Ó Lè Wò Mí Sàn!
Ìwòsàn àti agbára ìràpadà Olùgbàlà ṣeé múlò sí àwọn àṣìṣe àìròtẹ́lẹ̀, àwọn ìpinnu tí kò dára, àwọn ìpèníjà, àti àwọn ìdánwò onírúurú—bákannáà sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.
Mórónì ṣèlérí pé bí a bá ka Ìwé ti Mọ́mọ́nì, tí a sì béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run Baba Ayérayé, pẹ̀lú ọkàn òtítọ́, pẹ̀lú èrò inú gidi, níní ìgbàgbọ́ nínú Krístì bí ó bá jẹ́ òtítọ́, Ọlọ́run yíò fi òtítọ́ rẹ̀ hàn nípa agbára Ẹ̀mí Mímọ́.1 Àwọn míllíọ̀nù ènìyàn ti mú ìlérí yìí lò tí wọ́n sì gba ẹ̀rí ìdánilójú ti Ìmúpadàbọ̀sípò ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhìnrere ti Jésù Krístì.
Mórónì gbàwá níyànjú, bí a ṣe nka Ìwé ti Mọ́mọ́nì, láti “rántí bí Olúwa ti jẹ́ alãnú sí àwọn ọmọ ènìyàn, láti ìgbà ìṣẹ̀dá Ádámù àní títí di àkókò [yìí],… àti [láti] ronú nípa rẹ̀ nínú ọkàn [wa].”2 Àwọn ìtàn àti àwọn ẹ̀kọ́ inú Ìwé ti Mọ́mọ́nì rán wa létí wọ́n sì jẹ́rìí nípa ìfẹ́, ìyọ́nú, àti àánú Olùgbàlà.
Baba mi kú ní Oṣù Kẹ́rin ọdún 2013. Bí mo ṣe nmúra sílẹ̀ láti sọ̀rọ̀ níbi ìsìnkú rẹ̀, mo rí i bí a ṣe bùkún mi tó láti mọ àti láti fẹ́ràn àwọn ààyò ẹsẹ Ìwé Mímọ́. Ó máa nṣe àjọpín wọn nínú àwọn ìpéjọ ẹbí, ó sì máa nkà wọ́n pẹ̀lú mi nígbàtí mo bá nílò ìmọ̀ràn, ìtọ́sọ́nà, tàbí fífún ìgbàgbọ́ mi lókun. Mo gbọ́ tí ó pín wọn ní àwọn ìjíròrò àti àwọn iṣẹ́ ìyànsílẹ̀. Kìí ṣe pé mo mọ̀ wọ́n nìkan, ṣùgbọ́n mo ṣì lè rántí dídún ohùn rẹ̀ àti ìmọ̀lára ti ẹ̀mí tí mo máa nní bí ó ti npín wọn. Nípa ṣíṣe àjọpín àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àti ìmọ̀lára, baba mi ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe àgbékalẹ̀ ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú Jésù Kristi Olúwa.
Baba mi ní pàtàkì fẹ́ràn àkọsílẹ̀ ti ìbẹ̀wò Olùgbàlà sí àwọn ènìyàn Néfì.3 Àkọsílẹ̀ mímọ́ yìí jẹ́ ti Olúwa Jésù Kristi tí ó jíǹde, tí a sì gbéga. Ó ti mu nínú ago kíkorò náà Ó sì jìyà ohun gbogbo kí a má bàá jìyà bí a bá ronúpìwàdà.4 Ó ti bẹ ayé ẹ̀mí wò Ó sì ṣètò ìwàásù ìhìnrere níbẹ̀.5 Ó ti jíǹde kúrò nínú òkú, ó sì ti wà pẹ̀lú ó sì ti gba àwọn òfin láti ọ̀dọ̀ Baba láti pín àwọn ìwé mímọ́ pẹ̀lú àwọn ará Néfì tí yíò bùkún àwọn ìran ọjọ́ iwájú.6 A gbe E ga Ó sì ní gbogbo agbára àti ipa ayérayé Rẹ. A lè kẹ́kọ̀ọ́ láti inú gbogbo àwọn àlàyé ti àwọn ìkọ́ni Rẹ̀.
Ní 3 Néfì 11, a kà bí Olùgbàlà ṣe sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run láti kọ́ àwọn ará Néfì pé Òun ni Jésù Krístì, ẹni tí àwọn wòlíì jẹ́rìí pé yíò wá sí ayé. Ó kéde pé Òun ni Ìmọ́lẹ̀ Ayé àti pé Ó yin Baba lógo nínú kíkó àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ. Ó pe àwọn ènìyàn náà láti jáde wá láti fi ọwọ́ wọn sí ẹ̀gbẹ́ Rẹ̀ àti láti ní ìmọ̀ àpá ìṣó ní ọwọ́ Rẹ̀ àti ní ẹsẹ̀ Rẹ̀. Ó fẹ́ kí wọ́n ó mọ̀ pé Òun ni Ọlọ́run Ísráẹ́lì, tí a pa nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ayé. Àwọn ènìyàn náà fi ayọ̀ dáhùn, wọ́n jáde lọ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan títí gbogbo wọn fi rí i tí wọ́n sì mọ̀ lára pé lõtọ́ Òun ni nípa ẹni tí a ti kọ̀wé láti ọwọ́ àwọn wòlíì pé ó nbọ̀.7
Jésù kọ́ àwọn ọmọ Néfì nípa pàtàkì ìrònúpìwàdà, nípa dídà bi ọmọdé, àti pé wọ́n nílò láti ṣe ìrìbọmi nípasẹ̀ ẹni tí ó ní àṣẹ Rẹ̀. Lẹ́hìnnáà Ó kọ púpọ̀ nínú ẹ̀kọ́ tí a nkọ́ ní ọdún yìí nínú Májẹ̀mú Titun.
Nínú 3 Néfì 17, a kà pé Jésù sọ fún àwọn ènìyàn pé ó tó àkokò fún Un láti lọ sọ́dọ̀ Baba àti pẹ̀lú láti fi ara Rẹ̀ hàn fún àwọn ẹ̀yà Ísráẹ́lì tí ó sọnù.8 Bí Ó ti gbé ojú sókè sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, Ó ṣàkíyèsí pé wọ́n nsunkún, wọ́n sì tẹjúmọ́ Ọ bí ẹni pé wọ́n fẹ́ sọ pé kí Ó dúró díẹ̀ síi.9
Ìdáhùn Olùgbàlà sí àwọn ará Néfì jẹ́ ìfọwọ́kàn àti ìtọ́ni. Ó wípé, “Ẹ kíyèsĩ, inú mi kún fún ìyọ́nú sí yín.10
Mo gbàgbọ́ pé àánú Rẹ̀ jẹ́ púpọ̀ díẹ̀ síi ju ìdáhùn sí àwọn omijé àwọn ènìyàn náà. Ó dàbí pé Ó lè rí wọn nípasẹ̀ àwọn ojú ti ẹbọ ètùtù Rẹ̀. Ó rí gbogbo ìrora, ìpọ́njú, àti ìdánwò wọn. Ó rí àwọn àìsàn wọn. Ó rí àìlera wọn, ó sì mọ̀ láti inú ìrora ìjìyà Rẹ̀ ní Gẹtsémánì àti Gọ́gọ́tà bí yíò ti ràn wọ́n lọ́wọ́ ní ìbámu sí àwọn àìlera wọn.11
Bákannáà, nígbàtí Olùgbàlà, Jésù Krístì, bá wò wá, Ó nrí Ó sì ní òye àwọn ìrora àti ẹrù àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ó rí àwọn bárakú àti àwọn ìpèníjà wa. Ó rí àwọn ìjàkadì àti àwọn ìpọ́njú wa ní onírúurú—ó sì kún fún ìyọ́nú sí wa.
Ìpè onínúure rẹ̀ sí àwọn ará Néfì tẹ̀lé e: “Ǹjẹ́ ẹ ní ẹnikẹ́ni tí ó ṣàìsàn nínú yín? Ẹ mú wọn wá sìhín. Njẹ́ ẹ̀yin ní àwọn amúkun, tàbí afọ́jú, tàbí arọ, tàbí akéwọ́, tàbí adẹ́tẹ̀, tàbí àwọn gbígbẹ, tàbí adití, tàbí tí a pọ́n lójú ní onírurú ọ̀nà? Ẹ mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi èmi yíò sì wò wọ́n sàn, nítorítí èmi ní ìyọ́nú sí yín; inú mi kún fún ãnú.”12
Àwọn ènìyàn náà sì jáde wá “pẹ̀lú gbogbo àwọn tí a pọ́n lójú ní èyíkéyí ðnà; ó sì mú wọn láradá olukúlùkù bí a ti mú wọn jáde wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.”13
Ní 1990 a ngbé ní ìlú kékeré Sale, ní Victoria, Australia. À nṣiṣẹ́ tayọ̀tayọ̀ pẹ̀lú ẹbí, ìjọ, àti àwọn iṣẹ́ ìfarasìn. Ní Sátidé ìgbà ooru rírẹwà kan ṣaájú Kérésìmesì, a pinnu láti ṣàbẹ̀wò sí díẹ̀ nínú àwọn pápá ìtura àti ààyò etí òkun kan. Lẹ́hìn gbígbádùn ọjọ́ alárinrin kan ní síṣeré bí ẹbí kan, a kó gbogbo ènìyàn sínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ a sì kọrí sí ilé. Bí mo ṣe nwakọ̀, mo rọra sùn fún ìgbà díẹ̀, mo sì fa ìjànbá ìforígbárí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan. Lẹ́hìn àwọn ìṣẹ́jú díẹ̀ ìmúláradá, Mo wò yíká ọkọ̀ náà. Ẹsẹ̀ Ìyàwó mi, Maxine, bàjẹ́ gidigidi ó sì ntiraka láti mí. Stánọ́ọ̀mù rẹ̀ ti bàjẹ́. Àwọn ọmọbìnrin wa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wà nínú jìnnìjìnnì ṣùgbọ́n a dúpẹ́ pé wọ́n dára. Mo ní àwọn ìpalára díẹ̀ kékeré. Ṣùgbọ́n ọmọkùnrin wa tó jẹ́ ọmọ oṣù márùn-ún kò dáhùn.
Láàárín másùnmáwo àti ìdàrúdàpọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ ìjànbá náà, ọmọbìnrin wa àgbà, Kate, ọmọ ọdún mọ́kànlá, sọ ní kánjúkánjú pé, “Baba, o ní láti fi ìbùkún kan fún Jarom.” Lẹ́hìn ìjàkadì díẹ̀, èmi àti àwọn ọmọ mi gbìyànjú láti jáde kúrò nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ náà. Maxine kò lè gbéra. Ní ìfaràbàlẹ̀ mo gbé Jarom sókè; nígbà náà nígbà tí mo dùbúlẹ̀ sí ẹ̀hìn mi, mo rọra gbé e lé àyà mi, mo sì fún un ní ìbùkún oyèàlùfáà. Ní àkokò ti ọkọ̀ aláìsàn dé ní ogójì iṣẹju lẹ́hìnnáà, Jarom ti dáhùn.
Ní alẹ́ ọjọ́ náà mo fi àwọn ọmọ ẹbí mi mẹ́ta sílẹ̀ ní ilé ìwòsàn mo sì gun takisí tí kò dán mọ́rán lọ sílé pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin mi méjì. Ní alẹ́ gígùn náà, mo bẹ Baba Ọ̀run pé kí ẹbí mi àti àwọn tí wọ́n farapa nínú ọkọ̀ kejì lè sàn. Pẹ̀lú àánú, àwọn àdúrà mi àti àwọn àdúrà fífi ìtara gbà nípasẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn míràn rí ìdáhùn. Gbogbo wọn ni a mú láradá ní lẹ́hìn àkokò díẹ̀, ìbùkún nlá kan àti àánú tútù.
Síbẹ̀ mo tẹ̀síwájú láti máa ní ìmọ̀lára ìdálẹ́bi àti ìbànújẹ́ fún fífa irú ìjàmbá búburú bẹ́ẹ̀. Mo má njí láarín òru tí èmi ó sì rántí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bíbanilẹ́rù náà. Mo tiraka fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún láti wá àláfíà ati láti dáríji ara mi. Lẹ́hìnnáà, nígbàtí mo nran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ronúpìwàdà tí mo sì nràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀lára ìyọ́nú, àánú, àti ìfẹ́ Olùgbàlà, mo rí i pé Òun lè wò mí sàn.
Ìwòsàn àti agbára ìràpadà Olùgbàlà ṣeé múlò sí àwọn àṣìṣe àìròtẹ́lẹ̀, àwọn ìpinnu tí kò dára, àwọn ìpèníjà, àti àwọn ìdánwò onírúurú—bákannáà sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Bí mo ti yípadà si I, àwọn ìmọ̀lára ẹ̀bi àti àìbalẹ̀ ọkàn mi fi díẹ̀díẹ̀ di rírọ́pò pẹ̀lú àláfíà àti ìsinmi.
Ààrẹ Nelson kọ́ni pé: “Nígbàtí Olùgbàlà ṣe ètùtù fún gbogbo aráyé, Ó ṣí ọ̀nà kan sílẹ̀ kí àwọn tí wọ́n ntẹ̀lé E lè ní ààyè sí agbára ìmúláradá, ìfúnnilókun, àti ti ìràpadà Rẹ̀. Àwọn ànfàní ti-ẹ̀mí wọ̀nyí wà fún gbogbo ẹnití ó nwá láti gbọ́ Tirẹ̀ àti láti tẹ̀lé E.”14
Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, bóyá ẹ nru ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tí a kò yanjú, ẹ ndi ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti ṣẹ̀ sí yín láti ìgbà pípẹ́ sẹ́hìn mú, tàbí ẹ ntiraka láti dáríji ara yín fún àṣìṣe àìròtẹ́lẹ̀ kan, ẹ ní àyè sí agbára ìwòsàn àti ìràpadà ti Jésù Krístì Olùgbàlà.
Mo jẹri pé Ó wà láàyè. Òun ni Olùgbàlà wa àti Olùràpadà wa. Ó fẹ́ràn wa. Ó ní ìyọ́nú si wa, Ó sì kún fún àánú, ó sì lè wòyín sàn. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.