Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Lẹ́hìn Ọjọ́ Kẹ́rin Náà
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2023


Lẹ́hìn Ọjọ́ Kẹ́rin Náà

Bí a ti nlọ síwájú pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, ọjọ́ kẹ́rin yíò wá nígbàgbogbo. Òun yíò wá nígbàgbogbo láti ràn wá lọ́wọ́.

Bí a ti rán wa létí ní òwúrọ̀ yí, lónìí ni Ìsinmi Ọpẹ, tí ó nsàmìsi ìwọlé bí aṣẹ́gun ti Olùgbàlà sí Jerusalemu àti ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀sẹ̀ mímọ́ náà tí ó ṣáájú Ètùtù nlá Rẹ̀, tí yíò ní ìjìyà Rẹ̀, Ìkànmọ́ àgbélèbú, àti Àjíǹde nínú.

Kò pẹ́ púpọ̀ ṣaájú wíwọlé Rẹ̀ sí inú ìlú náà tí a ti sọtẹ́lẹ̀, Jésù Krístì nkópa ní kíkún nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ nígbà tí Ó gba ọ̀rọ̀ látọ̀dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ Rẹ̀ ọ̀wọ́n Maria àti Marta pé arákùnrin wọn Lásárù nṣàìsàn.1

Bótilẹ̀jẹ́pé àìsàn Lásárù le gan-an, Olúwa “gbé ọjọ́ méjì sí i ní ibi kan náà tí ó wà. Nígbànáà lẹ́hìn èyí ni ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ pé, Ẹ jẹ́ kí á tún lọ sí Jùdéà.”2 Kí ó tó bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò náà lọ sí ilé àwọn ọ̀rẹ́ Rẹ̀ ní Bẹ́tánì, “Jésù sọ fún wọn ní gbangba pé, Lásárù ti kú.”3

Nígbà tí Jésù wá sí Bẹ́tánì tó sì kọ́kọ́ pàdé Màtá àti Màríà—bóyá nítorí ìbànújẹ́ nítorí pípẹ́ dé Rẹ̀—wọ́n sì kí i pé, “Olúwa, ìbá ṣe pé o ti wà níbí, arákùnrin mi kì bá tí kú.”4 Màtá tún sọ síwájú pé: “Ní àkókò yìí, ó nrùn: nítorí ó ti kú fún ọjọ́ mẹ́rin.”5

Àwọn ọjọ́ mẹ́rin yìí ṣe pàtàkì lójú Màríà àti Màtá. Gẹ́gẹ́ bí èrò tí àwọn ilé-ìwé rábì kan, wọ́n gbà gbọ́ pé ẹ̀mí ẹnìkan tó kú yíò wà, nínú ara fún ọjọ́ mẹ́ta, tí ó sì nfúnni ní ìrètí pé wíwà láàyè ṣì ṣeé ṣe. Síbẹ̀síbẹ̀, nígbàtí ó fi di ọjọ́ kẹ́rin ìrètí náà ti sọnù, bóyá nítorípé ara náà yíò ti bẹ̀rẹ̀ síí jẹrà tí yíó sì máa rùn.”6

Mary àti Martha wà ní ipò àìníìrètí. “Njẹ́ nígbàtí Jésù rí [Mary] tí ó nsọkún, … ó kérora ní ọkàn rẹ̀, inú rẹ̀ sì bàjẹ́,

“O sì wípé, Níbo ni ẹ̀yin gbé tẹ́ ẹ sí? Wọ́n wí fún un pé, Olúwa, wá kí o sì ríi.”7

Ní àkókò yìí ni a rí ọ̀kan lára ​​àwọn iṣẹ́ ìyanu nlá ní àkokò iṣẹ́ ìránṣẹ́ Olùgbàlà ní ayé kíkú. Ní àkọ́kọ́ Olúwa wípé, “Ẹ gbé òkúta náà kúrò.”8 Lẹ́hìnnáà, lẹ́hìn tí ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Baba Rẹ̀, “ó kígbe lóhun rara pé, Lásárù, jáde wá.

“Ẹni tí ó ti kú náà sì jáde wá, tí a fi aṣọ sàréè dìí lọ́wọ́ àti ẹsẹ̀: a sì fi gèlè dìí lójú. Jésù wí fún wọn pé, Ẹ tú u, ẹ jẹ kí ó lọ.”9

Bíi Màríà àti Màtá, a ní ànfàní láti ní ìrírí gbogbo ti-ikú, àní ìbànújẹ́10 àti àìlera.11 Ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yíò ní ìrírí ìrora ọkàn tí ó tẹ̀lé ikú ẹnìkan tí a fẹ́ràn. Ìrìn-àjò ti-ikú wa lè ní àìsàn ti araẹni tàbí àìsàn líle ti olùfẹ́ kan; ìbànújẹ́, àníyàn, tàbí àwọn ìpèníjà ìlera ọpọlọ míràn; ìnira owo; dídalẹ̀; ẹ̀ṣẹ̀ nínú. Àti nígbà míràn ìwọ̀nyí máa nwá pẹ̀lú àwọn ìmọ̀lára àìnírètí. Èmi kò yàtọ̀. Bí ẹ̀yin, mo ti ní ìrírí ìpàdánù àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpèníjà tí a lè retí nínú ayé yìí. Mo fà sí àkọọ́lẹ̀ yí nípà Olùgbàlà àti ohun tí ó nkọ́ mi nípa ìbáṣepọ̀ wa pẹ̀lú Rẹ̀.

Ní àkokò àwọn àníyàn wa tí ó tóbì jùlọ, àwa, bíi Maria ati Marta, wá Olùgbàlà tàbí bèèrè lọ́wọ́ Baba fún ìdásí àtọ̀runwá Rẹ̀. Ìtàn Lásárù kọ́ wa ní àwọn ìlànà tí a lè múlò sí ìgbésí ayé tiwa bí a ṣe nkojú àwọn ìpèníjà ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.

Nígbàtí Olùgbàlà dé Bẹ́tánì, gbogbo wọn ti sọ ìrètí nù pé Lásárù lè rí ìgbàlà—ọjọ́ mẹ́rin ti pé, òun sì ti lọ. Nígbà míràn ní àkokò àwọn ìpèníjà ti wa, a lè nímọ̀lára pé Krístì ti pẹ́ jù, àti pé ìrètí àti ìgbàgbọ́ wa pàápàá lè ní ìmọ̀làra ìpèníjà. Ẹlẹrí àti ẹ̀rí mi ni pé bí a ṣe ntẹ̀ síwájú pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, ọjọ́ kẹrin yíò ma fi ìgbà gbogbo wá. Òun yíò fi ìgbà gbogbo wá fún ìrànlọ́wọ́ wa tàbí láti gbé àwọn ìrẹ̀tí wa padà sí ààyè. Ó ti ṣèlérí:

“Ẹ máṣe jẹ́ kí ọkàn yín kí ó dàmú.”4

“Èmi kì yíò fi yín sílẹ̀ ní aláìní olùtùnú: Èmi yíó tọ̀ yín wá.”13

Àti nígbà míràn ó lè dàbí i pé Òun kò wá bá wa títí di ọjọ́ kẹ́rin bí àpèjúwe, lẹ́hìn tí gbogbo ìrètí dàbí i pé ó sọnù. Ṣùgbọ́n kílódé tí ó pẹ́ bẹ́ẹ̀? Ààrẹ Thomas S. Monson kọ́ni pé, “Baba wa Ọ̀run, ẹni tí ó fún wa ní ohun púpọ̀ láti ní inú dídùn sí, mọ̀ bákannáà pé a nkọ́ ẹ̀kọ́ a sì ndàgbà a sì nlágbára sí i bí a ṣe ndojú kọ tí a sì nla àwọn àdánwò tí a gbọ́dọ̀ là kọjá.”14

Wòlíì Joseph Smith pàápàá dojúkọ ìrírí ọjọ́ kẹrin nlá kan. Rántí ẹ̀bẹ̀ rẹ? “Áà Ọlọ́run, níbo ni ìwọ wà?” Àti pé níbo ni àgọ́ ti o bo ibi ìpamọ́ rẹ wà?”15 Bí a ti ngbọ́kànlé E, a lè retí ìdáhùn bíi: “Ọmọkùnrin mi [tàbí obìnrin], àlàáfíà fún ọkàn rẹ; àwọn ìrora rẹ àti àwọn ìpọ́njú rẹ yíò jẹ́ fún ìgbà díẹ̀.”16

Ọ̀rọ̀ míràn tí a tún lè kọ́ nínú ìtàn Lásárù ní ipa tí àwa fúnra wa lè kó nínú dídásí àtọ̀runwá tí à nwá. Nígbà tí Jesu súnmọ́ ibojì náà, ó kọ́kọ́ sọ fún àwọn tí ó wà níbẹ̀ pé, “Ẹ gbé òkúta náà kúrò.”17 Pẹ̀lú agbára tí Olùgbàlà ní, njẹ́ Òun kì bá ti lè gbé òkúta náà kúrò lọ́nà ìyanu láìsí ìgbìyànjú bí? Èyí ì bá jẹ́ ìwúrí láti rí àti ìrírí mánigbàgbé, síbẹ̀ Ó sọ fún àwọn yòókù pé, “Ẹ gbé òkúta náà kúrò.”

Èkejì, Olúwa “kígbe lóhun rara pé, Lásárù, jáde wá.”18 Njẹ́ kì yíò dùmọ́ni síi bí Olúwa fúnrarẹ̀ bá ti fi ìyanu gbé Lásárù sí ẹnu-ọ̀nà kí ó ba lè jẹ́ rírí fún ogunlọ́gọ̀ náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nígbàtí a bá gbé òkúta náà kúrò?

Ìkẹta, nígbàtí Lásárù jáde wá, a “fi aṣọ ibojì dì í lọ́wọ́ àti ẹsẹ̀, a sì fi gèlè dì í lójú. Jésù wí fún wọn pé, Ẹ tú u, ẹ jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ lọ.”19 Mo ní ìdánilójú pé Olúwa lágbára láti mú Lásárù dìde ní ẹnu ọ̀nà náà, tí a ṣe ní mímọ́ tẹ́lẹ̀ tí ó sì ṣee súnmọ́, pẹ̀lú àwọn aṣọ ibojì rẹ tí a ṣẹ léra dáradára.

Kíni kókó fífi àwọn apákan wọ̀nyí hàn? Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn nkan mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí ní ohun kan papọ̀—kò sí èyí tí ó béèrè fún lílo agbára àtọ̀runwá ti Krístì. Ohun tí àwọn ọmọẹ̀hìn rẹ̀ lè ṣe, ó pàṣẹ fún wọn láti ṣe é. Ó dájú pé àwọn ọmọ-ẹ̀hìn náà lè gbé òkúta náà fúnra wọn; Lásárù, lẹ́hìn jíji dìde, ó ní agbára láti dúró làti fi ara rẹ̀ hàn ní ẹnu ṣíṣí ihò; àwọn tó fẹ́ràn Lásárù sì lè ràn án lọ́wọ́ gan-an láti bọ́ àwọn aṣọ ibojì náà kúrò.

Síbẹ̀síbẹ̀, Krístì nìkan ní ó ní agbára àti àṣẹ láti jí Lásárù dìde kúrò nínú okú. Ìmọ̀lára mí ni pé Olùgbàlà nretí wa láti ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe, àti pé Òun yíò ṣe ohun tí Òun nìkanlè ṣe.20

A mọ̀ pé “ìgbàgbọ́ [nínú Olúwa Jésù Kristi] jẹ́ ìlànà ìṣe”21 àti pé “àwọn iṣẹ́ ìyanu kì í mú ìgbàgbọ́ jáde, ṣùgbọ́n ìgbàgbọ́ tí ó lágbára ni a mú dàgbà nípa ìgbọràn sí ìhìnrere Jésù Kristi. Ní ọ̀nà míràn, ìgbàgbọ́ nwá nípa ìṣòdodo.”22 Bí a ṣe nlàkàkà láti ṣe ìṣe òdodo nípa dídá àti pípa àwọn májẹ̀mú mímọ́ mọ́ àti mímú ẹ̀kọ́ Krístì lò nínú ìgbésí ayé wa, ìgbàgbọ́ wa kì yíò tó láti gbé wa dé ọjọ́ kẹrin nìkan, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olúwa a ó ní agbára láti gbé àwọn òkúta tí wọ́n wà ní ipa ọ̀nà wa, tí ó ndìde láti ara àìnírètí, àti ní títú ara wa sílẹ̀ kúrò nínú ohun gbogbo tí ó dè wá. Nígbàtí Olúwa nretí wa láti “ṣe ohun gbogbo tí ó wà ní agbára wa,”23 ẹ rántí pé Óun yíò pèsè ìrànlọ́wọ́ ti a nílò nínú gbogbo nkan wọ̀nyí bí a ṣe ngbẹ́kẹ̀lé E.

Báwo ni a ṣe lè gbé àwọn òkúta kí á sì kọ́lé sí orí àpáta Rẹ̀?24 A lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àwọn wòlíì.

Fún àpẹrẹ, Ààrẹ Russell M. Nelson ní oṣù kẹwa tó kọjá bẹ̀ wá láti máa bójú tó àwọn ẹ̀rí àwa fúnra wa nípa Olùgbàlà àti ìhìnrere Rẹ̀, láti ṣiṣẹ́ fún wọn àti láti tọ́ wọn dàgbà, láti fi òtítọ́ bọ́ wọn, àti láti yẹra fún sísọ wọ́n di elẽrí pẹ̀lú àwọn ìmọ̀ ọgbọ́n orí àwọn aláìgbàgbọ́. . Ó ṣèlérí fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa pé, “Bí ẹ̀yin ti fi fífún ẹ̀rí yín nípa Jésù Krístì lókun títí lọ ṣe ohun pàtàkì jùlọ, ẹ wò fún àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó máa ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé yín.”25

A lè ṣe èyí!

Báwo la ṣe lè dìde lọ́nà ìṣàpẹrẹ, ká sì jáde wá? A lè fi pẹ̀lú ayọ̀ ronúpìwàdà kí a sì yàn láti gbọ́ràn sí àwọn òfin. Olúwa wípé, “Ẹnití ó bá ní àwọn òfin mi, tí ó sì pa wọ́n mọ́, òun ni ẹnití ó fẹ́ràn mi: ẹnití ó bá sì fẹ́ràn mi, Baba mi yíò fẹ́ràn rẹ̀, Èmi ó sì fẹ́ràn rẹ̀, èmi ó sì fi ara mi hàn fún un.”26 A lè gbìyànjú láti ronúpìwàdà lójoojúmọ́ kí a sì máa fi ayọ̀ tẹ̀síwájú pẹ̀lú ọkàn tí ó fẹ́ tí ó kún fún ìfẹ́ fún Olúwa.

A lè ṣe èyí!

Báwo ni a ṣe lè, pẹ̀lu ìrànlọ́wọ́ Olúwa, tú ara wa kúrò nínú gbogbo ohun tí ó dè wa? A lè mọ̀ọ́mọ̀ dè ara wa lákọ̀ọ́kọ́ sí Baba wa Ọ̀run àti Ọmọ Rẹ̀, Jésù Krístì, nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú. Alàgbà D. Todd Christofferson kọ́ni pé: “Kí ni orísun agbára ìwà rere àti ti ẹ̀mí [wa] báwo, la sì ṣe lè ri gbà? Orísun náà ni Ọlọ́run. Ọ̀nà wa sí agbára náà jẹ́ nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú wa pẹ̀lú Rẹ̀. Nínú àwọn àdéhùn àtọ̀runwá wọ̀nyí, Ọlọ́run dè ara Rẹ̀ láti gbé wa dúró, sọ wá di mímọ́, àti láti gbé wa ga ní àṣepadà fún ìfaramọ́ wa láti sìn Ín àti láti pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́.”27 A lè ṣe kí à sì pa àwọn májẹ̀mú mímọ́ mọ́.

A lè ṣe èyí!

“Ẹ gbé òkúta náà kúrò.” “Jáde wa.” “Tu sílẹ̀, jẹ́ kí ó lọ.”

Àwọn ìmọ̀ràn, àwọn òfin, àti àwọn májẹ̀mú. A lè ṣe èyí!

Alàgbà Holland ti ṣèlérí pé, “àwọn ìbùkún kan nwá kíákíá, àwọn kan npẹ́ láti wá, àwọn kan kò ní wá títí di ọ̀run; ṣùgbọ́n fún àwọn wọnnì tí wọ́n gba ìhìnrere ti Jésù Krístì mọ́ra, wọn nwá.”28

Àti níkẹhìn, “Nítorínáà, ẹ tújúká, ẹ máṣe bẹ̀rù, nítorí Èmi Olúwa wà pẹ̀lú yín, Èmi yíò sì dúró tì yín.”29

Èyí ni ijẹri àti ẹ̀rí mi, ní orúkọ mímọ́ ti Ẹni náà tí yíò wá nígbàgbogbo, àní Jésù Krístì, Amin.

Àwọn Àkọsílẹ̀ ránpẹ́

  1. Wo Jòhánù 11:3.

  2. Jòhánù 11:6–7.

  3. Jòhánù 11:14.

  4. Jòhánù 11:21, 32.

  5. Jòhánù 11:39.

  6. “Ọkàn naa, gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ Júù, dúró ní agbègbè ara ní ọjọ́ mẹ́ta lẹ́hìn ikú. Gẹ́gẹ́ bí ìdánilójú àwọn Júù, nítorí náà, jíjí ẹni tí ó kú dìde kò ṣeé ṣe ní ọjọ́ kẹrin, níwọ̀n bí ọkàn kì yóò ti tún wọnú ara tí ó ti yí ipò rẹ̀ padà. Ó wúni lórí gan-an fún àwọn ẹlẹ́rìí iṣẹ́ ìyanu tí Jésù jí Lásárù dìde ní ọjọ́ kẹrin. Nípa bẹ́ẹ̀, ọjọ́ kẹrin ní ìtumọ̀ àkànṣe kan níhìn-ín a sì gbà á lọ́kàn mọ́ra láti ọ̀dọ̀ atúmọ̀ èdè fún ìlò ní ìsopọ̀ pẹ̀lú títóbi jùlọ nínú gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu àjíǹde.” ( Ernst Haenchen, Jòhánnù 2: Ọrọìwòye lórí Ìhìnrere ti Jòhánnù, Àwọn orí 7–21ed. Robert W. Funk ati Ulrich Busse, trans. Robert W. Funk [1984], 60–61).

  7. Jòhánù 11:33-36.

  8. Jòhánù 11:39.

  9. Jòhánù 11:43–44.

  10. Wo Mósè 4:22–25.

  11. Wo Étérì 12:27

  12. Jòhánù 14:6.

  13. Jòhánù 14:18.

  14. Thomas S. Monson,“Èmi Kò Ní Já Ọ kulẹ̀, tàbí Kọ̀ Ọ́ Sílẹ̀,” LàìhónàOṣù kọkànla 2013, 87. Ààrẹ Monson tún ṣàlàyé síwájú sí i: “A mọ̀ pé àwọn àkókò kan wà tí a ó ní ìrírí ìbànújẹ́ tí ń bani nínú jẹ́, nígbàtí a yíò ṣọ̀fọ̀, àti nígbàtí a lè dán wa wò dé ààlà wa. Síbẹ̀síbẹ̀, irú àwọn ìṣòro bẹ́ẹ̀ ń jẹ́ kí a yí padà sí rere, láti tún ìgbésí-ayé wa kọ́ ní ọ̀nà tí Baba wa Ọ̀run ti ń kọ́ wa, àti láti di ohun tí ó yàtọ̀ sí ohun tí a jẹ́—dara ju tiwa lọ, òye ju tiwa lọ, oníyọ̀ọ́nú ju àwa lọ. wà, pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tí ó lágbára jù tí a ti ní tẹ́lẹ̀ lọ” (“Èmi Kò Ní Já Ọ kulẹ̀, tàbí Kọ̀ Ọ́ Sílẹ̀,” 87). Wo bákanáà Ẹ̀kọ́ ati Àwọn Májẹ̀mú 84:119: “Nitori Emi, Oluwa, ti na ọwọ mi lati fi awọn agbara ọrun ṣiṣẹ; ẹnyin ko le ri i nisisiyi, nigba diẹ si i, ẹnyin o si ri i, ẹnyin o si mọ̀ pe emi wà, ati pe emi o wá.

    Bákannáà wo Mosiah 23:21–24:

    “Bíótilẹ̀ríbẹ̃, Olúwa rí i pé ó tọ́ láti bá àwọn ènìyàn rẹ̀ wí; bẹ̃ni, òun dán sũrù nwọn àti ìgbàgbọ́ nwọn wò.

    “Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀—ẹnikẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀ lé e kan náà ni a ó gbé sókè ní ọjọ́ ìkẹhìn. Bẹ̃ni, báyĩ ni ó sì rí fún àwọn ènìyàn yí.

    “Nítorí kíyèsĩ, èmi yíò fihàn yín pé a mú nwọn wá sínú oko-ẹrú, kò sì sí ẹni nã tí ó lè gbà nwọ́n àfi Olúwa Ọlọ́run nwọn, bẹ̃ni, àní Ọlọ́run Ábráhámù àti Ísãkì àti ti Jákọ́bù.

    “Ó sì ṣe, tí ó gbà nwọ́n, ó sì fi agbára nlá rẹ̀ hàn sí wọ́n, púpọ̀ sì ni àjọyọ̀ nwọn.”

  15. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 121:1.

  16. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 121:7.

  17. Jòhánù 11:39.

  18. Jòhánù 11:43.

  19. Jòhánù 11:44.

  20. Ààrẹ Nelson sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà, àwọn olùdámọ̀ràn mi àti èmi ti máa nwo nínú ojú omije bí Ó ṣe nbẹ̀bẹ̀ nínú àwọn ipò tí ó le gan-an lẹ́hìn tí a ti ṣe gbogbo ohun tí a lè ṣe tí a kò sì lè ṣe mọ́. Ẹnu ya gbogbo wa nítòótọ́” (“Ọ̀rọ̀ Ìkínni-káàbọ̀,” Làìhónà, Oṣù karun 2021, 6).

  21. Ìwé-ìtumọ̀ Bíbélì, “Ìgbàgbọ́.”

  22. Ìtọ́sọ́nà sí Ìwé Mímọ́, “Ìgbàgbọ́,” scriptures.ChurchofJesusChrist.org.

  23. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 123:17.

  24. Wo 3 Néfì 11:32–39.

  25. Russell M. Nelson, “Ẹ Ṣẹ́gun Ayé kí ẹ sì Rí Ìsinmi,” LàìhónàOṣù kọkànlá 2022, 97.

  26. Jòhánù 14:21.

  27. D. Todd Christofferson, “Agbára ti àwọn Májẹ̀mú,” LàìhónàOṣù karun 2009, 20.

  28. Jeffrey R. Holland, “Àlùfáà Gíga Ti Ohun Rere Tó Nbọ̀,” Làìhónà, Oṣù kínní 2000, 45.

  29. Ẹ̀kọ́ àti Àwọn Májẹ̀mú 68:6.

Tẹ̀