Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò
Iṣẹ́ ti Tẹ́mpìlì àti Ìtàn Ẹbí Náà—Ọkan àti Iṣẹ́ Kannáà
Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò Oṣù Kẹrin 2023


10:12

Iṣẹ́ ti Tẹ́mpìlì àti Ìtàn Ẹbí Náà—Ọkan àti Iṣẹ́ Kannáà

Gbùngbun ìfojúsùn ti ètò Baba wa Ọ̀run ni dída ẹbí pọ̀ fún ayé yí àti fún ayérayé.

Mo dúpẹ́ fún kíkọ́ ti àwọn tẹ́mpìlì tó nlọ lọ́wọ́ “ní ìgbà iṣẹ́ ìríjú ti kíkún àkókò yí” (Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 128:18). Láti ìgbà àwọn ọjọ́ ìṣaájú ti ìmúpadàbọ̀sípò, àwọn Ènìyàn Mímọ́ ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìrúbọ lati gba àwọn ìlànà àti àwọn májẹ̀mú tẹ́mpìlì. Ní títẹ̀lé àpẹrẹ nlá wọn, ní 1975, lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrúbọ ní ti ètò ọrọ̀ ajé láti rin ìrìn àjò láti Ilú Mexico, ìyàwó mi ọ̀wọ́n, Evelia, àti èmi, tí àwọn òbí wa ọ̀wọ́n tẹ̀lé wa, di sísopọ̀ bíi ọkọ àti ìyàwó ayérayé kan nínú Tẹ́mpìlì Mesa Arizona. Ní ọjọ́ náà, bí a ti fi wa ṣe ọ̀kan nípa àṣẹ ti oyè-àlùfáà nínú ilé Olúwa, nítòótọ́ a ní ìrírí wíwo ọ̀run fírí.

Ìṣẹ́ àti Èrèdí Àwọn Tẹ́mpìlì

Ìrírí náà ti gbà mí láàyè láti mọ rírì ní dáradára síi bí, lẹ́hìn ọdún mẹ́ta ti iṣẹ́ àṣekára àti ìrúbọ nlá, àwọn Ènìyàn Mímọ́ ní Kirtland, Ohio, parí tẹ́mpìlì rírẹwà wọn nígbẹ̀hìn ní ìgbà rírú ewé ti 1836—àkọ́kọ́ ní ìgbà iṣẹ ìríjú yi. Ní Oṣù Kẹta ọdún kannáà, ju ẹgbẹ̀rún kan àwọn ènìyàn péjọ nínú tẹ́mpìlì náà àti ní àwọn ibi àbáwọlé rẹ̀ fún ìsìn ìyàsímímọ́. Wòlíì Joseph Smith dìde láti gba àdúrà ìyàsímímọ́ , èyí tí ó ti gbà nípa ìfihàn (wo Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 109). Nínú rẹ̀ ó ṣe júwe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìbùkún àrà ọ̀tọ̀ tí a fi le orí àwọn wọnnì tí wọ́n bá wọ inú àwọn tẹ́mpìlì Olúwa ní yíyẹ. Nígbànáà àwọn akọrin kọ orin isìn “Ẹmí Ọlọ́run Náà,” gbogbo ìjọ náà sì dìde dúró fún Igbe Hòsánnà “pẹ̀lú irú [agbára bẹ́ẹ̀ tí ó] fi dàbí … láti gbé òrùlé kúrò ní orí ille náà” (Ìkọ́ni àwọn Ààrẹ Ìjọ: Joseph Smith [2007], 307).

Ní ọ̀sẹ̀ kan lẹ́hìnnáà wòlíì ṣe àpèjúwe ìfarahàn Olúwa nínú tẹ́mpìlì náà, ẹnití ó wípé:

“Nítorí kíyèsíi, mo ti tẹ́wọ́ gba ilé yìí, orúkọ mi yíò sì wà níbẹ̀; èmi yíò si fi ara mi hàn sí àwọn ènìyàn mi nìnù àánú nìnù ilé yìí. …

“Òkìkí Ilé yí yíò sì tànká sí àwọn ilẹ̀ òkèèrè; èyí yíò sì jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìbùkún èyí tí a ó dà jáde sórí àwọn ènìyàn mi.”20

Lẹ́hìn èyí àti àwọn ìran mĩràn, wòlíì Elijah, ẹnití a gbà sí ọ̀run láì tọ́ ikú wò, fi ara hàn níwájú Wòlíì Joseph Smith àti Oliver Cowdery ó sì wípé:

“Kíyèsíi, àkókò náà ti dé ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, èyítí a sọ nípa rẹ̀ láti ẹnu Málákì—ní jijẹri pé òun [wòlíì] [Èlíjàh] ni a níláti rán, síwájú ọjọ́ nlá tí ó sì ní ẹ̀rù ti Olúwa tó dé—

“Láti yí ọkàn àwọn baba sí àwọn ọmọ, àti ti awọn ọmọ sí àwọn bàbá, bíbẹ́ẹ̀kọ́ gbogbo ilẹ̀ yío di kíkọlù pẹ̀lú ègún—

“Nítorínáà, àwọn kọ́kọ́rọ́ ìgbà iṣẹ ìríjú yí ni a ti fi sí ọwọ́ yín; àti nípa èyí ni ẹ̀yin yíò lè mọ̀ pé ọjọ́ nlá tí ó sì ní ẹ̀rù ti Olúwa súnmọ́ itòsí, àní ní ẹnu àwọn ilẹ̀kùn.”2

Tẹ́mpìlì àti Ìtàn Ẹbí

Lẹ́hìn tí Olúwa ti mú àwọn kọ́kọ́rọ́ ìsopọ̀ padàbọ̀sípò sí Joseph Smith, iṣẹ́ ìgbàlà ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì ikelè bẹ̀rẹ̀ ní ìgbà iṣẹ ìríjú wa (wo 1 Kọ́rintì 15:22, 29; Ẹ̀kọ́ ati awọn Májẹ̀mú 128:8–18).

Alàgbà Boyd K. Packer kọ́ni pé “ìṣẹ̀lẹ̀ àmì yí kọjá lọ láìfọkànsí lati ọwọ́ àwọn aráyé, ṣùgbọ́n yío ní ipá lórí àyànmọ́ olukúlùkù ọkàn tí ó ti gbé rí tàbí tí yío gbé. Àwọn nkan bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹlẹ̀ ní ìdákẹjẹ́ Ìjọ náà di ìjọ kan tí nkọ́-tẹ́mpìlì.

“Nínú ayé ó njáde nihin àti níbẹ̀, ní ọ̀nà tí a rò pé ó jẹ́ ẹ̀ẹkọ̀ọ̀kan, àwọn ènìyàn àti ìṣètò àti ẹgbẹ́ tí wọ́n ní ìfẹ́ ní wíwá ìtàn ìdílé. Gbogbo èyí ti wáyé láti ìgbà ìfarahàn Èlíjàh nínú Tẹ́mpìlì Kirtland (Tẹ́mpìlì Mímọ́ [1980], 141).

“Láti ọjọ́ náà gan-an, Ọjọ́ Kẹta Oṣù Kẹrin, 1836, ọkàn àwọn ọmọ bẹ̀rẹ̀sí yí sí àwọn bàbá wọn. Lẹ́hìnnáà àwọn ìlànà kìí ṣe fún ìgbà díẹ̀, ṣùgbọ́n pípẹ́ títí. Agbára fífi èdìdi dì wà pẹ̀lú wa; Kò sí àṣẹ fífúnni tí ó tayọ rẹ̀ ní iye. Agbára náà nfi iyì àti pípẹ́ títí ayérayé sí gbogbo àwọn ìlànà tí a bá ṣe pẹ̀lú aṣẹ tó tọ́ fún àwọn alààyè àti òkú” (Mímúra lati Wọ Inú Tẹ́mpìlì Mímọ́ [2002], 28).

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, kíkọ́ àti lílo àwọn tẹ́mpìlì ní ọ̀nà tó dára ti jẹ́ àmì kan ti ìjọ òtítọ́ Jésù Krístì. Lẹ́hìn yíyàsímímọ́ Tẹ́mpìlì Salt Lake ní 1893, Ààrẹ Wilford Woodruff gba àwọn ọmọ ìjọ níyànjú láti wá àwọn àkọsílẹ̀ ti àwọn baban;a wọn àti láti ṣe àkọsílẹ̀ ìtàn ìrandíran wọn nípa lílọ sẹ́hìn jìnnà bí ó bá ti ṣeéṣe tó kí wọn ó le mú àwọn orúkọ wá sí inú tẹ́mpìlì kí wọn ó sì ṣe àwọn ìlànà ìgbàlà àti ìgbéga (wo Ìkọ́ni àwọn Ààrẹ Ìjọ: Wilford Woodruff [2004], 174).

Ìtàn Ẹbí àti Iṣẹ́ Tẹ́mpìlì—Iṣẹ́ Kan

Ní ọdún kan lẹ́hìnwá (1894), Ààrẹ Woodruff kannáà ṣe àmójútó ìdásílẹ̀ Ẹgbé Ìtàn Ìrandíran ti Utah. Ní ọgọ́rũn ọdún lẹ́hìnwá, ní 1994, Alàgbà Russell M. Nelson, ọmọ ẹgbẹ́ iyejú àwọn Àpóstélì Méjìlá nígbànáà sọ pé, “Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ti ọdún onítàn náà ṣe àgbékalẹ̀ ètò ìwádĩ ìtàn ẹbí àti iṣẹ́-ìsìn tẹ́mpìlì bíi iṣẹ́ kan nínú Ìjọ” (“Ẹ̀mí ti Elijah,” Ensign, Nov. 1994, 85).

Iṣẹ́ ìtàn Ẹbí

Ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n, Olúwa ngbà wá níyànjú bíi ọmọ ìjọ ti Ìjọ Rẹ̀ láti ṣe ìpamọ́ ìtàn ẹbí tiwa, láti kọ́ ẹ̀kọ́ láti ara àwọn aṣaájú wa, àti láti ṣe àwọn ètò tí ó bá yẹ fún wọn láti gba àwọn ìlànà ìhìnrere nínú àwọn tẹ́mpìlì láti ràn wọ́n lọ́wọ́ tẹ̀síwájú ní ipa ọ̀nà májẹ̀mú, èyítí yío bùkún wọn pẹ̀lú ẹbí ayérayé kan. Èyí ni ìfojúsùn pàtàkì kan tiètò Baba wa Ọ̀run: ní dída ẹbí pọ̀ fún ayé yí àti fún ayérayé.

Sí ẹ̀yin tí kò ní ìmọ̀lára pé ẹ le ṣe iṣẹ́ yìí, ẹ nílàti mọ̀ pé ẹ kò nìkan wà. Gbogbo wa le yí sí àwọn ohun èlò tí Ìjọ ti pèsè tí a sì le rí ní àwọn ibi Ìwádìí Ẹbí, èyítí a mọ̀ tẹ́lẹ̀ bíi àwọn ibi ìtàn ẹbí. Àwọn Ibi ǐwádìí Ẹbí wọ̀nyí ni a ti ṣe kí ó le jẹ́ pé ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ gbogbo olukúlùkù, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ díẹ̀, le wá ìwífúnni ti àwọn babanla wọn kí wọn ó sì ṣètò rẹ̀ dáradára kí wọn ó le mú un lọ sí ilé Olúwa. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ kàn sí àwọn àjùmọpérò ní wọ́ọ̀dù tàbí ẹ̀ka yín ẹnití yío tọ́ yín ní olukúlùkù ìgbésẹ̀ ti ọ̀nà náà.

Bí a ti ntẹ̀lé ìtọ́ni àwọn wòlíì tí a sì nkọ́ ẹ̀kọ́ nípa bí a ó ti ṣe ìtàn ẹbí wa kí a sì ṣe àwọn ìlànà tẹ́mpìlì fún àwọn aṣaájú wa, a ó ní ìrírí ayọ̀ nlá dé ibi pé a kò ní fẹ́ láti dáwọ́ dúró ní síṣe rẹ̀. Ẹmí yío kún ọkàn wa, yío ta àwọn èrò orí wa jí láti ṣe é, yío sì tọ́ wa sọ́nà bí a ti nwá àwọn orúkọ àwọn aṣaájú wa. Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́kí a rántí pé ìtàn ẹbí ju kí a kàn wá kiri fún àwọn orúkọ, àwọn ònkà ọjọ́, àti àwọn ibi ìṣẹ̀lẹ̀ lọ. Ó jẹ́ dída àwọn ẹbí pọ̀ àti níní ìmọ̀lára ayọ̀ tí ó nwá láti inú nínawọ́ àwọn ìlànà ìhìnrere sí wọn.

Mo fẹ́ràn ìkọ́ni onímísí ti àyànfẹ́ wòlíì wa, Ààrẹ Russell M. Nelson, ẹnití ó wí pé: “Tẹ́mpìlì wà ní oókan ìfúnlókun ìgbàgbọ́ wa àti ìtìlẹ́hìn ti-ẹ̀mí nítorí Olùgbàlà àti ẹ̀kọ́ Rẹ̀ jẹ́ ọkàn tẹ́mpìlì gan-an. Ohun gbogbo tí a nkọ́ni ní tẹ́mpìlì, nípasẹ̀ ìkọ́ni àti nípasẹ̀ Ẹmí, nmú òye wa nípa Jésù Krístì pọ̀ síi. Àwọn ìlànà pàtàkì Rẹ̀ nso wá mọ́ Ọ nípasẹ̀ àwọn májẹ̀mú mímọ́ oye-àlùfáà. Nígbànáà, bí a ti npa àwọn májẹ̀mú wa mọ́, Ó nfún wa ní agbára ìfùnnilókun ìwòsàn Rẹ̀ ” (“Tẹ́mpìlì Náà àti Ìpìnlẹ̀ Ti-ẹ̀mí Yín,” Liahona, Nov. 2021, 93–94).

Dájúdájú, Iṣẹ́ ti tẹ́mpìlì àti ìtàn ẹbí jẹ́ ọ̀kan àti iṣẹ́ kannáà ní Ìjọ.

Mo jẹ́rí sí àwọn òtítọ́ wọ̀nyí Mo mọ̀ pé èyí ni Ìjọ ti Olúwa Jésù Krístì, Olùgbàlà àti Olùràpadà wa, ẹnití a nrántí ti a sì njọ́sìn ní àkókò Ajínde yìí. Mo mọ̀ pé Ó fẹ́ràn wa, àti pé nígbàtí a bá pa àwọn májẹ̀mú wa mọ́ tí a sì fi ìgbẹkẹ̀lé wa sí inú Rẹ̀, Òun yío fún wa ní ẹ̀bùn pẹ̀lú agbára ìwòsàn àti ìfunnilókun Rẹ̀. Ní orúkọ Jésù Krístì, àmín.