Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2023


14:31

Ṣíṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́

Ẹ jẹ́kí a nawọ́ jáde kí a sì ṣe ìtọ́jú bí Olùgbàlà wa yío ti ṣe, pàápàá sí àwọn wọnnì tí a ní ànfààní nípa ìfẹ́ àti iṣẹ́ yíyàn láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́.

Ẹyin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, ọ̀rẹ́, káàbọ̀ sí ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò!

Lẹ́hìn ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbò ní Oṣù Kẹwàá tó kọjá, Arábìnrin Gong àti èmi rìn la Gbọ̀ngàn Ìpàdé-Àpapọ kọjá láti kíi yín kí a sì gbọ́ àwọn ìrírí ìhìnrere yín.

Àwọn ọmọ ijọ wa láti Mexico sọ pé, “Hoy es el tiempo de Mexico.”

Gilly àti Mary pẹ̀lú Alàgbà àti Arábìnrin Gong

A gbọ́ pé Gilly àti Mary jẹ́ ọ̀rẹ́ láti England. Nígbàtí Mary darapọ̀ mọ́ Ijọ, ó pàdánù ààyè rẹ̀ láti gbé. Gilly fi pẹ̀lú inú rere pe Mary láti wá gbé pẹ̀lú òun. Ní kíkún fún ìgbàgbọ́, Gilly sọ pé, “Èmi kò tíì ṣe iyèméjì rí láé pé Olúwa wà pẹ̀lú mi.” Níbi ìpàdé àpapọ̀, Gilly bákannáà ní ìdàpọ̀ aláyọ̀ kan pẹ̀lú arábìnrin ìránṣẹ́ ìhìnrere ẹnití ó rì í bọmi ní ọdún mẹtadín ní àádọ́ta sẹ́hìn.

Jeff àti Mesissa pẹ̀lú Alàgbà àti Arábìnrin Gong

Jeff àti ìyàwó rẹ̀, Melissa, wà níbi ìpàdé-àpapọ gbogbogbò fún ìgbà àkọ́kọ́. Jeff jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ irú eré bọ́ọ̀lù kan tẹ́lẹ̀rí (ó máa nṣọ́ ojú ilé) àti pé nísisìyí ó jẹ́ oníṣègùn òyìnbó akunnilóorun. Ó sọ fúnmi pé, “Púpọ̀ sí ìyàlẹ́nu mi, mo nsún sí ìhà ìrìbọmi nítorípé ó fúnni ní ìmọ̀lára bíi ọ̀nà tí ó jẹ́ ojúlówó àti òtítọ́ jùlọ láti gbé.”

Ṣaájú, Melissa ti tọrọ àforíjì lọ́wọ́ arákùnrin oníṣẹ́ ìránṣẹ́ tí a yàn fún Jeff, “Jeff kò fẹ́ ‘àwọn sẹ́ẹ̀tì funfun’ ní ilé wa.” Arákùnrin oníṣẹ́ ìránṣẹ́ náà sọ pé, “Èmi ó wá ọ̀nà kan.” Nísisìyí òun àti Jeff jẹ́ ọ̀rẹ́ gidi. Ní ibi ìrìbọmi Jeff, mo pade àpéjọ àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ikẹhìn àwọn ẹnití Jeff, Melissa, àti ọmọbìnrin wọn, Charlotte, fẹ́ràn.

Àwa bí atẹ̀lé Jésù Krístì, a nwá láti ṣe iṣẹ́ ìrànṣẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn bí Òun ti ṣe nítorípé Ó ndúró láti yí àwọn ìgbé ayé padà.

Nígbàtí Peggy so fúnmi pé ọkọ rẹ̀, John, lẹ́hìn ìgbeyàwó ọdún 31, ti múra lati jẹ́ rírì bọmi, mo bèèrè kinni ohun tí o ti yípadà.

Peggy wípé, “John àti èmi nṣe àṣàrò Májẹ̀mú Titun Wá, Tẹ̀lé Mi, John sì béèrè nípa ẹ̀kọ́ Ìjọ.”

Peggy wípé, “Jẹ́kí a pe àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere.”

John wípé, “Kò sí àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere—àfi bí ọ̀rẹ́ mi bá le wá.” Láàrin bíi ọdún mẹ́wàá, arákùnrin oníṣẹ́ ìránṣẹ́ John ti di ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó ṣeé gbẹ́kẹ̀lé. (Mo ròó, kínni ìbá ti rí bí arákùnrin oníṣẹ́ ìránṣẹ́ John bá ti dúró wíwá lẹ́hìn ọdún kan, méjì, tàbí mẹ́sãn?)

John fetísílẹ̀. Ó ka Ìwé ti Mọ́mọ́nì pẹ̀lú èró inú gidi. Nígbàtí àwọn ìránṣẹ́ ìhìnrere pe John láti jẹ́ rírì bọmi, ó wípé bẹ́ẹ̀ni. Peggy wípé, “mo ṣubú kúrò lórí àga ìjókòó mi mo sì bẹ́rẹ̀ sí sunkún.”

John wípé, “Mo yípadà bí mo ti nsúnmọ́ Olúwa.” Lẹ́hìnwá, John àti Peggy di sísopọ̀ nínú tẹ́mpìlì mímọ́. Ní Oṣù Kejìlá tó kọjá, John kọjá lọ ní ọjọ́ orí 92. Peggy wípé, “John jẹ́ ènìyàn rere ní gbogbo ìgbà, ṣùgbọ́n ó di yíyàtọ̀ ní ọ̀nà rírẹwà kan lẹ́hìn tí a rí í bọmi.”

Jenny àti Meb

Arábìnrin Gong àti èmi pàdé Meb àti Jenny nípa fídíò ní àkókò àjàkálẹ̀ àrùn COVID. (A pàdé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tọkọ-taya àti àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan nípa fidiò ní àkókò COVID, ìkọ̀ọ̀kan wọn ni a fihàn pẹ̀lú àdúrà nípasẹ̀ àwọn ààrẹ èèkàn wọn.)

Meb àti Jenny fi ìrẹ̀lẹ̀ sọ pé àwọn àníyàn inú ìgbé ayé wọn mú àwọn ròó bí ìgbeyàwó tẹ́mpìlì àwọn bá le di pípamọ́, àti pé bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo. Wọ́n gbàgbọ́ pé Ètùtù Jésù Krístì àti àwọn fífi ọkàn sí májẹ̀mú wọn le ràn àwọn lọ́wọ́.

Ẹ wo ayọ̀ mi nígbàtí Meb àti Jenny gba àwọn ìwé ìkaniyẹ tẹ́mpìlì tuntun tí wọ́n sì jọ padà sí ilé Olúwa. Lẹ́hìnwá Meb fẹ́rẹ̀ kú. Irú ìbùkún wo ni pé Meb àti Jenny ti mú ìbáṣepọ̀ májẹ̀mú padà bọ̀sípò pẹ̀lú Olúwa àti ara wọn tí wọ́n sì ní ìmọ̀lára ìfẹ́ síṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní àyíká wọn.

Ní ibikíbi tí mo bá lọ, mo máa nfi pẹ̀lú ìmoore kọ́ ẹ̀kọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn wọnnì tí wọ́n nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ àti ìtọ́jú bí Olùgbàlà wa yío ti ṣe.

Salvador `ẹ̀lú Alàgbà àti Arábìnrin Gong

Ní Peru, Arábìnrin Gong àti èmi pàde Salvador àti àwọn ọmọ òbí rẹ̀.1 Salvador àti àwọn ọmọ òbí rẹ̀ jẹ́ àwọn ọmọ aláìlóbìí. Ó jẹ́ ọjọ́ ìbí Salvador. Àwọn olùdarí àti àwọn ọmọ Ijọ tí wọ́n nfi òtítọ́ ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ẹbí yìí mísí mi. “Ẹ̀sìn mímọ́ àti àìlábàwọ́n … ni èyí, Láti ṣe ìbẹ̀wò sí àwọn aláìníbaba àti àwọn opó,”3 “ran àwọn aláìlágbára lọ́wọ́, fa ọwọ́ tí ó rọ sókè, … fi okun fún àwọn eékún àìlera.”4

Ní Hong Kong, ààrẹ ìyejú àwọn alàgbà kan rọra ṣe àbápín bí iyejú wọn ti nṣe gbogbo ìdá ọgọ́rũn àwọn ìfọ̀rọ̀-wáni-lẹ́nuwò ti ṣíṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́. “A nfi pẹ̀lú àdúrà ṣètò àwọn ojúgbà kí gbogbo ẹnìkọ̀ọ̀kan ó le ṣe ìtọ́jú fún ẹnìkan kí a sì ṣe ìtọjú tiwọn náà.” ni ó wí. “A máa nbèèrè lóòrè-kóòrè lọ́wọ́ àwọn ojúgbà kọ̀ọ̀kan nípa àwọn wọnnì tí wọ́n nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún. A kíì máàkì àwọn ihò; a máa nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn oníṣẹ́ ìránṣẹ́ tí wọ́n nṣe ìtọ́jú fún àwọn ènìyàn wa.”

Ẹbí Bokolo

Ní Kinshasha, Ìpínlẹ̀ Ìṣejọba ti Congo, Ààrẹ Bokolo ṣe àbápín bí òun àti ẹbí rẹ̀ ṣe darapọ̀ mọ́ Ìjọ ní France. Ní ọjọ́ kan, bí ó ti nka ìbùkún babanlá rẹ̀, Ẹmí mísí Arákùnrin Bokolo láti padà pẹ̀lú ẹbí rẹ̀ sí DR Congo. Arákùnrin Bokolo mọ̀ pé àwọn ó dojúkọ àwọn ìpèníjà púpọ̀ bí wọ́n bá padà. Àti pé Ìjọ wọn, Ìjọ Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́ Ìkẹhìn, kò tíi jẹ́ gbígbékalẹ̀ ní Kinshasha.

Síbẹ̀, nínú ìgbàgbọ́, bí ọ̀pọ̀ àwọn ẹlòmíràn ti ṣe, àwọn Bokolo tẹ̀lé Ẹmí Olúwa. Ní Kinshasha, wọ́n ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọ́n sì búkún àwọn wọnnì ní àyíká wọn, wọ́n borí àwọn ìpèníjà, wọ́n gba àwọn ìbùkún ti ẹ̀mí àti ti ara. Lóni, wọ́n yọ̀ nínú níní ilé Olúwa ní orílẹ̀-èdè wọn.4

Ẹni tí ó yí pàdà kan jẹ́ síṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí nípa àpẹrẹ ti ara ẹni. Bí ọ̀dọ́mọkùnrin kan, ó nlo àwọn ọjọ́ rẹ̀ ní ṣíṣeré ní etí òkun. Ó wípé, ní ọjọ́ kan, “Mo rí ọmọbìnrin arẹwà kan nínú aṣọ ìwẹ̀ tí ó wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì.” Ní ìyanu, ó lọ béèrè ìdí tí irú arẹwà bẹ́ẹ̀ ṣe wọ irú aṣọ ìwẹ̀ tí ó wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì. Ó jẹ́ ọmọ Ìjọ Jésù Krístì ti awọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ó sì béèrè pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́, “Ṣé ìwọ ó fẹ́ láti wá sí ilé ìjọsìn ní Ọjọ́ Ìsinmi? Ó wípé bẹ́ẹ̀ni.

Ní àwọn ọdún sẹ́hìn, Alàgbà L. Tom Perry ṣe àbápín bí òun àti alábãrìn rẹ̀ ṣe nfi òòrè-kóòrè ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí arábìnrin kan tí ó ndá gbé ní àdúgbò gbókogbòko kan ní Boston. Nígbàtí Alàgbà Perry àti alábarìn rẹ̀ dé, arábìnrin náà rọra darí wọn pé, “Ẹ sún ìwé ìkaniyẹ tẹ́mpìlì yín wọlé ní abẹ́ ìlẹ̀kùn.” Lẹ́hìn rírí àwọn ìwé ìkaniyẹ tẹ́mpìlì nìkan ni ó mú oríṣiríṣi àwọn ìdè kúrò tí ó sì ṣí ìlẹ̀kùn náà.5 Bẹ́ẹ̀ni, kìí ṣe pé mo nsọ pé àwọn alábarìn nílò àwọn ìwé ìkaniyẹ tẹ́mpìlì. Ṣùgbọ́n mo fẹ́ràn èrò pé, bí àwọn tí wọ́n bu ọlá fún májẹ̀mú ti nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, ìdè àwọn ilé nkúrò àwọn ọkàn sì nṣí.

Alàgbà Perry fúnni ní ìmọ̀ràn àfojúrí bákannáà. Ó wípé, “Ẹ fún àwọn alábarìn ní iye àwọn iṣẹ́ yíyàn tí ó mú ọgbọ́n wá, tí a yàn pẹ̀lú àdúrà, ní kíkópọ̀ níbití ó ti dára kí àsìkò ìrìnàjò ó le jẹ́ lílò dáradára,” Òun ó gbanilámọ̀ràn pé, “Ẹ bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n nílò àbẹ̀wò jùlọ. Ẹ fi lée láti ọ̀dọ̀ àwọn wọnnì tí ó ṣeéṣe pé kí wọ́n ó faramọ́ kí wọn ó sì dáhùn dáradára sí àbẹ̀wò.” Ó parí pé, “Ìtẹramọ́ nítòótọ́ nmú àwọn iṣẹ́ ìyanu wá,

Iṣẹ́ ìránṣẹ́ gígajù àti mímọ́jù6 nwá nígbàtí a bá gbàdúrà fún “ìfẹ́ àìlábàwọ́n ti Krístì”7 tí a sì tẹ̀lé Ẹ̀mí. Ó máa nwá bákannáà bí àwọn ajọ ààrẹ iyejú àwọn alàgbà àti Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́, lábẹ́ ìdarí bíṣọ́pù, ti nmójútó àwọn aápọn iṣẹ́ ìránṣẹ́ síṣe,nínú èyítí yíyàn àwọn alábarìn iṣẹ́ ìránṣẹ́ síṣe wà. Ẹ jọ̀wọ́ fún àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin wa ní ànfàní tí wọ́n nílò láti tẹ̀lé àti láti jẹ́ kíkọ́ níṣẹ́ nípasẹ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin oníṣẹ́ ìránṣẹ́ tí wọ́n ti ní ìrírí. Ẹ sì jọ̀wọ́ jẹ́kí àwọn ọ̀dọ́ ìran tí ó ndìde mí sí àwọn alábarin arákùnrin àti arábìnrin oníṣẹ́ ìránṣẹ́.

Ní àwọn ibikan nínú Ijọ, a ní àlàfo iṣẹ́ ìránṣẹ́ síṣe. Púpọ̀ sọ pé àwọn nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ju sísọ pé wọ́n njẹ́ síṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí lọ. A kò fẹ́ àníyàn mímáàkì ojú ìhò. Ṣùgbọ́n ní ọ̀pọ̀ ìgbà a nílò ju sísọ báwo nítòótọ́ nínú gbọ̀ngàn tàbí “Njẹ́ mo le ràn ọ́ lọ́wọ́?” tí kò dénú ní ibi ààyè ìgbọ́kọ̀sí. Ní àwọn ibi púpọ̀, a le nawọ́ jáde, ní òye àwọn ẹlòmíràn ní ibití wọ́n wà, kí a sì ní àwọn ìbáṣepọ̀ nígbàtí a bá bẹ̀ àwọn ọmọ ijọ wò déédé nínú ilé wọn. Àwọn ìfipè tó ní ìmĩsí nyí ìgbé àwọn ayé padà. Nígbàtí àwọn ìfipè bá ràn wá lọ́wọ́ láti dá àti láti pa àwọn májẹ̀mú mímọ́ mọ́, a nsúnmọ́ Olúwa àti ara wa síi.

Wọ́n sọ pé àwọn tí wọ́n ní òye ẹ̀mí tòótọ́ ti iṣẹ́ ìránṣẹ́ nṣe púpọ̀ ju ìṣaájú, nígbàtí àwọn tí kò ní òye nṣe dínkù. Ẹ jẹ́kí a ṣe púpọ̀ síi, bí Olùgbàlà wa yío ti ṣe. Bí orin wa ti sọ, ó jẹ́ “ìbùkún ti ojúṣe àti ìfẹ́.”8

Ẹyin ìgbìmọ̀ wọ́ọ̀dù, ẹ̀yin iyejú àwọn alàgbà, àti Ẹgbẹ́ ǐrànlọ́wọ́, ẹ jọ̀wọ́ ẹ fetísílẹ̀ sí Olùṣọ́ Àgùtàn Rere kí ẹ sì ràn Án lọ́wọ́ “wá èyíinì tí ó ti sọnù, … ẹ mú wá lẹ́ẹ̀kansíi èyítí a ti le lọ, … ẹ di èyíinì tí ó ti fọ́, … Ẹ fún èyíinì tí ó nṣàìsàn lókun.”9 A lè ṣe àlejò “àwọn ángẹ́lì láìmọ̀”10 bí a ṣe nfi aàayè fún nínú ilé-ìtura Rẹ̀ fún gbogbo wa.11

Síṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ tó ní ìmísí nbùkún àwọn ẹbí àti àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan; bákannáà ni ó nfún àwọn wọ́ọ̀dù àti àwọn ẹ̀ka ní okun. Ẹ ronú wọ́ọ̀dù tabi ẹka yín bíi ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àyíká. Nínú ẹ̀mí òwe ti àwọn igi ólífì nínú Ìwé Mọ́mọ́nì, Olúwa ọgbà àjàrà náà àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ mú èso oníyebíye jáde wá wọ́n sì fi okun fún igi kọ̀ọ̀kan nípa síso àwọn okun àti àwọn àìlágbára gbogbo àwọn igi náà papọ̀.12 Olúwa Ọgbà àjàrà náà àti àwọn ìránṣẹ́ Rẹ̀ béèré ní títúnsọ pé, “Kínni ohun tí mo le ṣe síi?”13 Lápapọ̀, wọ́n nbùkún àwọn ọkàn àti àwọn ilé, àwọn wọ́ọ̀dù àti àwọn ẹ̀ka, nípasẹ̀ síṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, tó ní ìmísí, déédé.14

Títunsomọ́ àwọn gbòngbò àti ẹ̀ká

Síṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́—síṣe olùṣọ́-àgùtàn—nmú ọgbà àjàrà jẹ́ “ara kan”15—igbó ṣúúrú mímọ́ kan. Ọkọ̀ọ̀kan àwọn igi nínú igbó ṣúúrú wa jẹ́ alààyè igi ẹbí kan. Àwọn gbòngbò àti àwọn ẹ̀ka ní lílọ́pọ̀. Síṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ nbùkún àwọn ìrandíran. Nígbàtí iṣẹ́ ìsìn bá nílò, àwọn ọlọ́gbọ́n bíṣọ́pù, àwọn ajọ ààrẹ iyejú àwọn alàgbà àti Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ a béèrè pé, “Àwọn wo ni òjíṣẹ́ ìránṣẹ́ arákùnrin àti arábìnrin?” Àwọn ìgbìmọ̀ wọ́ọ̀dù àti àwọn ìfọrọ̀-wáni-lẹ́nuwò síṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ kìí béèrè nípa àwọn ìpèníjà àti àwọn ìṣòro nìkan ṣùgbọ́n bákannáà máa nwò pẹ̀lú ojú láti rí àti láti yọ̀ nínú àwọn ọ̀pọ̀ àánú Olúwa nínú ayé wa bí a ti nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ bí Òun yio ti ṣe.

Olùgbàlà wa ni àpẹrẹ wa pípé.16 Nítorí Òun jẹ́ rere, Ó lè kiri ní ṣíṣe rere.17 Ó nbùkún ọ̀kan àti mọ́kàndínlọgọ́rún. Ó jẹ́ iṣẹ́ ìránṣẹ́ síṣe nínú ènìyàn, A ndàbí Jésù Krístì síi nígbàtí a bá ṣe “sí … èyítí ó kéré jùlọ nínú àwọn wọ̀nyí” bí a ó ti ṣe sí Òun,18 nígbàtí a bá fẹ́ràn aládũgbò wa bí ara wa,19 nígbàtí a bá “fẹ́ràn ara yín; bí Èmi ti fẹ́ràn yín,”20 àti nígbàtí “ẹnikẹ́ni ti yío bá jẹ́ nlá ní ààrin yín, kí òun jẹ́ oníṣẹ́ ìránṣẹ́ yín.”21

Jésù Krístì nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́. Àwọn ángẹ́lì nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́.22 Àwọn atẹ̀le Jésù Krístì “ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ọ̀kan sí òmíràn,”23 “ẹ yọ̀ pẹ̀lú àwọn tí wọ́n nyọ̀, kí ẹ sì sunkún pẹ̀lú àwọn tí nsunkún,”24 “ẹ ṣe ìṣọ́ [kí ẹ sì] … bọ́ [àwọn ènìyàn] pẹ̀lú àwọn ohun tí ó ní í ṣe sí òdodo,”25 “ẹ máa rántí … àwọn tálákà àti àwọn aláìní, àwọn aláìsàn àti àwọn tí a pọ́n lójú,”26 ẹ jẹ́kí orúkọ Rẹ̀ di mímọ̀ nípasẹ̀ iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa.27 Bí a ti nṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ bí Òun yio ti ṣe, a njẹ́rìí àwọn iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀, ìbùkún Rẹ̀.28 A ngba “iṣẹ́ ìránṣẹ́ dídárajù kan.”29

Ó le rẹ̀ wá ní ti ara. Ṣùgbọ́n nínú iṣẹ́ ìsìn Rẹ̀ a “kìí ṣe àárẹ̀ ní rere ṣíṣe.”30 A máa nṣe bí a ti le ṣe tó pẹ̀lú aápọn, a kìí sáré kọjá bí a ṣe ní agbára,31 ṣùgbọ́n a ní ìgbẹkẹ̀lé, bí Àpóstélì Paulù ti kọ́ni, pé “Ọlọ́run fẹ́ràn onínú-dídùn ọlọ́rẹ.”32 Nítorí Ọlọ́run ẹnití ó “nfi irúgbìn fún afúnrúgbìn Ó tún nfi àkàrà fún ounjẹ yín, Ó sì nmú irúgbìn tí ẹ gbìn pọ̀ síi.”33 Ní àwọn ọ̀rọ̀ míràn, Ọlọ́run nṣe àfikún “olukúlùkù nkan sí gbogbo dídi púpọ̀.”34 Àwọn “ẹnití wọ́n bá gbin púpọ̀ yío ká púpọ̀ bákannáà.”35

Níbikíbi tí a bá wà, ẹ jẹ́kí a nawọ́ jáde kí a sì ṣe ìtọ́jú bí Olùgbàlà wa yío ti ṣe, pàápàá sí àwọn wọnnì tí a ní ànfààní nípa ìfẹ́ àti iṣẹ́ yíyàn láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, njẹ́ kí a le súnmọ́ Òun àti arawa síi, ní dídàbí Rẹ̀ àti àtẹ̀lé Jésù Krístì Òun yío fẹ́ kí a wà. Ní orúkọ mímọ́ Rẹ̀, Jésù Krístì, àmín.