ntì mí. Ó jẹ́ nítorí ìwé yí, ju òmíràn kankan tí a ti tẹ̀ jáde rí ní orí ilẹ̀ ayé, jẹ́ ẹ̀rí ìgbé ayé, iṣẹ́ ìránṣẹ́, àwọn ìkọ́ni, Ètùtù, àti Àjínde Jésù Krístì. Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ṣíṣe àṣàrò déédé látinú ìwé nípa Jésù Krístì yíò yí wa padà. Yíò ṣí ojú yín sí àwọn ìṣeéṣe titun nínú ayé yín. Yíò mú ìrètí yín pọ̀ si yíò sì kún inú yín pẹ̀lú ifẹ́ àìlẹ́gbẹ́. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, yíò gbéga yíò sì fi okun fún ìgbàgbọ́ yín nínú Jésù Krístì yíò sì bùkún yín pẹ̀lú ìmọ̀ dídájú pé Òun àti Baba wa mọ̀ yín, ó sì fẹ́ kí ẹ wá ọ̀nà yín padà sí ilé, pẹ̀lú ọ̀rọ̀ nlá kan H.

Arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, ìgbà náà tí tó, tí àwọn wòlíì àtijọ́ sọtẹ́lẹ̀, “nígbàtí ìmọ̀ Olùgbàlà yíò tàn káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè, àti ènìyàn.”8 Àwa nrí ìmúṣẹ ti àsọtẹ́lẹ̀ yí ní ojú wa gan, nípasẹ̀ ẹ̀rí Jésù Krístì nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì.

Àwòrán
Olúwa Jésù Krístì wípé:

Kò sí ìwé tí ó fi èyí hàn:

  • Nítorí Jésù Krístì, ohun gbogbo ti yípadà.

  • Nítorí Rẹ̀, ohun gbogbo ti dára si.

  • Nítorí Rẹ̀, ìgbé ayé ti ṣeéṣe—nípàtàkì àwọn àkokò ìrora.

  • Nítorí Rẹ̀, ohun gbogbo ti ṣeéṣe.

Ó ṣèbẹ̀wò bí Olùgbàlà tó jínde, tí a fihàn nípasẹ̀ Ọlọ́run Baba, nínú ọ̀rọ̀ ológo àti ìṣẹ́gun jùlọ Ọdún Àjínde. Yíò ran àwọn ọmọ ẹbí wa lọ́wọ́ láti jèrè ẹ̀rí araẹni nípa Jésù Krístì bí Olùgbàlà àti Olùràpadà wa, ẹnití ó já ìdè ikú.

Mo parí pẹ̀lú ẹ̀rí mi nípa ti òtítọ́ Ìwé ti Mọ́mọ́nì àti nípa Jésù Krístì bí Ọmọ Ọlọ́run alààyè. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Wo Lẹ́tà Àjọ Ààrẹ Ìkínní, Ọjọ Mẹẹdógún Oṣù Keji, 2023

  2. Àwọn Ìkọ́ni ti Àwọn Ààre ti Ìjọ: Joseph Smith (2007), 49; àfikún àtẹnumọ́.

  3. N. T. Wright, Surprised by Hope: Rethinking Heaven, the Resurrection, and the Mission of the Church (2008), 256.

  4. Matteu 28:6.

  5. Àwọn Ìkọ́ni: Joseph Smith, 64.

  6. 3 Néfì 17:17.

  7. Wo 3 Nefi 11:1–7.

  8. Mòsíàh 3:20.

Tẹ̀