Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Olúwa Jésù Krístì Kọ́ Wa láti Ṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2023


11:29

Olúwa Jésù Krístì Kọ́ Wa láti Ṣe Iṣẹ́ Ìránṣẹ́

Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olùgbàlà, a lè ní ìfẹ́ àwọn àgùtàn iyebíye Olùgbàlà kí a sì ṣe iṣẹ́ ìrànṣẹ́ sí wọn bí Òun ó ti ṣe.

Olúwa Jésù Krístì wípé:

“Èmi ni Olùṣọ́-àgùtàn rere: olùṣọ́-àgùtàn rere fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùtàn. …

“Bí Baba ti mọ̀ mí, tí èmi sì mọ Baba; mo sì fi ẹ̀mí mi lélẹ̀ nítorí àwọn àgùtàn.”1

Nínú ẹ̀yà ìwé mímọ́ ti Greek yí, ọ̀rọ̀ náà fún rere bákannáà túmọ̀ sí “dídára, rírẹ̀wà.” Nítorínáà ní òní, mo fẹ́ láti sọ̀rọ̀ nípa Olùṣọ̀-àgùtàn rere, Olùṣọ̀-àgùtàn dídara, Olùṣọ̀-àgùtàn rírẹwà, àní Jésù Krístì.

Nínú Májẹ̀mú Titun, òun ni a pè ní “olùṣọ̀-àgùtàn nlá,”2 “olórí Olùṣọ̀-àgùtàn,”3 àti “Olùṣọ̀-àgùtàn àti Bíṣọ́ọ̀pù ti ọkàn [wa].”4

Nínú Májẹ̀mú Láéláé, Isaiah kọ pé “Òun yíò bọ́ ọ̀wọ́-ẹran rẹ̀ bí olùṣọ̀-àgùtàn.”5

Nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì, a pè É ní “olùṣọ̀-àgùtàn rere”6 àti “olùṣọ̀-àgùtàn nlá àti òtítọ́.”7

Nínú Ẹ̀kọ́ àti àwọn Májẹ̀mú, Ó kéde pé, “Nítorínáà, Èmi wà ní àárín yín, èmi sì ni olùṣọ̀-àgùtàn rere.”8

Ní ọjọ́ wa, Ààrẹ Russell M. Nelson ti kéde pé: “Olùṣọ̀-àgùtàn Rere nfi ìfẹ́ tójú gbogbo àwọn àgùtàn agbo Rẹ̀, àwà sì ni àgùtàn òtítọ́ àbẹ́ Rẹ̀. Ànfàní wa ni láti gba ìfẹ́ Rẹ̀ kí a sì fi ìfẹ́ tiwa kún un sí àwọn ọ̀rẹ́ àti aládugbo—ní bíbọ́, títọ́jú, àti ṣíṣé ìkẹ́ wọn—bí Olùgbàlà yíò ti fẹ́ kí a ṣe.”9

Láìpẹ́ jọjọ, Ààrẹ Nelson ti wípé “Ohun-àmì Ìjọ alààyè àti òtítọ́ ti Olúwa yíò fi ìgbà gbogbo jẹ́ ìṣètò kan, akitiyan dídarí láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí olúkúlùkù àwọn ọmọ Ọlọ́run àti ẹbí wọn. Nítorí ó jẹ́ Ìjọ Rẹ̀, àwa bí ìránṣẹ́ Rẹ̀ yíò ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí ẹnìkan náà, gẹ́gẹ́ bí Ó ti ṣe.” A ó ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní orúkọ Rẹ̀, pẹ̀lú agbára àti àṣẹ Rẹ̀, àti pẹ̀lú ìfẹ́-inúrere.”10

Nígbàtí àwọn Farisí àti akọ̀we nkùn tako Olúwa, “wípé, Ọkùnrin yí ngba ẹlẹ́ṣẹ̀, ó sì nbá wọn jẹun,”11 Ó fèsì nípa gbígbé àwọn ìtàn mẹ́ta dídára tí a ti mọ̀ bí òwe àgùtàn tí ó nú, òwe owó ẹyọ̀ tó sọnù, àti òwe ọmọ oninakuna kalẹ̀.

Ó dùnmọ́ni láti kíyèsi pé nígbàtí Lúkù, akọ̀wé Ìhìnrere, nfi àwọn ìtàn mẹ̀ta náà hàn, ó lo ọ̀rọ̀ òwe nínú ọ̀kan, kìí ṣe ní púpọ̀.12 Ó hàn pé Olúwa nkọ́ni ní ẹ̀kọ́ àìláfiwé kan pẹ̀lú àwọn ìtàn mẹ́ta—àwọn ìtàn tí ó gbé onírurú àwọn oye kalẹ̀: àgùtàn ọgọ́ọ̀rún, owó ẹ̀yọ mẹwa, àti àwọn ọmọ méjì.

Nọ́mbà pàtàkì nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìtàn wọ̀nyí, bákannáà, ni nọ́mba oókan Àti pé ẹ̀kọ́ tí a lè kọ́ látinú nọ́mbà náà ni pé ẹ lè jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn abẹ́ fún àwọn alàgbà ọgọ́ọ̀rún àti olùfojúsọ́nà alàgbà nínú iyejú àwọn alàgbà yín tàbí olùdámọ̀ràn sí àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin mẹwa tàbí olùkọ́ni kan sí àwọn ọmọ Alakọbẹrẹ méjì, ṣùgbọ́n ẹ nfi ìgbàgbogbo, ìgbàgbogbo ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí wọn, tọ́jú wọn àti nifẹ wọn ní ẹyọ kọ̀ọ̀kan, ní olúkúlùkù. Ẹ kò sọ rí pé, “Irú àláìgbọ́n àgùtàn wo,” tàbí “Lẹ́hìn gbogbo rẹ̀, èmi kò nílò ẹyọ owó náà nítòótọ́,” tàbí “Irú olóríkunkun ọmọ wo ló jẹ́.” Bí ẹ̀yin àti èmi bá ní “ìfẹ́ mímọ́ ti Krístì,”13 pẹ̀lú wa, àwà bí ènìyàn nínú ìtàn àgùtàn tí ó nù, yíò “fi àádọ́wá àti mẹ́sán sílẹ̀ … a ó sì wá èyí tí ó nù lọ, títí, [… títí … títí a] ó fi ri.”14 Tàbí bí obìnrin nínú ìtàn ẹyọ owó tí ó nù, a ó tan àbẹ́là, a ó sì gbá ilé, a ó sì wáa taratara [… taratara] títí [… títí … títí a ó] fi ri.”15 Bí a bá ní “ìfẹ́ mímọ́ ti Krístì,” pẹ̀lú wa a ó tẹ̀lé àpẹrẹ baba nínú ìtàn ọmọ oninakuna, ẹni tí àánú ṣe nígbàtí “ó sì wà ní òkèèrè, ó rí i, ó ní àánú, ó sì sáré, ó rọ̀ mọ ní ọrùn, ó sì fi ẹnu kò ó ni ẹnu.”16

Njẹ́ a lè ní ìmọ̀lára ìkánjú tí ó wà nínú ọkàn ọkùnrin tí ó pàdánù àgùtàn kanṣoṣo bí? Tàbí ìkánjú tí ó wà nínú ọkàn obìnrin tí ó pàdánù ẹyọ owó kanṣoṣo bí? Tàbí ìfẹ́ àìṣìṣe àti àánú tí ó wà nínú baba oninakuna bí?

Ìyàwó mi, Maria Isabel, àti èmi sìn ní Central America, a dúró sí Ìlú Guatemala. Níbẹ̀ ni mo ní ànfàní láti pàdé Julia, ọmọ Ìjọ olótítọ́ kan. Mo ní ìtẹ̀mọ́rá láti bèèrè nípa ẹbì rẹ̀. Ìyá rẹ̀ kú nípa àrùn jẹjẹrẹ ní 2011. Baba rẹ̀ ti jẹ́ olõtọ́ olùdarí kan nínú èèkan rẹ̀, tí ó sìn bí bíṣọ́ọ̀pù àti bí olùdámọ̀ràn sí ààrẹ̀ èèkàn rẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Ó jẹ́ olùṣọ́-àgùtàn abẹ́ òtítọ́ ti Olúwa. Julia wí fún mi nípa àwọn ìtiraka àìsimi rẹ̀ láti ṣèbẹ̀wò, làti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, àti láti sin. Lódodo ó nyọ̀ ní bíbọ́ áti títọ́jú àwọn àgùtàn iyebíye Olúwa. Ó tún tún ìgbeyàwó ṣe ó sí dúró nínú aápọn ní Ìjọ.

Ọdún díẹ̀ lẹ́hìnnáà, ó lọ nínú ìkọ̀sílẹ̀ ó sì níláti dá lọ sílé ìjọsìn lẹ́ẹ̀kansi. O ní ìmọ̀lára àìní ìbámu bákannáà ó dàbí àwọn ènìyàn kan nda á lẹ́jọ́ nítori ìkọ̀sílẹ̀ rẹ̀. Ó dúró ní lílọ sí ilé ìjọsìn bí ẹ̀mí àìdáa ti kún ọkàn rẹ̀.

Julia sọ̀rọ̀ gíga nípa oníyanu olùṣọ̀-àgùtàn abẹ́ yí, tí ó jẹ́ ẹni takuntakun, olùfẹ́ni, àti aláànú ọkùnrin. Mo rántí kedere pé ìmọ̀lára ìkánjú wá sí mi bí ó ṣe njúwe rẹ̀. Mo kan fẹ́ láti ṣe ohun kan fún ọkùnrin náà, ọkùnrin náà tí ó ṣe ohun púpọ̀ gan fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní gbogbo àwọn ọdún wọnnì.

Ó fún mi ní nọ́mbà fóònù àgbéká rẹ̀, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí pè é, ní ìrètí láti ní ààyè láti pàdé rẹ̀ lójúkojú. Lẹ́hìn ọ̀sẹ̀ púpọ̀ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpè láìsí aṣeyege, nígbẹ̀hìn ó dáhùn fóònú rẹ̀ níjọ̀ kan.

Mo wí fun pé mo padé Júlíà, ọmọbìnrin rẹ̀, àti pé mo ní ojúrere nípa ọ̀nà tí ó fi sìn, ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́, àti fẹ́ràn àgùtàn iyebíye Olúwa fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Ko retí irú ìdásí bẹ́ẹ̀. Mo wí fun pé èmi fẹ́ láti ṣèbẹ̀wò pẹ̀lú rẹ̀ gidi ní ojú sí ojú, ojúkojú. Ó bèèrè èrèdí fún gbígbèrò irú ìpàdé bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ mi. Mo fèsì pé, “Mo fẹ́ láti pàdé baba irú obìnrin oníyanu kan bẹ́ẹ̀.” Nígbànáà fún ìṣẹ́jú díẹ̀ ìdákẹ́jẹ́ wà lórí fóónú—ìṣẹ́jú díẹ̀ tí ó dàbí àìlópin sí mi. Ó wí jẹ́jẹ́ pé, “Nígbàwo àti níbo?”

Ní ọjọ́ tí mo pàdé rẹ̀, mo pèé láti pín àwọn ìrírí díẹ̀ nípa ìbẹ̀wò, iṣẹ́ ìránṣẹ́, àti sísin àwọn àgùtàn iyebíye Olúwa pẹ̀lú mi. Bí ó tí nsọ àwọn ìtàn wíwọnilọ́kàn, mo kíyèsi pé ìsọ̀rọ̀ ohùn rẹ̀ yípadà àti ní irú ẹ̀mí kannáà ó ní ìmọ̀lára tí ó ti ní lọ́pọ̀lọpọ̀ ìgbà bí olùṣọ́-àgùtàn abẹ́ ní pípadà wá. Nísisìyí ojú rẹ̀ kún fún omijé. Mo mọ̀ pé èyí ni àkokò títọ́ fún mi, ṣùgbọ́n mo ri pé èmi kò mọ ohun láti sọ. Mo gbàdúrà ní inú mi pé, “Baba, ràn mí lọ́wọ́.”

Lọ́gán, mo gbọ́ ara mi tí ó nwí pé , “Arákùnrin Florian, gẹ́gẹ́bí òjíṣẹ́ Olúwa mo bẹ̀bẹ̀ fún àìsí níbẹ̀ wa fún ọ. Jọ̀wọ́, dáríjì wa. Fún wa ní ààyè míràn láti fihàn ọ́ pé a ní ìfẹ́ rẹ. Pé a nílò rẹ. Pé ó jẹ́ pàtàkì sí wa.

Ní Ọjọ́ Ìsinmi tí ó tẹ̀le ó padà wá. Ó ní ìbanisọ̀rọ̀ pípẹ́ pẹ̀lú bíṣọ́ọ̀pù rẹ̀ ó sì dúró ni aápọn. Ní oṣù díẹ̀ lẹ́hìn náà ó kọjá lọ—ṣùgbọ́n ó ti padà wá. Ó ti wá padà. Mo jẹ́ ẹ̀rí pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Olùgbàlà, pé a lè ní ìfẹ́ àwọn àgùtàn iyebíye Olùgbàlà kí a sì ṣe iṣẹ́ ìrànṣẹ́ sí wọn bí Òun ó ti ṣe. Àti pé nítorínáà, níbẹ̀ ní ìlú Guatemala ni Olúwa Jésù Krístì ti mú àgùtàn iyebíye kan wá padà sínú agbo Rẹ̀. Ó sì kọ́ mi ní ẹ̀kọ́ kan lórí iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí èmi kò lè gbàgbé. Ní orúkọ Olùṣọ́-àgùtàn Rere, Olùṣọ́-àgùtàn Dídára, Olùṣọ́-àgùtàn Rírẹwà, àní Olúwa Jésù Krístì, àmín.