Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
“Gbé nínú mi, àti Emi nínú Rẹ, Nítorínáà, Rìn pẹ̀lú Mi”
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2023


“Gbé nínú mi, àti Emi nínú Rẹ, Nítorínáà, Rìn pẹ̀lú Mi”

Ìlérí Olùgbàlà láti gbé nínú wa jẹ́ òtítọ́ ó sì wà ní àrọ́wọ́tó sí olukúlùkù olùpa májẹ̀mú mọ́ ọmọ Ìjọ Rẹ̀ tí a múpadàbọ̀sípò.

Wòlíì àtijọ́ nì Enọ́kù, ṣe àpéjuwe nínú Májẹ̀mú Láeláe pé, Ẹkọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú, àti Péálì Olówó Iyebíye,1 jẹ́ irinṣẹ́ ní síṣe àgbékalẹ̀ ilú Síonì.

Àkọsílẹ̀ inú ìwé mímọ́ nípa ìpè Enọ́kù láti sìn tọ́ka síi pé “ó gbọ́ ohùn kan láti ọ̀run, wípé: Enọ́kù, ọmọ mi, sọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ènìyàn yí, kí o sì sọ fún wọn pé—Ẹ ronúpìwàdà, … nítorí ọkan wọn ti di líle, etí wọn sì ti rẹ̀hìn ní gbígbọ́, àti pé ojú wọn kò le rí láti òkèrè.”2

“Nígbàtí Enọ́kù sì ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó tẹ ara rẹ̀ ba sí ilẹ̀ … ó sì sọ̀rọ̀ níwájú Olúwa, wípé: Kíniṣe tí èmi ti rí ojúrere ní ojú rẹ, ṣùgbọ́n èmi sì jẹ́ ọmọdé, gbogbo àwọn ènìyàn sì kórĩra mi; nítorí èmi lọ́ra ní ọ̀rọ̀ sísọ; báwo ni èmi ṣe jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ?”3

Ẹ jọ̀wọ́ kíyèsi pé ní àkókò ìpè Enọ́kù láti sìn, ó di níní òye jinlẹ̀ nípa àwọn àìkún-ojú-òsùnwọ̀n tó àti àwọn àìpé rẹ̀ Mo sì fura pé gbogbo wa ní àkókò kan tàbí òmíràn nínú iṣẹ́ ìsìn Ìjọ wa tí a sì ní ìmọ̀lára bíi ti Enọ́kù dáadáa. Ṣùgbọ́n mo gbàgbọ́ pé ìdáhùn Olúwa sí ìbéèrè ẹ̀bẹ̀ Enọ́kù jẹ́ ìkọ́ni ó sì wúlò fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa lónìí.

“Olúwa sì wí fún Enọ́kù pé: Jáde lọ kí o sì ṣe bí èmi ti pàṣẹ fún ọ, kì yío sì sí ènìyàn kan tí yío gún ọ. La ẹnu rẹ, á ó sì kún un, èmi yíò sì fún ọ ní ọ̀rọ̀ sísọ. …

“Kíyèsi Ẹ̀mí mi wà ní orí rẹ, nítorínáà gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ rẹ ni èmí yíò dáláre; àwọn òkè yíò sì sá níwájú rẹ, àwọn odò yíò sì yà kùrò ní ipa ọ̀nà wọn; ìwọ yíò sì gbé nínú mi, àti èmi nínú rẹ; nítorínáà rìn pẹ̀lú mi.4

Nígbẹ̀hìn Enọ́kù di wòlíì nlá àti ohun èlò ní ọwọ́ Ọlọ́run láti ṣe àṣeparí iṣẹ́ nlá kan, ṣùgbọ́n kò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ọ̀nà yí! Dípò bẹ́ẹ̀, agbára rẹ̀ lẹ́hìn àkókò díe di mímú-tóbi bí ó ti kọ́ ẹ̀kọ́ láti gbé nínú àti láti rìn pẹ̀lú Ọmọ Ọlọ́run náà.

Mo fi ìtara gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ ti Ẹmí Mímọ́ bí a ti ngbèrò papọ̀ nípa ìmọ̀ràn ti a fifún Enọ́kù láti ọwọ́ Olúwa àti ohun tí ó le túmọ̀ sí fún ìwọ àti èmi lóni.

Iwọ Yío Gbé nínú Mi

Olúwa Jésù Krístì mú dé ọ̀dọ̀ ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ìpè láti gbé nínú Rẹ̀.5 Ṣùgbọ́n báwo ni a ti le kọ́ ẹ̀kọ́ kí a sì wá láti gbé nínú Rẹ̀ nítòótọ́?

Ọrọ̀ náà gbé túmọ̀ sí dídúró láìyẹsẹ̀ tàbí láìmira àti fífi ara dà láì yẹra. Alàgbà Jeffrey R. Holland ti ṣàlàyé pé “gbígbé” bíi ìṣe túmọ̀ sí “‘[láti] dúró—ṣùgbọ́n [láti] dúró títíláé.’ Èyí ni ìpè ọ̀rọ̀ ìhìnrere sí … olukúlùku ènìyàn … àgbáyé. Wá, ṣùgbọ́n wá láti dúró. Wá pẹ̀lú ìdánilójú àti ìfaradà. Wá ní pípẹ́ títí, nítorí tìrẹ àti nítorí gbogbo àwọn ìran tí ó gbọdọ̀ tẹ̀lé ọ.”6 Nípa báyi, a ngbé nínú Krístì bí a ti wà láìyẹsẹ̀ àti dídúróṣinṣin nínú ìfọkànsìn wa sí Olùràpadà ati àwọn èrò mímọ́ Rẹ̀, ní àwọn àkókò rere àti búburú.7

A nbẹ̀rẹ̀ láti máa gbé nínú Olúwa nípa lílo ìwà rere agbára òmìnira wa láti gbé àjàgà Rẹ̀ lé orí ara wa8 nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú àti àwọn ìlànà ti ìhìnrere tí a mú padàbọ̀sípò. Ìsopọ̀ májẹ̀mú tí a ní pẹ̀lú Baba wa Ọrun àti ọmọ Rẹ̀ tó jínde tó sì wà láàyè jẹ́ orísun dídárajùlọ ti ìwòye, ìrètí, àláfíà, àti ayọ̀ pípẹ́ títí; ó tún jẹ́ ìpìlẹ̀ líle bíi àpáta9 lórí èyí tí a gbọdọ̀ gbé ìgbé ayé wa lé.

A ngbé nínú Rẹ̀ nípa títiraka títílọ láti fún àsopọ̀ májẹ̀mú wa bí ẹnìkọ̀ọ̀kan pẹ̀lú Baba àti Ọmọ lókun. Fún àpẹrẹ, gbígbàdúrà nítòótọ́ sí Baba Ayérayé ní orúkọ Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀ nsọ àsopọ̀ májẹ̀mú wa pẹ̀lú Wọn di jíjinlẹ̀ àti dídáàbò bò.

A ngbé nínú Rẹ̀ nípa ṣíṣe àpéjẹ lórí àwọn ọ̀rọ̀ Krístì. Ẹkọ́ ti Olùgbàlà nfà àwa, bíi ọmọ májẹ̀mú, súnmọ́ ọ̀dọ̀ Rẹ̀10 yío sì sọ ohun gbogbo fúnwa tí a níláti ṣe.11

A ngbé nínú Rẹ̀ nípa mínúrasílẹ̀ pẹ̀lú ìtara láti kópa nínú ìlànà ti oúnjẹ Olúwa, ṣíṣe àgbéyẹ̀wò àti rírónú lórí àwọn ìlérí májẹ̀mú wa, àti ríronúpìwàdà nítòótọ́. Ṣíṣe àbápín oúnjẹ Olúwa ní yiyẹ jẹ́ ẹ̀rí sí Ọlọ́run pé a fẹ́ láti gbé orúkọ Jésù Krístì sí orí ara wa kí a sì tiraka láti “rántí rẹ̀ nígbà gbogbo”12 lẹ́hìn àkókò kúkúrú tí a nílò láti kópa nínú ìlànà mímọ́ náà.

A sì ngbé nínú Rẹ̀ nípa sísin Ọlọ́run bí a ti nsin àwọn ọmọ Rẹ̀ tí a sì nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin wa.13

Olùgbàlà sọ pé, “Bí ẹ bá pa àwọn òfin mi mọ̀, ẹ ó gbé nínú ìfẹ́ mi; àní bí mo ti pà àwọn òfin Bàbá mi mọ́, tí mò sì ngbé nínú ìfẹ́ Rẹ̀.”14

Mo ti ṣe àpèjúwe díẹ̀ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀nà tí a fi le gbé nínú Olùgbàlà. Àti nísisìyí mo pè ọ̀kọ̀ọ̀kan wa bí ọmọẹ̀hìn Rẹ̀ láti bèèrè, wá kiri, kànkùn, kí a sì kẹ́kọ̀ọ́ fún ara wa nípa agbára Ẹmí Mímọ́ àwọn ọ̀nà mĩràn tó nítumọ̀ tí a fi lè fi Krístì sí ààrin gbùngbùn ìgbé ayé wa nínú gbogbo ohun tí a bá nṣe.

Àti Èmi nínú Yín

Ìlérí Olùgbàlà sí àwọn atẹ̀lé Rẹ̀ jẹ́ ìpín méjì: bí a bá gbé nínú Rẹ̀, Òun ó gbé nínú wa. Ṣùgbọ́n njẹ́ ó ṣeéṣe fún Krístì láti gbé nínú ẹ̀yin àti èmi—bí ẹnìkọ̀ọ̀kan àti ní ti ara-ẹni? Ìdáhùn sí ìbèèrè yí ni àsọtúnsọ bẹ́ẹ̀ni!

Nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, a kọ́ nípa Álmà tí nkọ́ni tí ó sì njẹ́rìí sí àwọn tálákà tí àwọn ìpọ́njú wọn ti mú kí wọ́n ó di onírẹ̀lẹ̀. Nínú ìkọ́ni rẹ̀, ó ṣe àfiwé ọ̀rọ̀ náà sí èso tí a gbọdọ̀ gbìn kí a sì tọ́jú, ó sì ṣe àpèjúwé “ọ̀rọ̀ naà” bí ìgbé ayé, iṣẹ́, àti ẹbọ ètùtù ti Jésù Krístì.

Álmà wípé, “Ẹ bẹ̀rẹ̀sí gbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run, pé ó nbọ̀wá láti ra àwọn ènìyàn rẹ padà, àti pé yíò jìyà yíò sì kú láti ṣe ètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn; àti pé yíò tún jínde kúrò nínú ipò òkú, èyítí yíò mú àjĩnde náà ṣẹ, pé gbogbo ènìyàn yíò dúró níwájú rẹ̀, láti jẹ́ dídá lẹ́jọ́ ní ọjọ́ ìkẹhìn àti ti ìdájọ́, ní ìbámu sí àwọn iṣẹ́ wọn.”15

Bí a ti fi àpèjúwe “ọ̀rọ̀ náà” funni láti ọwọ́ Álmà, ẹ jọ̀wọ́ ẹ rònú nípa àsopọ̀ onímĩsí tí ó tọkasí lẹ́hìnnáà.

“Àti nísisìyí … èmi fẹ́ kí ẹ gbin ọ̀rọ̀ yĩ sínú ọkàn yín, bí ó sì ti bẹ̀rẹ̀sí wú sókè bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kí ẹ̀yin bọ́ ọ nípa ìgbàgbọ́ yín. Ẹ sì kíyèsĩ, yíò di igi kan, tí yíò máa sun jáde nínú yín sí ìyè àìlópin. Àti nígbànáà njẹ́ kí Ọlọ́run fi fún yín kí ẹrù yín lè fúyẹ́, nípasẹ ayọ̀ ti Ọmọ Rẹ̀. Àní gbogbo nkan yí ni ẹ̀yin lè ṣe bí ẹ̀yin bá fẹ́.”16

Èso tí a gbọdọ̀ tiraka láti gbìn sínú ọkàn wa ni ọ̀rọ̀ náà—àní ìgbé ayé, iṣẹ́, àti ẹ̀kọ́ ti Jésù Krístì. Àti bí ọ̀rọ̀ náà ti njẹ́ títọ́jú nípa ìgbàgbọ́ ó le di igi kan tí yíò máa sun jáde nínú wa sí ìyè àìlópin.17

Kínni jíjẹ́ àpẹrẹ ti igi inú ìran Léhì? Igi náà le jẹ́ gbígbéyẹ̀wò bíi ìdúró-funni ti Jésù Krístì.18

Ẹyin àyànfẹ́ arákùnrin àti arábìnrin mi, njẹ́ Ọrọ̀ náà wà nínú wa? Njẹ́ àwọn òtítọ́ ìhìnrere Olùgbàlà ti jẹ́ kíkọ sí inú tábìlì ẹran ti ọkàn wa?19 Njẹ́ a nwá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ tí a sì nfi díẹ̀díẹ̀ dàbíi Rẹ̀ síi? Njẹ́ igi Krístì ndàgbà nínú wa bí? Njẹ́ a ntiraka láti di “ẹ̀dá [titun]”20 nínú Rẹ̀ bí?21

Bóyá agbára ìyanu yi mí sí Álmà láti béèrè: “Njẹ́ a ti bí yin ní ti ẹ̀mí nípa ti Ọlọ́run bí? Njẹ́ ẹ̀yin ti gba àwòrán rẹ nínú àwọn ìrísí yín bí? Njẹ́ ẹ̀yin ti ní ìrírí ìyípadà nlá yìi ní ọkàn yín bí?”22

A níláti máa fi ìgbà gbogbo rántí ẹ̀kọ́ Olúwa sí Énọkù: “Ìwọ yío gbé nínú mi, àti èmi nínú rẹ.”23 Mo sì jẹ́rìí pé ìlérí Olùgbàlà láti gbé nínú wa jẹ́ òtítọ́ ó sì wà ní àrọ́wọ́tó sí olukúlùkù olùpa májẹ̀mú mọ́ ọmọ Ìjọ Rẹ̀ tí a múpadàbọ̀sípò.

Nítorínáà; Rìn pẹ̀lú Mi

Àpóstélì Paulù gba àwọn onígbàgbọ́ tí wọ́n ti gba Olúwa níyànjú pé: “nítorínáà ẹ máa rìn nínú rẹ̀.”24

Rírìn nínú àti pẹ̀lú Olùgbàlà ṣe àfihàn àwọn abala méjì pàtàkì ti jíjẹ́ ọmọẹ̀hìn: (1) gbígbọ́ràn sí àwọn òfin Ọlọ́run, àti (2) rírántí àti bíbu ọlá fún àwọn májẹ̀mu mímọ́ tí ó so wá mọ́ Baba àti Ọmọ.

John kéde:

“Nípa èyí ni a sì mọ̀ pé àwa mọ̀ ọ́, bí àwa bá npa àwọn òfin rẹ̀ mọ́.

“Ẹnití ó bá wípé, èmi mọ̀ ọ́, tí kò sì pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, èké ni, òtítọ́ kò sì sí nínú rẹ̀.

“Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá npa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́, nínú rẹ̀ ni a gbé mú ìfẹ́ Ọlọ́run pé nítòótọ́: nípa èyí ni àwa mọ̀ pé àwa nbẹ nínú rẹ̀.

“Ẹnití ó bá wípé òun ngbé nínú rẹ̀, òun náà pẹ̀lú sì yẹ láti máa rìn gẹ́gẹ́ bí òun ti rìn.”25

Jésù pe ẹnìkọ̀ọ̀kan wa láti, “Wá, Tẹ̀lé Mi”26 kí a sì “Rìn pẹ̀lú mi.”27

Mo jẹ́rìí pé bí a ti ntẹ̀síwájú nínú ìgbàgbọ́ tí a sì nrìn nínú ìwà pẹ̀lẹ́ ti ẹ̀mí Olúwa,26 a ndi alábùkún fún pẹ̀lú agbára, ìtọ́ni, ààbò, àti àláfíà.

Ẹrí àti Ìlérí

Álmà ṣe àpèjúwe ẹ̀bẹ̀ ìfẹ́ni kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa sí gbogbo àwọn alààyè ọkàn:

“Ẹ kíyèsĩ, ó rán ìfipè kan sí gbogbo ènìyàn, nítorí ó na ọwọ́ àánú rẹ̀ sí wọn, òun sì wípé: Ẹ ronúpìwàdà, èmi yíò sì gbà yín.

“… Ẹ wá sí ọ̀dọ̀ mi ẹ̀yin yíò sì pín nínú èso igi ìyè náà; bẹ́ẹ̀ni, ẹ̀yin yíò jẹ ẹ ó sì mú nínú àkàrà àti omi ìyè náà lọ́fẹ̀ẹ́.”27

Mo ṣe àtẹnumọ́ jíjẹ́ pípé pátápátá ti ẹ̀bẹ̀ Olùgbàlà náà. Ó npòngbẹ láti bùkún olukúlùkù ènìyàn kọ̀ọ̀kan ẹnití ó ngbé nísisìyí, ẹnití ó ti gbé tẹ́lẹ̀ rí, àti ẹnití yío gbé ní orí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú oore-ọ̀fẹ́ àti àánú Rẹ̀.

Àwọn ọmọ Ìjọ kan gba ẹ̀kọ́, àwọn ìpilẹ̀sẹ̀ ẹ̀kọ́, àti àwọn ẹ̀rí tí a nkéde ní àsọtúnsọ láti orí aga ìwàásù yi ní Gbàgede Ìpàdé Àpapọ̀ àti nínú àwọn ìpéjọpọ̀ abẹ́lé káàkiri àgbáyé bíi òtítọ́—àti síbẹ̀ wọ́n le máa tiraka láti gbàgbọ́ pé àwọn òtítọ́ ayérayé wọ̀nyí ní í ṣe nínú ìgbé ayé wọn ní pàtó àti sí àwọn ipò wọn. Wọ́n gbàgbọ́ nítòótọ́ wọ́n sì nsìn pẹ̀lú ojúṣe, ṣùgbọ́n ìsopọ̀ májẹ̀mú wọn pẹ̀lú Baba àti Ọmọ Rẹ̀ Olùràpadà kò tíì di òtítọ́ ààyè àti tó nyínipadà nínú ìgbé ayé wọn.

Mo ṣe ìlérí pé nípa agbára Ẹmí Mímọ́, ẹ le mọ̀ kí ẹ sì ní ìmọ̀lára pé àwọn òtítọ́ ìhìnrere tí mo ti gbìyànjú láti ṣe àpèjúwe jẹ́ fún yín—fún yín ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àti ní ti araẹni.

Mo jẹ́ ẹ̀ri pé Jésù Krístì ni olùfẹ́ni àti alààyè Olùgbàlà àti Olùràpadà wa. Bí a bá gbé nínú Rẹ̀, Òun yíò gbé nínú wa.28 Àti pé bí a ti nrìn nínú àti pẹ̀lú Rẹ̀, a ó di alábùkún fún láti mú èso púpọ̀ jáde wá. Mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ mímọ́ ti Olúwa Jésù Krístì, àmín.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Wo Genesis 5:18–24; Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú 107:48–57; Moses 6–7.

  2. Moses 6:27.

  3. Moses 6:31.

  4. Mósè 6:32, 34; àfikún àtẹnumọ́.

  5. Wo Jòhánù 15:4–9.

  6. Jeffrey R. Holland, “Gbé Nínú Mi,” LiahonaMay 2004, 32.

  7. Wo Jòhánù 15:10.

  8. Wo Máttéù 11:29–30.

  9. Wo Hẹ́lámánì 5:12.

  10. Wo 3 Néfì 27:14–15.

  11. Wo 2 Néfì 32:3.

  12. Mórónì 4:3; 5:2.

  13. Wo Mòsíàh 2:17.

  14. Jòhánù 15:10.

  15. Álmà 33:22.

  16. Álmà 33:23; àfikùn àtẹnumọ́.

  17. Wo Álmà 26:13.

  18. I explained this principle in a devotional in 2017:

    “Álmà ‘bẹ̀rẹ̀sí wãsù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí àwọn ènìyàn nã, tí nwọ́n sì nwọ inú àwọn sínágọ́gù nwọn, àti inú ilé nwọn; bẹ̃ni, àní nwọn sì wãsù ọ̀rọ̀ nã nínú àwọn ìgboro nwọn’ [Alma 31:1; àfikùn àtẹnumọ́]. Bákannáà ó fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wé èso kan.

    “’Nísisìyí, tí ẹ̀yin bá fi ààyè gbà, pé kí a gbin irúgbìn nã sínú ọkàn nyín, ẹ wõ, bí ó bá ṣe irúgbìn òtítọ́, tàbí irúgbìn rere, tí ẹ̀yin kò bá fã tu nípa àìgbàgbọ́ nyín, kí ẹ̀yin tako Ẹ̀mí Olúwa, ẹ kíyèsĩ, yíò bẹ̀rẹ̀sí wú nínú ọkàn nyín; bí ẹ̀yin bá sì ní irú àpẹrẹ ọkàn wíwú báyĩ, ẹ̀yin yíò bẹ̀rẹ̀sí sọ nínú ara nyín pé ó níláti jẹ́ pé—ó di dandan ki eyi jẹ irúgbìn rere, tàbí pé rere ni ọ̀rọ̀ náà í ṣe, nítorítí ó bẹ̀rẹ̀sí mú ìdàgbàsókè bá ẹ̀mí mi; bẹ̃ni, ó bẹ̀rẹ̀sí tan ìmọ́lẹ̀ sí òye mi, bẹ̃ni, ó bẹ̀rẹ̀sí fún mi ní ayọ̀’ [Alma 32:28; àfikùn àtẹnumọ́].

    “Ní dídùnmọ́ni, èso rere ndi igi kan bí a ti gbìn ín sínú ọkàn òun a sì bẹ̀rẹ̀sí wú, hù jáde, àti dàgbà.

    “Sì kíyèsĩ, bí igi nã ṣe ndàgbà, ẹ̀yin yíò wípé: Ẹ jẹ́ kí a tọ́ọ dàgbà dáradára, kí ó lè ta gbòngbò, kí ó lè dàgbà, kí ó sì mú èso jáde wá fún wa. Àti nísisìyí i, ẹ kíyèsĩ, bí ẹ̀yin bá tọ́ ọ dáradára, yíò ta gbòngbò, yíò sì dàgbà, yíò sì so èso jáde wá.

    “Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá pa igi nã tì, tí ẹ kò sì bìkítà fún bíbọ́ rẹ̀, ẹ kíyèsĩ kì yíò ní gbòngbò kankan; nígbàtí ìgbóná oòrùn bá sì dé tí ó sì jó o, nítorípé kò ní gbòngbò, yíò rẹ̀ dànù ẹ̀yin ó sì fã tu sọnù.

    “Nísisìyí, eleyĩ kò rí bẹ̃ nítorípé irúgbìn nã kò dára, tàbí nítorípé èso rẹ̀ kò dára; ṣùgbọ́n ó rí bẹ̃ nítorípé ilẹ̀ nyín ti ṣá, ẹ̀yin kò sì tọ́ igi nã dàgbà, nítorínã, ẹ̀yin kò lè rí èso rẹ̀ gbà.

    “’Bákannã ni ó rí tí ẹ̀yin kò bá tọ́jú ọ̀rọ̀ nã, tí ẹ̀yin sì fojúsọ́nà pẹ̀lú ojú ìgbàgbọ́ sí èso rẹ̀, ẹ̀yin kò lè ká èso igi ìyè láéláé.

    “’Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá tọ́jú ọ̀rọ̀ náà, bẹ́ẹ̀ni, tọ́jú igi náà bí ó ti bẹ̀rẹ̀sí dàgbà, nípa ìgbàgbọ́ yín pẹ̀lú ìtẹramọ́ nlá, àti pẹ̀lú sùúrù, ní fífi ojúsọ́nà sí èso rẹ̀, yíò ta gbòngbò; ẹ sì kíyèsí, yíò sì jẹ́ igi tí yíò máa sun sí ìyè àìnípẹ̀kun’ [Alma 32:37–41; àfikùn àtẹnumọ́].

    “… Ohun tí ó jẹ́ ààrin gbùngbùn nínú àlá Léhì ni igi ìyè náà—ó dúró fún ‘ìfẹ́ Ọlọ́run’ [1 Nephi 11:21–22].

    “Nítorí Ọlọ́run fẹ́ aráyé tóbẹ́ẹ́ gẹ́, tí ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kanṣoṣo fúnni, pé ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàá gbọ́ má bàá ṣègbé, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun’ [Jòhánnù 3:16].

    “The birth, life, and atoning sacrifice of the Lord Jesus Christ are the greatest manifestations of God’s love for His children. As Nephi testified, this love was ‘most desirable above all things’ and ‘most joyous to the soul’ [1 Nephi 11:22–23; bákannáà wo 1 Nephi 8:12, 15]. Chapter 11 of 1 Nephi presents a detailed description of the tree of life as a symbol for the life, ministry, and sacrifice of the Savior—the ‘condescension of God’ [1 Nephi 11:16]. The tree can be considered as a representation of Christ.

    “One way of thinking about the fruit on the tree is as a symbol for the blessings of the Savior’s Atonement. The fruit is described as ‘desirable to make one happy’ [1 Nephi 8:10] and produces great joy and the desire to share that joy with others.

    “Significantly, the overarching theme of the Book of Mormon, inviting all to come unto Christ [see Moroni 10:32], is paramount in Lehi’s vision [see 1 Nephi 8:19]” (“The Power of His Word Which Is in Us” [address given at seminar for new mission leaders, June 27, 2017], 4–5).

  19. Wo 2 Korinti 3:3.

  20. 2 Kọ́ríntì 5:17.

  21. Àláyé Álmà kọ́wa pé ìfẹ́ inú láti gbàgbọ́ ti ngbin èso náà sí ọkàn wa, títọ́jú èso náà nípa ìgbàgbọ́ wa nmú igi iyè hù jáde, àti pé títọ́jú igi náà nmú èso igi náà wá, èyítí ó “dùn tayọ gbogbo ohun tí ó dùn” (Álmà 32:42) tí ó sì jé “títóbi jùlọ nínú gbogbo àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run” (1 Néfì 15:36).

  22. Álmà 5:14.

  23. Mósè 6:34; àtẹnumọ́ àfikún.

  24. Kólósè 2:6.

  25. 1 Jòhánù2:3–7; àfikún ìtẹnumọ́.

  26. Lúkù 18:22,

  27. Mósè 6:34.

  28. Wo Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 19:23.

  29. Álmà 5:33–34; àfikùn àtẹnumọ́.

  30. Wo Jòhánnù 15:5,

Tẹ̀