Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Máṣe fi Ànfàní láti jẹ́rìí Krístì sílẹ̀
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2023


11:15

Máṣe fi Ànfàní láti Jẹ́rìí Krístì sílẹ̀

Ayọ̀ tòótọ́ wà lórí ìfẹ́ wa láti súnmọ́ Krístì síi kí a sì jẹ́ ẹ̀rí fúnra wa.

Ní ọdún márùn-ún sẹ́hìn lónìí, a gbé ọwọ́ wa sókè láti ṣe ìmúdúró wòlíì àyànfẹ́ wa, Ààrẹ Russell M. Nelson, gẹ́gẹ́bí Ààrẹ Ìjọ ti Jésù Krístì ti Àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn—agbẹnusọ Olúwa fún ìgbà àgbàyanu ti ìdàgbàsókè àti ìfihàn. Nípasẹ̀ rẹ̀, a ti gba àìlónkà ìpè, a sì ti ṣèlérí àwọn ìbùkún ológo bí a bá gbé ìgbésí ayé wa lé gbùngbun Olùgbàlà wa, Jésù Krístì.

Ní 2011, nígbà tí mo nsìn pẹ̀lú ọkọ mi gẹ́gẹ́bí olórí míṣọ̀n ní Curitiba ẹlẹ́wà, Brazil, fóònù mi dún nígbà ìpàdé kan. Sísáré láti pa ẹnu rẹ̀ mọ́, mo ṣàkíyèsí ìpè náà wá làti ọ̀dọ̀ baba mi. Mo yára fi ìpàdé sílẹ̀ láti dáhùn: “Háà, Baba!”

Láìròtẹ́lẹ̀, ohùn rẹ̀ kún fún ẹ̀dùn: “Háà, Bonnie. Mo nílò láti sọ ohun kan fún ọ. A ti yẹ̀míwò pẹ̀lú àrùn ALS.”

Ọkàn mi yípo pẹ̀lú ìdàmú, “Dúró! Kíni ALS jẹ́?

Baba ti nṣàlàyé tẹ́lẹ̀, “Ọkàn mi yíò wà lójúfò nígbàtí ara mi yíò rọra máa kú.”

Mo nímọ̀lára pé gbogbo ayé mi yípadà bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ síí jìjàkadì pẹ̀lú àwọn ipa tí àwọn ìròhìn búrukú yí. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ mánigbàgbé yẹn, gbólóhùn ọ̀rọ̀ ìkẹhìn rẹ̀ ni ó rí àyè kan títí láé nínú ọkàn mi. Baba mi ọ̀wọ́n sọ ní kánjúkánjú pé, “Bonnie, má ṣe jáwọ́ nínú ànfààní láti jẹ́rìí nípa Krístì.”

Mo ti ronú jinlẹ̀, mo sì ti gbàdúrà lórí ìmọ̀ràn Baba fún ọ̀pọ̀ ọdún. Mo ti sábà máa nbi ara mi léèrè bí mo bá mọ ní kíkún ohun tó túmọ̀ sí pé má fi ànfààní láti jẹ́rìí nípa Jésù Krístì sílẹ̀.

Bíi tìrẹ, mo ti dìdedúró lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan ní Ọjọ́ ìsimi àkọ́kọ́ nínú oṣù láti jẹ́rìí nípa Krístì. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà mo ti jẹ́rìí ti àwọn òtítọ́ ìhìnrere bí apákan ẹ̀kọ́ kan. Mo ti fi ìgboyà kọ́ni ní òtítọ́, mo sì ti polongo bí ìrànṣẹ ìhìnrere Krístì.

Síbẹ̀síbẹ̀ ẹ̀bẹ̀ yí ní mímọ̀lára araẹni díẹ̀ si! Ó dàbí ẹnipé ó nwípé, Bonnie, máṣe jẹ́ kí ayé kọjá rẹ lọ! Dúró ní òtítọ́ sí àwọn májẹ̀mú rẹ pẹ̀lú Olùgbàlà. Wá láti ní ìrírí àwọn ìbùkún Rẹ̀ lójoójúmọ́, kí o sì ní ànfàní láti jẹ́rìí nípasẹ̀ Ẹmí Mímọ́ ti agbára àti wíwà Rẹ̀ nínú ayé rẹ!”

A ngbé nínú ayé tí ó ti ṣubú, pẹ̀lú àwọn ohun ìyapalára tó nmú ojú àti ọkàn wa wò sísàlẹ̀ dípò sí ọ̀run. Gẹ́gẹ́bí àwọn ara Néfì ní 3 Néfì 11, a nílò Jésù Krístì. Njẹ́ o lè fojúinú wo araàrẹ níbẹ̀, láàrin àwọn ènìyàn tí ó ti ní ìrírí rúdurùdu àti ìparun púpọ̀ bí? Báwo ló ṣe máa rí láti gbọ́ ìpè araẹni Olúwa:

“Dìde, kí o sì jáde wá sọ́dọ̀ mi, kí ẹ̀yin lè fi ọwọ́ yin sí ẹ̀gbẹ́ mi, àti pé kí ẹ̀yin lè ní ìmọ̀ ìró ìṣó ní ọwọ́ mi àti ní ẹsẹ̀ mi, kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé èmi ni … Ọlọ́run gbogbo ayé, ti a sì pa fún ẹ̀ṣẹ̀ aráyé.

“Àti … ọ̀pọ̀ ènìyàn náà jáde lọ … ní ọ̀kọ̀ọ̀kan … wọ́n sì fi ojú wọn rí wọ́n sì fi ọwọ́ wọn nímọ̀lára rẹ̀, wọ́n sì mọ̀ … wọ́n sì ti jẹ́rìí fúnra wọn.”1

Àwọn ará Néfì wọ̀nyí fi ìtara lọ síwájú láti fi ọwọ́ wọn sí ẹ̀gbẹ́ Rẹ̀ kí wọ́n sì nímọ̀lára àmì ìṣó ní ọwọ́ àti ẹsẹ̀ Rẹ̀ kí wọ́n lè jẹ́rìí fún ara wọn pé èyí ni Krístì náà. Lọ́nà kannáà, ọ̀pọ̀ àwọn olõtọ́ ènìyàn tí a ti wádìí nínú Májẹ̀mú Titun lọ́dún yìí ló ti nretí dídé Krístì pẹ̀lú àníyàn. Nígbànáà ni wọ́n jáde kúrò ní oko wọn, àwọn ìjókòó iṣẹ́, àti tábìlì oúnjẹ alẹ́ wọn, wọ́n tẹ̀ lé E, wọ́n dì mọ́ Ọ, wọ́n gbá A mọ́lẹ̀, wọ́n sì jókòó tì Í. Njẹ́ a nṣàníyàn láti jẹ́rìí fún arawa gẹ́gẹ́bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nínú àwọn ìwé mímọ́ bí? Njẹ́ àwọn ìbùkún tí a nwá kò fi bẹ́ẹ̀ nílò rẹ̀ ju tiwọn lọ bí?

Nígbàtí Olùgbàlà bẹ àwọn ará Néfì wò ní ti ara ní tẹ́mpìlì wọn, ìpè Rẹ̀ kìí ṣe láti dúró ní ọ̀nà jínjìn kí wọ́n sì wo Òun, ṣùgbọ́n láti fọwọ́ kàn Án, láti ní ìmọ̀lára fún ara wọn ní òtítọ́ ti Olùgbàlà ẹ̀dá ènìyàn. Báwo la ṣe lè sún mọ́ ọ tó láti jèrè ẹ̀rí araẹni nípa Jésù Kristi? Èyí lè jẹ́ apákan ohun ti baba mi ngbìyànjú láti kọ́ mi. Lákokò tí a lè má gbádùn ìsúnmọ́tòsí ti ara kannáà gẹ́gẹ́bí àwọn wọnnì tí wọ́n bá Krístì rìn ní àkokò iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ ní ayé, nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ a lè ní ìrírí agbára Rẹ̀ lójoójúmọ́! Bí a ṣe nílò tó!

Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin káàkiri ayé ti kọ́ mi púpọ̀ nípa wíwá Krístì àti jíjẹ́rìí lójoojúmọ́, ti araẹni nípa Rẹ̀. Jẹ́ kí nṣe àbápín ọgbọ́n ti àwọn méjì nínú wọn:

Livvy ti wo ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbo ní gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀. Nítòótọ́, nínú ilé rẹ̀ wọ́n fi wíwò gbogbo abala ṣe àṣà gẹ́gẹ́bi ẹbí. Ní àtẹ̀hìnwa, ìpàdé fún Livvy ti túmọ̀ sí dídì tàbí lílọ sínú orun tí a kò pinnu lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ṣùgbọ́n ìpàdé àpapọ gbogbogbò Oṣù Kẹwa tí ó kọjá yí yàtọ̀. Ó di ti araẹni.

Ní àkokò yí, Livvy pinnu láti jẹ́ olùgbà lọ́wọ́. Ó fi àwọn ìfitónilétí rẹ̀ sí ìpalọ́lọ́ lórí fóònù rẹ̀ ó sì ṣe àkíyèsí àwọn ìwúnilórí láti ọ̀dọ́ Ẹ̀mí. Ó yà á lẹ́nu bí ó ṣe nnímọ̀lára àwọn ohun pàtó tí Ọlọ́run fẹ́ kí ó gbọ́ kí ó sì ṣe. Ìpinnu yí ṣe ìyàtọ̀ kan nínú ayé rẹ̀ bíi lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Ní ọjọ́ díẹ̀ lẹ́hìnnáà àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ pè é sí sinimá tí kò bójú mu. Ó ronú pé, “Mo ní ìmọ̀lára pé àwọn ọ̀rọ̀ àti ẹ̀mí ìpàdé náà padà sínú ọkàn mi, mo sì gbọ́ tí èmi fúnra mi nkọ ìfipè wọn sílẹ̀.” Ó tún ní ìgboyà láti pín ẹ̀rí rẹ̀ nípa Olùgbàlà nínú wọ́ọ̀dù rẹ̀.

Lẹ́hìn àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí, ó wípé, “Ohun tó yani lẹ́nu ni pé, nígbàtí mo gbọ́ tí èmi fúnra mi njẹ́rìí pé Jésù ni Krístì náà, mo rí i pé Ẹ̀mí Mímọ́ tún fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ fún mi.”

Livvy kò fò bí òkúta lórí òde òpin ọ̀sẹ̀ ìpàdé àpapọ̀; ó wọ inú rẹ̀, pẹ̀lú iyè inú àti ẹ̀mí, ó sì rí Olùgbàlà níbẹ̀.

Àti lẹ́hìnnáà Maddywà. Nígbàtí ẹbí rẹ̀ dẹ́kun lílọ sí ilé ìjọsìn, Maddy ní ìdàmú kò sì mọ èyí tí yío ṣe. Ó ríi pé nkan pàtàkì kan nsọnù. Nítorínáà, ní ọdún mẹ́tàlá, Maddy bẹ̀rẹ̀ sí í dá lọ ilé ìjọsìn. Bíótilẹ̀jẹ́pé dídá-nìkan-wà máa nle nígbà míràn àti àìrọ̀rùn, ó mọ̀ pé òun lè rí Olùgbàlà nínú ilé ìjọsìn àti pé òun fẹ́ láti wà níbi tí Ó wà. Ó wípé, “Nínú ilé ìjọsìn ọkàn mi dà bíi pé ó wà nílé.”

Maddy di òtítọ́ pé ẹbí rẹ̀ ti ṣe èdìdí papọ̀ fún ayérayé mú. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í kó àwọn àbúrò rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ lọ sí ilé ìjọsìn ó sì nṣàṣàrò ìwé mímọ́ pẹ̀lú wọn nílé. Níkẹhìn ìyá rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ síí darapọ̀ mọ́ wọn. Maddy sọ ìfẹ́-inú rẹ̀ láti sin ní míṣọ̀n fún ìyá rẹ̀ ó síí bèèrè bóyá ó lè ṣetán láti lọ sí tẹ́mpìlì pẹ̀lú rẹ̀.

Lónìí Maddy wà ní MTC. Ó nsìn. Ó njẹ́rìí nípa Krístì. Àpẹẹrẹ rẹ̀ ṣe ìrànlọ́wọ́ láti darí àwọn òbí rẹ̀ méjèèjì padà sí tẹ́mpìlì àti padà sọ́dọ̀ Krístì.

Gẹ́gẹ́bí Livvy àti Maddy, bí a ṣe yàn láti wá Krístì, Ẹ̀mí yíò jẹ́rìí Rẹ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ipò lóríṣiríṣi. Àwọn ẹlẹ́rìí ti Ẹ̀mí wọ̀nyí wáyé bí a ṣe ngbàwẹ̀, gbàdúrà, dúró, àti títẹ̀síwájú. Sísúnmọ́ Krístì wa ngbèrú síi nípasẹ̀ sísìn nígbà gbogbo nínú tẹ́mpìlì, rírònúpìwàdà ojoójúmọ́, ṣíṣàrò ìwé mímọ́, lílọ sílé ìjọsìn àti sẹ́mínárì, jíjíròrò àwọn ìbùkún babanla wa, gbígba àwọn ìlànà ní yíyẹ, àti bíbuọlá fún àwọn májẹ̀mú mímọ́. Gbogbo ìwọ̀nyí npe Ẹ̀mí láti fún ọkàn wa lóye, wọ́n sì mú àfikún àláfíà àti ààbò wá. Ṣùgbọ́n njẹ́ a nbu ọlá fún wọn bí àwọn ànfààní mímọ́ láti jẹ́rìí Krístì bí?

Mo ti lọ sí tẹ́mpìlì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, ṣùgbọ́n nígbàtí mo bá jọ́sìn nínú ilé Olúwa, ó yími padà. Nígbà míràn tí mo bá ngbàwẹ̀, ebi npa mí lásán, ṣùgbọ́n àwọn ìgbà míràn, mo njẹun lórí Ẹ̀mí pẹ̀lú èrèdí. Nígbà míràn mo máa nsọ àwọn àdúrà àsọtúnsọ tí wọ́n sì nṣe déédéé, ṣùgbọ́n mo tún ti fi ìtara gba ìmọ̀ràn pẹ̀lú Olúwa nípasẹ̀ àdúrà.

Agbára wà ní ṣíṣe àwọn ìhùwàsí mímọ́ wọ̀nyí kéré sí àtòkọ àyẹ̀wò àti díẹ̀ sí ti ẹlẹ́rìí. Ìlànà náà yío jẹ́ díẹ̀díẹ̀ ṣùgbọ́n yíò dàgbà pẹ̀lú lójoójúmọ́, ìkópa ti ìṣe àti àwọn ìrírí èrèdí pẹ̀lú Krístì. Bí a ṣe nṣe ìṣe léraléra lórí ẹ̀kọ́ Rẹ̀, a njèrè ẹ̀rí nípa Rẹ̀; a ngbé ìbáṣepọ̀ kan pẹ̀lú Rẹ̀ àti Baba wa Ọ̀run ga. A bẹ̀rẹ̀ síí dàbí Wọn.

Ọ̀tá nṣẹ̀dá ariwo púpọ̀ tí ó lè ṣòro láti gbọ́ ohun Olúwa. Ayé wa, àwọn ìpèníjà wà, àwọn ipò wa kì yíò dákẹ́, ṣùgbọ́n a lè a sì gbọdọ̀ pebi àti pòngbẹ lẹ́hìn àwọn ohun ti Krístì láti “gbọ́ Tirẹ̀ ”ni kedere.2 A nílò láti ṣẹ̀dá ìràntì iṣan ti ọmọlẹ́hìn àti ẹ̀rí tí yíò mú wa wá sí ìdojúkọ ìgbẹ́kẹ̀lé wa lórí Olùgbàlà wa lójoójúmọ́.

Baba mi ti lọ ju ọdún mẹ́wàá báyìí, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ wà lààyè nínú mi. “Bonnie, máṣe fi àyè láti jẹ́rìí Krístì sílẹ̀.” Mo pé yín láti bá mi lọ láti gba ìpè rẹ̀. Wá Krístì níbi gbogbo—Mo ṣ̣e ìlérí pé Ó wà níbẹ̀!3 Ayọ̀ tòótọ́ wà lórí ìfẹ́ wa láti súnmọ́ Krístì àti jẹ́ ẹ̀rí fúnra wa.

A mọ̀ pé ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn, “gbogbo eékún yíò tẹrí ba, gbogbo ahọ́n yío sì jẹ́wọ́ pé Jésù ni Krístì.4 Mo gbàdúrà pe ẹ̀rí yí yíò di déédé àti ìrírí àdánidá fún wa báyìí—pé a ó lo gbogbo ààyè láti jẹ́ ẹ̀rí pẹ̀lú ayọ̀ pé: Jésù Krístì wà láàyè!

Ah, báwo ni mo ṣe nífẹ Rẹ̀ tó. Èmi ti kún fún ìmoore tó fún Ètùtù Rẹ̀ àìlópin, tí ó ti “sọ ìyè ayérayé di ṣíṣeéṣe àti àìlèkú ní òtítọ́ fún gbogbo [wa].” Mo jẹ́ ẹ̀rí oore àti ògo nla ti Olùgbàlà wa ní orúkọ mímọ́ Rẹ̀, àní Jésù Krístì, àmín.