Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Dídúró Bíiti Krístì
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2023


11:17

Dídúró Bíiti Krístì

“Ó sì jí, ó bá afẹ́fẹ́ ná wí, ó sì wí fún òkun pé, Dákẹ́, jẹ́. Afẹ́fẹ́ sì dá, ìparọ́rọ́ nlá sì dé” (Mark 4:39).

Ìgbà tí mo sọ̀rọ̀ kẹ́hìn nínú ìpàdé àpapọ̀, ọkọ-ọmọ-mi Ryan fi mí àtẹ̀kọ kan hàn mí tó wípé, “Nítòótọ́? Orukọ ọkùnrin náà ni Bragg”—tó túmọ̀sí “láti yangàn”—“òun kìí sọ̀rọ̀ nípa ìrẹ̀lẹ̀ ni? Irú òfò kan!” Pẹ̀lú ìbànújẹ́, ìjákulẹ̀ ntẹ̀síwájú.

Don Bragg bí olùgbá bọ́ọ̀lù àfọwọ́gbá kan.

Baba mi oníyanu ni olùṣèré bọ́ọ̀lù àfọwọ́gbọ́ ti Gbogbo-America fún UCLA lábẹ́ Aláròsọ Adarí John Wooden. Wọ́n wà tímọ́tímọ́ ní gbogbo ọjọ́ ayé baba mi, ati pé nígbà kọ̀ọ̀kan, Adarí àti Abilékọ. Wooden yíò wá sí ilé wa fún oúnjẹ alẹ́. Inú rẹ̀ máa ndùn ní gbogbo ìgbà láti bá mi sọ̀rọ̀ nípa bọ́ọ̀lù àfọwọ́gbá tàbí ohunkóhun míràn ní inú mi. Nígbàkan mo bi í léérè irú ìmọ̀ràn tí ó ní fún mi bí mo ti wọ ọdún àgbà ní ilé ìwé gíga mi. Nígbàgbogbo olùkọ́ni, ó wípé, “Baba rẹ wí fún mi pé o ti darapọ̀ mọ́ Ìjọ ti Jésù Krísti nítorìnáà mo mọ̀ pé o ní ìgbàgbọ́ nínú Olúwa. Pẹ̀lú ìgbàgbọ́ náà rii dájú láti dúró nínú gbogbo ipò. Jẹ́ ẹni rere nínú ìjì.”

Ní àwọn ọdún sẹ́hìn, ìbánisọ̀rọ̀ náà ti lẹ̀ mọ́ mí. Ìmọ̀ràn náà láti wà jẹ́jẹ́, parọ́rọ́, àti gbáradì ní gbogbo ipò, nípàtàkì ní àwọn ìgba ìpọ́njú àti ìtẹ̀mọ́lẹ̀, ti níbámu pẹ̀lú mi. Mo lè rí bí àwọn ẹgbẹ́ Adarí eré Wooden ti ṣeré pẹ̀lú ìdúró àti àṣeyege nlá tí wọ́n ní ìrírí ní bíborí ere-ìdíje gbogbogbo kẹwa.

Ṣùgbọ́n a kò sọ̀rọ̀ nípa dídúró ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí àti pé tí à ndáṣe àní díẹ̀ nínú àwọn ìgbà ewu àti pípínyà. A máà ntọ́ka si nínú eré-ìdárayá—pé olùṣere kan pẹ̀lu dídúró ní sísúnmọ́ ìparí, tàbí tí ẹgbẹ́ kan ṣí nítorí àìní ìdúró. Ìwà ìyanu yí lọ kọjá àwọn eré ìdárayá. Ìdúró ní ìlò gbígbòòrò púpọ̀ kan sí ìgbé ayé ó sì lè bùkún àwọn òbí, olórí, ìránṣẹ́ ìhìnrere, olùkọ́, akẹkọ, àti gbogbo ènìyàn míràn tí wọ́n nkojú ìjì ayé.

Ìdúró ti ẹ̀mí nbùkún wa láti dúró jẹ́jẹ́ kí a sì ní ifojúsùn lórí ohun tí ó pọndandan jùlọ, nípàtàkì nígbàtí a wà lábẹ́ ìtẹ̀mọ́lẹ̀. Ààrẹ Hugh B. Brown kọni pé, “Ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti nínú ìṣẹ́gun ìgbẹ̀hìn ti ẹ̀tọ́ ndásí ìlera ọpọlọ àti ìdúró ti ẹ̀mí ní àkokò àwọn ìṣòro.”1

Ààrẹ Russell M. Nelson ni àpẹrẹ ìyanu ti ẹ̀mí ìdúró. Ìgbà kan, nígbàtí Dókítà-ìgbànáà. Nelson nígbàtí ó nṣe iṣẹ́ abẹ iṣan-àlọ̀ ọkàn mẹ́rin, ìfúnpá aláìsàn náà dédé wálẹ̀. Dókíta Nelson fi jẹ́jẹ́ wo ipò náà ó sì ri pé ọmọ ẹgbẹ́ kan ti ṣèèsì yọ ìdìmú kan lójijì. A rọ́pò rẹ̀ kíákíá, àti pé Dókítà. Nelson tu ọmọ ẹgbẹ́ nínú, ó wípé, “mo ṣì fẹ́ràn rẹ,” lẹ́hìnnáà ọ sọ pẹ̀lú ẹ̀fẹ̀ pé, “Nígbàmíràn mo fẹ́ràn yín ju àwọn ìgbà míràn!” Ó fi hàn bí a ṣe níláti ṣe pàjáwìrì—pẹ̀lú ìdúro, ní fífojúsùn lórí ohun tó pọndandan jùlọ—yíyanjú pàjáwìrì náà. Ààrẹ Nelson wípé, “Ó jẹ́ ọ̀ràn ìkoraẹni-níjanu gidigidi. Àdẹ̀hìnbọ̀ ìwà yín ó jẹ, , ‘Mú mi jáde, adarí! Mo fẹ́ lọ sílé.’ Ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀ni ẹ kò lè ṣé. Ẹmí kan gbáralé gbogbo ẹgbẹ́ oníṣẹ́ abẹ pátápátá. Nítorínáà ẹ níláti dúró jẹ́jẹ́ kí ẹ sì parọ́rọ́ kí ẹ gbọ́nféfé bí ẹ tì máa nwà rí. ”2

Bẹ́ẹ̀ni, Olùgbàlà ni àpẹrẹ ìgbẹ̀hìn ti ìdúró.

Nínú Ọgbà Gẹ́tsémánì, nínú ìrora àìlèrò, bí “ó ti nlààgùn tí ó dàbí ìsun ẹ̀jẹ̀ nlá,”3 O fi àpẹrẹ ìdúró àtọ̀runwá pẹ̀lú ìsọ̀rọ̀ ọlọ́lá jẹ́jẹ́ hàn pé, “Kìí ṣe ìfẹ́ tèmi, ṣùgbọ́n tìrẹ, ni ká ṣe.”4 Lábẹ́ ìtẹ̀mọ́lẹ̀ líle láti mú ìgbàlà gbogbo ènìyàn ṣeéṣe, Jésù ti júwe àwọn ipò mẹta pàtàkì tí ó nràn wá lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ ìdúró títóbi Rẹ̀. Àkọ́kọ́, Ó mọ ẹnití Òun jẹ́ ó sì jẹ́ òtítọ́ sí iṣẹ́ ìhìnrere àtọ̀runwá Rẹ̀. Títẹ̀le, Ó mọ̀ pé ètò nlá ti ìdùnnú kan wà. Àti nígbẹ̀hìn, Ó mọ̀ pé nípasẹ̀ Ètùtù àìlópin Rẹ̀ pé, gbogbo ẹni tí ó bá fi òtítọ́ wé ara wọn mọ́ Ọ nípa dídá àti pípa àwọn májẹ̀mú mímọ́ mọ́ nípasẹ̀ àwọn ìlànà oyè-àlùfáà yíò ní ìgbàlà, bí a ti kọ́ni dáradára láti ọwọ́ Alàgbà Dale G. Relund ní òní.

Láti lòdìsí ìyàtọ̀ ní àárín sísọnù àti mímúdúró ìdúró, ronú nípa ohun tí ó ṣẹlẹ̀ bí Krístì àti àwọn Àpóstélì Rẹ̀ ti fi Ọgbà Gẹ́tsémánì sílẹ̀. Nígbàtí a kojú wọn nípa àwọn ológun láti mú Jésù, àdẹ̀hìnbọ̀ Pétérù ni láti sọ ìdúró rẹ̀ nù tí ó sì pariwo pẹ̀lú ìtara nípa gígé etí ìránṣẹ́ àlùfáà gíga kan, Malchus kúrò. Àdẹ̀hìnbọ̀ ti Jésù Krístì, ní ọ̀nà míràn, ni láti pa ìdúró Rẹ̀ mọ́ kí ó sì mú ipò tì ò le kàn wálẹ̀ nípa ìwòsàn Malchus.

Àti fún àwọn kan lára wa tí wọ́n nlàkàkà pẹ̀lú mímú ìdúró wa dúró àti pé bóyá a ti di onírẹ̀wẹ̀sì, ronú lórí ìyókù ìtàn Pétérù. Ìgbà díẹ̀ lẹ́hìn ìṣẹ̀lẹ̀ yí àti ìroraọkàn ti sísẹ́ ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Krístì,6 Pétérù dúró níwájú àwọn olórí èsìn kannáà tí wọ́n dá Olùgbàlà lẹbi, àti pẹ̀lú ìdúró títóbi lábẹ́ ìbèèrè líle ó jẹ́ ẹ̀rí dídára nípa àtọ̀runwá Jésù Krístì.7

Ẹ Mọ Ẹni Tí Ẹ Jẹ́ Kí Ẹ Sì Jẹ́ Olotitọ sí Ìdánimọ̀ Àtọ̀runwá Yín

Ẹ jẹ́ kí a ro àwọn ohun èlò ti dídúró bíiti Krístì. Láti bẹ̀rẹ̀, mímọ ẹni tí a jẹ́ àti jíjẹ́ òtítọ́ sí ìdánimọ̀ tọ̀run wa nmú ìparọ́rọ́ wá. Ìdúró bíiti Krístì nílò kí a yẹra fún fífi ara wa wé àwọn ẹlòmíràn tàbí dídíbọ́n láti jẹ́ ẹnìkan tí a kò jẹ́.8 Joseph Smith kọ́ni pé, “Bí ènìyàn kò bá ní òye ìwà Ọlọ́run, wọn kò ní òyè ara wọn.”9 Kò kàn ṣeéṣe láti ní ìdúró ti ọ̀run láì mọ̀ pé a jẹ́ àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin tọ̀run ti olùfẹ́ni Baba Ọ̀run.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ “Àwọn Yíyan fún Ayérayé,” Ààrẹ Nelson kọ́ni ni àwọn òtítọ́ ayérayé wọ̀nyí nípa ẹni tí a jẹ́: àwa jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, a jẹ́ ọmọ májẹ̀mú náà, a sì jẹ́ ọmọẹ̀hìn Krístì. Nígbànáà ó ṣèlérí pé, “Bí ẹ ti nrọ̀mọ́ àwọn òtítọ́ wọ̀nyí, Baba wa Ọ̀run yíò ràn yín lọ́wọ́ láti dé ìfojúsùn ìgbẹ̀hìn ti gbígbé ní ayérayé ní ọ̀dọ̀ mímọ́ Rẹ̀.”10 A jẹ́ ẹ̀dá àtọ̀runwá ti ẹ̀mí nítòótọ́ tí ó ní ìrírí ayé ikú nítòótọ́. Mímọ ẹni tí a jẹ́ àti jíjẹ́ òtítọ́ sí ìdánimọ̀ tọ̀run náà ni ìpìlẹ̀ sí ìdàgbàsókè ìdúró bíiti Krístì.

Ẹ Mọ̀ Pé Ètò Tọ̀run Kan Wà

Títẹ̀le, ní rírántí pé ètò ọlọ́lá kan wà nmú ìgboyà àti ìdúró wá nínú àwọn ipò pípeniníjà. Nefi lè “lọ kí ó sì ṣe”11 bí Olúwa ti pàṣẹ “láìmọ̀ ṣíwájú”12 àwọn ohun tí òun níláti ṣe nítorí ó mọ̀ pé òun ó gba ìdarí nípa Ẹ̀mí, ní ìmúṣẹ ètò ayérayé ti olùfẹ́ni Baba Ọ̀run. Ìdúró nwá nígbàtí a bá ri àwọn nkan látinú ìwò ayérayé. Olúwa ti gba àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ ní ìmọ̀ràn láti “gbé ojú yín sókè”13 àti láti “jẹ́ kí àwọn ọ̀wọ̀ àìlópin dúró lé inú yín.”14 Nípa híha àwọn ìgbà pípeni-níja sí àárín ètò ayérayé kan, ìtẹ̀mọ́lẹ̀ ndi ànfàní láti ní ìfẹ́, sìn, kọ́ni, àti láti búkúnni. Ìwò ayérayé kan nmú ìleṣe ìdúró bíiti Krístì wá.

Mọ Agbára ìlèṣe Jésù Krístì àti Ètùtù Rẹ̀.

ǎti ní ìparí, agbára ìlèṣe Krístì, mu ṣeéṣe nípasẹ̀ ìrúbọ ètùtù Rẹ̀, ó nfún wa ní okun láti faradà àti láti borí. Nítorí Jésù Krístì a lè dá májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run kí a sì gba okun ní pípa májẹ̀mú náà mọ́. A lè so mọ́ Olùgbàlà nínú ayọ̀ àti ìparọ́rọ́, láìka àwọn àyídàyídà ti ara wa sí.15 Alma orí keje kọ́ni dáadáa nípa agbára ìlèṣe Krístì. Ní àfikún sí rírà wá padà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀, Olùgbàlà lè fún wa lókun nínú àwọn àìlera, ẹ̀rù, àti àwọn ìpènijà wa nínú ayé yí.

Bí a ti nfojúsùn sí Krístì, a lè pa àwọn ẹ̀ru wa rẹ́, bí àwọn ènìyàn Álmà ti ṣe ní Helam.16 Bí àwọn ológun dídẹ́rùbani ti kórajọ, àwọn olotitọ ọmọẹ̀hìn Krístì fi ìdúró hàn. Alàgbà David A. Bednar ti kọ́ni: “Álmà gba àwọn onígbàgbọ́ ní ìmọ̀ràn láti rántí Olúwa àti ìdándè tí Òun nìkan lè fúnni (wo 2 Nefi 2:8). Àti ìmọ̀ ìtọ́jú ààbò Olùgbàlà mú kí ó ṣeéṣe fún àwọn ènìyàn láti pa àwọn ẹ̀rù ti ara wọn rẹ́.”17 Èyí fi àpẹrẹ ìdúró hàn.

Ọkùnrin Nlá Náà nínú Ìji

Noah kọ́ wa lọ́pọ̀ nípa sùúrù nínú ìjì, ṣùgbọ́n Olùgbàlà ni olùkọ́ni gíga jùlọ lórí bí a ṣe le yè nínú ìji. Òun ni ọkùnrin nlá náà nínú ìji. Lẹ́hìn ọjọ́ gígùn kan ti kíkọ́ ẹ̀kọ́ pẹ̀lú àwọn Àpóstélì Rẹ̀, Olùgbàlà nílò ìsinmi díẹ̀ ó sì daba pé kí wọ́n sọdá nípa ọkọ̀ sí ẹ̀gbẹ́ kejì ti Òkun Galilee. Bí Olùgbàlà ti nsinmi, ìjì líle dìde. Bí afẹ́fẹ́ àti ìgbì ṣe dẹ́rùbani láti tẹ ọkọ̀ rì, àwọn Àpóstélì bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù fún ayé wọn. Ẹ sì rántí pé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Àpóstélì wọnnì jẹ́ apẹja tí wọ́n wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìjì lórí òkun náà! Síbẹ̀, wọ́n dààmú,18 wọ́n jí Olúwa dìde wọ́n sì bèèrè pé, “[Olúwa], ṣe ìwọ̀ kò bìkítà kí àwa ṣègbé?” Nígbànáà, pẹ̀lú àpẹrẹ ìdúró, Olùgbàlà “dìde, ó sì bá afẹ́fẹ́ náà wí, ó sì wí fún òkun pé, Dákẹ́, jẹ́. Afẹ́fẹ́ sì dá dúró, ìdákẹ́jẹ́ nlá … sì wà.”19

Àti lẹ́hìnnáà ẹ̀kọ́ nlá nínú ìdúrò fún àwọn Àpóstélì Rẹ̀. Ó bèèrè pé, “Kílódé tí ẹ̀yin fi bẹ̀rù tó bẹ́ẹ̀? kínní ṣe tí ẹyin kò ní ìgbàgbọ́?”20 Ó nrán wọn létí pé Òun ni Olùgbàlà aráyé àti pé Òun ni a rán nípasẹ̀ Baba láti mú àìkú àti ìyè ayérayé àwọn ọmọ Ọlọ́run wá sí ìmúṣẹ. Dájúdájú Ọmọ Ọlọ́run kò ní ṣègbé nínú ọkọ̀. Ó fi ápẹrẹ ìdúró tọ̀run hàn nítorí Ó mọ àtọ̀runwá Rẹ̀ àti pé Ó mọ̀ pé ètò ìgbàlà àti ìgbéga kan wà àti bí Ètùtù Rẹ̀ yío ti jẹ́ pàtàkì tó sí àṣeyege ayérayé ètò náà.

Nípasẹ̀ Krístì àti Ètùtù Rẹ̀ ni gbogbo ohun rere ti nwá sínú ayé wa. Bí a ti nrántí ẹni tí a jẹ́, tí a sì mọ̀ pé ètò àánú tọ̀run kan wà, àti pé ní fífa ìgboyà látinú okun Olúwa, a lè ṣe ohun gbogbo. A ó rí ìparọ́rọ́. A ó jẹ́ àwọn obìnrin àti ọkùnrin rere nínú ìjì èyíkéyí.

Njẹ́ kí a wá ìbùkún ti ìdúró biiti Krístì, kìí ṣe láti ran ara wa lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbà pípèníjà nìkan ṣùgbọ́n láti bùkún àwọn ẹlòmíràn àti láti ràn wọ́n lọ̀wọ̀ nínú àwọn ìjì nínú ayé wọn. Ní ìrọ̀lẹ́ Ọjọ́ Ìsinmi Ọ̀pẹ yí, mo jẹ́ ẹ̀rí nípa Jésù Krístì. Ó ti jínde. Mo jẹ́ ẹ̀rí àlàáfíà, ìparọ́rọ́, àti ìdúró tọ̀run tí Oùn nìkan nmú wá sí ayé wa ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Hugh B. Brown,” nínú Ìròhìn Ìpàdé Àpapọ̀ Oct. 1952, 57.

  2. Wo Sheri Dew, Wo àwọn Ìmoye látinú Ìgbé Ayé: Russell M. Nelson (2019), 66–67.

  3. Wo Ìyírọ̀padà-èdè Joseph Smith, Lúkù 22:44 (ní Luku 22:44, footnote b).

  4. Luke 22:42.

  5. Wo Lúku 22:50–51; Jòhánnù 18:10–12.

  6. Wo Matteu 26:34–35, 69–75.

  7. Wo Acts 4:8–10; Neal A. Maxwell, “Ìtẹ́lọ́rùn Pẹlú Àwọn Ohun Tí A Pín Sí Wa,” Ensign, May 2000, 74; Liahona, July 2000, 89: “Nígbàtí ẹ̀mí bá wà ní ìbámu, ìdúró kàn lè wá, ání nígbàtí a ko bá mọ ‘ìtumọ̀ ohun gbogbo’ [1 Nephi 11:17].”

  8. Wo John R. Wooden, Wooden on Leadership (2005), 50: “Mo sọ ìtumọ̀ ìdúró gẹ́gẹ́ bí jíjẹ́ olotitọ sí araẹni, láì ní ìdàrú, jíjù kúrò, tàbí àìbáramu láìka ipò tàbí àyídàyídà sí. Èyí lè dàbí ìrọ̀rùn, ṣùgbọ́n Ìdúró lè jẹ́ ìwà ẹ̀tàn jùlọ nínú àwọn ìgbà pípeni-níjà. Àwọn olórí tí wọn kò ní Ìdúró ngbọ̀n lábẹ́ ìtẹ̀mọ́lẹ̀.

    “Ìdúró túmọ̀ sí dídi ìgbàgbọ́ yín mú àti ṣiṣe ní ìbámu pẹ̀lú wọn, láìka bí ipò náà ti dára tàbí lè burú tó. Ìdúró túmọ̀ sí yíyẹra ipò tàbí ṣẹ̀tàn, fi ara yín wé àwọn ẹlòmíràn, àti ṣiṣe bí ẹnìkan tí ẹ kò jẹ́. Ìdúró túmọ̀sí níní ọkàn ìgboyà nínú gbogbo àyídàyídà.”

  9. Ìkọ́ni Àwọn Ààrẹ Ìjọ: Joseph Smith (2007), 40.

  10. Russell M. Nelson, “Àwọn Yíyàn Fún Ayérayé” (worldwide devotional for young adults, May 15, 2022), broadcasts.ChurchofJesusChrist.org

  11. 1 Néfì 3:7.

  12. 1 Néfì 4:6.

  13. John 12:46.

  14. Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 43:34; bákannáà wo James E. Faust, “Iyì ti Araẹni,” Ensign, May 1981, 10: “Iyì araẹni ni a nmú gbòòrò nípa wíwo iwájú ní wíwá ìwàmímọ́. Bíiti àwọn igi nlá, a níláti d`de fún ìmọ́lẹ náà. Orísun ìmọ́lẹ̀ pàtàkì jùlọ tí a lè mọ̀ ni ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́. Ó jẹ́ orísun okun inú àti àláfíà.”

  15. Wo Russell M. Nelson, “Ayọ̀ àti Wíwà Láàyè Ti-Ẹ̀mí,” Liahona, Nov. 2016, 82: “Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, ayọ̀ tí a nní ìmọ̀lára ní díẹ̀ íṣe pẹ̀lú àwọn àyídàyídà ìgbé ayé wa àti ohungbogbo láti ṣe pẹ̀lú ìdojúkọ ìgbé ayé wa.”

  16. Wo Mòsíàh 23:27–28.

  17. David A. Bednar, “Nítorínáà Wọ́n Tẹ Ẹ̀rù Wọn Mọ́lẹ̀,” Liahona, May 2015, 46–47.

  18. Wo Jeffrey R. Holland, Ọjọ́ Ìràwọ̀ Dídìde Wa: Wíwá Májẹ̀mú Titun pẹ̀lú Jeffrey R. Holland (2022), 61–62: “Pẹ̀lúpẹ̀lù, wọ́n jẹ́ àwọn ọkùnrin aláìní ìrírí lórí ìgbìmọ̀ pẹ̀lú Rẹ̀—mọ́kànlá ti Méjìlá àkọ́kọ́ ni àwọn ará Galilee (Judas Iscariot nìkan ni ará Juda). Àti pé mẹ́fà àwọn mọ́kànlá ni Apẹja. Wọ́n ti gbé ní òkun yí. Wọ́n ti mú gbígbé wọn nípa pípa ẹja lórí rẹ̀. Wọ́n ti wà níbẹ̀ látìgbà tí wọ́n ti wà lọ́mọdé. Àwọn baba wọn àti àwọn tí wọ́n ntún àwọn àwọ̀n ṣe tí wọ́n sì nṣe àtúnṣe lórí ọkọ̀ náà nígbàtí wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́. Wọ́n mọ òkun yí; wọ́n mọ afẹ́fẹ́ àti ìjì. Wọ́n jẹ́ onírírí ènìyàn—ṣùgbọ́n wọ́n bẹ̀rù. Ati bí wọ́n bẹ̀rù, èyí jẹ́ ìjì àìlófin.”

  19. Wo Markù 5:25–34.

  20. Márkù 4:40.