Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Nígbàgbogbo Ni Ìdáhùn Jẹ́ Jésù Krístì.
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2023


6:20

Nígbàgbogbo Ni Ìdáhùn Jẹ́ Jésù Krístì.

Ìbèèrè èyíkeyí tàbí wàhálà tí ẹ ní, ìdáhùn ni à nrí nígbàgbogbo nínú ìgbé ayé àti ìkọ́ni Jésù Krístì.

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, a ti bọ́ wa ní ti ẹ̀mí nínú àwọn ọjọ́ méjì tó kọjá wọ̀nyí. Àwọn akọrin ti darájù. Àwọn tí wọ́n ti bá wa sọ̀rọ̀ ti jẹ́ ohun èlò fún Olúwa. Mo gbàdúrà pé ẹ ó wá Ẹ̀mí Mímọ́ láti tọ́ ọ yín sọ́nà nínú àṣàrò yín bí ẹ ti ngbèrò àwọn òtítọ́ láti orí pẹpẹ yí. Wọ́n ti jẹ́ láti ọ̀run wá nítòótọ́.

Ọ̀sẹ̀ kan sí òní ni Ọjọ́ Ìsinmi Àjínde. Ó jẹ́ pàtàkì àkíyèsí ẹ̀sìn jùlọ fún àwọn àtẹ̀lé Jésù Krístì. Èrèdí kan tí a fi nṣe ayẹyẹ Kérésìmesì ni nítorí Ọdún Àjìnde. Ẹ̀kọ́ Wa, Tẹ̀lé Mi ní ọ̀sẹ̀ yí yíò ṣíi yín létí láti ṣe àṣàrò wíwọ Jerusalem bí aṣẹ́gun ti Olùgbàlà, títún tẹ́mpìlì Rẹ̀ ṣe, ìjíyà Rẹ̀ nínú Ọgbà Gethsemane, Ìkanmọ́-àgbélèbú Rẹ̀, Àjínde ológo Rẹ̀, àti àwọn ìfarahàn Rẹ̀ lẹ́hìnwá sí àwọn àtẹ̀lé Rẹ̀.1

Ẹ sọ àwọn ẹsẹ wọ̀nyí di dídùn kí ẹ sì wá gbogbo ọ̀nà tí ẹ fi lè dúpẹ́ lọ́wọ́ Baba wa Ọ̀run fún rírán Ọmọ Bíbí Rẹ̀ Níkanṣoṣo sí wa.2 Nítorí Jésù Krístì, a lè ronùpìwàdà a sì lè gba ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Nítorí Rẹ̀, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa yíò jínde.

Bákannáà mo pè yín lẹ́ẹ̀kansi láti ṣe àṣàrò ìtàn àkọsílẹ̀ fífi arahàn Olùgbàlà sí àwọn ará Néfì ní Amẹ́ríkà, bí a ti kọ́sílẹ̀ ní 3 Nefì. Kò pẹ́ ṣíwájú fífarahàn náà, a gbọ́ ohun Rẹ̀ ní àárín àwọn ènìyàn, pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀bẹ̀ wọ̀nyí pé.

“Ṣé ẹ kò ní padà sí ọ̀dọ̀ mi nísisìyí, kí ẹ sì ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì yípadà, kí èmi lè wò yin sàn?

“… Ẹ kíyèsĩ, apá ãnú mi nã síi yín, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wá sí ọ̀dọ̀ mi, òun ni èmi yíò gbà.”3

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, Jésù Krístì na irú ìpè kannáà sí yín ní òní. Mo bẹ̀bẹ̀ pẹ̀lú yín láti wá sí ọ̀dọ̀ Rẹ̀ nítorí kí Òun lè wò yín sàn! Òun yíò wò yín sàn kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹ ti nronúpìwàdà. Òun yíò wò yín sàn kúrò nínú ìbànújẹ́ àti ẹ̀rù. Òun yíò wò yín sàn kúrò nínú àwọn ọgbẹ́ ayé yí.

Ìbèèrè èyíkeyí tàbí wàhálà tí ẹ ní, ìdáhùn ni à nrí nígbàgbogbo nínú ìgbé ayé àti àwọn ìkọ́ni Jésù Krístì. Ẹ kẹkọ si nípa Ètùtù Rẹ̀, ìfẹ́ Rẹ̀, àánú Rẹ̀, ẹ̀kọ́ Rẹ̀, àti ìmúpadábọ̀sípò ìhìnrere ìwòsàn àti ìlọsíwájú Rẹ̀. Yípadà sí I! Tẹ̀lé E!

Jésù Krístì ni èrèdí tí a fi nkọ́ àwọn tẹ́mpìlì. Ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́ ilé mímọ́ Rẹ̀. Dídá àwọn májẹ̀mú àti gbígba àwọn ìlànà pàtàkì nínú tẹ́mpìlì, bákannáà wíwá láti súnmọ́ Ọ̀ síi níbẹ̀, yíò bùkún ìgbé ayé yín ní àwọn ọ̀nà tí kò sí irú ìjọsìn míràn tí ó lè ṣé. Fún èrèdí yí, a nṣe gbogbo ohun ní ìkáwọ́ agbára wa láti mú kí àwọn ìbùkún tẹ́mpìlì wà ní àrọ́wọ́tó àwọn ọmọ ìjọ yíká àgbáyé. Ní òní, mo fi ìmoore hàn láti kéde àwọn ètò wa láti kọ́ tẹ́mpìlì titun kan ní ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìbí wọ̀nyí:

  • Retalhuleu, Guatemala

  • Iquitos, Peru

  • Teresina, Brazil

  • Natal, Brazil

  • Tuguegarao City, Philippines

  • Iloilo, Philippines

  • Jakarta, Indonesia

  • Hamburg, Germany

  • Lethbridge, Alberta, Canada

  • San Jose, California

  • Bakersfield, California

  • Springfield, Missouri

  • Charlotte, North Carolina

  • Winchester, Virginia

  • Harrisburg, Pennsylvania

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi ọ̀wọ́n, mo jẹ́ ẹ̀rí pé Jésù Krístì ndarí ètò Ìjọ Rẹ̀. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé títẹ̀lé E ni ọ̀nà kanṣoṣo láti ní ìdúnnú pípẹ́. Mo mọ̀ pé agbára rẹ̀ nsọ̀kalẹ̀ wá sórí àwọn ènìyàn olùpamọ́ májẹ̀mú Rẹ̀, “ní ríró pẹ̀lú òdodo àti pẹ̀lú agbára Ọlọ́run nínú ògo nlá.”4 Mo jẹri bẹ́ẹ̀, pẹ̀lú ìfẹ́ mi àti ìbùkún fún ẹnìkọ̀ọ̀kan yín, ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.