Jésù Krístì Ni Okun Àwọn Òbí
Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì; láti fẹ́ràn ìhìnrere Rẹ̀ àti Ìjọ Rẹ̀; láti múrasílẹ̀ fún ìgbé ayé àwọn àṣàyàn òdodo.
Ní ìgbà kan, bàbá kan ṣetán láti lọ fun ìpàdé àjọ bísọ́pù ní ìrọ̀lẹ́ kan. Ọmọbìnrin ọmọ ọdún mẹ́rin rẹ̀ bọ́ síwájú rẹ̀, ó wọ àṣọ àwọ̀sùn ó sì mú iwé Àwọn Ìtàn Ìwé ti Mọ́mọ́nì lọ́wọ́.
Kínidí tí o níláti lọ sí ìpàdé?
“Nítorípé mo jẹ́ olùdámọ̀ràn kan nínú àjọ bísọ́pù,” ó dáhùn.
“Ṣùgbọ́n bàbá mi ni ìwọ!” ọmọbìnrin rẹ̀ fi ẹ̀rónú hàn.
Ó kúnlẹ̀ ní iwájú rẹ̀. Ó wípé, “Olùfẹ́-ọkàn, mo mọ̀ pé o fẹ́ kí nka ìwé fún ọ láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sùn, ṣùgbọ́n ní alẹ́ yi, mo nílò láti ran bíṣọ́pù lọ́wọ́.”
Ọmọbìnrin rẹ̀ fèsì pé, “Ṣé bíṣọ́pù náà kò ní bàbá tó le ràn án lọ́wọ́ láti sùn ni?”
A fi ìmoore ayérayé hàn fún àìníye àwọn ọmọ ijọ tí wọ́n nsìn tọkàntọkàn nínú Ijọ Jésù Krístì ní ojojúmọ́. Ìrúbọ yín jẹ́ mímọ́ nítòótọ́.
Ṣùgbọ́n bí ó ti dàbí ẹnipé ọmọdébìnrin yi ní òye, ohun kan wà tí ó jẹ́ mímọ́ dọ́gba—ohun tí a kò le rọ́pò—nípa kí òbí ó ṣe ìtọ́jú ọmọ. Ó ṣe àfihàn àwòṣe ti ọ̀run.1 Baba wa ní Ọ̀run, Òbí wa Ti Ọrun, máa nyọ̀ dájúdájú nígbàtí àwọn ọmọ Rẹ̀ bá jẹ́ kíkọ́ àti títọ́jú nípasẹ̀ àwọn òbí wọn ní ilẹ̀ ayé.2
Ẹyin òbí, ẹ ṣeun fún gbogbo ohun tí ẹ nṣe láti tọ́ àwọn ọmọ yín. Àti ẹ̀yin ọmọ, ẹ ṣeun fún gbogbo ohun tí ẹ nṣe láti tọ́ àwọn òbí yín, nítorípé bí olukúlùkù àwọn òbí ti mọ̀, a máa nfi ọ̀pọ̀ ìgbà kọ́ ẹ̀kọ́ púpọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ wa bí nípa ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ bí wọ́n ti nkọ́ láti ọ̀dọ̀ wa!3
Àwọn Òbí Ní Ojúṣe Mímọ́ kan
Njẹ́ ẹ ti ronú rí nípa ewu nlá ti Baba wa ní Ọ̀run máa ndojúkọ ní ìgbà kọ̀ọ̀kan tí Ó bá rán ọmọ kan sí ilẹ̀ ayé? Àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ẹ̀mí Rẹ̀ ni ìwọ̀nyí. Wọ́n ní agbára ìleṣe tí kò lópin. Wọ́n ní àyànmọ́ láti di ẹ̀dá ológo ti ìṣerere, oore ọ̀fẹ́, àti òtítọ́. Àti síbẹ̀ wọ́n wá sí ilẹ̀ ayé ní àìlágbára pátápátá, tí wọ́n fẹ́rẹ̀ má le ṣe ohunkóhun lẹ́hìn kíké fún ìrànlọ́wọ́. Ìrántí àkókò wọn ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìbòjú ti bò, àti pẹ̀lú ìmọ̀ ẹnití wọ́n jẹ́ gan-an àti ẹnití wọ́n le jẹ́. Wọ́n ṣe ẹ̀dá òye wọn nípa ìgbé ayé, ìfẹ́, Ọlọ́run, àti ètò Rẹ̀ tí ó dá lórí ohun tí wọ́n fiyesí láti ara àwọn ènìyàn ní àyíká wọn—pàápàá àwọn òbí wọn, àwọn ẹnití, nítòótọ́ àwọn fúnrawọn ṣì ntiraka láti ní oye àwọn nkan.
Ọlọ́run ti fún àwọn òbí ní “ojúṣe mímọ́ láti tọ́ àwọn ọmọ wọn nínú ìfẹ́ àti ìwà òdodo, láti pèsè fún àwọn àìní wọn ní ti ara àti ti ẹ̀mí, àti láti kọ́ wọn láti … fiyèsí àwọn òfin Ọlọ́run.”4
Àní yí to láti mú kí àní àwọn òbí tó dára jùlọ ó ṣe àìsùn lóru.
Ọrọ̀ mi sí gbogbo ẹ̀yin òbí, ni èyí:
Olúwa fẹ́ràn yín.
Ó wà pẹ̀lú yín.
Ó dúró sí ẹ̀gbẹ́ yín.
Òun ni okun yín ní títọ́ àwọn ọmọ yín láti ṣe àwọn àṣàyàn òdodo.
Ẹ gba ànfàní àti ojúṣe yi pẹ̀lú ìgboyà àti pẹ̀lú ayọ̀. Ẹ máṣe gbé orísun àwọn ìbùkún ti ọ̀run yi fún ẹnikẹ́ni mĩràn. Ní ààrin àwòrán àwọn iyì àti àwọn ẹkọ́ ìpìlẹ̀ ti ìhìnrere, ẹ ó jíhìn sí Ọlọ́run láti tọ́ ọmọ yín nínú àlàyé ìgbé ayé ojojúmọ́. Ẹ ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì; láti fẹ́ràn ìhìnrere Rẹ̀ àti Ìjọ Rẹ̀; láti múrasílẹ̀ fún ìgbé ayé àwọn àṣàyàn òdodo. Ní tòótọ́, èyí ni ètò Ọlọ́run fún àwọn òbí.
Sátánì yío takò yín, dààmú yín, yío gbìyànjú láti mú yín rẹ̀wẹ̀sì.
Ṣùgbọ́n olukúlùkù ọmọ ti gba Ìmọ́lẹ̀ Krístì bí ìlà tààrà kan sí ọ̀run. Olùgbàlà yío sì ràn yín lọ́wọ́, yío tọ́ yín, yío sì fún yín ní ìgboyà. Ẹ Wá Ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀. Ẹ béèrè lọ́wọ́ Olúwa.
Gẹ́gẹ́bí Jésù Krístì ti jẹ́ okun àwọn ọ̀dọ́, Jésù Krístì jẹ́ okun awọn òbí bákannáà.
Ó Nmú Ìfẹ́ Tóbi
Nígbà mĩràn a le ro bóyá ẹnìkan mĩràn bá le dára jùlọ láti tọ́ àti láti kọ́ àwọn ọmọ wa. Ṣùgbọ́n bí ó ti wù kí ẹ ní ìmọ̀lára àìkún ojú òsùnwọ̀n tó, ẹ ní ohun kan tí ó mú yín yege ní àrà ọ̀tọ̀: ìfẹ́ yín fún ọmọ yín.
Ìfẹ́ obí kan fún ọmọ jẹ́ ọ̀kan lára ipá tó lágbára jùlọ ní gbogbo àgbáyé. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun díẹ̀ ní orí ilẹ̀ ayé yi tí ó le jẹ́ ti ayérayé ní tòótọ́.
Nísisìyí, bóyá o ní ìmọ̀lára pé ìbáṣepọ̀ rẹ pẹ̀lú ọmọ rẹ kéré ju bí ó ti yẹ lọ Èyí ni ibití agbára Olùgbàlà ti nwọlé wá. Ó nwo aláìsàn sàn, Ó sì le wo àwọn ìbáṣepọ̀ sàn. Ó sọ àkàrà àti ẹja di púpọ̀, Ó sì le sọ ìfẹ́ àti ayọ̀ di púpọ̀ nínú ilé yín.
Ifẹ́ yín fún àwọn ọmọ yín nṣe ẹ̀dá àyíká alárinrin kan fún kíkọ́ni ní òtítọ́ àti mímú ìgbàgbọ́ dàgbà. Ẹ ṣe ibùgbé yín ní ilé àdúrà, ìkọ́ni, àti ti ìgbàgbọ́; ilé àwọn ìrírí aláyọ̀, ibi jíjẹ́ ti ẹni, ilé Ọlọ́run.5 Àti kí ẹ “gbàdúrà sí Bàbá pẹ̀lú gbogbo agbára tí ó wà nínú yín, pé kí [ẹ̀yin] le kún fún ìfẹ́ [Rẹ̀], inú yín, èyítí ó ti fi [jínkí] … àwọn atẹ̀lé Ọmọ rẹ̀, Jésù Krístì.”6
Ó Nmú Àwọn Aápọn Kékeré àti Rírọrùn Tóbi.
Okun mĩràn tí ẹ ní, bí òbí, ni ànfàní fún ipá ojoojúmọ́, tí ó ntẹ̀síwájú. Àwọn ọ̀gbà, àwọn olùkọ́, àti àwọn ìròhìn tó nlo ipá nwá wọ́n sì nlọ. Ṣùgbọ́n ìwọ le jẹ́ ipá kan tó dúró lemọ́lemọ́ jùlọ nínú ìgbé ayé ọmọ rẹ.
Àwọn aápọn yín le dàbí pé ó kéré ní àfiwé sí àwọn ohùn aláriwo tí àwọn ọmọ yín ngbọ́ nínú ayé. Nígbàmíràn, ó le dà bí ẹnipé ẹ kò ṣe àṣeyọrí púpọ̀. Ṣùgbọ́n ẹ rántí pé “nípa ọ̀nà kékeré Olúwa lè mú àwọn ohun nlá wá.”7 Ìpàdé ìrọ̀lẹ́ nílé kan, ìbánisọ̀rọ̀ ìhìnrere kan, tàbí àpẹrẹ rere kan le má yí ayé ọmọ rẹ padà ní ojú ẹ̀sẹ̀, ju bí ìkán òjò kan yío ṣe mú kí irúgbìn dàgbà lójú ẹ̀sẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn nkan kékeré àti rírọrùn lemọ́lemọ́, ọjọ́ lẹ́hìn ọjọ́, nṣe ìtọ́jú àwọn ọmọ yín dára púpọ̀ ju ọ̀pọ̀ rẹ̀ ní ẹ̀kọ̀ọ̀kan.8
Èyí ni ọ̀nà Olùwa.” Ó nbá ẹ̀yin àti ọmọ yín sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ohùn jẹ́jẹ́, kékeré, kìí ṣe ohùn ààrá.9 Ó wo Námánì sàn kíì ṣe nípasẹ̀ “àwọn ohun nlá kan” ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ìṣe ìwẹ̀ títúnwẹ̀, rírọrùn.10 Àwọn ọmọ Israẹlì gbádùn àpèjẹ awó nínú aginjù, ṣùgbọ́n ohun tó pa wọ́n mọ́ ní ààyè ni ìyanu kékeré àti rírọrùn ti mánà—oúnjẹ òòjọ́ wọn.11
Ẹyin arákùnrin àti ẹyin arábìnrin, oúnjẹ òòjọ́ máa njẹ́ pípèsè àti pípínfúnni dára jùlọ nínú ibùgbé. Ìgbàgbọ́ àti ẹ̀rí máa njẹ́ títọ́jú dára jùlọ ní àwọn ọ̀nà tó wọ́pọ̀ àti àdánidá, gígé kan ní àkókò kan, ní àwọn àk/pkò kékeré àti rírọrùn, nínú ìṣàn lemọ́lemọ́ ti ìgbé ayé ojojúmọ́.12
Gbogbo àkókò jẹ́ àkókò ìkọ́ni. Ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan àti ìṣe lè jẹ́ ìtọ́sọ́nà fún ṣíṣe àṣàyàn.13
Ẹ le má rí àwọn ipa ojú ẹsẹ̀ ti àwọn aápọn yín. Ṣùgbọ́n ẹ máṣe sọ ìrètí nù. “Ohun gbogbo gbọ́dọ̀ wá sí ìmúṣẹ ní àkokò tiwọn,” ni Olúwa sọ. “Nítorínáà, ẹ máṣe kãrẹ̀ ní rere síṣe, nítorí [ẹyin] nfi ìpìlẹ̀ iṣẹ́ nlá kan lélẹ̀.”14 Iṣẹ́ wo ni ó le tóbi ju ríran àwọn ọmọ iyebíye Ọlọ́run lọ́wọ́ láti kọ́ nípa enití wọ́n jẹ́ gan-an àti láti fi ìgbàgbọ́ wọn sí inú jésù Krístì, ìhìnrere Rẹ̀, àti Ìjọ Rẹ̀? Jésù Krístì yío bùkún yín yío sì mú àwọn aápọn lemọ́lemọ́ yín tóbi.
Ó Nfúnni ní Ìfihàn
Ọ̀nà tó lágbára mĩràn ti Olúwa fi nti àwọn òbí lẹ́hìn ni nípasẹ̀ àìláfiwé ẹ̀bùn ìfihàn ti ara ẹni. Olúwa nyára láti tú Ẹ̀mí Rẹ̀ jáde láti tọ́ àwọn òbí sọ́nà.
Bí ẹ ti nkún fún àdúrà tí ẹ sì nfura sí Ẹmí, Òun yío kìlọ̀ fún yín nípa àwọn ewu tó farapamọ́.15 Òun yío fi àwọn ẹ̀bùn, àwọn okun, àti àwọn aníyàn àwọn ọmọ yín tí wọn kò sọ jáde hàn.16 Ọlọ́run yío ràn yín lọ́wọ́ láti rí àwọn ọmọ yín bí Òun ti rí wọn—tayọ ìfarahàn lóde wọn àti sí inú ọkàn wọn.17
Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, ẹ le kọ́ láti mọ àwọn ọmọ yín ní ọ̀nà mímọ́ àti ti ọ̀run. Mo pè yín láti gba ìfilélẹ̀ Ọlọ́run láti tọ́ ẹbí yín nípa ìfihàn ara ẹni. Ẹ wá ìtọ́ni Rẹ̀ nínú àwọn àdúrà yín.18
Ìyípadà Nla Kan
Bóyá ìrànlọ́wọ́ tó ṣe pàtàkì jùlọ tí Jésù Krístì fi lélẹ̀ fún àwọn òbí ni “ìyípadà nlá” nínú ọkàn yín.19 Ó jẹ́ ìyanu tí olúkúlùkù ẹnìkọ̀ọ̀kan wa nílò.
Fún ìṣẹ́jú díẹ̀ kan, ẹ fi ojú inú wo ipò yí: Ẹ wà ní ilé ìjọsìn, tí ẹ ngbọ́ ọ̀rọ̀ kan nípa àwọn ẹbí. Olùsọ̀rọ̀ náà ṣe àpújúwe ibùgbé pípé kan àti ẹbí tí ó tilẹ̀ jẹ́ pípé síi. Ọkọ àti aya kò jà rí. Àwọn ọmọ máa ndáwọ́ kíka àwọn ìwé mímọ́ wọn dúró nígbàtí ó bá tó àkókò láti ṣe iṣẹ́ àmúrelé nìkan. Orin “Ẹ Fẹ́ràn Ara Yín”20 sì ndún ní abẹ́lẹ̀. Kí olùsọrọ̀ náà tó dé abala ibití gbogbo wọn ti darapọ̀ ní fífi ọ̀yàyà fọ baluwẹ̀, ẹ ti nro sínú pé, “Ẹbí mi kò ní ìrètí.”
Ẹyin arákùnrin àti arábìnrin, ẹ sinmi! Olúkúlùkù ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú ìpéjọpọ̀ náà nro ohun kannáà! Òtítọ́ ni pé, gbogbo àwọn òbí nṣe àníyàn nípa àìjẹ́ dídára tó.
Ní oríre, orísun ìrànlọ́wọ́ àtọ̀runwá kan wà fún àwọn òbí: ó jẹ́ Jésù Krístì. Òun ni orísun ìyípadà ọkàn nlá wa.
Bí ẹ ti nwa súnmọ́ Olùgbàlà àti àwọn ìkọ́ni Rẹ̀ síi, Òun yío fi àìlera yín hàn yín. Bí ẹ bá gbẹ́kẹ̀lé Jésù Krístì pẹ̀lú ọkàn ìrẹ̀lẹ̀, Òun yío sọ àwọn ohun aláìlágbára di alágbára.20 Òun ni wòlíì Ọlọ́run.
Njẹ́ èyí túmọ̀ sí pé a ó rí ẹ̀yin àti ẹbí yín bíi pípé? Rárá. Ṣùgbọ́n ẹ ó dára síi. Nípasẹ̀ ore ọ̀fẹ́ Olùgbàlà, díẹ̀ díẹ̀, ẹ ó mú àwọn ìhúwàsí tí àwọn òbí nílò dàgbà; ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti àwọn ọmọ Rẹ̀, sùúrù, àìmọti-araẹni-nìkan, ìwà pẹ̀lẹ́, àti ìgboyà láti ṣe ohun tó tọ́
Jésù Krístì ṣe Ìfilélẹ̀ Àtìlẹ́hìn nípasẹ̀ Ìjọ Rẹ̀.
Aápọn láti mú ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì dàgbà jẹ́ ti ààrin ilé, tí ó fojúsùn sí orí ẹnìkọ̀ọ̀kan. Ó sì jẹ́ èyítí Ìjọ ntìlẹ́hìn. Yàtọ̀ sí àwọn ìwé mímọ́ àti àwọn ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì tó jẹ́ mímọ́, Ìjọ Olùgbàlà fi àwọn ohun èlò púpọ̀ lélẹ̀ láti ran àwọn òbí àti àwọn ọmọ lọ́wọ́ ní síṣe àwọn yíyàn òdodo:
-
Fún Okun àwọn Ọ̀dọ́: Ìtọ̀nisọ́nà kan fún Ṣíṣe àwọn Àṣàyàn kò fún yín ní ìtòsílẹ̀ ṣeé àti má ṣeé. Ó kọ́ni ní àwọn òtítọ́ ayérayé láti ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àṣàyàn dídá lórí àwọn ìkọ́ni ìgbé ayé Jésù Krístì. Ẹ kà á pẹ̀lú àwọn ọmọ yín. Ẹ jẹ́kí wọn ó sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní àwọn òtítọ́ ayérayé àti òtítọ́ ti ọ̀run wọ̀nyí láti tọ́ àwọn àṣàyàn wọn sọ́nà.21
-
Àwọn ìpàdé àpapọ̀ FSY jẹ́ ohun èlò ìyanu mĩràn. Mo ní ìrètí pé olukúlùkù ọ̀dọ́ yío wà níbẹ̀. Mo pe àwọn ọ̀dọ́ langba ànìkanwà láti darapọ̀ mọ́ àwọn ìpàdé àpapọ̀ wọ̀nyí bíi àwọn akọ́ni àti olùdámọ̀ràn. Mo pe àwọn òbí láti kọ́ lé orí ìtara ti ẹ̀mí tí àwọn ọmọ wọn bá mú wá sí ilé láti àwọn ìpàdé àpapọ̀ FSY.
-
Àwọn ọmọdé àti ọ̀dọ́ nínú Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn ní àwọn olùkọ́, àwọn olùdarí, àti àwọn akọ́ni. Nígbà púpọ̀ ẹ nwọ inú ìgbé ayé ọ̀dọ́ ènìyàn kan ní àkókò tó ṣe kókó láti mú ìgbàgbọ́ àti ẹ̀rí dàgbà àti láti ṣe àtìlẹ́hìn. Àwọn kan nínú yín jẹ́ àgbà ànìkanwà. Ẹyin kan kò ní àwọn ọmọ ti ara yín. Iṣẹ́-ìsìn aláyọ̀ yín sí àwọn ọmọ Ọlọ́run jẹ́ mímọ́ ní ojú Ọlọ́run.22
Ẹ Máṣe Sọ Ìrètí Nù lóri Iṣẹ́ Ìyanu náà
Ẹyin ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, mímú ìgbàgbọ́ dàgbà nínú ọmọ kan fi díẹ̀ dàbíi ríran òdòdó kan lọ́wọ́ láti dàgbà. Ẹ kò le fa igi rẹ̀ sókè láti mú un ga síi. Ẹ kò le ṣí àpò ìtànná rẹ̀ láti mú kí tètè tú yẹ́yẹ́. Ẹ kò sì le ṣe àìtọ́jú òdòdó náà kí ẹ sì retí rẹ̀ láti dàgbà tàbí kí ó ṣe dáradára nígbà-kannáà.
Ohun tí ẹ le ṣe tí ẹ sì gbọdọ̀ ṣe fún ìran tí ó ńdìde ní pípèsè ilẹ̀ dáradára, ọlọ́ràá, pẹ̀lú ọ̀nà sí omi ti ọ̀run tí ó nṣàn. Ẹ mú àwọn koríko àti ohunkóhun tí ó le dènà ìtànṣàn òòrùn kúrò. Ẹ ṣe ẹ̀dá àwọn ipò dídára jùlọ tí ó ṣeéṣe fún dídàgbà. Pẹ̀lú sùúrù ẹ fi ààyè gba àwọn ìran tí ó ńdìde láti ṣe àwọn yíyàn tó ní ìmísí, kí ẹ sì jẹ́kí Ọlọ́run ṣe iṣẹ́ ìyanu Rẹ̀. Àbájáde yío jẹ́ rírẹwà jù àti yíyanilẹ́nu jù àti aláyọ̀ ju ohunkóhun tí ẹ kàn le ṣe láti ọwọ́ ara yín.
Nínú ètò Baba Ọrun, àwọn ìbáṣepọ̀ àwọn ẹbí jẹ́ níní lọ́kàn láti jẹ́ fún ayérayé. Èyí ni ìdí tí, bí òbí, ẹ kò le sọ ìrètí nù láé, àní bí ẹ kò tilẹ̀ le yangàn nípa bí àwọn nkan ti lọ nígbà kan sẹ́hìn.
Pẹ̀lú Jésù Krístì, Ọgá Olùwòsàn, nígbà gbogbo ni ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun kan le wà; nígbà gbogbo ni ìrétí wà.
Jésù Krístì ni okun awọn ẹbí.
Jésù Krístì ni okun awọn ọdọ́.
Jésù Krístì ni okun awọn òbí.
Nípa èyí ni mo jẹ́ ẹ̀rí ni orúkọ Jésù Krístì, àmín.