Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Wíwá Àláfíà Araẹni
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2023


15:54

Wíwá Àláfíà Araẹni

Mo gbàdúrà pé ẹ ó rí àláfíà, ran ọ̀pọ̀plọpọ̀ àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ri, kí wọ́n sì tíí síwájú.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, a ti di alábùkún fún nípa ìkọ́ni ìmísí àti orin alárinrin tí ó ti fọwọ́ tọ́ wa nínú abala ṣíṣí ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò. A dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ìkópa yín àti fún ìgbàgbọ́ yín.

Ní òní èmi ó sọ̀rọ̀ lórí ohun tí mo ti kọ́ nípa ìṣẹ́ ìyanu ti wíwá àláfíà araẹni, eyikeyi àwọn ipò wa. Olùgbàlà mọ̀ pé àwọn ọmọ Baba Ọ̀run nyọ́nú fún àláfíà, àti pé Ó wípé Òun lè fi fún wa. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ rántí àwọn ọ̀rọ̀ ti Jésù Krístì tí a kọsílẹ̀ nínú ìwé Jòhánnù: “Àláfíà ni mo fi fún yín, àláfíà mi ni mo fi fún yín: kìí ṣe bí ayé ti í funni, ni èmi fi fún yín. Ẹ máṣe jẹ́ kí ọkàn yín kí ó dàrú, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí ó wárìrì.”1

Ohun tí Ó túmọ̀sí nípa àláfíà àti bí Òun ti lè fi fúnni ni a fihàn nípa ipò àwọn ẹni tí wọ́n gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Rẹ̀ wọnnì. Ẹ fetísílẹ̀ sí àkọsílẹ̀ Jòhánnù nípa àpapọ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ ti Krístì. Àwọn ipa líle nípa ibi ni ó ngbé wa sílẹ̀ lórí Rẹ̀ tí yíò sì wá sórí àwọn ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ láìpẹ́.

Nihin ni àwọn ọ̀rọ̀ Olùgbàlà:

“Tí ẹ bá fẹ́ràn mi, ẹ pa àwọn òfin mi mọ́.

“Èmi ó sì gbàdúrà sí Baba, òun ó sì fún yín ní Olùtùnú míràn, kí ó lè báa yín gbé títíláé;

“Àní Ẹ̀mí òtítọ́ nì; ẹnití aráyé kò lè gbà, nítorítí kò rí i, bẹ́ẹ̀ni kò sì mọ̀ ọ́: ṣùgbọ́n ẹ̀yin mọ̀ọ́; nítorítí ó nba yín gbé, yíò sì wà nínú yín.

“Èmi kì yíò fi yín sílẹ̀ ní aláìní baba: èmi ó tọ̀ yín wá.

“Nígbà díẹ̀ sí i, ayé kò sì rí mi mọ́; nítorí ẹ̀yin ó rí mi: nítorítí èmi wà láàyè, ẹ̀yin ó wà láàyè pẹ̀lú mi.

“Ní ọjọ́ náà ni ẹ̀yin ó mọ̀ pé, èmi wà nínú Baba mi, àti ẹ̀yin nínú mi, àti èmi nínú yín.

“Ẹni tí ó bá ní òfin mi, tí ó bá sì npa wọ́n mọ́, òun ni ẹnití ó fẹ́ràn mi: ẹnití ó bá sì fẹ́ràn mi a ó fẹ́ràn rẹ láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá, èmi ó sì fẹ́ràn rẹ̀, èmi ó sì fi ara mi hàn fún un.

“Judasi wí fún un pé, kìí ṣe Iscariot, Olúwa, ehatiṣe tí ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn fún àwa, tí kì yíò si ṣe fún aráyé?

“Jésù dáhùn ó sì wí fun pé, Bí ẹnìkan bá fẹ́ràn mi, yíò pa ọ̀rọ̀ mi mọ́: Baba mi yíò sì fẹ́ràn rẹ̀, àwa ó sì tọ̀ọ́ wá, a ó sì ṣe ibùgbé wa pẹ̀lú rẹ̀.

“Ẹnití kò fẹ́ràn mi ni kò lè pa ọ̀rọ̀ mi mọ́: ọ̀rọ̀ tí ẹ̀yin ngbọ́ kì sì ṣe ti èmi, ṣùgbọ́n ti Baba tí ó rán mi.

“Nkan wọ̀nyí ni èmi ti sọ fún yín, nígbàtí mo nbá yín gbé.

“Ṣùgbọ́n Olùtùnú náà, Ẹ̀mí Mímọ́, ẹnití Baba yíò rán ní orúkọ mi, òun yíò kọ́ yín ní ohun gbogbo, yíò sì ràn yín létí ohun gbogbo tí mo ti sọ fún yín.

“Àláfíà ni mo fi fún yín, àláfíà mi ni mo fi fún yín: kìí ṣe bí ayé ti í funni, ni èmi fi fún yín. Ẹ máṣe jẹ́ kí ọkàn yín kí ó dàmú, ẹ má sì ṣe jẹ́ kí ó wárìrì.”8

Mo ti kọ́ ó kéréjù àwọn òtítọ́ marun látinú ìkọ́ni Olùgbàlà.

Àkọ́kọ́, ẹ̀bùn àláfíà ni a fúnni lẹ́hìn tí a bá ní ìgbàgbọ́ láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́. Fún àwọn ẹnití wọ́n bá jẹ́ onímájẹ̀mú ọmọ ìjọ ti Ìjọ Olúwa, ìgbọ́ran ni ohun tí a ti ṣèlérí láti ṣe.

Ìkejì, Ẹ̀mí Mímọ́ yíò wá bá wa gbé. Olúwa wí pé bí a bá ti tẹ̀síwájú láti jẹ́ olotitọ, Ẹ̀mí Mímọ́ yíò bá wa gbé. Èyí ni ìlérí nínú àdúrà ti oúnjẹ́ Olúwa pé kí Ẹ̀mí jẹ́ ojúgbà wa àti pé a ó ní ìmọ̀lára, ìtùnú Rẹ, nínú ọkàn àti inú wa.

Ìkẹ́ta, Olùgbàlà ṣe ìlérí pé bí a ti npa àwọn májẹ̀mú mọ́, a lè ní ìmọlára ìfẹ́ Baba àti Ọmọ fún ara wa àti fún wa. A lè ní ìmọ̀lára ìsúnmọ́ Wọn nínú ìgbé ayé ikú wa, gẹ́gẹ́bí a ó ti ṣe nígbàtí a bá di alábùkún láti wà pẹ̀lú Wọn títíláé.

Ìkẹ́rin, pípa àwọn òfin Olúwa mọ́ bèèrè ju ìgbọ́ràn lọ. A níláti fẹ́ràn Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn, okun, inú, àti ẹ̀mí wa.3

Àwọn tí wọ́n kò fẹ́ràn Rẹ̀ kì yíò pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́. Àti nítorínáà wọn kò ní ní ẹ̀bùn àláfíà nínú ayé yí àti nínú ayé tí ó nbọ.

Ìkárún, ó hàn kedere pé Olúwa fẹ́ràn wa tó láti san oye ti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa kí a lè—nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ wa nínú Rẹ̀ àti ìrònúpìwàdà wa, nípasẹ̀ àbájáde Ètùtù Rẹ̀—ní ẹ̀bùn àláfíà tí ó “kọjá gbogbo òye,”4 ní ayé yí àti pẹ̀lú Rẹ̀ ni ayérayé.

Àwọn díẹ̀ lára yín, bóyọ́ púpọ̀, kò ní ìmọ̀lára àláfíà tí Olúwa ṣe ìlérí. Ẹ lè ti gbàdúrà fún àláfíà araẹni àti ìtùnú ti ẹ̀mí. Síbẹ́ ẹ lè ní ìmọ̀lára pé àwọn ọ̀run dákẹ́ sí ẹ̀bẹ̀ yín fún àláfíà.

Ọ̀tà ẹ̀mí yín kan wà tí kò fẹ́ kí ẹ̀yin àti àwọn tí ẹ fẹ́ràn rí àláfíà. Oun kò lè gbádùn rẹ̀. Àní ó nṣiṣẹ́ láti dènà yín kúrò ní wíwá àláfíà tí Olùgbàlà àti Baba wa Ọ̀run nfẹ́ kí ẹ ní.

Àwọn ìgbìyànjú Sátánì láti gbin ìkóríra àti ìjà ní gbogbo àyíká wa dàbí ó npọ̀ si. A rí ẹ̀rí rẹ̀ tí ó nṣẹlẹ̀ ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè àti ìlú, ní àwọn adúgbò, ní ẹ̀rọ ìròhìn, àti káàkiri gbogbo ayé.

Síbẹ̀ èrèdí wà fún ìgbàgbọ́ rere: ó jẹ́ Ìmọ́lẹ̀ Krístì tí a gbé sí inú gbogbo ọmọ tí a ṣẹṣẹ bí. Pẹ̀lú ẹ̀bùn káríayé náà ni ọgbọ́n ohun tí ó tọ́ fi nwá, ìfẹ́ kan láti fẹ́ràn àti láti jẹ́ fífẹ́ràn. Ọgbọ́n àbímọ́ kan wà nípa ìdáláre àti òtítọ́ nínú gbogbo ọmọ Ọlọ́run bí ọkúnrin tàbí obìnrin ṣe nwá sí inú ayé ikú.

Ìgbágbọ́ rere wa fún àláfíà araẹni fún àwọn ọmọ wọnnì wà nínú àwọn ènìyàn tí ó nṣètọ́jú wọn. Bí àwọn ẹnití ó ntọ́jú wọn bá ṣiṣẹ́ láti gba ẹ̀bùn àláfíà láti ọ̀dọ̀ Olùgbàlà, wọn yíò, nípasẹ̀ apẹrẹ àti ììtiraka araẹni, gba ìgbàgbọ́ ọmọ náà níyànjú láti yege fún ẹ̀bùn títayọ ti àláfíà.

Èyí ni ohun tí ìwé mímọ́ ṣe ìlérí pé “Tọ́ ọmọ ní ọ̀nà tí yio tọ̀: nígbàtí o bá dàgbà tán, kì yio kúrò nínú rẹ.”7 Yíò gba ọ̀kan tí ó ní agbára pẹ̀lú ìtọ́jú ọmọ àti ṣíṣe ìkẹ́ láti jẹ́ yíyẹ nípa ẹ̀bùn àláfíà.

Pẹ̀lú ìbànújẹ́ gbogbo wa ti ní ìmọ̀lára ìrora àwọn ọmọ tí a tọ́ láyi ọwọ́ àwọn òbí onímísí—nígbàmíràn òbí kanṣoṣo—yàn, lẹ́hìn ìgbà-ayé ìgbàgbọ́ àti àláfíà, láti gba ipa ọ̀nà ìkorò.

Àní nígbàtí ìbànújẹ́ bá ṣẹlẹ̀, ìgbàgbọ́ rere ndálé ẹ̀bùn míràn láti ọ̀dọ̀ Olúwa. Ó jẹ́ èyí: pé ó tọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn onílàjà ní àárín àwọn ọmọẹ̀hìn tí Ó gbẹ́kẹ̀lé. Wọ́n ti ní ìmọ̀lára àláfíà àti ìfẹ́ Ọlọ́run. Wọ́n ti ní Ẹ̀mí Mímọ́ nínú ọkàn wọn, àti pé Olúwa lè tọ́ wọ́n sọ́nà láti nawọ́ sí àwọn àgùtàn tí ó nṣáko.

Mo ti rí i ní ìgbà aye mi àti káàkiri ayé. Ẹ ti rí i bákannáà. Ní ìgbamíràn, nígbàtí a bá ndarí yín sí ìgbàlà, ó lè dàbí ó léwu.

Nígbàkan, mo kan bí ẹnìkan tí mo pàdé ní ìrìnàjò kan pé, “Ṣé ìwọ ó sọ fún mi díẹ̀ nípa ẹbí rẹ̀?” Ìbárasọ̀rọ̀ náà darí mi láti bèèrè láti rí àwòrán kan nípa ọmọbìnrin rẹ àgbà, ẹnití ó wípé ó nlàkàkà. Ìwàrere ojú ọmọbìnrin náà ní inú àwòrán là mí gàrà. Mo ní ìmọ̀lára ìtẹ̀mọ́ra láti bèèrè bí èmi bá lè ní àdírẹ́sì ayélujára rẹ̀. Ọmọbìnrin náà ní àkokò náà ti sọnù tí ó sì nronú bóyá Ọlọ́run ti ní ọ̀rọ̀ kankan fún òun. Ó ní i. O jẹ́ èyí: “Olúwa fẹ́ràn rẹ̀. Ó ní nígbàgbogbo. Olúwa nfẹ́ kí o padà wá. Ìlérí àwọn ìbùkún rẹ̀ si wa níbẹ̀.”

Àwọn ọmọ ìjọ káàkiri Ìjọ ti ní ìmọ̀lára ẹ̀bùn Olúwa nípa àláfíà ti araẹni. Òun ngba gbogbo ènìyàn níyànjú láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ní ànfàní láti wá sọ́dọ̀ Rẹ̀ àti láti yege fún irú àláfíà kannáà fúnra wọn. Nígbànáà, ní bíbọ̀wá, wọn yíò yàn láti wá ìmísí láti mọ̀ bí wọ́n yíò ti fi ẹ̀bún nàá sọ́dá lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn.

Ìran tí ó ndìde yíò di olùṣìkẹ́ ìran tí tẹ̀le. Àbájáde púpọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ yíò mú iṣẹ́ ìyanu jáde. Yíò tàn ká yíò sì dàgbà ní àkokò, àti pé ìjọbá Olúwa lórí ilẹ̀ ayé yíò ṣetán láti kí I pẹ̀lú igbe hòsánnà. Àláfíà yíò wà ní orí ilẹ̀ ayé.

Mó jẹ́ ẹ̀rí dídáju mi pé Olùgbàlà wà láàyè àti pé Ó ndarí Ìjọ yí. Mo ti nímọ̀lára ìfẹ́ Rẹ̀ nínú ayé mi àti ìfẹ́ Rẹ̀ àti àníyàn fún gbogbo àwọn ọmọ Baba Ọ̀run. Ìpè Olùgbàlà náà láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ ni ìfúnni ní àláfíà kan.

Ààrẹ Russell M. Nelson ni wòlíì Ọlọ́run alààyè fún gbogbo ayé. Ó wípé, “Mo fún yín ní ìdánilójú mi pé láìka ipò ti ayé sí àti àwọn àyídàyídà araẹni yín, ẹ ó dojúkọ ọjọ́ ọ̀la pẹ̀lú ìgbàgbọ́ fún rere àti ayọ̀.”6

Mo fi ìfẹ́ mi hàn sí yín. Ìgbàgbọ́ nlá yín àti ìfẹ́ ndé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ó sì nfi ààyè gba Olúwa láti yí àwọn ọkàn padà kí a sì jèrè ìfẹ́ láti fún àwọn ẹlòmíràn ní ẹ̀bùn tí ó kọjá gbogbo ìmọ̀.

Mo gbàdúrà pé ẹ ó rí àláfíà, ran ọ̀pọ̀plọpọ̀ àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ri, kí wọ́n sì tíí síwájú. Àwọn ẹgbẹ̀rún ọdún oníyanu àláfíà yíò wà nígbàtí Olúwa yíò wá lẹ́ẹ̀kansi. Mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ nínú ayọ̀ àti ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.