Ọkàn Álmà ṣe ìdìmú lórí ero ti Jésù yí.
Bí ẹ ti ntẹ̀síwájú ní fífi arabalẹ̀ ṣe ìdìmú nípa èrò Jésù Krístì, mo ṣe ìlérí fún yín kìí ṣe ìtọ́ni tọ̀run nìkan ṣùgbọ́n agbára tọ̀run.
Ní àkokò dídára Ọdún Àjínde yí, mo tún àdúrà orin alágbára yí sọ, “Tọ́ Wa Sọ́nà, Ah Jehovah Nlá.”1
Ìtàn kan tó lókìkí nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì wí nípa ọ̀dọ́mọkùnrin kan látinú ẹbí gbajúmọ̀ kan, tí a pè ní Álmà, ẹni tí àwọn ìwé mímọ́ júwe bíi aláìgbàgbọ́ abọ̀rìṣà.1 Ó jẹ́ ẹnití ó nsọ̀rọ̀ yéni àti dídánilójú, ní lílo ìpọ́nni láti pàrọwá sí àwọn ẹlòmíràn láti tẹ̀lé òun. Pẹ̀lú ìyanu, àngẹ́lì kan farahàn sí Álmà àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Álmà ṣubú sí ilẹ̀ ó sì ṣe àìlágbára tóbẹ́ẹ̀ tí a gbé e láìnírànwọ́ lọ sí ilé baba rẹ̀. Ó dúró nínú ipò tí ó dàbí áílèmira fún ọjọ́ mẹ́ta.2 Lẹ́hìnnáà, ó ṣe àlàyé pé nígbàtí òun wà ní àìlèmira sí àwọn tí ó wà ní àyíká òun, iyè-inú òun nṣiṣẹ́ kánkán bí ẹ̀mí tí ó nṣọ̀fọ̀, tí ó nronú nípa ayé rẹ̀ nípa àìpà àwọn òfin Ọlọ́run mọ́. Ó júwe iyè-inú rẹ̀ bí ẹnití ó ní “ìfòró nìpasẹ̀ ìrántí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ [rẹ̀]”3 tí “oró ayérayé sì gbóo.”4
Nínú ìjìnlẹ̀ àìní ìrètí, ó rántí jíjẹ́ kíkọ́ nígbà ọ̀dọ́ rẹ̀ nípa “bíbọ̀ ti Jésù Krístì kan, Ọmọ Ọlọ́run, láti ṣe ètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ aráyé.”5 Títẹ̀le ó ṣe ìsọ̀rọ̀ tí ó wọni-lọ́kàn gan an: “Bí ọkàn mi ṣe tẹ̀ mọ́ èrò yí, mo kígbe nínú ọkàn mi pé: Áà Jésù, ìwọ Ọmọ Ọlọ́run, ṣàánú fún mi.”6 Bí ó ṣe bẹ̀bẹ̀ fún agbára àtọ̀runwá ti Olùgbàlà, ohun ìyanu kan ṣẹlẹ̀: “Nígbà tí mo ronú nípa èyí,” ó wípé, “Èmi kò rántí àwọn ìrora mi mọ́.”7 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó ní ìmọ̀lára àláfíà àti ìmọ́lẹ̀. “Kò sí ohun [tí] ó lè tayọ adùn àti ayọ̀ tí mo ní,”8 ni ó kéde.
Álmà “ṣe ìdìmú lórí” òtítọ́ Jésù Krístì. Bí a bá máa lo àwọn ọ̀rọ̀ “ṣe ìtẹ̀mọ́ lórí” nínú ọgbọ́n àfojúrí, a lè wípé, “Ó ṣe ìdìmú lórí ìtọ́ni-irin bí ó ti nṣubú lọ, “ ó túmọ̀sí pé ó nawọ́ síta lọ́gán àti pé ó so ararẹ̀ mọ́ ohun kan típẹ́típẹ́ tí ó le koko láti mú ìpìlẹ̀ dúró.
Nínú ọ̀ràn Álmà, ọkàn rẹ̀ ni ó nà jáde ti ó sì mú òtítọ́ alágbára ti ìrúbọ ètùtù Jésù Krístì dúró. Ṣíṣe ìṣe nínú ìgbàgbọ́, àti nípa agbára àti oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, a gbà á là kúrò nínú àìnírètí tí ó sì kún fún ìrètí.
Nígbàtí àwọn ìrírí wa lè má rí bí ìyára bíiti Álmà, bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀ wọ́n jẹ́ pàtàkì ayérayé. Bákannáà iyè-inú wa ní ó “ṣe ìdìmú lórí èrò yí” nípa Jésù Krístì àti ìrúbọ àánú Rẹ̀, àti pé ẹ̀mí wa ti ní ìmọ̀lára ìmọ́lẹ̀ àti ayọ̀ tí ó tẹ̀le.
Mímú Èrò Jésù Krístì Dúró
Àdúrà mi ní àkokò Ọdún Àjínde yí ni pé a ó fi tọkàntọkàn túnṣe, fún lókún, àti dáàbo bo èrò pàtàkì jùlọ yí nípa Jésù Krístì nínú oókan ẹ̀mí wa,9 ní fífi ààyè gbà á láti fi ìtara ṣàn sínú wa, kí ó tọ́ wa sọ́nà nínú ohun tí a rò àti ṣe, kí ó sì máa mú ayọ̀ dídùn ti ìfẹ́ Olùgbàlà wá títí lọ.9
Kíkún inú wa pẹ̀lú agbára Jésù Krístì kò túmọ̀ sí pé Òun nìkan ni èrò tí a ní. Ṣùgbọ́n ó túmọ̀ sí pé gbogbo àwọn èrò wa ni ó yí ìfẹ́ Rẹ̀ ká, ìgbé ayé Rẹ̀ àti àwọn ìkọ́ni, àti ìrúbọ̀ ètùtù àti Àjínde ológo Rẹ̀. Jésù kò sí ní igun ìgbàgbé láéláé, nítorí àwọn èrò nípa Rẹ̀ nwà nígbàgbogbo àti pé “ohun gbogbo tí ó wà nínú [wa nfi ìyìn] fun!”11 A ngbàdúrà a sì nṣe àtúnrò nínú iyè wa ní ti àwọn ìrírí tí ó ti mú wa súnmọ́ Ọ síi. A ngba àwọn àwòrán tọ̀run, àwọn ìwé mímọ́, àti àwọn orin onímísí wá sí inú wa láti fi jẹ́jẹ́ mú àwọn èrò àìlónkà ojojúmọ́ tí ó nlọ nínú ìgbé ayé àṣekára wa. Ìfẹ́ wa fún Un kò mú wa kúrò nínú ìbànújẹ́ àti ìkorò nínú ayé ikú yí, ṣùgbọ́n ó fi ààyè gbà wá láti rìn nínú àwọn ìpènijà pẹ̀lú okun tí ó tayọ jìnnà sí ti arawa.
Jésù, rírò nípa rẹ gan an
Pẹ̀lú àdun ló kún àyà mi;
Ṣùgbọ́n dídùnjù ni ojú rẹ láti rí
Àti ní ìsinmi níwájú rẹ.11
Ẹ rántí pé, ẹ jẹ́ ọmọ ẹ̀mí Baba Ọ̀run. Bí Àpóstélì Páúlù ti ṣàlàyé, a jẹ́ “irú ọmọ Ọlọ́run.”10 Ẹ ti gbé pẹ̀lú ìdánimọ̀ ti ara ẹnìkọ̀ọ̀kan yín típẹ́tipẹ́ ṣíwájú wíwá sí ilẹ̀ ayé. Baba wa dá ètò pípé kan sílẹ̀ fún wa láti wá sí ilẹ̀ ayé, kẹkọ, kí a sì padà sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀. Ó rán Àyànfẹ́ Ọmọ Rẹ̀ pé nípasẹ̀ agbára Ètùtù àìlópin àti Àjínde Rẹ̀, kí a gbé tayọ ibojì; àti bí a ti nfẹ́ láti lo ìgbàgbọ́ nínú Rẹ̀ kí a sì ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa,13 à nní ìdáríjì a sì ngba ìrètí ìyè ayérayé.14
Fífún Iyè-inú àti Ẹ̀mí Wa Ní Ìfarabalẹ̀ Títayọ
Nínú ayé ikú yí, inú àti ẹ̀mí wa nílò ìfarabalẹ̀ títayọ.17 Iyè-inú wa nfi àyè gbà wá láti gbé, láti yàn, àti láti ní òye rere àti ibi.18 Ẹ̀mí wa ngba ẹ̀rí ìfẹsẹ̀múlẹ̀ pé Ọlọ́run ni Baba wa, pé Jésù Krístì ni Ọmọ Ọlọ́run, àti pé àwọn ìkọ́ni Wọn jẹ́ ìtọ́nisọ́nà sí ìdùnnú nihin àti ìyè ayérayé kọjá isà-òkú.
Ọkàn Álmà ṣe ìdìmú lórí ero ti Jésù yí. Ó yí ìgbé ayé rẹ̀ pada. Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò ni àkokò láti ní ìmọ̀ ohun tí Olúwa yíò fẹ́ kí a ṣe àti kí a dà. Bákannáà ó jẹ́ àkokò láti ronú lórí ìlọsíwájú wa. Bí àwọn yíyàn síṣẹ́ mi ti gbé mi káàkiri ayé, mo ti ṣe àkíyèsí okun ti ẹ̀mí púpọsi nínú òdodo, àwọn olùfọkànsìn ọmọ Ìjọ.
Ọdún marun sẹ́hìn, wọ́n ní kí a gbé Olùgbàlà sí gbangba síi nínú gbogbo ohun tí a bá nṣe nípa lílo orúkọ tòótọ́ ti Ìjọ Jésù Krístì ti àwọn Ènìyàn Mímọ́ Ọjọ́-ìkẹhìn.19 A nsọ orúkọ Rẹ̀ síi pẹ̀lú ìtara.
Ọdún mẹ́rin sẹ́hìn, nípa dídín àkokò ìpàdé oúnjẹ Olúwa kù, a mú ìdojúkọ wa lórí ṣíṣe àbápín oúnjẹ Olúwa pọ̀ si. A nronú síi nípa Jésù Krístì a sì ní ìkáramọ́ si nínú ìlérí wa láti rántí Rẹ̀ nígbàgbogbo.20
Pẹ̀lú ìpàtì àjàkálẹ̀ àrùn káríayé àti ìrànlọ́wọ́ ti Wa, Tẹ̀lé Mi, àwọn ìkọ́ni Olùgbàlà di ìṣàfihàn síi nínú ilé wa, ó nranìjọ́sìn wa lọ́wọ́ nípa Olùgbàlà ní àárín ọ̀sẹ̀.
Nípa títẹ́lé ìmọ̀ràn Ààrẹ Russell M. Nelson láti “gbọ́ Tirẹ̀,”20 à ntú agbára wa láti dá àwọn ìṣílétí Ẹ̀mí Mímọ́ mọ̀ àti láti rí ọwọ́ Olúwa nínú ayé wa.
Pẹ̀lú kíkéde àti píparí àwọn dọ́sìnnì tẹ́mpìlì, à nwọ ilé Olúwa léraléra a sì ngba àwọn ìbùkún Rẹ̀ tí Ó ṣèlérí. À nní ìmọ̀lára pẹ̀lú agbára tí ó kọjá oye dídára Olùgbàlá àti Olùràpàdà wa.
Ààrẹ Nelson wípé: “Kò sí ohun tí ó rọrùn tàbi jẹ́ tààrà nípa dída alágbára [ọmọlẹ́hìn] [kan]. Ìfojúsùn wa gbọ́dọ̀ jẹ́ síso mọ́ Olùgbàlà àti ìhìnrere Rẹ̀. Ó jẹ́ iṣẹ́ líle fún ọpọlọ láti tiraka láti wò Ó nínú gbogbo èrò.”16
Nípa ìfojúsùn ìgbáralé wa lórí Jésù Krístì, gbogbo àwọn míràn ní àyíká wa—nígbàtí a ṣì wà—ni a nwò nípasẹ̀ ìfẹ́ wa fún Un. Àwọn ìdíwọ́ tí kò ṣe pàtàkì a parẹ́, a ó sì mú àwọn ohun wọnnì tí kò wà ní pípamọ́ pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ àti ìwà Rẹ̀ kúrò. Bí e ti nfi ìgbáralé ṣe ìtẹ̀mọ́ èrò Jésù Krístì yí, ẹ gbẹ́kẹ̀lé E, kí ẹ sì pa àwọn òfin Rẹ̀ mọ́, mo ṣe ìlérí fún yín kìí ṣe pẹ̀lú ìtọ́nisọ́nà tọ̀run nìkàn ṣùgbọ́n pẹ̀lú agbára tọ̀run—agbára ti ó nmú okun wá fún àwọn májẹ̀mú yín, àláfíà fún àwọn ìṣòro yín, àti ayọ̀ fún àwọn ìbùkún yín.
Rírántí Jésù Krístì
Ní ọ̀sẹ̀ díẹ̀ sẹ́hìn, Kathy àti èmi bẹ ilé Matt àti Sarah Johnson wo. Ní ara ògiri ni àwòrán ẹbí iyebíye wọn wà, àwòrán ẹlẹ́wà ti Olùgbàlà, àti ìjúwe tẹ́mpìlì.
Àwọn ọmọbìnrin wọn mẹrin, Maddy, Ruby, Clare, àti June, sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìdùnnú nípa bí wọ́n ṣe fẹ́ràn ìyá wọn.
Fún ọdún kan ó lé Sarah ti fi ìpàdé àwọn Ọjọ́ Sátidé lọ́lẹ̀ déédé fún ẹbí láti lọ sí tẹ́mpìlì papọ̀ kí àwọn obìnrin náà lè kópa nínú ìrìbọmi fún àwọn ọmọ ẹbí tí wọ́n ti gbé tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.
Ní Oṣù Kọkànlá ọdún tí ó kọjá, Sarah ti fi ìpàdé tẹ́mpìlì ẹbí lọ́lẹ̀ fún ọ̀sẹ̀ tó kẹ́hìn ní Oṣù Kejìlá ní Ọjọ́bọ̀ dípò Ọjọ́ Sátidé. “Mo ní ìrètí pé o wà dáadáa pẹ̀lú èyí,” ni ó wí fún Matt.
Sarah ni a ti yẹ̀wò tí ó ni àrùn jẹjẹrẹ, ṣùgbọ́n àwọn dókítà ngbèrò pé ó lè gbé ọdún méjì tàbí mẹta síi. Nínú ìpàdé oúnjẹ Olúwa, Sarah ti pín ẹ̀rí alágbára, ó wí pé ohunkóhùn tí àbájáde bá jẹ́ fún òun, òun fẹ́ràn Olùgbàlà pẹ̀lú gbogbo ọkàn òun àti pé “a ti di aṣẹ́gun tẹ́lẹ̀” nípa Rẹ̀. Bí Oṣù Kejìlá ṣe nlọsíwájú, láìròtẹ́lẹ̀ ìlera Sarah dínkù kíákíá, ó sì wà ní ilé ìwòsàn. Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù Ọjọ́bọ̀, Ọjọ́ Kọkàndínlọ́gbọ́n Oṣù Kejìlá, ó parí ayé ikú rẹ̀ jẹ́jẹ́. Matt ti wà ní ẹ̀gbẹ́ Sarah ní gbogbo òru.
Pẹ̀lú ọkàn ìrora rẹ̀, ó sì ti rẹ̀ẹ́ níti ara àti ẹ̀dùn ọ̀kàn, ó dé ilé, ó nṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin rẹ̀. Bí Matt ti wo fóònù rẹ̀, ó kíyèsí ìránnilétí ìpàdé tẹ́mpìlì Ọjọ́bọ̀ tí Sarah filọ́lẹ̀ fún ìgbàmíì ní ọjọ́ náà. Matt wípé, “Nígbàtí mo kọ́kọ́ ri, mo ròó pé, èyí kò lè ṣiṣẹ́.”
Ṣùgbọ́n nígbànáà ọkàn Matt ṣe ìdìmú lórí èrò yí pé: “Olùgbàlà wà láàyè. Kò sí ibi tí a tún lè wà bí ẹbí kan bíkòṣe nínú ilé mímọ́ Rẹ̀.”
Matt, Maddy, Ruby, Claire, àti June dé tẹ́mpìlì fún ìpàdé ti Sarah ti fi lọ́lẹ̀ fún wọn. Pẹ̀lú omijé tí ó nṣàn sílẹ̀ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀, Matt ṣe ìrìbọmi pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin rẹ̀. Wọ́n ní ìmọ̀lára ìjìnlẹ̀ ìfẹ́ àti ìsopọ̀ ayérayé pẹ̀lú Sarah, wọ́n sì ní ìmọ̀lára ìfẹ́ títóbi àti àláfíà ìtùnú nípa Olùgbàlà. Matt fi jẹ́jẹ́ ṣe àbápín pé, “Nígbàtí mo ní ìmọ̀lára ìjìnlẹ̀ ìbànújẹ́ àti ọ̀fọ̀, mo ké fún ayọ̀. Ní mímọ̀ ètò ìgbàlà ìyanu ti Baba.”
Ní àkokò Ọdún Àjinde yí, mo jẹ́ ẹ̀rí òtítọ́ píparí àti títóbi ti ìrúbọ ètùtù àìláfiwé Olùgbàlà àti Àjínde ológo Rẹ̀. Bí ọkàn yín ti ṣe ndúró daindain àti títíláé lórí èrò Jésù Krístì, àti bí ẹ ti nní ìdojúkọ lemọ́lemọ́ ìgbé ayé yín lórí Olùgbàlà ní kíkún, mo ṣe ìlérí pé ẹ ó ní ìmọ̀lára ìrètí Rẹ̀, àláfíà Rẹ̀, àti ìfẹ́ Rẹ̀. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.