Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
“Kò Sí Ohunkankan Tí ó Tayọ Adùn àti Ayọ̀ Tí Mo Ní”
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2023


9:58

“Kò Sí Ohunkankan Tí ó Tayọ Adùn àti Ayọ̀ Tí Mo Ní”

Ríronúpìwàdà ojojúmọ́ àti wíwá sọ́dọ̀ Jésù Krístì ni ọ̀nà láti ní ìrírí ayọ̀—ayọ̀ tí ó kọjá òye wa.

Ní gbogbo iṣẹ́ ìránṣẹ́ ayé ikú Rẹ̀, Olùgbàlà fi àánú nlá hàn fún gbogbo àwọn ọmọ Ọlọ́run—nípàtàkì fún àwọn ẹnití wọ́n njìyà tàbí ti ṣáko lọ. Nígbàtí a ṣe òfíntótó rẹ̀ láti ọwọ́ àwọn Farisí fún dídarapọ̀ pẹ̀lú àti jíjẹ́ oúnjẹ́ ní àárín àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, Jésù fèsì nípa kíkọ́ àwọn òwe mẹ́ta tí a mọ̀ dáadáa.1 Nínú ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn òwe wọ̀nyí, Ó tẹnumọ́ pàtàkì wíwá àwọn tí ó ti ṣáko lọ jáde àti ayọ̀ tí à nní ìmọ̀lára nígbàtí wọ́n bá padàdé. Fún àpẹrẹ, nínú òwe àgùtàn tí ó nù Ó wípé, “Ayọ̀ [nlá] yíò wà ní ọ̀run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronúpìwàdà.”2

Ìfẹ́ mi ní òní ni láti fi okun fún ìsopọ̀ ní àárín ayọ̀ àti ìrònúpìwàdà—nípàtàkì jùlọ, ayọ̀ tí ó nwá nígbàtí a bá ronúpìwàdà àti ìmọ̀lára ayọ̀ tí à ngbà bí a ti npe àwọn ẹlòmíràn láti wá sọ́dọ̀ Krístì kí a sì gba ìrúbọ̀ ètùtù Rẹ̀ nínú ayé wa.

A Wà Kí A Lè Ní Ayọ

Nínú àwọn ìwé mímọ́, ọ̀rọ̀ náà ayọ̀ túmọ̀ sí ju àwọn àkokò ìtẹ́lọ́rùn tí ó nkọja lọ tàbí àní àwọn ìmọ̀lára ìdùnnú. Ayọ̀ nínú ọ̀rọ̀ yí ni ìhùwàsí bí Ọlọ́run, tí a rí nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ rẹ̀ nígbàtí a padà láti gbé ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.3 Ó jinlẹ̀ , ó nígbéga, ó nífaradà, ó sì jẹ́ ìyípadà ìgbé ayé ju adùn kankan tàbí ìtùnú tí ayé lè fúnni.

A dá wa láti ní ayọ̀. Ó jẹ́ wíwàlọ́nà àyànmọ́ ìpín wa bí àwọn olùfẹ́ni ọmọ Baba Ọ̀run. Òun nfẹ́ láti pín ayọ̀ Rẹ̀ pẹ̀lú wa. Wòlíì Léhì kọ́ni pé ètò Ọlọ́run fún ẹnìkọ̀ọ̀kan wa ni pé kí a “lè ní ayọ̀.”4 Nítorí à ngbé nínú ayé ìṣubú, ayọ̀ ìfaradà tàbí ayọ̀ àìlópin máa nkọjá àrọ́wọ́tó wa nígbàkugbà. Síbẹ̀, ní ẹsẹ tó tẹ̀le gan, Lehi tẹ̀síwájú nípa ṣíṣe àlàyè pé “Messiah [wá láti] … rà [wá] padà kúrò nínú ìṣubú.”5 Ìràpadà, nípasẹ̀ àti nínú Olùgbàlà Jésù Krístì, nmú ayọ̀ ṣeéṣe.

Ọ̀rọ̀ ìhìnrere ni ọ̀rọ̀ ìrètí, ti “ìròhìn rere ayọ̀ nlá,”6 àti ọ̀nà èyí tí gbogbo ènìyàn fi lè ní ìrírí àláfíà àti àwọn ìgbà ayọ̀ nínú ayé yí kí wọ́n sì gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀ ní ayé tó nbọ̀.7

Ayọ̀ tí à nsọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni ẹ̀bùn fún olotítọ́, síbẹ̀síbẹ̀ ó nwá pẹ̀lu oye kan. Ayọ̀ kò wọ́pọ̀ tàbí kí a fúnni lásán. Ṣùgbọ́n, a rà á “pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ iyebíye ti [Jésù] Krístì.”8 Bí a bá ní òyè iyì òtítọ́, ayọ̀ ti ọ̀run lódodo, a kò ní lọ́ra láti rúbọ ohun-ìní kankan tàbí ṣe ìyípadà ìgbé ayé tó ṣeéṣe láti gbà á.

Ọba alágbára ṣùgbọ́n onírẹ̀lẹ̀ kan nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì ní òye èyí. “Kíni èmi ó ṣe,” ó bèère, tí a ó fi bí mi nípa Ọlọ́run, tí a ó fi fa ẹ̀mí burúkú yí tu jáde ní àyà mi, tí èmi yíò sì gba ẹ̀mí rẹ̀, kí èmi lè kún fún ayọ̀ … ? Kíyèsíi, ni ó wí, èmi yíò fi ohun gbogbo tí mo ní sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ni, èmi yíò kọ ìjọba mi sílẹ̀, kí èmi ó le gba ayọ̀ nlá yìí.”8

Ní ìfèsì sí ìbèèrè ọba, òjíṣẹ́ ìránṣẹ́ Aaron wípé, “Bí ìwọ bá fẹ́ ohun yí, … bẹ̀rẹ̀ mọ̀lẹ̀ níwájú Ọlọ́run … [kí ó sì] kí o sì ronúpìwàdà gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.”10 Ìrònúpìwàdà ni ipa ọ̀nà sí ayọ̀,11 nítorí ó jẹ́ ipa ọ̀nà tí ó ndarí sí Olùgbàlà Jésù Krístì.12

Ayọ̀ Nwá nípasẹ̀ Ìrònúpìwàdà Àtinúwá

Fún àwọn kan, láti ronú nípa ìronúpìwàdà bí ipa ọ̀nà sí ayọ̀ lè dàbí àtakò. Irònúpìwàdà, ní ìgbà míràn, lè rora ó sì lè ṣòro. Ó nílò gbígbà pé díẹ̀ lára àwọn èrò wa àti ìṣe—àní díẹ̀ lára àwọn ìgbàgbọ́ wa—ti jẹ́ àṣìṣe. Bákannáà ìronúpìwàdà nílò ìyípadà, èyí, tí ó lè jẹ́ àìtura, ní ìgbà míràn Ṣùgbọ́n ayọ̀ àti ìtùnú kìí ṣe ohun kannáà. Ẹ̀ṣẹ̀—pẹ̀lú ẹ̀ṣẹ̀ ti ìtẹ́lọ́run—ndín ayọ wa kù.

Bí a ti sọ nípa Olórin, “Ẹkún lè pẹ́ dalẹ́, ṣùgbọ́n ayọ̀ nbọ̀ ní òwúrọ̀.”13 Bí a ti nronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, a gbọ́dọ̀ dojúkọ ayọ̀ nlá tí ó tẹ̀le. Àwọn alẹ́ lè dàbí ó gùn, ṣùgbọ́n òwúrọ̀ ó wá, àti ah, bí àláfíà àti ayọ̀ ògo ti ó tayọ tí à nní ìmọ̀lára bí Ètùtù Olùgbàlà ṣe nsọ̀ wá di òmìnira kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ìjìyà.

“Kò Sí Ohunkankan Tí ó Lè Tayọ kí ó sì Dùn”

Ro ìrírí ti Álmà nínú Ìwé ti Mọ́mọ́nì Ó ti “gbó pẹ̀lú oró ayéraye,” ẹ̀mí rẹ̀ sì “fòro” nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbàtí ó yí sí Olùgbàlà fún àánú, òun “kò lè rántí ìrora [rẹ̀] mọ́.”14

“Àti pe ah, irú ayọ̀,” ó kéde, “àti pé irú ìmọ́lẹ̀ ìyanu wo ni èmi rí; bẹ́ẹ̀ni, … kò sí ohun tí ó lè tayọ adùn àti ayọ̀ tí mo ní.”14

Èyí ni irú ayọ̀ tí ó wà fún àwọn tí wọ́n wá sọ́dọ̀ Jésù Krístì nípasẹ̀ ìrònúpìwàdà.15 Ààrẹ Russell M. Nelson ti kọ́ni:

“Ìrònúpìwàdà nṣí ààyè wa sí agbára Ètùtù ti Jésù Krístì. …

Nígbàtí a bá yàn láti ronúpìwàdà, a lè yàn láti yípadà! A nfàyè gba Olùgbàlà láti yí wa padà sínú ẹ̀yà arawa tó dárajùlọ. A yàn láti dàgbà ní ti ẹ̀mí kí a sì gba ayọ̀—ayọ̀ ìràpadà nínú Rẹ̀. Nígbàtí a yàn láti ronúpìwàdà, a yàn láti dàbíi ti Jésù Krístì síi!”9

Ìrònúpìwàdà nmú ayọ̀ wá nítorí ó nmúra ọkàn wa sílẹ̀ láti gba okun Ẹ̀mí Mímọ́. Láti kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ túmọ̀sí láti kún fún ayọ̀. Láti kún fún ayọ̀ túmọ̀ sí láti kún fún Ẹ̀mí Mímọ́.18 Ayọ̀ wa npọ̀si bí a ti nṣiṣẹ́ ojojúmọ́ láti mú Ẹ̀mí wá sínú ayé wa. Bí a ti kọ́ni látẹnu wòlíì Mọ́mọ́nì, “Bíótilẹ̀ríbẹ́ẹ̀ wọ́n gbàwẹ̀ wọ́n sì gbàdúrà nígbàkugbà, wọ́n sì túbọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ síi, wọ́n sì túbọ̀ dúró ṣinṣin síi ní ìgbàgbọ́ [wọn] [nínú] Krístì, títí ọkàn wọn fi kún fún ayọ̀ àti ìtùnú.”19 Oluwa ṣe ìlérí fún gbogbo àwọn ẹnití wọ́n bá ṣiṣẹ́ láti tẹ̀le, “Èmi ó fi fún yín … Ẹ̀mí mi, èyí tí yíò fi òye fún ọkàn yín, tí yíò kún ọkàn yín fún ayọ̀.”20

Ayọ Ríran àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́ láti Ronúpìwàdà

Lẹ́hìn tí a bá ti ní ìmọ̀lára ayọ̀ tí ó nwa látinú ìronúpìwàdà àtinúwá, a máa nfẹ́ láti pín ayọ̀ náà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Àti pé nígbàtí a bá ṣeé, ayọ̀ wa npọ̀si. Ohun to ṣẹlẹ̀ sí Álmà gan an nìyẹn.

“Èyí sì ni ògo mi,” ó wípé, “pé bóyá èmi lè jẹ́ ohun èlò ní ọwọ́ Ọlọ́run láti mú àwọn ẹ̀mí díẹ̀ wá sí ìrònúpìwàdà; èyí sì ni ayọ̀ mi.

“Sì kíyèsĩ, nígbàtí mo bá rí púpọ̀ nínú àwọn arákùnrin mi pé nwọ́n ti ronúpìwàdà nítoótọ́, tí nwọ́n sì wá sí ọ̀dọ̀ Olúwa Ọlọ́run nwọn, ìgbàyĩ ni ọkàn mi kún fún ayọ̀; tí èmi sì rántí ohun tí Olúwa ti ṣe fún mi, … bẹ̃ni, àní tí ó ti gbọ́ àdúrà mi, bẹ̃ni, ìgbànã ni èmi rántí ọwọ́ ãnú rẹ̀ èyítí ó ti nà [sí] mi.”21

Ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti ronúpìwàdà ni ìwò àdánidá ti ìmoore wa níwájú Olùgbàlà; òun sì ni orísun ayọ̀ nlá. Olúwa ti ṣe ìlérí:

“Bí ó bá sì rí bẹ́ẹ̀ pé ẹ̀yin … tí ẹ̀yin sì mú, bí ó ṣe ọkàn kan péré wá sí ọ̀dọ̀ mi, báwo ni ayọ̀ yín yíò ṣe pọ̀ tó pẹ̀lú rẹ̀ ní ìjọba Baba mi!

Àti nísisìyí, bí ayọ̀ yín yíò bá pọ̀ pẹ̀lú ọkàn kan tí ẹ̀yin mú wá sí ọ̀dọ̀ mi … , báwo ni ayọ̀ yín yíò ṣe pọ̀ tó bí ẹ̀yin bá lè mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkàn wá sí ọ̀dọ̀ mi!”22

Bí Ayọ̀ Rẹ̀ Ti Tóbi nínú Ẹ̀mí Tí Ó Ronúpìwàdà

Mo ri bí ìrànlọ́wọ́ láti gbìyànjú láti ro ayọ̀ tí Olùgbàlà gbọ́dọ̀ ti ní ìmọ̀lára ní ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan tí a bá gba àwọn ìbùkún ìrúbọ ètùtù Rẹ̀ sínú ayé wa.23 Bí a ti sọọ́ nípa Ààrẹ Nelson,22 Àpóstélì Páùlù nínú lẹ́tà gígun rẹ̀ sí àwọn Heberu pín òye jẹ́jẹ́ yí: “Ẹ gbé gbogbo … ẹ̀ṣẹ̀ tí ó rọrùn láti dì mọ́ wa sẹgbẹ, … Kí a ma wo Jésù olùpilẹ̀ṣẹ̀ àti aláṣepé ìgbàgbọ́ wa; ẹni tí ó farada agbelebu nítorí ayọ̀ tí a gbé ka iwájú rẹ̀ … tí ó sì joko ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọ́run.”25 A máa nsọ̀rọ̀ léraléra nípa ìrora àti ìjìyà Gẹtsemánì àti Calvary, ṣùgbọ́n kìí fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ ayọ̀ nlá tí Olùgbàlà gbọ́dọ̀ ti gbèrò bí Ó ti fi ayé Rẹ̀ fún wa. Ní kedere, ìrora Rẹ̀ àti ìjìyà Rẹ̀ wà fún wa, kí a lè ní ìrírí ayọ̀ ti pípadà pẹ̀lú Rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

Lẹ́hìn kíkọ́ àwọn ènìyàn ní Àmẹ́ríkà àtijọ́, Olùgbàlà fi ìfẹ́ nlá Rẹ̀ hàn fún wọn nípa sísọ pé:

“Nísisìyí, kíyèsi, ayọ̀ mi kún, àní sí kíkún, nítorí yín … ; bẹ́ẹ̀ni, àní Baba sì yọ̀, àti gbogbo àwọn ángẹ́lì bákannáà. …

“… Nínú [yín] mo [a] ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀ kíkún.”26

Ẹ wá sọ́dọ̀ Krístì kí ẹ sì gba Ayọ̀ Rẹ̀

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin, mo parí nípa pínpín ẹ̀rí araẹni mi, èyí tí mo rò bí ẹ̀bùn mímọ́. Mo jẹ́ ẹ̀rí pé Jésù Krístì ni Olùgbàlà àti Olùràpadà aráyé. Mo mọ̀ pé Ó fẹ́ràn ẹnìkọ̀ọ̀kan wa. Ìdojúkọ Rẹ̀ kanṣoṣo, iṣẹ́ “Rẹ̀ àti ògo [Rẹ̀],”27 ni láti ràn wá lọ́wọ́ láti gba ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ayọ̀ nínú Rẹ̀. Mo jẹ́ ẹlẹri kan pé ríronúpìwàdà ojojúmọ́ àti wíwá sọ́dọ̀ Jésù Krístì ni ọ̀nà láti ní ìrírí ayọ̀—ayọ̀ tí ó kọjá òye wa.28 Èyí ni ìdí tí a fi wà nihin lórí ilẹ̀ ayé. Èyí ni ìdí tí Ọlọ́run fi múra ètò nlá ti ìdùnnú Rẹ̀ fún wa. Jésù Krístì lótítọ́ ni “ọ̀nà, òtítọ́, àti ìyè”29 àti pé “orúkọ kanṣoṣo tí a fúnni lábẹ́ ọ̀run níbití a ti lè gba ènìyàn là ní ìjọba Ọlọ́run.”30 Mo jẹ́ ẹ̀rí bẹ́ẹ̀ ní orúkọ mímọ́ ti Jésù Krístì, àmín.